Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Kọ́ Àwọn Míì Kí Wọ́n Lè Tóótun Fún Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn

Ẹ Kọ́ Àwọn Míì Kí Wọ́n Lè Tóótun Fún Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn

Ẹ Kọ́ Àwọn Míì Kí Wọ́n Lè Tóótun Fún Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn

“Gbogbo ẹni tí a fún ní ìtọ́ni lọ́nà pípé yóò dà bí olùkọ́ rẹ̀.”—LÚÙKÙ 6:40.

1. Báwo ni Jésù ṣe fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún iṣẹ́ ìwàásù nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé?

 KÍ ÀPỌ́SÍTÉLÌ JÒHÁNÙ tó parí ìwé Ìhìn Rere tó kọ, ó kọ̀wé pé: “Ní ti tòótọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan mìíràn wà pẹ̀lú tí Jésù ṣe, tí ó jẹ́ pé, bí a bá ní láti kọ̀wé kúlẹ̀kúlẹ̀ wọn ní kíkún, mo rò pé, ayé tìkára rẹ̀ kò ní lè gba àwọn àkájọ ìwé tí a bá kọ.” (Jòh. 21:25) Lára àwọn nǹkan tí Jésù gbé ṣe lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó fi àkókò kúkúrú ṣe àmọ́ tó jẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ aláápọn ni pé ó wá àwọn èèyàn, ó fún wọn ní ìdálẹ́kọ̀ọ́, ó sì ṣètò àwọn ọkùnrin tí yóò máa mú ipò iwájú lẹ́yìn tó bá ti parí iṣẹ́ rẹ̀ láyé. Torí náà, nígbà tó pa dà sókè ọ̀run ní ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àwùjọ àwọn èèyàn tó kó jọ láti máa ṣiṣẹ́ ìwàásù yìí yára gbèrú di ẹgbẹẹgbẹ̀rún.—Ìṣe 2:41, 42; 4:4; 6:7.

2, 3. (a) Kí nìdí tó fi túbọ̀ ṣe pàtàkì pé kí àwọn ọkùnrin tó ti ṣèrìbọmi sapá kí wọ́n lè tóótun fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

2 Ní báyìí, àwọn tó ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ti lé ní mílíọ̀nù méje, wọ́n sì wà ní àwọn ìjọ tó lé ní ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] jákèjádò ayé, torí náà, a túbọ̀ nílò àwọn ọkùnrin tí yóò máa múpò iwájú nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, a nílò àwọn alàgbà púpọ̀ sí i. Ó yẹ ká gbóríyìn fún àwọn tó bá sapá láti tóótun fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn yìí torí pé ‘iṣẹ́ àtàtà ni wọ́n ń fẹ́.’—1 Tím. 3:1.

3 Àmọ́ ṣá o, àwọn ọkùnrin kì í ṣàdédé tóótun fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ. Ẹ̀kọ́ ìwé tàbí ìrírí tí ọkùnrin kan ní nígbèésí ayé kò sì tó láti mú kó tóótun fún irú iṣẹ́ yìí. Kí ọkùnrin kan tó lè ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ ó gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tí Ìwé Mímọ́ béèrè. Kì í ṣe béèyàn ṣe mọ nǹkan ṣe sí tàbí àwọn ohun téèyàn ti gbé ṣe ló máa ń mú kéèyàn tóótun bí kò ṣe àwọn ànímọ́ tó bá Ìwé Mímọ́ mu. Báwo la ṣe lè ran àwọn ọkùnrin tó wà nínú ìjọ lọ́wọ́ kí wọ́n lè tóótun? Jésù sọ pé: “Gbogbo ẹni tí a fún ní ìtọ́ni lọ́nà pípé yóò dà bí olùkọ́ rẹ̀.” (Lúùkù 6:40) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí Àgbà Olùkọ́ náà, Jésù Kristi gbà ran àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè tóótun fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn púpọ̀ sí i àti àwọn ohun tá a lè rí kọ́ nínú ohun tí Jésù ṣe.

“Mo Pè Yín Ní Ọ̀rẹ́”

4. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun jẹ́ ọ̀rẹ́ àtàtà fáwọn ọmọ ẹ̀yìn òun?

4 Jésù kò bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lò bíi pé ó sàn jù wọ́n lọ, ńṣe ló bá wọn lò bí ọ̀rẹ́. Ó máa ń wà pẹ̀lú wọn, ó fọkàn tán wọn, ó sì ‘jẹ́ kí wọ́n mọ gbogbo nǹkan tó ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba rẹ̀.’ (Ka Jòhánù 15:15.) Ẹ sì wo bí ọkàn wọn ti kún fún ayọ̀ tó nígbà tí Jésù dáhùn ìbéèrè wọn pé: “Kí ni yóò sì jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?” (Mát. 24:3, 4) Ó tún máa ń sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ àti bí nǹkan bá ṣe rí lára rẹ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ ní alẹ́ ọjọ́ tí wọ́n mú Jésù, ó mú Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù lọ sínú ọgbà Gẹtisémánì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní ẹ̀dùn ọkàn gidigidi, ó gbàdúrà látọkànwá nígbà tí wọ́n débẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí àwọn àpọ́sítélì mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà máà gbọ́ ohun tí Jésù sọ nígbà tó ń gbàdúrà, àmọ́ wọ́n ti ní láti fòye mọ̀ pé Jésù ní ẹ̀dùn ọkàn tó pọ̀. (Máàkù 14:33-38) Tún ronú nípa bí ìyípadà ológo tó wáyé ṣáájú ìgbà yẹn ti ní láti fún àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lókun tó. (Máàkù 9:2-8; 2 Pét. 1:16-18) Bí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mú kí wọ́n ní okun tó pọ̀ tó láti bójú tó iṣẹ́ ńlá tí Jésù gbé lé wọn lọ́wọ́.

5. Kí ni díẹ̀ lára ọ̀nà tí àwọn alàgbà ìjọ lè gbà ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́?

5 Bíi ti Jésù, àwọn alàgbà ìjọ máa ń bá àwọn míì dọ́rẹ̀ẹ́, wọ́n sì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Wọ́n máa ń ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ nípa wíwá àkókò láti tẹ́tí gbọ́ wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alàgbà mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n máa pa àṣírí mọ́, wọn kì í ṣe ohun tó bá yẹ kí wọ́n sọ fún àwọn ará ní ọ̀rọ̀ àṣírí. Àwọn alàgbà máa ń fọkàn tán àwọn ará, wọ́n sì máa ń bá wọn sọ̀rọ̀ tó dá lórí ohun táwọn fúnra wọn ti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ látinú Ìwé Mímọ́. Àwọn alàgbà kì í bá ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan tó ṣeé ṣe kó máà tó wọn lọ́jọ́ orí lò bíi pé wọ́n sàn jù ú lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń wò ó gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin tẹ̀mí tó ní ànímọ́ tó mú kó máa ṣe iṣẹ́ ìsìn tó ń ṣe ìjọ láǹfààní.

“Mo Fi Àwòṣe Lélẹ̀ fún Yín”

6, 7. Ṣàpèjúwe àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àti ipa tí èyí ní lórí wọn.

6 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù mọrírì àwọn nǹkan tó bá jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run, àṣà ìbílẹ̀ wọn àti bí wọ́n ṣe tọ́ wọn dàgbà máa ń nípa lórí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ronú nígbà mìíràn. (Mát. 19:9, 10; Lúùkù 9:46-48; Jòh. 4:27) Àmọ́, Jésù kì í ṣe àríwísí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tàbí kó máa dúnkookò mọ́ wọn. Kì í fúngun mọ́ wọn pé kí wọ́n máa ṣe àwọn nǹkan tí apá wọn ò ká, kì í sì í sọ fún wọn pé kí wọ́n ṣe ohun kan kí òun fúnra rẹ̀ wá máa ṣe ohun mìíràn. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù kọ́ wọn nípa fífi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún wọn.—Ka Jòhánù 13:15.

7 Irú àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀? (1 Pét. 2:21) Kó lè rọrùn fún un láti ṣèránṣẹ́ fún àwọn ẹlòmíì, kò kó àwọn ohun ìní tara jọ. (Lúùkù 9:58) Jésù mọ̀wọ̀n ara rẹ̀, ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ ló sì ń kọ́ àwọn èèyàn. (Jòh. 5:19; 17:14, 17) Ó ṣeé sún mọ́, ó sì jẹ́ onínúure. Ìfẹ́ ló mú kó ṣe gbogbo ohun tó ṣe. (Mát. 19:13-15; Jòh. 15:12) Àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́ gan-an ni. Bí àpẹẹrẹ, Jákọ́bù kò ṣojo nígbà tó dojú kọ ikú àmọ́ ó jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run títí tí wọ́n fi pa á. (Ìṣe 12:1, 2) Jòhánù tẹ̀ lé ipasẹ̀ Jésù láìyẹsẹ̀ fún ohun tó lé ní ọgọ́ta [60] ọdún.—Ìṣí. 1:1, 2, 9.

8. Àpẹẹrẹ wo ni àwọn alàgbà ń fi lélẹ̀ fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin àtàwọn mìíràn?

8 Àwọn alàgbà ń fi àpẹẹrẹ táwọn ọ̀dọ́kùnrin nílò lélẹ̀ fún wọn nípa jíjẹ́ ẹni tó ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ, onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni tó ń fìfẹ́ báni lò. (1 Pét. 5:2, 3) Síwájú sí i, inú àwọn alàgbà tí wọ́n jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ nínú ìgbàgbọ́, nínú kíkọ́ni, nínú bó ṣe yẹ káwọn Kristẹni máa gbé ìgbé ayé wọn àti lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ máa ń dùn bí wọ́n bá mọ̀ pé àwọn mìíràn lè fara wé ìgbàgbọ́ àwọn.—Héb. 13:7.

‘Jésù fún Wọn Ní Àṣẹ Ìtọ́ni Ó sì Rán Wọn Jáde’

9. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere?

9 Lẹ́yìn tí Jésù ti fìtara lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ fún nǹkan bí ọdún méjì, ó mú kí iṣẹ́ ìwàásù náà gbòòrò sí i nípa rírán àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá jáde láti lọ wàásù. Àmọ́, ó kọ́kọ́ fún wọn ní ìtọ́ni. (Mát. 10:5-14) Kí Jésù tó ṣe iṣẹ́ ìyanu tó fi bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bó ṣe fẹ́ kí wọ́n to àwọn èèyàn náà àti bí wọ́n ṣe máa pín oúnjẹ fún wọn. (Lúùkù 9:12-17) Ó ṣe kedere nígbà náà pé Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nípa fífún wọn ní ìtọ́ni pàtó tó sì ṣe kedere. Ọ̀nà tó gbà kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ yìí àti ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run wá mú kí àwọn àpọ́sítélì tóótun lẹ́yìn náà tí wọ́n fi lè ṣètò iṣẹ́ ìwàásù gbígbòòrò tó wáyé ní ọdún 33 Sànmánì Kristẹni àti lẹ́yìn ìgbà náà.

10, 11. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà máa fún àwọn ẹni tuntun ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé?

10 Lónìí, ìgbà tí ọkùnrin kan bá gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í gba ìtọ́ni látinú Ìwé Mímọ́. Bí kò bá mọ̀wé kà, a lè ràn án lọ́wọ́ láti mọ̀ ọ́n kà dáadáa. A óò tún máa ràn án lọ́wọ́ sí i bá a ṣe ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tó bá bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ déédéé, á túbọ̀ máa lóye Ìwé Mímọ́, á di ẹni tó ń ṣiṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, á di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Lẹ́yìn ìrìbọmi, ó tún lè gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nípa bá a ṣe ń ṣàtúnṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bó bá yá, arákùnrin náà máa mọ àwọn ohun tó yẹ kó ṣe kó bàa lè tóótun gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.

11 Bí alàgbà kan bá ń yan iṣẹ́ fún arákùnrin kan tó ti ṣèrìbọmi, inú alàgbà bẹ́ẹ̀ máa ń dùn láti ṣàlàyé fún un nípa ọ̀nà tí ètò Ọlọ́run fẹ́ ká máa gbà ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, á sì tún fún un láwọn ìtọ́ni tó nílò. Ó ṣe pàtàkì pé kí arákùnrin tó ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà mọ ohun tó yẹ kóun ṣe. Bó bá ṣòro fún un láti ṣe iṣẹ́ tí wọ́n ní kó ṣe, alàgbà tó nífẹ̀ẹ́ kò ní tètè torí ìyẹn sọ pé kò tóótun. Kàkà bẹ́ẹ̀, alàgbà náà á fi pẹ̀lẹ́tù ṣàlàyé àwọn ibi tó bá kù sí fún un á sì tún àlàyé ṣe nípa ohun tó fẹ́ kó ṣe àti ọ̀nà tó máa gbà ṣe é. Inú àwọn alàgbà máa ń dùn bí wọ́n bá rí àwọn ọkùnrin tó ń tẹ̀ lé ìtọ́ni tí wọ́n fún wọn torí wọ́n mọ̀ pé wọ́n máa láyọ̀ bí wọ́n ti ń sin àwọn ẹlòmíì.—Ìṣe 20:35.

“Ẹni Tí Ń Fetí sí Ìmọ̀ràn Ni Ọlọ́gbọ́n”

12. Kí ló fà á tí ìmọ̀ràn Jésù fi máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́?

12 Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nípa fífún wọn ní ìmọ̀ràn tó bá rí i pé wọ́n nílò. Bí àpẹẹrẹ, ó bá Jákọ́bù àti Jòhánù wí lọ́nà mímúná torí pé wọ́n fẹ́ láti pe iná sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run kó sì jó àwọn ará Samáríà kan tí kò gba Jésù sílé run. (Lúùkù 9:52-55) Nígbà tí ìyá Jákọ́bù àti Jòhánù wá bá àwọn ọmọ rẹ̀ sọ fún Jésù pé kó jẹ́ kí wọ́n jókòó sí ipò ọlá nínú Ìjọba Ọlọ́run, Jésù sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì pé: “Jíjókòó yìí ní ọwọ́ ọ̀tún mi àti ní òsì mi kì í ṣe tèmi láti fi fúnni, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti àwọn tí a ti pèsè rẹ̀ sílẹ̀ fún láti ọwọ́ Baba mi.” (Mát. 20:20-23) Ìgbà gbogbo ni ìmọ̀ràn tí Jésù ń fúnni máa ń ṣe kedere, ó máa ń mọ́gbọ́n dání, ó sì máa ń bá àwọn ìlànà inú Ìwé Mímọ́ mu. Ó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti máa ronú lórí irú àwọn ìlànà bẹ́ẹ̀. (Mát. 17:24-27) Jésù tún mọ ibi tí agbára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mọ kì í sì í retí pé kí wọ́n ṣe nǹkan lọ́nà pípé. Ojúlówó ìfẹ́ tó ní sí wọn ló máa ń mú kó gbà wọ́n nímọ̀ràn.—Jòh. 13:1.

13, 14. (a) Ta ló nílò ìmọ̀ràn? (b) Fúnni ní àpẹẹrẹ irú ìmọ̀ràn tí alàgbà kan lè fún ẹnì kan tí kò tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.

13 Bí ọkùnrin èyíkéyìí bá ń sapá láti tóótun fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ, ìgbà kan máa wà tó máa nílò ìmọ̀ràn látinú Ìwé Mímọ́. Ìwé Òwe 12:15 sọ pé: “Ẹni tí ń fetí sí ìmọ̀ràn ni ọlọ́gbọ́n.” Ọ̀dọ́kùnrin kan sọ pé: “Àìpé mi ni ìṣòro tó ń dà mí láàmú jù lọ, mi ò sì mọ ohun tí màá ṣe nípa rẹ̀. Ìmọ̀ràn tí alàgbà kan fún mi ló jẹ́ kí n máa fojú tó tọ́ wo ara mi.”

14 Bí àwọn alàgbà bá kíyè sí i pé ìwà kan tí ń kọni lóminú ni kò jẹ́ kí arákùnrin kan tẹ̀ síwájú, wọ́n lè lo ìdánúṣe láti fi ẹ̀mí tútù ràn án lọ́wọ́. (Gál. 6:1) Nígbà míì, ẹnì kan lè nílò ìmọ̀ràn torí irú ìwà tó ń hù. Bí àpẹẹrẹ, bó bá dà bíi pé arákùnrin kan kì í ṣe tó bó ṣe lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, alàgbà kan lè rí i pé ó dára kóun ṣàlàyé fún un pé Jésù fìtara polongo Ìjọba Ọlọ́run, ó sì pàṣẹ pé káwọn ọmọlẹ́yìn òun sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 28:19, 20; Lúùkù 8:1) Bó bá dà bíi pé arákùnrin kan ń wá ipò ọlá, alàgbà kan lè fi hàn án bí Jésù ṣe jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rí ewu tó wà nínú kéèyàn máa wá ipò ọlá. (Lúùkù 22:24-27) Bí arákùnrin kan kì í bá fẹ́ láti dárí jini ńkọ́? Àkàwé nípa ẹrú tí kò dárí gbèsè kékeré tí wọ́n jẹ ẹ́ jini bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti dárí gbèsè tó pọ̀ ji òun fúnra rẹ̀ máa ràn án lọ́wọ́ gan-an ni. (Mát. 18:21-35) Bó bá yẹ kí alàgbà fún ẹnì kan ní ìmọ̀ràn, ó máa dára jù lọ kó ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó bá kọ́kọ́ láǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀.—Ka Òwe 27:9.

“Máa Kọ́ Ara Rẹ”

15. Báwo ni àwọn tó wà nínú ìdílé ọkùnrin kan ṣe lè ràn án lọ́wọ́ kó lè tóótun láti sin àwọn ẹlòmíì?

15 Àwọn alàgbà lè múpò iwájú nínú fífún àwọn ọkùnrin ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè sapá láti tóótun fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn, àmọ́ àwọn míì náà lè kọ́wọ́ tì wọ́n. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó wà nínú ìdílé ọkùnrin kan lè ràn án lọ́wọ́ kó lè tóótun láti sin àwọn ẹlòmíràn ó sì yẹ kí wọ́n ràn án lọ́wọ́. Bó bá sì ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà, àǹfààní ńlá ló máa jẹ́ fún un bí ìyàwó rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ bá ń tì í lẹ́yìn. Kó bàa lè ṣàṣeyọrí, ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n fínnú-fíndọ̀ gbà pé kó lò lára àkókò tó yẹ kó fi wà pẹ̀lú wọn láti ṣe ojúṣe rẹ̀ nínú ìjọ. Àwọn mìíràn á mọrírì ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tí wọ́n fi hàn yìí gidigidi, á sì mú kí òun náà láyọ̀.—Òwe 15:20; 31:10, 23.

16. (a) Ọwọ́ ta ló kù sí fún ẹnì kan láti sapá kó lè tóótun fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn? (b) Báwo ni ọkùnrin kan ṣe lè sapá kó lè tóótun fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ?

16 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn míì lè ran ọkùnrin náà lọ́wọ́ kí wọ́n sì kọ́wọ́ tì í, òun fúnra rẹ̀ ló máa sapá kó lè tóótun fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn. (Ka Gálátíà 6:5.) Kò pọn dandan kí arákùnrin kan jẹ́ ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà kó tó lè ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ tàbí kó tó lè máa kópa ní kíkún nínú iṣẹ́ ìwàásù. Àmọ́, ohun tó túmọ̀ sí láti máa sapá kéèyàn lè tóótun fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn ni pé kó máa làkàkà láti ní àwọn ànímọ́ tí Ìwé Mímọ́ sọ pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ gbọ́dọ̀ ní. (1 Tím. 3:1-13; Títù 1:5-9; 1 Pét. 5:1-3) Torí náà, bí ọkùnrin kan bá fẹ́ láti sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà àmọ́ tí wọn kò tíì yàn án sípò láti sìn, ó yẹ kó ṣiṣẹ́ lórí àwọn apá ibi tó bá ti yẹ kó tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Èyí gba pé kó máa ka Bíbélì déédéé, kó máa fi taratara dá kẹ́kọ̀ọ́, kó máa ṣe àṣàrò gan-an, kó máa gbàdúrà látọkànwá, kó sì máa fìtara lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù. Lọ́nà yìí, á máa fi ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún Tímótì sílò, ó ní: “Máa kọ́ ara rẹ pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìfojúsùn rẹ.”—1 Tím. 4:7.

17, 18. Kí ni arákùnrin kan tó ti ṣèrìbọmi lè ṣe bó bá ń ṣàníyàn, tó ń lérò pé òun kò tóótun, tàbí tí kò wù ú láti sìn?

17 Bó bá ṣẹlẹ̀ pé arákùnrin kan kò sapá láti tóótun fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn torí pé ó ń ṣàníyàn tàbí tó ń lérò pé òun kò tóótun ńkọ́? Ó máa dára kó ronú lórí ọ̀pọ̀ nǹkan tí Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi ti ṣe fún wa. Ó ṣe tán, Jèhófà “ń bá wa gbé ẹrù [wa] lójoojúmọ́.” (Sm. 68:19) Torí náà, Baba wa ọ̀run lè ran arákùnrin kan lọ́wọ́ kó lè tóótun fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ. Bí arákùnrin kan ò bá sì tíì máa sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà, ó dára kó rántí pé a nílò àwọn ọkùnrin púpọ̀ sí i tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn tí wọ́n á fẹ́ láti tẹ́wọ́ gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ètò Ọlọ́run. Bí arákùnrin kan bá ronú lórí irú kókó yìí, ìyẹn lè mú kó sapá láti borí èrò tí kò tọ́. Ó lè gbàdúrà fún ẹ̀mí mímọ́, kó sì ní in lọ́kàn pé lára èso rẹ̀ ni àlàáfíà àti ìkóra-ẹni-níjàánu, tí wọ́n jẹ́ àwọn ànímọ́ tó máa ràn án lọ́wọ́ láti borí àníyàn tàbí èrò pé òun kò tóótun. (Lúùkù 11:13; Gál. 5:22, 23) Èyí á sì mú kéèyàn ní ìdánilójú pé Jèhófà máa bù kún gbogbo àwọn tí èrò tó tọ́ bá sún láti sapá kí wọ́n lè tóótun fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn.

18 Àbí ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni kò wu ẹnì kan tó ti ṣèrìbọmi láti sapá kó lè tóótun fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn? Bí kò bá wu arákùnrin kan láti sìn, kí ló lè ràn án lọ́wọ́? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ọlọ́run . . . ń gbéṣẹ́ ṣe nínú yín, nítorí ti ìdùnnú rere rẹ̀, kí ẹ lè fẹ́ láti ṣe, kí ẹ sì gbé ìgbésẹ̀.” (Fílí. 2:13) Ọlọ́run ló máa ń jẹ́ kó wuni láti sìn, ẹ̀mí Jèhófà sì lè fún ẹnì kan ní agbára láti ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́. (Fílí. 4:13) Síwájú sí i, Kristẹni kan lè gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ran òun lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó tọ́.—Sm. 25:4, 5.

19. Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ náà pé a óò gbé ‘olùṣọ́ àgùntàn méje, bẹ́ẹ̀ ni, mọ́gàjí mẹ́jọ’ dìde mú kó dá wa lójú?

19 Jèhófà máa ń bù sí ìsapá àwọn àgbà ọkùnrin tí wọ́n ń fún àwọn mìíràn ní ìdálẹ́kọ̀ọ́. Àwọn tó bá gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n fún wọn tí wọ́n sì sapá láti tóótun fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ tún máa ń rí ìbùkún rẹ̀ gbà. Ìwé Mímọ́ mú kó dá wa lójú pé láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run, ‘olùṣọ́ àgùntàn méje, bẹ́ẹ̀ ni, mọ́gàjí mẹ́jọ,’ èyí tó ń tọ́ka sí iye àwọn èèyàn tó tóótun tá a nílò, ní a óò gbé dìde láti máa múpò iwájú nínú ètò Jèhófà. (Míkà 5:5) Ìbùkún ńlá ló jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ Kristẹni là ń fún ní ìdálẹ́kọ̀ọ́, àwọn náà sì ń fi ìrẹ̀lẹ̀ sapá láti tóótun fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn, èyí sì ń mú ìyìn wá fún Jèhófà!

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Báwo ni Jésù ṣe mú kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tóótun fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn púpọ̀ sí i?

• Báwo ni àwọn alàgbà ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù bí wọ́n ṣe ń ran àwọn ọkùnrin tó wà nínú ìjọ lọ́wọ́ láti múpò iwájú?

• Ipa wo làwọn tó wà nínú ìdílé ọkùnrin kan lè kó láti mú kó tóótun fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn?

• Kí ni ọkùnrin kan fúnra rẹ̀ lè ṣe kó bàa lè tóótun fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Ìdálẹ́kọ̀ọ́ wo lo lè fún ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bó ṣe ń sapá láti tẹ̀ síwájú?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

Báwo ni àwọn ọkùnrin ṣe lè fi hàn pé àwọn ń sapá láti tóótun fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn?