Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà, “Ọlọ́run Ìtùnú Gbogbo”

Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà, “Ọlọ́run Ìtùnú Gbogbo”

Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà, “Ọlọ́run Ìtùnú Gbogbo”

“Ìbùkún ni fún Ọlọ́run àti Baba Olúwa wa Jésù Kristi, Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.”—2 KỌ́R. 1:3.

1. Láìka ọjọ́ orí àwọn èèyàn sí, kí ni gbogbo wọ́n nílò?

 LÁTÌGBÀ tí wọ́n ti bí wa ni gbogbo wa ti nílò ìtùnú. Igbe ni ọmọ ọwọ́ fi máa ń jẹ́ ká mọ̀ pé òun nílò ìtùnú. Ó lè jẹ́ pé ó fẹ́ kí wọ́n gbé òun mọ́ra tàbí kí ebi máa pa á. Kódà, lẹ́yìn tá a bá ti dàgbà, a ṣì máa ń nílò ìtùnú lọ́pọ̀ ìgbà, pàápàá jù lọ tá a bá wà nínú ìṣòro.

2. Báwo ni Jèhófà ṣe mú kó dá wa lójú pé òun á tu gbogbo àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé òun nínú?

2 Àwọn ìbátan wa àtàwọn ọ̀rẹ́ wa sábà máa ń pèsè ìtùnú tá a nílò fún wa. Àmọ́, àwọn ìgbà míì wà tó jẹ́ pé wàhálà tó dé bá wa lè kọjá ohun tí èèyàn ẹlẹgbẹ́ wa lè wá ojútùú sí. Nírú àkókò bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló lè tù wá nínú bó ti wù kí wàhálà tó dé bá wa náà pọ̀ tó. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú kó dá wa lójú pé: “Jèhófà ń bẹ nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é, . . . igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́ ni òun yóò sì gbọ́.” (Sm. 145:18, 19) Bẹ́ẹ̀ ni, “ojú Jèhófà ń bẹ lọ́dọ̀ àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́.” (Sm. 34:15) Àmọ́ kí Ọlọ́run tó lè tì wá lẹ́yìn kó sì tù wá nínú, a gbọ́dọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e. Onísáàmù náà Dáfídì mú kí ìyẹn ṣe kedere nínú orin tó kọ. Ó sọ pé: “Jèhófà yóò sì di ibi gíga ààbò fún ẹni tí a ni lára, ibi gíga ààbò ní àwọn àkókò wàhálà. Àwọn tí ó mọ orúkọ rẹ yóò sì gbẹ́kẹ̀ lé ọ, nítorí tí ìwọ, Jèhófà, kì yóò fi àwọn tí ń wá ọ sílẹ̀ dájúdájú.”—Sm. 9:9, 10.

3. Àkàwé wo ni Jésù lò láti ṣàlàyé bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn Rẹ̀?

3 Àwọn tó ń sin Jèhófà ṣeyebíye lójú rẹ̀. Jésù mú kí èyí ṣe kedere nígbà tó sọ pé: “Ológoṣẹ́ márùn-ún ni a ń tà ní ẹyọ owó méjì tí ìníyelórí rẹ̀ kéré, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Síbẹ̀síbẹ̀, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí a gbàgbé níwájú Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n irun orí yín pàápàá ni a ti ka iye gbogbo wọn. Ẹ má bẹ̀rù; ẹ níye lórí ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́.” (Lúùkù 12:6, 7) Jèhófà tipasẹ̀ wòlíì Jeremáyà sọ fún àwọn èèyàn Rẹ̀ ìgbàanì pé: “Ìfẹ́ tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin ni mo fi nífẹ̀ẹ́ rẹ. Ìdí nìyẹn tí mo fi fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ fà ọ́.”—Jer. 31:3.

4. Kí nìdí tá a fi lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ìlérí Jèhófà?

4 Tá a bá ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà tá a sì gbà pé àwọn ìlérí rẹ̀ á ní ìmúṣẹ, èyí lè tù wá nínú nígbà tí wàhálà bá dé bá wa. Torí náà, ó yẹ káwa náà ní irú ìgbẹ́kẹ̀lé tí Jóṣúà ní nínú Ọlọ́run, èyí tó mú kó polongo pé: “Kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín. Gbogbo wọn ti ṣẹ fún yín. Kò sí ọ̀rọ̀ kan lára wọn tí ó kùnà.” (Jóṣ. 23:14) Ní àfikún sí i, ó lè dá wa lójú pé bí àwọn ipò kan tí ń dẹni wò bá tiẹ̀ kó ìdààmú bá wa fúngbà díẹ̀, “Ọlọ́run jẹ́ olùṣòtítọ́” kò sì ní fi àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ adúróṣinṣin sílẹ̀ láé.—Ka 1 Kọ́ríńtì 10:13.

5. Báwo la ṣe lè tu àwọn míì nínú?

5 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pe Jèhófà ní “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.” Ohun tó túmọ̀ sí láti “tu” ẹnì kan “nínú” ni pé kéèyàn ṣe nǹkan tó máa mú kára tu ẹni tó wà nínú wàhálà tàbí ẹni tí inú rẹ̀ bà jẹ́. Èyí lè jẹ́ nípa ṣíṣe ohun tó máa dín ìbànújẹ́ tàbí ẹ̀dùn ọkàn onítọ̀hún kù táá sì mára tù ú. Ohun tí Jèhófà máa ń ṣe nìyẹn. (Ka 2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.) Kò sí ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni tó lè dí Baba wa ọ̀run lọ́wọ́ torí náà ohun yòówù tó bá nílò láti tu àwọn tó fẹ́ràn rẹ̀ nínú wà ní ìkáwọ́ rẹ̀. Àwa pẹ̀lú sì lè tu àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ nínú bí wọ́n bá wà “nínú ìpọ́njú èyíkéyìí.” A lè ṣe bẹ́ẹ̀ “nípasẹ̀ ìtùnú tí Ọlọ́run fi ń tu àwa tìkára wa nínú.” Ẹ sì wo bí èyí ṣe jẹ́ ká rí i pé agbára tí Jèhófà ní láti tu àwọn tí kò nírètí nínú kò láfiwé!

Ohun Tá A Lè Ṣe Nípa Àwọn Nǹkan Tó Ń Fa Ìdààmú

6. Fúnni ní àpẹẹrẹ àwọn nǹkan tó lè fa ìdààmú.

6 Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń ṣẹlẹ̀ sí wa tó mú ká nílò ìtùnú. Ọ̀kan lára ohun tó máa ń bà wá nínú jẹ́ jù lọ ni ikú èèyàn wa, pàápàá jù lọ ọkọ, ìyàwó, tàbí ọmọ wa ọ̀wọ́n. Ẹni tí wọ́n bá ń ṣe kèéta tàbí ẹ̀tanú sí náà lè nílò ìtùnú. Gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan sì lè nílò ìtùnú nítorí àìlera, ọjọ́ ogbó, ipò òṣì, ìṣòro ìgbéyàwó, tàbí àwọn ohun tó ń kó ìdààmú báni nínú ayé.

7. (a) Bí ohun kan bá kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa, irú ìtùnú wo la máa nílò? (b) Kí ni Jèhófà lè ṣe láti wo ọkàn-àyà “tí ó ní ìròbìnújẹ́ tí ó sì wó palẹ̀” sàn?

7 Bí ohun kan bá kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa, a lè nílò ìtùnú tó máa fi wá lọ́kàn balẹ̀, tí kò ní jẹ́ ká máa ro àròdùn, tí kò ní jẹ́ ká ní ìmọ̀lára tí kò tọ́, tí kò ní jẹ́ kí ẹ̀dùn ọkàn náà ṣàkóbá fún ìlera wa, tí kò sì ní jẹ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà bà jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ọkàn-àyà. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi hàn pé ọkàn-àyà lè “ní ìròbìnújẹ́” kó sì di èyí ‘tí ó wó palẹ̀.’ (Sm. 51:17) Ó dájú pé Jèhófà lè ran ẹni tí ọkàn-àyà rẹ̀ bá wà nírú ipò yìí lọ́wọ́, torí pé “ó ń mú àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn lára dá, ó sì ń di àwọn ojú ibi tí ń ro wọ́n.” (Sm. 147:3) Kódà, bí ipò tá a bára wa bá nira gan-an tí ìdààmú sì bá ọkàn-àyà wa, Ọlọ́run lè tù wá nínú tá a bá gbàdúrà sí i, tá a ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, tá a sì ń pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́.Ka 1 Jòhánù 3:19-22; 5:14, 15.

8. Báwo ni Jèhófà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá ní ìdààmú ọkàn?

8 A sábà máa ń nílò ìtùnú bí onírúurú àdánwò bá mú ká máa ní èrò tí kò tọ́ tí èyí sì ń mú ká máa ní ìdààmú ọkàn gan-an. Kò sí bí àwa fúnra wa ṣe lè dá kojú àwọn ìdánwò ìgbàgbọ́ wọ̀nyí. Àmọ́, nínú orin tí onísáàmù náà kọ, ó sọ pé: “Nígbà tí ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè di púpọ̀ nínú mi, ìtùnú tìrẹ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣìkẹ́ ọkàn mi.” (Sm. 94:19) Síwájú sí i, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílí. 4:6, 7) Tá a bá ń ka Ìwé Mímọ́ tá a sì ń ṣe àṣàrò lé e lórí, ó lè ràn wá lọ́wọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ láti kojú ìdààmú ọkàn.—2 Tím. 3:15-17.

9. Kí la lè ṣe bí ohun kan tó ń da ọkàn wa láàmú bá mú ká ní ìmọ̀lára tí kò tọ́?

9 Nígbà míì, a lè rẹ̀wẹ̀sì gan-an débi tí a ó fi bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìmọ̀lára tí kò tọ́. Bóyá, ńṣe là ń rò pé kò ní ṣeé ṣe fún wa láti bójú tó ojúṣe tàbí àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan nínú ìjọ. Bọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, Jèhófà ṣì lè tù wá nínú kó sì tún ràn wá lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ ká ṣàpèjúwe rẹ̀ lọ́nà yìí: Nígbà tí Ọlọ́run ní kí Jóṣúà kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ bá àwọn orílẹ̀-èdè alágbára tó jẹ́ ọ̀tá wọn jà, Mósè sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ jẹ́ onígboyà àti alágbára. Má fòyà tàbí kí o gbọ̀n rìrì níwájú wọn, nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ẹni tí ń bá ọ lọ. Òun kì yóò kọ̀ ọ́ tì, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ pátápátá.” (Diu. 31:6) Pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn Jèhófà, ó ṣeé ṣe fún Jóṣúà láti kó àwọn èèyàn Ọlọ́run dé Ilẹ̀ Ìlérí, wọ́n sì ṣẹ́gun gbogbo àwọn ọ̀tá wọn. Kó tó dìgbà yẹn, Mósè ti rí irú ìtìlẹ́yìn bẹ́ẹ̀ gbà nígbà tí wọ́n fẹ́ kọjá níbi Òkun Pupa.—Ẹ́kís. 14:13, 14, 29-31.

10. Bí ẹ̀dùn ọkàn bá ṣàkóbá fún ìlera wa, kí ló lè ràn wá lọ́wọ́?

10 Àwọn nǹkan tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn báni lè ṣàkóbá fún ìlera wa. Àmọ́ ṣá o, tá a bá ń jẹ oúnjẹ tó ṣara lóore, tá à ń sinmi dáadáa, tá à ń ṣeré ìmárale, tá a sì ń wà ní mímọ́ tónítóní, àìsàn máa jìnnà sí wa. Tá a bá ń ronú nípa àwọn ohun rere tí Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ń bọ̀ wá ṣe lọ́jọ́ iwájú, a máa láyọ̀, ayọ̀ náà á sì hàn lójú wa. Torí náà, bí àwọn àdánwò tàbí ìṣòro kan bá ń pọ́n wa lójú, ó máa dára ká fi ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù sọ́kàn ká sì rántí ọ̀rọ̀ tí ń gbéni ró tó sọ. Ó ní: “A há wa gádígádí ní gbogbo ọ̀nà, ṣùgbọ́n a kò há wa ré kọjá yíyíra; ọkàn wa dàrú, ṣùgbọ́n kì í ṣe láìsí ọ̀nà àbájáde rárá; a ṣe inúnibíni sí wa, ṣùgbọ́n a kò fi wá sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́; a gbé wa ṣánlẹ̀, ṣùgbọ́n a kò pa wá run.”—2 Kọ́r. 4:8, 9.

11. Kí la lè ṣe nípa ohun tó bá fẹ́ ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́?

11 Àwọn àdánwò kan wà tó lè ṣàkóbá fún àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà. Jèhófà lè gbà wá lọ́wọ́ irú àwọn àdánwò bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú kó dá wa lójú pé: “Jèhófà ń fún gbogbo àwọn tí ó ṣubú ní ìtìlẹyìn, ó sì ń gbé gbogbo àwọn tí a tẹ̀ lórí ba dìde.” (Sm. 145:14) Bí ohun kan bá fẹ́ ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́, a gbọ́dọ̀ wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn alàgbà ìjọ. (Ják. 5:14, 15) Bá a bá sì ń fi ìyè àìnípẹ̀kun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa rẹ̀ sọ́kàn nígbà gbogbo, ìyẹn á lè ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà á nígbà tá a bá ń dojú kọ àwọn ìdánwò ìgbàgbọ́.—Jòh. 17:3.

Bí Ọlọ́run Ṣe Tu Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Nínú

12. Ṣàlàyé bí Jèhófà ṣe tu Ábúráhámù nínú.

12 Onísáàmù kan tí Ọlọ́run mí sí kọ̀wé pé: “Rántí ọ̀rọ̀ tí a sọ fún ìránṣẹ́ rẹ, èyí tí ìwọ [Jèhófà] mú mi dúró dè. Èyí ni ìtùnú mi nínú ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ mi níṣẹ̀ẹ́, nítorí pé àsọjáde tìrẹ ti pa mí mọ́ láàyè.” (Sm. 119:49, 50) Lónìí, a ní Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ Jèhófà, a sì lè rí àpẹẹrẹ tó pọ̀ nínú rẹ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe tu àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nínú. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe kí ìdààmú ọkàn ti bá Ábúráhámù nígbà tó gbọ́ pé Jèhófà fẹ́ pa ìlú Sódómù àti Gòmórà run. Baba ńlá tó jẹ́ olùṣòtítọ́ yẹn wá bi Ọlọ́run pé: “Ìwọ, ní ti tòótọ́, yóò ha gbá olódodo lọ pẹ̀lú àwọn ẹni burúkú bí?” Jèhófà tu Ábúráhámù nínú nípa mímú kó dá a lójú pé bí òun bá rí kìkì àádọ́ta [50] olódodo èèyàn níbẹ̀, Òun kò ní pa ìlú Sódómù run. Àmọ́, ní ìgbà márùn-ún sí i, Ábúráhámù béèrè lọ́wọ́ Jèhófà pé: Ká sọ pé àwọn olódodo tó wà níbẹ̀ jẹ́ márùndínláàádọ́ta, ogójì, ọgbọ̀n, ogún, tàbí mẹ́wàá ńkọ́? Jèhófà fi sùúrù àti pẹ̀lẹ́tù dáhùn ìbéèrè kọ̀ọ̀kan tí Ábúráhámù bi í yìí, ó sì mú kó dá a lójú pé òun kò ní pa Sódómù run bí iye olódodo tó tóyẹn bá wà níbẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tiẹ̀ sí olódodo mẹ́wàá pàápàá níbẹ̀, Jèhófà ṣì pa Lọ́ọ̀tì àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ mọ́.—Jẹ́n. 18:22-32; 19:15, 16, 26.

13. Báwo ni Hánà ṣe fi hàn pé òun gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?

13 Ó wu Hánà tó jẹ́ ìyàwó Ẹlikénà gan-an pé kó bímọ. Àmọ́ ó yàgàn, ìyẹn sì ń kó ìdààmú ọkàn bá a. Ó gbàdúrà sí Jèhófà nípa ọ̀ràn náà, Élì, tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà, sì sọ fún un pé: “Kí Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì yọ̀ǹda ìtọrọ” tí o ṣe lọ́dọ̀ rẹ̀. Ọ̀rọ̀ yìí tu Hánà nínú, “ìdàníyàn fún ara ẹni kò sì hàn lójú rẹ̀ mọ́.” (1 Sám. 1:8, 17, 18) Hánà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ọkàn rẹ̀ sì balẹ̀ láti fi ohun gbogbo lé e lọ́wọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Hánà kò mọ ibi tí ọ̀rọ̀ náà máa parí sí, ọkàn rẹ̀ balẹ̀ pẹ̀sẹ̀. Nígbà tó yá, Jèhófà dáhùn àdúrà rẹ̀. Ó lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì sọ ọ́ ní Sámúẹ́lì.—1 Sám. 1:20.

14. Kí nìdí tí Dáfídì fi nílò ìtùnú, ọ̀dọ̀ ta ló sì wá ìtùnú lọ?

14 Ẹlòmíràn tí Ọlọ́run tù nínú ni Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì. Níwọ̀n bí Jèhófà ti “ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́,” kó tó yan Dáfídì láti di ọba Ísírẹ́lì, ó ti ní láti rí i pé ó fi ọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn tòótọ́ kò sì sí ẹ̀tàn nínú rẹ̀. (1 Sám. 16:7; 2 Sám. 5:10) Àmọ́, lẹ́yìn náà, Dáfídì ṣe panṣágà pẹ̀lú Bátí-ṣébà ó sì gbìyànjú láti bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ nípa mímú kí wọ́n pa ọkọ obìnrin náà. Nígbà tó ṣe kedere sí Dáfídì bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ṣe burú tó, ó gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Nu àwọn ìrélànàkọjá mi kúrò gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ yanturu àánú rẹ. Wẹ̀ mí mọ́ tónítóní kúrò nínú ìṣìnà mi, kí o sì wẹ̀ mí mọ́ àní kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi. Nítorí èmi fúnra mi mọ àwọn ìrélànàkọjá mi, ẹ̀ṣẹ̀ mi sì ń bẹ ní iwájú mi nígbà gbogbo.” (Sm. 51:1-3) Dáfídì ronú pìwà dà tọkàntọkàn, Jèhófà sì dárí jì í. Àmọ́, Dáfídì jìyà ìwà àìtọ́ tó hù. (2 Sám. 12:9-12) Síbẹ̀, àánú tí Jèhófà fi hàn sí ìránṣẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ oníwà ìrẹ̀lẹ̀ yìí tù ú nínú.

15. Báwo ni Jèhófà ṣe ran Jésù lọ́wọ́ ṣáájú ikú rẹ̀?

15 Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó dojú kọ ọ̀pọ̀ àwọn ipò tó le koko. Ọlọ́run fàyè gba àwọn ipò tó dán ìgbàgbọ́ Jésù wò yìí. Torí pé Jésù jẹ́ ẹni pípé tó ń fìgbà gbogbo ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà tó sì fara mọ́ ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ, ó pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́. Kí Júdásì tó dà á àti kí wọ́n tó pa á, ó gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Kì í ṣe ìfẹ́ mi ni kí ó ṣẹ, bí kò ṣe tìrẹ.” Lẹ́yìn náà ni áńgẹ́lì kan fara han Jésù tó sì fún un lókun. (Lúùkù 22:42, 43) Ọlọ́run tu Jésù nínú, ó fún un lókun, ó sì tì í lẹ́yìn, ní àkókò tó rí i pé ó nílò rẹ̀ gan-an.

16. Bí ìwàláàyè wa bá wà nínú ewu torí pé à ń pa ìwà títọ́ mọ́ tí èyí sì mú ká ní ìdààmú ọkàn, kí ni Ọlọ́run lè ṣe fún wa?

16 Bí ìwàláàyè tiwa náà bá tiẹ̀ wà nínú ewu torí pé a jẹ́ Kristẹni adúróṣinṣin, Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́, ó sì máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè pa ìwà títọ́ wa mọ́. Síwájú sí i, ìrètí tá a ní pé àwọn òkú máa jíǹde tún máa ń tù wá nínú. A sì ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí Ọlọ́run yóò “sọ” ikú, tíì ṣe ọ̀tá ìkẹyìn, “di asán”! (1 Kọ́r. 15:26) Jèhófà kò jẹ́ gbàgbé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin àti àwọn míì tí wọ́n ti kú, ó máa jí wọn dìde. (Jòh. 5:28, 29; Ìṣe 24:15) Ìgbẹ́kẹ̀lé tá a ní nínú ìlérí Jèhófà pé ó máa jí àwọn òkú dìde máa ń tù wá nínú, ó sì máa ń mú kí ìrètí tá a ní túbọ̀ dájú bí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí wa.

17. Báwo ni Jèhófà ṣe ń tù wá nínú bí ìbátan wa kan bá kú?

17 Ẹ wo bó ṣe tuni nínú tó láti mọ̀ pé àwọn ìbátan wa tó wà nínú ibojì báyìí ní àǹfààní láti pa dà wà láàyè nínú ayé tuntun àgbàyanu kan tí kò ti ní í sí àwọn ohun tó ń fa ìdààmú lóde òní mọ́! Ẹ sì wo àǹfààní tó ń dúró de “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n bá la òpin ètò àwọn nǹkan búburú yìí já láti kí àwọn tó bá jíǹde sórí ilẹ̀ ayé káàbọ̀ kí wọ́n sì kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́!—Ìṣí. 7:9, 10.

Nísàlẹ̀ Ni Àwọn Apá Ayérayé Ọlọ́run Wà

18, 19. Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń tu àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nínú bí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí wọn?

18 Nínú orin kan tó ń fúnni lókun tó sì ń múni lọ́kàn yọ̀, Mósè mú kó dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lójú pé: “Ibi ìfarapamọ́ ni Ọlọ́run àtayébáyé náà, àti nísàlẹ̀ ni àwọn apá tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin wà.” (Diu. 33:27) Lẹ́yìn ìgbà yẹn, wòlíì Sámúẹ́lì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ má ṣe yà kúrò nínú títọ Jèhófà lẹ́yìn, kí ẹ sì fi gbogbo ọkàn-àyà yín sin Jèhófà. . . . Jèhófà kì yóò kọ àwọn ènìyàn rẹ̀ tì, nítorí orúkọ ńlá rẹ̀.” (1 Sám. 12:20-22) Bí a bá ń bá a nìṣó láti rọ̀ mọ́ Jèhófà nínú ìjọsìn tòótọ́, kò ní kọ̀ wá sílẹ̀ láé. Yóò máa wà pẹ̀lú wa ní gbogbo ìgbà tá a bá nílò ìtìlẹ́yìn rẹ̀.

19 Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn líle koko yìí, Ọlọ́run máa ń ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ ó sì máa ń tù wọ́n nínú nígbàkigbà tí wọ́n bá nílò rẹ̀. Kárí ayé, ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún báyìí tí wọ́n ti ń ṣe inúnibíni sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún lára àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ tí wọ́n sì ń jù wọ́n sẹ́wọ̀n torí pé wọ́n ń sin Jèhófà. Ìrírí wọ́n jẹ́ kó ṣe kedere pé òótọ́ ni Jèhófà máa ń tu àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nínú nígbà àdánwò. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n fi ọ̀kan lára àwọn arákùnrin wa tó wà ní ìlú Soviet Union àtijọ́ sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́tàlélógún [23] nítorí ohun tó gbà gbọ́. Síbẹ̀, àwọn ará wá ọ̀nà láti mú oúnjẹ tẹ̀mí dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ kó lè fún un lókun kó sì tù ú nínú. Ó sọ pé: “Ní gbogbo ọdún wọ̀nyẹn, mo kọ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó sì fún mi lókun.”—Ka 1 Pétérù 5:6, 7.

20. Kí nìdí tó fi lè dá wa lójú pé Jèhófà kò ní pa wá tì?

20 Láìka ìṣòro yòówù tá a ṣì lè dojú kọ sí, ó máa dára ká fi àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú tí onísáàmù náà kọ lórin sọ́kàn. Ó ní: “Jèhófà kì yóò ṣá àwọn ènìyàn rẹ̀ tì.” (Sm. 94:14) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa náà nílò ìtùnú, a tún ní àǹfààní ńlá láti máa tu àwọn ẹlòmíràn nínú. Bá a ṣe máa rí i nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a lè kópa nínú títu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú ayé oníwàhálà yìí nínú.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó lè mú ká ní ìdààmú ọkàn?

• Báwo ni Jèhófà ṣe ń tu àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nínú?

• Bí ìwàláàyè wa bá wà nínú ewu, kí ló lè tù wá nínú?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

OHUN TÁ A LÈ ṢE NÍPA ÀWỌN NǸKAN TÓ LÉ KÓ ÌDÀÀMÚ BÁ . . .

ọkàn-àyà Sm. 147:3; 1 Jòh. 3:19-22; 5:14, 15

èrò Sm. 94:19; Fílí. 4:6, 7

ìmọ̀lára Ẹ́kís. 14:13, 14; Diu. 31:6

ìlera 2 Kọ́r. 4:8, 9

àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà Sm. 145:14; Ják. 5:14, 15