A Jẹ́ “Olùgbé Fún Ìgbà Díẹ̀” Nínú Ayé Búburú
A Jẹ́ “Olùgbé Fún Ìgbà Díẹ̀” Nínú Ayé Búburú
‘Gbogbo àwọn wọ̀nyí nínú ìgbàgbọ́, wọ́n polongo ní gbangba pé àwọn jẹ́ àjèjì àti olùgbé fún ìgbà díẹ̀ ní ilẹ̀ náà.’—HÉB. 11:13.
1. Kí ni Jésù sọ nípa ojú tí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ gbọ́dọ̀ máa fi wo ayé?
JÉSÙ sọ nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Wọ́n wà ní ayé.” Àmọ́, ó ṣàlàyé pé: “Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.” (Jòh. 17:11, 14) Nípa báyìí, lọ́nà tó ṣe kedere, Jésù sọ ojú tí àwọn tó jẹ́ ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní tòótọ́ gbọ́dọ̀ máa fi wo “ètò àwọn nǹkan yìí,” tí Sátánì jẹ́ ọlọ́run rẹ̀. (2 Kọ́r. 4:4) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú ayé búburú yìí ni wọ́n á máa gbé, wọn kò ní jẹ́ apá kan rẹ̀. Nínú ètò àwọn nǹkan yìí, wọ́n máa jẹ́ “àtìpó àti olùgbé fún ìgbà díẹ̀.”—1 Pét. 2:11.
Wọ́n Gbé Gẹ́gẹ́ bí “Olùgbé fún Ìgbà Díẹ̀”
2, 3. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Énọ́kù, Nóà, Ábúráhámù àti Sárà gbé gẹ́gẹ́ bí “àtìpó àti olùgbé fún ìgbà díẹ̀”?
2 Ọjọ́ pẹ́ táwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ti máa ń yàtọ̀ pátápátá sí àwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn tí kò ṣèfẹ́ Ọlọ́run. Ṣáájú Ìkún-omi, Énọ́kù àti Nóà “bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn.” (Jẹ́n. 5:22-24; 6:9) Àwọn méjèèjì lo ìgboyà bí wọ́n ti ń wàásù nípa ìdájọ́ tí Jèhófà ń mú bọ̀ wá sórí ayé búburú Sátánì. (Ka 2 Pétérù 2:5; Júúdà 14, 15.) Torí pé wọ́n bá Ọlọ́run rìn nínú ayé tí àwọn èèyàn kò ti ṣèfẹ́ Ọlọ́run, Énọ́kù “wu Ọlọ́run dáadáa,” Nóà sì “fi ara rẹ̀ hàn ní aláìní-àléébù láàárín àwọn alájọgbáyé rẹ̀.”—Héb. 11:5; Jẹ́n. 6:9.
3 Nígbà tí Ọlọ́run ní kí Ábúráhámù àti Sárà fi ìlú Úrì ti àwọn ará Kálídíà sílẹ̀, wọ́n gbà láti yááfì ìtura tí wọ́n ń gbádùn níbẹ̀, wọ́n sì yàn láti máa ṣí kiri ní ilẹ̀ òkèèrè bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn. (Jẹ́n. 11:27, 28; 12:1) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni Ábúráhámù, nígbà tí a pè é, fi ṣègbọràn ní jíjáde lọ sí ibì kan tí a ti yàn án tẹ́lẹ̀ láti gbà gẹ́gẹ́ bí ogún; ó sì jáde lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò mọ ibi tí òun ń lọ. Nípa ìgbàgbọ́ ni ó ṣe àtìpó ní ilẹ̀ ìlérí bí ní ilẹ̀ òkèèrè, ó sì gbé nínú àwọn àgọ́ pẹ̀lú Ísákì àti Jékọ́bù, àwọn ajogún ìlérí kan náà pẹ̀lú rẹ̀.” (Héb. 11:8, 9) Pọ́ọ̀lù sọ nípa irú àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà bẹ́ẹ̀ pé: “Gbogbo àwọn wọ̀nyí kú nínú ìgbàgbọ́, bí wọn kò tilẹ̀ rí ìmúṣẹ àwọn ìlérí náà gbà, ṣùgbọ́n wọ́n rí wọn lókèèrè réré, wọ́n sì fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà wọ́n, wọ́n sì polongo ní gbangba pé àwọn jẹ́ àjèjì àti olùgbé fún ìgbà díẹ̀ ní ilẹ̀ náà.”—Héb. 11:13.
Ìkìlọ̀ fún Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì
4. Ìkìlọ̀ wo ni Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ní ilẹ̀ wọn?
4 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí wọ́n jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù, di púpọ̀, lẹ́yìn náà Ọlọ́run sọ wọ́n di orílẹ̀-èdè kan, ó sì fún wọn ní ilẹ̀ àti àkójọ òfin. (Jẹ́n. 48:4; Diu. 6:1) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò gbọ́dọ̀ gbàgbé láé pé Jèhófà gangan ló ni ilẹ̀ wọn. (Léf. 25:23) Ńṣe ni wọ́n dà bí ẹni tó yá nǹkan tó sì gbọ́dọ̀ lò ó bí Oní-nǹkan ṣe fẹ́. Bákan náà, wọ́n gbọ́dọ̀ rántí pé “ènìyàn kì í tipa oúnjẹ nìkan ṣoṣo wà láàyè”; wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ohun ìní tí wọ́n kó jọ mú kí wọ́n gbàgbé Jèhófà. (Diu. 8:1-3) Kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ní ilẹ̀ wọn, Ọlọ́run kìlọ̀ fún wọn pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé ní ìgbà tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò mú ọ wá sínú ilẹ̀ tí ó búra fún àwọn baba ńlá rẹ Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù láti fi fún ọ, àwọn ìlú ńlá títóbi, tí wọ́n sì dára ní ìrísí, tí ìwọ kò tẹ̀ dó, àti àwọn ilé tí ó kún fún àwọn ohun rere gbogbo, tí ìwọ kò sì fi nǹkan kún, àti àwọn ìkùdu tí a ti gbẹ́, tí ìwọ kò gbẹ́, àwọn ọgbà àjàrà àti igi ólífì tí ìwọ kò gbìn, ni ìwọ yóò sì jẹ ní àjẹtẹ́rùn, ṣọ́ ara rẹ, kí o má bàa gbàgbé Jèhófà.”—Diu. 6:10-12.
5. Kí nìdí tí Jèhófà fi kọ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sílẹ̀, orílẹ̀-èdè tuntun wo ló sì fojú rere hàn sí dípò wọn?
5 Ó nídìí tí Ọlọ́run fi fún wọn ní ìkìlọ̀ yẹn. Ní ìgbà ayé Nehemáyà, àwùjọ àwọn ọmọ Léfì kan rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gba Ilẹ̀ Ìlérí, ojú sì tì wọ́n. Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé nínú àwọn ilé tó tù wọ́n lára, tí wọ́n ní oúnjẹ àti wáìnì tó pọ̀, “wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ, wọ́n sì yó, wọ́n sì sanra.” Wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, wọ́n tiẹ̀ pa àwọn wòlíì tó rán láti kìlọ̀ fún wọn pàápàá. Torí náà, Jèhófà fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́. (Ka Nehemáyà 9:25-27; Hós. 13:6-9) Nígbà tó yá, lákòókò tí ìjọba Róòmù ń ṣàkóso wọn, àwọn Júù aláìgbàgbọ́ yẹn bá a débi pé wọ́n pa Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí! Jèhófà kọ̀ wọ́n sílẹ̀, ó sì fojú rere hàn sí orílẹ̀-èdè tuntun, ìyẹn Ísírẹ́lì tẹ̀mí, dípò wọn.—Mát. 21:43; Ìṣe 7:51, 52; Gál. 6:16.
Wọn “Kì Í Ṣe Apá Kan Ayé”
6, 7. (a) Báwo lo ṣe máa ṣàlàyé ohun tí Jésù sọ nípa ojú tó yẹ káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ máa fi wo ayé? (b) Kí nìdí táwọn Kristẹni tòótọ́ kò fi gbọ́dọ̀ di apá kan ètò Sátánì?
6 Gẹ́gẹ́ bá a ṣe fi hàn ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, Jésù Kristi tó jẹ́ Orí ìjọ Kristẹni, mú kó ṣe kedere pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun gbọ́dọ̀ ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé, tí í ṣe ètò àwọn nǹkan búburú Sátánì. Kí Jésù tó kú, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Bí ẹ̀yin bá jẹ́ apá kan ayé, ayé yóò máa ní ìfẹ́ni fún ohun tí í ṣe tirẹ̀. Wàyí o, nítorí pé ẹ kì í ṣe apá kan ayé, ṣùgbọ́n mo ti yàn yín kúrò nínú ayé, ní tìtorí èyí ni ayé fi kórìíra yín.”—Jòh. 15:19.
7 Bí ẹ̀sìn Kristẹni ṣe ń gbilẹ̀, ṣé ó wá yẹ káwọn Kristẹni gbà láti máa ṣe bí àwọn èèyàn ayé, kí wọ́n máa ṣe ohun táyé ń ṣe kí wọ́n sì wá di apá kan rẹ̀? Rárá o. Ibi yòówù kí wọ́n máa gbé, wọ́n gbọ́dọ̀ ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú ètò Sátánì. Ní nǹkan bí ọgbọ́n ọdún lẹ́yìn ikú Kristi, àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé sáwọn Kristẹni tí wọ́n ń gbé ní apá ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìlú Róòmù. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, mo gbà yín níyànjú gẹ́gẹ́ bí àtìpó àti olùgbé fún ìgbà díẹ̀ láti máa ta kété sí àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ara, tí í ṣe àwọn ohun náà gan-an tí ń bá ìforígbárí nìṣó lòdì sí ọkàn. Ẹ tọ́jú ìwà yín kí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.”—1 Pét. 1:1; 2:11, 12.
8. Kí ni òpìtàn kan sọ nípa àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní àti ayé?
8 Nínú ìwé tí òpìtàn Kenneth Scott Latourette kọ, ó jẹ́rìí sí i pé àwọn Kristẹni tó gbé ní ìlú Róòmù ní ọ̀rúndún kìíní gbé ìgbé ayé wọn gẹ́gẹ́ bí “àtìpó àti olùgbé fún ìgbà díẹ̀.” Ó sọ pé: “Ní ọ̀rúndún mẹ́ta àkọ́kọ́ lẹ́yìn tí ẹ̀sìn Kristẹni bẹ̀rẹ̀, àwọn èèyàn mọ̀ dáadáa pé wọ́n máa ń ṣe inúnibíni líle koko sí àwọn Kristẹni léraléra àti lọ́pọ̀ ìgbà . . . Ẹ̀sùn tí wọ́n fi ń kàn wọ́n sì máa ń yàtọ̀ síra. Wọ́n ní àwọn Kristẹni kò gbà pé Ọlọ́run wà, torí pé wọn kò lọ́wọ́ sí ayẹyẹ ìbọ̀rìṣà. Wọ́n tún ń fi wọ́n ṣẹ̀sín pé ọ̀tá ọmọ aráyé ni wọ́n torí pé wọn kò lọ́wọ́ sí ohun tó ń lọ nílùú, irú bí ayẹyẹ ìbọ̀rìṣà, àwọn eré táwọn ará ìlú fi ń dára wọn lára yá, èyí tó kún fún ẹ̀kọ́ àti àṣà àwọn abọ̀rìṣà àti onírúurú ìṣekúṣe.”
Wọn Kò Lo Ayé Dé Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́
9. Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tòótọ́, báwo la ṣe ń fi hàn pé a kì í ṣe “ọ̀tá ọmọ aráyé”?
9 Báwo ni ipò nǹkan ṣe rí lónìí? Ojú kan náà táwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní fi wo ayé, làwa náà fi ń wo “ètò àwọn nǹkan burúkú ìsinsìnyí.” (Gál. 1:4) Èyí ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣì wá lóye, àwọn kan tiẹ̀ kórìíra wa pàápàá. Síbẹ̀, ó dájú pé a kì í ṣe “ọ̀tá ọmọ aráyé.” A nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn bíi tiwa, ìdí nìyẹn tá a fi máa ń lọ láti ilé dé ilé, tá a sì ń sa gbogbo ipá wa láti wàásù “ìhìn rere ìjọba [Ọlọ́run]” fún gbogbo àwọn tá a bá bá nílé. (Mát. 22:39; 24:14) Ìdí tá a fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó dá wa lójú pé Ìjọba Jèhófà lábẹ́ ìṣàkóso Kristi máa tó fòpin sí ìṣàkóso èèyàn aláìpé, ó sì máa fi ètò àwọn nǹkan tuntun nínú èyí tí òdodo yóò máa gbé rọ́pò rẹ̀.—Dán. 2:44; 2 Pét. 3:13.
10, 11. (a) Báwo ni a kì í ṣeé lo ayé dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́? (b) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà táwọn Kristẹni tó wà lójúfò máa ń gbà yẹra fún lílo ayé dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́?
10 Ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí máa tó wá sí òpin, torí náà àwa ìránṣẹ́ Jèhófà gbọ́dọ̀ lóye pé àkókò kọ́ nìyí láti máa jẹ̀gbádùn nínú ayé tó ń kú lọ yìí. À ń ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Èyí ni mo sọ, ẹ̀yin ará, pé àkókò tí ó ṣẹ́ kù ti dín kù. Láti ìsinsìnyí lọ, kí àwọn . . . tí ń rà [dà] bí àwọn tí kò ní, àti àwọn tí ń lo ayé bí àwọn tí kò lò ó dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́; nítorí ìrísí ìran ayé yìí ń yí padà.” (1 Kọ́r. 7:29-31) Ọ̀nà wo ni àwọn Kristẹni òde òní ń gbà lo ayé? Wọ́n ń ṣe èyí nípa lílo àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé àti onírúurú ọ̀nà téèyàn lè gbà bá àwọn míì sọ̀rọ̀ láti mú káwọn èèyàn jákèjádò ayé tó ń sọ ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè túbọ̀ lóye Bíbélì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń ṣiṣẹ́ kí wọ́n lè rówó gbọ́ bùkátà, wọn kì í lo ayé dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Wọ́n máa ń ra àwọn ohun tí wọ́n bá nílò, wọ́n sì máa ń náwó lórí àwọn ohun tó bá pọn dandan. Àmọ́, wọ́n máa ń ṣọ́ra kí wọ́n má bàa lo ayé dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ní ti pé wọ́n máa ń fi àwọn nǹkan ìní àti iṣẹ́ sí ipò tó yẹ kí wọ́n wà.—Ka 1 Tímótì 6:9, 10.
11 Àwọn Kristẹni tó wà lójúfò kì í lo ayé dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ tó bá kan ọ̀rọ̀ ilé ẹ̀kọ́ gíga. Nínú ayé lónìí, ọ̀pọ̀ ló gbà pé béèyàn bá fẹ́ tẹ́gbẹ́ kó sì máa gbé ìgbé ayé yọ̀tọ̀mì dandan ni kó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga. Àmọ́ àwa Kristẹni jẹ́ olùgbé fún ìgbà díẹ̀, àfojúsùn wa sì yàtọ̀ síyẹn. A kì í wá “àwọn ohun ńláńlá.” (Jer. 45:5; Róòmù 12:16) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọmọlẹ́yìn Jésù ni wá, à ń ṣègbọràn sí ìkìlọ̀ tó fún wa. Jésù ní: “Ẹ la ojú yín sílẹ̀, kí ẹ sì máa ṣọ́ra fún gbogbo onírúurú ojúkòkòrò, nítorí pé nígbà tí ẹnì kan bá tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu pàápàá, ìwàláàyè rẹ̀ kò wá láti inú àwọn ohun tí ó ní.” (Lúùkù 12:15) Torí náà, a gba àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n máa fi àwọn nǹkan tẹ̀mí ṣe àfojúsùn wọn, kí wọ́n ka ìwọ̀n ìwé táá jẹ́ kí wọ́n lè bójú tó àwọn ohun tó jẹ́ kòṣeémáàní, kí wọ́n sì gbájú mọ́ bí wọ́n ṣe máa múra ara wọn sílẹ̀ láti sin Jèhófà ‘pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà wọn àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn àti pẹ̀lú gbogbo okun wọn àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú wọn.’ (Lúùkù 10:27) Lọ́nà yìí, wọ́n lè dẹni tó “ní ọrọ̀ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”—Lúùkù 12:21; ka Mátíù 6:19-21.
Má Ṣe Jẹ́ Kí Àníyàn Ìgbésí Ayé Wọ̀ Ẹ́ Lọ́rùn
12, 13. Bí a bá ń ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Mátíù 6:31-33, báwo ni ìyẹn ṣe máa mú ká yàtọ̀ sí àwọn èèyàn ayé?
12 Ojú tí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà fi ń wo àwọn nǹkan ìní yàtọ̀ sí ti àwọn èèyàn ayé. Látàrí èyí, Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ má ṣàníyàn láé, kí ẹ sì wí pé, ‘Kí ni a ó jẹ?’ tàbí, ‘Kí ni a ó mu?’ tàbí, ‘Kí ni a ó wọ̀?’ Nítorí gbogbo ìwọ̀nyí ni nǹkan tí àwọn orílẹ̀-èdè ń fi ìháragàgà lépa. Nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan wọ̀nyí. Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.” (Mát. 6:31-33) Ọ̀pọ̀ àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ ti rí i nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn fúnra wọn pé òótọ́ ni Baba wa ọ̀run ń pèsè àwọn ohun tí wọ́n nílò.
13 Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ó jẹ́ ọ̀nà èrè ńlá, àní fífọkànsin Ọlọ́run pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí ohun-moní-tómi.” (1 Tím. 6:6) Èyí yàtọ̀ pátápátá sí ojú tí ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ayé lónìí fi ń wo nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, gbàrà tí àwọn ọ̀dọ́ bá ti ṣègbéyàwó ni ọ̀pọ̀ lára wọn ti máa ń retí pé ó ti yẹ káwọn ‘ní gbogbo nǹkan,’ irú bí ibùgbé tó kún fún àwọn nǹkan mèremère, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tó dáa àti àwọn ẹ̀rọ abánáṣiṣẹ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde. Àmọ́, ní ti àwọn Kristẹni tó ń gbé gẹ́gẹ́ bí olùgbé fún ìgbà díẹ̀ ohun tó bọ́gbọ́n mu tí agbára wọn sì ká ni wọ́n máa ń rà. Dájúdájú, ó yẹ ká gbóríyìn fún ọ̀pọ̀ àwọn tó yááfì àwọn ohun amáyédẹrùn kí wọn bàa lè máa lo àkókò àti okun púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà gẹ́gẹ́ bí akéde tó ń fìtara wàásù Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn míì ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, wọ́n ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì, wọ́n ń ṣe iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn àjo, tàbí kí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì. Ẹ wo bí gbogbo wa ṣe mọrírì bí àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà ṣe ń fi tọkàntọkàn sin Ọlọ́run!
14. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú àkàwé Jésù nípa afúnrúgbìn?
14 Nínú àkàwé Jésù nípa afúnrúgbìn, ó sọ pé “àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí àti agbára ìtannijẹ ọrọ̀” lè fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pa nínú ọkàn-àyà wa kó sì sọ wa di aláìléso. (Mát. 13:22) A kò ní kó sínú páńpẹ́ yìí bó bá tẹ́ wa lọ́rùn láti máa gbé gẹ́gẹ́ bí olùgbé fún ìgbà díẹ̀ nínú ètò àwọn nǹkan yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa mú kí ojú wa “mú ọ̀nà kan,” tàbí ká “máa wo ọ̀kánkán gan-an,” ká máa wo “ojú ọ̀nà kan ṣoṣo,” tó lọ sí Ìjọba Ọlọ́run, a ó sì jẹ́ kí àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú rẹ̀ wà nípò àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé wa.—Mát. 6:22; àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.
“Ayé Ń Kọjá Lọ”
15. Kí ni àpọ́sítélì Jòhánù sọ tó jẹ́ ká mọ ojú tí àwa Kristẹni tòótọ́ fi ń wo ayé yìí àti bá a ṣe ń gbé ìgbé ayé wa?
15 Ìdí pàtàkì táwa Kristẹni tòótọ́ fi ń wo ara wa gẹ́gẹ́ bí “àtìpó àti olùgbé fún ìgbà díẹ̀” nínú ayé yìí ni pé ó dá wa lójú pé ayé yìí máa tó pa run. (1 Pét. 2:11; 2 Pét. 3:7) Tá a bá ń fi irú ojú yìí wo ayé, ó máa nípa lórí àwọn ìpinnu tá à ń ṣe nínú ìgbésí ayé wa, àwọn nǹkan tá a nífẹ̀ẹ́ sí àtàwọn ohun tá à ń lépa. Àpọ́sítélì Jòhánù fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ ní ìmọ̀ràn pé kí wọ́n má ṣe nífẹ̀ẹ́ ayé tàbí àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé torí pé “ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—1 Jòh. 2:15-17.
16. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a wà lára àwọn èèyàn tí Ọlọ́run ti yà sọ́tọ̀ gedegbe?
16 Jèhófà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé bí wọ́n bá ṣègbọràn sí òun, wọ́n máa di “àkànṣe dúkìá [òun] nínú gbogbo àwọn ènìyàn yòókù.” (Ẹ́kís. 19:5) Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ olóòótọ́, ìjọsìn wọn àti ọ̀nà tí wọ́n gbà gbé ìgbé ayé wọn yàtọ̀ sí ti gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yòókù. Bákan náà lónìí, Jèhófà ti ya àwọn èèyàn kan tó yàtọ̀ pátápátá sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé Sátánì kí wọ́n lè máa sìn ín. Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé ká ‘kọ àìṣèfẹ́ Ọlọ́run sílẹ̀ àti àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ayé,’ ká sì máa “gbé pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú àti òdodo àti fífọkànsin Ọlọ́run nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí, bí a ti ń dúró de ìrètí aláyọ̀ àti ìfarahàn ológo ti Ọlọ́run ńlá náà àti ti Olùgbàlà wa, Kristi Jésù, ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fúnni nítorí wa kí ó bàa lè dá wa nídè kúrò nínú gbogbo onírúurú ìwà àìlófin, kí ó sì wẹ àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ tirẹ̀ lákànṣe mọ́ fún ara rẹ̀, àwọn onítara fún iṣẹ́ àtàtà.” (Títù 2:11-14) “Àwọn ènìyàn” tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ń sọ ni àwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí yàn àti àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn “àgùntàn mìíràn” Jésù, tí wọ́n ń ràn wọ́n lọ́wọ́, tí wọ́n sì ń tì wọ́n lẹ́yìn.—Jòh. 10:16.
17. Kí nìdí tí àwọn tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn kò fi ní kábàámọ̀ láé pé àwọn gbé gẹ́gẹ́ bí olùgbé fún ìgbà díẹ̀ nínú ayé búburú yìí?
17 “Ìrètí aláyọ̀” tí àwọn tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn ní ni pé wọ́n máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run. (Ìṣí. 5:10) Tí Ọlọ́run bá ti mú ìrètí tí àwọn àgùntàn mìíràn ní láti gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé ṣẹ, wọn kò ní jẹ́ olùgbé fún ìgbà díẹ̀ nínú ayé búburú mọ́. Wọ́n máa ní ilé tó rẹwà, wọ́n sì tún máa ní ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ àti ohun mímu. (Sm. 37:10, 11; Aísá. 25:6; 65:21, 22) Wọn kò jẹ́ dà bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ní ti pé wọn kò ní gbàgbé láé pé ọwọ́ Jèhófà “Ọlọ́run gbogbo ilẹ̀ ayé” ni gbogbo èyí ti wá. (Aísá. 54:5) Àwọn tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn tàbí àwọn àgùntàn mìíràn kò ní kábàámọ̀ pé àwọn ti gbé gẹ́gẹ́ bí olùgbé fún ìgbà díẹ̀ nínú ayé búburú yìí.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Báwo ni àwọn olóòótọ́ ìgbàanì ṣe gbé ìgbé ayé wọn gẹ́gẹ́ bí olùgbé fún ìgbà díẹ̀?
• Ojú wo ni àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní fi wo ayé?
• Báwo ni àwọn Kristẹni kì í ṣeé lo ayé dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́?
• Kí nìdí tí a kò fi ní kábàámọ̀ láé pé à ń gbé gẹ́gẹ́ bí olùgbé fún ìgbà díẹ̀ nínú ayé búburú yìí?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní kò lọ́wọ́ sí eré ìnàjú tó ń gbé ìwà ipá àti ìṣekúṣe lárugẹ