Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Àbá Tó Lè Wúlò fún Yín Nígbà Ìjọsìn Ìdílé àti Ìdákẹ́kọ̀ọ́

Àwọn Àbá Tó Lè Wúlò fún Yín Nígbà Ìjọsìn Ìdílé àti Ìdákẹ́kọ̀ọ́

Àwọn Àbá Tó Lè Wúlò fún Yín Nígbà Ìjọsìn Ìdílé àti Ìdákẹ́kọ̀ọ́

NÍ ÌBẸ̀RẸ̀ ọdún 2009, ọ̀nà táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé gbà ń ṣe àwọn ìpàdé ìjọ yí pa dà. Ìgbìmọ̀ Olùdarí pa àwọn ìpàdé tá à ń ṣe láàárín ọ̀sẹ̀ pọ̀, kí ìrọ̀lẹ́ kan bàa lè ṣí sílẹ̀. Wọ́n sì fún gbogbo wa níṣìírí pé ká máa lo ìrọ̀lẹ́ tó ṣí sílẹ̀ yìí fún Ìjọsìn Ìdílé tàbí ìdákẹ́kọ̀ọ́. Ṣé o ti ń lo ìrọ̀lẹ́ tó ṣí sílẹ̀ náà bí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣe sọ pé ká máa lò ó? Ṣé o sì ń jàǹfààní kíkún látinú ṣíṣe bẹ́ẹ̀?

Kò tíì rọrùn fún àwọn kan láti mọ ìtẹ̀jáde ti wọ́n lè máa lò nígbà Ìjọsìn Ìdílé. Ìgbìmọ̀ Olùdarí kọ́ ni yóò sọ ohun tí ìdílé kọ̀ọ̀kan á máa kẹ́kọ̀ọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ fún wọn. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé nǹkan ò rí bákan náà nínú gbogbo ìdílé, ohun tó dáa ni pé kí olórí ìdílé kọ̀ọ̀kan ronú nípa ohun tí ìdílé rẹ̀ nílò kó sì pinnu ohun tó máa ṣe wọ́n láǹfààní jù lọ. Ẹnì kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú lè pinnu ọ̀nà tó dára jù lọ tí wọ́n á máa gbà lo ìrọ̀lẹ́ tó ṣí sílẹ̀ náà.

Àwọn ìdílé kan máa ń fi àkókò náà múra àwọn ìpàdé ìjọ sílẹ̀, àmọ́ kì í ṣe ìyẹn nìkan ló yẹ kí wọ́n máa ṣe nígbà Ìjọsìn Ìdílé. Àwọn ìdílé míì máa ń ka àwọn ìsọfúnni tó ṣàlàyé Ìwé Mímọ́, wọ́n á jíròrò rẹ̀, wọ́n tiẹ̀ tún lè ṣe àwòkẹ́kọ̀ọ́ tó dá lórí ohun tí wọ́n kà nínú Ìwé Mímọ́. Àwọn ọmọdé máa ń jàǹfààní gan-an látinú èyí. Kì í ṣe gbogbo ìgbà ló yẹ ká máa lo ìbéèrè àti ìdáhùn bá a ṣe máa ń ṣe láwọn ìpàdé ìjọ, èyí kì í sábà jẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ gbádùn mọ́ni. Ohun tó dáa jù ni pé kí àkókò Ìjọsìn Ìdílé tuni lára kó fún ìdílé láǹfààní láti jíròrò ohun tí wọ́n ń kọ́ kí olúkúlùkù sì lè sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. Nírú àkókò bẹ́ẹ̀, olúkúlùkù á lè ronú jinlẹ̀ nípa ohun tí wọ́n jọ ń jíròrò, wọ́n á lè sọ̀rọ̀ fàlàlà, èyí á sì mú kí gbogbo wọn gbádùn Ìjọsìn Ìdílé náà.

Bàbá kan tó ní ọmọ mẹ́ta sọ bí wọ́n ṣe ń ṣe Ìjọsìn Ìdílé tiwọn, ó ní: “Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ la sábà máa ń lò. Ṣáájú àkókò Ìjọsìn Ìdílé wa, ẹnì kọ̀ọ̀kan á ti ka àwọn orí Bíbélì náà, àwọn ọmọ wa á ṣèwádìí lórí díẹ̀ lára ohun tí wọ́n kà, wọ́n á sì sọ ohun tí wọ́n rí kọ́ látinú ìwádìí náà. Michael [ọmọ ọdún méje] sábà máa ń ya àwòrán ohun tó bá kà tàbí kó kọ nǹkan kan nípa rẹ̀. David [ọmọ ọdún mẹ́tàlá] àti Kaitlyn [ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún] lè kọ ìtàn kan nínú Bíbélì bíi pé wọ́n wà níbẹ̀ nígbà tí ìtàn náà wáyé. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tá à ń ka ìtàn nípa bí Jósẹ́fù ṣe túmọ̀ àlá tí olùṣe búrẹ́dì àti agbọ́tí ọba Fáráò lá, Kaitlyn kọ ìtàn náà bíi pé ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ọ̀ràn náà ṣojú rẹ̀.”—Jẹ́n., orí 40.

Torí pé ipò ẹnì kọ̀ọ̀kan wa yàtọ̀ síra, ohun tí ẹnì kan tàbí ìdílé kan rí pó wúlò fáwọn lè yàtọ̀ sí ohun tó máa wúlò fún ìdílé míì. Nínú àpótí tó wà lójú ìwé tó kàn, ẹ máa rí àwọn àbá mélòó kan tẹ́ ẹ lè lò nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe Ìjọsìn Ìdílé tàbí ìdákẹ́kọ̀ọ́. Ó ṣeé ṣe kẹ́ ẹ tún ronú kan ọ̀pọ̀ àwọn àbá míì.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6, 7]

Fún àwọn ìdílé tó ní àwọn ọ̀dọ́:

• Ẹ ka ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́ kí ẹ sì jíròrò rẹ̀.

• Bẹ́ ẹ bá ń ka Bíbélì, ẹ lè lo àwọn ìbéèrè bíi “Ká sọ pé ìwọ ni ẹni tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbí yìí ńkọ́. . . ?” (Wo Ilé-Ìṣọ́nà May 15, 1996, ojú ìwé 14, ìpínrọ̀ 17 sí 18.)

• Ẹ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tẹ́ ẹ máa fẹ́ láti ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú.

• Látìgbàdégbà, ẹ máa wo àwọn fídíò tí ètò Ọlọ́run ṣe jáde, kẹ́ ẹ sì máa jíròrò rẹ̀.

• Ẹ máa lo àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Abala Àwọn Ọ̀dọ́” nínú Ilé Ìṣọ́.

Fún tọkọtaya tí kò tíì bímọ:

• Ẹ jíròrò orí 1, 3 àti 11 sí 16 nínú ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé.

• Ẹ máa ka àwọn orí kan nínú Bíbélì, kẹ́ ẹ ṣe ìwádìí lé wọn lórí, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò àwọn ohun tẹ́ ẹ rí kọ́.

• Ẹ múra Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ tàbí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ sílẹ̀.

• Ẹ jíròrò bí ẹ̀yin méjèèjì ṣe lè máa ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.

Fún àwọn tí kò lọ́kọ tàbí aya tàbí àwọn tó wà nínú ìdílé tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn tó yàtọ̀ síra:

• Ẹ kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìwé tó jáde ní àpéjọ àgbègbè.

• Ẹ ka àwọn ìwé ọdọọdún, ìyẹn Yearbook of Jehovah’s Witnesses ti lọ́ọ́lọ́ọ́ àti tàwọn ọdún tó ti kọjá.

• Ẹ ṣe ìwádìí lórí àwọn ìbéèrè táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ yín.

• Ẹ múra bí ẹ ṣe máa gbé ọ̀rọ̀ yín kalẹ̀ lóde ẹ̀rí.

Fún àwọn ìdílé tó ní àwọn ọmọ kéékèèké:

• Ẹ máa ṣe àwòkẹ́kọ̀ọ́ tó dá lórí Bíbélì.

• Ẹ máa ṣe eré àṣedárayá. Bí àpẹẹrẹ, ẹ lè lo àpilẹ̀kọ́ náà “Àtúnyẹ̀wò fún Ìdílé” tó máa ń wà lójú ìwé 31 nínú àwọn ìwé ìròyìn Jí! kan.

• Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ẹ máa ṣe ohun tó lè mú kẹ́ ẹ ronú jinlẹ̀. (Wo “Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Nínú Ọgbà Ẹranko!” nínú ìwé ìròyìn Jí! March 8, 1996, ojú ìwé 16 sí 19.)

• Ẹ jíròrò àpilẹ̀kọ tó ní àkọlé náà, “Kọ́ Ọmọ Rẹ” tó máa ń jáde nínú Ilé Ìṣọ́.