Fi Ọgbọ́n Lo Íńtánẹ́ẹ̀tì
Fi Ọgbọ́n Lo Íńtánẹ́ẹ̀tì
LÁTÌGBÀ tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í fi ẹ̀rọ tẹ̀wé ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn ni ìyípadà ti dé bá ọ̀nà táwa èèyàn ń gbà bára wa sọ̀rọ̀. Àwọn kan ti fi ìyípadà yìí wé ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Íńtánẹ́ẹ̀tì wọlé dé. Àwọn kan pe Íńtánẹ́ẹ̀tì ní ẹ̀rọ ayé-lu-jára, bó sì ṣe rí nìyẹn. Béèyàn bá dórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ó lè rí onírúurú ìsọfúnni àti àkọsílẹ̀ oníṣirò, kó sì gbọ́ èrò àwọn èèyàn nípa ohun tó ń lọ.
Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ jẹ́ ẹ̀bùn àgbàyanu látọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá. Ẹ̀bùn yìí ló ń jẹ́ ká lè sọ èrò wa fáwọn ẹlòmíràn ká sì bá wọn fèrò wérò. Jèhófà ló kọ́kọ́ bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Ó ṣe àlàyé kedere tí kò ṣòro láti lóye fún wọn nípa bí wọ́n ṣe lè gbé ìgbé ayé to nítumọ̀. (Jẹ́n. 1:28-30) Àmọ́, bí ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá èèyàn ṣe fi hàn, ó ṣeé ṣe láti ṣi ẹ̀bùn tá a ní láti bá àwọn ẹlòmíì sọ̀rọ̀ lò. Kò sí òótọ́ kankan nínú ohun tí Sátánì sọ fún Éfà. Àmọ́, Éfà gba ohun tó sọ gbọ́, òun náà sọ fún Ádámù, Ádámù ṣe ohun tí aya rẹ̀ sọ fún un, ìyẹn ló sì fà á tí aráyé fi kó sínú ìyọnu.—Jẹ́n. 3:1-6; Róòmù 5:12.
Kí la lè sọ nípa lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè rí ìsọfúnni tó níye lórí gbà látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì, kó dín àkókò tá à ń lò kù, ká sì lò ó ní onírúurú ọ̀nà, síbẹ̀ ó tún lè fúnni ní ìsọfúnni tí kì í ṣòótọ́, kó gbà wá ní àkókò tó pọ̀, ó sì lè mú ká máa ṣe ohun tí kò tọ́. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè lo Íńtánẹ́ẹ̀tì lọ́nà tó máa ṣe wá láǹfààní.
Ṣé Òótọ́ Ni àbí Irọ́?
A kò gbọ́dọ̀ ronú pé gbogbo ohun tá a bá ti rí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ló dára tó sì ṣàǹfààní. Ńṣe ni àwọn ìkànnì Íńtánẹ́ẹ̀tì tá a fi lè wá ìsọfúnni dà bí agbo àwọn èèyàn tó ń ṣa olú kiri nínú igbó. Wọ́n ṣiṣẹ́ kára láti kó onírúurú olú jọ, èyí tó ṣeé jẹ àti èyí tó ní májèlé, wọ́n kó gbogbo rẹ̀ sínú abọ́ kan ṣoṣo, wọ́n sì gbé e fún wa láti jẹ. Ṣé wàá bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ àwọn olú náà láì kọ́kọ́ fara balẹ̀ yẹ̀ wọ́n wò níkọ̀ọ̀kan? Kò dájú pé wàá ṣe bẹ́ẹ̀! Àwọn ìkànnì Íńtánẹ́ẹ̀tì tá a fi lè wá ìsọfúnni máa ń lo ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ kọ̀ǹpútà láti ṣa àwọn ìsọfúnni jọ látinú ọ̀kẹ́ àìmọye ìkànnì. Lára àwọn ìsọfúnni wọ̀nyí dára gan-an àwọn míì sì burú jáì. Torí náà, a nílò ìfòyemọ̀ ká bàa lè mọ ìyàtọ̀ láàárín àwọn ìsọfúnni tó lè ṣe wá láǹfààní àti èyí tó lè pa wá lára kí àwọn ìsọfúnni tó dà bíi májèlé má bàa wọnú ọkàn wa.
Ní ọdún 1993 ìwé ìròyìn kan táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹní mowó gbé àwòrán ẹ̀fẹ̀ kan jáde, àwọn ajá méjì tó dúró síwájú kọ̀ǹpútà ló sì wà nínú àwòrán ẹ̀fẹ̀ náà. Ọ̀kan lára àwọn ajá náà wá sọ fún èkejì pé: “Bó o bá wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, kò sẹ́ni tó máa mọ̀ pé ajá ni ẹ́.” Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, Sátánì lo ejò láti bá Éfà sọ̀rọ̀ bí ìgbà téèyàn ń bá ẹlòmíì sọ̀rọ̀ lórí kọ̀ǹpútà, ó sì sọ fún un pé ó lè dà bí Ọlọ́run. Lónìí, ẹnikẹ́ni tó bá ní Íńtánẹ́ẹ̀tì lè purọ́ pé òun mọ tinú tòde ohun
kan, síbẹ̀ kó má sọ orúkọ ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni ló sì lè gbé èrò tirẹ̀, ìsọfúnni èyíkéyìí, àwòrán àti àbá tó bá wù ú síbẹ̀ torí kò sí òfin tó de irú nǹkan bẹ́ẹ̀.Bó o bá ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì má ṣe dà bí Éfà, tó gba gbogbo ohun tí Èṣù sọ fún un gbọ́ láìwádìí. Má máa tètè gba gbogbo ohun tó o bá rí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì gbọ́, máa fura sí i. Kó o tó gba ìsọfúnni èyíkéyìí gbọ́, béèrè pé: (1) Ta ló gbé ìsọfúnni náà síbẹ̀? Kí ni onítọ̀hún mọ̀ nípa ìsọfúnni tó gbé síbẹ̀? (2) Kí nìdí tí wọ́n fi gbé ìsọfúnni náà sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì? Kí ló mú kí onítọ̀hún kọ ohun tó kọ? Ṣé èrò tiẹ̀ ló ń gbé lárugẹ? (3) Ibo ni ẹni tó kọ ọ̀rọ̀ náà síbẹ̀ ti rí ohun tó kọ? Ṣó mẹ́nu kan àwọn ibi tá a ti lè ṣèwádìí nípa ohun tó kọ? (4) Ṣé ìsọfúnni náà bágbà mu? Ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún Tímótì ní ọ̀rúndún kìíní, wúlò fún wa lónìí pẹ̀lú. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Máa ṣọ́ ohun tí a tò jọ ní ìtọ́júpamọ́ sọ́dọ̀ rẹ, yẹra fún àwọn òfìfo ọ̀rọ̀ tí ó máa ń fi àìmọ́ ba ohun mímọ́ jẹ́ àti fún àwọn ìtakora ohun tí a fi èké pè ní ‘ìmọ̀.’”—1 Tím. 6:20.
Ṣé Ó Ń Dín Àkókò Kù Ni àbí Ó Ń Gbani Lákòókò?
Bá a bá ń fọgbọ́n lo Íńtánẹ́ẹ̀tì, ó dájú pé ó lè dín àkókò, okun àti owó tó yẹ ká lò kù. Ó máa ń mú kó rọrùn láti ra ọjà láì kúrò nílé. Ó tún máa ń mú kó rọrùn láti fi owó ọjà wéra, ìyẹn sì máa ń dínni lówó kù. Ó tiẹ̀ tún ti mú kí nǹkan dẹrùn fún ọ̀pọ̀ èèyàn torí pé láì kúrò nílé wọ́n lè ṣe ohun tí wọn ì bá ṣẹ̀ṣẹ̀ lọ ṣe ní báńkì lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì; gbogbo ọ̀ràn tó bá jẹ mọ́ owó lèèyàn sì lè bójú tó níbẹ̀. Íńtánẹ́ẹ̀tì tún lè mú kó rọrùn láti ṣètò ìrìn àjò kéèyàn sì ra tíkẹ́ẹ̀tì, èyí sì máa ń dín ìnáwó kù. Ó mú kó rọrùn láti ṣàwárí nọ́ńbà tẹlifóònù, àdírẹ́sì àti oríṣiríṣi ọ̀nà téèyàn lè gbà dé ibi tó ń lọ. Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé máa ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì láwọn ọ̀nà yìí láti dín iye àkókò, àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni àti owó tá à ń lò kù.
Àmọ́, àwọn ewu kan wà tó yẹ ká gbé yẹ̀ wò. Ó ní í ṣe pẹ̀lú bí àkókò tá à ń lò nídìí Íńtánẹ́ẹ̀tì ṣe pọ̀ tó. Dípò kó jẹ́ ohun tó wúlò fún àwọn kan, wọ́n ti sọ ọ́ di ohun ṣeréṣeré. Wọ́n máa ń lo àkókò tó pàpọ̀jù láti ṣeré lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, láti rajà, láti bá àwọn míì sọ̀rọ̀, láti fi lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà ránṣẹ́, láti ṣe ìwádìí, kí wọ́n sì máa ti orí ìkànnì kan lọ sí òmíràn. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í pa àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù tì, irú bí àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìdílé, àwọn ọ̀rẹ́ àti ìjọ. Kódà èèyàn lè sọ lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì di bárakú. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìsọfúnni kan tó jáde ní ọdún 2010, wọ́n fi ojú bù ú pé láàárín àwọn ọ̀dọ́ márùn-ún lórílẹ̀-èdè Kòríà, Íńtánẹ́ẹ̀tì ti di bárakú fún ẹyọ kan. Àwọn tó ṣe ìwádìí ní orílẹ̀-èdè Jámánì sọ pé, “àwọn obìnrin púpọ̀ sí i ń ṣàròyé nípa bí ọkọ wọn ṣe sọ Íńtánẹ́ẹ̀tì di bárakú.” Obìnrin kan ṣàròyé pé bí ọkọ òun ṣe sọ Íńtánẹ́ẹ̀tì di kòríkòsùn ti mú kí ìwà rẹ̀ ṣàdédé yí pa dà débi pé ó ti da ìgbéyàwó àwọn rú.
Ọ̀kan lára ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gba lẹ́tà kan látọ̀dọ̀ ẹnì kan tó sọ pé Íńtánẹ́ẹ̀tì ti di bárakú fún òun. Nígbà míì ó máa ń lò tó wákàtí mẹ́wàá lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì lóòjọ́. Lẹ́yìn tó sọ pé “ó kọ́kọ́ dà bíi pé kò sí ohun tó burú níbẹ̀,” ó wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Nígbà tó yá, mi ò lọ sí ìpàdé déédéé mọ́, mi ò sì gbàdúrà mọ́.” Bó bá lọ sí ìpàdé, kì í múra sílẹ̀, ilé lọkàn rẹ̀ máa ń wà, á sì máa wù ú pé “kó tún lọ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.” A dúpẹ́
pé ó wá rí i pé kì í ṣe ìṣòro kékeré ni èyí ti mú wá, ó sì gbé àwọn ìgbésẹ̀ tó jẹ́ kó lè ṣàtúnṣe. Ẹ má ṣe jẹ́ ká lo Íńtánẹ́ẹ̀tì débi tá a fi máa sọ ọ́ di bárakú.Ṣé Ìsọfúnni Náà Wúlò àbí Kò Wúlò?
Nínú 1 Tẹsalóníkà 5:21, 22, a kà pé: “Ẹ máa wádìí ohun gbogbo dájú; ẹ di ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ mú ṣinṣin. Ẹ ta kété sí gbogbo oríṣi ìwà burúkú.” A gbọ́dọ̀ pinnu bóyá ìsọfúnni tá à ń rí gbà látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì máa jẹ́ ká rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run, ká sì mọ̀ bóyá ó bá ìlànà gíga rẹ̀ mu. Kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ohun táwọn míì a máa kọminú sí, ó sì gbọ́dọ̀ bójú mu fún Kristẹni. Ó ti wá wọ́pọ̀ gan-an báyìí pé káwọn èèyàn máa wo àwọn ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, bá ò bá sì ṣọ́ra a lè kó sínú páńpẹ́ yìí.
Ó bọ́gbọ́n mu ká bi ara wa pé, ‘Ṣé màá fẹ́ láti yára fi ohun tí mò ń wò lójú kọ̀ǹpútà pa mọ́ fún ìyàwó mi tàbí ọkọ mi, àwọn òbí mi tàbí àwọn arákùnrin àti arábìnrin mi bí wọ́n bá wọnú yàrá?’ Bó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, ì bá dára ká máa lo Íńtánẹ́ẹ̀tì kìkì nígbà táwọn ẹlòmíì bá wà níbẹ̀. Kò sí àní-àní pé Íńtánẹ́ẹ̀tì ti yí ọ̀nà tá a gbà ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ àti bá a ṣe ń rajà pa dà. Bákan náà, ó ti ṣí ọ̀nà tuntun sílẹ̀ láti ‘ṣe panṣágà nínú ọkàn-àyà wa.’—Mát. 5:27, 28.
Bá A Ṣe Lè Pinnu Bóyá Ó Yẹ Ká Fi Ìsọfúnni Kan Ránṣẹ́ Tàbí Ká Má Fi Ránṣẹ́
Ó ṣeé ṣe láti gba ìsọfúnni lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ó sì ṣeé ṣe láti máa pín in kiri. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a lómìnira láti gba ìsọfúnni ká sì fi ránṣẹ́ sí àwọn míì, ó tún yẹ ká mọ̀ pé ojúṣe wa ni láti wádìí bóyá òótọ́ ni àti bóyá kò ní ìṣekúṣe nínú. Ǹjẹ́ a lè fọwọ́ sọ̀yà pé òótọ́ ni ohun tá a kọ tàbí fi ránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíì? Ṣé a lẹ́tọ̀ọ́ láti fi irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ ránṣẹ́? * Ṣé ìsọfúnni náà wúlò, ṣé ó sì ń gbéni ró? Torí kí la ṣe fẹ́ fi í ránṣẹ́? Àbí torí ká bàa lè gbayì lójú àwọn míì la ṣe fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀?
Bí a bá lo lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà bó ṣe yẹ, ó lè ṣe wá láǹfààní. Ó sì tún lè jẹ́ ká rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsọfúnni gbà. Ṣé kì í ṣe pé à ń fi àkókò tí ọ̀pọ̀ àwọn ojúlùmọ̀ wa ì bá lò fún àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì ṣòfò nípa fifi àwọn ìsọfúnni rẹpẹtẹ ránṣẹ́ láti sọ ohun tó ń lọ lóde tàbí àwọn ohun tí kò ṣe pàtàkì fún wọn? Ṣé kò yẹ ká ronú nípa ìdí tá a fi fẹ́ fi ìsọfúnni kan ránṣẹ́ ká tó fi ránṣẹ́? Kí la fẹ́ kí ìsọfúnni náà ṣe gan-an? Tẹ́lẹ̀rí àwọn èèyàn máa ń kọ lẹ́tà sí tẹbí tọ̀rẹ́ nípa ara wọn láti jẹ́ kí wọ́n mọ bí nǹkan ṣe ń lọ sí. Ṣé irú àwọn ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ náà kọ́ ló yẹ kó máa wà nínú àwọn lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà tá a bá kọ ni? Kí nìdí tá a ó fi máa fi ohun tí kò dá wa lójú ránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn?
Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló wá yẹ ká ṣe nípa Íńtánẹ́ẹ̀tì? Ṣé ká má lò ó mọ́ rárá ni? Nígbà míì, ó lè jẹ́ pé ohun tó yẹ ká ṣe nìyẹn. Ohun tí ẹni tó sọ lẹ́ẹ̀kan pé òun ti sọ Íńtánẹ́ẹ̀tì di bárakú ṣe nìyẹn kó bàa lè borí ìṣòro tó ti ní fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àǹfààní wà nínú lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn bá a bá jẹ́ kí ‘agbára láti ronú máa ṣọ́ wa, kí ìfòyemọ̀ sì máa fi ìṣọ́ ṣọ́ wa.’—Òwe 2:10, 11.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Ohun kan náà la lè sọ nípa àwọn fọ́tò tá a lè gbé sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè ya fọ́tò fún ìlò tara wa, a lè máà lẹ́tọ̀ọ́ láti pín wọn kiri bó ṣe wù wá, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ pé ká sọ orúkọ àwọn tó wà nínú fọ́tò náà àti ibi tí wọ́n ń gbé fáwọn ẹlòmíì.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Kí lo lè ṣe tí o kò fi ní gba ìsọfúnni tí kì í ṣòótọ́ láyè?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Kí ló yẹ kó o rò kó o tó fi ìsọfúnni èyíkéyìí ránṣẹ́?