Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mo Bẹ̀rù Ikú, Àmọ́ Ìyè “Lọ́pọ̀ Yanturu” Ni Mò Ń retí Báyìí

Mo Bẹ̀rù Ikú, Àmọ́ Ìyè “Lọ́pọ̀ Yanturu” Ni Mò Ń retí Báyìí

Mo Bẹ̀rù Ikú, Àmọ́ Ìyè “Lọ́pọ̀ Yanturu” Ni Mò Ń retí Báyìí

Gẹ́gẹ́ bí Piero Gatti ṣe sọ ọ́

A BẸ̀RẸ̀ sí í gbọ́ ariwo kan lábẹ́lẹ̀, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ariwo náà ń pọ̀ sí í. Lẹ́yìn náà, agogo ìdágìrì bẹ̀rẹ̀ sí í dún láti kìlọ̀ fáwọn èèyàn pé kí wọ́n wá ibi fara pa mọ́ sí. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà la bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ ariwo bọ́ǹbù tó ń ba àwọn nǹkan jẹ́. Ìpayà sì bá àwọn èèyàn nítorí bí ariwo náà ṣe ń milẹ̀ tìtì.

Ìlú Milan ní orílẹ̀-èdè Ítálì ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti wáyé ní ọdún 1943 sí ọdún 1944. Sójà ni mí nígbà yẹn, mi ò sì tíì dàgbà púpọ̀. Níbi tí wọ́n yàn mí sí, wọ́n sábà máa ń pàṣẹ fún mi pé kí n lọ sínú àwọn ilé tí wọ́n kọ́ fáwọn èèyàn láti máa fara pa mọ́ sí nígbà tí ọkọ̀ òfuurufú bá ń ju bọ́ǹbù látòkè, kí n sì máa kó òkú àwọn tí bọ́ǹbù pa síbẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà àwọn òkú yìí kì í ṣe dá mọ̀ torí pé bọ́ǹbù á ti já wọn jálajàla. Àmọ́, yàtọ̀ sí àwọn òkú tí mò ń rí lójoojúmọ́, ọ̀pọ̀ ìgbà ni ikú máa ń yẹ̀ lórí mi bí ìpakúpa náà ṣe ń lọ lọ́wọ́. Mo máa ń gbàdúrà mo sì máa ń ṣèlérí fún Ọlọ́run pé bó bá dá ẹ̀mí mi sí, ìfẹ́ rẹ̀ ni màá ṣe.

Mi Ò Bẹ̀rù Ikú Mọ́

Abúlé kan tó fi nǹkan bíi kìlómítà mẹ́wàá jìn sí ìlú Como, ní orílẹ̀-èdè Ítálì tó sì sún mọ́ ẹnubodè orílẹ̀-èdè Switzerland ni mo gbé dàgbà. Láti kékeré ni àwọn ohun tó ń fa ìbànújẹ́ ti ń ṣẹlẹ̀ sí mi tí mo sì ń bẹ̀rù ikú. Àjàkálẹ̀-àrùn gágá pa méjì lára àwọn ẹ̀gbọ́n mi obìnrin. Nígbà tí ìyá mi Luigia kú ní ọdún 1930, ọmọ ọdún mẹ́fà péré ni mí. Gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́sìn Kátólíìkì, láti kékeré ni mo ti mọ òfin ẹ̀sìn náà tí mo sì ń tẹ̀ lé e, mo tún máa ń lọ síbi ààtò gbígba ara Olúwa. Àmọ́, ṣọ́ọ̀ṣì kọ́ ló paná ìbẹ̀rù mi, ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà ní ṣọ́ọ̀bù kan tí wọ́n ti ń gẹrun ni kò jẹ́ kí n bẹ̀rù mọ́.

Ní ọdún 1944, ọ̀pọ̀ èèyàn ni Ogun Àgbáyé Kejì pa. Mo wà lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọmọ ogun orílẹ̀-èdè Ítálì tó sá kúrò lójú ogun lọ sí orílẹ̀-èdè Switzerland tí kò lọ́wọ́ sí ogun náà. Nígbà tá a débẹ̀ wọ́n kó wa lọ sí àwọn àgọ́ mélòó kan tí wọ́n ń kó àwọn tí ogun lé wá láti orílẹ̀-èdè míì sí. Ọ̀kan lára àwọn àgọ́ yìí tó wà ní abúlé kan tí wọ́n ń pè ní Steinach ní àríwá ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè yẹn ni wọ́n fi mí sí. Wọ́n fún wa lómìnira díẹ̀ níbẹ̀. Ẹni tó ń gẹrun ní abúlé Steinach nílò ẹnì kan tó máa ràn án lọ́wọ́ ní ṣọ́ọ̀bù rẹ̀ fúngbà díẹ̀. Oṣù kan péré ni mo fi bá a ṣiṣẹ́, ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni mo sì gbé, àmọ́ àkókò yẹn náà ni mo pàdé ẹni tó yí ìgbésí ayé mi pa dà.

Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ọmọ Ítálì kan tó ń gbé orílẹ̀-èdè Switzerland tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Adolfo Tellini ti ń gẹrun, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mi ò tíì gbọ́ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí, èyí ò sì ṣàjèjì torí pé àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Ítálì nígbà yẹn kò ju àádọ́jọ [150] lọ. Adolfo sọ àwọn ohun àgbàyanu tí Bíbélì fi kọ́ni fún mi àti bó ṣe ṣèlérí àlàáfíà àti ‘ìyè lọ́pọ̀ yanturu.’ (Jòh. 10:10; Ìṣí. 21:3, 4) Ohun tí mo gbọ́ nípa ọjọ́ iwájú kan tí kò ní sí ogun àti ikú mọ́ dùn mọ́ mi gan-an ni. Nígbà tí mo pa dà sí àgọ́ tí wọ́n fi wá sí, mo sọ ohun tí mo kọ́ yìí fún Giuseppe Tubini, ọ̀dọ́kùnrin kan tí òun pẹ̀lú wá láti Ítálì, òun náà sì nífẹ̀ẹ́ sí ohun tó gbọ́. Adolfo àti àwọn Ẹlẹ́rìí míì máa ń wá bẹ̀ wá wò lóòrèkóòrè ní àgọ́ tá a wà.

Adolfo mú mi lọ sí ìlú Arbon tó fi nǹkan bíi kìlómítà mẹ́wàá jìn sí abúlé Steinach, níbẹ̀ àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí kéréje kan ń ṣèpàdé lédè Ítálì. Mo gbádùn ohun tí mo gbọ́ nípàdé lọ́jọ́ yẹn débi pé lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e mo fẹsẹ̀ rìn lọ síbẹ̀. Lẹ́yìn náà, mo lọ sí àpéjọ kan tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní gbọ̀ngàn àpéjọ kan ní ìlú Zurich. Níbẹ̀ wọ́n lo ẹ̀rọ tó máa ń gbé àwòrán sára ògiri láti fi àwọn àgọ́ tí wọ́n ti ń pa àwọn èèyàn ní ìpakúpa hàn wá, a sì rí bí wọ́n ṣe to àwọn òkú sórí ara wọn gègèrè. Wọ́n sọ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn Ẹlẹ́rìí ilẹ̀ Jámánì ni wọ́n pa nítorí ìgbàgbọ́ wọn. Àpéjọ yẹn ni mo ti pàdé Maria Pizzato. Ìjọba Aláṣẹ Oníkùmọ̀ ti orílẹ̀-èdè Ítálì rán an lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún mọ́kànlá nítorí pé ó ń lọ́wọ́ sí ìgbòkègbodò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Nígbà tí ogun parí, mo pa dà sí orílẹ̀-èdè Ítálì, mo sì dara pọ̀ mọ́ ìjọ kékeré tó wà ní ìlú Como. Kò sẹ́ni tó bá mi ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì irú èyí tá a máa ń ṣe lónìí. Àmọ́, mo ní òye tó ṣe kedere nípa àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tí Bíbélì fi kọ́ni. Ìjọ tí mo wà náà ni Maria Pizzato wà. Ó jẹ́ kí n mọ ìdí tí mo fi gbọ́dọ̀ ṣe ìrìbọmi, ó sì mú mi lọ sọ́dọ̀ Arákùnrin Marcello Martinelli tó ń gbé ní ìlú Castione Andevenno ní ẹkùn-ìpínlẹ̀ Sondrio. Adúróṣinṣin ni Arákùnrin Marcello ó sì tún jẹ́ ẹni àmì òróró. Ọdún mọ́kànlá ni ìjọba bóofẹ́bóokọ̀ yẹn fi jù ú sẹ́wọ̀n. Mo máa ń fi kẹ̀kẹ́ rin ìrìn àjò ọgọ́rin [80] kìlómítà lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.

Marcello lo Bíbélì láti ṣàlàyé béèyàn ṣe lè tóótun láti ṣe ìrìbọmi, lẹ́yìn náà a gbàdúrà a sì lọ sí odò Adda, ibẹ̀ ni mo ti ṣe ìrìbọmi ní oṣù September, ọdún 1946. Ọjọ́ pàtàkì ni ọjọ́ náà! Inú mi dùn gan-an lọ́jọ́ yẹn pé mo pinnu láti máa sin Jèhófà àti pé mo ní ìrètí tó dájú nípa ọjọ́ ọ̀la, ìyẹn ló sì gbà mí lọ́kàn débi pé ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, mi ò mọ̀ pé mo ti fi kẹ̀kẹ́ rin ìrìn àjò tó tó ọgọ́jọ [160] kìlómítà!

Lẹ́yìn ogun, a ṣe àpéjọ àkọ́kọ́ ní oṣù May, ọdún 1947 ní ìlú Milan ní orílẹ̀-èdè Ítálì. Nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700] èèyàn ló wá sí àpéjọ náà, tó fi mọ́ àwọn tó fara da inúnibíni lábẹ́ Ìjọba Aláṣẹ Oníkùmọ̀. Ohun kan ṣẹlẹ̀ ní àpéjọ yìí tó ṣàjèjì. Giuseppe Tubini tí mo wàásù fún ní àgọ́ tí wọ́n ń kó àwọn tí ogun lé wá láti orílẹ̀-èdè míì sí ló sọ àsọyé ìrìbọmi, lẹ́yìn tó sọ ọ́ tán ni òun fúnra rẹ̀ wá ṣèrìbọmi!

Ní àpéjọ yẹn, mo láǹfààní láti pàdé Arákùnrin Nathan Knorr tó wá láti Bẹ́tẹ́lì ti Brooklyn. Ó gba èmi àti Giuseppe níyànjú pé ká fi ìgbésí ayé wa sin Ọlọ́run. Mo pinnu pé láàárín oṣù kan sígbà yẹn ni mo máa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Nígbà tí mo délé, mo sọ ohun tí mo pinnu láti ṣe fún àwọn èèyàn mi, gbogbo wọ́n sì rọ̀ mí pé kí n má ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, mi ò jẹ́ kí ohunkóhun yẹ ìpinnu mi. Torí náà, ní oṣù kan lẹ́yìn náà mo bẹ̀rẹ̀ sí í sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní ìlú Milan. Àwọn míṣọ́nnárì mẹ́rin ló ń sìn níbẹ̀ nígbà yẹn. Àwọn ni: Giuseppe (Joseph) Romano àti ìyàwó rẹ̀, Angelina; Carlo Benanti àti ìyàwó rẹ̀, Costanza. Ẹni karùn-ún tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dara pọ̀ mọ́ wọn ni Giuseppe Tubini, èmi sì ni ẹni kẹfà.

Lẹ́yìn tí mo ti sìn ní Bẹ́tẹ́lì fún oṣù kan, wọ́n yàn mí gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká. Èmi ni ọmọ bíbí ilẹ̀ Ítálì àkọ́kọ́ tó di alábòójútó àyíká ní orílẹ̀-èdè wa. Ṣáájú ìgbà yẹn Arákùnrin George Fredianelli, tó jẹ́ míṣọ́nnárì àkọ́kọ́ tó wá sìn ní orílẹ̀-èdè Ítálì láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní ọdún 1946, ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò. Ó dá mi lẹ́kọ̀ọ́ fún ọ̀sẹ̀ mélòó kan, lẹ́yìn náà ni mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tuntun náà fúnra mi. Mo ṣì rántí ìjọ tí mo kọ́kọ́ bẹ̀ wò, ìjọ Faenza. Àǹfààní ńlá mà nìyẹn o! Kí n tó bẹ ìjọ yẹn wò, mi ò tíì sọ àsọyé rí nínú ìjọ! Síbẹ̀, mo rọ gbogbo àwọn tó gbọ́ àsọyé náà, títí kan àwọn ọ̀dọ́, pé kí wọn gbìyànjú láti ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Nígbà tó yá, àwọn kan lára àwọn ọ̀dọ́ yẹn ní àǹfààní láti máa bójú tó iṣẹ́ àyànfúnni pàtàkì ní ilẹ̀ Ítálì.

Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò iṣẹ́ tó ń múni lọ́kàn yọ̀ ni mo dáwọ́ lé. Iṣẹ́ ìsìn yẹn kún fún ìyàlẹ́nu, ó gba pé kéèyàn máa ṣe àwọn ìyípadà, ó kún fún ìpèníjà, ó ń fúnni láyọ̀, àwọn ará mi ọ̀wọ́n sì fìfẹ́ hàn sí mi lọ́pọ̀lọpọ̀.

Bí Ọ̀ràn Ẹ̀sìn Ṣe Rí Lórílẹ̀-Èdè Ítálì Lẹ́yìn Ogun

Ẹ jẹ́ kí n sọ díẹ̀ fún yín nípa bí ọ̀ràn ẹ̀sìn ṣe rí lórílẹ̀-èdè Ítálì nígbà yẹn. Ẹ̀sìn Kátólíìkì lágbára gan-an, kò sì sí ẹni tó lè yẹ ẹ̀sìn náà lọ́wọ́ wò. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọdún 1948 ni orílẹ̀-èdè Ítálì bẹ̀rẹ̀ sí í lo òfin tuntun, ọdún 1956 ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fagi lé òfin tí kò jẹ́ káwọn Ẹlẹ́rìí lè wàásù fàlàlà lórílẹ̀-èdè náà. Lọ́pọ̀ ìgbà àwọn aṣáájú ẹ̀sìn máa ń fẹ́ láti dá àpéjọ àyíká tá à ń ṣe dúró. Àmọ́, ìsapá wọn máa ń já sí pàbó nígbà míì. Èyí ni ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 1948 ní abúlé kékeré kan tó ń jẹ́ Sulmona ní àárín gbùngbùn Ítálì.

Inú gbọ̀ngàn eré orí ìtàgé la ti ṣe àpéjọ náà. Èmi ni alága ní òwúrọ̀ Sunday, Giuseppe Romano ló sọ àsọyé fún gbogbo ènìyàn. Àwọn tó wá sí àpéjọ yẹn pọ̀ gan-an tá a bá fi wọ́n wé iye akéde tó wà lórílẹ̀-èdè náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn akéde tó wà ní orílẹ̀-èdè náà kò tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500], iye èèyàn tó kún inú gbọ̀ngàn yẹn jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì [2,000]. Bí àsọyé náà ṣe parí ni ọ̀dọ́kùnrin kan bẹ́ sórí pèpéle. Àwọn àlùfáà méjì tí wọ́n wà nínú àwùjọ náà ni wọ́n bẹ̀ ẹ́ lọ́wẹ̀. Ọ̀dọ́kùnrin náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í lọgun, kó lè da ibẹ̀ rú. Mo sọ fún un lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé, “Bó o bá lọ́rọ̀ tó o fẹ́ sọ, lọ gba gbọ̀ngàn tìrẹ, o sì lè sọ ohun tó bá wù ẹ́ níbẹ̀.” Ohun tó ń sọ kò tà létí àwùjọ, ariwo tí wọ́n pa lé e lórí pé kó kúrò níbẹ̀ sì bo ohùn rẹ̀ mọ́lẹ̀. Bí ọ̀dọ́kùnrin náà ṣe bẹ́ kúrò lórí pèpéle nìyẹn tó sì pòórá.

Nígbà yẹn, ìrìn àjò máa ń gbádùn mọ́ni bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn. Nígbà míì mo máa ń rìn láti ìjọ kan lọ sí ìjọ mìíràn, mo lè gun kẹ̀kẹ́, mo lè wọ ọkọ̀ hẹ́gẹhẹ̀gẹ tó kún àkúnya, mo sì lè wọ ọkọ̀ ojú irin. Àwọn ìgbà míì sì wà tó jẹ́ pé ilé ẹran tàbí ibi tí wọ́n ń tọ́jú nǹkan èlò sí ni mo máa ń dé sí. Ogun ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ni, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn tó wà ní Ítálì nígbà yẹn ló tòṣì. Àwọn ará tó wà níbẹ̀ kò pọ̀, wọn kò sì lówó. Síbẹ̀, wọ́n ṣì rí i pé iṣẹ́ ìsìn Jèhófà dára gan-an ni.

Mo Lọ Gba Ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì

Lọ́dún 1950, wọn fi ìwé pe èmi àti Giuseppe Tubini pé ká wá sí kíláàsì kẹrìndínlógún ti ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì tó wà fún àwọn míṣọ́nnárì. Látilẹ̀ ni mo ti mọ̀ pé ó máa ṣòro fún mi láti kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Mo sapá gidigidi, àmọ́ kò rọrùn. A ní láti ka Bíbélì látìbẹ̀rẹ̀ dópin ní èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ìgbà míì wà tí mi ò kí ń jẹ oúnjẹ ọ̀sán, kí n lè fi àkókò yẹn ka Bíbélì sókè ketekete. Nígbà tó ṣe, ó yí kàn mí láti sọ àsọyé. Mo ṣì rántí ohun tí olùkọ́ wa sọ dáadáa. Ó ní, “O ní ìtara, o sì ń fọwọ́ ṣàpèjúwe bó ti yẹ, àmọ́ ìwọ nìkan ni èdè Gẹ̀ẹ́sì tó ò ń sọ yé!” Síbẹ̀, mo tiraka láti bá wọn parí ilé ẹ̀kọ́ náà. Lẹ́yìn náà, wọ́n rán èmi àti Giuseppe pa dà sí Ítálì. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n fún wa yìí jẹ́ ká túbọ̀ tóótun láti sin àwọn ará wa.

Ní ọdún 1955, mo gbé Lidia níyàwó. Èmi ni mo sọ àsọyé ìrìbọmi rẹ̀ ní ọdún méje sẹ́yìn. Arákùnrin ọ̀wọ́n ni Domenico bàbá Lidia, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ìjọba Oníkùmọ̀ ṣe inúnibíni sí i tí wọ́n sì lé e jáde kúrò nílùú fún ọdún mẹ́ta, síbẹ̀ ó ran gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèje lọ́wọ́ láti wá sínú òtítọ́. Lidia náà gbèjà òtítọ́. Kó tó di pé òfin fàyè gbà wá láti máa wàásù láti ilé dé ilé, ìgbà mẹ́ta ló ti fojú ba ilé ẹjọ́. Lẹ́yìn ọdún kẹfà tá a ti ṣègbéyàwó la bí Beniamino, àkọ́bí wa ọkùnrin. Ní ọdún 1972 a bí Marco ọmọkùnrin wa kejì. Inú mi dùn pé àwọn ọmọ wa méjèèjì ń fìtara sin Jèhófà pa pọ̀ pẹ̀lú ìdílé wọn.

Mi Ò Dẹwọ́ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà

Ní gbogbo àkókò tí mo fi sin àwọn ẹlòmíì, mo láyọ̀ mi ò sì jẹ́ gbàgbé ọ̀pọ̀ ìrírí tí mo ní. Bí àpẹẹrẹ, ní ọdún 1980 tàbí láìpẹ́ lẹ́yìn náà, bàbá ìyàwó mi kọ lẹ́tà sí Sandro Pertini tó jẹ́ ààrẹ orílẹ̀-èdè Ítálì nígbà yẹn. Nígbà Ìjọba Oníkùmọ̀, wọ́n lé àwọn méjèèjì lọ sí ìgbèkùn ní erékùṣù Ventotene tí ìjọba máa ń kó àwọn tí wọ́n kà sí ọ̀tá orílẹ̀-èdè sí. Bàbá ìyàwó mi sọ nínú lẹ́tà yẹn pé òun fẹ́ bá ààrẹ náà sọ̀rọ̀, ó fẹ́ lo àǹfààní yẹn láti wàásù fún un. Nígbà tí ààrẹ gbà pé kí bàbá ìyàwó mi wá rí òun, mo bá a lọ, wọ́n sì gbà wá lálejò dáadáa, èyí tí kì í sábàá rí bẹ́ẹ̀. Ààrẹ fi ọ̀yàyà kí bàbá ìyàwó mi káàbọ̀ ó sì gbá a mọ́ra. Lẹ́yìn náà, a sọ ohun tá a gbà gbọ́ fún un, a sì fún un ní àwọn ìwé wa mélòó kan.

Ní ọdún 1991, lẹ́yìn tí mo ti fi ọdún mẹ́rìnlélógójì [44] sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò, tí mo sì ti bẹ gbogbo ìjọ tó wà ní orílẹ̀-èdè Ítálì wò, mo fi iṣẹ́ àyíká sílẹ̀. Ní ọdún mẹ́rin tó tẹ̀ lé e, mo sìn gẹ́gẹ́ bí Alábòójútó Gbọ̀ngàn Àpéjọ títí tí àìsàn tó nira fi mú kó di dandan pé kí n dín iṣẹ́ tí mò ń ṣe kù. Àmọ́, mo dúpẹ́ fún inúure àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Jèhófà fi hàn sí mi, tó jẹ́ kí n ṣì wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Mo máa ń ṣe gbogbo ohun tí agbára mi bá gbé lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni ní ìhìn rere, ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí mò ń darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì díẹ̀. Àwọn ará ṣì máa ń sọ pé mo máa ń lo ìtara “gbígbóná janjan” tí mo bá ń sọ àsọyé. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé ara ti ń dara àgbà kò jẹ́ kí ìtara mi dín kù.

Nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́, mo máa ń bẹ̀rù ikú gan-an ni, àmọ́ nígbà tí mo ní ìmọ̀ pípéye nípa Bíbélì mo ti wá ní ìrètí tó dájú pé mo lè ní ìyè àìnípẹ̀kun, ìyẹn ni Jésù pè ní ìyè “lọ́pọ̀ yanturu.” (Jòh. 10:10) Ohun tí mò ń wọ̀nà fún báyìí nìyẹn. Ìgbésí ayé tó kún fún àlàáfíà, ààbò àti ayọ̀, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ yanturu ìbùkún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà. Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́ ni gbogbo ìyìn yẹ fún, ẹni tó jẹ́ ká láǹfààní láti máa jẹ́ orúkọ mọ́ òun.—Sm. 83:18.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 22, 23]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

SWITZERLAND

BERN

Zurich

Arbon

Steinach

ÍTÁLÌ

RÓÒMÙ

Como

Milan

Odò Adda

Castione Andevenno

Faenza

Sulmona

Ventotene

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

À ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Ìgbà tí èmi àti Giuseppe wà ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ọjọ́ tá a ṣe ìgbéyàwó

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ó ti lé ní ọdún márùnléláàádọ́ta tí èmi àti aya mi ọ̀wọ́n ti jọ wà pa pọ̀