Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
June 15, 2011
Ẹ̀dà Tó Wà Fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ TÁ A MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍ Ọ̀SẸ̀:
August 1-7, 2011
Ìhìn Rere Tó Yẹ Kí Gbogbo Èèyàn Gbọ́
OJÚ ÌWÉ 7
ÀWỌN ORIN TÍ A Ó KỌ: 47, 101
August 8-14, 2011
Ọlọ́run Dámọ̀ràn Ìfẹ́ Rẹ̀ fún Wa
OJÚ ÌWÉ 11
ÀWỌN ORIN TÍ A Ó KỌ: 18, 91
August 15-21, 2011
“Ẹ Máa Ṣe Olùṣọ́ Àgùntàn Agbo Ọlọ́run Tí Ń Bẹ Lábẹ́ Àbójútó Yín”
OJÚ ÌWÉ 20
ÀWỌN ORIN TÍ A Ó KỌ: 42, 84
August 22-28, 2011
“Ẹ Ní Ẹ̀mí Ìkanisí fún Àwọn Tí Ń Ṣiṣẹ́ Kára Láàárín Yín”
OJÚ ÌWÉ 24
ÀWỌN ORIN TÍ A Ó KỌ: 123, 53
Ohun Táwọn Àpilẹ̀kọ Tá A Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Dá Lé
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 1, 2 OJÚ ÌWÉ 7 sí 15
Nínú ìwé Róòmù, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa “ìhìn rere” tó wà fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. Kí ni “ìhìn rere” náà? Àǹfààní wo lo lè rí látinú rẹ̀? Àwọn àpilẹ̀kọ méjì yìí máa jẹ́ kó o ní òye púpọ̀ sí i nípa ẹbọ Jésù àti bí Ọlọ́run ṣe tipasẹ̀ ẹbọ náà fi ìfẹ́ tó ní sí wa hàn, wọ́n á sì tún jẹ́ kí ìmọrírì rẹ pọ̀ sí i fún ẹbọ náà àti ìfẹ́ tí Ọlọ́run fi hàn.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 3, 4 OJÚ ÌWÉ 20 sí 28
Àlàyé tá a ṣe nínú àwọn àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kí àwọn alàgbà túbọ̀ mọyì àǹfààní tí wọ́n ní láti jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn. Bákan náà, a jíròrò àwọn ọ̀nà tí ìjọ lè gbà máa bọ̀wọ̀ fún àwọn alàgbà látọkànwá.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
3 Ṣó Yẹ Kí Àwọn Ọmọdé Ṣe Ìrìbọmi?
16 Ṣé Òótọ́ Ni Ábúráhámù Ní Ràkúnmí?
18 ‘Mú Àwọn Àkájọ Ìwé Wá àti ní Pàtàkì Àwọn Ìwé Awọ’
29 Báwo Lo Ṣe Lè “Mú Kí Ọ̀nà Rẹ Yọrí sí Rere”?