Ìgbọ́kànlé Kíkún Nínú Jèhófà Ń Mú Ká Ní Ìgboyà
Ìgbọ́kànlé Kíkún Nínú Jèhófà Ń Mú Ká Ní Ìgboyà
“Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò gbọ́ nígbà tí mo bá ké pè é.”—SM. 4:3.
1, 2. (a) Ipò tó léwu wo ló dojú kọ Dáfídì? (b) Àwọn ìwé sáàmù wo la máa jíròrò?
Ó TI ṣe díẹ̀ tí Dáfídì Ọba ti ń ṣàkóso orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, àmọ́ ní báyìí, ipò kan tó léwu dojú kọ ọ́. Ábúsálómù, ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tó fẹ́ fèrú gbapò mú kí wọ́n kéde pé òun ti di ọba, ìyẹn sì mú kí Dáfídì fi ìlú Jerúsálẹ́mù sílẹ̀. Ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan tó finú tán tún ti dà á, àwọn mélòó kan tó jẹ́ adúróṣinṣin ni wọ́n tẹ̀ lé e bó ṣe ń sunkún, tó sì ń fẹsẹ̀ lásán rìn gba orí Òkè Ólífì kọjá. Nígbà tó ṣe, Ṣíméì tó wá láti ìdílé Sọ́ọ̀lù Ọba bẹ̀rẹ̀ sí í sọ òkúta lu Dáfídì, ó ń fọ́n ekuru, ó sì ń bú u.—2 Sám. 15:30, 31; 16:5-14.
2 Ṣé ìṣẹ̀lẹ̀ búburú yìí máa ba Dáfídì lọ́kàn jẹ́, ṣé ó sì máa jẹ́ kó kú ikú ẹ̀sín? Rárá, ìdí sì ni pé ó gbọ́kàn lé Jèhófà. Èyí ṣe kedere nínú Sáàmù Kẹta tí Dáfídì kọ nígbà tó sá kúrò nílùú torí ti Ábúsálómù. Òun náà ló tún kọ Sáàmù Kẹrin. Àwọn ìwé sáàmù méjì yìí ṣe àlàyé tó mú kó dá wa lójú pé Ọlọ́run máa ń gbọ́ wa ó sì máa ń dáhùn àwọn àdúrà wa. (Sm. 3:4; 4:3) Àwọn ìwé sáàmù yìí mú kó dá wa lójú pé Jèhófà ń wà pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ nígbà gbogbo, ó máa ń tì wọ́n lẹ́yìn, ó sì máa ń mú kí wọ́n ní àlàáfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn. (Sm. 3:5; 4:8) Torí náà, ẹ jẹ́ ká ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn sáàmù wọ̀nyí ká sì rí bí wọ́n ṣe lè mú ká ní ìgboyà kí ìgbọ́kànlé tá a ní nínú Ọlọ́run sì pọ̀ sí i.
Nígbà Tí ‘Ọ̀pọ̀ Bá Dìde sí Wa’
3. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì nígbà tó kọ ohun tó wà nínú Sáàmù 3:1, 2?
3 Ìránṣẹ́ kan mú ìròyìn wá pé: “Ọkàn-àyà àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì ti wà lẹ́yìn Ábúsálómù.” (2 Sám. 15:13) Ó ya Dáfídì lẹ́nu bí Ábúsálómù ṣe lè kó àwọn èèyàn tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ jọ sẹ́yìn ara rẹ̀, ó wá béèrè pé: “Jèhófà, èé ṣe tí àwọn elénìní mi fi di púpọ̀? Èé ṣe tí ọ̀pọ̀ fi ń dìde sí mi? Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń wí nípa ọkàn mi pé: ‘Kò sí ìgbàlà fún un lọ́dọ̀ Ọlọ́run.’” (Sm. 3:1, 2) Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rò pé Jèhófà kò ní gba Dáfídì sílẹ̀ lọ́wọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ tó kó ìdààmú bá a látọwọ́ Ábúsálómù àtàwọn ìsọ̀ǹgbè rẹ̀.
4, 5. (a) Kí ló dá Dáfídì lójú? (b) Kí ni ìjẹ́pàtàkì gbólóhùn náà, “Ẹni tí ń gbé orí mi sókè”?
4 Àmọ́ Dáfídì ní ìgboyà torí pé ó gbọ́kàn lé Ọlọ́run pátápátá. Ó kọrin pé: “Síbẹ̀, ìwọ, Jèhófà, ni apata yí mi ká, ògo mi àti Ẹni tí ń gbé orí mi sókè.” (Sm. 3:3) Ó dá Dáfídì lójú pé Jèhófà máa dáàbò bo òun gẹ́gẹ́ bí apata ṣe máa ń dáàbò bo ọmọ ogun. Òótọ́ ni pé ọkàn ọba tó ti darúgbó náà kún fún ìbànújẹ́ bó ṣe tẹrí ba tó sì ń fi ìtìjú sá lọ. Àmọ́, Ẹni Gíga Jù Lọ máa yí ipò Dáfídì pa dà sí èyí tó ní ògo. Jèhófà máa jẹ́ kó lè dúró ṣánṣán, kó sì tún gbé orí rẹ̀ sókè lẹ́ẹ̀kan sí i. Dáfídì ké pe Ọlọ́run torí pé ó dá a lójú pé ó máa dá òun lóhùn. Ṣé ìwọ náà ní irú ìgbọ́kànlé bẹ́ẹ̀ nínú Jèhófà?
5 Bí Dáfídì ṣe lo gbólóhùn náà “Ẹni tí ń gbé orí mi sókè” tún fi hàn pé ó gbà pé ọ̀dọ̀ Jèhófà ni òun ti máa rí ìrànlọ́wọ́. Bíbélì Today’s English Version tiẹ̀ kà pé: “Àmọ́ ìwọ, OLÚWA, ò ń gbà mí lọ́wọ́ ewu nígbà gbogbo; ò ń ṣẹ́gun fún mi ó sì ń mú kí n pa dà ní ìgboyà.” Ohun tí ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ nípa gbólóhùn náà, “Ẹni tí ń gbé orí mi sókè,” ni pé: “Nígbà tí Ọlọ́run bá . . . gbé ‘orí’ ẹnì kan sókè, Ó máa mú kí onítọ̀hún ní ìrètí àti ìgboyà.” Níwọ̀n bí Dáfídì ti ní láti sá kúrò lórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọba fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, ìdí wà tí ìbànújẹ́ fi ní láti sorí rẹ̀ kodò. Àmọ́, ‘gbígbé tí Ọlọ́run gbé orí rẹ̀ sókè’ sọ ìgboyà, ìdánilójú àti ìgbọ́kànlé kíkún tó ní nínú Ọlọ́run dọ̀tun.
‘Jèhófà Yóò Dáhùn!’
6. Kí nìdí tí Dáfídì fi sọ pé òun rí ìdáhùn àdúrà òun láti òkè ńlá mímọ́ Jèhófà?
6 Níwọ̀n bí Dáfídì ti ní ìgbọ́kànlé nínú Jèhófà tó sì ní ìgboyà, ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Èmi yóò fi ohùn mi pe Jèhófà, òun yóò sì dá mi lóhùn láti orí òkè ńlá mímọ́ rẹ̀.” (Sm. 3:4) Ní ìgbọràn sí àṣẹ Dáfídì, wọ́n ti gbé àpótí ẹ̀rí, tó ṣàpẹẹrẹ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀, lọ sórí Òkè Ńlá Síónì. (Ka 2 Sámúẹ́lì 15:23-25.) Ó bá a mu nígbà náà kí Dáfídì sọ pé Jèhófà dáhùn àdúrà òun láti òkè ńlá mímọ́ Rẹ̀.
7. Kí nìdí tí Dáfídì kò fi fòyà?
7 Níwọ̀n bó ti dá Dáfídì lójú pé àdúrà tóun gbà sí Ọlọ́run kò ní já sí asán, kò fòyà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó kọrin pé: “Ní tèmi, ṣe ni èmi yóò dùbúlẹ̀ kí n lè sùn; dájúdájú, èmi yóò jí, nítorí tí Jèhófà ń tì mí lẹ́yìn.” (Sm. 3:5) Kódà ní alẹ́ tí ewu pé ọ̀tá lè gbéjà koni lójijì máa ń pọ̀ jù lọ pàápàá, ẹ̀rù kì í ba Dáfídì láti sùn. Ó dá a lójú pé òun máa jí, torí ó ti mọ̀ látinú àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí i kọjá pé òun lè ní ìgbọ́kànlé kíkún pé Ọlọ́run máa ti òun lẹ́yìn láìkùnà. Àwa náà lè ní ìgbọ́kànlé nínú Ọlọ́run bá a bá ń tọ “àwọn ọ̀nà Jèhófà” tí a kò sì fi Jèhófà sílẹ̀ láé.—Ka 2 Sámúẹ́lì 22:21, 22.
8. Báwo ni Sáàmù 27:1-4 ṣe fi hàn pé Dáfídì gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run?
8 Bá a bá wo àwọn sáàmù míì tí Dáfídì kọ, ó rọrùn láti rí i pé ó ní ìgboyà àti ìgbọ́kànlé kíkún nínú Ọlọ́run. Nínú ọ̀kan lára àwọn sáàmù tí Ọlọ́run mí sí náà, ó sọ pé: “Jèhófà ni ìmọ́lẹ̀ mi àti ìgbàlà mi. Ta ni èmi yóò bẹ̀rù? Jèhófà ni odi agbára ìgbésí ayé mi. Ta ni èmi yóò ní ìbẹ̀rùbojo fún? . . . Bí àwọn adótini tilẹ̀ pàgọ́ tì mí, ọkàn-àyà mi kì yóò bẹ̀rù. . . . Ohun kan ni mo béèrè lọ́wọ́ Jèhófà—ìyẹn ni èmi yóò máa wá, kí n lè máa gbé inú ilé Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé mi, kí n lè máa rí adùn Jèhófà kí n sì lè máa fi ẹ̀mí ìmọrírì wo tẹ́ńpìlì rẹ̀.” (Sm. 27:1-4) Bó o bá gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ yìí tí ipò rẹ sì yọ̀ǹda fún ẹ, wàá máa pé jọ déédéé pẹ̀lú àwọn tó jẹ́ olùjọ́sìn Jèhófà bíi tìẹ.—Héb. 10:23-25.
9, 10. Kí nìdí tí o kò fi lè sọ pé Dáfídì ní ẹ̀mí ìgbẹ̀san torí ohun tó sọ nínú Sáàmù 3:6, 7?
9 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà ẹ̀tàn Ábúsálómù àti ìwà àìṣòdodo táwọn míì hù kó ìdààmú ọkàn bá Dáfídì, ó kọrin pé: “Èmi kì yóò fòyà ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ènìyàn tí wọ́n ti to ara wọn ní ẹsẹẹsẹ yí mi ká. Dìde, Jèhófà! Gbà mí là, ìwọ Ọlọ́run mi! Nítorí pé ṣe ni ìwọ yóò gbá gbogbo ọ̀tá mi ní páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́. Eyín àwọn ẹni burúkú ni ìwọ yóò ká.”—Sm. 3:6, 7.
10 Dáfídì kò ní ẹ̀mí ìgbẹ̀san. Bí ìdí bá wà láti ‘gbá àwọn ọ̀tá rẹ̀ ní páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́,’ Ọlọ́run ló máa ṣèyẹn. Dáfídì Ọba ti fi ọwọ́ ara rẹ ṣe ẹ̀dà Òfin, torí náà ó mọ̀ pé Jèhófà sọ níbẹ̀ pé: “Tèmi ni ẹ̀san, àti ẹ̀san iṣẹ́.” (Diu. 17:14, 15, 18; 32:35) Ọwọ́ Ọlọ́run náà ló kù sí láti ‘ká eyín àwọn ẹni burúkú.’ Kíká eyín wọn túmọ̀ sí pé kó sọ wọ́n di ẹni tí kò lágbára láti ṣe ìpalára. Jèhófà mọ àwọn ẹni búburú torí pé “ó ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́.” (1 Sám. 16:7) Àfi ká máa dúpẹ́ pé Ọlọ́run fún wa ní ìgbàgbọ́ àti okun láti dúró gbọn-in lòdì sí olórí ẹni ibi náà, Sátánì, tí Jésù Kristi máa tó gbé jù sínú ọ̀gbun bíi kìnnìún tí kò léyín, tó ń ké ramúramù tí kò sì sí ohun tó tọ́ sí i ju ìparun lọ!—1 Pét. 5:8, 9; Ìṣí. 20:1, 2, 7-10.
“Ìgbàlà Jẹ́ Ti Jèhófà”
11. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà fún àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́?
11 Dáfídì mọ̀ pé Jèhófà nìkan ló lè mú ìdáǹdè tóun nílò lójú méjèèjì wá. Àmọ́ onísáàmù náà kò ronú nípa ara rẹ̀ nìkan ṣoṣo. Gbogbo àwọn tó jẹ́ àyànfẹ́ Jèhófà ńkọ́? Àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí èyí tí Dáfídì fi parí orin rẹ̀ ṣe wẹ́kú nígbà náà, ó ní: “Ìgbàlà jẹ́ ti Jèhófà. Ìbùkún rẹ wà lára àwọn ènìyàn rẹ.” (Sm. 3:8) Òótọ́ ni pé Dáfídì ní ìṣòro ńlá, àmọ́ ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn Jèhófà lápapọ̀ jẹ ẹ́ lógún, ó sì dá a lójú pé Ọlọ́run máa bù kún wọn. Ṣé kò wá yẹ kí ọ̀rọ̀ àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ máa jẹ àwa náà lógún? Ẹ jẹ́ ká máa rántí wọn nínú àwọn àdúrà wa, ká máa bẹ Jèhófà pé kó fún wọn ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ kí wọ́n lè ní ìgboyà, kí ìgbọ́kànlé tí wọ́n ní nínú Ọlọ́run sì lè mú kí wọ́n máa polongo ìhìn rere.—Éfé. 6:17-20.
12, 13. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Ábúsálómù, kí ni Dáfídì sì ṣe?
12 Ikú ẹ̀sín ni Ábúsálómù kú, ìkìlọ̀ nìyẹn sì jẹ́ fún gbogbo àwọn tó bá fẹ́ láti hùwà àìdáa sáwọn ẹlòmíràn, pàápàá jù lọ àwọn ẹni àmì òróró Ọlọ́run, bíi Dáfídì. (Ka Òwe 3:31-35.) Ìjà kan wáyé láàárín àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì àti àwọn ọmọ ogun Ábúsálómù, àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì sì ṣẹ́gun. Ó wá ṣẹlẹ̀ pé bí Ábúsálómù ṣe ń gun ìbaaka lọ, irun rẹ̀ tó ṣù pọ̀ ṣìkìtì lọ́ mọ́ àárín ẹ̀ka igi kan tó sún mọ́ ìsàlẹ̀. Ó ṣì wà láàyè láàárín igi tó há sí náà, àmọ́ ńṣe ló ń rọ̀ dirodiro láìlè ṣe ohunkóhun títí tí Jóábù fi fi ọ̀kọ̀ tẹ́ẹ́rẹ́ mẹ́ta gún ọkàn-àyà rẹ̀ ní àgúnyọ tó sì pa á.—2 Sám. 18:6-17.
13 Ǹjẹ́ inú Dáfídì dùn nígbà tó gbọ́ ìròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọmọ rẹ̀? Ó tì o. Dípò kí inú rẹ̀ dùn, ńṣe ló ń lọ tó ń bọ̀, ó ń sunkún, ó sì ń ké jáde pé: “Ọmọkùnrin mi Ábúsálómù, ọmọkùnrin mi, ọmọkùnrin mi Ábúsálómù! Áà ì bá ṣe pé mo ti kú, èmi fúnra mi, dípò ìwọ, Ábúsálómù ọmọkùnrin mi, ọmọkùnrin mi!” (2 Sám. 18:24-33) Ẹ̀dùn ọkàn tó bá Dáfídì pọ̀ débi pé àfi ìgbà tí Jóábù bá a sọ̀rọ̀ ló tó mọ ohun tó yẹ kó ṣe. Ẹ kò rí i pé ibi tí Ábúsálómù parí ayé rẹ̀ sí yìí bani nínú jẹ́ gan-an ni! Ipò ọlá tó ń lépa mú kó bá bàbá tó bí i lọ́mọ, tó sì jẹ́ ẹni àmì òróró Jèhófà, jà ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi ọwọ́ ara rẹ̀ fa ikú òjijì.—2 Sám. 19:1-8; Òwe 12:21; 24:21, 22.
Dáfídì Tún Fi Hàn Pé Òun Ní Ìgbẹ́kẹ̀lé Nínú Ọlọ́run
14. Kí la lè sọ nípa orin tó wà nínú Sáàmù Kẹrin?
14 Bíi ti Sáàmù Kẹta, Sáàmù Kẹrin náà jẹ́ àdúrà àtọkànwá tí Dáfídì gbà, èyí tó fi ẹ̀rí hàn pé ó gbọ́kàn lé Jèhófà pátápátá. (Sm. 3:4; 4:3) Ó ṣeé ṣe kí Dáfídì kọ orin náà láti fi ìmoore rẹ̀ hàn fún Ọlọ́run torí pé ó rí ìtura gbà lẹ́yìn tí Ábúsálómù tó fẹ́ fi ọ̀tẹ̀ gba ìṣàkóso mọ́ ọn lọ́wọ́ ti kùnà. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé torí àwọn akọrin tó jẹ́ ọmọ Léfì ló ṣe kọ orin náà. Èyí tó wù kó jẹ́ nínú méjèèjì, bá a bá ṣe àṣàrò lórí orin yìí, ó lè mú kí ìgbọ́kànlé wa nínú Jèhófà lágbára sí i.
15. Kí nìdí tá a fi lè gbàdúrà sí Jèhófà nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀, ká sì ní ìdánilójú pé ó máa gbọ́ àdúrà wa?
15 Dáfídì tún fi hàn pé òun gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run pátápátá, ó sì dá a lójú pé ó máa ń gbọ́ àdúrà. Ó kọrin pé: “Nígbà tí mo bá pè, dá mi lóhùn, ìwọ Ọlọ́run mi olódodo. Nínú wàhálà, kí ó ṣe àyè fífẹ̀ fún mi. Fi ojú rere hàn sí mi, kí o sì gbọ́ àdúrà mi.” (Sm. 4:1) Àwa náà lè ní ìgbọ́kànlé bíi tirẹ̀ bá a bá ń fi òdodo ṣèwà hù. Níwọ̀n bí àwa náà ti mọ̀ pé Jèhófà, ‘Ọlọ́run olódodo’ máa ń bù kún àwọn olódodo, a lè gbàdúrà sí i nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ ká sì ní ìdánilójú pé ó máa gbọ́ àdúrà wa, bá a bá ní ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù. (Jòh. 3:16, 36) Ìyẹn mà fini lọ́kàn balẹ̀ gan-an ni o!
16. Kí ló ṣeé ṣe kó fà á tí Dáfídì fi rẹ̀wẹ̀sì?
16 Nígbà míì, a lè bá ara wa nínú ipò kan tó máa mú ká rẹ̀wẹ̀sì tá ò sì ní ní ìgboyà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí ọ̀ràn Dáfídì ṣe rí fun àkókò díẹ̀ nìyí, torí ó kọrin pé: “Ẹ̀yin ọmọ ènìyàn, yóò ti pẹ́ tó tí ògo mi yóò fi jẹ́ fún ìwọ̀sí, nígbà tí ẹ ń nífẹ̀ẹ́ àwọn nǹkan òfìfo, nígbà tí ẹ ń wá ọ̀nà láti rí irọ́?” (Sm. 4:2) Ó dájú pé kò lo gbólóhùn náà “ọmọ ènìyàn,” láti fi pọ́n aráyé lé. Àwọn ọ̀tá Dáfídì “nífẹ̀ẹ́ àwọn nǹkan òfìfo.” Bí Bíbélì New International Version ṣe túmọ̀ gbólóhùn yẹn nìyí: “Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó tí ẹ̀yin yóò máa nífẹ̀ẹ́ ẹ̀tàn tí ẹ ó sì máa wá àwọn ọlọ́run èké kiri?” Kódà bí ohun tí àwọn ẹlòmíràn ṣe bá mú ká rẹ̀wẹ̀sì, ẹ jẹ́ ká máa bá a nìṣó láti gbàdúrà látọkànwá ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà pátápátá.
17. Ní ìbámu pẹ̀lú Sáàmù 4:3, ṣàlàyé bá a ṣe lè jẹ́ adúróṣinṣin?
17 Ìgbọ́kànlé tí Dáfídì ní nínú Ọlọ́run ṣe kedere nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Nítorí náà, kí ẹ mọ̀ pé Jèhófà yóò fi ìyàtọ̀ sí ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ dájúdájú; Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò gbọ́ nígbà tí mo bá ké pè é.” (Sm. 4:3) Ó ṣe pàtàkì pé ká ní ìgboyà ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá ká bàa lè máa jẹ́ adúróṣinṣin sí i. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ànímọ́ yìí ṣe pàtàkì nínú ìdílé Kristẹni nígbà tí wọ́n bá yọ ìbátan kan tí kò ronú pìwà dà lẹ́gbẹ́. Ọlọ́run máa ń bù kún àwọn tó bá jẹ́ adúróṣinṣin sí I tí wọ́n sì ń rìn ní àwọn ọ̀nà Rẹ̀. Ìdúróṣinṣin àti ìgbọ́kànlé kíkún nínú Jèhófà sì máa ń mú kí ayọ̀ gbilẹ̀ láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run.—Sm. 84:11, 12.
18. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó wà nínú Sáàmù 4:4, kí la gbọ́dọ̀ ṣe bí àwọn èèyàn bá ti sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí wa tàbí tí wọ́n ti hùwà tí kò dára sí wa?
18 Bí ẹnì kan bá sọ̀rọ̀ tàbí tó ṣe ohun tó mú inú bí wa ńkọ́? A ṣì lè máa láyọ̀ bá a bá ṣe ohun tí Dáfídì sọ. Ó ní: “Kí inú yín ru, ṣùgbọ́n ẹ má ṣẹ̀. Ẹ sọ ohun tí ẹ ní í sọ ní ọkàn-àyà yín, lórí ibùsùn yín, kí ẹ sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.” (Sm. 4:4) Bí ẹnì kan bá ti sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí wa tàbí tó hùwà tí kò dára sí wa, ẹ má ṣe jẹ́ kí a ṣẹ̀ nípa gbígbẹ̀san. (Róòmù 12:17-19) A lè sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára wa nínú àdúrà nígbà tá a bá wà lórí ibùsùn wa. Bá a bá gbàdúrà nípa ọ̀ràn náà, ó ṣeé ṣe kí ojú tá a fi ń wò ó yí pa dà, kí ìfẹ́ sì sún wa láti dárí jini. (1 Pét. 4:8) Ó tún ṣe pàtàkì ká kíyè sí ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lórí ọ̀ràn yìí, èyí tó ṣeé ṣe kó gbé ka Sáàmù 4:4. Ìmọ̀ràn náà kà pé: “Ẹ fi ìrunú hàn, síbẹ̀ kí ẹ má ṣẹ̀; ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìbínú, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe fi àyè sílẹ̀ fún Èṣù.”—Éfé. 4:26, 27.
19. Kí Ọlọ́run lè tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa, kí ni Sáàmù 4:5 sọ pé ká ṣe?
19 Láti fi hàn bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, Dáfídì kọrin pé: “Ẹ rú ẹbọ òdodo, kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.” (Sm. 4:5) Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò bá ní èrò tó tọ́, ẹbọ tí wọ́n bá rú kò lè já mọ́ nǹkan kan. (Aísá. 1:11-17) Kí Ọlọ́run lè tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa, àwa pẹ̀lú gbọ́dọ̀ ní èrò tó tọ́ ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá.—Ka Òwe 3:5, 6; Hébérù 13:15, 16.
20. Kí ní gbólóhùn náà ‘ìmọ́lẹ̀ ojú Jèhófà’ dúró fún?
20 Dáfídì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ń sọ pé: ‘Ta ni yóò fi oore hàn sí wa?’ Gbé ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ sókè sí wa lára, Jèhófà.” (Sm. 4:6) ‘Ìmọ́lẹ̀ ojú Jèhófà’ dúró fún ojú rere Ọlọ́run. (Sm. 89:15) Torí náà, nígbà tí Dáfídì gbàdúrà pé: “Gbé ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ sókè sí wa lára,” ohun tó ní lọ́kàn ni pé kí Ọlọ́run ‘fi ojú rere hàn sí wa.’ Torí pé a ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà, ó fi ojú rere hàn sí wa, ó sì mú ká ní ayọ̀ ńláǹlà bá a ti ń fi ìgboyà ṣe ìfẹ́ rẹ̀.
21. Tá a bá ń kópa déédéé nínú iṣẹ́ ìkórè tẹ̀mí tó ń lọ lọ́wọ́, ìdánilójú wo la ní?
21 Bí Dáfídì ti ń fojú sọ́nà fún ìdùnnú tí Ọlọ́run máa ń pèsè, èyí tó ré kọjá ti àkókò ìkórè, ó kọrin sí Jèhófà pé: “Dájúdájú, ìwọ yóò fún mi ní ayọ̀ yíyọ̀ nínú ọkàn-àyà mi ju ìgbà tí ọkà wọn àti wáìnì tuntun wọn pọ̀ gidigidi.” (Sm. 4:7) A ní ìdánilójú pé a máa ní ìdùnnú àtọkànwá tá a bá ń kópa déédéé nínú iṣẹ́ ìkórè tẹ̀mí tó ń lọ lọ́wọ́. (Lúùkù 10:2) Bí ‘orílẹ̀-èdè púpọ̀’ ti àwọn ẹni àmì òróró ṣe ń mú ipò iwájú, inú wa ń dùn nísinsìnyí bí iye ‘àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìkórè’ ṣe ń pọ̀ sí i. (Aísá. 9:3) Ṣé ò ń kó ipa tó jọjú nínú iṣẹ́ ìkórè tó ń fúnni láyọ̀ yìí?
Gbẹ́kẹ̀ Lé Ọlọ́run ní Kíkún Kó O sì Máa Fìgboyà Tẹ̀ Síwájú
22. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó wà nínú Sáàmù 4:8, báwo ni ọ̀ràn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe rí nígbà tí wọ́n pa Òfin Ọlọ́run mọ́?
22 Àwọn ọ̀rọ̀ tí Dáfídì fi parí sáàmù náà nìyí: “Àlàáfíà ni èmi yóò dùbúlẹ̀, tí èmi yóò sì sùn, nítorí pé ìwọ tìkára rẹ, Jèhófà, nìkan ṣoṣo ni ó mú kí n máa gbé nínú ààbò.” (Sm. 4:8) Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa Òfin Jèhófà mọ́, wọ́n wà ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run, wọ́n sì ń gbé nínú ààbò. Bí àpẹẹrẹ, ‘Júdà àti Ísírẹ́lì gbé nínú ààbò’ nígbà ìṣàkóso Sólómọ́nì. (1 Ọba 4:25) Àwọn tó ní ìgbọ́kànlé nínú Ọlọ́run gbádùn àlàáfíà bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn orílẹ̀-èdè tó múlé gbè wọ́n jẹ́ òǹrorò. Bíi ti Dáfídì, àwa náà ń dùbúlẹ̀ ní àlàáfíà torí pé Ọlọ́run mú ká máa gbé nínú ààbò.
23. Kí la máa ní tá a bá ní ìgbọ́kànlé kíkún nínú Ọlọ́run?
23 Ẹ jẹ́ ká máa fìgboyà tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ẹ sì tún jẹ́ ká máa fi ìgbàgbọ́ gbàdúrà ká lè tipa bẹ́ẹ̀ ní “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.” (Fílí. 4:6, 7) Ẹ sì wo bí ìyẹn ṣe máa jẹ́ ká láyọ̀ tó! A sì tún lè ní ìdánilójú pé ọ̀la máa dára bá a bá ní ìgbọ́kànlé kíkún nínú Jèhófà.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Àwọn ìṣòro wo ni Dáfídì dojú kọ torí Ábúsálómù?
• Báwo ni Sáàmù Kẹta ṣe mú ká ní ìgboyà?
• Àwọn ọ̀nà wo ni Sáàmù Kẹrin lè gbà mú ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?
• Bá a bá ní ìgbọ́kànlé kíkún nínú Ọlọ́run, báwo ló ṣe máa ṣe wá láǹfààní?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Kódà nígbà tí Dáfídì fi ìlú sílẹ̀ torí Ábúsálómù, ó ṣì ní ìgbọ́kànlé nínú Jèhófà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]
Ǹjẹ́ o ní ìgbọ́kànlé kíkún nínú Jèhófà?