Ilé Ẹjọ́ Dá Àwọn Èèyàn Jèhófà Láre!
Ilé Ẹjọ́ Dá Àwọn Èèyàn Jèhófà Láre!
NÍ ỌDÚN 1995, ìgbẹ́jọ́ bẹ̀rẹ̀ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Ó gba ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún gbáko kí ilé ẹjọ́ tó dá wọn láre. Ní gbogbo ìgbà tí ẹjọ́ náà ń lọ lọ́wọ́, àwọn tí kò bọ̀wọ̀ fún òmìnira ẹ̀sìn ń ṣe inúnibíni sí àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Àwọn alátakò yìí fẹ́ láti rí i dájú pé ìjọba fi òfin de iṣẹ́ ìwàásù àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìlú Moscow tó jẹ́ olú ìlú Rọ́ṣíà àti láwọn ìlú míì. Síbẹ̀, ó wu Jèhófà pé kó san ẹ̀san rere fún àwọn ará wa ọ̀wọ́n tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà torí pé wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin. Ó mú kí ilé ẹjọ́ dá wọn láre. Àmọ́, kí ló fà á tí ọ̀ràn wọn fi dé ilé ẹjọ́?
ÌJỌBA FÚN ÀWỌN ARÁ WA LÓMÌNIRA!
Láti ọdún 1917 wá ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà kò ti ní òmìnira ẹ̀sìn mọ́. Àmọ́, láàárín ọdún 1990 sí ọdún 1995 ni wọ́n tó fún wọn lómìnira. Ní ọdún 1991, ìjọba Soviet Union fi orúkọ wọn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn tó bófin mu lórílẹ̀-èdè náà. Lẹ́yìn tí ìjọba Soviet Union pín sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, Ìjọba Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà tó jẹ́ ọ̀kan lára orílẹ̀-èdè mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tó pín sí, fi orúkọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn tó bá òfin mu. Ìjọba Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà gbà pé ìjọba Soviet Union àná ṣe inúnibíni sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láìtọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ní ọdún 1993, Ẹ̀ka Ilé Iṣẹ́ Ìjọba Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Ìdájọ́ ní Ìlú Moscow gbà pé ẹ̀sìn wọn bófin mu. Orúkọ tí wọ́n fi pè wọ́n nínú òfin wọn ni Àwùjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tó Wà ní Ìlú Moscow. Ní ọdún yẹn kan náà, orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà gbé òfin tuntun jáde, èyí tó fàyè gba ẹnikẹ́ni láti ṣe ẹ̀sìn tó bá wù ú. Arákùnrin kan fi ìtara sọ pé, “A kò tilẹ̀ ronú pé a máa rí irú òmìnira bẹ́ẹ̀ gbà!” Ó tún sọ síwájú sí i pé, “Àádọ́ta [50] ọdún sẹ́yìn rèé tá a ti ń dúró dè é!”
Àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà lo “àsìkò tí ó rọgbọ” yẹn lọ́nà tó dára. Wọ́n yára fi kún ìgbòkègbodò wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ọ̀pọ̀ èèyàn sì gbọ́rọ̀ wọn. (2 Tím. 4:2) Ẹnì kan tó kíyè sí ohun tó ṣẹlẹ̀ sọ pé: “Àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀ràn ẹ̀sìn gan-an.” Kò sì pẹ́ púpọ̀ tí àwọn akéde, aṣáájú-ọ̀nà àti àwọn ìjọ tó wà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fi pọ̀ sí i. Láàárín ọdún 1990 sí ọdún 1995, àwọn Ẹlẹ́rìí tí kò ju nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún [300] lọ ti yára lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000]! Àmọ́, bí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe ń pọ̀ sí i ní ìlú Moscow yìí ń kó ìdágìrì bá àwọn tí kò fẹ́ káwọn èèyàn ní òmìnira ẹ̀sìn. Torí náà, ní ọdún 1995, wọ́n gbé àwọn ará wa lọ sí ilé ẹjọ́. Ó sì máa gba àkókò kí ẹjọ́ náà tó lójú.
ÌWÁDÌÍ BẸ̀RẸ̀ LÓRÍ Ẹ̀SÙN TÍ WỌ́N FI KÀN WỌ́N
Ní oṣù June ọdún 1995, ìwádìí bẹ̀rẹ̀ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn ará wa. Àwùjọ àwọn èèyàn kan láti ìlú Moscow, tí wọ́n lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Ìlú Rọ́ṣíà, ni wọ́n gbé ẹjọ́ náà lọ sí kóòtù. Wọ́n fi ẹ̀sùn kan àwọn ará wa pé wọ́n ń ṣe ohun tí kò bá òfin mu. Àwùjọ náà sọ pé àwọn ń ṣojú fún àwọn ìdílé tó ń bínú nítorí pé ọkọ, aya tàbí àwọn ọmọ wọn ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní oṣù June, ọdún 1996, àwọn aṣojú ìjọba bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn ará wa, àmọ́ wọn kò rí ẹ̀rí kankan. Síbẹ̀, àwùjọ yìí gbé ẹjọ́ náà lọ sí kóòtù lẹ́ẹ̀kejì, wọ́n fi ẹ̀sùn kan àwọn ará wa pé wọ́n ń ṣe ohun tí kò bá òfin mu. Àwọn aṣojú ìjọba tún ṣe ìwádìí mìíràn lórí ẹjọ́ náà, ṣùgbọ́n wọn kò rí ẹ̀rí kankan. Síbẹ̀, àwọn alátakò yìí gbé ẹ̀sùn kan náà yẹn pa dà lọ sí ilé ẹjọ́ ní ìgbà kẹta. Lẹ́ẹ̀kan sí i, àwọn aṣojú ìjọba tún ṣe ìwádìí lórí ẹ̀sùn náà, àmọ́ ibì kan náà ni ìwádìí náà já sí. Kò sí ẹ̀rí tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìlú Moscow ṣe ohunkóhun tí kò bá òfin mu. Ṣùgbọ́n àwọn alátakò yìí tún gbé ẹjọ́ náà lọ sí kóòtù ní ìgbà kẹrin. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lọ́tẹ̀ yìí? Aṣojú ìjọba tó ṣèwádìí ọ̀ràn náà kò rí ẹ̀rí kankan. Ó yani lẹ́nu pé àwùjọ yìí kan náà sọ pé kí wọ́n tún ìwádìí
mìíràn ṣe. Níkẹyìn, àwọn tó tún ìwádìí náà ṣe fòpin sí ẹjọ́ náà ní April 13, ọdún 1998.Ọ̀kan lára àwọn agbẹjọ́rò tó lọ́wọ́ sí ẹjọ́ náà sọ pé: “Àmọ́ ohun àjèjì kan ṣẹlẹ̀.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aṣojú ìjọba tó ṣe ìwádìí nígbà karùn-ún lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wá gbà pé kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé àwọn ará wa jẹ̀bi, ó ṣì gba àwọn olùpẹ̀jọ́ níyànjú pé kí wọ́n jẹ́ kí àwọn aráàlú fi ẹ̀sùn kan àwọn ará wa. Aṣojú ìjọba náà sọ pé Àwùjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tó Wà ní Ìlú Moscow ti rú òfin ìlú àti òfin àwọn orílẹ̀-èdè míì lágbàáyé. Agbẹjọ́rò Ẹ̀ka Iléeṣẹ́ Ìjọba Tó Ń Rí Sí Ọ̀ràn Àbójútó ní Àríwá Ìlú Moscow fara mọ́ èrò rẹ̀ ó sì fẹ̀sùn kan àwọn ará wa lórúkọ àwọn aráàlú. * Ní September 29, ọdún 1998, ìgbẹ́jọ́ bẹ̀rẹ̀ ní Ilé Ẹjọ́ Àgbègbè Golovinsky ní Ìlú Moscow. Bí abala kejì nínú ìgbẹ́jọ́ náà ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn.
WỌ́N LO BÍBÉLÌ NÍLÉ ẸJỌ́
Ní ilé ẹjọ́ kan tó kún fọ́fọ́ ní àríwá ìlú Moscow ni ìgbẹ́jọ́ náà ti wáyé. Tatyana Kondratyeva tó jẹ́ agbẹjọ́rò ìjọba ló kọ́kọ́ fẹ̀sùn kan àwọn ará wa. Ó lo òfin kan tí ìjọba fọwọ́ sí lọ́dún 1997, èyí tó fi hàn pé ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì, ẹ̀sìn Mùsùlùmí, ẹ̀sìn àwọn Júù àti ẹ̀sìn Búdà ni òfin ilẹ̀ wọn fọwọ́ sí. * Òfin yìí kan náà ni kò jẹ́ kí wọ́n gbà láti fi orúkọ àwọn ẹ̀sìn míì sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Òfin yìí tún fàyè gba ilé ẹjọ́ láti fòfin de ẹ̀sìn tó bá ń mú kéèyàn kórìíra àwọn ẹlòmíì. Látàrí ohun tí òfin yẹn sọ, agbẹjọ́rò ìjọba fẹ̀sùn èké kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé wọ́n máa ń mú kéèyàn kórìíra àwọn ẹlòmíì wọ́n sì máa ń ba ìdílé jẹ́ torí náà ó yẹ kí ìjọba fòfin de iṣẹ́ wọn.
Agbẹjọ́rò tó ń ṣojú fún àwọn ará wa bi agbẹjọ́rò ìjọba pé: “Àwọn wo lára àwọn tó wà ní Ìjọ Moscow ni wọ́n rú òfin ìjọba?” Kò lè dárúkọ ẹnikẹ́ni. Àmọ́, ó sọ pé ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń mú kéèyàn kórìíra àwọn ẹlẹ́sìn míì. Kó lè fi ẹ̀rí ti ara rẹ̀ lẹ́yìn, ó ṣe àyọkà látinú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! àtàwọn ìtẹ̀jáde wa míì (wo òkè). Nígbà tí wọ́n ní kó sọ ọ̀nà tí àwọn ìtẹ̀jáde náà ń gbà mú kéèyàn kórìíra àwọn ẹlẹ́sìn míì, ó sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń sọ pé àwọn làwọn ń ṣe ẹ̀sìn tòótọ́.”
Arákùnrin kan tó jẹ́ agbẹjọ́rò fi Bíbélì kan lé adájọ́ lọ́wọ́, ó sì fún agbẹjọ́rò ìjọba náà ní Bíbélì kan. Lẹ́yìn náà, ó ka Éfésù 4:5 tó sọ pé: “Olúwa kan, ìgbàgbọ́ kan, ìbatisí kan.” Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí adájọ́, agbẹjọ́rò ìjọba àti arákùnrin náà fi bẹ̀rẹ̀ sí í lo Bíbélì tó wà lọ́wọ́ wọn láti jíròrò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi Jòhánù 17:18 àti Jákọ́bù 1:27. Adájọ́ wá béèrè pé: “Ǹjẹ́ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí máa ń mú kéèyàn kórìíra àwọn ẹlẹ́sìn míì?” Agbẹjọ́rò ìjọba náà dá adájọ́ lóhùn pé òun kò lè dáhùn ìbéèrè náà torí pé òun kì í ṣe onímọ̀ nípa Bíbélì. Agbẹjọ́rò tó ṣojú fún àwọn ará wa fi àwọn ìwé tí Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Ilẹ̀ Rọ́ṣíà fi sọ̀rọ̀ tó ta ko àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà han ilé ẹjọ́, ó wá béèrè pé: “Ṣé ohun tí wọ́n kọ sínú àwọn ìwé yìí bófin mu?” Agbẹjọ́rò ìjọba náà tún fèsì pé: “Mi ò lè dáhùn ìbéèrè náà torí pé mi ò kí ń ṣe onímọ̀ nípa ọ̀ràn ẹ̀sìn.”
Ẹ̀SÙN TÍ KÒ LẸ́SẸ̀ NÍLẸ̀
Lára ẹ̀sùn tí agbẹjọ́rò ìjọba fi kan àwọn Ẹlẹ́rìí láti fi hàn pé wọ́n ń ba ìdílé jẹ́ ni pé wọn kì í ṣe ọdún, irú bíi Kérésìmesì. Àmọ́, nígbà tó yá òun fúnra rẹ̀ sọ pé òfin ilẹ̀ Rọ́ṣíà kò fi dandan lé e pé káwọn aráàlú máa ṣe ọdún Kérésìmesì. Àwọn
ará Rọ́ṣíà, tó fi mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, ní òmìnira láti yan ohun tó wù wọ́n. Agbẹjọ́rò ìjọba náà tún sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ‘kì í fún àwọn ọmọ wọn ní ìsinmi, wọn kì í sì í jẹ́ kí wọ́n gbádùn ara wọn.’ Síbẹ̀, nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá ó ti bá ọ̀dọ́ èyíkéyìí táwọn òbí rẹ̀ jẹ́ Ẹlẹ́rìí sọ̀rọ̀ rí, ó sọ pé òun kò tíì ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tí agbẹjọ́rò kan sì tún béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá ó ti lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí, ó dáhùn pé: “Kò sídìí fún mi láti lọ síbẹ̀.”Agbẹjọ́rò ìjọba náà lo ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó jẹ́ onímọ̀ nípa ìtọ́jú ọpọlọ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí. Ọ̀jọ̀gbọ́n náà sọ pé ìwé wa máa ń da àwọn tó bá kà á lórí rú. Àmọ́, nígbà tí agbẹjọ́rò kan tó ń ṣojú fún àwọn Ẹlẹ́rìí sọ pé ohun tí ọ̀jọ̀gbọ́n náà kọ sínú ìwé tó gbé wá síwájú ilé ẹjọ́ kò yàtọ̀ sí ohun tí àwọn àlùfáà Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Ìlú Moscow kọ sínú ìwé tiwọn, kò jiyàn pé ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé: “Ọwọ́ wọn ni mo ti gba èyí tí mo dà kọ.” Lẹ́yìn tí agbẹjọ́rò ti bi ọ̀jọ̀gbọ́n náà ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè, ó jẹ́wọ́ pé òun kò tíì tọ́jú Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan rí. Ọ̀jọ̀gbọ́n mìíràn tó jẹ́ onímọ̀ nípa ìtọ́jú ọpọlọ jẹ́rìí níwájú ilé ẹjọ́ náà pé òun ti ṣèwádìí nípa àwọn Ẹlẹ́rìí tó ju ọgọ́rùn-ún [100] lọ ní ìlú Moscow. Ó rí i nínú ìwádìí rẹ̀ pé kò sí ohun tó ṣe ọpọlọ àwọn Ẹlẹ́rìí náà, àti pé lẹ́yìn tí wọ́n di Ẹlẹ́rìí Jèhófà wọ́n túbọ̀ ń fọgbọ́n bá àwọn ẹlẹ́sìn míì lò.
ILÉ ẸJỌ́ DÁ ÀWỌN ARÁ WA LÁRE, ṢÙGBỌ́N ẸJỌ́ Ò TÍÌ TÁN
Ní March 12, ọdún 1999, adájọ́ yan àwọn ọ̀mọ̀wé márùn-ún pé kí wọ́n ṣèwádìí lórí ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì dá ìgbẹ́jọ́ náà dúró dìgbà tí ìwádìí náà máa fi parí. Kí àwọn yẹn tó bẹ̀rẹ̀ ìwádìí wọn, Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ti ní kí àwùjọ àwọn ọ̀mọ̀wé kan lọ ṣèwádìí lórí àwọn ìwé wa nítorí ìdí mìíràn tó yàtọ̀. Àwùjọ tí Ìgbìmọ̀ Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ yanṣẹ́ fún yìí mú àbájáde ìwádìí wọn wá ní April 15, ọdún 1999. Wọ́n kò rí ohunkóhun tó lè ṣèpalára fúnni nínú ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Torí náà, ní April 29, ọdún 1999, Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ tún fi orúkọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn tó bá òfin mu. Síbẹ̀, ilé ẹjọ́ ìlú Moscow fi dandan lé e pé kí ìgbìmọ̀ tuntun náà ṣèwádìí lórí àwọn ìwé wa. Ó ṣàjèjì pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé
Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ ti Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà gbà pé ẹ̀sìn tó bófin mu tí kì í sì í tàpá sí òfin ìjọba ni ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ ti Ìlú Moscow ṣì fi wọ́n sábẹ́ àyẹ̀wò torí ẹ̀sùn táwọn kan fi kàn wọ́n pé wọ́n ń rú òfin!Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọdún méjì, kí ìgbẹ́jọ́ náà tó tún pa dà bẹ̀rẹ̀. Nígbà tó di February 23, ọdún 2001, àkókò tó fún Adájọ́ Yelena Prokhorycheva láti sọ ìdájọ́ rẹ̀ fún ilé ẹjọ́. Lẹ́yìn tó ti ṣàyẹ̀wò àbájáde ìwádìí ìgbìmọ̀ tó yanṣẹ́ fún, ó sọ ìpinnu rẹ̀ báyìí pé: “Kò sí ìdí kankan tó fi yẹ ká dá ìgbòkègbodò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìlú Moscow dúró tàbí ká fi òfin dè é.” Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, wọ́n fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lábẹ́ òfin pé àwọn ará wa kò jẹ̀bi èyíkéyìí lára gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n! Àmọ́ ṣá o, agbẹjọ́rò ìjọba náà kò fara mọ́ ìdájọ́ yìí, ó sì pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Ìlú Moscow. Ní oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà, ní May 30, ọdún 2001, ilé ẹjọ́ yẹn fagi lé ìpinnu Adájọ́ Prokhorycheva. Ó wá pàṣẹ pé kí wọ́n tún ẹjọ́ náà gbọ́ níwájú adájọ́ míì, kí agbẹjọ́rò ìjọba sì máa bá ẹjọ́ rẹ̀ lọ. Abala kẹta ìgbẹ́jọ́ náà ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀ wàyí.
ILÉ ẸJỌ́ DÁ WỌN LÁRE, ṢÙGBỌ́N ẸJỌ́ Ò TÍÌ TÁN
Ní October 30, ọdún 2001, Adájọ́ Vera Dubinskaya bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ náà lẹ́ẹ̀kan sí i. * Kondratyeva tó jẹ́ agbẹjọ́rò ìjọba tún ṣàlàyé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó sọ pé wọ́n ń jẹ́ kéèyàn kórìíra àwọn ẹlòmíì. Lọ́tẹ̀ yìí, ó wá fi kún un pé torí àti dáàbò bo ẹ̀tọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìlú Moscow ló ṣe yẹ kí ìjọba fi òfin dè wọ́n. Láti fi hàn pé irọ́ tó jìnnà sí òótọ́ ni agbẹjọ́rò ìjọba pa, gbogbo ẹgbàárùn-ún [10,000] Ẹlẹ́rìí tó wà ní ìlú Moscow yára kọ̀wé, wọ́n sì buwọ́ lù ú láti fi tó ilé ẹjọ́ létí pé àwọn kò fara mọ́ ẹ̀tọ́ tí agbẹjọ́rò ìjọba sọ pé òun fẹ́ báwọn dáàbò bò.
Agbẹjọ́rò ìjọba náà sọ pé kò sí ìdí fún òun láti mú ẹ̀rí wá kóun lè fi hàn pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń hùwà àìtọ́. Ó ní òun kò bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣẹjọ́ torí àwọn ìgbòkègbodò wọn bí kò ṣe nítorí ìwé wọn àti ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Ó sọ fún ilé ẹjọ́ náà pé ẹnì kan wà tó jẹ́ agbẹnusọ fún Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Ìlú Rọ́ṣíà tí òun máa fà kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí torí pé ó mọ bọ́rọ̀ náà ṣe jẹ́. Ọ̀rọ̀ tó sọ yìí, fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn aṣáájú ìsìn ló ń súnná sí i pé kí wọ́n fi òfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní May 22, ọdún 2003, adájọ́ náà pàṣẹ pé kí àwùjọ àwọn onímọ̀ nípa ọ̀ràn ẹ̀sìn tún lọ ṣèwádìí lórí ìtẹ̀jáde àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Ilé ẹjọ́ tún pa dà jókòó lórí ọ̀ràn náà ní February 17, 2004, kí wọ́n lè ṣàyẹ̀wò àbájáde ìwádìí tí àwọn onímọ̀ nípa ọ̀ràn ẹ̀sìn náà ṣe. Àwọn onímọ̀ nípa ọ̀ràn ẹ̀sìn yìí rí i pé àwọn ìtẹ̀jáde wa rọ àwọn òǹkàwé pé kí wọ́n “má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun ba ìṣètò ìdílé àti ti ìgbéyàwó jẹ́” àti pé “kò sí ohun tó fi hàn” pé àwọn ìwé wa ń mú káwọn èèyàn kórìíra ara wọn. Àwọn ọ̀mọ̀wé yòókù náà gbà pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn. Wọ́n bi ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó mọ̀ nípa ìtàn ẹ̀sìn pé: “Kí nìdí tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń wàásù?” Ó dá ilé ẹjọ́ náà lóhùn pé: “Dandan ni iṣẹ́ ìwàásù jẹ́ fún àwọn Kristẹni. Ohun tí ìwé Ìhìn Rere sọ nìyẹn, ìyẹn náà sì ni ohun tí Kristi pa láṣẹ pé kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ṣe, ‘kí wọ́n lọ wàásù ní gbogbo orílẹ̀-èdè.’” Pẹ̀lú gbogbo ẹ̀rí tó wà nílẹ̀ yìí, ní March 26, ọdún 2004, adájọ́ náà ṣì fi òfin de iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìlú Moscow. Ní June 16, ọdún 2004, Ilé Ẹjọ́ Ìlú Moscow fara mọ́ ìpinnu náà. * Nígbà tí Ẹlẹ́rìí kan tó ti ń sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún ń sọ èrò rẹ̀ lórí ìdájọ́ náà, ó ní: “Nígbà ìjọba Soviet Union, kó o tó lè jẹ́ ojúlówó ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà, o gbọ́dọ̀ gbà pé kò sí Ọlọ́run. Lóde òní, àfi kó o dara pọ̀ mọ́ ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì.”
Kí ni àwọn ará wa ṣe nígbà tí wọ́n fòfin de iṣẹ́ wọn? Àwọn náà ṣe bíi ti Nehemáyà ìgbàanì. Nígbà ayé Nehemáyà, àwọn tó jẹ́ ọ̀tá àwọn èèyàn Ọlọ́run kò fẹ́ kó tún ògiri Jerúsálẹ́mù kọ́, àmọ́ Nehemáyà àtàwọn èèyàn rẹ̀ kò jẹ́ kí àtakò èyíkéyìí mú kí wọ́n dáwọ́ iṣẹ́ dúró. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n “ń mọ” ògiri náà “nìṣó” wọ́n sì “ń bá a lọ láti ní ọkàn-àyà fún iṣẹ́ ṣíṣe.” (Neh. 4:1-6) Bákan náà, àwọn ará wa ní ìlú Moscow kò jẹ́ kí àwọn alátakò yẹn dí àwọn lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ tó yẹ ní ṣíṣe lákòókò wa yìí, ìyẹn iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere. (1 Pét. 4:12, 16) Ó dá wọn lójú pé Jèhófà máa dáàbò bò wọ́n, wọ́n sì ṣe tán láti gbé ìgbésẹ̀ tó máa bẹ̀rẹ̀ abala kẹrin ìgbẹ́jọ́ yìí.
WỌ́N TÚBỌ̀ GBÉJÀ KÒ WÁ
Ní August 25, ọdún 2004, àwọn ará wa kọ̀wé sí Vladimir Putin, tó jẹ́ ààrẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà nígbà yẹn, lórí ọ̀ràn náà. Nínú ìwé tí wọ́n kọ, wọ́n sọ ojú tí wọ́n fi wo ìfòfindè yìí. Apá mẹ́rìndínlọ́gọ́rin [76] ni ìwé náà pín sí, àwọn tó buwọ́ lù ú sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ [315,000]. Bí èyí ti ń lọ lọ́wọ́, àwọn àlùfáà Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Ilẹ̀ Rọ́ṣíà, fi irú ẹni tí wọ́n jẹ́ hàn ní ti gidi. Agbẹnusọ kan fún àwọn aṣáájú Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Ìlú Moscow sọ pé: “Inú wa kò dùn sí ìgbòkègbodò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rárá.” Aṣáájú ẹ̀sìn Mùsùlùmí kan tiẹ̀ sọ pé bí wọ́n ṣe fòfin de iṣẹ́ wa jẹ́ “ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì nínú ìtàn orílẹ̀-èdè náà, ó sì jẹ́ ohun tó dára.”
Torí náà, kò yani lẹ́nu pé àwọn ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà tí wọ́n ti purọ́ fún bẹ̀rẹ̀ sí í gbéjà ko àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn alátakò gbá àwọn Ẹlẹ́rìí kan tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ní ìlú Moscow lẹ́ṣẹ̀ẹ́, wọ́n sì ta wọ́n nípàá. Ọkùnrin kan bínú sí arábìnrin kan tó ń wàásù, ó lé e jáde kúrò nínú ilé rẹ̀, ó sì gbá a nípàá látẹ̀yìn débi pé arábìnrin náà ṣubú lulẹ̀ ó sì fi orí gbálẹ̀. Wọ́n ní láti gbé arábìnrin náà lọ sí ilé ìwòsàn; síbẹ̀, àwọn ọlọ́pàá kò mú ọkùnrin tó gbá a nípàá náà. Àwọn ọlọ́pàá mú àwọn Ẹlẹ́rìí kan, wọ́n ní kí wọ́n tẹ̀ka, wọ́n yà wọ́n ní fọ́tò, wọ́n sì fi wọ́n sí àtìmọ́lé títí di ọjọ́ kejì. Àwọn tó ni gbọ̀ngàn táwọn ará wa máa ń lò fún ìpàdé ní ìlú Moscow sọ pé àwọn máa lé àwọn òṣìṣẹ́ àwọn kúrò lẹ́nu iṣẹ́ bí wọ́n bá tún gbé gbọ̀ngàn náà fáwọn Ẹlẹ́rìí. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí ọ̀pọ̀ ìjọ kò fi rí gbọ̀ngàn lò fún ìpàdé mọ́. Ogójì [40] ìjọ ní láti máa lo ilé kan ṣoṣo tó ní Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́rin. Ọ̀kan lára àwọn ìjọ tó ń lo ilé yìí ní láti máa ṣe Ìpàdé fún Gbogbo Ènìyàn ní agogo méje ààbọ̀ òwúrọ̀. Alábòójútó arìnrìn-àjò kan sọ pé: “Kí àwọn ará bàa lè débẹ̀ lásìkò, wọ́n ti ní láti jí ní agogo márùn-ún ìdájí, àmọ́ tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀ fún ohun tó ju ọdún kan lọ.”
“Ẹ̀RÍ” LÓ JẸ́
Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ni ìlú Moscow fẹ́ láti fi hàn pé bí wọ́n ṣe fi òfin de iṣẹ́ ìwàásù wọn níbẹ̀ kò bá òfin mu. Torí náà, ní oṣù December, ọdún 2004 àwọn agbẹjọ́rò wa gbé ẹjọ́ náà lọ síwájú Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù. (Wo àpótí náà, “Ìdí Tí Ilẹ̀ Faransé Fi Ṣe Àtúnyẹ̀wò Ẹjọ́ Tí Ilẹ̀ Rọ́ṣíà Dá,” ní ojú ìwé 6.) Ní ọdún mẹ́fà lẹ́yìn náà, ní June 10, 2010, Ilé Ẹjọ́ náà fohùn ṣọ̀kan lórí àbájáde ìwádìí tí wọ́n ṣe, ìdájọ́ wọn sì ni pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò jẹ̀bi èyíkéyìí nínú ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n! * Ilé Ẹjọ́ náà wá rí i pé gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn ará wa kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Ilé Ẹjọ́ náà tún sọ pé ní ìbámu pẹ̀lú òfin, ó pọn dandan pé kí ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà “fi òpin sí títẹ òfin lójú gẹ́gẹ́ bó ṣe hàn nínú ìwádìí tí Ilé Ẹjọ́ náà ṣe kí wọ́n sì wá ohun tí wọ́n máa ṣe sí wàhálà tí ìyẹn ti dá sílẹ̀.”—Wo àpótí náà, “Ìdájọ́,” ní ojú ìwé 8.
Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àti orílẹ̀-èdè mẹ́rìndínláàádọ́ta [46] mìíràn tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Ìgbìmọ̀ Ilẹ̀ Yúróòpù gbọ́dọ̀ fara mọ́ àlàyé tó ṣe kedere tí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù ṣe nípa bí Àdéhùn Àjọṣe Ilẹ̀ Yúróòpù Lórí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ṣe dáàbò bo iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bákan náà, nítorí bí Ilé Ẹjọ́ náà ṣe ṣèwádìí tí wọ́n sì ṣe àyẹ̀wò tó gbòòrò nípa ẹ̀rí tó wà nílẹ̀ àti ohun tí òfin sọ kí wọ́n tó dórí ìpinnu, ọ̀pọ̀ àwọn amòfin, adájọ́, aṣòfin àtàwọn onímọ̀ nípa ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn kárí ayé máa fẹ́ láti mọ̀ nípa ìpinnu náà. Kí nìdí? Ìdí ni pé kí Ilé Ẹjọ́ náà tó ṣèdájọ́, wọ́n kọ́kọ́ ṣàlàyé nípa ìgbà mẹ́jọ táwọn ti kọ́kọ́ dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láre, wọ́n sì tún ṣàlàyé nípa ìgbà mẹ́sàn-án mìíràn tí àwọn Ẹlẹ́rìí ti jàre ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n láwọn ilé ẹjọ́ gíga jù lọ lórílẹ̀-èdè Ajẹntínà, Kánádà, Japan, Rọ́ṣíà, South Africa, Sípéènì, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Àwọn àlàyé tí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ṣe yìí àti bó ṣe túdìí àṣírí ẹ̀tàn tó wà nídìí ẹ̀sùn tí agbẹjọ́rò ìjọba fi kan àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí ní ìlú Moscow jẹ́ ohun pàtàkì kan tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé lè máa lò láti gbèjà ìgbàgbọ́ wọn àtàwọn ìgbòkègbodò wọn.
Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Wọn yóò fà yín lọ síwájú àwọn gómìnà àti àwọn ọba nítorí mi, láti ṣe ẹ̀rí fún wọn àti fún àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mát. 10:18) Ọ̀ràn ẹjọ́ tó wáyé láàárín ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] tó ti kọjá yìí ti fún àwọn ará ní àǹfààní láti sọ orúkọ Jèhófà di mímọ̀ lọ́nà tí a kò tíì rí irú rẹ̀ rí nílùú Moscow àti láwọn ìlú míì. Bí àwọn èèyàn ṣe láǹfààní láti mọ púpọ̀ sí i nípa àwa Ẹlẹ́rìí nígbà tí ìgbẹ́jọ́ náà ń lọ lọ́wọ́, àwọn ìwádìí tí wọ́n ṣe nípa wa, bí wọ́n ṣe ń gbé wa láti ilé ẹjọ́ kan lọ sí òmíràn àti ìpinnu tí àwọn adájọ́ ṣe ní ilé ẹjọ́ tó jẹ́ ti àpapọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè jẹ́ “ẹ̀rí” ó sì ti pa kún “ìlọsíwájú ìhìn rere.” (Fílí. 1:12) Ní báyìí, bí àwọn Ẹlẹ́rìí bá ń wàásù ní ìlú Moscow, ọ̀pọ̀ àwọn onílé máa ń sọ pé, “Ṣebí wọ́n ti fòfin dè yín?” Ìbéèrè yẹn sábà máa ń fún àwọn ará wa láǹfààní láti sọ púpọ̀ sí i fún onílé nípa ohun tá a gbà gbọ́. Ó ṣe kedere pé, kò sí àtakò kankan tó lè dá ìgbòkègbodò ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tá à ń ṣe dúró. Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà máa rọ̀jò ìbùkún rẹ̀ sórí àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ọ̀wọ́n tí wọ́n wà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà kó sì máa gbé wọn ró.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Ní April 20, ọdún 1998 ni wọ́n gbé ẹjọ́ náà lọ sí kóòtù. Ní ọ̀sẹ̀ kejì lẹ́yìn náà, ìyẹn ní May 5, orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà buwọ́ lu Àdéhùn Àjọṣe Ti Ilẹ̀ Yúróòpù Lórí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn.
^ Ìwé ìròyìn kan sọ pé: “Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Ilẹ̀ Rọ́ṣíà ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti rí sí i pé ìjọba gba òfin yìí wọlé. Ṣọ́ọ̀ṣì náà kò fẹ́ kí ẹ̀sìn míì gbapò mọ́ òun lọ́wọ́, torí náà ó fẹ́ kí ìjọba fi òfin de iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”—Àjọ akóròyìnjọ Associated Press, ti June 25, ọdún 1999.
^ Ó gbàfiyèsí pé ọjọ́ yìí kan náà ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, ni Ìjọba Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà gbà pé torí ọ̀ràn ẹ̀sìn ni ìjọba Soviet Union àná fi ṣenúnibíni sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láìtọ́.
^ Èyí túmọ̀ sí pé wọ́n fagi lé àjọ tí àwọn ìjọ tó wà ní ìlú Moscow ń lò lábẹ́ òfin. Èrò àwọn alátakò náà ni pé àwọn ará wa kò ní lè ṣe iṣẹ́ ìwàásù mọ́ torí pé ẹ̀sìn wọn kò bófin mu mọ́ ní orílẹ̀-èdè náà.
^ Lẹ́yìn tí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù ti sọ ìpinnu wọn lórí ẹjọ́ náà, ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà ṣì fẹ́ kí Ìgbìmọ̀ Tó Ga Jù Lọ ní Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù bá àwọn tún ẹjọ́ náà gbọ́. Àmọ́, ní November 22, 2010, ìgbìmọ̀ tó ní àwọn adájọ́ márùn-ún nínú yìí, kò fara mọ́ ìwé tí wọ́n kọ láti béèrè pé kí wọ́n bá àwọn tún ẹjọ́ náà gbọ́. Torí náà, kò sí ohun tó lè yí ìdájọ́ tó ti kọ́kọ́ wáyé ní June 10, 2010 pa dà, ìyẹn sì ni ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà gbọ́dọ̀ fara mọ́.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ìdí Tí Ilẹ̀ Faransé Fi Ṣe Àtúnyẹ̀wò Ẹjọ́ Tí Ilẹ̀ Rọ́ṣíà Dá
Ní February 28, ọdún 1996, orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fọwọ́ sí Àdéhùn Àjọṣe Ilẹ̀ Yúróòpù Lórí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn. (Ní May 5, 1998, orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà sọ Àdéhùn Àjọṣe náà di òfin.) Bí ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà ṣe fọwọ́ sí àdéhùn yẹn, ńṣe ló gbà pé àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè òun ní
‘ẹ̀tọ́ láti ṣe ẹ̀sìn tó wù wọ́n àti ẹ̀tọ́ láti ṣe ẹ̀sìn náà ní ilé, ní gbangba àti láti yí ẹ̀sìn wọn pa dà bí wọ́n bá fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.’—Abala Kẹsàn-án.
‘ẹ̀tọ́ láti sọ ohun tí wọ́n rò àti láti kọ ọ́ sílẹ̀ lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu kí wọ́n sì fún àwọn ẹlòmíì ní ìsọfúnni.’—Abala Kẹwàá.
‘ẹ̀tọ́ láti ṣe àwọn ìpàdé tí kò ní ba àlàáfíà ìlú jẹ́.’—Abala Kọkànlá.
Bí orílẹ̀-èdè èyíkéyìí bá tẹ àdéhùn àjọṣe yìí lójú nípa fífìyà jẹ ẹnikẹ́ni tàbí àjọ èyíkéyìí, ẹni yìí tàbí àjọ náà lè ké gbàjarè lọ sáwọn ilé ẹjọ́ tó wà lórílẹ̀-èdè rẹ̀. Àmọ́, bí kò bá rí ẹni kọ̀yà fún un, ó lè gbé ẹjọ́ rẹ̀ wá sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù, èyí tó wà ní ìlú Strasbourg, ní orílẹ̀-èdè Faransé (tó wà nínú àwòrán òkè yìí). Adájọ́ mẹ́tàdínláàádọ́ta [47] ló wà níbẹ̀. Ìyẹn náà sì ni iye àwọn orílẹ̀-èdè tó fọwọ́ sí Àdéhùn Àjọṣe Ilẹ̀ Yúróòpù Lórí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn. Ohun tí Ilé Ẹjọ́ náà bá sọ ni abẹ gé. Àwọn orílẹ̀-èdè tó fọwọ́ sí àdéhùn àjọṣe náà gbọ́dọ̀ fara mọ́ ìpinnu ilé ẹjọ́ náà.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]
Ìdájọ́
Díẹ̀ rèé lára ìdájọ́ Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù.
Ọ̀kan lára ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni pé wọ́n máa ń ba ìdílé jẹ́. Ọ̀tọ̀ ni ojú tí ilé ẹjọ́ fi wo ọ̀ràn náà. Ó sọ pé:
“Ohun tó ń fa ìforígbárí ni pé ìbátan àwọn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí kọ̀ láti fàyè gba àwọn èèyàn wọn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí láti lo òmìnira tí wọ́n ní láti ṣe ẹ̀sìn tó wù wọ́n, wọn kò sì bọ̀wọ̀ fún òmìnira náà.”—Ìpínrọ̀ 111.
Ilé ẹjọ́ tún rí i pé kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń “darí ìrònú àwọn èèyàn.” Torí náà, ó sọ pé:
“Ó ya ilé ẹjọ́ yìí lẹ́nu pé ilé ẹjọ́ [ilẹ̀ Rọ́ṣíà] kò rí orúkọ ẹnì kan ṣoṣo tọ́ka sí tí kò lè lo òmìnira tó ní láti ṣe ohun tó bá ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ mu torí pé àwọn Ẹlẹ́rìí darí ìrònú rẹ̀.”—Ìpínrọ̀ 129.
Ẹ̀sùn míì tí wọ́n fi kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni pé torí pé wọn kì í gbẹ̀jẹ̀, wọ́n máa ń ṣèpalára fún ìlera àwọn ará wọn. Ọ̀tọ̀ ni ojú tí ilé ẹjọ́ fi wo ọ̀rọ̀ náà. Ó sọ pé:
“Òmìnira tí ẹnì kan ní láti gba irú ìtọ́jú kan tàbí láti má ṣe gbà á, tàbí láti yan irú ìtọ́jú mìíràn tó bá fẹ́, ṣe pàtàkì nítorí ìlànà tó fàyè gba olúkúlùkù láti dá ṣe ìpinnu. Bí àpẹẹrẹ, àgbàlagbà tó ti tójúúbọ́ ní òmìnira láti pinnu yálà láti gbà tàbí láti má ṣe gbà kí wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ fún òun tàbí kí wọ́n tọ́jú òun, ó sì tún lómìnira láti pinnu bóyá òun máa gbẹ̀jẹ̀ tàbí òun kò ní gbẹ̀jẹ̀.”—Ìpínrọ̀ 136.