Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Mú Àwọn Àkájọ Ìwé Wá àti ní Pàtàkì Àwọn Ìwé Awọ’

‘Mú Àwọn Àkájọ Ìwé Wá àti ní Pàtàkì Àwọn Ìwé Awọ’

‘Mú Àwọn Àkájọ Ìwé Wá àti ní Pàtàkì Àwọn Ìwé Awọ’

ÀPỌ́SÍTÉLÌ PỌ́Ọ̀LÙ ló sọ ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí fún Tímótì tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì. Ó ní kó mú àwọn àkájọ ìwé àti àwọn ìwé awọ wá fún òun. Àwọn ìwé wo ni Pọ́ọ̀lù ń sọ? Kí nìdí tó fi ní kó mú àwọn ìwé náà wá? Ẹ̀kọ́ wo lèyí sì kọ́ wa?

Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ yìí fún Tímótì ní nǹkan bí ọdún 65 Sànmánì Kristẹni, wọ́n ti pín àwọn ìwé mọ́kàndínlógójì [39] tó wà nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù sí ìwé méjìlélógún [22] tàbí ìwé mẹ́rìnlélógún [24], tí ó ṣeé ṣe kí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n jẹ́ àkájọ ìwé. Ọ̀jọ̀gbọ́n Alan Millard sọ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé owó kékeré kọ́ ni wọ́n ń ta àwọn àkájọ ìwé náà, wọn “kò . . . wọ́n kọjá ohun táwọn tó rí já jẹ lè rà.” Ó kéré tán, àwọn kan ní ọ̀kan lára àwọn àkájọ ìwé náà. Bí àpẹẹrẹ, àkájọ ìwé kan wà lọ́wọ́ ìwẹ̀fà ará Etiópíà bí ó ti jókòó sínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀, ó sì ń “ka ìwé wòlíì Aísáyà sókè.” Ìwẹ̀fà náà ‘wà ní ipò agbára lábẹ́ Káńdésì ọbabìnrin àwọn ará Etiópíà, ó sì ń bójú tó gbogbo ìṣúra rẹ̀.’ Ó ti ní láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ débi tó fi lè ní díẹ̀ nínú àwọn àkájọ ìwé náà.—Ìṣe 8:27, 28.

Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Tímótì, ó sọ pé: “Nígbà tí o bá ń bọ̀, mú aṣọ ìlékè tí mo fi sílẹ̀ ní Tíróásì lọ́dọ̀ Kápọ́sì wá, àti àwọn àkájọ ìwé, ní pàtàkì àwọn ìwé awọ.” (2 Tím. 4:13) Àkọsílẹ̀ yìí fi hàn pé Pọ́ọ̀lù ní ìwé tó pọ̀ díẹ̀. Kí ni ì bá sì ṣe pàtàkì jù lọ níbi ìkówèésí rẹ̀ bí kò ṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Nígbà tí ọ̀mọ̀wé A. T. Robertson tó máa ń sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa “àwọn ìwé awọ” tí Pọ́ọ̀lù ń sọ nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí, ó ní: “Àwọn ìwé wọ̀nyẹn ní láti jẹ́ ẹ̀dà ìwé Májẹ̀mú Láéláé, torí pé wọ́n gbówó lórí ju àwọn tí wọ́n fi òrépèté ṣe lọ.” Láti ìgbà ọ̀dọ́ ni Pọ́ọ̀lù ti gba “ìmọ̀ ẹ̀kọ́ . . . lẹ́bàá ẹsẹ̀ Gàmálíẹ́lì,” tó máa ń kọ́ni ní Òfin Mósè. Gàmálíẹ́lì yìí sì jẹ́ ẹni tí gbogbo èèyàn kà sí. Èyí jẹ́ ká rí ìdí tí Pọ́ọ̀lù fi ní àwọn ẹ̀dà àkájọ ìwé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Ìṣe 5:34; 22:3.

Bí Àwọn Kristẹni Ṣe Lo Àwọn Àkájọ Ìwé

Síbẹ̀, àǹfààní ńlá ló jẹ́ láti ní àwọn àkájọ ìwé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nígbà yẹn. Báwo wá ni ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tí kò ní àkájọ ìwé ṣe ń rí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kà nígbà yẹn? Lẹ́tà àkọ́kọ́ tí Pọ́ọ̀lù kọ sí Tímótì jẹ́ ká rí ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn. Ó ní: “Láàárín àkókò tí mo ń bọ̀wá, máa bá a lọ ní fífi ara rẹ fún ìwé kíkà ní gbangba.” (1 Tím. 4:13) Ìwé kíkà ní gbangba jẹ́ ọ̀kan lára ohun tí wọ́n máa ń ṣe láwọn ìpàdé ìjọ nígbà yẹn, láti ìgbà Mósè sì ni àwọn èèyàn Ọlọ́run ti máa ń ṣe bẹ́ẹ̀.—Ìṣe 13:15; 15:21; 2 Kọ́r. 3:15.

Torí pé Tímótì jẹ́ alàgbà ó ní láti ‘fi ara rẹ̀’ fún kíka ìwé ní gbangba, kí àwọn tí kò ní Ìwé Mímọ́ lè gbọ́ ọ. Ó dájú pé, nígbà tí wọ́n bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní gbangba, gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ máa ń tẹ́tí sílẹ̀ kí wọ́n lè gbọ́ gbogbo ohun tí wọ́n bá kà sí wọn létí, àwọn òbí àtàwọn ọmọ sì máa ń jíròrò àwọn ohun tí wọ́n gbọ́ láwọn ìpàdé bí wọ́n bá délé.

Ọ̀pọ̀ èèyàn mọ àkájọ ìwé Aísáyà tí wọ́n rí níbi Òkun Òkú bí ẹní mowó. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ gùn tó mítà méje ààbọ̀, ìyẹn ẹsẹ̀ bàtà mẹ́rìnlélógún [24]. Àkájọ ìwé máa ń ní igi gbọọrọ méjì tí wọ́n fi ń ká a, ó sì ní ohun kan tí wọ́n máa ń tì í bọ̀ bí wọ́n bá ká a tán, torí náà ó máa ń wúwo. Ó lè má ṣeé ṣe fún èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn Kristẹni láti kó àkájọ ìwé tó pọ̀ lọ sóde ẹ̀rí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù ní àkájọ ìwé mélòó kan tó máa ń lò, ó ṣeé ṣe kó má lè máa kó gbogbo rẹ̀ káàkiri tó bá ń rìnrìn àjò. Ó ṣe kedere nígbà náà pé ó fi àwọn kan sílẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rẹ́ rẹ̀ Kápọ́sì ní Tíróásì.

Kí La Lè Rí Kọ́ Látinú Àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù?

Pọ́ọ̀lù ti wà látìmọ́lé fún ìgbà kejì ní ìlú Róòmù. Àmọ́, kó tó béèrè fún àwọn àkájọ ìwé yẹn, ó sọ pé: “Mo ti ja ìjà àtàtà náà, mo ti sáré ní ipa ọ̀nà eré ìje náà dé ìparí . . . Láti àkókò yìí lọ, a ti fi adé òdodo pa mọ́ dè mí.” (2 Tím. 4:7, 8) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ní nǹkan bí ọdún 65 Sànmánì Kristẹni, tí Nérò ń ṣe inúnibíni sí àwọn Kristẹni ni Pọ́ọ̀lù kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. Inúnibíni náà gbóná janjan ní àkókò tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí. Kódà, ara ti ń fu Pọ́ọ̀lù pé wọ́n máa tó pa òun. (2 Tím. 1:16; 4:6) Abájọ tó fi wù ú pé kí àwọn àkájọ ìwé òun wà lọ́wọ́ òun. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dá a lójú pé òun ti ja ìjà àtàtà náà títí dé òpin, ó ṣì ń fẹ́ láti máa fún ara rẹ̀ lókun nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

Ó ṣeé ṣe kí Tímótì ṣì wà ní Éfésù nígbà tó gba lẹ́tà Pọ́ọ̀lù. (1 Tím. 1:3) Ìrìn nǹkan bí ẹgbẹ̀jọ [1,600] kìlómítà ni ìlú Éfésù sí ìlú Róòmù béèyàn bá gba Tíróásì. Nínú lẹ́tà yẹn kan náà, Pọ́ọ̀lù rọ Tímótì pé kó “sa gbogbo ipá [rẹ̀] láti dé ṣáájú ìgbà òtútù.” (2 Tím. 4:21) Bíbélì kò sọ bóyá Tímótì rí ọkọ̀ ojú omi gbé e dé ìlú Róòmù ní àkókò tí Pọ́ọ̀lù fẹ́ kó débẹ̀.

Kí la lè rí kọ́ látinú bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ pé kí wọ́n bá òun kó “àwọn àkájọ ìwé, ní pàtàkì àwọn ìwé awọ” wá? Ó wù ú láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní àkókò tó nira jù lọ fún un nígbèésí ayé rẹ̀ yìí. Ǹjẹ́ o ti wá rí ohun tó fà á báyìí tí Pọ́ọ̀lù fi ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, tí ọwọ́ rẹ̀ fi ń dí fún iṣẹ́, tó sì ń fún àwọn míì ní ìṣírí?

Àǹfààní ńlá ló jẹ́ lónìí fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa láti ní odindi Bíbélì lọ́wọ́! Àwọn kan nínú wa tiẹ̀ ní ẹ̀dà tó ju ẹyọ kan lọ tí àkókò tí wọ́n tẹ̀ wọ́n sì yàtọ̀ síra. Bíi ti Pọ́ọ̀lù, a gbọ́dọ̀ ní ìháragàgà fún títúbọ̀ lóye Ìwé Mímọ́. Nínú lẹ́tà mẹ́rìnlá tí Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ, lẹ́tà rẹ̀ kejì sí Tímótì ló kọ gbẹ̀yìn. Ní apá ìparí lẹ́tà náà ló ti sọ fún Tímótì pé kó bá òun kó àwọn ìwé òun wá. Kódà, iṣẹ́ tí àkọsílẹ̀ fi hàn pé Pọ́ọ̀lù rán ẹlòmíì kẹ́yìn ni bó ṣe sọ pé kí Tímótì bá òun kó “àwọn àkájọ ìwé, ní pàtàkì àwọn ìwé awọ” wá.

Ṣé ó wu ìwọ náà pé kó o ja ìjà àtàtà ti ìgbàgbọ́ títí dé òpin bíi ti Pọ́ọ̀lù? Ṣé o fẹ́ láti máa kópa déédéé nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ṣé o sì ti múra tán láti máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù náà títí tí Olúwa fi máa sọ pé ó tó? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé wàá kúkú ṣe ohun tí Pọ́ọ̀lù gba àwa Kristẹni níyànjú pé ká ṣe? Ó sọ pé ká ‘máa fiyè sí ara wa nígbà gbogbo àti sí ẹ̀kọ́ wa’ nípa fífi ìháragàgà kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Bíbélì ti wà lárọ̀ọ́wọ́tó ọ̀pọ̀ èèyàn ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Kò sì dà bí àwọn àkájọ ìwé torí pé ó rọrùn láti gbé dání.—1 Tím. 4:16.

[Àwòrán ilẹ̀/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18, 19]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Éfésù

Tíróásì

Róòmù