Bá A Ṣe Lè Máa Tọ Kristi Aṣáájú Pípé Náà Lẹ́yìn
Bá A Ṣe Lè Máa Tọ Kristi Aṣáájú Pípé Náà Lẹ́yìn
ÀWỌN tó máa ń tọ àwọn èèyàn tó jẹ́ alákòóso lẹ́yìn sábà máa ń ní ìjákulẹ̀. Àmọ́ ipa ti ipò Kristi tó jẹ́ aṣáájú ń ní lórí àwọn tó wà lábẹ́ rẹ̀ yàtọ̀ pátápátá síyẹn. Jésù sọ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín.” (Mát. 11:28, 29) Aṣáájú tó ń mára tuni tó sì ń múni láyọ̀ ni Jésù. Ọ̀ràn àwọn ẹni rírẹlẹ̀ àti àwọn tí a tẹ̀ lórí ba máa ń jẹ ẹ́ lógún gan-an, ó sì ké sí wọn pé kí wọ́n wá sábẹ́ àjàgà òun tí ó jẹ́ ti inú rere. Àmọ́, kí ló túmọ̀ sí láti máa tọ Jésù tó jẹ́ aṣáájú lẹ́yìn?
Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Kristi . . . jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” (1 Pét. 2:21) Báwo ló ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Jésù? Ká sọ pé ìwọ àtàwọn kan fẹ́ gba orí pápá kan tí wọ́n ri àwọn àdó olóró sí kọjá, ẹnì kan ṣoṣo nínú yín ló sì mọ bí ẹ ṣe lè rìn tí ẹ fi máa kọjá láìfarapa. Ṣé o kò ní máa tẹ̀ lé onítọ̀hún pẹ́kípẹ́kí, bóyá kó o tiẹ̀ máa gbé ẹsẹ̀ sí ibi tó bá ń tẹ̀ pàápàá? Lọ́nà kan náà, bá a bá fẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la wa dára àfi ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nínú ọ̀nà tá a gbà ń gbé ìgbé ayé wa. Lára ọ̀nà tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa fetí sí i, ká máa ṣègbọràn sí i, ká sì máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń ṣojú fún un.
Gbọ́ Kí O sì Ṣègbọràn
Nígbà tí ìwàásù tí Jésù ṣe lórí òkè ń parí lọ, ó sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó gbọ́ àwọn àsọjáde tèmi wọ̀nyí, tí ó sì ń ṣe wọ́n ni a ó fi wé ọkùnrin olóye, ẹni tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí àpáta ràbàtà. Òjò sì tú dà sílẹ̀, ìkún omi sì dé, ẹ̀fúùfù sì fẹ́, wọ́n sì bì lu ilé náà, ṣùgbọ́n kò ya lulẹ̀, nítorí a ti fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ sórí àpáta ràbàtà.”—Mát. 7:24, 25.
Nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí, ó pe ọkùnrin tó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó sì ṣègbọràn sí i ní “olóye.” Ṣé à ń fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún Kristi a sì mọrírì àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀ nípa ṣíṣègbọràn sí i látọkànwá, àbí èyí tó bá wù wá tàbí tó rọ̀ wá lọ́rùn lára àwọn ìtọ́ni Jésù la máa ń yàn láti ṣègbọràn sí? Jésù sọ pé: ‘Nígbà gbogbo ni mo ń ṣe ohun tí ó wu Ọlọ́run.’ (Jòh. 8:29) Ẹ jẹ́ ká sapá láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ yẹn.
Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn àpọ́sítélì fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ ní ti bó ṣe yẹ ká máa tẹrí ba fún Kristi tó jẹ́ aṣáájú. Nígbà kan, Pétérù sọ fún Jésù pé: “Wò ó! Àwa ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì ti ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.” (Máàkù 10:28) Kò sí àní-àní pé àwọn àpọ́sítélì fọwọ́ pàtàkì mú ipò Jésù tó jẹ́ aṣáájú débi pé wọ́n fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda láti fi àwọn nǹkan míì sílẹ̀ kí wọ́n lè máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.—Mát. 4:18-22.
Fọwọ́ Sowọ́ Pọ̀ Pẹ̀lú Àwọn Tó Ń Ṣojú fún Kristi
Ní àkókò díẹ̀ kí Jésù tó kú, ó sọ ọ̀nà míì tá a lè gbà máa tọ òun lẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú wa. Ó sọ pé: “Ẹni tí ó bá gba ẹnikẹ́ni tí mo rán, gba èmi pẹ̀lú.” (Jòh. 13:20) Kódà, Jésù pe àwọn ẹni àmì òróró tó ń ṣojú fún un ní “àwọn arákùnrin” òun. (Mát. 25:40) Lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti jí Jésù dìde sí ọ̀run, ó yan “àwọn arákùnrin” rẹ̀ láti máa ṣojú fún òun, wọ́n ń “dípò fún Kristi” gẹ́gẹ́ bí ikọ̀ tó ń ké sí àwọn míì pé kí wọ́n pa dà bá Jèhófà Ọlọ́run rẹ́. (2 Kọ́r. 5:18-20) Lára ọ̀nà tá a lè gbà fi hàn pé a gbà pé Kristi ni aṣáájú wa ni pé ká máa wà ní ìtẹríba fún “àwọn arákùnrin” rẹ̀.
Ó dára ká ṣe àgbéyẹ̀wò ọwọ́ tá a fi ń mú àwọn ìmọ̀ràn tá a gbé karí Ìwé Mímọ́ tó sì bá àkókò mu, èyí tá à ń rí nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa tó ń ṣàlàyé Bíbélì. Bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ tá a sì ń lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ ń mú ká rántí àwọn ọ̀rọ̀ Kristi. (2 Pét. 3:1, 2) A lè fi hàn pé a ní ìmọrírì àtọkànwá fún àwọn oúnjẹ tẹ̀mí wọ̀nyí, bí a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ déédéé tí a kì í sì í pa ìpàdé jẹ. Àmọ́, kí ló yẹ ká ṣe bí a bá ń gbọ́ àwọn ìtọ́ni kan lóòrèkóòrè? Bí àpẹẹrẹ, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún àwọn Kristẹni ní ìtọ́ni láti ṣègbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.” (1 Kọ́r. 7:39) Ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún báyìí tí ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ti ń jíròrò kókó yìí látìgbàdégbà. Ó dájú pé àwọn arákùnrin Kristi nífẹ̀ẹ́ wa wọ́n sì fẹ́ ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà ni wọ́n ṣe máa ń tẹ àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí kókó yìí àti ìmọ̀ràn míì tí Ọlọ́run mí sí. Títẹ́tí sí àwọn ìránnilétí wọ̀nyí jẹ́ ọ̀nà kan tá a lè gbà fi hàn pé à ń tọ Jésù Kristi, Aṣáájú wa pípé lẹ́yìn.
Ìwé Òwe 4:18 sọ pé: “Ipa ọ̀nà àwọn olódodo dà bí ìmọ́lẹ̀ mímọ́lẹ̀ yòò, tí ń mọ́lẹ̀ síwájú àti síwájú sí i, títí di ọ̀sán gangan.” Kò sí àníàní pé Jésù Aṣáájú wa ń tẹ̀ síwájú, kò sì dúró sójú kan. Ọ̀nà míì tá a tún lè gbà fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú “àwọn arákùnrin” Kristi ni pé ká máa ní èrò tó dára bí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” bá lo àwọn ìtẹ̀jáde wa láti ṣe àtúnṣe èyíkéyìí sí òye tá a ní nípa àwọn ẹ̀kọ́ inú Ìwé Mímọ́.—Mát. 24:45.
A tún ń fi hàn pé a wà ní ìtẹríba fún “àwọn arákùnrin” Kristi bí a bá ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alábòójútó tá a yàn sípò nínú ìjọ Kristẹni. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba, nítorí wọ́n ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn yín.” (Héb. 13:17) Bí àpẹẹrẹ, alàgbà kan lè fún wa níṣìírí lórí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká ní ìrọ̀lẹ́ kan tá a fi ń ṣe Ìjọsìn Ìdílé wa déédéé tàbí kó fún wa láwọn àbá tó máa jẹ́ ká lè mú àwọn apá kan nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa sunwọ̀n sí i. Alábòójútó àyíká kan lè fún wa láwọn ìmọ̀ràn tá a gbé ka Ìwé Mímọ́ nípa irú ìwà tó yẹ kí Kristẹni máa hù. Bó bá jẹ́ pé tọkàntọkàn la fi ń fi irú àwọn ìmọ̀ràn wọ̀nyí sílò, ó fi hàn pé à ń tọ Jésù tó jẹ́ Aṣáájú wa lẹ́yìn.
Ó bani nínú jẹ́ pé ayé yìí kò ní aṣáájú tó lè ṣàkóso bó ṣe tọ́. Àmọ́ ẹ wo bó ti tuni lára tó láti máa tọ Kristi aṣáájú wa onífẹ̀ẹ́ lẹ́yìn! Ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti rí i pé à ń ṣègbọràn sí Aṣáájú wa, a sì ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń lò lónìí.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Ǹjẹ́ o fara mọ́ ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ tó sọ pé ká má ṣe fẹ́ aláìgbàgbọ́?