Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí ni ìtumọ̀ àwọn ìsọfúnni tó máa ń wà nínú ìròyìn iṣẹ́ ìsìn wa ọdọọdún?

Lọ́dọọdún, a máa ń hára gàgà láti rí ìròyìn iṣẹ́ ìsìn tó máa ń jáde nínú ìwé ọdọọdún wa àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù February. Inú wa máa ń dùn láti rí àṣeyọrí táwọn èèyàn Jèhófà lápapọ̀ ti ṣe kárí ayé lẹ́nu iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni nípa Ìjọba Ọlọ́run. Àmọ́ kí ìròyìn náà tó lè ṣe wá láǹfààní ní kíkún, ó yẹ kí àwọn ohun tá a kọ síbẹ̀ yé wa dáadáa, ká sì ní òye tó tọ́ nípa àwọn nọ́ńbà tí wọ́n kọ síbẹ̀. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.

Ọdún iṣẹ́ ìsìn. Ọdún iṣẹ́ ìsìn máa ń bẹ̀rẹ̀ láti oṣù September ọdún kan, ó sì máa ń parí ní oṣù August ọdún tó tẹ̀ lé e. Ìròyìn ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá ló máa ń wà nínú ìwé ọdọọdún wa àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù February. Torí náà, nínú ìwé ọdọọdún wa ti ọdún 2011 àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù February, ọdún 2011 la ti máa rí ìròyìn ọdún iṣẹ́ ìsìn 2010 tó kọjá. Ìròyìn náà sì sọ nípa ìgbòkègbodò wa bẹ̀rẹ̀ láti September 1, ọdún 2009 títí di August 31, ọdún 2010.

Góńgó akéde àti ìpíndọ́gba akéde. “Akéde” ni gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ti ṣèrìbọmi àtàwọn tí àwọn alàgbà ti fọwọ́ sí pé kí wọ́n máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run àmọ́ tí wọn kò tíì ṣe ìrìbọmi. “Góńgó akéde” ni iye akéde tó pọ̀ jù lọ tí wọ́n ròyìn ní oṣù èyíkéyìí láàárín ọdún iṣẹ́ ìsìn. Ìròyìn àwọn akéde tí kò ròyìn lóṣù tó ṣáájú ìyẹn sì lè wà lára irú ìròyìn bẹ́ẹ̀. Nípa báyìí, ó ṣeé ṣe ká ka akéde kan lẹ́ẹ̀mejì. Àmọ́, a kì í ka àwọn akéde tó bá jáde òde ẹ̀rí tí wọ́n sì gbàgbé láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn sílẹ̀. Èyí jẹ́ ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí akéde kọ̀ọ̀kan tètè máa ròyìn lóṣooṣù. “Ìpíndọ́gba akéde” ni iye àwọn akéde tó sábà máa ń ròyìn àkókò tí wọ́n lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lóṣooṣù.

Àròpọ̀ wákàtí. Ìwé ọdọọdún wa ti ọdún 2011 àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù February, ọdún 2011 fi hàn pé iye wákàtí tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 2010 lé ní bílíọ̀nù kan àti ẹgbẹ̀ta mílíọ̀nù [1,600,000,000]. Àmọ́, àròpọ̀ wákàtí yìí kọ́ ni gbogbo wákàtí tá a lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà, torí pé a kò ka àkókò tá a máa ń lò lẹ́nu àwọn ìgbòkègbodò kan mọ́ ọn, irú bí ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn, lílọ sí ìpàdé, ṣíṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti ṣíṣe àṣàrò.

Iye owó tí a ná. Ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 2010, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ná iye tó lé ní mílíọ̀nù márùndínlọ́gọ́jọ [155,000,000] dọ́là láti bójú tó àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, àwọn míṣọ́nnárì àtàwọn alábòójútó arìnrìn-àjò lẹ́nu iṣẹ́ àyànfúnni wọn. Àmọ́, a ka iye tá a fi ń tẹ àwọn ìtẹ̀jáde tó ń ṣàlàyé Bíbélì mọ́ ara owó yìí o. Bákan náà, owó tá à ń ná láti bójú tó àwọn tó lé ní ọ̀kẹ́ kan [20,000] tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn láti máa ṣiṣẹ́ sìn ní àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa kárí ayé, kò sí lára rẹ̀.

Iye àwọn tó jẹ ohun ìṣàpẹrẹ Ìrántí Ikú Kristi. Èyí ni iye àwọn tó ti ṣèrìbọmi tí wọ́n jẹ nínú ohun ìṣàpẹrẹ Ìrántí Ikú Kristi kárí ayé. Ṣé èyí ni iye gbogbo àwọn ẹni àmì òróró tó wà lórí ilẹ̀ ayé? Kò fi dandan jẹ́ bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń fà á tí àwọn míì fi máa ń ní èrò tí kò tọ́ pé ìrètí tọ̀run làwọn ní. Ó lè jẹ́ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ nínú ẹ̀sìn tí wọ́n ń dara pọ̀ mọ́ tẹ́lẹ̀ tàbí kó tiẹ̀ jẹ́ ìṣòro ọpọlọ tàbí ìdààmú ọkàn ló sún wọn sí i. Torí náà kò sí bá a ṣe lè mọ iye àwọn ẹni àmì òróró tó ṣì wà láyé; kò sì pọn dandan pé ká mọ iye wọn. Ìgbìmọ̀ Olùdarí kì í tọ́jú orúkọ àwọn tó ń jẹ ohun ìṣàpẹẹrẹ nígbà Ìrántí Ikú Kristi sọ́wọ́. *

Ohun tá a mọ̀ ni pé nígbà tí àwọn áńgẹ́lì bá tú ẹ̀fúùfù aṣèparun dà sórí ayé nígbà ìpọ́njú ńlá, díẹ̀ lára àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ “àwọn ẹrú Ọlọ́run wa” ṣì máa kù láyé. (Ìṣí. 7:1-3) Títí dìgbà yẹn, àwọn ẹni àmì òróró á máa mú ipò iwájú nínú ìgbòkègbodò tí ìròyìn iṣẹ́ ìsìn wa ọdọọdún máa ń ṣàlàyé tó ṣe kedere nípa rẹ̀, ìyẹn iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni tí kò tíì sírú rẹ̀ rí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Wo àpilẹ̀kọ náà, “Olùṣòtítọ́ Ìríjú náà àti Ìgbìmọ̀ Olùdarí Rẹ̀,” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ June 15, 2009, ojú ìwé 24.