Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ta Ló Ṣe Pàtàkì Jù Lọ ní Ìgbésí Ayé Rẹ?

Ta Ló Ṣe Pàtàkì Jù Lọ ní Ìgbésí Ayé Rẹ?

Ta Ló Ṣe Pàtàkì Jù Lọ ní Ìgbésí Ayé Rẹ?

“Ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”—SM. 83:18.

1, 2. Kí nìdí tí wíwulẹ̀ mọ orúkọ Jèhófà kò fi tó fún wa láti rí ìgbàlà?

 BÓYÁ ìgbà tí wọ́n fi orúkọ Jèhófà hàn ẹ́ nínú Sáàmù 83:18 lo kọ́kọ́ rí orúkọ yẹn. Ó tiẹ̀ lè yà ẹ́ lẹ́nu láti ka ohun tó wà níbẹ̀, pé: “Kí àwọn ènìyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” Kò sí iyè méjì pé látìgbà tí wọ́n ti fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn hàn ẹ́, o ti lò ó láti ran àwọn míì lọ́wọ́ láti wá mọ Jèhófà, Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́.—Róòmù 10:12, 13.

2 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣe pàtàkì pé káwọn èèyàn mọ orúkọ Jèhófà, irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ nìkan kò tó. Kíyè sí bí onísáàmù náà ṣe tẹnu mọ́ òtítọ́ pàtàkì mìíràn tá a gbọ́dọ̀ mọ̀ ká bàa lè rí ìgbàlà, nígbà tó sọ pé: “Ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ni Ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ láyé àtọ̀run. Torí pé òun ni Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo, ó ní ẹ̀tọ́ láti retí pé kí gbogbo ohun tó dá máa tẹrí ba fún un nínú ohun gbogbo. (Ìṣí. 4:11) Èyí wá mú ká rí ìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa bi ara wa pé, ‘Tá lo ṣe pàtàkì jù lọ ní ìgbésí ayé mi?’ Ó ṣe pàtàkì pé ká fara balẹ̀ ṣe àyẹ̀wò ìdáhùn wa sí ìbéèrè yẹn!

Ọ̀ràn Tó Wáyé Nínú Ọgbà Édẹ́nì

3, 4. Kí ló mú kó ṣeé ṣe fún Sátánì láti tan Éfà jẹ, kí ló sì jẹ́ àbájáde rẹ̀?

3 Ìbéèrè pàtàkì ni ìbéèrè tó yẹ ká bi ara wa yìí. A sì lè rí bó ti ṣe pàtàkì tó nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé nígbà yẹn lọ́hùn-ún nínú ọgbà Édẹ́nì. Ibẹ̀ ni áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ tá a wá mọ̀ sí Sátánì Èṣù ti tan Éfà, obìnrin àkọ́kọ́ jẹ. Ó mú kí ìfẹ́ ọkàn Éfà jẹ ẹ́ lógún ju àṣẹ tí Jèhófà pa fún wọn pé wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ èso ọ̀kan lára àwọn igi tó wà nínú ọgbà náà. (Jẹ́n. 2:17; 2 Kọ́r. 11:3) Bí Éfà ṣe gbà kí Sátánì tan òun jẹ yìí fi hàn pé kò bọ̀wọ̀ fún ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ. Éfà kò ka Jèhófà sí Ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ ní ìgbésí ayé rẹ̀. Àmọ́, kí ló mú kó ṣeé ṣe fún Sátánì láti tan Éfà jẹ?

4 Onírúurú ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ ni Sátánì lò nígbà tó ń bá Éfà sọ̀rọ̀. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5.) Lákọ̀ọ́kọ́, Sátánì kò lo Jèhófà tó jẹ́ orúkọ Ọlọ́run. Ńṣe ló wulẹ̀ pè é ní “Ọlọ́run.” Àmọ́, ẹni tó kọ ìwé Jẹ́nẹ́sísì kò ṣe bẹ́ẹ̀ ní tiẹ̀, ó lo Jèhófà tó jẹ́ orúkọ Ọlọ́run ní ẹsẹ àkọ́kọ́ nínú orí yẹn. Èkejì, dípò kí Sátánì sọ̀rọ̀ nípa “àṣẹ” Ọlọ́run ńṣe ló wulẹ̀ bi Éfà nípa ohun tí Ọlọ́run “sọ.” (Jẹ́n. 2:16) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé nítorí kí Sátánì lè mú kí àṣẹ Ọlọ́run fara hàn bí èyí tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì ló ṣe lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ yẹn. Ẹ̀kẹta, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Éfà nìkan ni Sátánì ń bá sọ̀rọ̀, ó lo ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ náà, “ẹ̀yin,” èyí tó wà fún ẹni méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ló gbìyànjú láti gbin ẹ̀mí ìgbéraga sí Éfà lọ́kàn, ó mú kó rí ara rẹ̀ bí ẹni pàtàkì, bí ẹni pé òun ló ń gbẹnu sọ fún ara rẹ̀ àti ọkọ rẹ̀. Ibo lọ̀rọ̀ náà wá já sí? Àfàìmọ̀ kí Éfà má rò pé ńṣe ni òun ń gbẹnu sọ fún àwọn méjèèjì nígbà tó sọ fún ejò náà pé: “Àwa lè jẹ nínú àwọn èso igi ọgbà.”

5. (a) Kí ni Sátánì mú kí Éfà pọkàn pọ̀ lé lórí? (b) Kí ni jíjẹ tí Éfà jẹ́ èso tí Ọlọ́run sọ pé wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ náà fi hàn?

5 Sátánì tún yí òtítọ́ po. Ó dọ́gbọ́n sọ pé kò dáa bí Ọlọ́run ṣe sọ pé Ádámù àti Éfà “kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú gbogbo igi ọgbà.” Lẹ́yìn náà, Sátánì mú kí Éfà bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa ara rẹ̀ àti bó ṣe lè fi ọwọ́ ara rẹ̀ tún ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ ṣe, kó lè dà “bí Ọlọ́run.” Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó mú kó pọkàn pọ̀ sórí igi náà àti èso rẹ̀ dípò tí ì bá fi pọkàn pọ̀ sórí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ẹni tó fún un ní ohun gbogbo. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:6.) Ó bani nínú jẹ́ pé jíjẹ tí Éfà jẹ èso náà fi hàn pé Jèhófà kọ́ ni Ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ ní ìgbésí ayé rẹ̀.

Ọ̀ràn Tó Wáyé Nígbà Ayé Jóòbù

6. Báwo ni Sátánì ṣe fẹ̀sùn kan Jóòbù nítorí ìwà títọ́ rẹ̀, àǹfààní wo nìyẹn sì mú kó ṣí sílẹ̀ fún Jóòbù?

6 Ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn náà, Jóòbù, ọkùnrin olóòótọ́ náà ní àǹfààní láti fi Ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ ní ìgbésí ayé rẹ̀ hàn. Nígbà tí Jèhófà sọ̀rọ̀ nípa ìwà títọ́ Jóòbù lójú Sátánì, Sátánì fìbínú fèsì pé: “Lásán ha ni Jóòbù ń bẹ̀rù Ọlọ́run bí?” (Ka Jóòbù 1:7-10.) Sátánì kò jiyàn pé Jóòbù ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Ìdí tó fi ń ṣègbọràn gan-an ni ẹ̀sùn tó fi kan Jóòbù dá lé. Lọ́nà ọgbọ́n ẹ̀wẹ́, ó fẹ̀sùn kan Jóòbù pé kì í ṣe torí pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ló ṣe ń sìn ín, bí kò ṣe nítorí ohun tó ń rí gbà lọ́wọ́ rẹ̀. Jóòbù nìkan ló lè já ẹ̀sùn yẹn nírọ́, Jèhófà sì fún un láǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀.

7, 8. Àwọn àdánwò wo ló dé bá Jóòbù, kí ni bó ṣe fi ìṣòtítọ́ fara dà á sì fi hàn?

7 Jèhófà fàyè gba Sátánì láti mú ọ̀kan-kò-jọ̀kan ìjábá dé bá Jóòbù, ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. (Jóòbù 1:12-19) Báwo ni ìyípadà tó dé bá Jóòbù yìí ṣe rí lára rẹ̀? Bíbélì sọ fún wa pé “kò dẹ́ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ka ohunkóhun tí kò bẹ́tọ̀ọ́ mu sí Ọlọ́run lọ́rùn.” (Jóòbù 1:22) Síbẹ̀, Sátánì kò dẹ̀yìn lẹ́yìn rẹ̀. Ó tún ṣàròyé síwájú sí i pé: “Awọ fún awọ, ohun gbogbo tí ènìyàn bá sì ní ni yóò fi fúnni nítorí ọkàn rẹ̀.” * (Jóòbù 2:4) Sátánì fẹ̀sùn kan Jóòbù pé bí ọwọ́ ìyà bá tó o, ó máa pinnu pé kì í ṣe Jèhófà ni Ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ ní ìgbésí ayé òun.

8 Àìsàn burúkú kan sọ ẹran ara Jóòbù dìdàkudà, ìyàwó rẹ̀ sì tún fúngun mọ́ ọn pé kó bú Ọlọ́run kó sì kú. Lẹ́yìn náà, àwọn olùtùnú èké mẹ́ta fẹ̀sùn kàn án pé ńṣe ló hùwà tí kò dáa. (Jóòbù 2:11-13; 8:2-6; 22:2, 3) Àmọ́ ṣá o, ní gbogbo ìgbà tí Jóòbù fi jẹ̀rora, ó di ìwà títọ́ rẹ̀ mú. (Ka Jóòbù 2:9, 10.) Bí Jóòbù ṣe fara dà á láìjuwọ́sílẹ̀ fi hàn pé Jèhófà ni Ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ ní ìgbésí ayé rẹ̀. Jóòbù tún fi hàn pé ó ṣeé ṣe fún ẹ̀dá aláìpé láti já ẹ̀sùn èké Èṣù nírọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ nínú ọ̀ràn tí kò fi bẹ́ẹ̀ tó nǹkan.—Fi wé Òwe 27:11.

Jésù Já Ẹ̀sùn Èké Sátánì Nírọ́ Pátápátá

9. (a) Báwo ni Sátánì ṣe gbìyànjú láti fi ebi tó ń pa Jésù dẹ ẹ́ wò? (b) Kí ni Jésù ṣe nípa ìdẹwò náà?

9 Ní àkókò díẹ̀ lẹ́yìn tí Jésù ṣèrìbọmi, Sátánì gbìyànjú láti tàn án kó bàa lè máa lépa ìfẹ́ ìmọtara-ẹni-nìkan dípò kó fi Jèhófà ṣe Ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ ní ìgbésí ayé rẹ̀. Ìdẹwò mẹ́ta ni Èṣù gbé ka iwájú Jésù. Èyí àkọ́kọ́ ni pé ó fẹ́ kí Jésù tẹ́ ìfẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn, torí náà ó ní kó sọ àwọn òkúta di àkàrà. (Mát. 4:2, 3) Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ gbààwẹ̀ fún ogójì [40] ọjọ́ ni, ebi sì ń pa á gidigidi. Èṣù fẹ́ kó ṣi agbára tó ní láti ṣe iṣẹ́ ìyanu lò, torí náà, ó rọ̀ ọ́ pé kó fi agbára náà mú ebi tó ń pa á kúrò. Kí wá ni Jésù ṣe? Jésù kò ṣe bíi ti Éfà, ńṣe ló pọkàn pọ̀ sórí Ọ̀rọ̀ Jèhófà tó sì kọ ìdẹwò náà lójú ẹsẹ̀.—Ka Mátíù 4:4.

10. Kí nìdí tí Sátánì fi pe Jésù níjà pé kó fi ara rẹ̀ sọ̀kò sílẹ̀ láti orí odi òrùlé tẹ́ńpìlì?

10 Sátánì tún gbìyànjú láti tan Jésù kó bàa lè hùwà ìmọtara-ẹni-nìkan. Ó pe Jésù níjà pé kó fi ara rẹ̀ sọ̀kò sílẹ̀ láti orí odi òrùlé tẹ́ńpìlì. (Mát. 4:5, 6) Kí ló fà á tí Sátánì fi fẹ́ kó ṣe bẹ́ẹ̀? Ó sọ pé bí Jésù bá fi ara rẹ̀ sọ̀kò sílẹ̀, síbẹ̀ tí kò fara pa, lòun á tó gbà pé òótọ́ ló jẹ́ “ọmọ Ọlọ́run.” Ó dájú pé ńṣe ni Èṣù fẹ́ kí Jésù máa ṣàníyàn ju bó ṣe yẹ lọ nípa ohun táwọn èèyàn ń rò nípa rẹ̀ kó bàa lè fi irú ẹni tó jẹ́ hàn lọ́nà ṣekárími. Sátánì mọ̀ pé bí ẹnì kan bá rí ìpèníjà, ìgbéraga lè mú kó gbà láti ṣe ohun tó léwu kó má bàa tẹ́ lọ́wọ́ àwọn tó ń gba tiẹ̀. Sátánì ṣi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan lò, àmọ́ Jésù fi hàn pé Òun ní òye Ọ̀rọ̀ Jèhófà ní kíkún. (Ka Mátíù 4:7.) Bí Jésù kò ṣe gbà láti ṣe ohun tó léwu yẹn tún mú kó fi ẹ̀rí hàn pé Jèhófà ni Ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ ní ìgbésí ayé rẹ̀.

11. Kí nìdí tí Jésù fi kọ gbogbo ìjọba ayé tí Èṣù fi lọ̀ ọ́?

11 Ìdẹwò kẹta tó gbẹ̀yìn ló wá pabanbarì jù lọ, torí pé Sátánì fi gbogbo ìjọba ayé lọ Jésù. (Mát. 4:8, 9) Jésù kọ ohun tí Èṣù fi lọ̀ ọ́ lójú ẹsẹ̀. Ó mọ̀ pé bí òun bá gbà á, a jẹ́ pé òun kò fara mọ́ ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run, ìyẹn ẹ̀tọ́ tó ní gẹ́gẹ́ bí Ẹni Gíga Jù Lọ. (Ka Mátíù 4:10.) Nínú ìdẹwò kọ̀ọ̀kan, Jésù dá Sátánì lóhùn nípa fífa ọ̀rọ̀ yọ látinú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ní orúkọ Ọlọ́run.

12. Bí àkókò tí Jésù máa parí iṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ṣe ń sún mọ́lé, kí ni ipò líle koko tó dojú kọ Jésù, èyí tó béèrè pé kó pinnu ohun tó máa ṣe, kí la sì rí kọ́ látinú ọ̀nà tó gbà bójú tó ọ̀ràn náà?

12 Bí àkókò tí Jésù máa parí iṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ṣe ń sún mọ́lé, ó dojú kọ ipò líle koko kan tó béèrè pé kó pinnu ohun tó máa ṣe. Jálẹ̀ gbogbo àkókò tó fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ó fi hàn pé òun múra tán láti fi ẹ̀mí òun rúbọ. (Mát. 20:17-19, 28; Lúùkù 12:50; Jòh. 16:28) Àmọ́, Jésù tún mọ̀ pé wọ́n máa fi ẹ̀sùn èké kan òun, ilé ẹjọ́ àwọn Júù máa dá òun lẹ́bi, wọ́n sì tún máa pa òun gẹ́gẹ́ bí asọ̀rọ̀-òdì. Apá tó da ọkàn Jésù láàmú jù lọ nípa ikú rẹ̀ nìyí. Ó gbàdúrà pé: “Baba mi, bí ó bá ṣeé ṣe, jẹ́ kí ife yìí ré mi kọjá lọ.” Àmọ́, ó ń bá àdúrà náà lọ pé: “Síbẹ̀, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí èmi tí fẹ́, bí kò ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti fẹ́.” (Mát. 26:39) Kò sí àní-àní pé ìṣòtítọ́ Jésù títí dójú ikú fi ẹ̀rí tó ṣe kedere hàn nípa Ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ ní ìgbésí ayé rẹ̀!

Bí A Ṣe Lè Já Ẹ̀sùn Èké Sátánì Nírọ́

13. Àwọn ẹ̀kọ́ wo la ti rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Éfà, Jóòbù àti Jésù Kristi?

13 Àwọn ẹ̀kọ́ wo la ti rí kọ́? Nínú ọ̀ràn ti Éfà, a ti rí ẹ̀kọ́ kọ́ pé ńṣe ni àwọn tó bá jẹ́ kí ìfẹ́ ọkàn wọn jẹ wọ́n lógún jù tàbí tí wọ́n ní ẹ̀mí ìgbéraga ń fi hàn pé Jèhófà kọ́ ni Ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ ní ìgbésí ayé àwọn. Àmọ́, ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ nínú bí Jóòbù ṣe pa ìwà títọ́ mọ́ ni pé ó ṣeé ṣe fún ẹ̀dá èèyàn aláìpé pàápàá láti fi hàn pé Jèhófà làwọn fi sí ipò àkọ́kọ́ bí wọ́n bá ń fara da ìpọ́njú láìbọ́hùn, kódà bí wọn kò bá tiẹ̀ ní òye kíkún nípa ohun tó fa ìṣòro náà. (Ják. 5:11) Lákòótán, àpẹẹrẹ Jésù kọ́ wa láti múra tán láti fara da ẹ̀gàn àti pé ká má máa ṣàníyàn ju bó ṣe yẹ lọ nípa ohun táwọn èèyàn ń rò nípa wa. (Héb. 12:2) Àmọ́ báwo la ṣe lè máa fi àwọn ẹ̀kọ́ yìí sílò?

14, 15. Báwo ni ọ̀nà tí Jésù gbà kojú ìdẹwò ṣe yàtọ̀ sí ti Éfà, báwo la sì ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù? (Ṣàlàyé lórí àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18.)

14 Má ṣe jẹ́ kí ìdẹwò mú ẹ gbàgbé Jèhófà. Éfà kò ro ohun mìíràn, kìkì ìdẹwò tó dé bá a ló gbájú mọ́. Ó rí i pé èso náà “dára fún oúnjẹ àti pé ohun kan tí ojú ń yánhànhàn fún ni, bẹ́ẹ̀ ni, igi náà fani lọ́kàn mọ́ra láti wò.” (Jẹ́n. 3:6) Ìyẹn yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí Jésù ṣe nígbà tó dojú kọ ìdẹwò! Ó wò ré kọjá ìdẹwò kọ̀ọ̀kan tó dojú kọ ọ́, ó sì ronú nípa ohun tó máa jẹ́ àbájáde ọ̀nà tó bá gbà kojú ìdẹwò náà. Ó gbára lé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ó sì tún lo orúkọ Jèhófà.

15 Bí a bá dojú kọ ìdẹwò láti ṣe àwọn nǹkan tí kò dùn mọ́ Jèhófà nínú, kí ló máa ń gbà wá lọ́kàn? Bá a bá ṣe jẹ́ kí ìdẹwò náà gbà wá lọ́kàn tó, bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe túbọ̀ máa wù wá láti ṣe ohun tó burú. (Ják. 1:14, 15) A gbọ́dọ̀ yára fa èrò tí kò tọ́ náà tu kúrò lọ́kàn wa, kódà bí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ bá máa dà bí ìgbà téèyàn gé apá kan ẹ̀yà ara rẹ̀ tó fẹ́ mú un kọsẹ̀ kúrò. (Mát. 5:29, 30) Bíi ti Jésù, ohun tó máa jẹ́ àbájáde àwọn ohun tá a bá ń ṣe ló yẹ kó máa gbà wá lọ́kàn, ìyẹn ipa tí wọ́n máa ní lórí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà. A gbọ́dọ̀ máa rántí ohun tí Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ. Ọ̀nà yìí nìkan la lè gbà fi hàn pé Jèhófà ni Ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ ní ìgbésí ayé wa.

16-18. (a) Kí ló lè mú kí ọkàn-àyà wa di èyí tí a di ẹrù pa? (b) Kí ló máa mú ká lè kojú àwọn ipò tó nira?

16 Má ṣe jẹ́ kí àwọn àjálù tó dé bá ẹ mú kó o bínú sí Jèhófà. (Òwe 19:3) Bí òpin ayé búburú yìí ṣe túbọ̀ ń sún mọ́lé, èyí tó pọ̀ sí i lára àwọn èèyàn Jèhófà ni onírúurú ìjábá àti ìṣòro ń dé bá. A kò retí pé kí Ọlọ́run dáàbò bò wá lọ́nà ìyanu nínú ayé tá a wà yìí. Síbẹ̀, bó ti rí nínú ọ̀ràn ti Jóòbù, ọkàn-àyà wa lè di èyí tí a di ẹrù pa tàbí ká rẹ̀wẹ̀sì bí èèyàn wa kan bá kú tàbí tá a kó sínú ìṣòro.

17 Jóòbù kò mọ ìdí tí Jèhófà fi fàyè gba àwọn ohun kan láti ṣẹlẹ̀, ìgbà míì sì wà tí àwa náà lè má mọ ohun tó fà á tí àwọn ohun búburú fi ń ṣẹlẹ̀. Bóyá a ti gbọ́ nípa àwọn ará tó jẹ́ olùṣòtítọ́ tí wọ́n kú nígbà tí ìsẹ̀lẹ̀ wáyé, irú bíi ti orílẹ̀-èdè Haiti, tàbí nígbà tí àwọn ìjábá mìíràn wáyé. Tàbí ká mọ olùpàwàtítọ́mọ́ kan tí wọ́n hùwà ipá sí tàbí tó kú nínú ìjàǹbá burúkú kan. Tàbí kí àwa fúnra wa bá ara wa nínú ipò kan tí kò bára dé tàbí ká rò pé wọ́n rẹ́ wa jẹ. Àwọn ìṣòro tó dé bá wa lè mú ká máa ronú pé: ‘Jèhófà, irú kí lèyí? Kí ni mo ṣe tírú èyí fi tọ́ sí mi? Kí ni ẹ̀ṣẹ̀ mi?’ (Háb. 1:2, 3) Kí ló máa mú ká lè fara da irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀?

18 A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má bàa máa lérò pé ńṣe ni irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ń fi hàn pé a ti pàdánù ojú rere Jèhófà. Kókó yìí ni Jésù tẹnu mọ́ nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn àjálù méjì tó wáyé nígbà ayé rẹ̀. (Ka Lúùkù 13:1-5.) Ọ̀pọ̀ àjálù ń wáyé nítorí “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀.” (Oníw. 9:11) Àmọ́, ohun yòówù kó fà á tá a fi ní ìrora ọkàn, a lè fara dà á bí a bá wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.” Ó máa fún wa ní okun tá a nílò ká lè máa bá a nìṣó láìbọ́hùn.—2 Kọ́r. 1:3-6.

19, 20. Kí ló ran Jésù lọ́wọ́ láti fara da àwọn ipò tí ń rẹni sílẹ̀, kí ló sì lè ran àwa náà lọ́wọ́ láti ṣe bíi tirẹ̀?

19 Má ṣe jẹ́ kí ìgbéraga tàbí ríronú pé àwọn kan lè kó ìtìjú bá ẹ gbà ẹ́ lọ́kàn. Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Jésù mú kó “sọ ara rẹ̀ di òfìfo, ó sì gbé ìrísí ẹrú wọ̀.” (Fílí. 2:5-8) Ó ṣeé ṣe fún un láti fara da ọ̀pọ̀ ipò tí ń rẹni sílẹ̀ torí pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. (1 Pét. 2:23, 24) Jésù tipa bẹ́ẹ̀ fi ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà sí ipò àkọ́kọ́, èyí sì mú kí Ọlọ́run gbé e sí ipò gíga. (Fílí. 2:9) Irú ìgbésí ayé tí Jésù fẹ́ kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ náà máa gbé nìyẹn.—Mát. 23:11, 12; Lúùkù 9:26.

20 Nígbà mìíràn, àwọn ìdánwò ìgbàgbọ́ tó dojú kọ wá lè jẹ́ èyí tó ń dójú tini. Síbẹ̀, a gbọ́dọ̀ ní ìgboyà bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tó sọ pé: “Fún ìdí yìí gan-an ni èmi pẹ̀lú ṣe ń jìyà nǹkan wọ̀nyí, ṣùgbọ́n ojú kò tì mí. Nítorí tí mo mọ ẹni tí èmi ti gbà gbọ́, mo sì ní ìgbọ́kànlé pé ó lè ṣọ́ ohun tí mo tò jọ ní ìtọ́júpamọ́ sọ́dọ̀ rẹ̀ títí di ọjọ́ náà.”—2 Tím. 1:12.

21. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan wà nínú ayé, kí lo pinnu láti ṣe?

21 Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ní àkókò tá à ń gbé yìí àwọn èèyàn yóò jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn.” (2 Tím. 3:2) Abájọ nígbà náà tó fi jẹ́ pé àwọn èèyàn tó ní ìfẹ́ tèmi làkọ́kọ́ ló yí wa ká. Ká má ṣe gbà láé fún irú ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan bẹ́ẹ̀ láti kó àbààwọ́n bá wa! Kàkà bẹ́ẹ̀, yálà ìdẹwò dojú kọ wá, àjálù dé bá wa, tàbí àwọn kan ń gbìyànjú láti dójú tì wá, a gbọ́dọ̀ pinnu lẹ́nì kọ̀ọ̀kan láti fi ẹ̀rí hàn pé ní tòótọ́, Jèhófà ni Ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ ní ìgbésí ayé wa!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Àwọn ọ̀mọ̀wé kan tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀rọ̀ inú Bíbélì lérò pé gbólóhùn náà “awọ fún awọ” lè túmọ̀ sí pé Jóòbù kò ní bìkítà bí àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ẹran rẹ̀ bá pàdánù ẹran ara wọn, tàbí ìwàláàyè wọn, bí ohunkóhun kò bá ṣáà ti ṣẹlẹ̀ sí ẹran ara, tàbí ìwàláàyè tirẹ̀. Àwọn mìíràn lérò pé ńṣe ni gbólóhùn náà ń tẹnu mọ́ ọn pé ẹnì kan á múra tán láti pàdánù díẹ̀ lára ẹran ara rẹ̀ bó bá jẹ́ pé ọ̀nà tó fi lè gba ẹ̀mí rẹ̀ là nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, bí wọ́n bá fẹ́ fi ohun kan gbá ẹnì kan lórí, ó lè na apá rẹ̀ sókè láti fi gba nǹkan náà dúró, kó sì tipa bẹ́ẹ̀ pàdánù díẹ̀ lára awọ apá rẹ̀ kó lè dáàbò bo awọ orí rẹ̀. Ohun yòówù kí àkànlò èdè náà túmọ̀ sí, ó ṣe kedere pé ohun tó ń sọ ni pé inú Jóòbù máa dùn láti pàdánù gbogbo ohun tó ní kó lè gba ẹ̀mí rẹ̀ là.

Kí La Lè Rí Kọ́ Látinú . . .

• ọ̀nà tí Sátánì gbà tan Éfà jẹ?

• ohun tí Jóòbù ṣe nígbà tí àjálù dé bá a?

• ohun tí Jésù kà sí pàtàkì jù lọ?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Éfà kùnà láti fi àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà sí ipò àkọ́kọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Jésù kọ àwọn ìdẹwò Sátánì ó sì gbájú mọ́ ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Àwọn ará ń wàásù láti àgọ́ dé àgọ́ lẹ́yìn ìsẹ̀lẹ̀ tó wáyé lórílẹ̀-èdè Haiti

Tá a bá ní ìrora ọkàn, a lè wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo”