‘Má Ṣe Gbára Lé Òye Tìrẹ’
‘Má Ṣe Gbára Lé Òye Tìrẹ’
“Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ.”—ÒWE 3:5.
1, 2. (a) Àwọn ìṣòro wo ló lè dé bá wa? (b) Ta ló yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé tá a bá wà nínú ipò tí ń kó ìdààmú báni, tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu kan, tàbí ká lè borí ìdẹwò, kí sì nìdí?
Ọ̀GÁ tó gba Cynthia * síṣẹ́ ti dín iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe ní iléeṣẹ́ rẹ̀ kù, ó sì ti dá àwọn òṣìṣẹ́ mélòó kan dúró lẹ́nu iṣẹ́. Cynthia rò pé òun ni wọ́n máa dá dúró lọ́tẹ̀ yìí. Kí ló máa ṣe bí iṣẹ́ bá bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀? Báwo ló ṣe máa san gbèsè tó jẹ? Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Pamela fẹ́ lọ sí ibi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run púpọ̀ sí i, àmọ́ ṣó yẹ kó lọ? Ìṣòro tó dojú kọ ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Samuel yàtọ̀ ní tiẹ̀. Ó ṣì kéré nígbà tó ti bẹ̀rẹ̀ sí í wo àwòrán oníhòòhò. Ní báyìí, Samuel ti lé ní ọmọ ogún ọdún ó sì máa ń wù ú gan-an pé kó pa dà sídìí àṣà yẹn. Kí ló lè ṣe kó má bàa dáṣà yẹn mọ́?
2 Ta lo máa ń gbẹ́kẹ̀ lé tó o bá wà nínú ipò tí ń kó ìdààmú báni, tó o bá fẹ́ ṣe ìpinnu, tàbí kó o lè borí ìdẹwò? Ṣé o máa ń rò pé o lè dá bójú tó ọ̀ràn ara rẹ, àbí o máa ń “ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà”? (Sm. 55:22) Bíbélì sọ pé: “Ojú Jèhófà ń bẹ lọ́dọ̀ àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́.” (Sm. 34:15) Ẹ wo bó ti ṣe pàtàkì tó nígbà náà pé ká fi gbogbo ọkàn-àyà wa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká má sì gbára lé òye tiwa!—Òwe 3:5.
3. (a) Kí ló túmọ̀ sí láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà? (b) Kí ló lè mú káwọn kan fẹ́ láti gbára lé òye tí wọ́n ní?
3 Bá a bá fẹ́ fi gbogbo ọkàn wa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ìyẹn gba pé ká máa ṣe àwọn ohun tó bá fẹ́ ká ṣe, ká sì ṣe é lọ́nà tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. Ọ̀nà pàtàkì tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa gbàdúrà sí i nígbà gbogbo, ká sì máa fi tọkàntọkàn béèrè fún ìtọ́sọ́nà rẹ̀. Àmọ́, ó ṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan tó ń jẹ́ Lynn sọ pé, “Mo ṣì ń tiraka láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nínú gbogbo ohun tí mo bá ń ṣe.” Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Ó sọ pé: “Bàbá mi ò rí tèmi rò, màmá mi kì í ráyè gbọ́ tèmi, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò bójú tó mi. Torí náà, kò pẹ́ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí í dá bójú tó ọ̀ràn ara mi.” Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Lynn yìí ò tiẹ̀ jẹ́ kó lè gbẹ́kẹ̀ lé ẹnikẹ́ni. Bí ẹnì kan bá mọ ohun kan ṣe dáadáa tó sì ń ṣàṣeyọrí, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í rò pé òun lè dá bójú tó ọ̀ràn ara òun. Alàgbà kan lè fẹ́ láti máa lo ìrírí tó ti ní láti bójú tó àwọn ọ̀ràn tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọ kó má sì kọ́kọ́ gbàdúrà sí Ọlọ́run.
4. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
4 Jèhófà máa ń retí pé ká sapá tọkàntọkàn láti máa ṣe ohun tó bá àdúrà tá a bá ń gbà mu, ká sì máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo la ṣe lè fi ìyàtọ̀ sí ìgbà tó yẹ ká gbára lé Jèhófà pé kó bá wa yanjú ìṣòro kan tó nira àti ìgbà tó yẹ kí àwa fúnra wa sapá láti wá nǹkan ṣe sí i? Tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu, kí ló yẹ ká ṣọ́ra fún? Kí nìdí tí àdúrà fi ṣe pàtàkì tá a bá ń sapá láti borí ìdẹwò? Ká lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí a máa jíròrò àwọn àpẹẹrẹ kan látinú Ìwé Mímọ́.
Bí A Bá Ní Ìdààmú Ọkàn
5, 6. Kí ni Hesekáyà ṣe nígbà tí ọba Ásíríà fẹ́ wá gbéjà kò ó?
5 Bíbélì sọ nípa Hesekáyà Ọba Júdà pé: “Ó . . . ń bá a nìṣó ní fífà mọ́ Jèhófà. Kò yà kúrò nínú títọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ṣùgbọ́n ó ń bá a lọ láti pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè.” Bẹ́ẹ̀ ni, “Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni ó gbẹ́kẹ̀ lé.” (2 Ọba 18:5, 6) Kí ni Hesekáyà ṣe nígbà tí Senakéríbù Ọba Ásíríà rán àwọn aṣojú rẹ̀ títí kan Rábúṣákè wá sí Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun tó bùáyà? Àwọn ọmọ ogun Ásíríà alágbára ti fipá gba àwọn ìlú olódi Júdà mélòó kan, àmọ́ Jerúsálẹ́mù ni Senakéríbù fẹ́ wá gbéjà kò báyìí. Hesekáyà lọ sí ilé Jèhófà ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà pé: “Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run wa, jọ̀wọ́, gbà wá là lọ́wọ́ rẹ̀, kí gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé lè mọ̀ pé ìwọ, Jèhófà, nìkan ṣoṣo ni Ọlọ́run.”—2 Ọba 19:14-19.
6 Hesekáyà ṣe ohun tó bá àdúrà tó gbà mu. Kódà kó tó lọ sínú tẹ́ńpìlì láti lọ gbàdúrà, ó fún àwọn èèyàn náà ní ìtọ́ni pé wọn kò gbọ́dọ̀ fèsì bí Rábúṣákè ṣe ń ṣáátá wọn. Hesekáyà tún rán aṣojú sí wòlíì Aísáyà láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé kí ni káwọn ṣe. (2 Ọba 18:36; 19:1, 2) Hesekáyà ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu pé kó ṣe. Kò wá ìrànlọ́wọ́ lọ sí ilẹ̀ Íjíbítì tàbí àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nítòsí wọn torí ó mọ̀ pé èyí lòdì sí ohun tí Jèhófà fẹ́. Dípò kí Hesekáyà gbára lé òye tirẹ̀, ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Lẹ́yìn tí áńgẹ́lì Jèhófà pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [185,000] lára àwọn ọmọ ogun Senakéríbù, ńṣe ni Senakéríbù “ṣí kúrò” ó sì pa dà lọ sí ìlú Nínéfè.—2 Ọba 19:35, 36.
7. Báwo ni bí Ọlọ́run ṣe gbọ́ àdúrà Hánà àti Jónà ṣe tù wá nínú?
7 Hánà, ìyàwó Ẹlikénà tí í ṣe ọmọ Léfì, pẹ̀lú gbára lé Jèhófà nígbà tí ìdààmú bá a torí pé kò rọ́mọ bí. (1 Sám. 1:9-11, 18) Bákan náà, Ọlọ́run dá wòlíì Jónà nídè kúrò nínú ikùn ẹja ńlá lẹ́yìn tó gbàdúrà pé: “Láti inú wàhálà mi ni mo ti ké pe Jèhófà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí dá mi lóhùn. Láti inú ikùn Ṣìọ́ọ̀lù ni mo ti kígbe fún ìrànlọ́wọ́. Ìwọ gbọ́ ohùn mi.” (Jónà 2:1, 2, 10) Ẹ wo bó ti ń tuni nínú tó láti mọ̀ pé bó ti wù kí ìṣòro tó ń bá wa fínra burú tó, a lè ké pe Jèhófà pé kó fi “ojú rere” hàn sí wa!—Ka Sáàmù 55:1, 16.
8, 9. Kí ni àdúrà Hesekáyà, Hánà àti Jónà fi hàn pé ó jẹ wọ́n lógún, kí la sì rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ wọn?
8 Àpẹẹrẹ Hesekáyà, Hánà àti Jónà tún kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ pàtàkì nípa ohun tí kò yẹ ká gbàgbé tá a bá ń gbàdúrà nígbà tí nǹkan bá nira. Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ní ẹ̀dùn ọkàn nígbà tí nǹkan nira fún wọn. Síbẹ̀, àdúrà wọn fi hàn pé kì í ṣe ọ̀ràn ara wọn àti bí wọ́n ṣe máa rí ìtura lọ́wọ́ ìṣòro nìkan ló jẹ wọ́n lógún. Orúkọ Ọlọ́run, ìjọsìn rẹ̀ àti ṣíṣe ìfẹ́ rẹ̀ ló jẹ wọ́n lógún jù lọ. Ó dun Hesekáyà pé àwọn èèyàn ń kẹ́gàn orúkọ Jèhófà. Bó ṣe wu Hánà tó pé kó bímọ, síbẹ̀ ó ṣèlérí pé òun máa yọ̀ọ̀da pé kí ọmọ náà ṣe iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run nínú àgọ́ ìjọsìn tó wà ní Ṣílò. Jónà ní tiẹ̀ sì sọ pé: “Èmi yóò san ohun ti mo jẹ́jẹ̀ẹ́.”—Jónà 2:9.
9 Tá a bá ń gbàdúrà pé kí Jèhófà ṣe ọ̀nà àbáyọ fún wa nígbà tí nǹkan bá nira, ó bọ́gbọ́n mu pé ká ṣàyẹ̀wò ohun tó wà lọ́kàn wa tá a fi ń gba irú àdúrà bẹ́ẹ̀. Ṣé bá a ṣe máa bọ́ lọ́wọ́ ìnira náà nìkan ló máa ń jẹ wá lógún, àbí a máa ń rántí Jèhófà àti ohun tó fẹ́ ṣe nínú àdúrà wa? Bí nǹkan bá nira fún wa, èyí lè tètè mú ká máa ṣàníyàn nípa ìṣòro wa débi tí a ó fi bẹ̀rẹ̀ sí í gbàgbé àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Jèhófà. Tá a bá ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́, ẹ jẹ́ ká máa ronú nípa Jèhófà, ìsọdimímọ́ orúkọ rẹ̀ àti ìdáláre ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. Èyí á jẹ́ ká lè máa ní èrò tó dáa bí a kò tilẹ̀ rí ojútùú tá à ń retí. Nígbà míì, Ọlọ́run máa ń dáhùn àdúrà wa nípa fífún wa lágbára tó máa jẹ́ ká lè fara da ìṣòro tó dé bá wa.—Ka Aísáyà 40:29; Fílípì 4:13.
Tá A Bá Ń Ṣèpinnu
10, 11. Kí ni Jèhóṣáfátì ṣe nígbà tí ìṣòro kan yọjú tí kò sì mọ ohun tó lè ṣe nípa rẹ̀?
10 Báwo lo ṣe máa ń ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì nínú ìgbésí ayé rẹ? Ṣé o kọ́kọ́ máa ń pinnu ohun tó o fẹ́ ṣe kó o tó wá gbàdúrà pé kí Jèhófà bù kún ìpinnu tó o ṣe? Ronú nípa ohun tí Jèhóṣáfátì, ọba Júdà, ṣe nígbà tí àwọn ọmọ ogun Móábù àtàwọn ọmọ ogun Ámónì pawọ́ pọ̀ láti wá gbéjà kò ó. Júdà kò lágbára láti bá wọn jà. Kí ni Jèhóṣáfátì máa ṣe báyìí?
11 Bíbélì sọ pé: “Àyà fo Jèhóṣáfátì, ó sì gbé ojú rẹ̀ lé wíwá Jèhófà.” Ó kéde pé kí gbogbo Júdà gbààwẹ̀ ó sì kó gbogbo àwọn èèyàn náà jọ “láti ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ Jèhófà.” Lẹ́yìn náà, ó dìde dúró nínú ìjọ Júdà àti ti Jerúsálẹ́mù ó sì gbàdúrà. Díẹ̀ rèé lára ohun tó sọ nígbà tó gbàdúrà: “Ìwọ Ọlọ́run wa, ìwọ kì yóò ha mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún lé wọn lórí? Nítorí pé kò sí agbára kankan nínú wa níwájú ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí tí ń bọ̀ wá gbéjà kò wá; àwa alára kò sì mọ ohun tí à bá ṣe, ṣùgbọ́n ojú wa ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ.” Ọlọ́run tòótọ́ gbọ́ àdúrà Jèhóṣáfátì, ó sì ṣe ọ̀nà àbáyọ fún un lọ́nà ìyanu. (2 Kíró. 20:3-12, 17) Tá a bá ń ṣèpinnu, pàápàá jù lọ àwọn tó bá máa nípa lórí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run, ǹjẹ́ Jèhófà kọ́ ló yẹ ká gbára lé dípò tá a ó fi gbára lé òye tara wa?
12, 13. Àpẹẹrẹ wo ni Dáfídì Ọba fi lélẹ̀ lórí ọ̀ràn ìpinnu ṣíṣe?
12 Kí ló yẹ ká ṣe bí a bá dojú kọ ìṣòro tó dà bíi pé ó rọrùn láti yanjú, bó bá ṣẹlẹ̀ pé ìrírí tá a ti ní nípa irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ mú ká tètè ronú kan ojútùú sí ìṣòro náà? Ohun kan tí Bíbélì sọ nípa Dáfídì Ọba jẹ́ ká rí ohun tó yẹ ká ṣe. Nígbà táwọn ará Ámálékì gbéjà ko ìlú Síkílágì, wọ́n kó àwọn ìyàwó àtàwọn ọmọ Dáfídì àti tàwọn ọkùnrin rẹ̀ lọ. Dáfídì wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà pé: “Ṣé kí n lépa ẹgbẹ́ onísùnmọ̀mí yìí?” Jèhófà dá a lóhùn pé: “Lépa wọn, nítorí ìwọ yóò lé wọn bá láìkùnà, ìwọ yóò sì ṣe ìdáǹdè láìkùnà.” Dáfídì ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ fún un, ó sì “dá gbogbo ohun tí àwọn ọmọ Ámálékì ti kó nídè.”—1 Sám. 30:7-9, 18-20.
13 Lẹ́yìn tí àwọn ará Ámálékì gbéjà ko ìlú Síkílágì, àwọn Filísínì wá gbéjà ko àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Dáfídì tún wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, ó sì rí ìtọ́ni tó ṣe kedere gbà. Ọlọ́run sọ fún un pé: “Gòkè lọ, nítorí láìkùnà, èmi yóò fi àwọn Filísínì lé ọ lọ́wọ́.” (2 Sám. 5:18, 19) Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, tí àwọn Filísínì tún wá bá Dáfídì jà. Kí ló máa ṣe lọ́tẹ̀ yìí? Ó lè ronú pé: ‘Irú nǹkan báyìí ti ṣẹlẹ̀ sí mi lẹ́ẹ̀mejì rí. Ẹ jẹ́ kí n lọ bá àwọn ọ̀tá Ọlọ́run jà, bí mo ti ṣe nígbà yẹn.’ Àbí ńṣe ni Dáfídì máa gbàdúrà sí Jèhófà pé kó tọ́ òun sọ́nà? Dáfídì ò gbára lé ìrírí tó ti ní. Ó tún gbàdúrà sí Jèhófà. Ẹ wo bí inú rẹ̀ ṣe máa dùn tó pé òun ṣe bẹ́ẹ̀! Ìtọ́ni tí Jèhófà fún un lọ́tẹ̀ yìí sì wá yàtọ̀. (2 Sám. 5:22, 23) Tá a bá bá ara wa nínú irú ipò tó jọ èyí tàbí tá a dojú kọ ìṣòro, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kó má bàa jẹ́ pé ìrírí tá a ti ní nìkan la máa gbára lé.—Ka Jeremáyà 10:23.
14. Kí la lè rí kọ́ látinú bí Jóṣúà àtàwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì ṣe bójú tó ọ̀ràn àwọn ará Gíbéónì?
14 Nítorí pé gbogbo wa jẹ́ aláìpé, tó fi mọ́ àwọn alàgbà tó nírìírí, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kó máa bàa di pé a kì í wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà tá a bá ń ṣe ìpinnu. Ronú lórí ohun tí Jóṣúà tó rọ́pò Mósè, àtàwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì sọ fún àwọn ọlọ́gbọ́n ará Gíbéónì tí wọ́n díbọ́n, tí wọ́n sì ṣe bíi pé ilẹ̀ tó jìnnà làwọn ti wá. Jóṣúà àtàwọn yòókù rẹ̀ kò wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ará Gíbéónì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn Jèhófà fọwọ́ sí àdéhùn tí wọ́n ṣe, ó rí sí i pé a ṣàkọsílẹ̀ bí wọ́n ṣe kọ̀ láti wá ìtọ́sọ́nà òun sínú Ìwé Mímọ́ fún àǹfààní wa.—Jóṣ. 9:3-6, 14, 15.
Tá A Bá Ń Sapá Láti Borí Ìdẹwò
15. Ṣàlàyé ìdí tí àdúrà fi ṣe pàtàkì tá a bá ń sapá láti borí ìdẹwò.
15 Nítorí pé a ní “òfin ẹ̀ṣẹ̀” nínú ara wa, a gbọ́dọ̀ jà fitafita ká lè borí àwọn èrò tó lè mú ká dẹ́ṣẹ̀. (Róòmù 7:21-25) A lè borí nínú ìjà yìí. Lọ́nà wo? Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé àdúrà ṣe pàtàkì béèyàn bá fẹ́ borí ìdẹwò. (Ka Lúùkù 22:40.) Kódà bí èrò tí kò tọ́ kò bá kúrò lọ́kàn wa lẹ́yìn tá a ti gbàdúrà sí Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ “máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run” pé kó fún wa ní ọgbọ́n ká lè fara da àdánwò náà. Bíbélì mú kó dá wa lójú pé “òun a máa fi fún gbogbo ènìyàn pẹ̀lú ìwà ọ̀làwọ́ àti láìsí gíganni.” (Ják. 1:5) Jákọ́bù pẹ̀lú kọ̀wé pé: “Ẹnikẹ́ni ha wà tí ń ṣàìsàn [nípa tẹ̀mí] láàárín yín bí? Kí ó pe àwọn àgbà ọkùnrin ìjọ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì gbàdúrà lé e lórí, ní fífi òróró pa á ní orúkọ Jèhófà. Àdúrà ìgbàgbọ́ yóò sì mú aláàárẹ̀ náà lára dá.”—Ják. 5:14, 15.
16, 17. Tá a bá ń wá bá a ṣe máa borí ìdẹwò, ìgbà wo ló dára jù lọ pé ká gbàdúrà?
16 Ká bàa lè borí ìdẹwò, àdúrà ṣe pàtàkì, àmọ́ a gbọ́dọ̀ mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká gbàdúrà lákòókò tó tọ́. Ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀dọ́kùnrin kan tí ìwé Òwe 7:6-23 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ní wíríwírí ọjọ́, ó ń kọjá lọ ní ojú pópó kan tó mọ̀ pé obìnrin aṣẹ́wó kan ń gbé. Obìnrin náà fi ọ̀rọ̀ dídùn ṣì í lọ́nà, ó sì fi ètè rẹ̀ dídùn mọ̀ràn-ìn mọran-in sún un dẹ́ṣẹ̀. Ọ̀dọ́kùnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í tọ̀ ọ́ lẹ́yìn bí akọ màlúù tí wọ́n ń mú lọ síbi tí wọ́n ti máa pa á. Kí ni ọ̀dọ́kùnrin náà wá lọ sí ojú pópó tó mọ̀ pé aṣẹ́wó yẹn ń gbé? Ìwé Mímọ́ sọ pé “ọkàn-àyà kù” fún un, ìyẹn ni pé kò ní ìrírí, torí náà ó ní láti jẹ́ pé ó nira fún un láti borí èrò tí kò tọ́. (Òwe 7:7) Ìgbà wo ni ì bá ti dára jù lọ pé kó gbàdúrà? Òótọ́ ni pé kò sí ìgbà tí àdúrà kò lè ràn án lọ́wọ́ láàárín ìgbà tó ń dojú kọ ìdẹwò yẹn. Àmọ́, ìgbà tó dára jù lọ pé kó gbàdúrà ni ìgbà tó kọ́kọ́ wá sí i lọ́kàn pé kó gba ojú pópó yẹn kọjá.
17 Lóde òní, ọkùnrin kan lè máa sapá gidigidi kó má bàa wo àwòrán oníhòòhò. Àmọ́, bó bá ṣẹlẹ̀ pé ó lọ sórí ìkànnì Íńtánẹ́ẹ̀tì kan níbi tó mọ̀ pé òun á ti rí àwọn àwòrán tàbí fídíò tí ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe ńkọ́? Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò ní dà bíi ti ọ̀dọ́kùnrin tí ìwé Òwe orí 7 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yẹn? Ọ̀nà tó léwu gbáà nìyẹn fún ẹnì kan láti forí lé! Kí ẹnì kan bàa lè borí ìdẹwò tó lè mú kó wo àwòrán oníhòòhò, ó ti yẹ kó gbàdúrà sí Jèhófà kó tó lọ sórí ìkànnì Íńtánẹ́ẹ̀tì tí irú àwòrán bẹ́ẹ̀ wà.
18, 19. (a) Kí ló lè mú kó ṣòro láti borí ìdẹwò, àmọ́ báwo la ṣe lè borí ìṣòro náà? (b) Kí lo pinnu láti ṣe?
18 Kò rọrùn láti borí ìdẹwò tàbí láti ṣẹ́pá àṣà búburú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹran ara lòdì sí ẹ̀mí nínú ìfẹ́-ọkàn rẹ̀, ẹ̀mí sì lòdì sí ẹran ara.” Torí náà, “àwọn ohun náà tí [a] óò fẹ́ láti ṣe ni [a] kò ṣe.” (Gál. 5:17) Ká tó lè borí ìdẹwò, a gbọ́dọ̀ fìtara gbàdúrà ní gbàrà tí àwọn èrò tí kò tọ́ tàbí ohun tó lè fa ìdẹwò bá kọ́kọ́ wá sọ́kàn wa ká sì ṣe ohun tó bá àdúrà tá a gbà mu. “Kò sí ìdẹwò kankan tí ó ti bá yín bí kò ṣe ohun tí ó wọ́pọ̀ fún àwọn ènìyàn,” ó sì dájú pé lọ́lá ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, ó máa ṣeé ṣe fún wa láti máa bá ìṣòtítọ́ wa nìṣó.—1 Kọ́r. 10:13.
19 Yálà ipò líle koko kan ló ń bá wa fínra ni o, a fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì kan ni o, tàbí à ń sapá láti borí ìdẹwò, Jèhófà ti fún wa ní ẹ̀bùn àgbàyanu kan, ìyẹn ni àǹfààní ṣíṣeyebíye tá a ní láti máa gbàdúrà. Bá a bá ń gbàdúrà, a ó máa fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. A tún gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó láti gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, èyí táá máa tọ́ wa sọ́nà táá sì tún máa fún wa lókun. (Lúùkù 11:9-13) Àti pé ní gbogbo ọ̀nà, ẹ jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ká má sì ṣe gbára lé òye tiwa.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ A ti yí àwọn orúkọ náà pa dà.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí lo rí kọ́ lára Hesekáyà, Hánà àti Jónà nípa ìdí tó fi yẹ ká máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?
• Báwo ni àpẹẹrẹ Dáfídì àti Jóṣúà ṣe jẹ́ ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó láti máa kíyè sára tá a bá ń ṣe ìpinnu?
• Ìgbà wo ló ṣe pàtàkì jù lọ pé ká gbàdúrà ká lè borí ìdẹwò?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Tá a bá fẹ́ borí ìdẹwò, ìgbà wo ló ṣe pàtàkì jù lọ pé ká gbàdúrà?