Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Lè Ṣe Bíi Ti Fíníhásì Bó O Bá Dojú Kọ Àwọn Ipò Tó Nira?

Ǹjẹ́ O Lè Ṣe Bíi Ti Fíníhásì Bó O Bá Dojú Kọ Àwọn Ipò Tó Nira?

Ǹjẹ́ O Lè Ṣe Bíi Ti Fíníhásì Bó O Bá Dojú Kọ Àwọn Ipò Tó Nira?

ÀǸFÀÀNÍ iyebíye ló jẹ́ láti máa sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà ìjọ. Àmọ́, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi hàn pé àwọn ipò kan tó nira máa ń dojú kọ àwọn alàgbà. Nígbà mìíràn, ó máa ń pọn dandan pé kí wọ́n bójú tó ìwà àìtọ́, kí wọ́n sì ‘ṣe ìdájọ́ fún Jèhófà.’ (2 Kíró. 19:6) Tàbí kẹ̀, alábòójútó kan lè gba iṣẹ́ kan, kó sì wá ronú bíi ti Mósè pé òun kò tóótun láti ṣe iṣẹ́ náà. Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Mósè mú kó béèrè nípa iṣẹ́ kan tí Jèhófà gbé fún un pé: “Ta ni èmi tí èmi yóò fi lọ bá Fáráò?”—Ẹ́kís. 3:11.

Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run kan náà tó yan àwọn alàgbà sípò ló mí sí àwọn tó kọ Ìwé Mímọ́. Nínú Ìwé Mímọ́, a rí àpẹẹrẹ tó ṣeé fara wé nípa àwọn alábòójútó tí wọ́n kojú àwọn ipò tó nira tí wọ́n sì ṣàṣeyọrí. Ọ̀kan lára irú àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀ ni ti Fíníhásì, ọmọ Élíásárì. Áárónì ni bàbá rẹ̀ àgbà torí náà ó lẹ́tọ̀ọ́ láti di àlùfáà àgbà. Àwọn ohun mẹ́ta kan tó ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé rẹ̀ jẹ́ kí àwọn tó jẹ́ alàgbà lónìí rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí wọ́n máa lo ìgboyà àti ìjìnlẹ̀ òye, kí wọ́n sì tún ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà, bí wọ́n bá kojú ipò tó nira.

“Ní Kíá, Ó Dìde”

Ọ̀dọ́kùnrin ni Fíníhásì nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pàgọ́ sí Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù. Bíbélì ròyìn pé: “Àwọn ènìyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí ní ìbálòpọ̀ oníṣekúṣe pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin Móábù. . . . Àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ, wọ́n sì ń tẹrí ba fún àwọn ọlọ́run wọn.” (Núm. 25:1, 2) Jèhófà fi àrùn tó ń ṣekú pani kọ lu àwọn oníwà àìtọ́ yẹn. Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára Fíníhásì nígbà tó gbọ́ nípa ìwà àìtọ́ náà àti àrùn tí Jèhófà fi kọ lù wọ́n?

Àkọsílẹ̀ náà ń bá a lọ pé: “Wò ó! ọkùnrin kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá, ó sì ń mú obìnrin Mídíánì kan bọ̀ lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀ lójú Mósè àti lójú gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, bí wọ́n ti ń sunkún ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.” (Núm. 25:6) Kí ni Fíníhásì tó jẹ́ àlùfáà máa ṣe? Fíníhásì kò tíì dàgbà púpọ̀, ọmọ Ísírẹ́lì tó hùwàkiwà yìí sì jẹ́ ìjòyè tó ń ṣáájú àwọn èèyàn náà nínú ìjọsìn.—Núm. 25:14.

Àmọ́ Jèhófà ni Fíníhásì bẹ̀rù, kì í ṣe àwọn èèyàn. Nígbà tó tajú kán rí àwọn méjèèjì, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló mú aṣóró kan ní ọwọ́ rẹ̀, ó tẹ̀ lé ọkùnrin náà wọnú àgọ́ náà, ó sì gún àwọn méjèèjì ní àgúnyọ. Ojú wo ni Jèhófà fi wo ìgboyà tí Fíníhásì fi hàn àti bó ṣe gbé ìgbésẹ̀? Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jèhófà dá àrùn tó fi kọ lu àwọn èèyàn náà dúró, ó sì bá Fíníhásì dá májẹ̀mú pé nítorí ohun tó ṣe ipò àlùfáà kò ní kúrò ní ìlà ìdílé rẹ̀ “fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Núm. 25:7-13.

Èyí kò túmọ̀ sí pé káwọn alàgbà ìjọ lóde òní hùwà ipá. Àmọ́ bíi ti Fíníhásì, àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ múra tán láti gbé ìgbésẹ̀ kí wọ́n sì lo ìgboyà. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn oṣù mélòó kan péré tí Guilherme bẹ̀rẹ̀ sí í sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà, wọ́n ní kó wà lára ìgbìmọ̀ onídàájọ́ kan. Alàgbà kan tó ti ran Guilherme lọ́wọ́ nígbà tó ṣì kéré ló hùwà àìtọ́. Guilherme sọ pé: “Ó ṣe mí bíi pé mi ò tóótun láti gbọ́ ẹjọ́ yẹn. Ó ṣòro fún mi láti sùn ní alẹ́. Mo ṣáà ń ronú nípa ọ̀nà tí mo lè gbà gbọ́ ẹjọ́ náà láì jẹ́ kí bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára mi dí mi lọ́wọ́ láti tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà. Mo gbàdúrà fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, mo sì ṣèwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde tá a gbé ka Bíbélì.” Èyí ràn án lọ́wọ́ láti ní ìgboyà tó nílò kó bàa lè bójú tó ipò tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tó bá ara rẹ̀ kó sì fi Bíbélì ran arákùnrin rẹ̀ tó ṣàṣìṣe lọ́wọ́.—1 Tím. 4:11, 12.

Bí àwọn alàgbà bá ń ló ìgboyà tí wọ́n sì ń gbé ìgbésẹ̀ nígbà tí àwọn ipò tó béèrè fún un bá wáyé nínú ìjọ, wọ́n á máa tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn láti ní ìgbàgbọ́ kí wọ́n sì jẹ́ adúróṣinṣin. Àwọn Kristẹni mìíràn pẹ̀lú gbọ́dọ̀ lo ìgboyà nípa sísọ fún àwọn alàgbà nígbà tí wọ́n bá mọ̀ pé arákùnrin tàbí arábìnrin kan ti hùwà àìtọ́ tó burú jáì. Bákan náà, bí wọ́n bá yọ ọ̀rẹ́ tàbí ìbátan wa kan lẹ́gbẹ́, ó gba ìdúróṣinṣin láti má ṣe bá onítọ̀hún kẹ́gbẹ́ mọ́.—1 Kọ́r. 5:11-13.

Ìjìnlẹ̀ Òye Fòpin sí Ìṣòro

Ìgboyà tí Fíníhásì fi hàn yàtọ̀ sí bí àwọn ọ̀dọ́ ṣe sábà máa ń gbé ìgbésẹ̀ láìronú. Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò bó ṣe lo ìjìnlẹ̀ òye nípa lílo ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀ nígbà tí wọ́n fi ohun mìíràn tó ṣẹlẹ̀ tó o létí. Àwọn ẹ̀yà Rúbẹ́nì àti Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè mọ pẹpẹ kan sítòsí Odò Jọ́dánì. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kù rò pé ó ní láti jẹ́ pé wọ́n fẹ́ máa fi rúbọ sí àwọn ọlọ́run èké ni, wọ́n sì múra láti lọ bá wọn jà.—Jóṣ. 22:11, 12.

Kí ni Fíníhásì ṣe? Fíníhásì àti àwọn ìjòyè mìíràn ní Ísírẹ́lì, fi ọgbọ́n jíròrò ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú àwọn tó kọ́ pẹpẹ náà. Àwọn ẹ̀yà tí wọ́n fẹ̀sùn kàn náà ṣàlàyé bí ọ̀ràn náà ṣe jẹ́ gan-an, wọ́n sọ pé “iṣẹ́ ìsìn Jèhófà” ni pẹpẹ náà wà fún. Bí ìṣòro tí ì bá wáyé ṣe dópin nìyẹn o.—Jóṣ. 22:13-34.

Bí Kristẹni kan bá gbọ́ tí wọ́n fẹ̀sùn kan ẹnì kan tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà tàbí tí wọ́n sọ ohun tí kò dáa nípa rẹ̀, ẹ wo bó ti bọ́gbọ́n mu tó pé kó tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Fíníhásì! Tá a bá ní ìjìnlẹ̀ òye, a kò ní máa bínú tàbí ká máa sọ àwọn ohun tá a kíyè sí pó kù díẹ̀ káàtó nípa àwọn ará wa.—Òwe 19:11.

Báwo ni ìjìnlẹ̀ òye ṣe lè ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ láti ṣe bíi ti Fíníhásì? Jaime tó ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà fún ohun tó lé ní ọdún mẹ́wàá sọ pé: “Nígbà tí akéde kan bá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ìṣòro tó ní pẹ̀lú ẹlòmíì fún mi, mo máa ń tètè gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ kí n má bàa gbè sẹ́yìn ẹnì kan, àmọ́ kí n lè fi Ìwé Mímọ́ tọ́ onítọ̀hún sọ́nà. Nígbà kan arábìnrin kan sọ fún mi pé òun ní ìṣòro pẹ̀lú arákùnrin kan tó wà nípò àbójútó nínú ìjọ míì. Ó ní ohun tí arákùnrin náà ṣe fún òun dun òun. Torí pé ọ̀rẹ́ mi ni arákùnrin náà, ohun tí ì bá rọrùn fún mi ni pé kí n lọ bá a sọ̀rọ̀. Dípò ìyẹn, èmi àti arábìnrin náà jọ jíròrò àwọn ìlànà mélòó kan látinú Bíbélì. Ó sì gbà pé òun máa kọ́kọ́ lọ bá arákùnrin náà sọ̀rọ̀. (Mát. 5:23, 24) Ọ̀ràn náà kò yanjú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Torí náà mo sọ fún un pé kó gbé àwọn ìlànà míì yẹ̀ wò látinú Ìwé Mímọ́. Ó pinnu láti gbàdúrà nípa ọ̀ràn náà, ó sì gbìyànjú láti dárí ji arákùnrin náà.”

Ibo lọ̀ràn náà wá yọrí sí? Jaime rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sì sọ pé: “Lẹ́yìn oṣù mélòó kan, arábìnrin yẹn wá bá mi. Ó ṣàlàyé pé, nígbà tó yá arákùnrin tí wọ́n jọ ní èdèkòyédè yẹn kábàámọ̀ ohun tó sọ. Ó ṣètò láti bá òun ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, ó sì sọ pé òun mọrírì ohun tí òun ṣe. Bí ọ̀ràn náà ṣe yanjú nìyẹn. Ṣé ìṣòro náà ì bá ti yanjú ká sọ pé mo ti dá sí ọ̀ràn náà, tó sì wá dà bíi pé mo gbè sẹ́yìn ẹnì kan?” Bíbélì fún wa ní ìmọ̀ràn pé: “Má fi ìkánjú jáde lọ ṣe ẹjọ́.” (Òwe 25:8) Àwọn alàgbà tó ní ìjìnlẹ̀ òye máa ń ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu nípa fífún àwọn ará tó níṣòro láàárín ara wọn níṣìírí láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ kí wọ́n lè jẹ́ kí àlàáfíà jọba.

Ó Wádìí Lọ́dọ̀ Jèhófà

Fíníhásì láǹfààní láti sìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà fún àwọn èèyàn tó jẹ́ àyànfẹ́ Ọlọ́run. A ti rí i pé kódà nígbà tí kò tíì fi bẹ́ẹ̀ dàgbà, ó lo ìgboyà àti ìjìnlẹ̀ òye tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Àmọ́, bó ṣe gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ló jẹ́ kó lè ṣàṣeyọrí láti kojú àwọn ipò tó nira.

Lẹ́yìn tí àwọn ará Gíbíà, tó wá láti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì fipá bá wáhàrì ọmọ Léfì kan lò pọ̀ tí wọ́n sì jẹ́ kó kú ikú ìkà, àwọn ẹ̀yà tó kù gbára dì láti bá ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì jagun. (Oníd. 20:1-11) Kí wọ́n tó lọ jagun, wọ́n gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́, àmọ́ àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ṣẹ́gun wọn lẹ́ẹ̀mejì, àwọn tó kú lára wọn sì pọ̀. (Oníd. 20:14-25) Ṣé wọ́n máa lérò pé Ọlọ́run kò gbọ́ àdúrà wọn ni? Ṣé Jèhófà tiẹ̀ fẹ́ kí wọ́n ṣe nǹkan kan nípa ìwà àìtọ́ náà?

Fíníhásì tó ti wá di àlùfáà àgbà ní Ísírẹ́lì báyìí tún gbé ìgbésẹ̀ tó fi hàn pé ó ṣì ní ìgbọ́kànlé nínú Jèhófà. Nínú àdúrà tó gbà, ó sọ pé: “Ṣé kí n ṣì tún jáde lọ bá àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì arákùnrin mi ja ìjà ogun tàbí kí n dáwọ́ dúró?” Jèhófà dáhùn àdúrà rẹ̀ nípa fífi àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì lé wọn lọ́wọ́, wọ́n sì jó ìlú Gíbíà ráúráú.—Oníd. 20:27-48.

Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí? Àwọn ìṣòro kan kì í lọ nílẹ̀ bọ̀rọ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alàgbà sapá gidigidi tí wọ́n sì gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn àwọn lọ́wọ́. Nígbà tí ọ̀ràn bá rí báyìí, ó máa dára kí àwọn alàgbà rántí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè [tàbí ní gbígbàdúrà], a ó sì fi í fún yín; ẹ máa bá a nìṣó ní wíwá kiri, ẹ ó sì rí; ẹ máa bá a nìṣó ní kíkànkùn, a ó sì ṣí i fún yín.” (Lúùkù 11:9) Bó bá tiẹ̀ dà bíi pé àwọn alábòójútó kò tètè rí ìdáhùn sí àdúrà wọn, ó yẹ kó dá wọn lójú pé Jèhófà máa dáhùn bí àkókò bá tó lójú rẹ̀.

Bí àpẹẹrẹ, ìjọ kan ní orílẹ̀-èdè Ireland nílò Gbọ̀ngàn Ìjọba lójú méjèèjì, àmọ́ wọn kò bá ojúure aṣojú ìjọba tó ń bójú tó ọ̀ràn ilẹ̀ pàdé. Ó kọ̀ láti fọwọ́ sí ìwé ilẹ̀ tí àwọn ará náà fẹ́ kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba sí. Ó wá dà bíi pé ẹnì kan ṣoṣo tó láṣẹ láti fọwọ́ sí ìwé ilẹ̀ náà ni ẹni tó jẹ́ ọ̀gá àgbà fún àwọn tó ń bójú tó gbogbo ilẹ̀ tó wà ní àgbègbè náà. Ǹjẹ́ wọ́n lè rí ìrànlọ́wọ́ gbà nípasẹ̀ àdúrà bó ṣe rí nígbà ayé Fíníhásì?

Ọ̀kan lára àwọn alàgbà ìjọ náà sọ pé: “Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀, a lọ sí oríléeṣẹ́ àwọn tó ń bójú tó ọ̀ràn ilẹ̀. Nígbà tá a débẹ̀, wọ́n sọ fún mi pé a ní láti dúró fún ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan ká tó lè rí ọ̀gá wọn àgbà. Àmọ́, a láǹfààní láti rí i fún ìṣẹ́jú márùn-ún. Lẹ́yìn tó rí àwọn àwòrán ilẹ̀ tá a tún yà náà, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló yọ̀ǹda fún wa láti máa bá iṣẹ́ lọ lórí Gbọ̀ngàn Ìjọba náà, láti ìgbà náà ni aṣojú ìjọba tí kò fọwọ́ sí ìwé ilẹ̀ wa tẹ́lẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti ràn wá lọ́wọ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí jẹ́ ká rí i pé àdúrà máa ń ṣiṣẹ́ ribiribi.” Kò sí àní-àní pé Jèhófà máa dáhùn àdúrà àtọkànwá tí àwọn alàgbà tó fọkàn tán an bá gbà.

Iṣẹ́ ńlá ló já lé Fíníhásì léjìká ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì; síbẹ̀, bó ṣe lo ìgboyà àti ìjìnlẹ̀ òye, tó sì tún ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run, mú kó lè borí àwọn ipò tó nira tó dojú kọ ọ́. Inú Jèhófà sì dùn sí bí Fíníhásì ṣe bójú tó ìjọ Ọlọ́run lọ́nà tó jáfáfá. Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún [1,000] ọdún lẹ́yìn náà, Ọlọ́run mí sí Ẹ́sírà láti kọ̀wé pé: “Fíníhásì ọmọkùnrin Élíásárì sì ni aṣáájú wọn tẹ́lẹ̀ rí. Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ̀.” (1 Kíró. 9:20) Ǹjẹ́ kí ọ̀ràn gbogbo àwọn tó ń mú ipò iwájú láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run lónìí rí bíi ti Fíníhásì, àní gbogbo àwọn Kristẹni tó ń fi ìṣòtítọ́ sìn Ọlọ́run.