Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ṣó o ti fara balẹ̀ ka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

• Àwọn ohun mẹ́ta wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ tí a kò fi ní fẹ́ láti hùwà àìṣòótọ́?

Àwọn ohun tó lè ràn wá lọ́wọ́ rèé: (1) Ní ìbẹ̀rù tó tọ́ fún Ọlọ́run. (1 Pét. 3:12) (2) Ní ẹ̀rí ọkàn tá a fi Bíbélì kọ́. (3) Sa gbogbo ipá rẹ kó o lè máa ní ìtẹ́lọ́rùn.—4/15, ojú ìwé 6 sí 7.

• Báwo la ṣe mọ̀ pé fífi ọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìsìn wa kò túmọ̀ sí pé kí ojú wa máa le koko ní gbogbo ìgbà tàbí ká má lè bá àwọn èèyàn ṣeré tó gbádùn mọ́ni?

A lè ronú lórí àpẹẹrẹ Jésù. Ó máa ń wá àkókò láti sinmi kó sì bá àwọn ẹlòmíì jẹun. A mọ̀ pé kì í fọwọ́ líle mú nǹkan kì í sì í ṣe òǹrorò. Ara máa ń tu àwọn míì, títí kan àwọn ọmọdé láti wà pẹ̀lú rẹ̀.—4/15, ojú ìwé 10.

• Kí ni tọkọtaya lè ṣe bí àárín wọn kò bá fi bẹ́ẹ̀ dán mọ́rán mọ́ lẹ́yìn tí wọ́n ti bímọ?

Ó yẹ kí wọ́n fi hàn pé wọ́n ṣì nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Ọkọ lè sapá láti máa ṣe ohun tí kò ní mú kí aya rò pé kò fẹ́ràn òun. Ó sì yẹ káwọn méjèèjì máa bára wọn sọ̀rọ̀ nípa bí nǹkan ṣe rí lára wọn àti àwọn ohun tí wọ́n nílò nípa tara.—5/1, ojú ìwé 12 sí 13.

• Kí ni igi ólífì tí Róòmù orí 11 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ dúró fún?

Igi ólífì náà ní í ṣe pẹ̀lú àwọn tó jẹ́ apá kejì lára irú-ọmọ Ábúráhámù, ìyẹn Ísírẹ́lì tẹ̀mí. Jèhófà dà bíi gbòǹgbò igi náà, ìtí igi ólífì ìṣàpẹẹrẹ náà sì dúró fún Jésù. Nígbà tí ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn Júù nípa tara kọ Jésù sílẹ̀, ó ṣeé ṣe láti lọ́ àwọn Kèfèrí tí wọ́n di onígbàgbọ́ sára igi ólífì náà, nípa báyìí ó ṣeé ṣe láti pèsè ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iye àwọn tó jẹ́ apá kejì lára irú-ọmọ Ábúráhámù.—5/15, ojú ìwé 22 sí 25.

• Ìhìn rere wo ní pàtàkì la lè wàásù rẹ̀ fáwọn òtòṣì?

Ìhìn rere náà ni pe: Ọlọ́run ti yan Jésù láti jẹ́ Ọba. Jésù ni alákòóso tó dára jù lọ tó máa fòpin sí ipò òṣì. Kí nìdí? Ìdí ni pé òun ló máa ṣàkóso gbogbo aráyé, ó sì ní agbára láti ṣe ohun tó bá yẹ; ó fi ìyọ́nú hàn sí àwọn òtòṣì; ó sì lè mú ohun tó ń fa ipò òṣì kúrò, ìyẹn ìmọtara-ẹni-nìkan tá a jogún.—6/1, ojú ìwé 7.

• Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ fún Káyáfà pé: “Ìwọ fúnra rẹ wí i”?—Mát. 26:63, 64.

Àkànlò èdè táwọn Júù sábà máa ń lò ni ọ̀rọ̀ náà, “ìwọ fúnra rẹ wí i,” wọ́n sì máa ń lò ó láti fi hàn pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. Káyáfà tó jẹ́ àlùfáà àgbà ti ní kí Jésù sọ ní gbangba tó bá jẹ́ pé òun ni Kristi, Ọmọ Ọlọ́run. Bí Jésù ṣe fèsì pé: “Ìwọ fúnra rẹ wí i” fi hàn pé bẹ́ẹ̀ ni ni ìdáhùn rẹ̀ sí ìbéèrè Káyáfà.—6/1, ojú ìwé 18.

• Ǹjẹ́ àwọn àtọmọdọ́mọ tí Jésù tó jẹ́ ẹni pípé lè bí jẹ́ apá kan ìràpadà náà?

Rárá o. Òótọ́ ni pé Jésù tó jẹ́ ẹni pípé lè bí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àtọmọdọ́mọ tí wọ́n jẹ́ ẹni pípé, àmọ́ irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ kì í ṣe apá kan ìràpadà náà. Ìwàláàyè pípé ti Jésù nìkan ṣoṣo ló ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ìwàláàyè pípé ti Ádámù. (1 Tím. 2:6)—6/15, ojú ìwé 13.

• Báwo làwọn Kristẹni ṣe lè fi hàn pé àwọn fi ìkìlọ̀ nípa àwọn olùkọ́ èké, èyí tó wà nínú Ìṣe 20:29, 30, sọ́kàn?

Wọn kì í jẹ́ kí àwọn olùkọ́ èké wá sínú ilé wọn, wọn kì í sì í kí wọn. (Róòmù 16:17; 2 Jòh. 9-11) Àwọn Kristẹni kì í ka ìwé àwọn apẹ̀yìndà, wọn kì í wo ètò orí tẹlifíṣọ̀n tó ń gbé wọn sáfẹ́fẹ́, wọn kì í sì í lọ síbi tí àwọn ẹ̀kọ́ wọn wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.—7/15, ojú ìwé 15 sí 16.

• Ta ló yẹ kó kọ́ àwọn ọmọ nípa Ọlọ́run?

Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Bíbélì sọ, bàbá àti ìyá ló yẹ kí wọ́n jọ máa kọ́ àwọn ọmọ. (Òwe 1:8; Éfé. 6:4) Ìwádìí fi hàn pé bí bàbá àti ìyá bá jọ tọ́mọ, ó máa ń ṣe àwọn ọmọ ní àǹfààní tó pọ̀.—8/1, ojú ìwé 6 sí 7.