Ǹjẹ́ Ò Ń Fòye Mọ Ẹ̀rí Tó Fi Hàn Pé Ọlọ́run Ń Tọ́ Wa Sọ́nà?
Ǹjẹ́ Ò Ń Fòye Mọ Ẹ̀rí Tó Fi Hàn Pé Ọlọ́run Ń Tọ́ Wa Sọ́nà?
ÀWỌN ọmọ Ísírẹ́lì àti àwọn ará Íjíbítì kò tíì rí irú rẹ̀ rí. Kí ni nǹkan náà? Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ń jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, ọwọ̀n àwọsánmà kan fara hàn nítòsí wọn, ó sì ń wà pẹ̀lú wọn lójoojúmọ́. Bó bá di alẹ́, á di ọwọ̀n iná. Ohun àgbàyanu mà lèyí o! Àmọ́ ibo ni ọwọ̀n náà ti wá? Kí ló wà fún? Ní báyìí tó sì ti tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ [3,500] ọdún sẹ́yìn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé, kí la lè rí kọ́ látinú ojú táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi wo “ọwọ̀n iná àti àwọsánmà náà”?—Ẹ́kís. 14:24.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ká mọ orísun ọwọ̀n náà àti ohun tó wà fún, ó sọ pé: “Jèhófà sì ń lọ níwájú wọn ní ìgbà ọ̀sán nínú ọwọ̀n àwọsánmà láti ṣamọ̀nà wọn lójú ọ̀nà náà, àti ní òru nínú ọwọ̀n iná láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ láti máa lọ ní ìgbà ọ̀sán àti ìgbà òru.” (Ẹ́kís. 13:21, 22) Jèhófà Ọlọ́run lo ọwọ̀n iná àti ti àwọsánmà náà láti ṣamọ̀nà àwọn èèyàn rẹ̀ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì àti nínú aginjù. Wọ́n gbọ́dọ̀ wà ní ìmúratán láti gbéra kí wọ́n bàa lè máa tẹ̀ lé ọwọ̀n náà. Nígbà tó kù díẹ̀ kí àwọn ọmọ ogun Íjíbítì tó ń lépa àwọn èèyàn Ọlọ́run gbéjà kò wọ́n, ọwọ̀n náà wá sáàárín àwùjọ méjèèjì, Ọlọ́run sì tipa bẹ́ẹ̀ dáàbò bo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Ẹ́kís. 14:19, 20) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ̀n náà kò darí wọn gba ọ̀nà tó yá jù, síbẹ̀ ọ̀nà kan ṣoṣo táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi lè dé Ilẹ̀ Ìlérí ni pé kí wọ́n máa tẹ̀ lé e.
Bí ọwọ̀n yẹn ṣe ń ṣamọ̀nà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ẹ̀rí pé Jèhófà wà pẹ̀lú wọn. Jèhófà ni ọwọ̀n náà ń ṣojú fún, ó sì máa ń bá wọn sọ̀rọ̀ láti inú rẹ̀ wá nígbà míì. (Núm. 14:14; Sm. 99:7) Síwájú sí i, àwọsánmà náà mú kó ṣe kedere pé Mósè ni ẹni tí Jèhófà yàn láti máa darí orílẹ̀-èdè náà. (Ẹ́kís. 33:9) Bákan náà, nígbà tí àwọsánmà náà fara hàn kẹ́yìn bí Ìwé Mímọ́ ṣe sọ, ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Jèhófà ti yan Jóṣúà láti rọ́pò Mósè. (Diu. 31:14, 15) Torí náà, kí jíjáde táwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì tó lè yọrí sí rere, wọ́n gbọ́dọ̀ fòye mọ ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run ń tọ́ wọn sọ́nà lẹ́yìn náà kí wọ́n tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀.
Wọ́n Gbàgbé Pé Ọlọ́run Ló Ń Tọ́ Wọn Sọ́nà
Kàyéfì ló ní láti jẹ́ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ rí ọwọ̀n náà. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé ohun ìyanu táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fojú rí kòrókòró yẹn kò wọ̀ wọ́n lọ́kàn débi tí ìgbẹ́kẹ̀lé wọn nínú Jèhófà fi máa wà pẹ́ títí. Wọ́n ṣiyè méjì nípa ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run lọ́pọ̀ ìgbà. Nígbà táwọn ọmọ ogun Íjíbítì ń lépa wọn, wọn kò fi hàn pé àwọn ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú agbára tí Jèhófà ní láti gbà wọ́n là. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n fi ẹ̀sùn kan Mósè tó jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run pé ńṣe ló fẹ́ lọ pa àwọn. (Ẹ́kís. 14:10-12) Lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti mú kí wọ́n la Òkun Pupa já, wọ́n kùn sí Mósè, Áárónì àti Jèhófà nípa ṣíṣe àwáwí pé kò sí oúnjẹ àti omi. (Ẹ́kís. 15:22-24; 16:1-3; 17:1-3, 7) Ní ọ̀sẹ̀ mélòó kan lẹ́yìn yẹn, wọ́n fúngun mọ́ Áárónì débi tó fi ṣe ère ọmọ màlúù kan fún wọn. Ó mà ga o! Ní apá kan àgọ́ wọn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń rí ọwọ̀n iná àti ti àwọsánmà tó jẹ́ ẹ̀rí àgbàyanu tó ń fi hàn pé Ẹni tó mú wọn jáde ní ilẹ̀ Íjíbítì wà pẹ̀lú wọn. Nítòsí ibẹ̀ náà ni wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn òòṣà tí kò lẹ́mìí, tí wọ́n ń wí pé: “Ìwọ Ísírẹ́lì, èyí ni Ọlọ́run rẹ tí ó mú ọ gòkè kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.” “Ìwà àìlọ́wọ̀ ńláǹlà” mà lèyí o!—Ẹ́kís. 32:4; Neh. 9:18.
Ìwà ọ̀tẹ̀ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì hù yìí fi hàn gbangba pé wọn kò ka ìtọ́sọ́nà Jèhófà sí rárá. Sm. 78:40-42, 52-54; Neh. 9:19.
Wọ́n ti fi ojú ara wọn rí ohun tó pọ̀ tó láti mú kí wọ́n ní ìgbọ́kànlé nínú Ọlọ́run, àmọ́ ó ṣòro fún wọn láti gbà pé Jèhófà ló ń láti darí wọn àti pé ó yẹ kí wọ́n máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀. Wọ́n rí ọwọ̀n tó jẹ́ àpẹẹrẹ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú wọn, àmọ́ wọn kò mọyì bí Ọlọ́run ṣe ń lò ó láti tọ́ wọn sọ́nà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì hù yìí “dun Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì,” Jèhófà ṣì ń fi àánú hàn sí wọn nípa fífi ọwọ̀n náà tọ́ wọn sọ́nà títí tí wọ́n fi dé Ilẹ̀ Ìlérí.—Fi Òye Mọ Ẹ̀rí Tó Fi Hàn Pé Ọlọ́run Ń Tọ́ Wa Sọ́nà Lónìí
Bákan náà lónìí, Jèhófà kò jẹ́ fi àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ láì fún wọn ní ìtọ́sọ́nà tó ṣe kedere. Bí kò ṣe retí pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá ojú ọ̀nà tí wọ́n máa gbà fúnra wọn, bẹ́ẹ̀ náà ni kò retí pé kí àwa pẹ̀lú wá ọ̀nà tá a lè gbà dé inú ayé tuntun tó ṣèlérí náà fúnra wa. Ọlọ́run ti yan Jésù Kristi láti jẹ́ Aṣáájú ìjọ. (Mát. 23:10; Éfé. 5:23) Jésù ti fún ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ ti àwọn Kristẹni olùṣòtítọ́ tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró ní díẹ̀ lára àṣẹ tó ní. Ẹgbẹ́ ẹrú yìí pẹ̀lú sì ti yan àwọn alábòójútó sípò nínú ìjọ Kristẹni.—Mát. 24:45-47; Títù 1:5-9.
Báwo ló ṣe lè dá wa lójú pé a ti mọ ẹni tí ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ tàbí ìríjú náà jẹ́? Kíyè sí bí Jésù fúnra rẹ̀ ṣe ṣàpèjúwe ẹrú náà: “Ní ti tòótọ́, ta ni olóòótọ́ ìríjú náà, ẹni tí í ṣe olóye, tí ọ̀gá rẹ̀ yóò yàn sípò lórí ẹgbẹ́ àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ láti máa fún wọn ní ìwọ̀n ìpèsè oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu? Aláyọ̀ ni ẹrú yẹn, bí ọ̀gá rẹ̀ nígbà tí ó dé bá rí i tí ó ń ṣe bẹ́ẹ̀!”—Lúùkù 12:42, 43.
Nítorí náà, ẹgbẹ́ ìríjú náà jẹ́ “olóòótọ́,” ní ti pé kì í ṣe ohun tó ta ko Jèhófà, Jésù, òtítọ́ Bíbélì tàbí àwọn èèyàn Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ sì ni kò jẹ́ kọ̀ wọ́n sílẹ̀. Níwọ̀n bí ẹgbẹ́ ìríjú náà sì ti jẹ́ “olóye,” ó ń fòye darí iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ, ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù “ìhìn rere ìjọba” Ọlọ́run àti sísọ “àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mát. 24:14; 28:19, 20) “Ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu,” ẹgbẹ́ ìríjú tó jẹ́ onígbọràn yìí ń pín oúnjẹ tẹ̀mí tó gbámúṣé tó sì ń ṣara lóore fún àwọn èèyàn Jèhófà. A sì rí ẹ̀rí tó fi hàn pé Jèhófà tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ tí ẹgbẹ́ ẹrú yìí ń ṣe ní ti pé Ó ń mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ pọ̀ sí i, ó ń tọ́ wọn sọ́nà bí wọ́n ti ń ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì, ó ń mú kí wọ́n túbọ̀ lóye òtítọ́ Bíbélì, ó ń dáàbò bò wọ́n kí àwọn ọ̀tá wọn má bàa pa wọ́n run, ó sì tún fi àlàáfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn jíǹkí wọn.—Aísá. 54:17; Fílí. 4:7.
Jẹ́ Kí Ọlọ́run Máa Tọ́ Ẹ Sọ́nà
Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọrírì ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba.” (Héb. 13:17) Ó lè má fìgbà gbogbo rọrùn láti fi ìtọ́ni yìí sílò. A lè ṣàpèjúwe rẹ̀ báyìí: Fi ara rẹ sípò ọmọ Ísírẹ́lì kan nígbà tí Mósè wà láyé. Bóyá ó ṣẹlẹ̀ pé ó ti ṣe díẹ̀ tẹ́ ẹ ti wà lórí ìrìn, àmọ́ nígbà tó yá ọwọ̀n náà dúró. Báwo ló ṣe máa dúró pẹ́ tó? Ṣó máa tó ọjọ́ kan? Ọ̀sẹ̀ kan? Oṣù mélòó kan? O wá ń bi ara rẹ pé, ‘Ṣé kí n tú gbogbo ẹrù mi kalẹ̀ àbí kí n máà tú u?’ Ó ṣeé ṣe kó o kọ́kọ́ kó àwọn ohun tó jẹ́ kòṣeémáàní jáde. Àmọ́, lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan tó ti ń ṣòro láti wá ohun tó o nílò rí, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í kó gbogbo ẹrù yòókù jáde. Ká wá sọ pé bó ṣe ku díẹ̀ kó o kó àwọn ẹrù náà jáde tán ni ọwọ̀n náà gbéra, tó o sì tún ní láti yára kó gbogbo ẹrù náà nílẹ̀ ńkọ́? Ó dájú pé ó máa nira gan-an. Síbẹ̀, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ “ṣí kété lẹ́yìn ìgbà náà.”—Núm. 9:17-22.
Kí ni àwa náà máa ń ṣe bí Jèhófà bá fún wa ní ìtọ́ni? Ṣé “kété lẹ́yìn ìgbà náà” la máa ń tẹ̀ lé ìtọ́ni tó fún wa? Àbí ọ̀nà tó ti mọ́ wa lára láti máa gbà ṣe nǹkan tẹ́lẹ̀ la ṣì máa ń gbà ṣe é? Ṣé a mọ àwọn ìtọ́ni tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ rí gbà dunjú, bóyá àwọn tó ní í ṣe pẹ̀lú dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wíwàásù fún àwọn èèyàn tó ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè, kíkópa nínú Ìjọsìn Ìdílé déédéé, fífi ọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Àwọn Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn àti híhùwà tó bójú mu ní àwọn àpéjọ? A tún lè fi hàn pé a mọrírì ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run nípa gbígba ìmọ̀ràn. Tá a bá ní àwọn ìpinnu pàtàkì láti ṣe, dípò tí a ó fi gbẹ́kẹ̀ lé ọgbọ́n tiwa, ọ̀dọ̀ Jèhófà àti ètò rẹ̀ ló yẹ ká ti gba ìtọ́sọ́nà. Bí ọmọ kan sì
ṣe máa ń wá ààbò lọ sọ́dọ̀ òbí rẹ̀ nígbà tí ìjì bá ń jà, bẹ́ẹ̀ ló ṣe yẹ ká wá ààbò wá sínú ètò Jèhófà bí ìṣòro ayé yìí bá kọ lù wá bí ìjì.Àmọ́ ṣá o, àwọn tó ń múpò iwájú nínú apá tó jẹ́ ti ilẹ̀ ayé lára ètò Ọlọ́run kì í ṣe ẹni pípé bí Mósè pẹ̀lú kì í ti í ṣe ẹni pípé. Síbẹ̀, ọwọ̀n náà ń fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lemọ́lemọ́ pé Ọlọ́run ló yan Mósè sípò àti pé Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà á. Sì tún kíyè sí i pé ọmọ Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan kọ́ ló ń pinnu ìgbà tóun máa ṣí kúrò níbi tí wọ́n wà. Kàkà bẹ́ẹ̀, “àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà nípasẹ̀ Mósè” làwọn èèyàn náà máa ń tẹ̀ lé. (Núm. 9:23) Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Mósè tí Ọlọ́run ń lò láti tọ́ àwọn èèyàn náà sọ́nà ló máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ bí àkókò bá tó láti gbéra.
Lónìí, ẹgbẹ́ ìríjú Jèhófà máa ń fún wa ní ìtọ́ni tó ṣe kedere nígbàkigbà tó bá yẹ ká gbéra. Ọ̀nà wo ni ìríjú náà ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀? Ó jẹ́ nípasẹ̀ àwọn àpilẹ̀kọ inú Ilé Ìṣọ́ àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, àwọn ìtẹ̀jáde tuntun àti àwọn àsọyé tá a máa ń gbọ́ ní àwọn àpéjọ àkànṣe, àyíká àti àgbègbè. A tún máa ń rí ìtọ́ni gbà nínú ìjọ nípasẹ̀ àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò tàbí nípasẹ̀ àwọn lẹ́tà tàbí ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó wà fún àwọn arákùnrin tá a yàn sípò nínú ìjọ.
Ṣé ò ń fi òye mọ ẹ̀rí tó ṣe kedere, èyí tó ń fi hàn pé Ọlọ́run ló ń tọ́ wa sọ́nà? Jèhófà máa ń lo ètò rẹ̀ láti tọ́ àwa èèyàn rẹ̀ sọ́nà ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ayé búburú Sátánì tó dà bí aginjù tó léwu yìí. Látàrí èyí, à ń gbádùn ìṣọ̀kan, ìfẹ́ àti ààbò.
Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì dé Ilẹ̀ Ìlérí, Jóṣúà sọ pé: “Ẹ̀yin sì mọ̀ dáadáa ní gbogbo ọkàn-àyà yín àti ní gbogbo ọkàn yín pé kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín. Gbogbo wọn ti ṣẹ fún yín.” (Jóṣ. 23:14) Bákan náà, kò sí iyè méjì pé àwọn èèyàn Ọlọ́run lónìí máa dé inú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí. Àmọ́ ṣá o, bóyá àwa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa débẹ̀ sinmi púpọ̀ lórí bá a bá ṣe múra tán láti máa fi ìrẹ̀lẹ̀ tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tí Ọlọ́run ń fún wa. Torí náà, ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa bá a nìṣó láti máa fòye mọ ẹ̀rí tó ń fi hàn pé Jèhófà ń tọ́ wa sọ́nà!
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ètò Jèhófà ló ń darí wa lónìí
Àwọn ìwé tó ń jáde ní àpéjọ àgbègbè
Ètò ẹ̀kọ́ ìṣàkóso Ọlọ́run
Ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá