Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe láti pinnu wákàtí náà gan-an tí wọ́n kan Jésù Kristi mọ́gi?

Kí ló fà á tí ìbéèrè yìí fi wáyé? Ìdí ni pé Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Máàkù àti Jòhánù láti kọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ikú Jésù sínú ìwé Ìhìn Rere, àmọ́ ó jọ pé àlàyé tí wọ́n ṣe yàtọ̀ síra. Máàkù sọ pé: “Ó ti di wákàtí kẹta nísinsìnyí, wọ́n [àwọn ọmọ ogun] sì kàn án mọ́gi.” (Máàkù 15:25) Ṣùgbọ́n Jòhánù sọ pé, “ó jẹ́ nǹkan bí wákàtí kẹfà,” Pílátù sì fa Jésù lé àwọn Júù lọ́wọ́ pé kí wọ́n lọ kàn án mọ́gi. (Jòh. 19:14-16) Àwọn tó máa ń ṣàlàyé lórí Bíbélì ti sapá láti wá ojútùú sí apá tó jọ pé ó yàtọ̀ síra yìí, torí náà wọ́n ti ṣe ọ̀pọ̀ àlàyé lórí gbólóhùn náà. Àmọ́, kò sí ìsọfúnni tó pọ̀ tó nínú Ìwé Mímọ́ tá a lè fi ṣàlàyé ìyàtọ̀ tó wà nínú àkọsílẹ̀ méjèèjì. Síbẹ̀, ohun kan tó lè ràn wá lọ́wọ́ ni pé ká ṣe àgbéyẹ̀wò ọ̀nà táwọn èèyàn ń gbà ka àkókò nígbà yẹn.

Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni, wákàtí méjìlá làwọn Júù pín ojúmọmọ sí, wọ́n sì máa ń ka wákàtí náà bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà yíyọ oòrùn. (Jòh. 11:9) Torí náà, “wákàtí kẹta” máa ń jẹ́ láti aago mẹ́jọ òwúrọ̀ sí aago mẹ́sàn-án òwúrọ̀, “wákàtí kẹfà” sì máa ń parí sí nǹkan bí agogo méjìlá ọ̀sán. Àmọ́ ṣá o, ìgbà tí oòrùn máa ń yọ àti ìgbà tó máa ń wọ̀ láàárín ọdún máa ń yàtọ̀ síra. Torí náà, bí ojúmọmọ ṣe máa ń gùn tó máa ń sinmi lórí ìgbà tó bá jẹ́ nínú ọdún. Ibi tí oòrùn bá sì dojú kọ ni wọ́n fi máa ń pinnu wákàtí tí wọ́n wà. Torí náà, ńṣe ni wọ́n máa ń fojú díwọ̀n àkókò. Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì sọ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní wákàtí kẹta, ìkẹfà, tàbí ìkẹsàn-án, èyí tó sábà máa ń túmọ̀ sí pé nǹkan bíi wákàtí yẹn ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé. (Mát. 20:3, 5; Ìṣe 10:3, 9, 30) Àmọ́, Ìwé Mímọ́ sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní wákàtí kan pàtó, irú bíi ní “wákàtí keje,” kìkì nígbà tó pọn dandan pé kó ṣe bẹ́ẹ̀ látàrí ohun tó ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.—Jòh. 4:52.

Ohun táwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sọ nípa àkókò àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé bára mu. Gbogbo wọ́n ṣàlàyé pé àwọn àlùfáà àtàwọn àgbà ọkùnrin pàdé pọ̀ ní kùtùkùtù òwúrọ̀ wọ́n sì mú Jésù lọ sọ́dọ̀ Pọ́ńtíù Pílátù, Gómìnà ìlú Róòmù. (Mát. 27:1; Máàkù 15:1; Lúùkù 22:66; Jòh. 18:28) Mátíù, Máàkù àti Lúùkù ròyìn pé láti wákàtí kẹfà, lẹ́yìn tí wọ́n ti gbé Jésù kọ́ sórí òpó igi, òkùnkùn ṣú bo ilẹ̀ náà, “títí di wákàtí kẹsàn-án.”—Mát. 27:45, 46; Máàkù 15:33, 34; Lúùkù 23:44.

Ohun pàtàkì kan tó ṣeé ṣe kó nípa lórí ojú tí òǹkọ̀wé kan á fi wo ìgbà tí wọ́n kan Jésù mọ́gi rèé: Kí wọ́n tó kan ọ̀daràn kan mọ́gi, wọ́n kọ́kọ́ máa ń nà án lẹ́gba. Nínà yìí máa ń burú nígbà míì débi pé orí rẹ̀ ni ọ̀daràn náà máa kú sí. Wọ́n ti ní láti na Jésù gan-an, tó fi di pé ó pọn dandan kí ọkùnrin míì bá a gbé òpó igi oró rẹ̀ lẹ́yìn tóun fúnra rẹ̀ ti kọ́kọ́ gbé e. (Lúùkù 23:26; Jòh. 19:17) Bó bá jẹ́ pé ìgbà tí wọ́n na Jésù yẹn ni àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣírò àkókò tí wọ́n kàn án mọ́gi, àkókò díẹ̀ ti ní láti kọjá kí àwọn ọmọ ogun tó kàn án mọ́gi ní ti gidi. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, àkókò táwọn èèyàn á sọ pé wọ́n kan Jésù mọ́gi máa yàtọ̀ síra, ìyẹn sì sinmi lórí ìgbà tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í ka àkókò náà láàárín ìgbà tí wọ́n nà án àti ìgbà tí wọ́n kàn án mọ́gi.

Ọ̀pọ̀ ọdún ti kọjá lẹ́yìn táwọn òǹkọ̀wé Ìhìn Rere yòókù kọ ìwé tiwọn kí Jòhánù tó kọ tirẹ̀. Torí náà, ó lè rí àkọsílẹ̀ tiwọn kà. Òótọ́ ni pé àkókò tí Jòhánù sọ pé wọ́n kan Jésù mọ́gi yàtọ̀ sí ti Máàkù. Àmọ́, èyí jẹ́ ẹ̀rí tó ṣe kedere pé Jòhánù kò wulẹ̀ da àkọsílẹ̀ Máàkù kọ. Ọlọ́run ló mí sí ohun táwọn méjèèjì kọ. Bí kò tilẹ̀ sí ìsọfúnni tó pọ̀ tó nínú Ìwé Mímọ́ tá a lè fi ṣàlàyé ohun tó fa ìyàtọ̀ náà, a lè ní ìgbọ́kànlé nínú àwọn ohun tí ìwé Ìhìn Rere sọ.