Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé O Máa Ń Gbádùn Kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

Ṣé O Máa Ń Gbádùn Kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

Ṣé O Máa Ń Gbádùn Kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

LORRAINE sọ pé: “Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì déédéé, ńṣe ló dà bí ohun tó nira láti ṣe tí kì í fi bẹ́ẹ̀ gbádùn mọ́ni. Ó ṣòro fún mi láti lóye ohun tí mo bá kà, torí náà ọ̀pọ̀ ìgbà ni mi ò kì í lè pọkàn pọ̀.”

Àwọn míì náà sọ pé àwọn kò gbádùn kíka Bíbélì nígbà táwọn bẹ̀rẹ̀ sí í kà á. Àmọ́, wọ́n tẹra mọ́ kíka Ìwé Mímọ́ torí wọ́n mọ̀ pé ohun tó yẹ káwọn ṣe nìyẹn. Marc sọ pé: “Kì í pẹ́ tí ọkàn èèyàn fi máa ń pínyà béèyàn bá ń ka Bíbélì tàbí tó ń dá kẹ́kọ̀ọ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo gbàdúrà tí mo sì sapá gidigidi kí Bíbélì kíkà tó di ọ̀kan lára ohun tí mo máa ń ṣe lójoojúmọ́.”

Kí lo lè ṣe kó o bàa lè túbọ̀ ní ìmọrírì fún Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Báwo lo ṣe lè máa gbádùn kíkà á? Gbé àwọn àbá yìí yẹ̀ wò.

Àfojúsùn Tó Yẹ Kó O Ní àti Bó Ṣe Yẹ Kó O Máa Kà Á

Gbàdúrà kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì kó o sì pọkàn pọ̀. Bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó lè máa wù ẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ṣí ọkàn-àyà àti èrò inú rẹ payá kó o lè túbọ̀ lóye ọgbọ́n rẹ̀. (Sm. 119:34) Bí o bá ń ka Bíbélì láì kọ́kọ́ gbàdúrà, ó lè máà pẹ́ táá fi dà bí ìgbà tó o kàn ń kàwé lásán, ó sì lè sú ẹ. Lynn sọ pé: “Nígbà míì, mo máa ń yára ju bó ṣe yẹ lọ bí mo bá ń ka Bíbélì, èyí sì máa ń mú kí n gbójú fo àwọn kókó tó fani mọ́ra. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tí mò ń kà kì í yé mi dáadáa. Àmọ́, mo gbàdúrà pé kí Ọlọ́run jẹ́ kí n lè máa kó ara mi níjàánu èyí sì mú kí n lè máa pọkàn pọ̀.”

Fi ọwọ́ pàtàkì mú ohun tó o bá kọ́. Rántí pé ó ṣe pàtàkì kó o lóye òtítọ́ Bíbélì kó o sì máa fi sílò kó o bàa lè jèrè ìyè. Torí náà sapá gidigidi láti wá àwọn kókó tó máa ṣe ẹ́ láǹfààní kó o sì fi wọ́n sílò. Chris sọ pé: “Mo máa ń wá àwọn ohun tó lè ràn mí lọ́wọ́ láti mọ àwọn ìwà tí kò dára tàbí èrò òdì tí mo bá ní. Ó máa ń múnú mi dùn láti rí i pé Bíbélì àti àwọn ìtẹ̀jáde wa ní àwọn ìsọfúnni tó lè ṣe mí láǹfààní, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó kọ ọ́ kò mọ̀ mí rí.”

Ní àwọn àfojúsùn tí ọwọ́ rẹ lè tẹ̀. Sapá láti mọ ohun tí o kò tíì mọ̀ rí nípa àwọn èèyàn inú Bíbélì. O lè rí ọ̀pọ̀ ohun tó fani lọ́kàn mọ́ra kọ́ nípa ọ̀pọ̀ lára wọn tó o bá ṣàyẹ̀wò ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Insight on the Scriptures tàbí ìwé atọ́ka náà, Watch Tower Publications Index. Bó o bá ṣe ń mọ púpọ̀ sí i nípa ìwà àti ìmọ̀lára àwọn ọkùnrin àti obìnrin tó wà nínú Bíbélì tó o sì rí i pé èèyàn bíi tìẹ làwọn náà, wàá túbọ̀ lè máa jàǹfààní látinú àpẹẹrẹ wọn.

Wá àwọn ọ̀nà míì tó o lè gbà máa fèrò wérò látinú Ìwé Mímọ́. (Ìṣe 17:2, 3) Ohun tí Sophia máa ń ní lọ́kàn nìyẹn tó bá ń ka Bíbélì. Ó sọ pé: “Ó wù mí pé kí n mọ àwọn ọ̀nà míì tí mo lè gbà máa fèrò wérò pẹ̀lú àwọn èèyàn lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi àti láwọn àkókò mìíràn, kí n lè máa ṣàlàyé òtítọ́ Bíbélì fún wọn lọ́nà tó ṣe kedere. Ọ̀nà tí ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ máa ń gbà fèrò wérò lórí Ìwé Mímọ́ jẹ́ àpẹẹrẹ tó dára nípa bá a ṣe lè ṣe èyí.”—2 Tím. 2:15.

Fi ojú inú yàwòrán àwọn ìtàn inú Bíbélì. Ìwé Hébérù 4:12 sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè.” Bó o bá ń ka Ìwé Mímọ́, jẹ́ kí ohun tí Ọlọ́run ń sọ máa wọ̀ ẹ́ lọ́kàn nípa fífi ojú inú yàwòrán ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó ò ń kà nípa wọn. Gbìyànjú láti gbọ́ ohun tí wọ́n ń gbọ́, kó o sì ní irú ìmọ̀lára tí wọ́n ní. Kó o wá fi ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wọn wé ohun pàtó kan tó ń ṣẹlẹ̀ ní ìgbésí ayé rẹ. Kọ́ ẹ̀kọ́ látinú bí wọ́n ṣe bójú tó ọ̀ràn tó dojú kọ wọ́n. Èyí á jẹ́ kó o ní òye tó sunwọ̀n sí i, á sì túbọ̀ rọrùn fún ẹ láti rántí ohun tó o kà.

Máa lo àkókò tó pọ̀ lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ṣòroó lóye àti àwọn àlàyé wọn kó o lè lóye wọn dáadáa. Máa lo àkókò tó pọ̀ ní gbogbo ìgbà tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́. Ó ṣeé ṣe kó o rí àwọn ìbéèrè tó fani mọ́ra tó máa gba pé kó o ṣe ìwádìí lé lórí. Bó bá jẹ́ pé Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun èyí tó ní atọ́ka lò ń lò, ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣòro láti lóye, wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé àti ibi tí wọ́n ti tọ́ka sí àwọn ẹsẹ Bíbélì míì. Bí o bá ṣe ń lóye ohun tó ò ń kà, tó o sì ń fi sílò bẹ́ẹ̀ ni wàá ṣe túbọ̀ máa gbádùn kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Wàá lè sọ bíi ti onísáàmù náà pé: “Mo ti gba àwọn ìránnilétí [Jèhófà] gẹ́gẹ́ bí ohun ìní fún àkókò tí ó lọ kánrin, nítorí pé àwọn ni ayọ̀ ńláǹlà ọkàn-àyà mi.”—Sm. 119:111.

Má ṣe máa kánjú kàwé nígbà tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́. Má ṣe jẹ́ kí àkókò tó ò ń lò fún ìdákẹ́kọ̀ọ́ pọ̀ jù, má sì jẹ́ kó kéré jù. Má ṣe jẹ́ kí àkókò tó o fi ń dá kẹ́kọ̀ọ́ pa àkókò tó o fi ń múra sílẹ̀ fún àwọn ìpàdé ìjọ lára. Raquel sọ pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà ara mi kì í balẹ̀ ó sì máa ń ṣòro fún mi láti pọkàn pọ̀. Torí náà mo rí i pé ara máa ń tù mí bí àkókò tí mo fi kẹ́kọ̀ọ́ kò bá gùn púpọ̀. Èyí sì máa ń jẹ́ kí n jàǹfààní tó pọ̀ jù lọ látinú ohun tí mò ń kọ́.” Chris sọ pé: “Bí mo bá ń kánjú kàwé mi kì í rántí nǹkan púpọ̀, èyí sì máa ń mú kí ẹ̀rí ọkàn mi dà mí láàmú. Ohun tí mò ń kà kì í wọ̀ mí lọ́kàn.” Torí náà, ó dára láti máa fara balẹ̀.

Túbọ̀ máa ní ìyánhànhàn fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ jòjòló tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, ẹ ní ìyánhànhàn fún wàrà aláìlábùlà tí ó jẹ́ ti ọ̀rọ̀ náà, pé nípasẹ̀ rẹ̀ kí ẹ lè dàgbà dé ìgbàlà.” (1 Pét. 2:2) A kì í retí pé kí àwọn ọmọdé ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ bí wọ́n ṣe máa ní ìyánhànhàn fún wàrà. Ńṣe ni Ọlọ́run dá ìfẹ́ fún mímu wàrà mọ́ wọn. Àmọ́ Ìwé Mímọ́ sọ pé a gbọ́dọ̀ ní ìyánhànhàn fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bó o bá ń ka ojú ìwé kan ṣoṣo péré nínú Bíbélì lójoojúmọ́, kò ní pẹ́ tí wàá fi ní ìyánhànhàn yẹn. Nípa bẹ́ẹ̀, ohun tó ti kọ́kọ́ dà bí èyí tó nira tẹ́lẹ̀ á wá di èyí tó gbádùn mọ́ ẹ.

Máa ṣe àṣàrò lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o bá kà. O tún lè rí ọ̀pọ̀ àǹfààní nínú ohun tó o kà, bó o bá ṣe àṣàrò lé e lórí. Èyí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti rí bí àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì tó o ti ṣèwádìí lé lórí ṣe tan mọ́ra. Kò ní pẹ́ tí wàá fi rí i pé òye rẹ nípa tẹ̀mí ti pọ̀ sí i, ìyẹn á sì máa fún ẹ láyọ̀.—Sm. 19:14; Òwe 3:3.

Ọ̀nà Rere Tó O Lè Gbà Lo Àkókò Rẹ

Ó gba ìsapá kó tó lè mọ́ni lára láti máa kẹ́kọ̀ọ́ bó ṣe yẹ, àmọ́ àwọn ìbùkún tó wà níbẹ̀ kò lóǹkà. Wàá túbọ̀ lóye Ìwé Mímọ́ sí i. (Héb. 5:12-14) Ìfòyemọ̀ àti ọgbọ́n tó o máa rí látinú Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí máa mú kó o ní ayọ̀, ìtura àti àlàáfíà. “Igi ìyè” ni ọgbọ́n tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní ìmísí jẹ́ fún àwọn tó bá wá a rí tí wọ́n sì ń fi í sílò.—Òwe 3:13-18.

Bí o bá kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jinlẹ̀, ó lè mú kó o ní ọkàn-àyà tó ní òye. (Òwe 15:14) Ìyẹn á ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa fúnni ní ìmọ̀ràn àtọkànwá tá a gbé karí Bíbélì. Bó o bá ń gbé ìpinnu rẹ karí àwọn ohun tó ò ń kà nínú Ìwé Mímọ́ àti àwọn ìtẹ̀jáde tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè, wàá rí i pé Ọ̀rọ̀ Jèhófà tó ní ìmísí á máa tù ẹ́ lára á sì jẹ́ kó o fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin. (Mát. 24:45) Wàá túbọ̀ máa ní èrò tó dára, o ò ní sọ̀rètí nù, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni yóò sì máa darí ọ̀rọ̀, èrò àti ìwà rẹ. Síwájú sí i, gbogbo nǹkan tó bá kan àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run ló máa yọrí sí rere.—Sm. 1:2, 3.

Bó o bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tọkàntọkàn, ó máa wù ẹ́ láti sọ ohun tó o gbà gbọ́ fún àwọn ẹlòmíì. Ìyẹn pẹ̀lú lè ṣe ẹ́ láǹfààní púpọ̀. Ohun tí Sophia ń ṣiṣẹ́ lé lórí báyìí ni bó ṣe lè máa rántí onírúurú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kó sì máa lò wọ́n láti mú kí àwọn onílé pọkàn pọ̀ sórí ohun tó ń sọ àti bó ṣe lè mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni gbéṣẹ́ kó sì máa fún un láyọ̀. Ó sọ pé: “Bí àwọn èèyàn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ tó wà nínú Bíbélì, bó ṣe máa ń rí lára wọn máa ń mú inú mi dùn gan-an ni.”

Àmọ́ ṣá o, àǹfààní títayọ jù lọ tó wà nínú jíjẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa gbádùn mọ́ni ni pé ó máa jẹ́ kéèyàn ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà. Bó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wàá mọ àwọn ìlànà Ọlọrun wàá sì mọrírì ìfẹ́, ìwà ọ̀làwọ́ àti ìdájọ́ òdodo rẹ̀. Kò sí àfojúsùn míì tó ṣe pàtàkì tó sì lè ṣeni láǹfààní tó èyí. Fi ara rẹ fún kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pátápátá. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ ọ̀nà rere tó o lè gbà lo àkókò rẹ.—Sm. 19:7-11.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

KÍKA Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN: ÀFOJÚSÙN TÓ YẸ KÓ O NÍ ÀTI BÓ ṢE YẸ KÓ O MÁA KÀ Á

▪ Gbàdúrà kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì kó o sì pọkàn pọ̀.

▪ Fi ọwọ́ pàtàkì mú ohun tó o bá kọ́.

▪ Ní àwọn àfojúsùn tí ọwọ́ rẹ lè tẹ̀.

▪ Wá àwọn ọ̀nà míì tó o lè gbà máa fèrò wérò látinú Ìwé Mímọ́.

▪ Fi ojú inú yàwòrán àwọn ìtàn inú Bíbélì.

▪ Máa lo àkókò tó pọ̀ lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ṣòroó lóye àti àwọn àlàyé wọn kó o lè lóye wọn dáadáa.

▪ Má ṣe máa kánjú kàwé nígbà tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́.

▪ Túbọ̀ máa ní ìyánhànhàn fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

▪ Máa ṣe àṣàrò lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o bá kà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Tó o bá ń ka ìtàn kan nínú Bíbélì, máa fojú inú wò ó pé ìwọ náà wà níbẹ̀