“Alábòójútó Rere àti Ọ̀rẹ́ Wa Ọ̀wọ́n”
“Alábòójútó Rere àti Ọ̀rẹ́ Wa Ọ̀wọ́n”
ARÁKÙNRIN JOHN (JACK) BARR, tó sìn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà parí iṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ní àárọ̀ Saturday, December 4, 2010. Ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún [97]. Àwọn tó mọ̀ ọ́n dáadáa sọ pé ó jẹ́ “alábòójútó rere àti ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n.”
Ìlú Aberdeen, lórílẹ̀-èdè Scotland ni wọ́n bí Arákùnrin John Barr sí, ọmọ mẹ́ta ni àwọn òbí rẹ̀ bí, òun sì ni àbígbẹ̀yìn. Ẹni àmì òróró ni àwọn òbí rẹ̀. Bí Arákùnrin Barr bá rántí ìgbà tó wà lọ́mọdé, tayọ̀tayọ̀ ló fi máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìdílé rẹ̀; ó mọyì àpẹẹrẹ àtàtà tí bàbá àti ìyá rẹ̀ fi lélẹ̀.
Gẹ́rẹ́ tí Arákùnrin Barr pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣòro gan-an fún láti bá ẹni tí kò bá mọ̀ rí sọ̀rọ̀. Àmọ́, ó sapá gidigidi láti borí ìṣòro náà, nígbà tó sì di ọ̀sán ni ọjọ́ Sunday kan báyìí ní ọdún 1927, ìyẹn nígbà tó ti pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, ó sọ fún bàbá rẹ̀ pé òun ti ṣe tán láti máa bá a lọ sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé. Bó ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí Jèhófà nìyẹn o. Láti ọjọ́ yẹn títí tí Arákùnrin Barr fi kú kò dẹ́kun láti máa fi ìtara wàásù ìhìn rere.
Jàǹbá burúkú kan tó fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ̀mí ìyá Arákùnrin John Barr mú kó ronú jinlẹ̀ nípa ète ìgbésí ayé, èyí sì mú kó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà ní ọdún 1929, ó sì fi ẹ̀rí èyí hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi ní gbàrà tí àǹfààní ṣí sílẹ̀ fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ ní ọdún 1934. Lẹ́yìn náà, ó di ọ̀kan lára ìdílé Bẹ́tẹ́lì nílùú London, ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ní ọdún 1939. Bó ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tó fi ṣe iṣẹ́ ìgbésí ayé rẹ̀ nìyẹn. Ó sì lo ọdún mọ́kànléláàádọ́rin [71] lẹ́nu iṣẹ́ náà.
Ní October 29, 1960, Arákùnrin Barr bẹ̀rẹ̀ ohun tó pè ní “àjọṣe tó ṣeyebíye jù lọ” nígbà tó fẹ́ Mildred Willett, tó ti ń fi ìtara ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àti iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì láti ìgbà pípẹ́. Àwọn tó mọ Arákùnrin àti Arábìnrin Barr mọ̀ pé tọkọtaya tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ ni wọ́n, bí wọ́n sì ṣe wà nìyẹn títí tí Mildred fi parí iṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ní oṣù October, ọdún 2004. Láti ìgbà tí Arákùnrin àti Arábìnrin Barr ti ṣe ìgbéyàwó, wọ́n jùmọ̀ máa ń ka apá díẹ̀ nínú Bíbélì lójoojúmọ́.
Bí àwọn tó mọ Arákùnrin Barr bá gbọ́ orúkọ náà, Jack Barr, ńṣe ló máa mú kí wọ́n rántí ọkùnrin kan tó máa ń fúnni ní ìmọ̀ràn tó fi àròjinlẹ̀ hàn, tí kì í fì sí apá kan ju ìkan lọ, tó máa ń fi inúure hàn, tó sì mọ Ìwé Mímọ́ dunjú. Ó jẹ́ òṣìṣẹ́ aláápọn, alábòójútó tó máa ń gba tẹni rò tó sì máa ń fìfẹ́ hàn àti ọ̀rẹ́ tó jẹ́ adúróṣinṣin. Àwọn ọ̀rọ̀, àsọyé àti àdúrà rẹ̀ máa ń fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ tó jinlẹ̀ fún òtítọ́ àti pé ó ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àárò Arákùnrin Barr tó jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n á máa sọ wá, a bá a yọ pé ó gba ẹ̀bùn àìleèkú, àǹfààní tó ti ń fojú sọ́nà fún tó sì sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ohun tó ti ń retí gan-an nìyẹn.—1 Kọ́r. 15:53, 54. *
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Bó o bá fẹ́ ka ìtàn ìgbésí ayé Arákùnrin John E. Barr, wo Ilé-ìṣọ́nà July 1, 1987, ojú ìwé 26 sí 31.