Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà Ń fún Mi Láyọ̀

Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà Ń fún Mi Láyọ̀

Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà Ń fún Mi Láyọ̀

Gẹ́gẹ́ bí Fred Rusk ṣe sọ ọ́

Látìgbà ọmọdé ni mo ti rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ inú Sáàmù 27:10, níbi tí Dáfídì ti sọ pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé baba mi àti ìyá mi fi mí sílẹ̀, àní Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gbà mí.” Ẹ jẹ́ kí n sọ bí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi ṣe bá ẹsẹ Bíbélì yìí mu.

OKO tí bàbá mi àgbà ti ń gbin òwú ní ìpínlẹ̀ Georgia ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni mo gbé dàgbà, ìyẹn sì jẹ́ ní àkókò Ìlọsílẹ̀ Gígadabú Nínú Ọrọ̀ Ajé tó wáyé láàárín ọdún 1930 sí ọdún 1939. Ikú ìyá mi àti àbúrò mi ọkùnrin tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí ba bàbá mi nínú jẹ́ gan-an ni. Torí náà, bàbá mi fi mí sọ́dọ̀ bàbá tiwọn, wọ́n sì wáṣẹ́ lọ sí ìlú tó jìnnà. Nígbà tó yá, bàbá mi ṣètò pé kí n wá máa gbé níbi táwọn wà, àmọ́ ètò tí wọ́n ṣe kò bọ́ sí i.

Àwọn tó dàgbà lára àwọn ọmọbìnrin tí bàbá bàbá mi bí ló ń bójú tó ilé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bàbá bàbá mi kò nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀sìn, síbẹ̀ ẹni tó fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀sìn ṣọ́ọ̀ṣì onítẹ̀bọmi tí wọ́n ń pè ní Southern Baptist làwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin. Wọ́n máa ń fipá mú mi lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ní gbogbo ọjọ́ Sunday, torí pé bí mo bá kọ̀ wọ́n máa ń sọ pé àwọn máa nà mí. Torí náà láti kékeré ni mi ò ti fi bẹ́ẹ̀ ka ẹ̀sìn sí pàtàkì. Àmọ́ mo gbádùn lílọ sí iléèwé àti ṣíṣe eré ìdárayá.

Ìbẹ̀wò Tó Yí Ìgbésí Ayé Mi Pa Dà

Ní ọ̀sán ọjọ́ kan lọ́dún 1941, nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, ọkùnrin àgbàlagbà kan àti ìyàwó rẹ̀ wá sí ilé wa. Bàbá mi àgbà sọ fún mi pé, “Talmadge Rusk tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n màmá rẹ àgbà rèé o.” Mi ò tíì gbọ́ nǹkan kan nípa rẹ̀ tẹ́lẹ̀ àmọ́ mo wá mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni òun àti ìyàwó rẹ̀. Ó ṣàlàyé pé Ọlọ́run fẹ́ kí àwa èèyàn máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn sì yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí mo ti gbọ́ ní ṣọ́ọ̀ṣì. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ìbátan mi ni kò gba ohun tí òun àti ìyàwó rẹ̀ sọ gbọ́, wọ́n tiẹ̀ tẹ́ńbẹ́lú wọn. Wọn kò jẹ́ kí wọ́n wọ inú ilé wa mọ́. Àmọ́, Mary, àbúrò bàbá mi tó fi ọdún mẹ́ta jù mí lọ, gba Bíbélì kan àti àwọn ìtẹ̀jáde tó ń ṣàlàyé Bíbélì lọ́wọ́ wọn.

Kò pẹ́ rárá tó fi dá Mary lójú pé òun ti lóye ẹ̀kọ́ Bíbélì, ó ṣèrìbọmi lọ́dún 1942, ó sì di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bákan náà, ohun tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ ṣẹ sí i lára. Jésù ní: “Àwọn ọ̀tá ènìyàn yóò jẹ́ àwọn ènìyàn agbo ilé òun fúnra rẹ̀.” (Mát. 10:34-36) Àtakò tí wọ́n ń ṣe sí i nínú ìdílé wá túbọ̀ pọ̀ sí i. Ẹ̀gbọ́n Mary obìnrin, tó gbajúmọ̀ ní ìlú wa, lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú olórí ìlú, wọ́n sì fi ọlọ́pàá mú Talmadge. Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án ni pé ó ń tajà láìní ìwé àṣẹ. Wọ́n sì dá a lẹ́bi.

Ìwé ìròyìn kan nílùú wa sọ pé olórí ìlú wa, tó dá ẹjọ́ náà, sọ fún àwọn tó wà ní kóòtù pé: “Ìwé ìròyìn tí ọkùnrin yìí ń pín kiri . . . léwu bíi májèlé.” Ẹ̀gbọ́n màmá mi àgbà ló jàre ẹjọ́ náà lẹ́yìn tó pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, àmọ́ ó ṣì lo ọjọ́ mẹ́wàá lẹ́wọ̀n.

Bí Àbúrò Bàbá Mi Ṣe Ràn Mí Lọ́wọ́

Àbúrò Bàbá mi, ìyẹn Mary, bẹ̀rẹ̀ sí í bá mi sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ látinú Bíbélì, ó sì tún ń wàásù fún àwọn aládùúgbò wa. Mo máa ń bá wọn lọ sọ́dọ̀ ọkùnrin kan tí wọ́n ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ìwé The New World. * Ìyàwó ọkùnrin náà sọ fún wa pé ńṣe ni ọkọ òun ka ìwé náà mọ́jú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò fẹ́ lọ́wọ́ sí ohunkóhun tó bá ti jẹ mọ́ ẹ̀sìn, ohun tí mò ń kọ́ wù mí. Àmọ́, ẹ̀kọ́ Bíbélì tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń kọ́ni gan-an kọ́ ló mú kó dá mi lójú pé èèyàn Ọlọ́run ni wọ́n. Ìwà táwọn èèyàn ń hù sí wọn ló mú kó dá mi lójú.

Bí àpẹẹrẹ, lọ́jọ́ kan tí èmi àti Mary ń bọ̀ láti ibi tá a ti lọ roko ìdí tòmátì tá a gbìn, a rí àjókù àwọn ìwé Mary nínú iná kan tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ jó tán, tó fi mọ́ ẹ̀rọ giramafóònù àtàwọn àwo rẹ́kọ́ọ̀dù tó ní ọ̀rọ̀ ìwàásù nínú, èyí tó jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ẹ̀gbọ́n Mary obìnrin ti dáná sun wọ́n. Nígbà tí mo bínú sí wọn, ọ̀kan lára àwọn ẹ̀gbọ́n Mary sọ fún mi pé, “Tó bá yá o ṣì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ wa nítorí ohun tá a ṣe yìí.”

Ní ọdún 1943 wọ́n lé Mary jáde nílé torí pé ó kọ̀ láti fi ẹ̀sìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ rí sílẹ̀ àti pé kò yéé wàásù fún àwọn aládùúgbò. Nígbà yẹn, inú mi dùn pé mo ti wá mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run, pé ó jẹ́ Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ àti aláàánú, kì í sì í sun àwọn èèyàn nínú ọ̀run àpáàdì. Mo tún wá mọ̀ pé Jèhófà ní ètò kan níbi tí ìfẹ́ ti gbilẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò tíì lọ sí ìpàdé èyíkéyìí rí.

Nígbà tó yá, níbi tí mo ti ń fi ẹ̀rọ gé koríko, ẹnì kan wa ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wá sẹ́gbẹ̀ẹ́ ibi tí mo wà, ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin méjì tó wà nínú ọkọ̀ náà sì bi mí bóyá èmi ni mò ń jẹ́ Fred. Nígbà tí mo wá mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n, mo sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí n wọlé, ká lè lọ síbi tá a ti máa lè sọ̀rọ̀ láìséwu.” Mary ló ní kí wọ́n wá bẹ̀ mí wò. Ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin náà ni Shield Toutjian, òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò kan tó fún mi ní ìṣírí àti ìtọ́ni tó bọ́ sákòókò látinú Ìwé Mímọ́. Àwọn ìbátan mi wá dájú sọ mí torí pé mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbèjà ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́.

Mary kọ̀wé sí mi láti ìpínlẹ̀ Virginia tó kó lọ, ó sì sọ pé bó bá jẹ́ pé òótọ́ ni mo ti pinnu láti sin Jèhófà, mo lè wá máa gbé lọ́dọ̀ òun. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni mo pinnu láti lọ. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Friday kan ní oṣù October ọdún 1943, mo fi àwọn nǹkan tó pọn dandan tí mo máa nílò sínú àpótí kan mo sì so ó mọ́ igi kan tó jìnnà díẹ̀ sílé wa. Ní ọjọ́ Sátidé, mo lọ gbé àpótí náà mo sì gba ọ̀nà ẹ̀yìn lọ sí ilé aládùúgbò wa kan, ibẹ̀ ni mo ti rí mọ́tò tó gbé mi lọ sígboro. Nígbà tí mo dé ìlú Roanoke, mo rí Mary ní ilé Edna Fowlkes.

Mo Túbọ̀ Sún Mọ́ Jèhófà, Mo Ṣèrìbọmi, Mo sì Lọ Sìn ní Bẹ́tẹ́lì

Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ aláàánú ni Edna, ẹni àmì òróró ni, mo lè pè é ní Lìdíà òde òní. Edna gbà kí ìyàwó ẹ̀gbọ́n rẹ̀ àtàwọn ọmọbìnrin wọn méjì àti Mary máa bá òun gbé nínú ilé ńlá kan tó háyà. Àwọn ọmọbìnrin méjèèjì yìí, ìyẹn Gladys àti Grace Gregory, wá di míṣọ́nnárì nígbà tó yá. Gladys tó ti lé ní ọmọ àádọ́rùn-ún [90] ọdún báyìí, ṣì ń fi ìṣòtítọ́ sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè Japan.

Nígbà tí mò ń gbé ní ilé Edna, mò ń lọ sípàdé déédéé, mo sì kọ́ bá a ṣe ń wàásù. Torí pé mo lómìnira láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí n sì lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ ó ṣeé ṣe fún mi láti mọ Jèhófà bí mo ṣe fẹ́. Mo ṣèrìbọmi ní June 14, ọdún 1944. Mary àti àwọn ọmọbìnrin Gregory méjèèjì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà wọ́n sì gbà láti lọ wàásù ní àríwá ìpínlẹ̀ Virginia. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, Jèhófà lò wọ́n láti dá ìjọ kan sílẹ̀ ní ìlú Leesburg. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1946, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní ìlú kan tó wà nítòsí ibẹ̀. Nígbà ẹ̀rùn ọdún yẹn, gbogbo wá jọ rìnrìn-àjò lọ sí àpéjọ àgbáyé mánigbàgbé tó wáyé ní ìlú Cleveland, ní ìpínlẹ̀ Ohio, láàárín August 4 sí 11.

Ní àpéjọ yẹn, Arákùnrin Nathan Knorr tó ń múpò iwájú nínú ètò Ọlọ́run nígbà yẹn, sọ àwọn ètò tí wọ́n ti ṣe láti mú Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn gbòòrò sí i. Lára rẹ̀ ni pé wọ́n fẹ́ kọ́ ilé gbígbé tuntun kí wọ́n sì mú ilé ìtẹ̀wé tí wọ́n ń lò gbòòrò sí i. Wọ́n nílò ọ̀pọ̀ arákùnrin tó jẹ́ ọ̀dọ́. Mo pinnu pé ibẹ̀ ni mo ti máa fẹ́ sin Jèhófà. Torí náà, mo gba fọ́ọ̀mù, lẹ́yìn tí mo kọ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tó wà nínú rẹ̀ tán mo fi ránṣẹ́. Láàárín oṣù mélòó kan, ìyẹn ní December 1, ọdún 1946, wọ́n pè mí sí Bẹ́tẹ́lì.

Ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà, alábòójútó ẹ̀ka ìtẹ̀wé, Max Larson, yà lọ́dọ̀ mi ní Ẹ̀ka Ìfìwéránṣẹ́, láti bá mi sọ̀rọ̀. Ó sọ fún mi pé Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn ni màá ti máa ṣiṣẹ́ báyìí. Iṣẹ́ yẹn jẹ́ kí n mọ béèyàn ṣe ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò gan-an àti bí ètò Ọlọ́run ṣe ń ṣiṣẹ́, pàápàá jù lọ nígbà tí mo bá Arákùnrin T. J. (Bud) Sullivan, tó jẹ́ alábòójútó níbẹ̀ ṣiṣẹ́.

Bàbá mi wá kí mi ní Bẹ́tẹ́lì ní ìgbà mélòó kan. Wọ́n ti dàgbà kó tó di pé wọ́n fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn. Lọ́dún 1965 tí wọ́n bẹ̀ mí wò kẹ́yìn, wọ́n sọ pé: “O lè wá kí mi o, àmọ́ mi ò tún ní wá ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ níbí yìí mọ́.” Mo rí i pé èmi náà lọ kí wọn nígbà mélòó kan kí wọ́n tó kú. Ó dá wọn lójú pé ọ̀run ni àwọn máa lọ. Àmọ́, ìrètí mi ni pé kí Jèhófà rántí wọn, bó bá sì rí bẹ́ẹ̀, wọ́n á rí i pé nígbà àjíǹde kì í ṣe ọ̀run táwọn fọkàn sí làwọn wà, bí kò ṣe orí ilẹ̀ ayé níbi tí wọ́n á ti láǹfààní láti máa gbé títí láé nínú Párádísè tí Ọlọ́rùn ń mú bọ̀ wá.

Àwọn Àpéjọ àti Iṣẹ́ Ìkọ́lé Míì Tó Jẹ́ Mánigbàgbé

Àwọn àpéjọ máa ń ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Àwọn àpéjọ àgbáyé tó wáyé láàárín ọdún 1950 sí ọdún 1959, pàápàá jù lọ irú èyí tó wáyé ní Pápá Ìṣeré Yankee ní ìlú New York jẹ́ mánigbàgbé. Nígbà tí apá kan àpéjọ ti ọdún 1958 ń lọ lọ́wọ́, iye àwọn èèyàn tó wà ní Pápá Ìṣeré Yankee àti ní Polo Grounds tí wọ́n ti ń gẹṣin gbá bọ́ọ̀lù jẹ́ ọ̀kẹ́ méjìlá lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàje àti ọ̀rìn dín lẹ́gbẹ̀rún lé méjì [253,922] wọ́n sì wá láti ilẹ̀ tí ó tó mẹ́tàlélọ́gọ́fà [123]. Ohun kan ṣẹlẹ̀ ní àpéjọ àgbáyé yẹn tí mi ò jẹ́ gbàgbé. Nígbà tí mò ń ṣèrànwọ́ ní ọ́fíìsì àpéjọ, Arákùnrin Knorr sáré wá bá mi. Ó sọ pé: “Fred, mi ò mọ bó ṣe ṣẹlẹ̀ àmọ́ mo gbàgbé láti yan arákùnrin tó máa bá gbogbo àwọn aṣáájú-ọ̀nà tí wọ́n ti wà ní gbọ̀ngàn ìjẹun kan tá a háyà nítòsí sọ̀rọ̀. Ǹjẹ́ wàá lè sáré lọ síbẹ̀ kó o sì sọ àsọyé kan tó máa wọni lọ́kàn tó dá lé ohun tó o bá ronú kàn kó o tó débẹ̀?” Ńṣe ni mò ń mí gúlegúle nígbà tí mo débẹ̀, mo sì gbàdúrà lọ́pọ̀ ìgbà lójú ọ̀nà.

Bí iye àwọn ìjọ ṣe ń pọ̀ sí i ní ìlú New York láàárín ọdún 1950 sí ọdún 1969, àwọn ibi tí à ń háyà gẹ́gẹ́ bíi Gbọ̀ngàn Ìjọba kò pọ̀ tó mọ́. Torí náà, láàárín ọdún 1970 sí ọdún 1990, a ra àwọn ilé mẹ́ta ní ìlú Manhattan a sì tún wọn ṣe kí wọ́n lè ṣeé lò fún àwọn ìpàdé wa. Èmi ni alága ìgbìmọ̀ ìkọ́lé tó bójú tó àtúnṣe àwọn ilé náà, ó sì máa ń mú mi lọ́kàn yọ̀ láti rántí ọ̀pọ̀ ìbùkún Jèhófà lórí àwọn ìjọ tó pawọ́ pọ̀ láti fowó ṣètìlẹ́yìn fún kíkọ́ àwọn ilé náà títí tá a fi parí rẹ̀. A ṣì ń lo àwọn ilé wọ̀nyí títí dòní, wọ́n sì wúlò gan-an fún ìjọsìn tòótọ́.

Àwọn Ìyípadà Tó Dé Bá Mi

Ní ọjọ́ kan lọ́dún 1957, bí mo ti ń gba ibi tí wọ́n ń gbé ọkọ̀ sí tó wà láàárín ibùgbé wa ní Bẹ́tẹ́lì àti ilé ìtẹ̀wé lọ síbi iṣẹ́, òjò bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀. Mo rí ọ̀dọ́mọbìnrin arẹwà kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sí Bẹ́tẹ́lì tí àwọ̀ irun rẹ̀ fani mọ́ra, ó ń rìn lọ níwájú mi. Kò ní agbòjò, torí náà mo ní kó jẹ́ ká jọ lo tèmi. Bí mo ṣe bá Marjorie pàdé nìyẹn, látìgbà tá a sì ti ṣègbéyàwó ní ọdún 1960, àwa méjèèjì ti ń fayọ̀ rìn nìṣó lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ní tòjò tẹ̀ẹ̀rùn. A ṣe ayẹyẹ àádọ́ta [50] ọdún tá a ti ṣègbéyàwó ní oṣù September, ọdún 2010.

Gbàrà tá a dé láti ibi tá a ti lọ lo ìsinmi oníyọ̀tọ̀mì lẹ́yìn ìgbéyàwó wa ni Arákùnrin Knorr sọ fún mi pé wọ́n ti yàn mí gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ mà nìyẹn o! Láàárín ọdún 1961 sí ọdún 1965, àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ka tí wọ́n wá gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n á ṣe máa bójú tó ẹ̀ka ọ́fíìsì ló wá sí àwọn kíláàsì gígùn márùn-ún tá a ṣe. Ní apá ìparí ọdún 1965, a tún bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn kíláàsì olóṣù márùn-ún, tó wà fún pípèsè ìdálẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn míṣọ́nnárì.

Ní ọdún 1972, láti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì wọ́n ní kí n lọ sí Ẹ̀ka Tó Ń Fèsì Lẹ́tà, mo sì láǹfààní láti sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó ẹ̀ka náà. Àwọn ìwádìí tí mo ní láti ṣe kí n bàa lè dáhùn oríṣiríṣi ìbéèrè kí n sì wá ojútùú sí àwọn ìṣòro tó bá yọjú ti ràn mí lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye ẹ̀kọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti bí mo ṣe lè fi àwọn ìlànà gíga tó jẹ́ ti Ọlọ́run ran àwọn míì lọ́wọ́.

Lẹ́yìn náà, lọ́dún 1987, wọ́n gbé iṣẹ́ míì fún mi ní Ẹ̀ka Ìpèsè Ìsọfúnni Ilé Ìwòsàn. A ṣètò àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ láti kọ́ àwọn alàgbà tí wọ́n jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn nípa bí wọ́n ṣe lè bá àwọn dókítà, adájọ́ àtàwọn afẹ́dàáfẹ́re sọ̀rọ̀ lórí ohun tá a gbà gbọ́ nípa ẹ̀jẹ̀. Ìṣòro ńlá tó wà nílẹ̀ ni pé lọ́pọ̀ ìgbà àwọn dókítà máa ń gba àṣẹ nílé ẹjọ́ láti fa ẹ̀jẹ̀ sí àwọn ọmọ wa lára, láìgbàṣẹ lọ́wọ́ àwọn òbí.

Bí a bá ti dábàá fún àwọn dókítà pé kí wọ́n lo ìtọ́jú tí kò la ẹ̀jẹ̀ lọ, ohun tí wọ́n sábà máa ń sọ ni pé kò sírú ìtọ́jú bẹ́ẹ̀ tàbí kí wọ́n sọ pé ó ti wọ́n jù. Bí dókítà oníṣẹ́ abẹ kan bá sọ bẹ́ẹ̀ fún mi, mo sábà máa ń sọ pé: “Jọ̀wọ́, na ọwọ́ rẹ.” Bó bá sì ti ṣe bẹ́ẹ̀, màá wá sọ fún un pé: “O mọ̀ pé o lè fi ọwọ́ tó o nà yẹn ṣe ojúlówó iṣẹ́ abẹ tí kò la ẹ̀jẹ̀ lọ.” Ọ̀rọ̀ yìí máa rán an létí ohun tó mọ̀ dáadáa, ìyẹn sì ni pé bó bá fi ìṣọ́ra lo ọ̀bẹ tó fi ń ṣiṣẹ́ abẹ, kò ní fi ẹ̀jẹ̀ ṣòfò.

Láàárín ogún ọdún tó ti kọjá, Jèhófà ti rọ̀jò ìbùkún rẹ̀ sórí ìsapá wa láti dá àwọn dókítà àti àwọn adájọ́ lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìtọ́jú tí kò la ẹ̀jẹ̀ lọ. Ìwà wọn yí pa dà gan-an lẹ́yìn tí wọ́n túbọ̀ lóye ohun tá a gbà gbọ́. Wọ́n wá mọ̀ pé ìwádìí ìṣègùn ti fi hàn pé ìtọ́jú ìṣègùn tí kò la ẹ̀jẹ̀ lọ máa ń ṣiṣẹ́ àti pé ọ̀pọ̀ dókítà ló ti ṣe tán láti tọ́jú aláìsàn láì lo ẹ̀jẹ̀, ọ̀pọ̀ ilé ìwòsàn ló sì wà tèèyàn lè gbé aláìsàn tó bá nílò irú ìtọ́jú bẹ́ẹ̀ lọ.

Láti ọdún 1996, èmi àti Marjorie ti ń sìn ní Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower tó wà ní Patterson, ní ìlú New York, tó fi nǹkan bí àádọ́fà [110] kìlómítà jìn sí àríwá Brooklyn. Nígbà tí mo débẹ̀, mo kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn fúngbà díẹ̀, lẹ́yìn náà ni mo kópa nínú kíkọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ka àtàwọn alábòójútó arìnrìn-àjò lẹ́kọ̀ọ́. Láti ọdún méjìlá sẹ́yìn, mo tún ti ní àǹfààní láti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí alábòójútó Ẹ̀ka Tó Ń Fèsì Lẹ́tà, èyí tí wọ́n ti gbé láti Brooklyn lọ sí Patterson báyìí.

Àwọn Ìṣòro Ọjọ́ Ogbó

Ó ti túbọ̀ ń nira fún mi láti bójú tó àwọn ojúṣe mi ní Bẹ́tẹ́lì báyìí torí pé mo ti lé lọ́mọ ọgọ́rin [80] ọdún. Ó ti lé ní ọdún mẹ́wàá tí àrùn jẹjẹrẹ ti ń bá mi fínra. Ńṣe lọ̀rọ̀ mi dà bíi ti Hesekáyà tí Jèhófà fi kún gígùn ìwàláàyè rẹ̀. (Aísá. 38:5) Ara ìyàwó mi náà ò le bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, àwa méjèèjì sì ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti kojú àrùn tó ń múni ṣarán èyí tó ń ṣe é. Ìránṣẹ́ Jèhófà tó dáńgájíá ni Marjorie, ó máa ń gba àwọn ọ̀dọ́ nímọ̀ràn, ó sì jẹ́ olùrànlọ́wọ́ tí kì í jáni kulẹ̀ àti adúróṣinṣin ọ̀rẹ́ fún èmi náà. Ó fẹ́ràn láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì mọ bá a ṣeé fi Bíbélì kọ́ni. Ọ̀pọ̀ àwọn tó tipasẹ̀ wa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣì máa ń kàn sí wa.

Àbúrò bàbá mi, ìyẹn Mary, kú ní March 2010 ní ọmọ ọdún mẹ́tàdínláàádọ́rùn-ún [87]. Olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó dáńgájíá lòun náà ó sì ran àwọn míì lọ́wọ́ láti máa ṣe ìjọsìn tòótọ́. Ó lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Mò ń dúpẹ́ gan-an pé ó ràn mí lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí èmi náà lè di ìránṣẹ́ Jèhófà, Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ bíi tirẹ̀. Wọ́n sin Mary sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọkọ rẹ̀, tóun náà ti ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì rí nílẹ̀ Ísírẹ́lì. Ó dá mi lójú pé Jèhófà kò ní gbàgbé wọn, mo sì nírètí pé ó máa jí wọn dìde.

Bí mo bá wẹ̀yìn pa dà sí ohun tó lé ní ọdún mẹ́tàdínláàádọ́rin [67] tí mo ti ń sin Jèhófà, mo máa ń dúpẹ́ fún ìbùkún yanturu tí mo ti rí gbà. Iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ti fún mi láyọ̀! Mo ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀, mo sì nírètí tó dájú pé ìlérí tí Ọmọ rẹ̀ ṣe máa ṣẹ sí èmi náà lára pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ti fi àwọn ilé tàbí àwọn arákùnrin tàbí àwọn arábìnrin tàbí baba tàbí ìyá tàbí àwọn ọmọ tàbí àwọn ilẹ̀ sílẹ̀ nítorí orúkọ mi yóò rí gbà ní ìlọ́po-ìlọ́po sí i, yóò sì jogún ìyè àìnípẹ̀kun.”Mát. 19:29.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ A ṣe é ní ọdún 1942 àmọ́ a kò tẹ̀ ẹ́ mọ́ báyìí.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Èmi rèé lọ́dún 1928, ní oko tí bàbá mi àgbà ti ń gbin òwú ní ìpínlẹ̀ Georgia ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Àbúrò bàbá mi, Mary àti ẹ̀gbọ́n màmá mi àgbà Talmadge rèé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Mary, Gladys àti Grace rèé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Ìgbà tí mo ṣèrìbọmi, June 14, ọdún 1944

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Ìgbà tí mò ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn ní Bẹ́tẹ́lì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Èmi àti Mary rèé ní àpéjọ àgbáyé tó wáyé lọ́dún 1958 ní Pápá Ìṣeré Yankee

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Èmi àti Marjorie rèé lọ́jọ́ tá a ṣègbéyàwó

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Àwa méjèèjì rèé lọ́dún 2008