Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Jèhófà Mọ̀ Ẹ́?

Ṣé Jèhófà Mọ̀ Ẹ́?

Ṣé Jèhófà Mọ̀ Ẹ́?

“Jèhófà mọ àwọn tí í ṣe tirẹ̀.”—2 TÍM. 2:19.

1, 2. (a) Kí ni Jésù kà sí pàtàkì? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká ronú lé lórí?

 NÍ ỌJỌ́ kan, Farisí kan tọ Jésù lọ, ó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Èwo ni àṣẹ títóbi jù lọ nínú Òfin?” Jésù dá a lóhùn pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.” (Mát. 22:35-37) Jésù nífẹ̀ẹ́ Baba rẹ̀ ọ̀run gan-an ni, ó sì gbé ìgbésí ayé rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ yẹn. Ohun míì tí Jésù tún kà sí pàtàkì ni àjọṣe tó ní pẹ̀lú Jèhófà, ó sì fi hàn pé òun kà á sí pàtàkì nípa jíjẹ́ olóòótọ́ jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. Torí náà, nígbà tó kù díẹ̀ kí Jésù kú, ó sọ pé Ọlọ́run mọ òun gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń fìgbàgbọ́ ṣègbọràn sí àwọn òfin Rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ó dúró nínú ìfẹ́ Jèhófà.—Jòh. 15:10.

2 Lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Ó dájú pé àwa náà máa ń sọ bẹ́ẹ̀. Àmọ́, àwọn ìbéèrè pàtàkì kan wà tó yẹ ká ronú lé lórí. Irú bíi, ‘Ǹjẹ́ Ọlọ́run mọ̀ mí? Ojú wo ni Jèhófà fi ń wò mí? Ǹjẹ́ àwọn èèyàn tiẹ̀ mọ̀ pé ti Jèhófà ni mo jẹ́?’ (2 Tím. 2:19) Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún wa láti máa ronú pé a lè ní irú àjọṣe tímọ́tímọ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run!

3. Kí nìdí táwọn kan fi máa ń kọminú pé bóyá làwọn lè ní àjọṣe pẹ̀lú Jèhófà, báwo ni wọ́n sì ṣe lè dẹ́kun ríronú lọ́nà yẹn?

3 Síbẹ̀, ó máa ń ṣòro fún àwọn kan tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an láti gbà pé Ọlọ́run lè mọ àwọn kó sì tún ka àwọn sí ọ̀rẹ́ rẹ̀. Àwọn kan máa ń rò pé àwọn kò já mọ́ nǹkan kan, torí náà ó máa ń kọ wọ́n lóminú pé bóyá ni àwọn lè ní àjọṣe pẹ̀lú Jèhófà. Àmọ́, ẹ wo bó ṣe yẹ kó dùn mọ́ wa tó pé ojú tí Ọlọ́run fi ń wò wá yàtọ̀ síyẹn! (1 Sám. 16:7) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ẹni yìí ni ó mọ̀.” (1 Kọ́r. 8:3) Ó ṣe pàtàkì pé kó o nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run bó o bá fẹ́ kí Jèhófà mọ̀ ẹ́. Ronú lórí ìbéèrè yìí ná: Kí nìdí tó o fi ń ka ìwé ìròyìn yìí? Kí nìdí tó o fi ń sapá láti sin Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà, ọkàn, èrò inú àti okun rẹ? Bó o bá ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Ọlọ́run tó o sì ti ṣèrìbọmi, kí ló mú kó o ṣe bẹ́ẹ̀? Bíbélì ṣàlàyé pé Jèhófà tó máa ń ṣàyẹ̀wò ọkàn-àyà máa ń fa àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀. (Ka Hágáì 2:7; Jòhánù 6:44.) Torí náà, o lè gbà pé ìdí tó o fi ń sin Jèhófà ni pé, òun ló fà ẹ́ sọ́dọ̀ ara rẹ̀. Kò ní fi àwọn tó ti fà sọ́dọ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀ láé bí wọ́n bá ń bá a nìṣó gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́. Wọ́n ṣeyebíye lójú Ọlọ́run, ó sì fẹ́ràn wọn gan-an.—Sm. 94:14.

4. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó láti ronú jinlẹ̀ lórí mímọ̀ tí Ọlọ́run mọ̀ wá?

4 Bí Jèhófà bá ti fà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ohun tó yẹ ká kà sí pàtàkì ni bá a ṣe máa dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀. (Ka Júúdà 20, 21.) Rántí pé Bíbélì sọ pé ó ṣeé ṣe kéèyàn sú lọ tàbí kó fi Ọlọ́run sílẹ̀. (Héb. 2:1; 3:12, 13) Bí àpẹẹrẹ, kó tó di pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú 2 Tímótì 2:19, ló ti mẹ́nu kan Híméníọ́sì àti Fílétọ́sì. Ó dájú pé àwọn ọkùnrin méjì yẹn ti fìgbà kan rí jẹ́ ti Jèhófà, àmọ́ nígbà tó ṣe, wọ́n yà bàrà kúrò nínú òtítọ́. (2 Tím. 2:16-18) Rántí pẹ̀lú pé nínú ìjọ àwọn ará Gálátíà, àwọn kan tí Ọlọ́run ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ kò dúró nínú ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ tí wọ́n ti wà nínú rẹ̀ nígbà kan rí. (Gál. 4:9) Ǹjẹ́ kí a má ṣe fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àjọṣe ṣíṣeyebíye tá a ní pẹ̀lú Ọlọ́run.

5. (a) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ànímọ́ tí Ọlọ́run kà sí pàtàkì? (b) Àwọn àpẹẹrẹ wo la máa gbé yẹ̀ wò?

5 Àwọn ànímọ́ kan wà tí Jèhófà kà sí pàtàkì gan-an. (Sm. 15:1-5; 1 Pét. 3:4) Àwọn kan tí Ọlọ́run mọ̀ ní ìgbàgbọ́ àti ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tó tayọ. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ àwọn ọkùnrin méjì kan yẹ̀ wò ká lè rí bí àwọn ànímọ́ yìí ṣe mú kí Jèhófà kà wọ́n sí ẹni ọ̀wọ́n. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin kan tó rò pé Ọlọ́run mọ òun àmọ́ tó di agbéraga tó sì wá ṣe kedere sí i pé Jèhófà ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀. A lè rí ẹ̀kọ́ pàtàkì kọ́ látinú àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí.

Baba Àwọn Tí Wọ́n Ní Ìgbàgbọ́

6. (a) Ìgbàgbọ́ wo ni Ábúráhámù ní nínú àwọn ìlérí Jèhófà? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe mọ Ábúráhámù?

6 Ábúráhámù “ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà.” Kódà, Bíbélì pè é ní “baba gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́.” (Jẹ́n. 15:6; Róòmù 4:11) Ìgbàgbọ́ tí Ábúráhámù ní mú kó fi ilé, àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn ohun ìní rẹ̀ sílẹ̀ láti lọ sí ilẹ̀ tó jìnnà réré. (Jẹ́n. 12:1-4; Héb. 11:8-10) Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, ìgbàgbọ́ Ábúráhámù kò tíì yingin. A mọ̀ bẹ́ẹ̀ torí pé ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ fi ọmọkùnrin rẹ̀ “Ísákì rúbọ tán” kó bàa lè ṣègbọràn sí àṣẹ tí Ọlọ́run pa fún un. (Héb. 11:17-19) Ábúráhámù ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Jèhófà, torí náà Ọlọ́run kà á sí ẹni pàtàkì; tó fi hàn pé ó mọ Ábúráhámù dáadáa. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 18:19.) Kì í ṣe pé Jèhófà mọ̀ pé ẹnì kan wà tó ń jẹ́ Ábúráhámù nìkan ni; ó tún nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ béèyàn ṣe ń nífẹ̀ẹ́ ọ̀rẹ́ ẹni.—Ják. 2:22, 23.

7. Kí ló gbàfiyèsí nípa bí Jèhófà ṣe mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ipa wo lèyí sì ní lórí Ábúráhámù?

7 Ó gbàfiyèsí pé Ábúráhámù kò rí ilẹ̀ tí Ọlọ́run ṣèlérí pé ó máa di tirẹ̀ gbà nígbà tó ṣì wà láàyè. Bẹ́ẹ̀ sì ni irú-ọmọ rẹ̀ kò dà “bí àwọn egunrín iyanrìn tí ó wà ní etíkun” níṣojú rẹ̀. (Jẹ́n. 22:17, 18) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìlérí wọ̀nyí kò ní ìmúṣẹ nígbà tí Ábúráhámù wà láyé, ìgbàgbọ́ tó ní nínú Jèhófà kò yingin. Ó mọ̀ pé bí Ọlọ́run bá ti ṣèlérí ohun kan, ohun náà ti di ṣíṣe nìyẹn. Ó ṣe kedere pé Ábúráhámù gbé ìgbé ayé rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó gbà gbọ́. (Ka Hébérù 11:13.) Ǹjẹ́ Jèhófà mọ̀ wá sí ẹni tó ní ìgbàgbọ́ bíi ti Ábúráhámù?

Fi Hàn Pé O Ní Ìgbàgbọ́ Nípa Fífọkàn Tán Jèhófà

8. Àwọn ohun yíyẹ wo làwọn kan lè ti máa retí pé kó ṣẹlẹ̀?

8 Ó lè ti pẹ́ tá a ti ń retí pé káwọn ohun kan ṣẹlẹ̀. Ìgbéyàwó, ọmọ bíbí àti ìlera tó dáa wà lára ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń fẹ́, kò sì burú. Àmọ́, ọ̀pọ̀ lára wa lè máà rí ju ẹyọ kan lọ lára àwọn ohun tá à ń fẹ́ yìí. Bí ọ̀ràn wa bá rí bẹ́ẹ̀, ohun tá a bá ṣe nípa rẹ̀ ló máa fi hàn bí ìgbàgbọ́ tá a ní ṣe pọ̀ tó.

9, 10. (a) Kí làwọn kan ń ṣe kọ́wọ́ wọn bàa lè tẹ ohun tí wọ́n ń fẹ́? (b) Ojú wo lo fi ń wo ìmúṣẹ àwọn ìlérí Ọlọ́run?

9 Ẹ wo bó ṣe jẹ́ ìwà òmùgọ̀ tó pé kéèyàn máa wá bí ọwọ́ rẹ̀ á ṣe tẹ ohun tó ń fẹ́ lọ́nà tí kò bá ọgbọ́n Ọlọ́run mu. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ máa ba àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan ti yàn láti gba ìtọ́jú tí kò bá ìtọ́ni Jèhófà mu. Àwọn mìíràn ti gba iṣẹ́ tí kì í jẹ́ kí wọ́n wà pẹ̀lú ìdílé wọn tàbí kí wọ́n ráyè lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ. Tàbí, tó bá di pé ọkàn èèyàn ń fà sí aláìgbàgbọ́ ńkọ́? Bí Kristẹni kan bá ṣe irú nǹkan báwọ̀nyí, ṣé a lè sọ lóòótọ́ pé ó fẹ́ kí Jèhófà mọ òun? Ojú wo ni Jèhófà ì bá fi wo Ábúráhámù ká sọ pé kò ní sùúrù káwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún un ní ìmúṣẹ? Ká ní Ábúráhámù ti yàn láti ṣe ìfẹ́ inú ara rẹ̀ ńkọ́, tó ń gbé níbi tó wù ú, tó sì sọ ara rẹ̀ di olókìkí èèyàn dípò kó fọkàn tán Jèhófà? (Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 11:4.) Ṣé Jèhófà á ṣì máa bá a lọ láti fi ojú rere wò ó?

10 Àwọn nǹkan wo ló ń wù ẹ́ gan-an? Ṣé ìgbàgbọ́ tó o ní lágbára débi pé wàá lè fọkàn tán Jèhófà, tó ṣèlérí pé gbogbo ohun yíyẹ tá a bá fẹ́ lòun máa ṣe fún wa? (Sm. 145:16) Bó ṣe rí nínú ọ̀ràn ti Ábúráhámù, ìgbà tí àwọn kan lára ìlérí tí Ọlọ́run ṣe máa ní ìmúṣẹ lè yàtọ̀ sí ìgbà tá a ní lọ́kàn. Síbẹ̀, Jèhófà máa mọyì rẹ̀ tá a bá ní ìgbàgbọ́ bíi ti Ábúráhámù, tá a sì ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ náà máa darí wa láti ṣe ohun tó tọ́. Ó dájú pé ìyẹn máa ṣe wá láǹfààní tó pọ̀ gan-an ni.—Héb. 11:6.

Ìyàtọ̀ Tó Wà Láàárín Ìrẹ̀lẹ̀ àti Ìgbéraga

11. Àwọn àǹfààní wo ló ṣeé ṣe kí Kórà ti ní, kí nìyẹn sì mú kó ṣe kedere nípa ìwà tó hù sí Ọlọ́run?

11 Ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ ló wà nínú ọ̀nà tí Mósè àti Kórà gbà fi ọ̀wọ̀ hàn fún ìṣètò Jèhófà àtàwọn ìpinnu rẹ̀. Ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ṣe nípa lórí ojú tí Jèhófà fi wò wọ́n. Ọmọ Kóhátì ni Kórà, ó wá látinú ẹ̀yà Léfì, ó sì ní ọ̀pọ̀ àǹfààní. Ó ṣeé ṣe kó wà lára àwọn tó fojú rí bí Ọlọ́run ṣe mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì la Òkun Pupa kọjá, kó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó mú ìdájọ́ Jèhófà ṣẹ lòdì sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n ṣàìgbọràn níbi Òkè Sínáì, kí wọ́n sì yanṣẹ́ fún un láti máa gbé àpótí májẹ̀mú. (Ẹ́kís. 32:26-29; Núm. 3:30, 31) Ó dájú pé ó ti ní láti jẹ́ olùṣòtítọ́ sí Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún kí ìyẹn sì ti mú kí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé nínú àgọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa fọ̀wọ̀ wọ̀ ọ́.

12. Bá a ṣe fi hàn nínú àwòrán tó wà lójú ìwé 28, báwo ni ìgbéraga ṣe nípa lórí irú ẹni tí Ọlọ́run mọ Kórà sí?

12 Láìka gbogbo àǹfààní tí Kórà ní yìí sí, nígbà tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì wà lójú ọ̀nà Ilẹ̀ Ìlérí, Kórà bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé ó dà bíi pé ohun kan kò tọ̀nà nípa ètò tí Ọlọ́run ṣe. Lẹ́yìn náà, àwọn àádọ́ta-lé-nígba [250] ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ aṣáájú láàárín àwọn èèyàn náà dara pọ̀ mọ́ Kórà wọ́n sì gbìyànjú láti yí ìṣètò Ọlọ́run pa dà. Ọkàn Kórà àti àwọn yòókù ti ní láti balẹ̀ pé àwọn ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Wọ́n sọ fún Mósè pé: “Ó tó gẹ́ẹ́ yín, nítorí pé gbogbo àpéjọ ni ó jẹ́ mímọ́ ní àtòkèdélẹ̀ wọn, Jèhófà sì wà ní àárín wọn.” (Núm. 16:1-3) Ìwà ìgbéraga tó fi hàn pé wọ́n ti dára wọn lójú jù mà nìyẹn o! Mósè sọ fún wọn pé: “Jèhófà yóò sọ ẹni tí ó jẹ́ tirẹ̀ di mímọ̀.” (Ka Númérì 16:5.) Kí ilẹ̀ ọjọ́ kejì tó ṣú, Kórà àti gbogbo àwọn tó gbè sẹ́yìn rẹ̀ nínú ìwà ọ̀tẹ̀ náà ti kú.—Núm. 16:31-35.

13, 14. Àwọn ọ̀nà wo ni Mósè gbà fi ìwà ìrẹ̀lẹ̀ hàn?

13 Ìwà tí Mósè hù yàtọ̀ sí ti Kórà. Mósè “fi gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ jẹ́ ọlọ́kàn tútù jù lọ nínú gbogbo ènìyàn tí ó wà ní orí ilẹ̀.” (Núm. 12:3) Ó fi hàn pé òun jẹ́ oníwà-tútù àti onírẹ̀lẹ̀ torí pé ó pinnu láti tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí Jèhófà fún un. (Ẹ́kís. 7:6; 40:16) Kò sí ohun tó fi hàn pé ńṣe ni Mósè ń kọminú ṣáá nípa ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ṣe nǹkan tàbí kó máa bínú nítorí pé ó gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àwọn ìlànà tí Jèhófà gbé kalẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà pàṣẹ fún un nípa bí wọ́n ṣe máa kọ́ àgọ́ ìjọsìn, ó sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe fún un, tó fi mọ́ àwọ̀ àwọn òwú àgọ́ àti iye àwọn ihò kóróbójó tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe sí àwọn aṣọ àgọ́ náà. (Ẹ́kís. 26:1-6) Bí ẹnì kan tó jẹ́ alábòójútó nínú ètò Ọlọ́run bá fún ẹ ní ìtọ́ni tó dà bíi pé kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀ ti pọ̀ jù, ìyẹn lè mú kí nǹkan tojú sú ẹ nígbà míì. Àmọ́, alábòójútó tó jẹ́ ẹni pípé ni Jèhófà, ó máa ń fa iṣẹ́ lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ ní fàlàlà, ó sì máa ń gbẹ̀rí wọn jẹ́. Bó bá ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé fún wọn, ìdí rere ní láti wà tó fi ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ṣá o, má ṣe gbàgbé pé nígbà tí Jèhófà fún Mósè ní kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé, inú kò bí Mósè, kó wá máa rò pé ńṣe ni Jèhófà ń tẹ òun mẹ́rẹ̀ tàbí pé kò jẹ́ kóun lo ìdánúṣe tàbí òmìnira tí òun ní. Kàkà bẹ́ẹ̀, Mósè rí i dájú pé àwọn òṣìṣẹ́ náà “ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́,” nípa títẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún wọn. (Ẹ́kís. 39:32) Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Mósè mà pọ̀ o! Mósè mọ̀ pé ti Jèhófà ni iṣẹ́ náà, ó sì mọ̀ pé ńṣe ló wulẹ̀ lo òun láti rí i pé iṣẹ́ náà di ṣíṣe.

14 Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Mósè tún fara hàn nígbà tó bá ara rẹ̀ nínú àwọn ipò tí kò bára dé, tí ìwà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì hù sì mú inú bí i. Nígbà kan, Mósè kò lo ìkóra-ẹni-níjàánu ó sì kùnà láti ya orúkọ Ọlọ́run sí mímọ́ nígbà tó ń wá ohun tó máa ṣe sí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń ráhùn. Látàrí èyí, Jèhófà sọ fún Mósè pé òun kọ́ ló máa kó àwọn èèyàn náà dé Ilẹ̀ Ìlérí. (Núm. 20:2-12) Òun àti Áárónì, arákùnrin rẹ̀ ti fara da ìráhùn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àmọ́, nítorí àṣìṣe kan ṣoṣo tí Mósè ṣe yẹn, ọwọ́ rẹ̀ kò ní lè tẹ ohun tó ti ń wá láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn! Kí ni Mósè ṣe? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹlẹ́ran ara ó ká a lára, síbẹ̀ ìwà ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ mú kó fara mọ́ ìpinnu Jèhófà. Ó mọ̀ pé Ọlọ́run òdodo ni Jèhófà, kò sì sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀. (Diu. 3:25-27; 32:4) Bó o bá ń ronú nípa Mósè, ǹjẹ́ o kì í gbà pé ó jẹ́ ẹni tí Jèhófà mọ̀?—Ka Ẹ́kísódù 33:12, 13.

A Kò Lè Tẹrí Bá fún Jèhófà Bí A Kò Bá Níwà Ìrẹ̀lẹ̀

15. Kí la lè rí kọ́ nínú ìwà ìgbéraga Kórà?

15 Yálà Jèhófà máa mọ̀ wá tàbí kò ní mọ̀ wá tún sinmi lórí ojú tá a bá fi ń wo àwọn àtúnṣe tó bá wáyé nínú ìjọ Kristẹni kárí ayé àtàwọn ìpinnu tí àwọn tó ń múpò iwájú nínú rẹ̀ bá ṣe. Kórà àtàwọn ìsọ̀ǹgbè rẹ̀ sọ ara wọn di àjèjì sí Ọlọ́run torí pé wọ́n ti dá ara wọn lójú jù, wọ́n gbéra ga, wọn kò sì ní ìgbàgbọ́ mọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lójú Kórà, Mósè tó ti darúgbó ló ń ṣe ìpinnu fún orílẹ̀-èdè náà láti ọjọ́ dé ọjọ́, òótọ́ tó wà níbẹ̀ ni pé Jèhófà ló ń darí orílẹ̀-èdè náà. Kórà kùnà láti fi ojú tó tọ́ wo ọ̀ràn náà, nípa bẹ́ẹ̀, kò kọ́wọ́ ti àwọn tí Ọlọ́run ń lò. Ẹ wò bí ì bá ṣe bọ́gbọ́n mu tó pé kí Kórà ní ìgbọ́kànlé nínú Jèhófà títí tó fi máa túbọ̀ lóye ohun tó ń ṣẹlẹ̀ tàbí títí tí Ọlọ́run fi máa ṣe àtúnṣe èyíkéyìí, bó bá pọn dandan. Ọ̀rọ̀ Kórà kò yọrí sí ibi tó dáa, ńṣe ló fi ìgbéraga ba gbogbo ohun rere tó ti fi ìṣòtítọ́ ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run jẹ́!

16. Bá a bá fẹ́ kí Jèhófà mọ̀ wá, báwo ni títẹ̀ lé àpẹẹrẹ Mósè ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?

16 Lónìí, ìkìlọ̀ tó lágbára ni ìtàn yìí jẹ́ fún àwọn alàgbà àtàwọn míì nínú ìjọ. Ó gba pé kéèyàn jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ kó tó lè ní ìgbọ́kànlé nínú Jèhófà kó sì tẹ̀ lé ìtọ́ni tó ń pèsè nípasẹ̀ àwọn tó ń mú ipò iwájú. Ṣé a máa ń fi hàn pé a jẹ́ oníwà ìrẹ̀lẹ̀ àti ọlọ́kàn-tútù bíi ti Mósè? Ṣé a lè fi hàn pé a fara mọ́ iṣẹ́ táwọn tó ń múpò iwájú láàárín wa ń ṣe ká sì máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí wọ́n ń fún wa? Bí nǹkan ò bá lọ bá a ṣe fẹ́, ǹjẹ́ a lè fi ojú tó yàtọ̀ wo ọ̀rọ̀ náà dípò tá a ó fi bínú? Bá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé Jèhófà máa mọ àwa náà sí rere. Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ àti ìtẹríba wa máa mú kó kà wá sí ẹni ọ̀wọ́n.

Jèhófà Mọ Àwọn Tó Jẹ́ Tirẹ̀

17, 18. Kí ló lè mú ká máa bá a nìṣó láti jẹ́ ti Jèhófà?

17 Àǹfààní púpọ̀ ló wà nínú rẹ̀ tá a bá ronú lórí àwọn tí Jèhófà ń fà wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tó sì mọ̀ sí rere. Aláìpé bíi tiwa ni Ábúráhámù àti Mósè, àwọn náà sì ṣe àṣìṣe. Síbẹ̀ Jèhófà mọ̀ pé tòun ni wọ́n jẹ́. Àmọ́, àpẹẹrẹ ti Kórà jẹ́ ká rí i pé ó ṣeé ṣe fún wa láti lọ kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà ká má sì jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́. Ó dára kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bi ara rẹ̀ pé: ‘Ojú wo ni Jèhófà fi ń wò mí? Kí ni mo lè rí kọ́ látinú àwọn àpẹẹrẹ inú Ìwé Mímọ́ yìí?’

18 O lè rí ìtùnú ńláǹlà bó o bá mọ̀ pé Jèhófà ka àwọn olùṣòtítọ́ tó ti fà mọ́ra sí tirẹ̀. Máa bá a nìṣó láti ní ìgbàgbọ́, ìrẹ̀lẹ̀ àtàwọn ànímọ́ mìíràn tó máa jẹ́ kó o túbọ̀ jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n sí Ọlọ́run wa. Láìsí àní-àní, dídi ẹni tí Jèhófà mọ̀ jẹ́ àǹfààní iyebíye tó ń mú kéèyàn gbé ìgbé ayé tó tuni lára nísinsìnyí, ó sì tún máa mú kéèyàn láǹfààní láti gbádùn ìbùkún àgbàyanu lọ́jọ́ iwájú.—Sm. 37:18.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Báwo lo ṣe lè ní àjọṣe tó ṣeyebíye pẹ̀lú Jèhófà?

• Báwo lo ṣe lè fara wé ìgbàgbọ́ Ábúráhámù?

• Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ lára Kórà àti Mósè?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Bíi ti Ábúráhámù, ǹjẹ́ àwa náà ní ìgbàgbọ́ pé Jèhófà máa mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ pátápátá?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Kórà kò ṣe tán láti fìrẹ̀lẹ̀ tẹ̀ lé ìtọ́ni

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Ṣé Jèhófà mọ̀ ẹ́ sí ẹni tó ń fi ìrẹ̀lẹ̀ tẹ̀ lé ìtọ́ni?