Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà, “Ọlọ́run Tí Ń fúnni Ní Àlàáfíà”

Jèhófà, “Ọlọ́run Tí Ń fúnni Ní Àlàáfíà”

Jèhófà, “Ọlọ́run Tí Ń fúnni Ní Àlàáfíà”

“Kí Ọlọ́run tí ń fúnni ní àlàáfíà wà pẹ̀lú gbogbo yín.”—RÓÒMÙ 15:33.

1, 2. Kí ni Ìwé Mímọ́ sọ pé ó ṣẹlẹ̀ nínú Jẹ́nẹ́sísì orí 32 àti 33, kí sì ni àbájáde rẹ̀?

 ÌLÚ kan tí kò jìn sí Pénúélì, lẹ́bàá àfonífojì ọ̀gbàrá Jábókù, ní ìlà oòrùn odò Jọ́dánì ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé. Ísọ̀ ti gbọ́ pé Jékọ́bù tó jẹ́ ìbejì rẹ̀ ń pa dà bọ̀ wálé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé láti ogún ọdún sẹ́yìn ni Ísọ̀ ti ta ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí fún Jékọ́bù, ẹ̀rù ń bà á pé Ísọ̀ ṣì lè máa di òun sínú kó sì fẹ́ pa òun. Ísọ̀ àti àwọn irínwó [400] ọkùnrin tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ gbéra láti lọ pàdé Jékọ́bù tó ti kúrò nílé láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Jékọ́bù ronú pé Ísọ̀ lè fẹ́ gbéjà ko òun, torí náà ó fi ọ̀pọ̀ ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí Ísọ̀. Gbogbo ẹran ọ̀sìn tó fi ránṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta lé àádọ́ta [550]. Bí àwọn ìránṣẹ́ tí Jékọ́bù rán ṣíwájú yìí ṣe ń fi àwọn ẹran ọ̀sìn náà jíṣẹ́ fún Ísọ̀ ni wọ́n ń sọ fún un pé wọ́n jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ arákùnrin rẹ̀.

2 Nígbà tó yá àwọn méjèèjì fojú kanra! Bí Jékọ́bù ṣe ń fi ìgboyà lọ pàdé Ísọ̀ bẹ́ẹ̀ ló ń tẹrí ba. Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ títí tó fi tẹrí ba ní ìgbà méje. Ṣáájú èyí, Jékọ́bù ti gbé ìgbésẹ̀ tó ṣe pàtàkì kó bàa lè pẹ̀tù sọ́kàn arákùnrin rẹ̀. Ó ti gbàdúrà sí Jèhófà pé kó gba òun lọ́wọ́ Ísọ̀. Ǹjẹ́ Jèhófà dáhùn àdúrà rẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni. Bíbélì sọ fún wa pé: “Ísọ̀ . . . sáré lọ pàdé rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbá a mọ́ra, ó sì gbórí lé e lọ́rùn, ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu.”—Jẹ́n. 32:11-20; 33:1-4.

3. Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín Jékọ́bù àti Ísọ̀?

3 Ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín Jékọ́bù àti Ísọ̀ fi hàn pé bí ìṣòro bá wáyé nínú ìjọ, èyí tó lè ba àlàáfíà tó wà láàárín wa jẹ́, a gbọ́dọ̀ máa gbé ìgbésẹ̀ tó bá yẹ ká lè tètè yanjú ìṣòro náà. Kì í ṣe torí pé Jékọ́bù ṣẹ Ísọ̀ tàbí pé ó yẹ kó tọrọ àforíjì lọ́wọ́ rẹ̀ ló ṣe ń wá àlàáfíà pẹ̀lú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ kọ́ lọ̀rọ̀ rí, Ísọ̀ fúnra rẹ̀ ló tẹ́ńbẹ́lú ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí, tó sì tà á fún Jékọ́bù fún abọ́ ọbẹ̀ kan ṣoṣo. (Jẹ́n. 25:31-34; Héb. 12:16) Àmọ́, ohun tí Jékọ́bù ṣe nígbà tó lọ pàdé Ísọ̀ jẹ́ ká rí bó ṣe yẹ ká fínnú fíndọ̀ ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe ká máa bàa fàyè gba ohunkóhun láti ba àlàáfíà tó wà láàárín àwa àtàwọn ará wa jẹ́. Ó tún fi hàn pé tá a bá gbàdúrà sí Ọlọ́run òtítọ́ pé kó ràn wá lọ́wọ́ láti máa wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, ó máa jẹ́ kí ìsapá wa yọrí sí rere. Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ mìíràn tó kọ́ wa báa ṣe lè máa wá àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn wà nínú Bíbélì.

Àpẹẹrẹ Tó Dára Jù Lọ Tó Yẹ Ká Tẹ̀ Lé

4. Ètò wo ni Ọlọ́run ti ṣe kó lè gba aráyé lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú?

4 Jèhófà, “Ọlọ́run tí ń fúnni ní àlàáfíà” ni àpẹẹrẹ tó ta yọ jù lọ tó yẹ ká tẹ̀ lé ní ti bó ṣe yẹ ká máa wá àlàáfíà. (Róòmù 15:33) Ronú nípa gbogbo ohun tí Jèhófà ṣe ká bàa lè wà ní àlàáfíà pẹ̀lú rẹ̀. Torí pé a jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà, a máa ń dẹ́ṣẹ̀, “owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san” sì tọ́ sí wa. (Róòmù 6:23) Síbẹ̀, torí pé Jèhófà fẹ́ràn wa lọ́pọ̀lọpọ̀, tó sì fẹ́ ká rí ìgbàlà, ó rán àyànfẹ́ Ọmọ rẹ̀ wá sórí ilẹ̀ ayé, ẹni tá a bí gẹ́gẹ́ bí ẹni pípé. Ọmọ náà fínnúfíndọ̀ ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Ó gbà káwọn ọ̀tá Ọlọ́run pa òun. (Jòh. 10:17, 18) Ọlọ́run òtítọ́ jí àyànfẹ́ Ọmọ rẹ̀ dìde, lẹ́yìn náà ni òun pẹ̀lú fún Baba rẹ̀ ní ìtóye ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tó fi rúbọ gẹ́gẹ́ bí ìràpadà tó máa gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ikú ayérayé.—Ka Hébérù 9:14, 24.

5, 6. Báwo ni ẹ̀jẹ̀ tí Jésù fi rúbọ ṣe mú kí àárín Ọlọ́run àti aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀ pa dà gún?

5 Báwo ni ẹbọ ìràpadà tí Ọlọ́run pèsè nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ ṣe mú kí àárín Ọlọ́run àti aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀ pa dà gún? Ìwé Aísáyà 53:5 sọ pé: “Ìnàlẹ́gba tí a pète fún àlàáfíà wa ń bẹ lára rẹ̀, àti nítorí àwọn ọgbẹ́ rẹ̀ ni ìmúniláradá fi wà fún wa.” Dípò tí Ọlọ́run ì bá fi kà wá sí ọ̀tá rẹ̀, ó ti ṣeé ṣe báyìí fún aráyé onígbọràn láti wà ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run. “Nípasẹ̀ [Jésù] àwa ní ìtúsílẹ̀ nípa ìràpadà nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ ẹni yẹn, bẹ́ẹ̀ ni, ìdáríjì àwọn àṣemáṣe wa.”—Éfé. 1:7.

6 Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run rí i pé ó dára pé kí ẹ̀kún gbogbo máa gbé inú [Kristi].” Ìdí ni pé ọ̀kan pàtàkì ni Kristi jẹ́ nínú ohun tí Ọlọ́run lò láti mú ète rẹ̀ ṣẹ. Kí sì ni ète Jèhófà? Ète rẹ̀ ni láti “mú gbogbo ohun mìíràn padà rẹ́ pẹ̀lú ara rẹ̀ nípa mímú àlàáfíà wá nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀” tí Jésù Kristi fi rúbọ. “Gbogbo ohun mìíràn” tí Ọlọ́run mú kó wà ní àlàáfíà pẹ̀lú ara rẹ̀ ni “àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run” àti “àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé.” Kí ni àwọn ohun wọ̀nyí?—Ka Kólósè 1:19, 20.

7. Kí ni “àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run” àti “àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé” tí Ọlọ́run mú kí wọ́n wà ní àlàáfíà pẹ̀lú òun?

7 Ẹbọ ìràpadà tí Ọlọ́run pèsè mú kó ṣeé ṣe fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, tí ‘a ti polongo ní olódodo’ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Ọlọ́run, láti “máa gbádùn àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run.” (Ka Róòmù 5:1.) Bíbélì pè wọ́n ní “àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run” torí pé wọ́n ní ìrètí láti lọ sí ọ̀rún “wọn yóò . . . ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí” wọn yóò sì tún sìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà fún Ọlọ́run. (Ìṣí. 5:10) “Àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé” ni àwọn ẹ̀dá èèyàn tí wọ́n ronú pìwà dà, tí wọ́n sì ń fojú sọ́nà fún gbígbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé.—Sm. 37:29.

8. Báwo ni ríronú lórí gbogbo ohun tí Jèhófà ṣe láti mú kí aráyé wà ní àlàáfíà pẹ̀lú rẹ̀ ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́?

8 Nínú ìwé tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà ní Éfésù, ó fi hàn pé tọkàntọkàn lòun fi mọyì ìpèsè Jèhófà yìí. Ó sọ pé: “Ọlọ́run, ẹni tí ó jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú àánú, . . . sọ wá di ààyè pa pọ̀ pẹ̀lú Kristi, àní nígbà tí a ti kú nínú àwọn àṣemáṣe—nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí a ti gbà yín là.” (Éfé. 2:4, 5) Yálà a ní ìrètí ti òkè ọ̀run tàbí ti ilẹ̀ ayé, a mọyì àánú àti inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Ọlọ́run fi hàn sí wa gan-an ni. Tá a bá ń ronú lórí gbogbo ohun tí Jèhófà ṣe kó bàa lè ṣeé ṣe fún aráyé láti wà ní àlàáfíà pẹ̀lú rẹ̀, ọkàn wa á máa kún fún ọpẹ́. Bí ohunkóhun bá sì ṣẹlẹ̀ tó lè ba àlàáfíà àti ìṣọ̀kan ìjọ jẹ́, ǹjẹ́ kò yẹ kí ìmọrírì sún wa láti ronú lórí àpẹẹrẹ tí Ọlọ́run fi lélẹ̀, ká sì máa wá àlàáfíà?

A Rí Ẹ̀kọ́ Kọ́ Látinú Àpẹẹrẹ Ábúráhámù àti Ísákì

9, 10. Báwo ni Ábúráhámù ṣe fi hàn pé òun jẹ́ ẹni tó ń wá àlàáfíà nínú ọ̀nà tó gbà bójú tó awuyewuye tó wáyé láàárín àwọn darandaran Lọ́ọ̀tì àtàwọn darandaran tirẹ̀?

9 Bíbélì sọ nípa baba ńlá náà, Ábúráhámù pé: “‘Ábúráhámù ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, a sì kà á sí òdodo fún un,’ ó sì di ẹni tí a ń pè ní ‘ọ̀rẹ́ Jèhófà.’” (Ják. 2:23) Bí Ábúráhámù ṣe máa ń wá àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn mú kó ṣe kedere pé ó ní ìgbàgbọ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí agbo ẹran Ábúráhámù bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i, awuyewuye wáyé láàárín àwọn darandaran rẹ̀ àti àwọn darandaran Lọ́ọ̀tì, tó jẹ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀. (Jẹ́n. 12:5; 13:7) Ó ṣe kedere pé ohun tó lè yanjú ọ̀ràn náà ni pé kí Ábúráhámù àti Lọ́ọ̀tì pínyà. Báwo ni Ábúráhámù ṣe máa bójú tó ọ̀ràn tó lè dá wàhálà sílẹ̀ yìí? Dípò kí Ábúráhámù pinnu fún Lọ́ọ̀tì torí pé ó jù ú lọ àti nítorí pé ó jẹ́ ẹni iyì lójú Ọlọ́run, ńṣe ló fi hàn pé lóòótọ́ lòun ń wá àlàáfíà.

10 Ábúráhámù sọ fún Lọ́ọ̀tì pé: “Jọ̀wọ́, má ṣe jẹ́ kí aáwọ̀ máa bá a lọ láàárín èmi àti ìwọ àti láàárín àwọn olùṣọ́ agbo ẹran mi àti àwọn olùṣọ́ agbo ẹran rẹ, nítorí arákùnrin ni wá.” Ábúráhámù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Gbogbo ilẹ̀ kò ha wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ? Jọ̀wọ́, yà sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi. Bí ìwọ bá lọ sí apá òsì, nígbà náà, èmi yóò lọ sí apá ọ̀tún; ṣùgbọ́n bí ìwọ bá lọ sí apá ọ̀tún, nígbà náà, èmi yóò lọ sí apá òsì.” Apá ibi tí ilẹ̀ tó lọ́ràá jù lọ wà ni Lọ́ọ̀tì mú, síbẹ̀ Ábúráhámù kò torí ìyẹn dì í sínú. (Jẹ́n. 13:8-11) Ìdí tá a sì fi mọ̀ bẹ́ẹ̀ ni pé nígbà kan tí àwọn ọmọ ogun wá mú Lọ́ọ̀tì lẹ́rú, Ábúráhámù kò lọ́ra láti gbà á sílẹ̀.—Jẹ́n. 14:14-16.

11. Báwo ni Ábúráhámù ṣe wá àlàáfíà pẹ̀lú àwọn Filísínì tí wọ́n jẹ́ aládùúgbò rẹ̀?

11 Tún ronú nípa bí Ábúráhámù ṣe wá àlàáfíà pẹ̀lú àwọn Filísínì tí wọ́n jẹ́ aládùúgbò rẹ̀ ní ilẹ̀ Kénáánì. Àwọn Filísínì ‘fi ipá gba’ kànga omi kan tí àwọn ìránṣẹ́ Ábúráhámù gbẹ́ sí Bíá-ṣébà. Ọ̀nà wo ni Ábúráhámù tó borí àwọn ọba mẹ́rin tí wọ́n wá mú Lọ́ọ̀tì, ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lẹ́rú, máa gbà bójú tó ọ̀ràn yìí? Dípò kí Ábúráhámù jà kó bàa lè gba kànga rẹ̀ pa dà, kò sọ ohunkóhun nípa ọ̀ràn náà. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, ọba àwọn Filísínì tọ Ábúráhámù lọ kó lè ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú rẹ̀. Lẹ́yìn tí ọba náà ti mú kí Ábúráhámù búra fún òun pé òun á fi inú rere bá ọba náà àtàwọn ọmọ rẹ̀ lò ni Ábúráhámù tó dá ọ̀rọ̀ kànga tí àwọn Filísínì fi ipá gbà náà sílẹ̀. Ó ya ọba náà lẹ́nu láti gbọ́ bẹ́ẹ̀, ó sì dá kànga náà pa dà fún Ábúráhámù. Ní ti Ábúráhámù, ó ń bá a nìṣó láti máa gbé ní àlàáfíà gẹ́gẹ́ bí àtìpó ní ilẹ̀ náà.—Jẹ́n. 21:22-31, 34.

12, 13. (a) Báwo ni Ísákì ṣe tẹ̀ lé àpẹẹrẹ bàbá rẹ̀? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe bù kún Ísákì torí pé ó fẹ́ láti máa wá àlàáfíà?

12 Ísákì tó jẹ́ ọmọ Ábúráhámù tẹ̀ lé àpẹẹrẹ bàbá rẹ̀ ní ti pé ó fẹ́ láti máa wá àlàáfíà. Èyí ṣe kedere nínú bí Ísákì ṣe bá àwọn Filísínì lò. Torí ìyàn tó wáyé ní ilẹ̀ náà, Ísákì kó àwọn tó wà nínú agbo ilé rẹ̀ kúrò ní àríwá Bia-laháí-róì ní ẹkùn ilẹ̀ Négébù gbígbẹ táútáú lọ sí àgbègbè àwọn ará Filísínì ní Gérárì tó jẹ́ ilẹ̀ tó túbọ̀ lẹ́tù lójú. Jèhófà bù kún Ísákì gan-an níbẹ̀, ó jẹ́ kí ohun ọ̀gbìn rẹ̀ pọ̀ wọ̀ǹtìwọnti kí àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ sì bí sí i. Bí àwọn Filísínì ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìlara rẹ̀ nìyẹn. Wọn kò fẹ́ kí Ísákì láásìkí bíi ti bàbá rẹ̀ Ábúráhámù, torí náà wọ́n dí àwọn kànga tí àwọn ìránṣẹ́ Ábúráhámù ti gbẹ́ sí ẹkùn ilẹ̀ náà. Níkẹyìn, ọba àwọn Filísínì sọ fún Ísákì pé kó ‘ṣí kúrò ní àdúgbò wọn.’ Torí pé èèyàn àlàáfíà ni Ísákì ó kúrò níbẹ̀.—Jẹ́n. 24:62; 26:1, 12-17.

13 Lẹ́yìn tí Ísákì ti ibẹ̀ kúrò láti lọ pàgọ́ sí ibòmíràn tó jìnnà, àwọn darandaran rẹ̀ tún gbẹ́ kànga mìíràn. Àwọn darandaran tó jẹ́ ará Filísínì sọ pé àwọn làwọn ni kànga náà. Àmọ́, bíi ti Ábúráhámù bàbá rẹ̀, Ísákì kò bá wọn jà nítorí kànga náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó tún ní kí àwọn ìránṣẹ́ òun gbẹ́ kànga míì. Àwọn Filísínì tún sọ pé àwọn làwọn ni kànga náà. Nítorí àtipa àlàáfíà mọ́, Ísákì tún fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ sí ibòmíràn. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gbẹ́ kànga míì tí Ísákì pè ní Réhóbótì. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́ ó lọ sí ẹkùn-ilẹ̀ Bíá-ṣébà tí ilẹ̀ ti túbọ̀ lẹ́tù lójú. Jèhófà bù kún un níbẹ̀, ó sì sọ fún un pé: “Má fòyà, nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì bù kún ọ, èmi yóò sì sọ irú-ọmọ rẹ di púpọ̀ ní tìtorí Ábúráhámù ìránṣẹ́ mi.”—Jẹ́n. 26:17-25.

14. Nígbà tí ọba àwọn Filísínì fẹ́ láti bá Ísákì ṣe àdéhùn àlàáfíà, báwo ni Ísákì ṣe fi hàn pé òun jẹ́ ẹni tó ń wá àlàáfíà?

14 Kò sí àní-àní pé Ísákì lágbára láti jà fún ẹ̀tọ́ tó ní láti lo gbogbo kànga tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gbẹ́. Ó ṣe tán, ọba àwọn Filísínì àtàwọn ìjòyè rẹ̀ ti lọ bá a ní Bíá-ṣébà pé kó bá àwọn ṣe àdéhùn àlàáfíà. Wọ́n sọ fún un pé: “A ti rí i láìsí àní-àní pé Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ.” Síbẹ̀, kí àlàáfíà lè jọba, Ísákì yàn láti kó kúrò láti ibì kan lọ sí ibòmíì nígbà tó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ dípò kó bá wọn jà. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tún jẹ́ ká rí i pé Ísákì jẹ́ ẹni tó ń wá àlàáfíà. Ìtàn náà sọ pé: “Ó se àsè fún [àwọn àlejò rẹ̀], wọ́n jẹ, wọ́n mu. Ní òwúrọ̀ [ọjọ́] kejì, wọ́n tètè dìde, wọ́n sì sọ gbólóhùn ìbúra, ẹnì kìíní fún ẹnì kejì. Lẹ́yìn ìyẹn, Ísákì rán wọn lọ . . . ní àlàáfíà.”—Jẹ́n. 26:26-31.

A Rí Ẹ̀kọ́ Kọ́ Lára Ọmọ Tí Jékọ́bù Fẹ́ràn Jù Lọ

15. Kí nìdí tí àwọn arákùnrin Jósẹ́fù kò fi lè bá a sọ̀rọ̀ lọ́nà àlàáfíà?

15 Jékọ́bù ọmọ Ísákì dàgbà di “ọkùnrin aláìlẹ́gàn.” (Jẹ́n. 25:27) Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, Jékọ́bù wá àlàáfíà pẹ̀lú Ísọ̀, arákùnrin rẹ̀. Ó dájú pé Jékọ́bù kẹ́kọ̀ọ́ látinú àpẹẹrẹ bàbá rẹ̀ Ísákì tó máa ń wá àlàáfíà. Àwọn ọmọ Jékọ́bù wá ńkọ́, kí la lè sọ nípa wọn? Nínu àwọn ọmọ méjìlá tí Jékọ́bù bí, Jósẹ́fù ló fẹ́ràn jù lọ. Jósẹ́fù jẹ́ onígbọràn ọmọ tó máa ń fọ̀wọ̀ hàn, ó sì jẹ́ ẹni tí bàbá rẹ̀ lè fọkàn tán. (Jẹ́n. 37:2, 14) Àmọ́, àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù bẹ̀rẹ̀ sí í jowú rẹ̀, wọn kò sì lè bá a sọ̀rọ̀ lọ́nà àlàáfíà. Wọ́n kórìíra rẹ̀ débi pé wọ́n tà á lẹ́rú, wọ́n sì tan bàbá wọn kó lè gbà gbọ́ pé ẹranko ẹhànnà kan ló pa Jósẹ́fù jẹ.—Jẹ́n. 37:4, 28, 31-33.

16, 17. Báwo ni Jósẹ́fù ṣe jẹ́ kó ṣe kedere sí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ pé òun fẹ́ láti máa wá àlàáfíà?

16 Jèhófà wà pẹ̀lú Jósẹ́fù. Nígbà tó ṣe, Jósẹ́fù di olórí ìjọba ilẹ̀ Íjíbítì, ìyẹn igbá kejì Fáráò. Nígbà tí àwọn arákùnrin Jósẹ́fù wá sí Íjíbítì nítorí ìyàn kan tó lágbára, wọn kò dá a mọ̀ nínú ẹ̀wù oyè ilẹ̀ Íjíbítì tó wọ̀. (Jẹ́n. 42:5-7) Ẹ wo bí ì bá ti rọrùn tó fún Jósẹ́fù láti gbẹ̀san ìwà òǹrorò táwọn arákùnrin rẹ̀ hù sí i àti sí bàbá wọn! Àmọ́, dípò kí Jósẹ́fù gbẹ̀san, ńṣe ló gbìyànjú láti wá àlàáfíà pẹ̀lú wọn. Nígbà tó rí i dájú pé àwọn arákùnrin òun ti ronú pìwà dà, ó sọ ara rẹ̀ di mímọ̀ fún wọn. Ó ní: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí inú yín bàjẹ́, ẹ má sì ṣe bínú sí ara yín nítorí pé ẹ tà mí síhìn-ín; nítorí àtipa ìwàláàyè mọ́ ni Ọlọ́run fi rán mi ṣáájú yín.” Lẹ́yìn náà ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi ẹnu ko gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ lẹ́nu, ó sì ń sunkún bó ṣe ń gbé orí lé wọn lọ́rùn.—Jẹ́n. 45:1, 5, 15.

17 Lẹ́yìn ikú bàbá wọn, Jékọ́bù, àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù rò pé ó ṣì lè gbẹ̀san lára àwọn. Nígbà tí wọ́n sọ ohun tó ń bà wọ́n lẹ́rù fún Jósẹ́fù, ńṣe ló “bú sẹ́kún” ó sì dá wọn lóhùn pé: “Ẹ má fòyà. Èmi fúnra mi yóò máa pèsè oúnjẹ fún ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín kéékèèké.” Bí Jósẹ́fù tó máa ń wá àlàáfíà ṣe “tù wọ́n nínú, [tí] ó sì bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà ìfinilọ́kànbalẹ̀” nìyẹn.—Jẹ́n. 50:15-21.

‘A Kọ Wọ́n fún Ìtọ́ni Wa’

18, 19. (a) Ṣé o ti jàǹfààní látinú àpẹẹrẹ àwọn tó ń wá àlàáfíà tá a ti jírorò nínú àpilẹ̀kọ yìí? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

18 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.” (Róòmù 15:4) Àwọn àǹfààní wo la ti rí nínú ṣíṣe àgbéyẹ̀wò àpẹẹrẹ títayọ jù lọ tí Jèhófà fi lélẹ̀ àti ìtàn tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa Ábúráhámù, Ísákì, Jékọ́bù àti Jósẹ́fù?

19 Tá a bá mọrírì ohun tí Jèhófà ti ṣe, tí èyí sì ń mú ká ronú lórí bó ṣe mú kí àárín òun àti aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀ pa dà gún, ǹjẹ́ kò yẹ kí ìyẹn sún wa láti máa ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe ká lè máa wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì? Àpẹẹrẹ Ábúráhámù, Ísákì, Jékọ́bù àti Jósẹ́fù fi hàn pé àpẹẹrẹ rere àwọn òbí lè mú káwọn ọmọ wọn máa wá àlàáfíà. Ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa wọn tún fi hàn pé Jèhófà máa ń bù kún ìsapá àwọn tó bá ń gbìyànjú láti wá àlàáfíà. Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi pe Jèhófà ní “Ọlọ́run tí ń fúnni ní àlàáfíà”! (Ka Róòmù 15:33; 16:20.) Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò ìdí tí Pọ́ọ̀lù fi tẹnu mọ́ ọn pé ká máa lépa àlàáfíà àti bá a ṣe lè jẹ́ èèyàn àlàáfíà.

Ẹ̀kọ́ Wo Lo Kọ́?

• Báwo ni Jékọ́bù ṣe fi hàn pé òun ń wá àlàáfíà nígbà tó fẹ́ lọ pàdé Ísọ̀?

• Báwo ni ohun tí Jèhófà ṣe kí àárín òun àti aráyé lè gún ṣe lè mú kó o máa wá àlàáfíà?

• Kí lo rí kọ́ látinú bí Ábúráhámù, Ísákì, Jékọ́bù àti Jósẹ́fù ṣe wá àlàáfíà?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Kí ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ tí Jékọ́bù ṣe kó lè wá àlàáfíà pẹ̀lú Ísọ̀?