Ẹ̀mí Ọlọ́run Darí Àwọn Olóòótọ́ Ayé Ìgbàanì
Ẹ̀mí Ọlọ́run Darí Àwọn Olóòótọ́ Ayé Ìgbàanì
“Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ tìkára rẹ̀ ti rán mi, àní ẹ̀mí rẹ̀.”—AÍSÁ. 48:16.
1, 2. Kí la nílò ká tó lè ní ìgbàgbọ́, báwo sì ni kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn olóòótọ́ ìgbàanì ṣe lè fún wa ní ìṣírí?
BÓ TILẸ̀ jẹ́ pé látìgbà Ébẹ́lì wá làwọn èèyàn ti ń fi hàn pé àwọn ní ìgbàgbọ́, síbẹ̀ “ìgbàgbọ́ kì í ṣe ohun ìní gbogbo ènìyàn.” (2 Tẹs. 3:2) Kí wá ló ń mú kí ẹnì kan ní ìgbàgbọ́, kí ló sì lè mú kó jẹ́ olóòótọ́? Kéèyàn tó lè ní ìgbàgbọ́, ó gbọ́dọ̀ lóye ohun tó ń gbọ́ látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Róòmù 10:17) Ìgbàgbọ́ jẹ́ apá kan èso ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. (Gál. 5:22, 23) Torí náà, a nílò ẹ̀mí mímọ́ ká tó lè ní ìgbàgbọ́ ká sì máa fi ìgbàgbọ́ náà sílò.
2 Àṣìṣe ló jẹ́ láti rò pé ńṣe ni wọ́n bí ìgbàgbọ́ mọ́ àwọn ọkùnrin àti obìnrin ìgbàgbọ́, pé kì í ṣe ohun téèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́. Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ, tá a kà nípa wọn nínú Bíbélì, jẹ́ àwọn èèyàn “tí ó ní ìmọ̀lára bí tiwa.” (Ják. 5:17) Àwọn náà ṣiyè méjì, wọ́n bára wọn nínú àwọn ipò tí kò fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, wọ́n sì ní àìlera, àmọ́ ẹ̀mí Ọlọ́run “sọ wọ́n di alágbára” kí wọ́n lè kojú àwọn ìpèníjà. (Héb. 11:34) Tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí ẹ̀mí Jèhófà ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́, ó máa jẹ́ kí àwa tá à ń gbé lóde òní lè máa bá a nìṣó láti jẹ́ olóòótọ́ bá a ṣe ń gbé ìgbé ayé wa, torí pé lákòókò tá a wà yìí, ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè sọ ìgbàgbọ́ wa di ahẹrẹpẹ.
Ẹ̀mí Ọlọ́run fún Mósè Lágbára
3-5. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé ẹ̀mí mímọ́ ran Mósè lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún un? (b) Kí ni àpẹẹrẹ Mósè kọ́ wa nípa bí Jèhófà ṣe ń fún wa ní ẹ̀mí rẹ̀?
3 Nínú gbogbo èèyàn tó gbáyé ní ọdún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Mósè “fi gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ jẹ́ ọlọ́kàn tútù jù lọ.” (Núm. 12:3) Iṣẹ́ bàǹtàbanta ni Ọlọ́run gbé lé ìránṣẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ onínú tútù yìí lọ́wọ́ ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Ẹ̀mí Ọlọ́run fún Mósè lágbára láti sọ àsọtẹ́lẹ̀, láti dájọ́, láti kọ̀wé, láti darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu. (Ka Aísáyà 63:11-14.) Síbẹ̀, ìgbà kan wà tí Mósè ṣàròyé pé iṣẹ́ yẹn ti wọ òun lọ́rùn. (Núm. 11:14, 15) Torí náà, Jèhófà “mú [díẹ̀] lára ẹ̀mí” tí ó wà lára Mósè ó sì fi sára àwọn àádọ́rin [70] ọkùnrin mìíràn kí wọ́n lè máa ràn án lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ náà. (Núm. 11:16, 17) Bó tilẹ̀ jọ pé ẹrù náà wọ Mósè lọ́rùn, òótọ́ ibẹ̀ ni pé òun nìkan kọ́ ló ń dá ẹrù náà gbé, bẹ́ẹ̀ sì ni Ọlọ́run kò ní dá iṣẹ́ náà dá àwọn àádọ́rin ọkùnrin tó sọ pé kó yàn kí wọ́n lè máa ràn án lọ́wọ́.
4 Ọlọ́run ti fún Mósè ní ẹ̀mí mímọ́ tó máa jẹ́ kó lè ṣe iṣẹ́ tó gbé fún un. Lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti mú díẹ̀ lára ẹ̀mí tó wà lára Mósè, ẹ̀mí mímọ́ kò wọ́n Mósè rárá. Mósè ní ànító, àwọn àádọ́rin àgbà ọkùnrin náà kò sì ní àníjù. Àwọn ohun tá a nílò àti ipò tó yí wa ká ni Jèhófà máa ń wò kó tó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. “Òun kì í fi ẹ̀mí fúnni nípasẹ̀ ìdíwọ̀n” àmọ́ ó máa ń fúnni “láti inú ẹ̀kún rẹ̀.”—Jòh. 1:16; 3:34.
5 Ṣé ò ń fara da àdánwò? Ṣé ohun tó pọn dandan pé kó o máa lo àkókò rẹ fún ń pọ̀ sí i? Ṣé ò ń sapá láti máa pèsè oúnjẹ àti ibùgbé fún ìdílé rẹ, ṣé o sì ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bó tilẹ̀ jẹ́ pé owó tó ò ń ná ń ga sí i tàbí tí o kò fi bẹ́ẹ̀ ní ìlera tó dára tó? Ṣé iṣẹ́ tó pọ̀ gan-an lò ń bójú tó nínú ìjọ? Ipò yòówù kó o bára ẹ, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run lè lo ẹ̀mí rẹ̀ láti fún ẹ ní okun tó o nílò.—Róòmù 15:13.
Ẹ̀mí Mímọ́ Mú Kí Bẹ́sálẹ́lì Tóótun
6-8. (a) Kí ni ẹ̀mí Ọlọ́run fún Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù lágbára láti ṣe? (b) Kí ló fi hàn pé ẹ̀mí Ọlọ́run darí Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù? (d) Kí nìdí tí àpẹẹrẹ Bẹ́sálẹ́lì fi fún wa ní ìṣírí gan-an?
6 Ìránṣẹ́ Jèhófà mìíràn tó gbáyé ní àkókò kan náà pẹ̀lú Mósè tó sì rí ẹ̀mí Ọlọ́run gbà ni Bẹ́sálẹ́lì. Àpẹẹrẹ rẹ̀ kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ tó pọ̀ nípa bí ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe lè máa darí wa. (Ka Ẹ́kísódù 35:30-35.) Jèhófà yan Bẹ́sálẹ́lì láti múpò iwájú nínú ṣíṣe àwọn ohun èlò fún àgọ́ ìjọsìn. Ṣé ó mọ̀ nípa iṣẹ́ ọnà kó tó di pé Ọlọ́run gbé iṣẹ́ bàǹtàbanta yìí lé e lọ́wọ́? Bóyá ni. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé iṣẹ́ mímọ bíríkì fáwọn ará Íjíbítì ló ṣe gbẹ̀yìn. (Ẹ́kís. 1:13, 14) Torí náà, báwo ni Bẹ́sálẹ́lì ṣe máa ṣe iṣẹ́ tó díjú tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́? Jèhófà “bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀mí Ọlọ́run tí ó jẹ́ ti ọgbọ́n, ti òye àti ti ìmọ̀ àti gbogbo onírúurú ọgbọ́n iṣẹ́ ọnà kún inú rẹ̀ àti fún ṣíṣe iṣẹ́ ọnà àwọn nǹkan àfọgbọ́nrọ . . . láti ṣe onírúurú nǹkan tí a fi ọgbọ́n hùmọ̀.” Ńṣe ni ẹ̀mí mímọ́ mú kí ẹ̀bùn àbímọ́ni yòówù kí Bẹ́sálẹ́lì ní sunwọ̀n sí i. Bí ọ̀rọ̀ ti Òhólíábù náà sì ṣe rí nìyẹn. Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù ti ní láti kẹ́kọ̀ọ́ dáadáa, torí pé kì í wulẹ̀ ṣe pé wọ́n ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún wọn nìkan ni, àmọ́ wọ́n tún kọ́ àwọn míì bí wọ́n ṣe máa ṣe iṣẹ́ náà. Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run fi í sí wọn lọ́kàn láti kọ́ àwọn míì.
7 Ohun mìíràn tó fi hàn pé ẹ̀mí Ọlọ́run ló darí Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù ni pé àwọn iṣẹ́ tí wọ́n ṣe wà fún ìgbà pípẹ́. Àwọn èèyàn ṣì lo àwọn ohun tí wọ́n ṣe ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣe wọ́n. (2 Kíró. 1:2-6) Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù kò dà bí àwọn tó máa ń ṣe nǹkan lóde òní tó jẹ́ pé wọ́n máa ń kọ orúkọ wọn sára ohun tí wọ́n bá ṣe tàbí kí wọ́n sàmì sí i. Jèhófà ni ọpẹ́ yẹ, torí pé òun ló mú kí wọ́n ṣàṣeyọrí.—Ẹ́kís. 36:1, 2.
8 Lóde òní, iṣẹ́ tí ń tánni lókun lè wà fún wa láti ṣe, kí èyí sì béèrè fún òye iṣẹ́ pàtàkì, irú bí ilé kíkọ́, ìwé títẹ̀, ṣíṣètò àwọn àpéjọ àgbègbè, pípín ohun táwọn tí ìjábá ṣẹlẹ̀ sí nílò fún wọn àti bíbá àwọn dókítà àti àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa ìdí tí a kò fi gbọ́dọ̀ lo ẹ̀jẹ̀. Nígbà míì, àwọn òṣìṣẹ́ tó mọ iṣẹ́ yìí dunjú ni wọ́n máa ń ṣe iṣẹ́ náà, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tí wọn kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n máa ń ṣe iṣẹ́ náà. Ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń mú kí wọ́n ṣàṣeyọrí. Ṣé o ti fìgbà kan rí fà sẹ́yìn láti gba iṣẹ́ kan tí wọ́n yàn fún ẹ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà torí pé ó ń ṣe ẹ́ bíi pé àwọn mìíràn tóótun jù ẹ́ lọ? Rántí pé ẹ̀mí Jèhófà lè mú kí ìmọ̀ àti òye tó o ní pọ̀ sí i, kó sì ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tó bá fún ẹ.
Ẹ̀mí Ọlọ́run Mú Kí Jóṣúà Ṣàṣeyọrí
9. Ipò wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ara wọn lẹ́yìn tí wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, ìbéèrè wo ló sì yẹ ká wá ìdáhùn sí?
9 Ẹ̀mí Ọlọ́run tún darí ẹlòmíì tó gbáyé ní àkókò kan náà pẹ̀lú Mósè àti Bẹ́sálẹ́lì. Láìpẹ́ lẹ́yìn tí àwọn èèyàn Ọlọ́run jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, àwọn ọmọ Ámálékì lọ gbéjà kò wọ́n láìnídìí. Àkókò ti wá tó wàyí fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti gbógun tì wọ́n. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò tíì di jagunjagun, síbẹ̀ wọ́n ní láti lọ jagun fún ìgbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn ìdáǹdè wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì. (Ẹ́kís. 13:17; 17:8) Ẹnì kan ní láti kó wọn lọ sójú ogun. Tá ni onítọ̀hún?
10. Kí nìdí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ja àjàṣẹ́gun nígbà tí Jóṣúà kó wọn lọ jagun?
10 Jóṣúà ni Ọlọ́run yàn. Àmọ́ èwo lára iṣẹ́ tí Jóṣúà ń ṣe tẹ́lẹ̀ ló lè mú kó tóótun fún iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an yìí? Ṣé ti pé ó jẹ́ ẹrú ni? Pé ó fi èérún pòròpórò ṣe bíríkì? Àbí ti pé ó kó mánà nínú aginjù? Òótọ́ ni pé ìjòyè látinú ẹ̀yà Éfúráímù ni Eliṣámà tó jẹ́ bàbá-bàbá Jóṣúà ó sì jẹ́ olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀kẹ́ márùn-ún ó lé ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ àti ọgọ́rùn-ún [108,100] tí wọ́n jẹ́ ọ̀kan lára ìpín ẹ̀yà mẹ́ta Ísírẹ́lì. (Núm. 2:18, 24; 1 Kíró. 7:26, 27) Síbẹ̀, Jèhófà kò sọ pé kí Mósè yan Eliṣámà tàbí ọmọ rẹ̀ Núnì. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jóṣúà ni Jèhófà sọ pé ó máa jẹ́ aṣáájú ẹgbẹ́ ọmọ ogun tó máa pa àwọn ọ̀tá run. Ìjà náà fẹ́rẹ̀ẹ́ gba odindi ọjọ́ kan gbáko. Àmọ́, torí pé Jóṣúà ṣe gbogbo ohun tí Ọlọ́run sọ fún un tó sì mọrírì bí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ṣe tọ́ ọ sọ́nà, Ísírẹ́lì ja àjàṣẹ́gun.—Ẹ́kís. 17:9-13.
11. Bíi ti Jóṣúà, báwo la ṣe lè ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn mímọ́?
11 Lẹ́yìn ikú Mósè, Jóṣúà tó “kún fún ẹ̀mí ọgbọ́n,” di aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Diu. 34:9) Ẹ̀mí mímọ́ kò fún Jóṣúà ní agbára láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ tàbí láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu bíi ti Mósè, àmọ́ ó mú kó ṣeé ṣe fún un láti jẹ́ olórí fún àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì tí wọ́n ja ọ̀pọ̀ ogun kí wọ́n tó lè gba ilẹ̀ Kénáánì. Lónìí, ó lè ṣe wá bíi pé a kò ní ìrírí tàbí pé a kò tóótun tó láti ṣe àwọn ohun kan nínú iṣẹ́ ìsìn mímọ́ wa. Síbẹ̀, bíi ti Jóṣúà, ó dá wa lójú pé a máa ṣàṣeyọrí tá a bá ń tẹ̀ lé gbogbo ìtọ́ni tí Ọlọ́run ń fún wa.—Jóṣ. 1:7-9.
‘Ẹ̀mí Jèhófà Bo Gídíónì’
12-14. (a) Kí la rí kọ́ nínú bí ọ̀ọ́dúnrún [300] ọkùnrin ṣe borí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ńlá ti àwọn ará Mídíánì? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe fi Gídíónì lọ́kàn balẹ̀? (d) Báwo ni Jèhófà ṣe ń fi wá lọ́kàn balẹ̀ lónìí?
12 Lẹ́yìn ikú Jóṣúà, Jèhófà ń bá a nìṣó láti jẹ́ káwọn olóòótọ́ máa rí bí agbára rẹ̀ ṣe lè fún wọn lókun. Ìwé Àwọn Onídàájọ́ kún fún ìtàn àwọn èèyàn tó jẹ́ pé “láti ipò àìlera, a sọ wọ́n di alágbára.” (Héb. 11:34) Ọlọ́run lo ẹ̀mí mímọ́ láti fún Gídíónì lágbára kó lè máa jà fún àwọn èèyàn Rẹ̀. (Oníd. 6:34) Àmọ́, ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí Gídíónì kó jọ kò tó nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mídíánì. Ó máa gba pé kí ọmọ ogun Ísírẹ́lì kan ṣoṣo kojú ọmọ ogun Mídíánì mẹ́rin. Síbẹ̀, lójú Jèhófà, ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ísírẹ́lì tí kò tó nǹkan yẹn ti pọ̀ jù. Ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló pàṣẹ pé kí Gídíónì dín ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ kù títí tó fi di pé ọmọ ogun Ísírẹ́lì kan ṣoṣo ní láti kojú irínwó lé àádọ́ta [450] ọmọ ogun Mídíánì. (Oníd. 7:2-8; 8:10) Bó ṣe wu Jèhófà pé kí ọ̀ràn rí nìyẹn. Kó lè jẹ́ pé báwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ṣẹ́gun, ẹnikẹ́ni nínú wọn kò ní lè fọ́nnu pé ìsapá tàbí ọgbọ́n ẹ̀dá ló mú káwọn ṣẹ́gun.
13 Gídíónì àtàwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣe tán. Ká sọ pé o wà lára ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí kò tó nǹkan yẹn, ṣé ọkàn rẹ máa balẹ̀ bó o bá mọ̀ pé wọ́n ti ní káwọn tó ń bẹ̀rù àtàwọn tí kò wà lójúfò tó lára yín pa dà sílé? Àbí ẹ̀rù á máa bà ẹ́ bó o ṣe ń ronú nípa ibi tọ́rọ̀ náà lè já sí? Kò sídìí láti méfò nípa bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára Gídíónì. Ó ṣe ohun tí Jèhófà sọ fún un pé kó ṣe! (Ka Àwọn Onídàájọ́ 7:9-14.) Jèhófà kò bínú sí Gídíónì torí pé ó béèrè fún àmì tó máa jẹ́ kó mọ̀ pé Ọlọ́run á wà pẹ̀lú òun. (Oníd. 6:36-40) Ńṣe ló fún ìgbàgbọ́ Gídíónì lágbára.
14 Agbára tí Jèhófà ní láti gbani kò láàlà. Ó lè gba àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ ìṣòro èyíkéyìí, bó bá tiẹ̀ gba pé kó lo àwọn tó jọ pé wọn kò lágbára tàbí tí wọn kò lè gbèjà ara wọn. Nígbà míì, ó lè ṣe wá bíi pé àwọn ọ̀tá pọ̀ jù wá lọ tàbí kí ìṣòro mù wá dọ́rùn. A kò ní retí pé kí Ọlọ́run ṣe iṣẹ́ ìyanu kan tó máa mú ká gbà pé ó wà pẹ̀lú wa bó ti ṣe fún Gídíónì, àmọ́ a lè rí ọ̀pọ̀ ìtọ́sọ́nà àti ohun tó máa fi wá lọ́kàn bálẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti nípasẹ̀ ìjọ tó ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ darí. (Róòmù 8:31, 32) Àwọn ìlérí tó fi bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó hàn máa fún ìgbàgbọ́ wa lókun wọ́n sì máa jẹ́ ká mọ̀ pé òun gan-an ni Olùrànlọ́wọ́ wa!
“Ẹ̀mí Jèhófà Bà Lé Jẹ́fútà Wàyí”
15, 16. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ohun tó dáa ni ọmọbìnrin Jẹ́fútà ṣe, báwo lèyí sì ṣe lè fún àwọn òbí ní ìṣírí?
15 Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ mìíràn yẹ̀ wò. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń lọ bá àwọn ọmọ Ámónì jagun, ẹ̀mí Jèhófà “bà lé Jẹ́fútà.” Jẹ́fútà ti ń hára gàgà láti ṣẹ́gun kó bàa lè gba ògo fún Jèhófà, torí náà ó jẹ́ ẹ̀jẹ́ kan tó ná an ní ohun tó ṣeyebíye. Ó jẹ́jẹ̀ẹ́ pé bí Ọlọ́run bá fi àwọn ọmọ Ámónì lé òun lọ́wọ́, ẹni tó bá kọ́kọ́ gba ẹnu ilẹ̀kùn wá pàdé òun lẹ́yìn tí òun bá pa dà délé máa di ti Jèhófà. Nígbà tí Jẹ́fútà pa dà délé lẹ́yìn tó ti ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ámónì, ọmọbìnrin rẹ̀ sáré wá pàdé rẹ̀. (Oníd. 11:29-31, 34) Ṣé èyí ya Jẹ́fútà lẹ́nu? Bóyá ni, torí pé ọmọ kan ṣoṣo ló ní. Ó mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣẹ nípa yíyọ̀ǹda pé kí ọmọbìnrin rẹ̀ fi gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ní ibùjọsìn Jèhófà tó wà ní Ṣílò. Torí pé ọmọbìnrin Jẹ́fútà ń fòótọ́ sin Jèhófà, ó gbà pé ó pọn dandan kóun mú ẹ̀jẹ́ bàbá òun ṣẹ. (Ka Àwọn Onídàájọ́ 11:36.) Ẹ̀mí Jèhófà fún àwọn méjèèjì ní okun tí wọ́n nílò.
16 Kí nìdí tí ọmọbìnrin Jẹ́fútà fi fínnú fíndọ̀ yááfì ara rẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run? Kò sí iyè méjì pé bó ṣe ń kíyè sí ìtara bàbá rẹ̀ àti ìfọkànsìn tí bàbá rẹ̀ ní fún Ọlọ́run mú kó ní ìgbàgbọ́ tó lágbára. Ẹ̀yin òbí, àwọn ọmọ yín ń kíyè sí àpẹẹrẹ yín o. Ìpinnu tẹ́ ẹ bá ṣe máa jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òótọ́ lẹ gba ohun tẹ́ ẹ̀ ń sọ gbọ́. Àwọn ọmọ yín ń kíyè sí bẹ́ ẹ ṣe ń gbàdúrà látọkànwá, wọ́n ń rí bẹ́ ẹ ṣe ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó gbéṣẹ́, wọ́n sì ń kíyè sí bẹ́ ẹ ṣe ń sapá láti fi ọkàn-àyà pípé sin Jèhófà. Bí àwọn ọmọ yín ṣe ń ṣe àkíyèsí yìí, ó ṣeé ṣe kó wá wu àwọn náà gan-an pé kí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn láti ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Èyí á sì mú kẹ́ ẹ láyọ̀.
‘Ẹ̀mí Jèhófà Bẹ̀rẹ̀ sí Ṣiṣẹ́ Lára’ Sámúsìnì
17. Kí ni ẹ̀mí Ọlọ́run fún Sámúsìnì lágbára láti ṣe?
17 Ẹ jẹ́ ká tún sọ̀rọ̀ nípa ẹlòmíì tí ẹ̀mí Ọlọ́run ràn lọ́wọ́. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà ní ìgbèkùn àwọn Filísínì, Bíbélì sọ pé “nígbà tí ó ṣe, ẹ̀mí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí sún” Sámúsìnì ṣiṣẹ́ kó bàa lè gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Oníd. 13:24, 25) Ẹ̀mí Ọlọ́run fún Sámúsìnì ní agbára tó pabanbarì èyí tó mú kó ṣe àwọn ohun àràmàǹdà. Nígbà táwọn Filísínì rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n mú Sámúsìnì, “ẹ̀mí Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lára rẹ̀, àwọn ìjàrá tí ó wà ní apá rẹ̀ sì wá dà bí àwọn fọ́nrán òwú ọ̀gbọ̀ tí iná ti jó gbẹ, tí àwọn ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ rẹ̀ fi yọ́ kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.” (Oníd. 15:14) Nígbà tó yá, Sámúsìnì ṣe ìpinnu tí kò dára, èyí tó mú kó pàdánù agbára rẹ̀. Síbẹ̀, nígbà tí Sámúsìnì kò lágbára mọ́, Ọlọ́run sọ ọ́ di alágbára “nípasẹ̀ ìgbàgbọ́.” (Héb. 11:32-34; Oníd. 16:18-21, 28-30) Nítorí bí ọ̀ràn ṣe rí nígbà yẹn, ẹ̀mí Jèhófà ṣiṣẹ́ lára Sámúsìnì lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Síbẹ̀, ìṣírí ńláǹlà ni àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i yìí jẹ́ fún wa. Lọ́nà wo?
18, 19. (a) Kí ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Sámúsìnì mú kó dá wa lójú? (b) Àǹfààní wo lo ti rí nínú àpẹẹrẹ àwọn olùṣòtítọ́ tá a ti gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
18 Ẹ̀mí mímọ́ tó fún Sámúsìnì lágbára ni àwa náà gbára lé. A ní ìgbọ́kànlé pé ó máa ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ tí Jésù gbé fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti ṣe, ìyẹn ni “láti wàásù fún àwọn ènìyàn àti láti jẹ́rìí kúnnákúnná.” (Ìṣe 10:42) Ó lè má rọrùn fún wa láti ṣe iṣẹ́ yìí. Àmọ́, a dúpẹ́ pé Jèhófà ń fi ẹ̀mí rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ ká bàa lè ṣe gbogbo ohun tó fẹ́ ká ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀! Torí náà, bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́, a lè sọ bíi ti wòlíì Aísáyà pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ tìkára rẹ̀ ti rán mi, àní ẹ̀mí rẹ̀.” (Aísá. 48:16) Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀mí Ọlọ́run ló rán wa! A gbájú mọ́ iṣẹ́ náà, ó sì dá wa lójú pé Jèhófà á mú ká túbọ̀ tóótun bíi ti Mósè, Bẹ́sálẹ́lì àti Jóṣúà. À ń lo “idà ẹ̀mí, èyíinì ni, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,” ó sì dá wa lójú pé Jèhófà máa fún wa lágbára bíi ti Gídíónì, Jẹ́fútà àti Sámúsìnì. (Éfé. 6:17, 18) Tá a bá ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ohun ìdènà, àwa náà lè di alágbára ńlá nípa tẹ̀mí bí Sámúsìnì ṣe jẹ́ alágbára ńlá nípa tara.
19 Láìsí àní-àní, Jèhófà máa ń bù kún àwọn tó bá ń fi ìgboyà kọ́wọ́ ti ìjọsìn tòótọ́. Bí a bá ṣe ń fàyè gba ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run láti máa darí wa, bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ wa á túbọ̀ máa pọ̀ sí i. Torí náà, ó dára pé ká ṣe àgbéyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ fífanimọ́ra tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì pẹ̀lú. Ìyẹn á jẹ́ ká rí bí ẹ̀mí Jèhófà ṣe ṣiṣẹ́ lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ ní ọ̀rúndún kìíní, ṣáájú àti lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Èyí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
Kí nìdí tó fi fún ẹ níṣìírí láti mọ ọ̀nà tí ẹ̀mí Ọlọ́run gbà ṣiṣẹ́ lára . . .
• Mósè?
• Bẹ́sálẹ́lì?
• Jóṣúà?
• Gídíónì?
• Jẹ́fútà?
• Sámúsìnì?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 22]
Ẹ̀mí Ọlọ́run lè sọ wá di alágbára ńlá nípa tẹ̀mí bí Sámúsìnì ṣe jẹ́ alágbára ńlá nípa tara
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Ẹ̀yin òbí, bẹ́ ẹ bá jẹ́ onítara, àwọn ọmọ yín á fẹ́ láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ yín