Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Olóòótọ́ Nínú Ayé Aláìṣòótọ́ Yìí

Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Olóòótọ́ Nínú Ayé Aláìṣòótọ́ Yìí

Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Olóòótọ́ Nínú Ayé Aláìṣòótọ́ Yìí

BÍ AFẸ́FẸ́ tá à ń mí símú ṣe wà níbi gbogbo, bẹ́ẹ̀ náà ni àìṣòótọ́ ṣe gbilẹ̀ kárí ayé. Àwọn èèyàn máa ń purọ́, wọ́n máa ń ṣèrú nídìí ọjà, wọ́n máa ń jalè, wọ́n kì í fẹ́ san gbèsè, wọ́n sì máa ń fi èrú tí wọ́n ṣe nídìí òwò yangàn. Bá a ti ń gbé láàárín irú àwọn èèyàn wọ̀nyí, a sábà máa ń dojú kọ àwọn ipò tó ń mú kó ṣòro fún wa láti jẹ́ olóòótọ́. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ tí a kò fi ní fẹ́ láti hùwà àìṣòótọ́? Ẹ jẹ́ ká gbé ohun pàtàkì mẹ́ta tó máa ràn wá lọ́wọ́ yẹ̀ wò. Àwọn ni ìbẹ̀rù Jèhófà, ẹ̀rí ọkàn rere àti ìtẹ́lọ́rùn.

Ní Ìbẹ̀rù Tó Tọ́ fún Jèhófà

Wòlíì Aísáyà kọ̀wé pé: “Jèhófà ni Onídàájọ́ wa, Jèhófà ni Ẹni tí ń fún wa ní ìlànà àgbékalẹ̀, Jèhófà ni Ọba wa.” (Aísá. 33:22) Mímọyì ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí aláṣẹ máa ń mú kéèyàn ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, ó sì máa mú kéèyàn pinnu pé òun kò ní hùwà àìṣòótọ́. Òwe 16:6 sọ pé: “Nípa ìbẹ̀rù Jèhófà, ènìyàn a yí padà kúrò nínú ohun búburú.” Irú ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ìbẹ̀rù jìnnìjìnnì torí kí Ọlọ́run kan tó máa ń ránró má bàa fìyà jẹni, bí kò ṣe pé ká máa ṣàníyàn nípa bí a kò ṣe ní ṣe ohun tí inú Baba wa ọ̀run kò dùn sí, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ohun tó máa ṣe wá láǹfààní ló ń fẹ́ fún wa.—1 Pét. 3:12.

Ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí tọkọtaya kan jẹ́ ká rí bí ìbẹ̀rù tàbí àníyàn láti ṣe ohun tó wu Jèhófà yìí ṣe lè yọrí sí ibi tó dára. Ricardo àti ìyàwó rẹ̀ Fernanda ni tọkọtaya náà. Wọ́n gba owó tó tó ọgọ́rùn-ún méje dọ́là ilẹ̀ Amẹ́ríkà látinú àkáǹtì wọn tó wà ní báńkì. * Fernanda ò ka owó náà tó fi kó o sínú pọ́ọ̀sì rẹ̀. Àmọ́, nígbà tí wọ́n délé lẹ́yìn tí wọ́n ti ná lára owó náà, ó yà wọ́n lẹ́nu láti rí i pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé iye tí wọ́n gbà ní báńkì ni wọ́n ṣì bá nínú pọ́ọ̀sì Fernanda. Ibi tí wọ́n parí ọ̀rọ̀ náà sí ni pé: “Ó ti ní láti jẹ́ pé ńṣe ni akọ̀wé báńkì náà ṣi owó san fún wa.” Ó kọ́kọ́ ṣe wọ́n bíi pé kí wọ́n tọ́jú owó náà, torí gbèsè ṣì pọ̀ nílẹ̀ tí wọn kò tíì san. Ricardo ṣàlàyé pé: “A gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún wa lókun ká lè dá owó náà pa dà. Ìfẹ́ tá a ní láti ṣe ohun tó wù ú ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó rọ̀ wá pé ká ṣe nínú Òwe 27:11 ló mú ká fẹ́ láti dá owó náà pa dà.”

Ẹ̀rí Ọkàn Tá A Fi Bíbélì Kọ́

A lè kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa kó lè máa ṣiṣẹ́ lọ́nà tó tọ́ nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ká sì máa sapá láti fi àwọn nǹkan tá à ń kọ́ sílò. Nípa bẹ́ẹ̀, ‘ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tó yè, tó sì ń sa agbára,’ á wọ inú èrò inú wa àti inú ọkàn wa. Èyí á wá mú ká “máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.”—Héb. 4:12; 13:18.

Tún gbé ọ̀ràn ti João yẹ̀ wò. Gbèsè tó ṣẹ́ jọ sí í lọ́rùn tó ẹgbẹ̀rún márùn-ún dọ́là owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Lẹ́yìn náà, ó kó lọ sí ìlú mìíràn láì san gbèsè tó jẹ. Ní ọdún mẹ́jọ lẹ́yìn náà, João kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tá a ti fi Bíbélì kọ́ sì sún un láti kàn sí ilé iṣẹ́ tó jẹ ní gbèsè, ó sì san gbèsè náà! Torí pé owó kékeré ló ń wọlé fún João tó sì ní láti gbọ́ bùkátà ìyàwó rẹ̀ àti ọmọ mẹ́rin, ilé iṣẹ́ náà gbà pé kó máa san owó náà díẹ̀díẹ̀ lóṣooṣù.

Ìtẹ́lọ́rùn

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ó jẹ́ ọ̀nà èrè ńlá, àní fífọkànsin Ọlọ́run pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí ohun-moní-tómi. . . . Bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.” (1 Tím. 6:6-8) Bá a bá fi ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n yìí sọ́kàn, kò ní jẹ́ ká kó sínú páńpẹ́ ìwọra, iṣẹ́ ajé tí ń kọni lóminú tàbí òwò tó lè sọni di olówó òjijì. (Òwe 28:20) Bí a bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù, ó tún máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa fi Ìjọba Ọlọ́run sí ipò kìíní, a ó sì ní ìdánilójú pé Ọlọ́run máa pèsè àwọn ohun tó jẹ́ kòṣeémánìí fún wa.—Mát. 6:25-34.

Àmọ́ ṣá o, torí “agbára ìtannijẹ ọrọ̀,” kò yẹ ká fojú kékeré wo ewu tó wà nínú jíjẹ́ kí ìwọra àti ojúkòkòrò borí wa. (Mát. 13:22) Rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ákáánì. Ó ṣojú rẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì la Odò Jọ́dánì kọjá lọ́nà ìyanu. Síbẹ̀, ìwọra borí rẹ̀, torí pé ó ṣe ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ nípa jíjí fàdákà àti góòlù díẹ̀ àti ẹ̀wù olówó-ńlá kan lára àwọn ohun ìfiṣèjẹ tí wọ́n rí ní ìlú Jẹ́ríkò. Ìwà tó hù yẹn yọrí sí ikú fún un. (Jóṣ. 7:1, 20-26) Abájọ tó fi jẹ́ pé ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn náà, Jésù kìlọ̀ pé: “Ẹ la ojú yín sílẹ̀, kí ẹ sì máa ṣọ́ra fún gbogbo onírúurú ojúkòkòrò”!—Lúùkù 12:15.

Jẹ́ Olóòótọ́ Níbi Iṣẹ́

Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ohun tó lè mú kó ṣòro fún wa láti máa jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo. Lára ohun tó wé mọ́ jíjẹ́ olóòótọ́ níbi iṣẹ́ ni pé ká “má jalè” kódà bó bá jẹ́ pé ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe nìyẹn. (Títù 2:9, 10) Jurandir, tó ń ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ aṣojú ìjọba kì í ṣe awúrúju tó bá ń jábọ̀ bó ṣe rìnrìn-àjò. Àmọ́, àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ máa ń bù lé owó tí wọ́n ná. Àyà ò sì fò wọ́n láti ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé ẹni tó jẹ́ ọ̀gá ní ẹ̀ka tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ máa ń bo àṣírí àwọn òṣìṣẹ́ tó jẹ́ aláìṣòótọ́. Kódà, ọ̀gá yẹn tiẹ̀ bá Jurandir wí torí pé ó jẹ́ olóòótọ́ kò sì rán an jáde mọ́. Nígbà tó ṣe, wọ́n ṣe àyẹ̀wò àkáǹtì ilé iṣẹ́ aṣojú ìjọba náà, wọ́n sì gbóríyìn fún Jurandir torí pé ó jẹ́ olóòótọ́. Kódà, wọ́n fún un ní ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́.

Iṣẹ́ ọjà títà ni André ń ṣe. Ẹni tó gbà á síṣẹ́ sọ fún un pé bí àwọn oníbàárà bá rajà lẹ́ẹ̀kan, kó dọ́gbọ́n sí i kí wọ́n lè sanwó ọjà náà nígbà méjì. Arákùnrin wa gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún òun ní ìgboyà kóun lè máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì. (Sm. 145:18-20) Ó tún gbìyànjú láti ṣàlàyé ìdí tí kò fi ní lè tẹ̀ lé ìtọ́ni náà fún ẹni tó gbà á síṣẹ́, àmọ́ pàbó ló já sí. Torí náà, André pinnu láti fi iṣẹ́ tó ń mówó gọbọi wọlé náà sílẹ̀. Àmọ́, ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà, ọ̀gá rẹ̀ yìí ní kó pa dà sẹ́nu iṣẹ́, ó sì mú kó dá a lójú pé àwọn kò fá àwọn oníbàárà àwọn lórí bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Wọ́n fún André ní ìgbéga, ó sì di ọ̀gá ní ilé iṣẹ́ náà.

San Gbèsè Tó O Bá Jẹ

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni nímọ̀ràn pé: “Kí ẹ má ṣe máa jẹ ẹnikẹ́ni ní gbèsè ẹyọ ohun kan.” (Róòmù 13:8) A lè máa rò pé kò sí ohun tó burú níbẹ̀ bí a kò bá san gbèsè tá a jẹ ẹnì kan torí pé onítọ̀hún rí já jẹ, kò sì nílò owó náà. Àmọ́, Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé: “Ẹni burúkú ń yá nǹkan, kì í sì í san án padà.”—Sm. 37:21.

Bó bá wá ṣẹlẹ̀ pé “ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” mú ká má lè san ohun tá a jẹ gbèsè rẹ̀ pa dà ńkọ́? (Oníw. 9:11) Francisco yá owó tí ó tó ẹgbẹ̀rún méje dọ́là owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà lọ́wọ́ Alfredo láti fi san owó ilé tó rà. Àmọ́ torí àwọn ìjákulẹ̀ kan tí Francisco ní lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀, kò ṣeé ṣe fún un láti san owó náà pa dà lọ́jọ́ tó dá. Ló bá tọ Alfredo lọ kí wọ́n lè jùmọ̀ jíròrò ọ̀rọ̀ náà, Alfredo sì gbà pẹ̀lú rẹ̀ pé kó máa san owó náà pa dà díẹ̀díẹ̀.

Má Ṣe Mú Káwọn Míì Ní Èrò Òdì

Rántí àpẹẹrẹ búburú tí tọkọtaya kan fi lélẹ̀ nínú ìjọ Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní, ìyẹn Ananíà àti Sáfírà. Wọ́n ta pápá kan tó jẹ́ tiwọn, wọ́n mú lára owó pápá náà wá sọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì. Àmọ́, wọ́n sọ fún wọn pé gbogbo owó táwọn ta pápá náà làwọn mú wá. Wọ́n fẹ́ fi ìwà ọ̀làwọ́ tí kò dénú náà ṣe fọ́rífọ́rí fáwọn ẹlòmíì. Àmọ́, lábẹ́ ìdarí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, àpọ́sítélì Pétérù túdìí àṣírí ìwà ẹ̀tàn tí wọ́n hù, Jèhófà sì pa wọ́n.—Ìṣe 5:1-11.

Ọ̀ràn ti àwọn tó kọ Bíbélì yàtọ̀ sí ti Ananíà àti Sáfírà torí pé òótọ́ pọ́ńbélé ni wọ́n sọ. Mósè kò purọ́ kankan nígbà tó ṣe àkọsílẹ̀ bó ṣe bínú tí ìyẹn sì jẹ́ kó pàdánù àǹfààní tó ní láti dé Ilẹ̀ Ìlérí. (Núm. 20:7-13) Bákan náà, Jónà kò fojú pa àwọn ìkùdíẹ̀ káàtó tó ní ṣáájú àti lẹ́yìn tó ti wàásù fáwọn ará Nínéfè rẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó kọ wọ́n sílẹ̀.—Jónà 1:1-3; 4:1-3.

Dájúdájú, ó gba ìgboyà kéèyàn tó lè sọ òtítọ́ kódà bó bá máa náni ní ohun kan, gẹ́gẹ́ bó ṣe rí nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọmọ ọdún mẹ́rìnlá kan tó ń jẹ́ Nathalia, nílè ẹ̀kọ́. Ó ṣe àyẹ̀wò ìdánwò kan tó ṣe nílé ìwé ó sì kíyè sí i pé òun kò gba ọ̀kan lára ìdáhùn tí olùkọ́ rẹ̀ sọ pé ó gbà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Nathalia mọ̀ pé èyí máa já máàkì òun wá sílẹ̀, kò lọ́ tìkọ̀ láti sọ fún olùkọ́ rẹ̀. Ó sọ pé: “Gbogbo ìgbà làwọn òbí mi máa ń kọ́ mi pé bí mo bá fẹ́ ṣe ohun tó dùn mọ́ Jèhófà nínú mi ò gbọ́dọ̀ purọ́. Ẹ̀rí ọkàn mi ì bá dà mí láàmú ká sọ pé mi ò sọ fún olùkọ́ mi.” Inú olùkọ́ náà dùn pé Nathalia jẹ́ olóòótọ́.

Jíjẹ́ Olóòótọ́ Máa Ń Gbé Orúkọ Jèhófà Ga

Giselle, ọmọbìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, rí àpamọ́wọ́ kan tó ní àwọn ìwé pàtàkì nínú àti owó tó tó dọ́là márùndínlógójì [35]. Ó mú àpamọ́wọ́ náà lọ sọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ ilé ìwé kí wọ́n lè dá a pa dà fún ẹni tó ni ín. Ní oṣù kan lẹ́yìn náà, igbá kejì ọ̀gá ilé ìwé náà ka lẹ́tà kan fún gbogbo kíláàsì, èyí tí wọ́n fi dúpẹ́ lọ́wọ́ Giselle torí pé ó jẹ́ olóòótọ́, wọ́n sì tún gbóríyìn fún àwọn òbí rẹ̀ tó fi ẹ̀kọ́ rere àti ìbẹ̀rù Ọlọ́run kọ́ ọ. “Iṣẹ́ àtàtà” rẹ̀ gbé orúkọ Jèhófà ga.—Mát. 5:14-16.

Ó gba ìsapá kéèyàn tó lè jẹ́ olóòótọ́ láàárín àwọn tó jẹ́ ‘olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera àti aláìdúróṣinṣin.’ (2 Tím. 3:2) Síbẹ̀, ìbẹ̀rù tó tọ́ fún Jèhófà, ẹ̀rí ọkàn tá a fi Bíbélì kọ́ àti ìtẹ́lọ́rùn á mú kó ṣeé ṣe fún wa láti jẹ́ olóòótọ́ nínú ayé aláìṣòótọ́ yìí. A óò túbọ̀ ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, tó jẹ́ ‘olódodo tó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn ìṣe òdodo.’—Sm. 11:7.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ìbẹ̀rù tó tọ́ fún Jèhófà máa jẹ́ kí ìpinnu wa láti jẹ́ olóòótọ́ túbọ̀ lágbára

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Bá a ṣe jẹ́ olóòótọ́ ń gbé orúkọ Jèhófà ga