Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìpàdé Kan Tó Jẹ́ Mánigbàgbé

Ìpàdé Kan Tó Jẹ́ Mánigbàgbé

Ìpàdé Kan Tó Jẹ́ Mánigbàgbé

NÍ ÌBẸ̀RẸ̀ ìpàdé ọdọọdún ti Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania, ìkẹrìndínláàádóje [126] irú rẹ̀, èyí tó wáyé ní October 2, 2010, ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ìlú Jersey tó wà ní ìpínlẹ̀ New Jersey, ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, Arákùnrin Stephen Lett tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé: “Nígbà tí ìpàdé yìí bá fi máa parí, ẹ máa sọ pé, ‘Dájúdájú, mánigbàgbé ni ìpàdé ọdọọdún tó wáyé lọ́dún yìí!’” Èyí mú kí ara àwọn tó wà láwùjọ túbọ̀ wà lọ́nà fún ohun tó máa wáyé nípàdé náà. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìsọfúnni pàtàkì tí wọ́n jíròrò ní ìpàdé mánigbàgbé náà?

Nínú àsọyé tí Arákùnrin Lett kọ́kọ́ sọ nígbà ìpàdé ọdọọdún náà, ó fi ìtara ṣàlàyé nípa kẹ̀kẹ́ ẹṣin òkè ọ̀run ti Jèhófà tí ìwé Ìsíkíẹ́lì ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú Bíbélì. Arákùnrin Lett sọ pé, kẹ̀kẹ́ ẹṣin ńlá ológo yìí ṣàpẹẹrẹ ètò Ọlọ́run, Jèhófà ló sì ń darí rẹ̀ bó ṣe fẹ́. Apá tó jẹ́ ti òkè ọ̀run lára ètò náà ń yára sáré bíi mànàmáná, èyí tó ṣàpẹẹrẹ bí ìrònú Jèhófà ṣe yára tó. Àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ló sì wà nínú apá tó jẹ́ ti òkè ọ̀run yìí. Apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò Jèhófà Ọlọ́run yìí náà ń yára sáré. Arákùnrin Lett sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra tó ti ń ṣẹlẹ̀ nínú apá tó ṣeé fojú rí lára ètò Ọlọ́run láwọn ọdún àìpẹ́ yìí.

Bí àpẹẹrẹ, a ti pa àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì mélòó kan pọ̀ di ẹyọ kan, èyí tó máa mú kí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì tó wà nírú àwọn orílẹ̀-èdè bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀ gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù. Arákùnrin Lett rọ gbogbo àwọn tó wà láwùjọ láti máa gbàdúrà pé kí Ìgbìmọ̀ Olùdarí tó ń ṣojú fún ẹrú olóòótọ́ àti olóye lè máa bá a nìṣó láti jẹ́ olóòótọ́, kí wọ́n sì tún jẹ́ ọlọ́gbọ́n.—Mát. 24:45-47.

Àwọn Ìròyìn Tí Ń Fúnni Ní Ìṣírí àti Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò Tó Ń Mọ́kàn Yọ̀

Arákùnrin Tab Honsberger, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ní orílẹ̀-èdè Haiti, sọ ìròyìn tó wọni lọ́kàn nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìsẹ̀lẹ̀ tó wáyé lórílẹ̀-èdè náà ní January 12, 2010, èyí tí wọ́n fojú bù pé ó pa èèyàn tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún [300,000]. Ó ní ńṣe làwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ń sọ fáwọn èèyàn pé ohun tó mú kí Ọlọ́run pa àwọn tó kú yẹn ni pé wọn kò nígbàgbọ́, àmọ́ ó dáàbò bo àwọn ẹni rere. Síbẹ̀, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn jàǹdùkú tó wà lẹ́wọ̀n ló sá lọ nígbà tí ìsẹ̀lẹ̀ yẹn mú kí ògiri ọgbà ẹ̀wọ̀n tí wọ́n wà wó lulẹ̀. Àmọ́, bí ọ̀pọ̀ àwọn tó ní ọkàn rere lórílẹ̀-èdè náà ṣe ń mọ ohun tó fà á tí àkókò tá a wà yìí fi kún fún ìyọnu, èyí ń tù wọ́n nínú. Arákùnrin Honsberger sọ ohun tí arákùnrin kan tó jẹ́ olùṣòtítọ́ tó sì jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Haiti, àmọ́ tí ìyàwó rẹ̀ kú nígbà ìsẹ̀lẹ̀ náà sọ. Ó ní: “Mo ṣì ń sunkún títí dòní. Mi ò mọ ìgbà tí mi ò ní ṣọ̀fọ̀ ìyàwó mi mọ́, àmọ́ ìfẹ́ tí ètò Jèhófà ti fi hàn sí mi mú inú mi dùn. Mo ní ìrètí, mo sì ti pinnu láti sọ ohun tí mo gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíì.”

Arákùnrin Mark Sanderson, tó ti di ọ̀kan lára ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní Brooklyn báyìí, ló sọ̀rọ̀ nípa orílẹ̀-èdè Philippines. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ní orílẹ̀-èdè náà tẹ́lẹ̀, tayọ̀tayọ̀ ló fi sọ̀rọ̀ nípa bí iye àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run tó wà lórílẹ̀-èdè náà ṣe pọ̀ sí i ní ìgbà méjìlélọ́gbọ̀n [32] tẹ̀lératẹ̀léra, àwọn tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sì pọ̀ fíìfíì ju àwọn akéde lọ. Ó sọ̀rọ̀ nípa Arákùnrin Miguel tí wọ́n pa ọmọ ọmọ rẹ̀. Miguel rí sí i pé ẹni tó pa ọmọ ọmọ rẹ̀ fojú ba ilé ẹjọ́, wọ́n sì rán an lọ sẹ́wọ̀n. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, Miguel lọ wàásù ní ọgbà ẹ̀wọ̀n yẹn, ó sì bá apànìyàn náà pàdé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojora mú Miguel ó fohùn pẹ̀lẹ́ bá apànìyàn náà sọ̀rọ̀. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó kọ́ ọkùnrin náà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ọkùnrin náà gba ohun tó kọ́ gbọ́, ó sì wá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Ní báyìí, ó ti ṣèrìbọmi. Òun àti Miguel ti di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Torí pé ó ti di arákùnrin, Miguel ń gbìyànjú láti ràn án lọ́wọ́ kí wọ́n lè tètè tú u sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. *

Apá tó tẹ̀ lé e ni ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tó jẹ́ kí àwọn èèyàn túbọ̀ mọ àwọn ará wa kan sí i. Arákùnrin Mark Noumair tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Ẹ̀kọ́ Ètò Ọlọ́run ló bójú tó o. Ó fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn tọkọtaya mẹ́ta. Àwọn ni Alex àti Sarah Reinmueller, David àti Krista Schafer, àti Robert àti Ketra Ciranko. Alex Reinmueller tó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún Ìgbìmọ̀ Ìṣèwéjáde, sọ bó ṣe sọ òtítọ́ di tirẹ̀ nígbà tó ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lórílẹ̀-èdè Kánádà. Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ni nígbà yẹn òun nìkan ló sì sábà máa ń dá ṣiṣẹ́. Nígbà tí wọ́n ní kí Arákùnrin Reinmueller sọ àwọn tó ràn án lọ́wọ́ jù lọ ní Bẹ́tẹ́lì, ó dárúkọ àwọn olùṣòtítọ́ mẹ́ta, ó sì ṣàlàyé bí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ṣe ran òun lọ́wọ́ láti mú kí àjọṣe òun pẹ̀lú Ọlọ́run sunwọ̀n sí i. Ìyàwó rẹ̀, Sarah, sọ nípa ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tó ní pẹ̀lú arábìnrin kan tó fara da ọ̀pọ̀ ọdún tó lò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n lórílẹ̀-èdè Ṣáínà nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀. Sarah sọ pé òun ti kọ́ láti máa gbára lé Jèhófà nípa gbígbàdúrà sí i.

Arákùnrin David Schafer, tó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún Ìgbìmọ̀ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́, fi hàn pé òun mọrírì rẹ̀ pé ìgbàgbọ́ màmá òun lágbára, ó sì tún sọ nípa àwọn arákùnrin tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ agégẹdú tí wọ́n ran òun lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ nígbà tóun wà lọ́dọ̀ọ́. Ìyàwó rẹ̀, Krista sọ bó ṣe mọrírì ipa rere táwọn tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì látìgbà tó ti pẹ́ ní lórí rẹ̀ torí pé wọ́n jẹ́ “olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó kéré jù lọ,” gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ.—Lúùkù 16:10.

Arákùnrin Robert Ciranko, tó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún Ìgbìmọ̀ Ìkọ̀wé rántí àwọn òbí rẹ̀ àgbà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí wọ́n lọ gbé nílùú Hungary tí wọ́n sì jẹ́ ẹni àmì òróró. Nígbà tó wà lọ́mọdé, ohun tó rí nígbà tó lọ sí àwọn àpéjọ ńláńlá tó wáyé láàárín ọdún 1950 sí ọdún 1959 wú u lórí, ó sì wá rí i pé kì í ṣe kìkì àwọn tó wà nínú ìjọ òun nìkan ló wà nínú ètò Jèhófà. Ketra, ìyàwó rẹ̀, sọ bóun ṣe kẹ́kọ̀ọ́ ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ adúróṣinṣin nígbà tóun ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nínú ìjọ kan táwọn apẹ̀yìndà wà tó sì tún ní ọ̀pọ̀ ìṣòro mìíràn. Ó fara dà á, nígbà tó sì yá wọ́n ní kó lọ sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe nínú ìjọ kan. Ìṣọ̀kan tó rí nínú ìjọ náà wú u lórí gan-an.

Lẹ́yìn náà ni Arákùnrin Manfred Tonak ròyìn nípa orílẹ̀-èdè Etiópíà. Orílẹ̀-èdè yìí ti wà nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn akéde tó ń wàásù ìhìn rere níbẹ̀ sì ti lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án [9,000] báyìí. Àwọn tó pọ̀ jù lọ nínú wọn ń gbé ní Addis Ababa tó jẹ́ olú ìlú náà tàbí nítòsí ibẹ̀. Torí náà, wọ́n ṣì nílò àwọn oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run láwọn ibi àdádó tó wà lórílẹ̀-èdè náà. Láti bójú tó àìní tó wà fún àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i yìí wọ́n ké sí àwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Etiópíà tí wọ́n ń gbé láwọn orílẹ̀-èdè mìíràn láti wá wàásù láwọn ibi àdádó kan lórílẹ̀-èdè náà. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló lọ síbẹ̀, wọ́n fún àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n bá níbẹ̀ níṣìírí, ọ̀pọ̀ èèyàn sì tẹ́tí sí ìwàásù wọn.

Ọ̀kan lára apá tó wọ àwọn ará lọ́kàn nípàdé náà ni àpínsọ àsọyé tó dá lórí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àti ìgbẹ́jọ́ tó wáyé lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè náà. Arákùnrin Aulis Bergdahl tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà sọ ìtàn nípa inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, pàápàá jù lọ ní Moscow tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè náà. Arákùnrin Philip Brumley tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Òfin ní ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ ọ̀rọ̀ tó ń múni lọ́kàn yọ̀ nípa bí ìgbẹ́jọ́ náà ṣe lọ sí lẹ́nu àìpẹ́ yìí nígbà tí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù gbọ́ ẹ̀sùn mẹ́sàn-án tí wọ́n fi kan àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀. Àwọn adájọ́ Ilé Ẹjọ́ náà fohùn ṣọ̀kan pé kò sí èyíkéyìí nínú àwọn ẹ̀sùn mẹ́sàn-án tí wọ́n fi kàn wá tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Kódà, àwọn ìgbà kan tiẹ̀ wà tí wọ́n ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ìdí tí àlàyé táwọn olùpẹ̀jọ́ ń ṣe nípa wa kò fi tọ̀nà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò tíì mọ bí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ náà ṣe máa nípa lórí iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, Arákùnrin Brumley sọ̀rọ̀ tó múni lọ́kàn lé nípa bí ìdájọ́ Ilé Ẹjọ́ náà ṣe máa nípa lórí àwọn ẹjọ́ tó bá wáyé láwọn ilẹ̀ mìíràn.

Lẹ́yìn ìròyìn tí ń múni lọ́kàn yọ̀ yìí, Arákùnrin Lett ṣèfilọ̀ pé Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù ti gbà láti ṣàyẹ̀wò ẹjọ́ tó wà láàárín ìjọba ilẹ̀ Faransé àti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú sísan owó orí. Díẹ̀ lára ẹjọ́ tí wọ́n bá gbé wá síwájú Ilé Ẹjọ́ táwọn èèyàn ní ọ̀wọ̀ gíga fún yìí ló máa ń gbà láti bójú tó. Títí di báyìí, àpapọ̀ ẹjọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí Ilé Ẹjọ́ náà ti gbé yẹ̀ wò jẹ́ mọ́kàndínlógójì [39], ó sì ti ṣèdájọ́ pé a jàre nínú mẹ́tàdínlógójì [37] lára àwọn ẹjọ́ náà. Arákùnrin Lett fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run níṣìírí pé kí wọ́n mú ọ̀ràn tó wà nílẹ̀ yìí tọ Jèhófà Ọlọ́run lọ nínú àdúrà.

Arákùnrin Richard Morlan, tó ń sìn ní pápá tó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà Ìjọ ló mú ìròyìn tó kẹ́yìn wá. Ó fìtara sọ̀rọ̀ nípa ilé ẹ̀kọ́ náà àti bí àwọn alàgbà tó ti wá síbẹ̀ ṣe fi ìmọrírì wọn hàn fún ilé ẹ̀kọ́ náà.

Àsọyé Míì Tí Àwọn Tó Jẹ́ Ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí Sọ

Arákùnrin Guy Pierce tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ àsọyé àtọkànwá tó dá lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2011, tó sọ pé: “Sá di orúkọ Jèhófà.” (Sef. 3:12) Ó sọ pé bí àwọn èèyàn Jèhófà tiẹ̀ ní ìdí láti máa yọ̀ lákòókò tá a wà yìí, ó tún yẹ ká fọwọ́ pàtàkì mú àkókò yìí ká sì máa ronú jinlẹ̀. Ọjọ́ ńlá Jèhófà ti sún mọ́lé; síbẹ̀ àwọn èèyàn ṣì ń wá ibi ìsádi lọ sọ́dọ̀ ìsìn èké, ètò òṣèlú, ọrọ̀, wíwá nǹkan tí wọ́n lè fi pàrònú rẹ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ká bàa lè rí ojúlówó ibi ìsádi, ó pọn dandan pé ká máa ké pe orúkọ Jèhófà, èyí tó gba pé ká mọ̀ ọ́n, ká ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún un, ká fọkàn tán Ẹni tó ni orúkọ náà, ká sì fi gbogbo ohun tá a ní fẹ́ràn rẹ̀.

Lẹ́yìn náà, Arákùnrin David Splane tóun náà jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ àsọyé tó ń múni ronú jinlẹ̀ tó ní àkòrí náà, “Ṣé O Ti Wọnú Ìsinmi Ọlọ́run?” Ó ṣàlàyé pé ìsinmi Ọlọ́run kò túmọ̀ sí pé ó ti dáwọ́ iṣẹ́ dúró, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ṣì “ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́” jálẹ̀ gbogbo ọjọ́ ìṣàpẹẹrẹ tó fi ń sinmi kí wọ́n bàa lè ṣe àṣeparí ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn nípa àwọn ohun tó dá sórí ilẹ̀ ayé. (Jòh. 5:17) Nígbà náà, báwo la ṣe lè wọnú ìsinmi Ọlọ́run? Lára ohun tó yẹ ká ṣe ni pé ká sá fún ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn ohun tó máa mú ká máa dá ara wa láre. A gbọ́dọ̀ máa lo ìgbàgbọ́, ká má ṣe gbàgbé ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe, ká sì máa sa gbogbo ipá wa láti ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ète rẹ̀. Nígbà mìíràn, ìyẹn lè jẹ́ ohun tó ṣòro gan-an fún wa láti ṣe, àmọ́ ó yẹ ká máa gba ìmọ̀ràn tí ètò Jèhófà bá fún wa ká sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú bí ètò náà ṣe ń darí wa. Arákùnrin Splane rọ gbogbo àwọn tó wà láwùjọ láti ṣe gbogbo ohun tó bá wà ní agbára wọn kí wọ́n lè wọnú ìsinmi Ọlọ́run.

Arákùnrin Anthony Morris tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló sọ àsọyé tó kádìí ìpàdé náà, àkòrí àsọyé náà ni, “Kí Là Ń Retí?” Ọ̀rọ̀ Arákùnrin Morris fi hàn pé a kò gbọ́dọ̀ jáfara, síbẹ̀ ó sọ ọ́ bí ìgbà tí bàbá ń bá ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Ó rán àwùjọ létí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣì máa nímùúṣẹ lọ́jọ́ iwájú, èyí tó jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ tí gbogbo àwọn olùṣòtítọ́ ń fi ìháragàgà wọ̀nà fún. Lára irú àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni igbe “Àlàáfíà àti ààbò!” àti ìparun ìsìn èké. (1 Tẹs. 5:2, 3; Ìṣí. 17:15-17) Arákùnrin Morris sọ pé àfi ká ṣọ́ra tá a bá gbọ́ ìròyìn nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú irú àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ká má lọ máa sọ pé, “Amágẹ́dọ́nì ti dé nìyẹn o.” Ó sọ pé ńṣe ló yẹ ká ní ẹ̀mí ìdúródeni irú èyí tí Míkà 7:7 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Irú ẹ̀mí ìdúródeni bẹ́ẹ̀ á mú ká máa láyọ̀ ká sì máa ṣe sùúrù. Bákan náà, ó tún rọ gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ pé kí wọ́n ṣera wọn lọ́kan pẹ̀lú Ìgbìmọ̀ Olùdarí, bí àwọn ọmọ ogun ṣe máa ń wà pa pọ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn bí wọ́n bá dé ibi tí ogun ti le. Ó ké sí àwọn tó wà láwùjọ pé, ‘ẹ jẹ́ kí ọkàn-àyà yín jẹ́ alágbára, gbogbo ẹ̀yin tẹ́ ẹ̀ ń dúró de Jèhófà.’—Sm. 31:24.

Ní àkótán, wọ́n ṣe àwọn ìfilọ̀ kan tó jẹ́ mánigbàgbé, tó sì ń múni lọ́kàn yọ̀. Arákùnrin Geoffrey Jackson tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣèfilọ̀ pé ètò ti wà nílẹ̀ láti dán ìṣètò tuntun kan wò. Ìyẹn ni títẹ ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tá a fi èdè Gẹ̀ẹ́sì tó rọrùn kọ torí àwọn tí kò lè fi bẹ́ẹ̀ ka èdè Gẹ̀ẹ́sì. Lẹ́yìn náà, Arákùnrin Stephen Lett ṣèfilọ̀ pé Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa ṣètò pé kí wọ́n máa ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ àwọn alábòójútó àgbègbè tí wọ́n wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àtàwọn ìyàwó wọn. Lẹ́yìn náà ló ṣèfilọ̀ pé orúkọ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ máa yí pa dà, àti pé ní báyìí Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Àpọ́n la ó máa pè é. Ilé ẹ̀kọ́ mìíràn tí wọ́n tún máa dá sílẹ̀ láfikún sí ìyẹn á máa jẹ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Tọkọtaya Tó Jẹ́ Kristẹni. Àwọn tọkọtaya á máa gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ yìí kí wọ́n lè túbọ̀ wúlò fún ètò Jèhófà. Arákùnrin Lett tún ṣèfilọ̀ pé ní báyìí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alábòójútó Arìnrìn-Àjò àti Àwọn Ìyàwó Wọn àti Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Tó Jẹ́ Ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka àti Àwọn Ìyàwó Wọn yóò máa wáyé lẹ́ẹ̀mejì lọ́dún ní Patterson. Àwọn tó ti wá sílé ẹ̀kọ́ náà tẹ́lẹ̀ sì tún máa láǹfààní láti lọ nígbà kejì.

Bí Arákùnrin John E. Barr tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún [97], tó sì ti ń sìn láti ọjọ́ pípẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣe fi àdúrà kádìí ìpàdé ọdọọdún náà tún jẹ́ apá tó wọni lọ́kàn. Ó fìrẹ̀lẹ̀ gbàdúrà náà, ó sì sọ̀rọ̀ látọkànwá. * Ní ìparí ìpàdé ọdọọdún náà, gbogbo àwọn tó pésẹ̀ síbẹ̀ gbà pé ọjọ́ mánigbàgbé ni ọjọ́ yẹn lóòótọ́.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Wo ìwé ọdọọdún wa, 2011 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ojú ìwé 62 sí 63.

^ Arákùnrin Barr parí iṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ní December 4, 2010.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 19]

Gbogbo àwọn tó wà láwùjọ gbádùn àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tó jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ mọ àwọn ará wa kan sí i

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 20]

Jèhófà ti rọ̀jò ìbùkún rẹ̀ sórí iṣẹ́ ìwàásù lórílẹ̀-èdè Etiópíà