“Ẹ Sáré . . . Kí Ọwọ́ Yín Lè Tẹ̀ Ẹ́”
“Ẹ Sáré . . . Kí Ọwọ́ Yín Lè Tẹ̀ Ẹ́”
“Ẹ sáré ní irúfẹ́ ọ̀nà bẹ́ẹ̀ kí ọwọ́ yín lè tẹ̀ ẹ́.”—1 KỌ́R. 9:24.
1, 2. (a) Kí ni Pọ́ọ̀lù lò láti fún àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù níṣìírí? (b) Kí ni Pọ́ọ̀lù gba àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run níyànjú láti ṣe?
NÍNÚ lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn Kristẹni bíi tirẹ̀ ní ìlú Hébérù, ó lo àfiwé tó wọni lọ́kàn láti fún wọn níṣìírí. Ó rán wọn létí pé àwọn nìkan kọ́ ló ń sá eré ìje ìyè náà. Ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí tí ó pọ̀” tí wọ́n ti borí nínú eré ìje náà wà yí wọn ká. Bí àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù yìí bá fi ìwà ìṣòtítọ́ àwọn tó ti sáré ìje náà ṣáájú wọn yìí àti bí wọ́n ṣe sapá gidigidi sọ́kàn, ó máa mú káwọn náà fẹ́ láti máa tẹ̀ síwájú, kí wọ́n má sì ṣe ṣíwọ́ láti máa sá eré ìje náà.
2 Nínú àpilẹ̀kọ́ tó ṣáájú èyí, a sọ̀rọ̀ nípa irú ìgbé ayé tí mélòó kan lára “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí” náà gbé. Gbogbo wọn fi hàn pé ìgbàgbọ́ tí kì í yẹ̀ tí wọ́n ní ló jẹ́ kí wọ́n lè máa bá a nìṣó gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ sí Ọlọ́run, bíi pé wọ́n tẹra mọ́ sísá eré ìje kan títí dópin. A lè rí ẹ̀kọ́ fà yọ látinú àṣeyọrí tí wọ́n ṣe. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe ṣàlàyé nínú àpilẹ̀kọ yẹn, àwọn tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run bíi ti Pọ́ọ̀lù tó fi mọ́ àwa náà lónìí ni Pọ́ọ̀lù gbà níyànjú nígbà tó sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí àwa pẹ̀lú mú gbogbo ẹrù wíwúwo kúrò àti ẹ̀ṣẹ̀ tí ó máa ń wé mọ́ wa pẹ̀lú ìrọ̀rùn, ẹ sì jẹ́ kí a fi ìfaradà sá eré ìje tí a gbé ka iwájú wa.”—Héb. 12:1.
3. Kí ni kókó ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù nínú ohun tó sọ nípa àwọn tó máa ń sáré táwọn Gíríìkì bá ń ṣeré ìdárayá?
3 Nígbà tí ìwé kan ń sọ̀rọ̀ nípa eré tí wọ́n ń fi ẹsẹ̀ sá, èyí tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn eré ìdárayá tí àwọn èèyàn mọ̀ dáadáa nígbà tí ẹ̀sìn Kristẹni ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, ó sọ pé: “Àwọn Gíríìkì kì í wọṣọ bí wọ́n bá ń múra sílẹ̀ fún eré ìdárayá tàbí tí wọ́n bá ń díje.” * (Backgrounds of Early Christianity) Lọ́nà yìí, àwọn sárésáré náà á bọ́ ohunkóhun tó dà bí ẹ̀rù wíwúwo tàbí ẹrù ìnira tí kò ní jẹ́ kí ara wọn fẹ́rẹ̀ tàbí tó máa dín ìjáfáfá wọn kù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bí wọ́n ṣe máa ń wà láìwọṣọ yìí kò bójú mu, ohun tó ń mú kí wọ́n sáré lọ́nà bẹ́ẹ̀ ni pé bí wọ́n ṣe máa rí ẹ̀bùn gbà lẹ́yìn tí wọ́n bá borí nínú eré ìje náà ló jẹ wọ́n lógún. Torí náà, kókó inú ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù ni pé kí àwọn sárésáré tó lè jèrè ẹ̀bùn ìyè, ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n mú gbogbo ohun tó bá lè ṣèdíwọ́ fún wọn kúrò. Ìmọ̀ràn tó múná dóko lèyí jẹ́ fún àwọn Kristẹni nígbà yẹn, ó sì wúlò fún àwa náà lónìí. Kí làwọn ohun tó dà bí ẹrù wíwúwo tàbí ẹrù ìnira tó lè ṣèdíwọ́ fún wa tí a kò fi ní jèrè ẹ̀bùn ìyè?
“Mú Gbogbo Ẹrù Wíwúwo Kúrò”
4. Kí ló gba gbogbo àkókò àwọn èèyàn ìgbà ayé Nóà?
4 Pọ́ọ̀lù fún wa nímọ̀ràn pé ká “mú gbogbo ẹrù wíwúwo kúrò.” Ìyẹn ní nínú gbogbo ohun tí kò ní jẹ́ ká lè pọkàn pọ̀ pátápátá sórí eré ìje náà ká sì sa gbogbo ipá wa. Irú àwọn nǹkan wo ló lè dà bí ẹrù wíwúwo tí Pọ́ọ̀lù ń sọ yìí? Ní ti Nóà tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí àpẹẹrẹ wọn, a lè rántí ohun tí Jésù sọ pé: “Bí ó ti ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọjọ́ Nóà, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò rí pẹ̀lú ní àwọn ọjọ́ Ọmọ ènìyàn.” (Lúùkù 17:26) Kì í ṣe ìparun tí irú rẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí tó ń bọ̀ nìkan ni Jésù ń sọ̀rọ̀ rẹ̀, àmọ́ kókó àlàyé Jésù ni pé, ọ̀nà táwọn èèyàn ń gbà gbé ìgbé ayé wọn lóde òní máa jọra pẹ̀lú ọ̀nà táwọn èèyàn gbà gbé ìgbé ayé wọn kí Ọlọ́run tó fi Ìkún-omi pa ayé run nígbà yẹn. (Ka Mátíù 24:37-39.) Ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn nígbà ayé Nóà kò nífẹ̀ẹ́ sí Ọlọ́run, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ pé kí wọ́n sapá láti ṣe ohun tó wù ú. Kí ló pín ọkàn wọn níyà? Kì í ṣe ohun àrà ọ̀tọ̀ kan bí kò ṣe jíjẹ, mímu àti gbígbéyàwó; àwọn ìgbòkègbodò tó jẹ́ apá kan ìgbésí ayé ẹ̀dá. Gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ, ìṣòro wọn ni pé, ‘wọn kò fiyè sí i.’
5. Kí ló lè mú ká sá eré ìje náà dópin?
5 Bíi ti Nóà àti ìdílé rẹ̀, iṣẹ́ pọ̀ fún wa láti ṣe lójoojúmọ́. A gbọ́dọ̀ wá jíjẹ mímu, ká sì tọ́jú ara wa àti ìdílé wa. Ìyẹn lè gba èyí tó pọ̀ lára àkókò, okun àtàwọn ohun ìní wa. Pàápàá jù lọ ní àwọn àkókò tí ọrọ̀ ajé kò rọgbọ, ó rọrùn láti máa ṣàníyàn nípa àwọn ohun téèyàn nílò. Torí pé a ti ya ara wa sí mímọ́ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, a tún ní àwọn ojúṣe pàtàkì míì láti bójú tó nínú ètò Ọlọ́run. A máa ń lọ sóde ẹ̀rí, a máa ń múra sílẹ̀ ká tó lọ sáwọn ìpàdé ìjọ, a máa ń dá kẹ́kọ̀ọ́ a sì tún máa ń ṣe Ìjọsìn Ìdílé, kí ohunkóhun má bàa ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Pẹ̀lú bí àwọn ohun tí Nóà gbọ́dọ̀ ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run ṣe pọ̀ tó, “ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.” (Jẹ́n. 6:22) Ó dájú pé ó ṣe pàtàkì ká dín ẹrù wíwúwo tí a ní láti gbé kù pátápátá, ká má sì ṣe di ẹrù ìnira èyíkéyìí tí kò pọn dandan ru ara wa, ká bàa lè sá eré ìje náà dé òpin.
6, 7. Ìmọ̀ràn tí Jésù fún wa wo ló yẹ ká fi sọ́kàn?
6 Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé ká mú “gbogbo ẹrù wíwúwo” kúrò? Kò sí bá a ṣe lè wà láìní ojúṣe tá a ó máa bójú tó. Nítorí èyí, ó dára ká fi ọ̀rọ̀ Jésù sọ́kàn. Ó ní: “Ẹ má ṣàníyàn láé, kí ẹ sì wí pé, ‘Kí ni a ó jẹ?’ tàbí, ‘Kí ni a ó mu?’ tàbí, ‘Kí ni a ó wọ̀?’ Nítorí gbogbo ìwọ̀nyí ni nǹkan tí àwọn orílẹ̀-èdè ń fi ìháragàgà lépa. Nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan wọ̀nyí.” (Mát. 6:31, 32) Ọ̀rọ̀ Jésù fi hàn pé àwọn ohun tá a nílò pàápàá, irú bí oúnjẹ àti aṣọ lè di ẹrù ìnira tàbí ohun ìkọ̀sẹ̀ bí a kò bá fi wọ́n sí ipò tó yẹ.
7 Ẹ pọkàn pọ̀ sórí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan wọ̀nyí.” Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé Baba wa ọ̀run, Jèhófà, máa ṣe ipa tirẹ̀ láti fún wa ní àwọn nǹkan tá a nílò. Ṣùgbọ́n ká má ṣe gbàgbé pé “gbogbo nǹkan wọ̀nyí” lè yàtọ̀ sí ohun tó wu àwa fúnra wa tàbí ohun tá a dìídì fẹ́. Síbẹ̀, a sọ fún wa pé ká má ṣe ṣàníyàn nípa “nǹkan tí àwọn orílẹ̀-èdè ń fi ìháragàgà lépa.” Kí nìdí? Jésù fún àwọn tó gbọ́rọ̀ rẹ̀ nímọ̀ràn lẹ́yìn náà pé: “Ẹ kíyè sí ara yín, kí ọkàn-àyà yín má bàa di èyí tí a dẹrù pa pẹ̀lú àjẹjù àti ìmutíyó kẹ́ri àti àwọn àníyàn ìgbésí ayé, lójijì tí ọjọ́ yẹn yóò sì dé bá yín ní ìṣẹ́jú akàn gẹ́gẹ́ bí ìdẹkùn.”—Lúùkù 21:34, 35.
8. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ìgbà yìí gan-an ló yẹ ká “mú gbogbo ẹrù wíwúwo kúrò”?
8 A ti ń wo ibi tí eré ìje náà máa parí sí níwájú wa. Kò ní ṣeé gbọ́ sétí pé àkókò tá a ti sún mọ́ òpin eré ìje náà pẹ́kípẹ́kí yìí la jẹ́ kí ẹrù ìnira tàbí ẹrù wíwúwo èyíkéyìí dí wa lọ́wọ́! Torí náà, ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún wa mọ́gbọ́n dání gan-an ni. Ó sọ pé: “Ó jẹ́ ọ̀nà èrè ńlá, àní fífọkànsin Ọlọ́run pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí ohun-moní-tómi.” (1 Tím. 6:6) Bá a bá fi ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí sọ́kàn, ó máa mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé a máa rí èrè náà gbà.
“Ẹ̀ṣẹ̀ Tí Ó Máa Ń Wé Mọ́ Wa Pẹ̀lú Ìrọ̀rùn”
9, 10. (a) Kí ni gbólóhùn náà, “ẹ̀ṣẹ̀ tí ó máa ń wé mọ́ wa pẹ̀lú ìrọ̀rùn” túmọ̀ sí? (b) Báwo ló ṣe lè wé mọ́ wa?
9 Ní àfikún sí “gbogbo ẹrù wíwúwo,” Pọ́ọ̀lù tún mẹ́nu kan mímú “ẹ̀ṣẹ̀ tí ó máa ń wé mọ́ wa pẹ̀lú ìrọ̀rùn” kúrò. Irú ẹ̀ṣẹ̀ wo nìyẹn ná? Ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “wé mọ́ wa pẹ̀lú ìrọ̀rùn” lédè Yorùbá fara hàn nínú Bíbélì, ẹsẹ yìí ló sì ti fara hàn. Ọ̀mọ̀wé Albert Barnes sọ pé: “Bí sárésáré ṣe máa ṣọ́ra kó má bàa kó aṣọ èyíkéyìí tó lè kọ́ ọ lẹ́sẹ̀ kọ́rùn nígbà tó bá ń sáré, kó sì ṣèdíwọ́ fún un, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ kí Kristẹni pa gbogbo ohun tó bá lè fa ìdíwọ́ fún un tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan.” Báwo ni nǹkan ṣe lè wé mọ́ Kristẹni kan kó sì sọ ìgbàgbọ́ rẹ̀ di ahẹrẹpẹ?
10 Kristẹni kan kò lè ṣàdédé dẹni tí kò ní ìgbàgbọ́ mọ́ ní ọ̀sán kan òru kan. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ni irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀, ó sì lè má fura pàápàá. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ lẹ́tà rẹ̀, ó kìlọ̀ nípa ewu tó wà nínú ‘sísú lọ’ àti ‘kí ọkàn-àyà burúkú tí ó ṣaláìní ìgbàgbọ́ má bàa dìde nínú ẹni.’ (Héb. 2:1; 3:12) Bí aṣọ tí sárésáré kan wọ̀ bá wé mọ́ ọn lẹ́sẹ̀, àfàìmọ̀ ni kò ní ṣubú. Àmọ́ irú ewu bẹ́ẹ̀ á tún wá pọ̀ sí i bí sárésáré náà kò bá kíyè sí bí irú aṣọ kan tó fẹ́ wọ̀ sáré ṣe léwu tó. Kí ló lè mú kó má ṣe kíyè sí irú ewu bẹ́ẹ̀? Ó lè jẹ́ pé kò bìkítà, kó dá ara rẹ̀ lójú jù tàbí kó má pọkàn pọ̀. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù?
11. Kí ló lè mú ká máà ní ìgbàgbọ́ mọ́?
11 A gbọ́dọ̀ fi í sọ́kàn pé bí Kristẹni kan kò bá ní ìgbàgbọ́ mọ́, ó ti ní láti jẹ́ pé ohun tó ń lo àkókò rẹ̀ fún ló fà á. Nígbà tí ọ̀mọ̀wé míì ń sọ̀rọ̀ nípa “ẹ̀ṣẹ̀ tí ó máa ń wé mọ́ wa pẹ̀lú ìrọ̀rùn” ó sọ pé ó jẹ́ “ẹ̀ṣẹ̀ tó máa ń nípa tó pọ̀ jù lọ lórí wa, torí ipò tá a bára wa, irú ẹni tá a jẹ́, àtàwọn tá à ń bá kẹ́gbẹ́.” Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé ipò tá a bára wa, àwọn ìkùdíẹ̀-káàtó wa àtàwọn tá à ń bá kẹ́gbẹ́ lè ní ipa tó pọ̀ lórí wa. Wọ́n lè sọ ìgbàgbọ́ wa di ahẹrẹpẹ tàbí kí wọ́n tiẹ̀ sọ wá di ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.—Mát. 13:3-9.
12. Àwọn ìránnilétí wo ló yẹ ká fi sọ́kàn ká má bàa di ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́ mọ́?
12 Ọjọ́ pẹ́ tí ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye ti ń rán wa létí pé ó yẹ ká ṣọ́ra ní ti ohun tá à ń wò àtohun tá à ń tẹ́tí sí, ìyẹn àwọn ohun tá à ń jẹ́ kó wọ inú ọkàn àti èrò inú wa. Wọ́n ti kìlọ̀ fún wa nípa ewu tó wà nínú jíjẹ́ kí ìfẹ́ láti máa kó owó àti ohun ìní rẹpẹtẹ jọ wé mọ́ni. Eré ìnàjú inú ayé tó máa ń fani lọ́kàn mọ́ra àti ìgbádùn kẹlẹlẹ táwọn èèyàn máa ń rí níbẹ̀ tàbí ọ̀pọ̀ ẹ̀rọ abánáṣiṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe jáde ní ọlọ́kan-kò-jọ̀kan lè gba àkókò tó yẹ ká lò fáwọn nǹkan tẹ̀mí mọ́ wa lọ́wọ́. Àṣìṣe ńlá ni tá a bá ronú pé irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ ti ń káni lọ́wọ́ kò jù tàbí pé àwọn míì ni ìmọ̀ràn náà wà fún àti pé àwọn nǹkan wọ̀nyẹn kò lè wu wá léwu. Ọ̀nà ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ àti ọ̀nà ẹ̀tàn ni Sátánì máa ń gbà gbé àwọn nǹkan tó lè wé mọ́ wa nínú ayé rẹ̀ wá. Ohun tó mú káwọn kan kùnà ni pé wọn kò kíyè sára, wọ́n ti dá ara wọn lójú jù, wọ́n ò sì fọkàn sí ohun tí wọ́n ń ṣe. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sì lè mú ká pàdánù èrè ìyè.—1 Jòh. 2:15-17.
13. Báwo la ṣe lè dáàbò bo ara wa ká má bàa lọ́wọ́ sí àwọn ohun tó lè wu wá léwu?
13 Ojoojúmọ́ là ń rí àwọn èèyàn tí wọ́n ń gbé ohun tí ayé ń fẹ́, ohun tí ayé kà sí pàtàkì àti èrò ayé lárugẹ. (Ka Éfésù 2:1, 2.) Síbẹ̀, ọwọ́ wa ló kù sí bóyá a máa gbà kí àwọn nǹkan wọ̀nyẹn nípa lórí wa tàbí a kò ní gbà. Pọ́ọ̀lù fi ọ̀nà táwọn èèyàn ayé ń gbà ronú wé “afẹ́fẹ́” tó lè ṣekú pani. A gbọ́dọ̀ máa wà lójúfò nígbà gbogbo kí afẹ́fẹ́ náà má bàa kó sí wa lọ́fun tàbí kí ó kó sí wa nímú tá ò fi ní lè mí dáadáa mọ́, tá ò sì ní lè parí eré ìje náà. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ ká má bàa yà kúrò lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè? O lè sọ pé títẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, ẹni pípé tó jẹ́ òléwájú nínú eré ìje náà ni. (Héb. 12:2) Yàtọ̀ síyẹn, a tún ní àpẹẹrẹ ti Pọ́ọ̀lù, torí pé òun náà ka ara rẹ̀ sí ọ̀kan lára àwọn sárésáré tó ń sá eré ìje Kristẹni ó sì rọ àwọn tí wọ́n jọ jẹ onígbàgbọ́ pé kí wọ́n fara wé òun.—1 Kọ́r. 11:1; Fílí. 3:14.
Báwo Ni ‘Ọwọ́ Yín Ṣe Lè Tẹ̀ Ẹ́’?
14. Ojú wo ni Pọ́ọ̀lù fi wo eré ìje tó sá?
14 Ojú wo ni Pọ́ọ̀lù fi wo eré ìje tó sá? Nígbà tí ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù bá àwọn alàgbà tó wá láti Éfésù sọ ń parí lọ, ó sọ pé: “Èmi kò ka ọkàn mi sí nǹkan kan tí ó ṣọ̀wọ́n fún mi, bí mo bá sáà ti lè parí ipa ọ̀nà mi àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí mo gbà lọ́wọ́ Jésù Olúwa.” (Ìṣe 20:24) Ó múra tán láti yááfì ohun gbogbo, títí kan ìwàláàyè rẹ̀, kó bàa lè parí eré ìje náà. Ní ti Pọ́ọ̀lù, gbogbo ìsapá rẹ̀ àti iṣẹ́ ribiribi tó ti ṣe ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìhìn rere kò ní já mọ́ nǹkan kan bó bá kùnà lọ́nà èyíkéyìí láti sáré ìje náà dópin. Síbẹ̀, kò dá ara rẹ̀ lójú jù, kó máa rò pé kò sí ohun tó lè dí òun lọ́wọ́ tóun ò fi ní lè borí nínú eré ìje náà. (Ka Fílípì 3:12, 13.) Ìgbà tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ń parí lọ ló tó lè fi ìdánilójú sọ pé: “Mo ti ja ìjà àtàtà náà, mo ti sáré ní ipa ọ̀nà eré ìje náà dé ìparí, mo ti pa ìgbàgbọ́ mọ́.”—2 Tím. 4:7.
15. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fún àwọn tí wọ́n jọ sá eré ìje náà ní ìṣírí?
15 Síwájú sí i, ó wu Pọ́ọ̀lù látọkàn wá pé kí àwọn Kristẹni bíi tirẹ̀ tí wọ́n jọ ń sáré ìje náà sá a dópin, kò fẹ́ kí wọ́n dẹ́kun eré sísá. Bí àpẹẹrẹ, ó rọ àwọn Kristẹni tó wà ní Fílípì pé kí wọ́n ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè rí ìgbàlà. Wọ́n gbọ́dọ̀ “di ọ̀rọ̀ ìyè mú ṣinṣin.” Ó sọ̀rọ̀ síwájú sí i pé: “Kí n lè ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà ní ọjọ́ Kristi, pé n kò sáré lásán tàbí ṣiṣẹ́ kára lásán.” (Fílí. 2:16) Bákan náà, ó rọ àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì pé: “Ẹ sáré ní irúfẹ́ ọ̀nà bẹ́ẹ̀ kí ọwọ́ yín lè [tẹ èrè náà].”—1 Kọ́r. 9:24.
16. Kí nìdí tó fi yẹ kó dá wa lójú pé a máa sáré ìje náà dópin, a sì máa rí èrè gbà?
16 Béèyàn bá ń sá eré ìje ẹlẹ́mìí ẹṣin, kò lè ti ìbẹ̀rẹ̀ rí ibi tí eré náà máa parí sí. Síbẹ̀, títí dìgbà tí sárésáré náà fi máa parí eré sísá, ibi tó máa parí sí ló máa wà lọ́kàn rẹ̀. Bó bá ti ń sún mọ́ ibi tí eré náà máa parí sí, bẹ́ẹ̀ ni yóò túbọ̀ máa jára mọ́ ọn kó lè kẹ́sẹ járí. Bó ṣe yẹ kó rí nínú eré ìje tí àwa Kristẹni náà ń sá nìyẹn. Ó yẹ kó dá wa lójú pé a máa sáré náà dópin, a sì máa rí èrè gbà. Ìyẹn gan-an ló sì máa jẹ́ kí ọwọ́ wa tẹ èrè náà.
17. Kí nìdí tí pípa ọkàn pọ̀ sórí èrè náà fi gba ìgbàgbọ́?
17 Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ìgbàgbọ́ ni ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú nípa àwọn ohun tí a ń retí, ìfihàn gbangba-gbàǹgbà àwọn ohun gidi bí a kò tilẹ̀ rí wọn.” (Héb. 11:1) Ábúráhámù àti Sárà múra tán láti fi ìgbésí ayé tó tuni lára tí wọ́n ń gbé tẹ́lẹ̀ sílẹ̀ kí wọ́n lè lọ máa gbé gẹ́gẹ́ bí “àjèjì àti olùgbé fún ìgbà díẹ̀ ní ilẹ̀ náà.” Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́? “Wọ́n rí [ìmúṣẹ àwọn ìlérí Ọlọ́run] lókèèrè réré.” Mósè kọ “jíjẹ ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀” àti “àwọn ìṣúra Íjíbítì.” Báwo ló ṣe ní ìgbàgbọ́ àti okun tó mú kó ṣe bẹ́ẹ̀? Ó “tẹjú mọ́ sísan ẹ̀san náà.” (Héb. 11:8-13, 24-26) Abájọ tó fi jẹ́ pé kí Pọ́ọ̀lù tó sọ̀rọ̀ nípa wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ó lo gbólóhùn náà “nípa ìgbàgbọ́.” Ìgbàgbọ́ mú kí wọ́n wò ré kọjá àwọn àdánwò àti ìnira ìsinsìnyí wọ́n sì ń rí ohun tí Ọlọ́run ń ṣe nítorí tiwọn àtàwọn ohun tó ṣì máa ṣe.
18. Kí làwọn ohun tó dára pé ká ṣe ká bàa lè mú “ẹ̀ṣẹ̀ tí ó máa ń wé mọ́ wa pẹ̀lú ìrọ̀rùn” kúrò?
18 Bá a bá ṣàṣàrò lórí àwọn ọkùnrin àti obìnrin ìgbàgbọ́ tí Hébérù orí 11 sọ̀rọ̀ wọn, tá a sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn, a lè ní ìgbàgbọ́ ká sì mú “ẹ̀ṣẹ̀ tí ó máa ń wé mọ́ wa pẹ̀lú ìrọ̀rùn” kúrò. (Héb. 12:1) Bákan náà, a lè “gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà” nípa pípé jọ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ bíi tiwa.—Héb. 10:24.
19. Báwo ni pípa ọkàn pọ̀ sórí èrè náà ṣe rí lára rẹ?
19 A ti wà ní ọ̀gẹ́gẹ́rẹ́ òpin eré ìje náà. Ńṣe ló tiẹ̀ dà bíi pé a ti ń wo ibi tí eré ìje náà máa parí sí ní iwájú wa. Nípa ìgbàgbọ́ àti ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, àwa pẹ̀lú lè “mú gbogbo ẹrù wíwúwo kúrò àti ẹ̀ṣẹ̀ tí ó máa ń wé mọ́ wa pẹ̀lú ìrọ̀rùn.” Bẹ́ẹ̀ ni, a lè sáré ní ọ̀nà tó fi jẹ́ pé a máa gba èrè náà, ìyẹn ni àwọn ìbùkún tí Bàbá wa, Jèhófà Ọlọ́run, ṣèlérí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Irú ìwà yìí máa ń bí àwọn Júù ìgbàanì nínú. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìgbàanì kan ṣe sọ, àríyànjiyàn ńlá lèyí dá sílẹ̀ nígbà tí Jason, àlùfáà àgbà tó di apẹ̀yìndà, tó sì ń fẹ́ láti gbé àṣà àwọn Gíríìkì lárugẹ, dá a lábàá pé kí wọ́n kọ́ gbọ̀ngàn eré ìdárayá kan sí ìlú Jerúsálẹ́mù.—2 Macc. 4:7-17.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Báwo la ṣe lè mú “gbogbo ẹrù wíwúwo” kúrò?
• Kí ló lè mú kí Kristẹni kan di ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́ mọ́?
• Kí nìdí tó fi yẹ ká pọkàn pọ̀ sórí bá a ṣe lè rí èrè náà gbà?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Kí ni “ẹ̀ṣẹ̀ tí ó máa ń wé mọ́ wa pẹ̀lú ìrọ̀rùn,” báwo ló sì ṣe lè wé mọ́ wa?