Ẹ Fi Ìfaradà Sá Eré Ìje Náà
Ẹ Fi Ìfaradà Sá Eré Ìje Náà
“Ẹ . . . jẹ́ kí a fi ìfaradà sá eré ìje tí a gbé ka iwájú wa.”—HÉB. 12:1.
1, 2. Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ìgbésí ayé àwọn Kristẹni tòótọ́ wé?
Ọ̀PỌ̀ ibi làwọn èèyàn ti máa ń sáré ìje ẹlẹ́mìí ẹṣin lọ́dọọdún. Ohun kan ṣoṣo ló máa ń wà lọ́kàn àwọn táyé mọ̀ sí ọ̀gá nínú eré sísá, ìyẹn ni pé kí wọ́n borí. Ọ̀pọ̀ àwọn míì tó ń sá irú eré ìje bẹ́ẹ̀ kì í fi dandan lé e pé káwọn borí. Ní tiwọn, ohun tí wọ́n kà sí àṣeyọrí ni kí wọ́n ṣáà ti sáré ìje náà dópin.
2 Bíbélì fi ìgbésí ayé àwọn Kristẹni tòótọ́ wé eré ìje. Nínú lẹ́tà àkọ́kọ́ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn Kristẹni bíi tirẹ̀ tí wọ́n wà ní ìlú Kọ́ríńtì ìgbàanì, ó pe àfiyèsí wọn sí kókó yìí. Ó sọ pé: “Ẹ kò ha mọ̀ pé gbogbo àwọn sárésáré nínú eré ìje ní ń sáré, ṣùgbọ́n ẹnì kan ṣoṣo ní ń gba ẹ̀bùn náà? Ẹ sáré ní irúfẹ́ ọ̀nà bẹ́ẹ̀ kí ọwọ́ yín lè tẹ̀ ẹ́.”—1 Kọ́r. 9:24.
3. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé sárésáré kan ṣoṣo ló máa ń borí nínú eré ìje?
3 Ṣé ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni pé ẹnì kan ṣoṣo lára àwọn Kristẹni yẹn ló máa jèrè ẹ̀bùn ìyè àti pé ńṣe làwọn tó kù wulẹ̀ ń sáré lásán? Rárá o! Àwọn sárésáré tó bá ń kópa nínú eré sísá máa ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ wọ́n sì máa ń tiraka tokuntokun kí wọ́n bàa lè borí. Pọ́ọ̀lù fẹ́ kí àwọn Kristẹni bíi tirẹ̀ máa tiraka ní irú ọ̀nà yẹn bí wọ́n ti ń wọ̀nà fún jíjogún ìyè àìnípẹ̀kun. Bí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n lè retí láti jèrè ẹ̀bùn ìyè. Torí náà, nínú eré ìje tí àwọn Kristẹni ń sá, gbogbo ẹni tó bá sá eré náà dópin ló máa gba èrè náà.
4. Kí ló yẹ ká gbé yẹ̀ wò nípa eré ìje tá a gbé ka iwájú wa?
4 Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ń fúnni ní ìṣírí gan-an, síbẹ̀ lọ́kàn àwọn tó ń sáré ìje ìyè lónìí, ọ̀rọ̀ náà tún gba àròjinlẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé èrè tí àwọn tó ń retí ìyè yálà ní ọ̀run tàbí nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé máa rí gbà kò láfiwé. Òótọ́ ni pé eré ìje náà gùn ó sì gba ìsapá gan-an; ọ̀pọ̀ ohun tó lè ṣèdíwọ́, tó lè pín ọkàn ẹni níyà, tó sì léwu, ló wà lójú ọ̀nà. (Mát. 7:13, 14) Ó ṣeni láàánú pé àwọn kan ti bẹ̀rẹ̀ sí í dẹ̀rìn, wọ́n ti juwọ́ sílẹ̀, tàbí kí wọ́n tiẹ̀ ti ṣubú lójú ọ̀nà. Àwọn ọ̀fìn àti ewu wo la lè bá pàdé bá a ti ń sáré ìje ìyè? Báwo lo ṣe lè yẹra fún wọn? Kí lo lè ṣe kó o bàa lè sáré náà dópin kó o sì tipa bẹ́ẹ̀ borí?
A Nílò Ìfaradà Ká Bàa Lè Borí
5. Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Hébérù 12:1, kí ni Pọ́ọ̀lù sọ nípa eré ìje?
5 Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù tí wọ́n wà ní Jerúsálẹ́mù àti Jùdíà, ó tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ nínú eré ìdárayá tàbí eré ìje. (Ka Hébérù 12:1.) Kì í wulẹ̀ ṣe pé ó pe àfiyèsí sí ìdí téèyàn fi lè kópa nínú eré ìje náà nìkan ni, àmọ́ ó tún ṣàlàyé ohun téèyàn gbọ́dọ̀ ṣe kó tó lè borí. Ká tó ṣàgbéyẹ̀wò ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti fún àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù ká lè mọ ẹ̀kọ́ tá a máa rí kọ́ níbẹ̀, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ lórí ohun tó mú kí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà náà àti ohun tó ń gba àwọn tó kọ̀wé sí náà níyànjú láti ṣe.
6. Kí ni àwọn olórí ìsìn ṣe fún àwọn Kristẹni?
6 Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, pàápàá jù lọ àwọn tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù àti Jùdíà, dojú kọ ọ̀pọ̀ àdánwò àti ìnira. Àwọn olórí ìsìn Júù ṣì ń jẹ gàba lé àwọn èèyàn lórí nígbà yẹn, torí náà wọ́n ń fínná mọ́ àwọn Kristẹni gan-an. Àwọn aṣáájú ìsìn yìí náà ló fẹ̀sùn kan Jésù Kristi pé ó dìtẹ̀ sí ìjọba tí wọ́n sì pa á nípa ọ̀daràn. Síbẹ̀, wọn kò tíì dáwọ́ àtakò wọn dúró. Nínú ìwé Ìṣe, a lè rí ọ̀kan-kò-jọ̀kan ìtàn kà nípa bí wọ́n ṣe ń halẹ̀ mọ́ àwọn Kristẹni tí wọ́n sì ń ta kò wọ́n, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ lẹ́yìn àwọn iṣẹ́ ìyanu tó wáyé ní Pẹ́ńtíkọ́sì, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ni àwọn àtakò náà bẹ̀rẹ̀. Ó dájú pé èyí mú kí ìgbésí ayé nira fún àwọn olùṣòtítọ́.—Ìṣe 4:1-3; 5:17, 18; 6:8-12; 7:59; 8:1, 3.
7. Àwọn àkókò líle koko wo làwọn Kristẹni tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí dojú kọ?
7 Àwọn Kristẹni wọ̀nyẹn pẹ̀lú ń gbé ní àkókò tó ṣáájú òpin ètò àwọn nǹkan ti àwọn Júù. Jésù ti sọ fún wọn nípa ìparun tó máa wá sórí orílẹ̀-èdè Júù tó jẹ́ aláìṣòótọ́. Ó ti sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó máa wáyé kété kí òpin tó dé, ó sì fún wọn ní àwọn ìtọ́ni pàtó lórí ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe kí wọ́n bàa lè là á já. (Ka Lúùkù 21:20-22.) Kí ló wá yẹ kí wọ́n ṣe nígbà náà? Jésù kìlọ̀ fún wọn pé: “Ẹ kíyè sí ara yín, kí ọkàn-àyà yín má bàa di èyí tí a dẹrù pa pẹ̀lú àjẹjù àti ìmutíyó kẹ́ri àti àwọn àníyàn ìgbésí ayé, lójijì tí ọjọ́ yẹn yóò sì dé bá yín ní ìṣẹ́jú akàn.”—Lúùkù 21:34.
8. Kí ló lè mú káwọn Kristẹni kan dẹ̀rìn tàbí kí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì?
8 Ọgbọ̀n [30] ọdún ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kọjá lẹ́yìn tí Jésù fún wọn ní ìkìlọ̀ yìí, kí Pọ́ọ̀lù tó kọ lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn Hébérù. Ipa wo ni àkókò tó ti kọjá ní lórí àwọn Kristẹni wọ̀nyẹn? Ìṣòro àtàwọn ohun mìíràn tó ń pín ọkàn níyà nínú ìgbésí ayé ti gba àwọn míì lọ́kàn, wọ́n sì dẹ́kun láti máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí ni ì bá mú kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run sunwọ̀n sí i. (Héb. 5:11-14) Àwọn míì tiẹ̀ rò pé ìgbésí ayé máa túbọ̀ rọrùn fún àwọn bí àwọn bá ṣáà ti ń ṣe bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn Júù tó yí wọn ká. Ó ṣe tán, àwọn Júù wọ̀nyẹn kò tíì kọ Ọlọ́run sílẹ̀ pátápátá; wọ́n ṣì ń tẹ̀ lé Òfin rẹ̀ dé ìwọ̀n àyè kan. Àwọn Kristẹni mìíràn sì wà tó jẹ́ pé àwọn kan tó wà nínú ìjọ tí wọ́n ń ṣagbátẹrù pípa Òfin Mósè mọ́ àti títẹ̀ lé àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ni wọ́n ń yí wọn lọ́kàn pa dà tàbí tí wọ́n ń kó wọn láyà jẹ. Kí ni Pọ́ọ̀lù lè sọ tó máa ran àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ́wọ́ láti máa wà lójúfò nípa tẹ̀mí kí wọ́n sì máa fara dà á nínú eré ìje náà?
9, 10. (a) Ọ̀rọ̀ ìṣírí tí Pọ́ọ̀lù fúnni wo la lè rí kà ní apá tó gbẹ̀yìn ìwé Hébérù orí 10? (b) Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé nípa ìwà ìṣòtítọ́ àwọn ẹlẹ́rìí ìgbàanì?
9 Ó fani lọ́kàn mọ́ra láti rí bí Pọ́ọ̀lù tí Ọlọ́run mí sí ṣe gbìyànjú láti fún àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù lókun. Ní orí 10 nínú lẹ́tà náà, Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé Òfin jẹ́ “òjìji àwọn ohun rere tí ń bọ̀,” ó sì ṣàlàyé bí ẹbọ ìràpadà Kristi ṣe níye lórí tó. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù fẹ́ parí orí yẹn, ó gba àwọn òǹkàwé rẹ̀ níyànjú pé: “Ẹ nílò ìfaradà, kí ó lè jẹ́ pé, lẹ́yìn tí ẹ ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tán, kí ẹ lè rí ìmúṣẹ ìlérí náà gbà. Nítorí ní ‘ìgbà díẹ̀ kíún’ sí i, àti pé ‘ẹni tí ń bọ̀ yóò dé, kì yóò sì pẹ́.’”—Héb. 10:1, 36, 37.
10 Ọ̀nà tó já fáfá ni Pọ́ọ̀lù gbà ṣàlàyé ohun tí ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run jẹ́ nínú ìwé Hébérù orí 11. Ó fi ìtàn àwọn ọkùnrin àti obìnrin ìgbàgbọ́ ṣe àpèjúwe ohun tó sọ. Ṣé a lè sọ pé ńṣe ni Pọ́ọ̀lù tún gbé ọ̀rọ̀ gba ibòmíràn láìnídìí? Rárá o. Àpọ́sítélì náà mọ̀ pé àwọn táwọn jọ jẹ́ onígbàgbọ́ gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ìgbàgbọ́ gba pé kéèyàn máa fi ìgboyà àti ìfaradà ṣe nǹkan. Àpẹẹrẹ àtàtà táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó jẹ́ olóòótọ́ yẹn fi lélẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe jẹ́ adúróṣinṣin máa fún àwọn Hébérù lókun kí wọ́n lè fara da àwọn ìṣòro àti ìnira tó bá dé bá wọn. Torí náà, lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti to àwọn ohun tí ìgbàgbọ́ sún àwọn adúróṣinṣin wọ̀nyẹn láti ṣe nígbà àtijọ́ lẹ́sẹẹsẹ, ó sọ fún wọn pé: “Nítorí tí a ní àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí tí ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ yí wa ká, ẹ jẹ́ kí àwa pẹ̀lú mú gbogbo ẹrù wíwúwo kúrò àti ẹ̀ṣẹ̀ tí ó máa ń wé mọ́ wa pẹ̀lú ìrọ̀rùn, ẹ sì jẹ́ kí a fi ìfaradà sá eré ìje tí a gbé ka iwájú wa.”—Héb. 12:1.
“Àwọsánmà Àwọn Ẹlẹ́rìí”
11. Tá a bá ń ronú nípa “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí tí ó pọ̀” kí ló máa mú ká ṣe?
11 Àwọn tó para pọ̀ di “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí tí ó pọ̀” yìí kì í ṣe òǹwòran lásán tàbí ẹni tó wulẹ̀ dúró sítòsí pápá, tá a lè sọ pé ó wá síbẹ̀ torí àtiwo eré ìje tàbí torí àtiwo bí sárésáré tàbí àwùjọ àwọn olùdíje tó yàn láàyò ṣe máa borí. Ńṣe làwọn náà kópa nínú rẹ̀ bí àwọn sárésáré ṣe máa ń ṣe nínú eré ìje. Wọ́n sì ti sá eré ìje náà dópin. Àmọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti kú báyìí, a lè máa fojú inú wò ó pé wọ́n jẹ́ sárésáré tó pegedé, wọ́n sì lè jẹ́ ìṣírí fún àwọn sárésáré tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ eré ìje náà. Ronú nípa bó ṣe máa rí lára sárésáré kan tó bá mọ̀ pé díẹ̀ lára àwọn sárésáré tó pegedé jù lọ wà yí òun ká tí wọ́n ń wo òun. Ṣé ìyẹn ò ní mú kó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe tàbí kó tiẹ̀ ṣe ju ohun tágbára rẹ̀ gbé lọ? Àwọn ẹlẹ́rìí ayé ọjọ́un lè jẹ́rìí sí i pé bó ti wù kí eré ìṣàpẹẹrẹ yẹn máa tánni lókun tó, èèyàn lè borí. Torí náà, bí àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù ní ọ̀rúndún kìíní ṣe ń fi àpẹẹrẹ “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí” yìí sọ́kàn, wọ́n ń ní ìgboyà, wọ́n ń “fi ìfaradà sá eré ìje” náà, àwa náà sì lè ṣe bẹ́ẹ̀ lónìí.
12. Báwo ni àwọn àpèjúwe tí Pọ́ọ̀lù mú wá ṣe jọ tiwa?
12 Ipò tí ọ̀pọ̀ lára àwọn olóòótọ́ tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn wà jọ tiwa. Bí àpẹẹrẹ, Nóà gbé láyé lákòókò tí ayé tó wà ṣáájú Ìkún-omi ń lọ sópin. Àwa náà ń gbé ní apá ìparí ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Jèhófà ní kí Ábúráhámù àti Sárà fi ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn sílẹ̀ kí wọ́n lè máa ṣe ìjọsìn tòótọ́ kí wọ́n sì máa dúró de ìgbà tóun máa mú ìlérí òun ṣẹ. A rọ̀ wá pé ká sẹ́ ara wa ká lè jèrè ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà àtàwọn ìbùkún tó ṣe tán láti fún wa. Mósè rìn gba inú aginjù tó bani lẹ́rù bó ti ń lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí. Àwa náà ń gba inú ètò àwọn nǹkan tó ń kú lọ yìí, bá a ti ń forí lé ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí. Dájúdájú, ó tó ká ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, àṣeyọrí tí wọ́n ṣe àti àwọn àṣìṣe wọn, tó fi mọ́ ibi tí wọ́n dáa sí àti ibi tí wọ́n kù díẹ̀ káàtó sí.—Róòmù 15:4; 1 Kọ́r. 10:11.
Báwo Ni Wọ́n Ṣe Kẹ́sẹ Járí?
13. Àwọn ìpèníjà wo ni Nóà dojú kọ, kí ló sì mú kó borí wọn?
13 Kí ló mú káwọn ìránṣẹ́ Jèhófà yìí fara dà á tí wọ́n fi kẹ́sẹ járí nínú eré ìje náà? Kíyè sí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa Nóà. (Ka Hébérù 11:7.) Nóà ‘kò tíì rí àkúnya omi tó máa wá sórí ilẹ̀ ayé láti run gbogbo ẹran ara.’ (Jẹ́n. 6:17) Irú rẹ̀ kò tíì wáyé rí, kò sì tíì fìgbà kan ṣẹlẹ̀ rí. Síbẹ̀, Nóà kò ṣàì ka ọ̀rọ̀ náà sí kó wá máa rò pé irú rẹ̀ kò lè ṣeé ṣe tàbí pé kò tiẹ̀ jẹ́ wáyé. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó gbà gbọ́ pé ohunkóhun tí Jèhófà bá sọ, ni Jèhófà máa ṣe. Nóà kò wo ohun tí Ọlọ́run ní kó ṣe bí èyí tó ṣòro jù. Kàkà bẹ́ẹ̀, “ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.” (Jẹ́n. 6:22) Bá a bá ronú lórí gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run sọ pé kí Nóà ṣe, a óò rí i pé kì í ṣe iṣẹ́ kékeré rárá. Ọlọ́run ní kó kan ọkọ̀ áàkì, kí ó kó àwọn ẹran jọ, kí ó kó oúnjẹ tí àwọn ẹran àtàwọn èèyàn máa jẹ sínú ọkọ̀ náà, kó wàásù láti kìlọ̀ fáwọn èèyàn, kó sì tún mú kí ìdílé rẹ̀ lókun nípa tẹ̀mí. “Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.” Síbẹ̀, ìgbàgbọ́ Nóà àti ìfaradà rẹ̀ yọrí sí ìyè àti ìbùkún fún òun àti ìdílé rẹ̀.
14. Àwọn àdánwò wo ni Ábúráhámù àti Sárà fara dà, ẹ̀kọ́ wo sì nìyẹn kọ́ wa?
14 Lẹ́yìn náà ni Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa Ábúráhámù àti Sárà níbi tí ó to orúkọ ‘àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí tó yí wa ká’ lẹ́sẹẹsẹ sí. Ọlọ́run ní kí wọ́n fi ìgbésí ayé tó ti mọ́ wọn lára ní ìlú Úrì sílẹ̀, wọn kò sì mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí wọn lọ́jọ́ iwájú. Wọ́n fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ pé èèyàn lè ní ìgbàgbọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ kó sì tún jẹ́ onígbọràn nígbà ìṣòro. Látàrí bí Ábúráhámù ṣe máa ń fẹ́ láti yááfì àwọn nǹkan torí ìjọsìn tòótọ́, Bíbélì pè é ní “baba gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ.” (Róòmù 4:11) Àwọn kókó pàtàkì pàtàkì nìkan ni Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn tó kọ lẹ́tà náà sí mọ ìtàn ìgbésí ayé Ábúráhámù dáadáa. Síbẹ̀ náà, ẹ̀kọ́ tó jíire ni Pọ́ọ̀lù fà yọ látinú ìtàn náà. Ó sọ pé: “Gbogbo àwọn wọ̀nyí [tó fi mọ́ Ábúráhámù àti ìdílé rẹ̀] kú nínú ìgbàgbọ́, bí wọn kò tilẹ̀ rí ìmúṣẹ àwọn ìlérí náà gbà, ṣùgbọ́n wọ́n rí wọn lókèèrè réré, wọ́n sì fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà wọ́n, wọ́n sì polongo ní gbangba pé àwọn jẹ́ àjèjì àti olùgbé fún ìgbà díẹ̀ ní ilẹ̀ náà.” (Héb. 11:13) Ó dájú pé ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Ọlọ́run àti àjọṣe wọn pẹ̀lú rẹ̀ ló ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fi ìfaradà sá eré ìje náà.
15. Kí ló mú kí Mósè gbé ìgbé ayé rẹ̀ bó ti ṣe?
15 Ìránṣẹ́ Jèhófà mìíràn tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ tó sì wà lára “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí” yìí ni Mósè. Mósè fi ìgbésí ayé aláásìkí tó máa jẹ́ kó gbádùn ọ̀pọ̀ àǹfààní sílẹ̀, “ó [sì] yàn pé kí a ṣẹ́ òun níṣẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọ́run.” Kí ló mú kó ṣe bẹ́ẹ̀? Pọ́ọ̀lù dáhùn pé: “Ó tẹjú mọ́ sísan ẹ̀san náà. . . . Ó ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni tí a kò lè rí.” (Ka Hébérù 11:24-27.) Mósè kò jẹ́ kí “jíjẹ ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀” dí òun lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀. Mósè mọ̀ pé Ọlọ́run kì í purọ́ àti pé àwọn ìlérí rẹ̀ kì í tàsé, ìyẹn ló mú kó fi ìgboyà àti ìfaradà àrà ọ̀tọ̀ hàn. Ó tiraka láti fi taratara ṣiṣẹ́ kó bàa lè kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí.
16. Kí nìdí tí Mósè kò fi rẹ̀wẹ̀sì torí pé Ọlọ́run kò jẹ́ kó wọ Ilẹ̀ Ìlérí?
16 Bíi ti Ábúráhámù, Mósè kò rí ìmúṣẹ àwọn ìlérí Ọlọ́run nígbà ayé rẹ̀. Nígbà tó kù díẹ̀ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, Ọlọ́run sọ fún Mósè pé: “Láti òkèèrè ni ìwọ yóò ti rí ilẹ̀ náà ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò lọ sí ibẹ̀, sórí ilẹ̀ tí èmi yóò fi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.” Ohun tó fà á ni pé ṣááju ìgbà yẹn, òun àti Áárónì bínú torí ìwà ọ̀tẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n “hùwà sí [Ọlọ́run] lọ́nà àìfinipè láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì níbi omi Mẹ́ríbà.” (Diu. 32:51, 52) Ṣé Mósè wá torí ìyẹn rẹ̀wẹ̀sì tàbí kó bínú? Rárá o. Ó kéde ìbùkún sórí àwọn èèyàn náà ó sì parí ọ̀rọ̀ ìkéde náà báyìí: “Aláyọ̀ ni ìwọ, Ísírẹ́lì! Ta ni ó wà bí ìwọ, àwọn ènìyàn tí ń gbádùn ìgbàlà nínú Jèhófà, apata ìrànlọ́wọ́ rẹ, àti Ẹni tí ó jẹ́ idà ọlọ́lá ògo rẹ?”—Diu. 33:29.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́
17, 18. (a) Ní ti eré ìje ìyè tá à ń sá, kí la lè rí kọ́ lára “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí”? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
17 Látinú ohun tá a ti jíròrò nípa ìgbésí ayé díẹ̀ lára àwọn tó para pọ̀ jẹ́ ‘àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí tó yí wa ká,’ ó ṣe kedere pé ká tó lè sá eré ìje náà dé òpin, a gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ kíkún nínú Ọlọ́run àtàwọn ìlérí rẹ̀. (Héb. 11:6) Ìgbàgbọ́ kì í ṣe ohun tó yẹ ká fọwọ́ yẹpẹrẹ mú; ńṣe ló gbọ́dọ̀ máa sún wa ṣe gbogbo ohun tá a bá ń ṣe. Láìdà bí àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lè ríran ré kọjá ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nísinsìnyí. Ó ṣeé ṣe fún wa láti rí “Ẹni tí a kò lè rí” ká sì tipa bẹ́ẹ̀ máa fi ìfaradà sá eré ìje náà.—2 Kọ́r. 5:7.
18 Eré ìje táwa Kristẹni ń sá kò rọrùn. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe fún wa láti sá eré ìje náà dópin. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa sọ̀rọ̀ nípa ohun tó lè ràn wá lọ́wọ́ síwájú sí i.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi kọ lẹ́tà gígùn nípa àwọn ẹlẹ́rìí ìgbàanì tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́?
• Bá a bá ń fojú wò ó pé ‘àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí yí wa ká,’ báwo ni ìyẹn ṣe lè mú ká máa fi ìfaradà sáré?
• Kí lo ti rí kọ́ látinú ohun tá a ti jíròrò nípa àwọn ẹlẹ́rìí olùṣòtítọ́ bíi Nóà, Ábúráhámù, Sárà àti Mósè?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Ábúráhámù àti Sárà múra tán láti fi àwọn ohun tí wọ́n ń gbádùn ní ìlú Úrì sílẹ̀