Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀yin Ìdílé Kristẹni—“Ẹ Wà Lójúfò”

Ẹ̀yin Ìdílé Kristẹni—“Ẹ Wà Lójúfò”

Ẹ̀yin Ìdílé Kristẹni​—“Ẹ Wà Lójúfò”

“Ẹ jẹ́ kí a wà lójúfò, kí a sì pa agbára ìmòye wa mọ́.” —1 TẸS. 5:6.

1, 2. Kí ìdílé kan tó lè kẹ́sẹ járí láti wà lójúfò nípa tẹ̀mí, kí ló ṣe pàtàkì pé kí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé náà máa ṣe?

 NÍGBÀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa “ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà” ó sọ nínú ìwé tó kọ sí àwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà pé: “Ẹ̀yin, ará, ẹ kò sí nínú òkùnkùn, tí ọjọ́ yẹn yóò fi dé bá yín lójijì gẹ́gẹ́ bí yóò ti dé bá àwọn olè, nítorí gbogbo yín jẹ́ ọmọ ìmọ́lẹ̀ àti ọmọ ọ̀sán. Àwa kì í ṣe ti òru tàbí ti òkùnkùn.” Pọ́ọ̀lù wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Nítorí bẹ́ẹ̀, ẹ má ṣe jẹ́ kí a máa sùn gẹ́gẹ́ bí àwọn yòókù ti ń ṣe, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a wà lójúfò, kí a sì pa agbára ìmòye wa mọ́.”—Jóẹ́lì 2:31; 1 Tẹs. 5:4-6.

2 Ìtọ́ni tí Pọ́ọ̀lù fún àwọn ará Tẹsalóníkà yẹn jẹ́ èyí tó bágbà mu, pàápàá jù lọ fún àwọn Kristẹni tó ń gbé ní “àkókò òpin.” (Dán. 12:4) Bí òpin ètò àwọn nǹkan búburú Sátánì ṣe ń sún mọ́lé, ó ti pinnu láti mú kí ọ̀pọ̀ àwọn olùjọsìn tòótọ́ kẹ̀yìn sí Ọlọ́run bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé ká fi ọ̀rọ̀ ìṣítí Pọ́ọ̀lù sọ́kàn pé ká máa wà lójúfò nípa tẹ̀mí. Kí ìdílé Kristẹni kan tó lè kẹ́sẹ járí láti wà lójúfò, ó ṣe pàtàkì pé kí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé náà máa ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ṣe lànà rẹ̀ sílẹ̀. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ìdílé lè “wà lójúfò” kí ni ojúṣe ọkọ, aya àti ti àwọn ọmọ?

Ẹ̀yin Ọkọ, Ẹ Máa Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ “Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà”

3. Gẹ́gẹ́ bí 1 Tímótì 5:8 ṣe sọ, kí ni ojúṣe ọkùnrin gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé?

3 Bíbélì sọ pé: “Orí obìnrin ni ọkùnrin.” (1 Kọ́r. 11:3) Gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé, kí ni ojúṣe ọkùnrin? Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Bí ẹnì kan kò bá pèsè fún àwọn tí í ṣe tirẹ̀, àti ní pàtàkì fún àwọn tí í ṣe mẹ́ńbà agbo ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.” (1 Tím. 5:8) Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé kí ọkùnrin pèsè ohun tí ìdílé rẹ̀ nílò nípa tara. Àmọ́ ṣá o, bó bá ní láti ran ìdílé rẹ̀ lọ́wọ́ láti máa wà lójúfò nípa tẹ̀mí, ó gbọ́dọ̀ ṣe kọjá wíwá owó láti fi gbọ́ bùkátà ìdílé. Ó gbọ́dọ̀ gbé agbo ilé rẹ̀ ró nípa tẹ̀mí, kó sì máa ran gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé lọ́wọ́ kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run lè túbọ̀ lágbára. (Òwe 24:3, 4) Báwo ló ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?

4. Kí ló lè mú kí ọkùnrin kan kẹ́sẹ járí láti gbé agbo ilé rẹ̀ ró nípa tẹ̀mí?

4 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé “ọkọ ni orí aya rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti jẹ́ orí ìjọ,” ọkọ gbọ́dọ̀ ṣàgbéyẹ̀wò bí Jésù ṣe lo ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orí ìjọ kó sì máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. (Éfé. 5:23) Ronú nípa bí Jésù ṣe ṣàlàyé àjọṣe tó ní pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. (Ka Jòhánù 10:14, 15.) Kí ló máa mú kí ọkùnrin kan kẹ́sẹ járí láti gbé agbo ilé rẹ̀ ró nípa tẹ̀mí? Ohun náà ni pé kó kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Jésù sọ àti ohun tó ṣe gẹ́gẹ́ bí “olùṣọ́ àgùntàn àtàtà,” kó sì máa “tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.”—1 Pét. 2:21.

5. Kí ni Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà mọ̀ nípa ìjọ?

5 Ohun tó máa ń jẹ́ kí àwọn àgùntàn àti olùṣọ́ àgùntàn mọwọ́ ara wọn dáadáa ni pé olùṣọ́ àgùntàn máa ń mọ gbogbo ohun tó yẹ kó mọ̀ nípa àwọn àgùntàn rẹ̀, àwọn àgùntàn rẹ̀ náà sì máa ń fọkàn tán an. Wọ́n dá ohùn rẹ̀ mọ̀, wọ́n sì máa ń ṣègbọràn sí i. Jésù sọ pé: ‘Mo mọ àwọn àgùntàn mi, àwọn àgùntàn mi sì mọ̀ mí.’ Kì í ṣe ìmọ̀ oréfèé lásán ni Jésù ní nípa ìjọ. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “mọ̀” nínú ẹsẹ yìí túmọ̀ sí “mímọ ẹnì kan ní àmọ̀dunjú.” Torí náà, Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà náà mọ àwọn àgùntàn rẹ̀ níkọ̀ọ̀kan. Ó mọ ohun tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn nílò, ó mọ àìlera wọn, ó sì mọ ohun tí agbára wọ́n gbé. Kódà, Àwòfiṣàpẹẹrẹ wa yìí ń rí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn àgùntàn rẹ̀. Àwọn àgùntàn náà mọ olùṣọ́ àgùntàn wọn dunjú wọ́n sì fọkàn tán an gẹ́gẹ́ bí aṣáájú wọn.

6. Báwo ni àwọn ọkọ ṣe lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà?

6 Bí ọkọ bá fẹ́ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi nínú ọ̀nà tó ń gbà lo ipò orí rẹ̀, ó gbọ́dọ̀ máa wo ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn, kó sì máa wo àwọn tó wà lábẹ́ àbójútó rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn. Ó gbọ́dọ̀ sapá láti mọ àwọn tó wà nínú ìdílé rẹ̀ dunjú. Ǹjẹ́ ọkọ lè mọ ìdílé rẹ̀ lọ́nà yìí? Bẹ́ẹ̀ ni, bó bá ń bá àwọn tó wà nínú ìdílé rẹ̀ sọ̀rọ̀ déédéé, tó ń tẹ́tí sílẹ̀ bí wọ́n bá ń sọ ẹ̀dùn ọkàn wọn fún un, tó ń mú ipò iwájú nínú àwọn ìgbòkègbodò ìdílé, tó ń fi ọwọ́ pàtàkì mú ṣíṣe ìpinnu tó dára nípa àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn ìdílé, lílọ sí ìpàdé, iṣẹ́ ìsìn pápá, eré ìtura àti eré ìnàjú. Bí Kristẹni kan tó jẹ́ ọkọ bá lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó sì mọ àwọn tó jẹ́ ara ìdílé rẹ̀ dáadáa, tí èyí sì ń mú kó ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání, á ṣeé ṣe fún ìdílé rẹ̀ láti ní ìgbọ́kànlé nínú bó ṣe ń lo ipò orí rẹ̀, òun náà á sì ní ìtẹ́lọ́rùn bó bá ṣe ń rí i tí gbogbo wọn wà ní ìṣọ̀kan nínú ìjọsìn tòótọ́.

7, 8. Báwo ni ọkọ kan ṣe lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà nínú bó ṣe ń fi ìfẹ́ hàn sí àwọn tó wà lábẹ́ àbójútó rẹ̀?

7 Olùṣọ́ àgùntàn rere tún máa ń nífẹ̀ẹ́ àwọn àgùntàn rẹ̀. Bí a bá kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí àwọn ìwé Ìhìn Rere sọ nípa ìgbésí ayé Jésù àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ọkàn wa máa kún fún ìmọrírì nítorí ìfẹ́ tí Jésù fi hàn sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ó tilẹ̀ ‘fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn.’ Àwọn ọkọ gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nípa nínífẹ̀ẹ́ àwọn tó wà lábẹ́ àbójútó wọn. Dípò tí ọkọ tó fẹ́ kí Ọlọ́run máa fi ojú rere wo òun á fi máa jẹ gàba lé aya rẹ̀ lórí, ńṣe ló yẹ kó máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ “gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti nífẹ̀ẹ́ ìjọ.” (Éfé. 5:25) Ó gbọ́dọ̀ máa bá a sọ̀rọ̀ lọ́nà tó fi inúure àti ìgbatẹnirò hàn, torí pé ó yẹ kó máa fi ọlá fún un.—1 Pét. 3:7.

8 Bí olórí ìdílé bá ń fún àwọn ọmọ ní ìdálẹ́kọ̀ọ́, ó yẹ kó máa rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà Ọlọ́run tímọ́tímọ́. Àmọ́, ó gbọ́dọ̀ máa fìfẹ́ hàn sáwọn ọmọ rẹ̀. Bó bá gba pé kó bá wọn wí, ó gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ tìfẹ́tìfẹ́. Àwọn ọmọ kan lè tètè lóye ohun táwọn òbí fẹ́ kí wọ́n ṣe ju àwọn ọmọ mìíràn lọ. Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, baba gbọ́dọ̀ ní sùúrù fún wọn dáadáa. Bí àwọn ọkùnrin bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nígbà gbogbo, ọkàn àwọn tó wà nínú ìdílé á balẹ̀ ará á sì tù wọ́n. Ìdílé wọn á máa gbádùn irú ààbò tẹ̀mí tí onísáàmù náà kọ lórin.—Ka Sáàmù 23:1-6.

9. Bíi ti baba ńlá náà, Nóà ojúṣe wo ni àwọn Kristẹni tó jẹ́ ọkọ ní, kí ló sì máa mú kí wọ́n lè bójú tó ojúṣe náà?

9 Baba ńlá náà, Nóà gbé ayé ní àkókò òpin ayé ìgbà yẹn. Àmọ́ Jèhófà pa á “mọ́ láìséwu pẹ̀lú àwọn méje mìíràn nígbà tí ó mú àkúnya omi wá sórí ayé àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.” (2 Pét. 2:5) Ojúṣe Nóà ló jẹ́ láti ran ìdílé rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè la Ìkún-omi náà já. Ipò tó fara jọ èyí ni àwọn Kristẹni tó jẹ́ olórí ìdílé bá ara wọn ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. (Mát. 24:37) Ẹ sì wo bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ látinú àpẹẹrẹ “olùṣọ́ àgùntàn àtàtà” kí wọ́n sì sapá láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀!

Ẹ̀yin Aya, ‘Ẹ Máa Gbé Agbo Ilé Yín Ró’

10. Kí ló túmọ̀ sí fún aya láti máa tẹrí ba fún ọkọ?

10 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kí àwọn aya wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ wọn gẹ́gẹ́ bí fún Olúwa.” (Éfé. 5:22) Gbólóhùn yìí kò tàbùkù sí àwọn aya. Kí Ọlọ́run tòótọ́ tó dá Éfà, obìnrin àkọ́kọ́, ó sọ pé: “Kò dára kí ọkùnrin náà máa wà nìṣó ní òun nìkan. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ kan fún un, gẹ́gẹ́ bí àṣekún rẹ̀.” (Jẹ́n. 2:18) Ojúṣe “olùrànlọ́wọ́” àti “àṣekún” yìí, ìyẹn láti máa ti ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn bó ṣe ń bójú tó ojúṣe rẹ̀ nínú ìdílé, jẹ́ èyí tó ní ọlá lóòótọ́.

11. Báwo ni aya tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ ṣe lè máa ‘gbé agbo ilé rẹ̀ ró’?

11 Aya tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ máa ń ṣe àwọn nǹkan tó máa ṣe ìdílé rẹ̀ láǹfààní. (Ka Òwe 14:1.) Òmùgọ̀ obìnrin kì í bọ̀wọ̀ fún ìṣètò ipò orí, àmọ́ ọlọgbọ́n obìnrin máa ń ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún ipò orí. Dípò kó máa ṣàìgbọràn kó sì tún fẹ́ máa dá ìpinnu ṣe bí àwọn èèyàn ti ń ṣe nínú ayé, ó máa ń tẹrí ba fún ọkọ rẹ̀. (Éfé. 2:2) Òmùgọ̀ obìnrin máa ń sọ̀rọ̀ tí kò dára nípa ọkọ rẹ̀, àmọ́ obìnrin tó jẹ́ ọlọgbọ́n máa ń wá bó ṣe máa mú kí ọ̀wọ̀ tí àwọn ọmọ rẹ̀ àtàwọn míì ní fún un pọ̀ sí i. Irú ìyàwó bẹ́ẹ̀ máa ń ṣọ́ra kó máa bàa jin ipò orí ọkọ rẹ̀ lẹ́sẹ̀ nípa fífi ọ̀rọ̀ pin ín lẹ́mìí tàbí kó máa bá a jiyàn. Mímọ bá a ṣe ń fi ọgbọ́n náwó náà tún wà níbẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí òmùgọ̀ obìnrin máa ná owó ìdílé rẹ̀ ní ìnákúnàá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé owó náà kò rọrùn láti rí. Aya tó jẹ́ alátìlẹyìn ọkọ kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Ó máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ nínú ọ̀ràn tó bá jẹ mọ́ ìnáwó. Ó máa ń fi ọgbọ́n ṣe nǹkan kì í sì í ná ìná àpà. Kì í fúngun mọ́ ọkọ rẹ̀ pé kó máa ṣe àfikún iṣẹ́.

12. Kí ni aya kan lè ṣe láti ran ìdílé rẹ̀ lọ́wọ́ láti “wà lójúfò”?

12 Àya tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ máa ń mú kí ìdílé rẹ̀ “wà lójúfò” nípa kíkọ́wọ́ ti ọkọ rẹ̀ láti kọ́ àwọn ọmọ lẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. (Òwe 1:8) Ó máa ń kópa tó jọjú nínú Ìjọsìn Ìdílé. Síwájú sí i, kì í ta ko ọkọ rẹ̀ bí ọkọ bá ń fún àwọn ọmọ ní ìmọ̀ràn àti ìbáwí. Ẹ kò rí i pé ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ ló wà láàárín irú aya bẹ́ẹ̀ àti ìyàwó tí kò fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ọkọ, táwọn ọmọ rẹ̀ kò sì lè jàǹfààní ìbáwí òbí àti ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run!

13. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí aya kọ́wọ́ ti ọkọ rẹ̀ bí ọkọ náà ṣe ń kó ipa tó jọjú nínú bíbójú tó iṣẹ́ nínú ìjọ àti nínú ètò Ọlọ́run?

13 Ojú wo ni aya tó jẹ́ alátìlẹyìn ọkọ fi ń wo ipa tó jọjú tí ọkọ rẹ̀ ń kó nínú ìjọ Kristẹni? Inú rẹ̀ máa ń dùn gan-an ni! Yálà ọkọ rẹ̀ jẹ́ ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, alàgbà tàbí ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn tàbí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tí ọkọ rẹ̀ ní máa ń mú inú rẹ̀ dùn. Kí ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀ lè fi hàn pé ó ń ti ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn, ó dájú pé ó ti ní láti yááfì àwọn nǹkan kan. Ṣùgbọ́n, ó mọ̀ pé bí ọwọ́ ọkọ òun ṣe dí fún bíbójú tó iṣẹ́ nínú ìjọ àti nínú ètò Ọlọ́run ń ran gbogbo ìdílé lọ́wọ́ láti máa wà lójúfò nípa tẹ̀mí.

14. (a) Kí ló lè jẹ́ ìṣòro fún aya tó jẹ́ alátìlẹyìn ọkọ rẹ̀, báwo ló sì ṣe lè borí ìṣòro náà? (b) Báwo ni aya ṣe lè pa kún àlàáfíà ìdílé lápapọ̀?

14 Ó lè ṣòro fún aya kan láti jẹ́ alátìlẹyìn ọkọ rẹ̀ kó sì tún jẹ́ àpẹẹrẹ rere bí ọkọ rẹ̀ bá ṣe ìpinnu tí kò fara mọ́. Síbẹ̀, ó máa ń fi “ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ti ìwà tútù” hàn, ó sì máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ kí ìpinnu tó ṣe lè kẹ́sẹ járí. (1 Pét. 3:4) Aya rere máa ń gbìyànjú láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere àwọn obìnrin ìgbàanì tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run, irú bíi Sárà, Rúùtù, Ábígẹ́lì àti Màríà, ìyá Jésù, ó sì máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. (1 Pét. 3:5, 6) Ó tún máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn àgbà obìnrin òde òní tí wọ́n jẹ́ “onífọkànsìn nínú ìhùwàsí.” (Títù 2:3, 4) Bí aya tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ bá ń fi ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ hàn fún ọkọ rẹ̀, èyí á mú kí ìgbéyàwó wọn kẹ́sẹ járí á sì pa kún àlàáfíà ìdílé lápapọ̀. Ilé tí irú aya bẹ́ẹ̀ bá wà máa ń tuni lára ó sì máa ń fini lọ́kàn balẹ̀. Aya tó bá ń ti ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn ṣeyebíye fún ọkùnrin tó bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà!—Òwe 18:22.

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹ ‘Tẹ Ojú Yín Mọ́ Àwọn Ohun Tí A Kò Rí’

15. Báwo ni àwọn ọ̀dọ́ ṣe lè máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn òbí wọn kí ìdílé lè “wà lójúfò”?

15 Báwo ni ẹ̀yin ọ̀dọ́ ṣe lè máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn òbí yín kí ìdílé yín lè máa “wà lójúfò” nípa tẹ̀mí? Ẹ ronú nípa èrè tí Jèhófà gbé ka iwájú yín. Ó ṣeé ṣe kí àwọn òbí yín ti máa fi àwòrán bí Párádísè ṣe máa rí hàn yín láti ìgbà kékeré yín. Bẹ́ ẹ ṣe ń dàgbà sí i, ó ṣeé ṣe kí wọ́n lo Bíbélì àtàwọn ìwé tí ètò Ọlọ́run ṣe láti mú kẹ́ ẹ fojú inú yàwòrán bí ìyè àìnípẹ̀kun ṣe máa rí nínú ayé tuntun. Bẹ́ ẹ bá gbájú mọ́ iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, tẹ́ ẹ sì jẹ́ kí ìyẹn nípa lórí gbogbo nǹkan tẹ́ ẹ bá ń ṣe, ó máa jẹ́ kẹ́ ẹ lè “wà lójúfò.”

16, 17. Kí ni àwọn ọ̀dọ́ lè ṣe kí wọ́n lè kẹ́sẹ járí nínú sísá eré ìje ìyè?

16 Ẹ fi ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 9:24 sọ́kàn. (Kà á.) Ẹ jẹ́ kí ọ̀nà tẹ́ ẹ gbà ń sá eré ìje ìyè náà fi hàn pé ẹ ní in lọ́kàn láti yege. Ẹ yan ipa ọ̀nà tó máa jẹ́ kẹ́ ẹ lè gba èrè ìyè àìnípẹ̀kun. Ọ̀pọ̀ èèyàn ti jẹ́ kí ìlépa àwọn nǹkan tara fa ìpínyà ọkàn fún wọn débi pé wọn kò lè tẹjú mọ́ èrè náà mọ́. Ìwà òmùgọ̀ gbáà mà nìyẹn o! Fífi ìgbésí ayé ẹni kó ọrọ̀ jọ kì í jẹ́ kéèyàn ní ojúlówó ayọ̀. Àwọn nǹkan tí owó lè rà kì í wà pẹ́ títí. Àmọ́, ẹ tẹ ojú yín mọ́ “àwọn ohun tí a kò rí.” Kí nìdí? Ìdí ni pé “àwọn ohun tí a kò rí jẹ́ fún àìnípẹ̀kun.”—2 Kọ́r. 4:18.

17 Lára “àwọn ohun tí a kò rí” ni àwọn ìbùkún tí Ìjọba Ọlọ́run máa mú wá. Gbé ìgbé ayé rẹ lọ́nà tó máa jẹ́ kí ọwọ́ rẹ tẹ àwọn ìbùkún náà. Wàá rí ojúlówó ayọ̀ bó o bá ń lo ìgbésí ayé rẹ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Bó o bá ń sin Ọlọ́run tòótọ́, ó máa fún ẹ ní àǹfààní láti ní àwọn àfojúsùn tí ọwọ́ lè tètè tẹ̀ àti àwọn àfojúsùn tó máa pẹ́ kí ọwọ́ tó tẹ̀. * Bẹ́ ẹ bá ní àfojúsùn tẹ̀mí tí ọwọ́ yín lè tẹ̀, ó máa ràn yín lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀ sórí sísin Ọlọ́run kẹ́ ẹ sì máa fojú sọ́nà fún jíjèrè ìyè àìnípẹ̀kun.—1 Jòhánù 2:17.

18, 19. Báwo ni ọ̀dọ́ kan ṣe lè mọ̀ bóyá ó ti sọ òtítọ́ di tirẹ̀?

18 Ẹ̀yin ọ̀dọ́, bẹ́ ẹ bá fẹ́ máa tọ ojú ọ̀nà tó lọ sí ìyè, ohun tó yẹ kẹ́ ẹ kọ́kọ́ ṣe ni pé kẹ́ ẹ sọ òtítọ́ di tiyín. Ǹjẹ́ o ti ṣe bẹ́ẹ̀? Bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ mo ka níní àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run sí pàtàkì, àbí torí àwọn òbí mi ni mo ṣe ń kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò ìjọ? Ǹjẹ́ mo ní àwọn ànímọ́ tó máa jẹ́ kí n rí ojú rere Ọlọ́run? Ǹjẹ́ mò ń sapá láti máa lọ́wọ́ déédéé nínú àwọn ìgbòkègbodò tó jẹ mọ́ ìjọsìn tòótọ́, irú bíi gbígbàdúrà déédéé, kíkẹ́kọ̀ọ́, lílọ sí ìpàdé déédéé àti kíkópa nínú iṣẹ́ ìsìn pápá? Ṣé mo túbọ̀ ń sún mọ́ Ọlọ́run nípa ṣíṣe àwọn ohun tó máa jẹ́ kí n ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀?’—Ják. 4:8.

19 Ronú lórí àpẹẹrẹ Mósè. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní láti kọ́ àṣà tó yàtọ̀ sí tirẹ̀, ó yàn kí àwọn èèyàn mọ òun sí olùjọ́sìn Jèhófà dípò tí wọn ì bá fi máa pè é ní ọmọkùnrin ọmọbìnrin Fáráò. (Ka Hébérù 11:24-27.) Ó yẹ kí ẹ̀yin Kristẹni tẹ́ ẹ jẹ́ ọ̀dọ́ náà pinnu láti máa fi òótọ́ sin Jèhófà. Tẹ́ ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ máa ní ojúlówó ayọ̀, ẹ ó máa gbádùn ìgbésí ayé tó nítumọ̀ jù lọ nísinsìnyí, ẹ ó sì ní ìrètí láti “di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.”—1 Tím. 6:19.

20. Àwọn wo ló máa gba èrè nínú eré ìje ìyè?

20 Nínú eré ìje ayé ọjọ́un, sárésáré kan ṣoṣo ló máa ń borí nínú eré ìje náà. Ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ nínú eré ìje ìyè. Ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tím. 2:3, 4) Ọ̀pọ̀ èèyàn ti kẹ́sẹ járí nínú eré sísá náà kó o tó bẹ̀rẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn sì ń sáré náà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú rẹ. (Héb. 12:1, 2) Gbogbo ẹni tí kò bá dẹ́kun láti máa sá eré náà ló máa gba èrè. Torí náà, pinnu pé wàá kẹ́sẹ járí!

21. Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

21 “Ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà” yóò dé láìkùnà. (Mál. 4:5) Kò yẹ kí ọjọ́ yẹn dé bá àwọn ìdílé Kristẹni lójijì. Ó ṣe pàtàkì pé kí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé máa ṣe ojúṣe tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ṣe lànà rẹ̀ sílẹ̀. Kí lo tún lè ṣe kó o lè máa wà lójúfò nípa tẹ̀mí kó o sì mú kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run lágbára sí i? Àpilẹ̀kọ tó kàn máa jíròrò àwọn ohun mẹ́ta tó lè nípa lórí àjọṣe tí ìdílé lápapọ̀ ní pẹ̀lú Ọlọ́run.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Wo Ilé Ìṣọ́, November 15, 2010, ojú ìwé 12 sí 16; July 15, 2004, ojú ìwé 21 sí 23.

Ẹ̀kọ́ Wo Lo Kọ́?

• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì fún àwọn ìdílé Kristẹni láti “wà lójúfò”?

• Báwo ni ọkọ kan ṣe lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà náà?

• Kí ni aya tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ lè ṣe kó bàa lè máa ti ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn?

• Báwo làwọn ọ̀dọ́ ṣe lè mú kí ìdílé wọn wà lójúfò nípa tẹ̀mí?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Aya tó ń ti ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn ṣeyebíye fún ọkùnrin tó bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà