Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀mí Ọlọ́run Darí Àwọn Kristẹni ní Ọ̀rúndún Kìíní ó Sì Ń Darí Àwa Náà Lónìí

Ẹ̀mí Ọlọ́run Darí Àwọn Kristẹni ní Ọ̀rúndún Kìíní ó Sì Ń Darí Àwa Náà Lónìí

Ẹ̀mí Ọlọ́run Darí Àwọn Kristẹni ní Ọ̀rúndún Kìíní ó Sì Ń Darí Àwa Náà Lónìí

“Gbogbo ọ̀nà ìṣiṣẹ́ wọ̀nyí ni ẹ̀mí kan ṣoṣo náà ń mú ṣe.”—1 KỌ́R. 12:11.

1. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

 PẸ́ŃTÍKỌ́SÌ. Ọ̀rọ̀ yìí máa ń ránni létí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ amọ́kànyọ̀ tó wáyé ní ọ̀rúndún kìíní! (Ìṣe 2:1-4) Bí Ọlọ́run ṣe tú ẹ̀mí mímọ́ dà sórí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nígbà yẹn ṣàmì sí ìyípadà mánigbàgbé kan tó wáyé nínú ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà bá wọn lò. Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, a jíròrò díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí ẹ̀mí Ọlọ́run gbà fún àwọn olóòótọ́ ìgbàanì lágbára láti ṣe àwọn iṣẹ́ tó ṣòro tó sì díjú. Àmọ́ ìyàtọ̀ wo ló wà nínú ọ̀nà tí ẹ̀mí Ọlọ́run gbà ṣiṣẹ́ nígbà àtijọ́ àti ní ọ̀rúndún kìíní? Báwo sì làwọn Kristẹni ṣe ń jàǹfààní nínú bí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ṣe ń ṣiṣẹ́ lóde òní? Ẹ jẹ́ ká wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí.

“Wò Ó! Ẹrúbìnrin Jèhófà!”

2. Báwo ni Màríà ṣe rí ọ̀nà tí ẹ̀mí mímọ́ gbà ṣiṣẹ́?

2 Màríà wà nínú yàrá ńlá tó wà nínú ìyẹ̀wù òkè ní Jerúsálẹ́mù nígbà tí Jèhófà tú ẹ̀mí mímọ́ tí Jésù ṣèlérí sórí àwọn ọmọlẹ́yìn. (Ìṣe 1:13, 14) Síbẹ̀, ní ohun tó ju ọgbọ̀n ọdún lọ kí ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn tó wáyé, ó ti rí bí ẹ̀mí Jèhófà ṣe ṣiṣẹ́ lọ́nà tó pabanbarì. Látòkè ọ̀run, Jèhófà fi ìwàláàyè Ọmọ rẹ̀ sínú ilé ọlẹ̀ Màríà lórí ilẹ̀ ayé, èyí mú kí Màríà lóyún bó tilẹ̀ jẹ́ pé wúńdíá ni. Torí náà, oyún ọmọ tó ní jẹ́ “nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́.”—Mát. 1:20.

3, 4. Kí ni Màríà ṣe, báwo la sì ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀?

3 Kí nìdí tí Jèhófà fi fojú rere hàn sí Màríà nípa fífún un ní àǹfààní àrà ọ̀tọ̀? Lẹ́yìn tí áńgẹ́lì ti ṣàlàyé ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fún Màríà, Màríà sọ pé: “Wò ó! Ẹrúbìnrin Jèhófà! Kí ó ṣẹlẹ̀ sí mi ní ìbámu pẹ̀lú ìpolongo rẹ.” (Lúùkù 1:38) Ọ̀rọ̀ tí Màríà sọ yìí jẹ́ ká mọ ohun tí Ọlọ́run ti rí tẹ́lẹ̀ pé ó wà lọ́kàn rẹ̀. Bó ṣe yára fún áńgẹ́lì náà lésì fi hàn pé ó ṣe tán láti fara mọ́ ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Kò jẹ́ kí ojú tí àwọn ará àdúgbò á fi wo oyún náà tàbí ohun tó lè ṣẹlẹ̀ láàárín òun àti ọkùnrin tó ń fẹ́ ẹ sọ́nà fún un ní ìṣòro kankan. Bí Màríà ṣe pe ara rẹ̀ ní ẹni tó rẹlẹ̀ jù lọ láàárín àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tún fi hàn pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá pé Ọ̀gá òun ló jẹ́.

4 Nígbà míì, ǹjẹ́ ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé àwọn ìpèníjà tó ò ń dojú kọ àtàwọn ojúṣe rẹ nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ti pọ̀ jù? Ó dára kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bi ara rẹ̀ pé: ‘Ǹjẹ́ mo fi gbogbo ara gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa mú káwọn nǹkan di ṣíṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀? Ǹjẹ́ mò ń fi hàn pé lóòótọ́ ni mo múra tán láti ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run bá fẹ́ kí n ṣe?’ Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run máa ń fún àwọn tó bá fi gbogbo ọkàn-àyà wọn gbẹ́kẹ̀ lé e tí wọ́n sì ń ṣègbọràn sí i gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run ní ẹ̀mí mímọ́.—Ìṣe 5:32.

Ẹ̀mí Mímọ́ Ran Pétérù Lọ́wọ́

5. Àwọn ọ̀nà wo ni Pétérù gbà rí iṣẹ́ tí ẹ̀mí mímọ́ ṣe kó tó di Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni?

5 Bíi ti Màríà, àpọ́sítélì Pétérù ti rí bí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ṣe ṣe àwọn iṣẹ́ lílágbára kó tó di Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Jésù ti fún òun àti àwọn àpọ́sítélì yòókù láṣẹ láti lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. (Máàkù 3:14-16) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ìwé Mímọ́ kò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ tó pọ̀ fún wa, ó dà bíi pé Pétérù lo àṣẹ náà. Pétérù tún rí agbára Ọlọ́run nígbà tí Jésù sọ fún un pé kó máa tọ òun bọ̀ lórí Òkun Gálílì, tí Pétérù sì ṣe bẹ́ẹ̀. (Ka Mátíù 14:25-29.) Ó dájú pé ẹ̀mí mímọ́ tí Pétérù gbára lé ló mú kó lè ṣe àwọn ohun ńláǹlà yìí. Láìpẹ́, ẹ̀mí yẹn máa ṣiṣẹ́ lára Pétérù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù ní àwọn ọ̀nà mìíràn.

6. Kí ni ẹ̀mí Ọlọ́run fún Pétérù lágbára láti ṣe ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni àti lẹ́yìn náà?

6 Ọlọ́run ṣe iṣẹ́ ìyanu kan nígbà Àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, ó fún Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù lágbára láti sọ èdè táwọn èèyàn tó wá ṣèbẹ̀wò sí Jerúsálẹ́mù ń sọ. Lẹ́yìn náà, Pétérù mú ipò iwájú láti bá àwùjọ àwọn èèyàn náà sọ̀rọ̀. (Ìṣe 2:14-36) Òótọ́ ni pé Pétérù máa ń ṣe wàdùwàdù nígbà mìíràn tàbí kó bẹ̀rù, àmọ́ ẹ̀mí mímọ́ mú un láyà le láti fìgboyà jẹ́rìí bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aláṣẹ ń halẹ̀ mọ́ wọn tí wọ́n sì ń ṣe inúnibíni sí wọn. (Ìṣe 4:18-20, 31) Ọlọ́run lo ẹ̀mí mímọ́ láti fún Pétérù ní àkànṣe ìmọ̀. (Ìṣe 5:8, 9) Ó sì tún fún un lágbára láti jí òkú dìde.—Ìṣe 9:40.

7. Ẹ̀kọ́ Jésù wo ló túbọ̀ ṣe kedere sí Pétérù lẹ́yìn tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn án?

7 Kó tó di ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ni Pétérù ti lóye ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ Ìwé Mímọ́ tí Jésù fi kọ́ni. (Mát. 16:16, 17; Jòh. 6:68) Àmọ́, àwọn ohun kan wà tí kò tíì yé e lára ẹ̀kọ́ Jésù kó tó di ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì. Bí àpẹẹrẹ, Pétérù kò tíì fòye mọ̀ pé Kristi máa jíǹde gẹ́gẹ́ bí ẹni ẹ̀mí ní ọjọ́ kẹta; kò sì tíì yé Pétérù pé òkè ọ̀run ni Ìjọba náà máa wà. (Jòh. 20:6-10; Ìṣe 1:6) Ti pé àwọn ẹ̀dá èèyàn á di ẹ̀dá ẹ̀mí tí wọ́n á sì ṣàkóso nínú Ìjọba kan lókè ọ̀run ṣì ṣàjèjì sí Pétérù. Àmọ́ lẹ́yìn tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn án tó sì ní ìrètí àtilọ sókè ọ̀run, ló tó lóye ẹ̀kọ́ tí Jésù fi kọ́ni yìí.

8. Ìmọ̀ wo ni àwọn tá a fẹ̀mí yàn àti “àwọn àgùntàn mìíràn” ní?

8 Lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti tú ẹ̀mí mímọ́ dà sórí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìjìnlẹ̀ òye nípa àwọn nǹkan tí kò yé wọn tẹ́lẹ̀. Fún àǹfààní wa, Ọlọ́run lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti mú káwọn tó kọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ohun àgbàyanu nípa ète Jèhófà. (Éfé. 3:8-11, 18) Lóde òní, àwọn tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn àti “àwọn àgùntàn mìíràn” ń jùmọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wọ́n sì ń lóye àwọn ohun àgbàyanu yìí. (Jòh. 10:16) Ṣé o mọyì bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe ń jẹ́ kó o ní ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kó sì yé ẹ?

Pọ́ọ̀lù “Kún fún Ẹ̀mí Mímọ́”

9. Kí ni ẹ̀mí mímọ́ ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ láti ṣe?

9 Ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, Ọlọ́run tún fún ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́. Sọ́ọ̀lù tá a wá mọ̀ sí Pọ́ọ̀lù ni ẹni náà. Lónìí, à ń jàǹfààní nínú ọ̀nà tí ẹ̀mí Ọlọ́run gbà ṣiṣẹ́ lára rẹ̀. Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ mẹ́rìnlá lára àwọn ìwé tó wà nínú Bíbélì. Bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe ran Pétérù lọ́wọ́ náà ló ṣe ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ láti ní òye àti láti kọ̀wé lọ́nà tó ṣe kedere nípa bí àwọn kan yóò ṣe rí àìleèkú àti àìdíbàjẹ́ gbà lọ́run. Ẹ̀mí mímọ́ fún Pọ́ọ̀lù lágbára láti ṣe ìwòsàn, láti lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ó sì tún jí òkú dìde! Àmọ́, ohun tó ṣe pàtàkì ju ìyẹn lọ ni agbára tí ẹ̀mí mímọ́ ń fúnni wà fún, ohun kan tó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe lọ́nà ìyanu.

10. Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe fún Pọ́ọ̀lù ní agbára láti sọ̀rọ̀?

10 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù “kún fún ẹ̀mí mímọ́” ó fi ìgboyà bá oníṣẹ́ oṣó kan wí. Alákòóso erékùṣù Kípírọ́sì tẹ́tí sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ. Ọ̀rọ̀ náà sì wọ̀ ọ́ lọ́kàn débi pé ó gba ẹ̀kọ́ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n fi kọ́ ọ, “níwọ̀n bí háà ti ṣe é sí ẹ̀kọ́ Jèhófà.” (Ìṣe 13:8-12) Ó ṣe kedere nígbà náà pé Pọ́ọ̀lù mọ bí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ti ṣe pàtàkì tó béèyàn bá ń sọ ohun tí Ìwé Mímọ́ fi kọ́ni. (Mát. 10:20) Lẹ́yìn náà, ó pàrọwà fún ìjọ tó wà ní Éfésù pé kí wọ́n bá òun rawọ́ ẹ̀bẹ̀ kí Ọlọ́run lè fún òun ní “agbára láti sọ̀rọ̀.”—Éfé. 6:18-20.

11. Báwo ni ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe darí Pọ́ọ̀lù?

11 Kì í ṣe pé ẹ̀mí mímọ́ fún Pọ́ọ̀lù lágbára láti sọ̀rọ̀ nìkan ni, àmọ́ láwọn ìgbà míì, ó ka sísọ ọ̀rọ̀ náà láwọn àgbègbè kan léèwọ̀ fún un. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe ń rìnrìn-àjò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì, ẹ̀mí Ọlọ́run ń darí rẹ̀. (Ìṣe 13:2; ka Ìṣe 16:6-10.) Jèhófà ṣì ń fi ẹ̀mí rẹ̀ darí iṣẹ́ ìwàásù náà. Bíi ti Pọ́ọ̀lù, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n jẹ́ onígbọràn ń sapá láti fi ìgboyà àti ìtara polongo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà darí wa lónìí yàtọ̀ sí bó ṣe rí lákòókò tí Pọ́ọ̀lù ṣe iṣẹ́ ìwàásù, ó yẹ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run ń lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti mú kí àwọn ẹni yíyẹ gbọ́ Ọ̀rọ̀ Rẹ̀.—Jòh. 6:44.

“Onírúurú Ọ̀nà Ìṣiṣẹ́”

12-14. Ṣé ọ̀nà kan náà ni ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbà ṣiṣẹ́ lára gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀? Ṣàlàyé.

12 Ǹjẹ́ ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa bí Jèhófà ṣe bù kún ìjọ àwọn ẹni àmì òróró ní ọ̀rúndún kìíní fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó ti ya ara wọn sí mímọ́ lóde òní ní ìṣírí lọ́nà tó ṣe pàtàkì? Bẹ́ẹ̀ ni, ó fún wọn níṣìírí! Ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti sọ fún ìjọ tó wà ní Kọ́ríńtì nípa ẹ̀bùn láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu ní ọjọ́ rẹ̀. Ó sọ pé: “Wàyí o, onírúurú ẹ̀bùn ní ń bẹ, ṣùgbọ́n ẹ̀mí kan náà ni ó wà; onírúurú iṣẹ́ òjíṣẹ́ sì ní ń bẹ, síbẹ̀ Olúwa kan náà ni ó wà; onírúurú ọ̀nà ìṣiṣẹ́ sì ní ń bẹ, síbẹ̀ Ọlọ́run kan náà ni ẹni tí ń mú gbogbo ọ̀nà ìṣiṣẹ́ náà ṣe nínú gbogbo ènìyàn.” (1 Kọ́r. 12:4-6, 11) Dájúdájú, ẹ̀mí mímọ́ lè ṣiṣẹ́ lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní onírúurú ọ̀nà fún ète pàtó kan. Ọlọ́run sì lè fún “agbo kékeré” Kristi àti “àwọn àgùntàn mìíràn” rẹ̀ ní ẹ̀mí mímọ́. (Lúùkù 12:32; Jòh. 10:16) Síbẹ̀, gbogbo ìgbà kọ́ ló máa ń ṣiṣẹ́ lọ́nà kan náà lára ẹnì kọ̀ọ̀kan tó wà nínú ìjọ.

13 Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀mí mímọ́ la fi ń yan àwọn alàgbà sípò. (Ìṣe 20:28) Àmọ́ kì í ṣe gbogbo àwọn tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn ló ń sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó nínú ìjọ. Kí la rí kọ́ nínú èyí? Ohun tá a rí kọ́ níbẹ̀ ni pé onírúurú ọ̀nà ni ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbà ṣiṣẹ́ lára àwọn tó wà nínú ìjọ.

14 Ẹ̀mí kan náà tó mú káwọn tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn mọ̀ dájú pé àwọn ti gba “ẹ̀mí ìsọdọmọ,” tàbí pé Ọlọ́run ti gba àwọn ṣọmọ, ni Jèhófà fi jí Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo dìde sí ìyè àìleèkú lókè ọ̀run. (Ka Róòmù 8:11, 15.) Ẹ̀mí kan náà yìí ni Jèhófà fi da ayé àtọ̀run. (Jẹ́n. 1:1-3) Ẹ̀mí mímọ́ yìí náà ni Jèhófà fi mú kí Bẹ́sálẹ́lì tóótun fún iṣẹ́ àkànṣe ti kíkọ́ àgọ́ ìjọsìn, òun ló fi fún Sámúsìnì lágbára láti ṣe àwọn ohun tó gba agbára àrà ọ̀tọ̀, tó sì tún fi mú kí Pétérù rìn lórí omi. Torí náà, ìyàtọ̀ wà láàárín kéèyàn ní ẹ̀mí Ọlọ́run àti kí Ọlọ́run fi ẹ̀mí rẹ̀ yanni, ńṣe ni kí Ọlọ́run fi ẹ̀mí rẹ̀ yanni wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà pàtàkì tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbà ṣiṣẹ́. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló máa ń pinnu ẹni tó máa fi ẹ̀mí rẹ̀ yàn.

15. Ṣé títí gbére ni Ọlọ́run á máa bá a nìṣó láti fi ẹ̀mí mímọ́ yanni? Ṣàlàyé.

15 Látìgbà tí Ọlọ́run ti ní àwọn ìránṣẹ́ tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, ìyẹn ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn, kó tiẹ̀ tó di pé ó bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ̀mí yanni, ni ẹ̀mí mímọ́ tó jẹ́ ipá ìṣiṣẹ́ Rẹ̀ ti ń ṣiṣẹ́ lónírúurú ọ̀nà lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́. Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ni Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ̀mí yanni, àmọ́ kò ní máa bá a nìṣó títí láé. Torí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé fífi ẹ̀mí yanni máa dópin, ẹ̀mí mímọ́ á ṣì máa bá a nìṣó láti ṣiṣẹ́ lára àwọn èèyàn Ọlọ́run kí wọ́n lè máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀ títí láé.

16. Kí ni ẹ̀mí Ọlọ́run ń ran àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ lọ́wọ́ láti ṣe lónìí?

16 Ohun pàtó wo ni ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ń mú kó ṣeé ṣe lórí ilẹ̀ ayé lónìí? Ìwé Ìṣípayá 22:17 dáhùn ìbéèrè yìí pé: “Ẹ̀mí àti ìyàwó ń bá a nìṣó ní sísọ pé: ‘Máa bọ̀!’ Kí ẹnikẹ́ni tí ń gbọ́ sì wí pé: ‘Máa bọ̀!’ Kí ẹnikẹ́ni tí òùngbẹ ń gbẹ sì máa bọ̀; kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.” Lónìí, ẹ̀mí Ọlọ́run ń mú káwọn Kristẹni ké sí “ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀” láti wá gba omi ìyè tí Jèhófà pèsè. Àwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn ló ń múpò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ yìí. Síbẹ̀, àwọn àgùntàn mìíràn pẹ̀lú ń dara pọ̀ mọ́ wọn láti ké sí àwọn èèyàn. Ẹ̀mí mímọ́ ló ń dárí àwọn tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn àti àwọn àgùntàn mìíràn láti máa jùmọ̀ ṣiṣẹ́ náà. Gbogbo wọ́n ti fi hàn pé àwọn ti ya ara àwọn sí mímọ́ fún Jèhófà nípa ṣíṣe ìrìbọmi “ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́.” (Mát. 28:19) Gbogbo wọn ń jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí ohun tí wọ́n ń fi ìgbésí ayé wọn ṣe, wọ́n sì ń jẹ́ kó ran àwọn lọ́wọ́ láti ní àwọn ànímọ́ tó para pọ̀ jẹ́ apá kan èso tẹ̀mí. (Gál. 5:22, 23) Bíi ti àwọn tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn, àwọn àgùntàn mìíràn ń jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run ràn wọ́n lọ́wọ́. Ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n ń rí gbà yìí ń jẹ́ kí wọ́n lè máa sa gbogbo ipá wọn kí wọ́n lè máa gbé ìgbé ayé tó mọ́ tó sì ń múnú Jèhófà dùn.—2 Kọ́r. 7:1; Ìṣí. 7:9, 14.

Máa Bá A Nìṣó ní Bíbéèrè fún Ẹ̀mí Mímọ́

17. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ní ẹ̀mí Ọlọ́run?

17 Torí náà, yálà o ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun lókè ọ̀run tàbí lórí ilẹ̀ ayé, Jèhófà lè fún ẹ ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” kó o bàa lè pa ìwà títọ́ rẹ mọ́ kó o sì gba èrè náà. (2 Kọ́r. 4:7) Àwọn èèyàn lè máa fi ẹ́ ṣẹ̀sín bó o ti ń bá a nìṣó láti máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, rántí ohun tí Bíbélì sọ pé “bí a bá ń gàn yín nítorí orúkọ Kristi, ẹ̀yin jẹ́ aláyọ̀, nítorí pé ẹ̀mí ògo, àní ẹ̀mí Ọlọ́run, ti bà lé yín.”—1 Pét. 4:14.

18, 19. Báwo ni Jèhófà ṣe máa fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn ẹ́ lọ́wọ́, kí nìyẹn sì mú kó o pinnu láti ṣe?

18 Ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run fún gbogbo àwọn tó bá ń fi tọkàntọkàn béèrè fún un. Kì í ṣe pé ó lè mú kó o túbọ̀ mọ nǹkan ṣe nìkan ni, àmọ́ ó tún lè mú kó túbọ̀ wù ẹ́ láti ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. “Ọlọ́run ni ẹni tí ń gbéṣẹ́ ṣe nínú yín, nítorí ti ìdùnnú rere rẹ̀, kí ẹ lè fẹ́ láti ṣe, kí ẹ sì gbé ìgbésẹ̀.” Bí ẹ̀mí mímọ́ tó jẹ́ ẹ̀bùn iyebíye ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ tá a sì ń sapá gidigidi láti “di ọ̀rọ̀ ìyè mú ṣinṣin,” a ó lè “máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà [wa] yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì.”—Fílí. 2:12, 13, 16.

19 Torí náà, bá a ṣe ní ìgbọ́kànlé kíkún pé ẹ̀mí Ọlọ́run á máa ràn wá lọ́wọ́, ẹ jẹ́ ká máa fi tọkàntọkàn ṣe gbogbo iṣẹ́ tí Jèhófà bá ní ká ṣe, ká di ọ̀jáfáfá, ká sì máa gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́. (Ják. 1:5) Ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ débi tó bá yẹ, kó o lè lóye Ọ̀rọ̀ rẹ̀, kó o lè kojú àwọn ìṣòro ìgbésí ayé, kó o sì máa wàásù ìhìn rere. Jésù ṣèlérí pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, a ó sì fi í fún yín; ẹ máa bá a nìṣó ní wíwá kiri, ẹ ó sì rí; ẹ máa bá a nìṣó ní kíkànkùn, a ó sì ṣí i fún yín.” Ẹ̀mí mímọ́ wà lára àwọn ohun tí Jésù sọ pé a lè béèrè fún. (Lúùkù 11:9, 13) Torí náà, máa bá a nìṣó láti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà pé kó jẹ́ kó o dà bí àwọn olùṣòtítọ́ ìgbàanì tí ẹ̀mí Ọlọ́run darí àtàwọn tó ń darí lóde òní.

Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

• Bíi ti Màríà, kí la lè ṣe tó máa jẹ́ ká rí ìbùkún gbà?

• Ọ̀nà wo ni ẹ̀mí Ọlọ́run gbà darí Pọ́ọ̀lù?

• Báwo ni ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe ń darí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Ẹ̀mí Ọlọ́run ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ láti borí àwọn ẹ̀mí búburú

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ìrètí yòówù káwọn Kristẹni ní lóde òní, Ọlọ́run lè jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ ràn wọ́n lọ́wọ́