Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe láti sọ ní pàtó iye àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù?

Bá a bá fara balẹ̀ ka Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù a óò kíyè sí i pé ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà níbẹ̀ ló ṣẹ sí Jésù Kristi lára. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ibi tí Mèsáyà ti máa wá, ìgbà tó máa fara hàn, àwọn ohun tó máa ṣe, ìwà táwọn èèyàn máa hù sí i àti bí Jèhófà Ọlọ́run ṣe máa lò ó láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ náà lápapọ̀ jẹ́ ká lè dá Jésù mọ̀ gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà. Àmọ́, ó gba ìṣọ́ra tó bá dọ̀ràn pé kéèyàn sọ ní pàtó iye àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù.

Èrò àwọn èèyàn kò ṣọ̀kan lórí iye àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ nípa Mèsáyà àti àwọn tí kò sọ nípa rẹ̀. Nínú ìwé tí Alfred Edersheim kọ, ó sọ pé nígbà àtijọ́, ó fara hàn nínú ìwé táwọn rábì kọ pé ọ̀tàlénírínwó ó dín mẹ́rin [456] ẹsẹ Ìwé Mímọ́ látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ló dá lórí Mèsáyà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wọn kò lo ọ̀rọ̀ náà Mèsáyà ní tààràtà. (Ìwé The Life and Times of Jesus the Messiah) Tá a bá fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò gbogbo ọ̀tàlénírínwó ó dín mẹ́rin [456] ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí, a lè máa ṣiyè méjì bóyá òótọ́ ni àwọn kan lára wọn sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jésù Kristi. Bí àpẹẹrẹ, Edersheim sọ pé àwọn Júù gbà pé àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà ló wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 8:11. Wọ́n sọ pé “láti orí Òkè Mèsáyà ni àdàbà náà ti já ewé ólífì tó mú wá.” Ó tún mẹ́nu kan Ẹ́kísódù 12:42 nínú ìwé náà, ó sì ṣàlàyé bí àwọn Júù ṣe ṣì í lóye. Ó sọ pé: “Bí Mósè ṣe jáde wá látinú aṣálẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni Mèsáyà ṣe máa jáde wá láti Róòmù.” Ó dájú pé ó máa ṣòro fún ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé àtàwọn míì láti rí ọ̀nà tí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ méjì yìí àti àlàyé tí kò tọ̀nà náà gbà kan Jésù Kristi.

Ká tiẹ̀ wá sọ pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣẹ sí Jésù Kristi lára nìkan la fẹ́ kà, ó máa ṣòro láti fohùn ṣọ̀kan lórí iye tí wọ́n jẹ́ ní pàtó. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo ìwé Aísáyà orí 53, níbi tí ọ̀pọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà wà. Nínú ìwé Aísáyà 53:2-7 àsọtẹ́lẹ̀ kan wà níbẹ̀ tó sọ pé: “Kò ní ìdúró onídàńsáákì . . . A tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀, àwọn ènìyàn sì yẹra fún un . . . Àwọn àìsàn wa ni òun fúnra rẹ̀ gbé . . . A gún un nítorí ìrélànàkọjá wa . . . A ń mú un bọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn fún ìfikúpa.” Ṣé àsọtẹ́lẹ̀ kan ṣoṣo nípa Mèsáyà ló yẹ ká ka gbogbo ohun tí ìwé Aísáyà orí 53 sọ yìí sí, àbí ká wo onírúurú àwọn nǹkan tó sọ pó máa ṣẹlẹ̀ sí Mèsáyà gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ kọ̀ọ̀kan?

Tún wo Aísáyà 11:1, tó kà pé: “Ẹ̀ka igi kan yóò sì yọ láti ara kùkùté Jésè; àti láti ara gbòǹgbò rẹ̀, èéhù kan yóò máa so èso.” Àsọtẹ́lẹ̀ tó jọ èyí tún fara hàn nínú ẹsẹ 10. Ṣé àsọtẹ́lẹ̀ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ká gbà pó wà nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ méjì yìí, àbí àsọtẹ́lẹ̀ kan ṣoṣo tí Aísáyà tún sọ? Iye àsọtẹ́lẹ̀ tá a bá gbà pó wà nínú Aísáyà orí 53 àti Aísáyà orí 11 máa nípa lórí iye àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù.

Torí náà, ó dára ká má ṣe máa sọ pé iye báyìí ni àpapọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Ètò Jèhófà ti gbé àwọn àtẹ ìsọfúnni tó ní ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jésù àti bí wọ́n ṣe ní ìmúṣẹ jáde nínú àwọn ìwé wa. * Irú àwọn àtẹ ìsọfúnni yìí lè jẹ́ ká mọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà kí wọ́n sì fún wa ní ìṣírí tá a bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́, nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé àti nígbà tá a bá wà lóde ẹ̀rí. Síwájú sí, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà, láìka iye wọn sí, fún wa ní ẹ̀rí tó fìdí múlẹ̀ pé Jésù ni Kristi tàbí Mèsáyà.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Insight on the Scriptures, Apá Kìíní, ojú ìwé 1223; Apá Kejì, ojú ìwé 387; ìwé “All Scripture Is Inspired of God and Beneficial,” ojú ìwé 343 sí 344; Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? ojú ìwé 200.