Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Jẹ́ Kí Ẹ̀mí Ọlọ́run Máa Darí Wa?
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Jẹ́ Kí Ẹ̀mí Ọlọ́run Máa Darí Wa?
“Ìwọ ni Ọlọ́run mi. Ẹ̀mí rẹ dára; kí ó máa ṣamọ̀nà mi.”—SM. 143:10.
1. Ìrànlọ́wọ́ wo lo nílò tó o bá ń lọ sí ibì kan tí o kò mọ̀?
JẸ́ KÁ sọ pé ò ń lọ sí ibì kan tí o kò mọ̀. Tí ẹnì kan tó o fọkàn tán, tó mọ ibẹ̀ dáadáa, sì júwe ọ̀nà fún ẹ. Ó dájú pé o kò ní sọ nù bó o bá gba ibi tó ní kó o gbà.
2, 3. (a) Agbára ńlá wo ni Jèhófà lò ní àìmọye ọdún sẹ́yìn? (b) Kí nìdí tá a fi lè retí pé kí agbára ńlá tí kò ṣeé fojú rí, tí Ọlọ́run ń lò máa darí ìgbésí ayé wa lónìí?
2 A nílò ohun tí yóò máa darí wa gba ibi tó yẹ nínú ayé tá à ń gbé yìí. Nínú Bíbélì, àwọn ẹsẹ tó bẹ̀rẹ̀ ìwé Jẹ́nẹ́sísì orí kìíní sọ nípa ohun kan tó lè máa darí wa. Nígbà tí ẹsẹ ìkíní ń ṣàlàyé ohun tí Jèhófà ṣe ní àìmọye ọdún sẹ́yìn, ó ní: “Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” Ó ṣe èyí nípa rírán agbára ńlá kan jáde. Ẹsẹ kejì sọ nípa agbára ńlá yìí pé: “Ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run sì ń lọ síwá-sẹ́yìn.” (Jẹ́n. 1:1, 2) Kí ló ń lọ síwá-sẹ́yìn? Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ni. Ẹ̀mí yìí ni Jèhófà fi dá wa, òun ló sì fi dá gbogbo nǹkan yòókù tó dá.—Jóòbù 33:4; Sm. 104:30.
3 Kì í wulẹ̀ ṣe pé Jèhófà lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti dá wa nìkan ni, àmọ́ ó tún ń lò ó láti máa darí wa. Jésù, Ọmọ Ọlọ́run, sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ̀mí . . . yóò ṣamọ̀nà yín sínú òtítọ́ gbogbo.” (Jòh. 16:13) Kí ni ẹ̀mí tí Jésù sọ yìí túmọ̀ sí, kí sì nìdí tó fi yẹ ká fẹ́ kí ẹ̀mí náà máa darí wa?
Ohun Tí Ẹ̀mí Mímọ́ Jẹ́
4, 5. (a) Èrò tí kò tọ̀nà wo ni àwọn tó gba Mẹ́talọ́kan gbọ́ ní nípa ohun tí ẹ̀mí mímọ́ jẹ́? (b) Kí lo lè sọ nípa ohun tí ẹ̀mí mímọ́ jẹ́?
4 Ó ṣeé ṣe kí díẹ̀ lára àwọn èèyàn tó o máa ń wàásù fún lóde ẹ̀rí ní èrò tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu nípa ẹ̀mí mímọ́. Àwọn tó gba Mẹ́talọ́kan gbọ́ ní èrò tí kò tọ̀nà nípa ẹ̀mí mímọ́ pé ó jẹ́ ẹni ẹ̀mí tó bá Ọlọ́run Baba dọ́gba. (1 Kọ́r. 8:6) Àmọ́, ó rọrùn láti rí i pé ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan kò bá Ìwé Mímọ́ mu.
5 Nígbà náà, kí wá ni ẹ̀mí mímọ́ jẹ́? Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé kan nínú Jẹ́nẹ́sísì 1:2 látinú Bíbélì New World Translation of the Holy Scriptures—With References sọ pé: “Yàtọ̀ sí pé wọ́n máa ń túmọ̀ èdè Hébérù náà ruʹach sí ‘ẹ̀mí,’ wọ́n tún máa ń túmọ̀ rẹ̀ sí ‘ẹ̀fúùfù’ tàbí kí wọ́n tú u sí àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn tó fi hàn pé ipá ìṣiṣẹ́ tí kò ṣeé fojú rí ló túmọ̀ sí.” (Fi wé àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé Jẹ́nẹ́sísì 3:8; 8:1, NW.) Bí a kò ṣe lè fojú rí ẹ̀fúùfù síbẹ̀ tá a máa ń mọ̀ bó bá ń fẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ni a kò lè fojú rí ẹ̀mí mímọ́, àmọ́ a lè rí ohun tó ń ṣe. Ẹ̀mí mímọ́ yìí ni agbára tí Ọlọ́run máa ń lò láti darí èèyàn tàbí ohunkóhun mìíràn láti ṣe ohun tó fẹ́. Ṣé ó wá ṣòro láti gbà gbọ́ pé irú agbára àgbàyanu bẹ́ẹ̀ lè wá látọ̀dọ̀ Ẹni mímọ́, ìyẹn Ọlọ́run Olódùmarè? Rárá o!—Ka Aísáyà 40:12, 13.
6. Ẹ̀bẹ̀ pàtàkì wo ni Dáfídì bẹ Jèhófà?
6 Ǹjẹ́ Jèhófà lè máa bá a nìṣó láti fi ẹ̀mí rẹ̀ darí wa? Ó ṣèlérí fún onísáàmù náà Dáfídì pé: “Èmi yóò mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, èmi yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí ìwọ yóò máa tọ̀.” (Sm. 32:8) Ǹjẹ́ Dáfídì fẹ́ kí Ọlọ́run ṣe bẹ́ẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni, torí pé ó bẹ Jèhófà pé: “Kọ́ mi láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ, nítorí pé ìwọ ni Ọlọ́run mi. Ẹ̀mí rẹ dára; kí ó máa ṣamọ̀nà mi.” (Sm. 143:10) Ó gbọ́dọ̀ wu àwa náà pé kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí wa, a sì gbọ́dọ̀ múra tán láti gba ibi tó bá darí wa sí. Kí nìdí? Ẹ jẹ́ ká jíròrò ìdí mẹ́rin tó fi yẹ ká fẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí wa.
A Kò Lè Darí Ara Wa
7, 8. (a) Kí nìdí tí a kò fi lè darí ara wa láìsí ọwọ́ Ọlọ́run níbẹ̀? (b) Àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé ó pọn dandan kí Ọlọ́run máa darí wa nínú ètò àwọn nǹkan búburú yìí?
7 Ìdí àkọ́kọ́ tó fi yẹ ká jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí wa ni pé a kò lè darí ara wa. “Láti darí” túmọ̀ sí láti “fini mọ̀nà tàbí láti tọ́ka ibi téèyàn máa gbà fún un.” Àmọ́, Jèhófà kò dá wa pé ká máa darí ara wa, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti pé a jẹ́ aláìpé. Jeremáyà tó jẹ wòlíì Ọlọ́run kọ̀wé pé: “Mo mọ̀ dáadáa, Jèhófà, pé ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jer. 10:23) Kí nìdí tá ò fi lè darí ara wa? Ọlọ́run ṣàlàyé ìdí tí a kò fi lè darí ara wa fún Jeremáyà. Nígbà tí Jèhófà ń sọ nípa irú ẹni tá a jẹ́ ní inú, ó sọ pé: “Ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà. Ta ni ó lè mọ̀ ọ́n?”—Jer. 17:9; Mát. 15:19.
8 Bí ẹnì kan kò bá mọ̀nà, tí kò sì sẹ́ni tó máa fi í mọ̀nà, ǹjẹ́ kò ní dà bí ìgbà tó ń fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu bó bá korí bọ inú aginjù tí kò dé rí lóun nìkan? Níwọ̀n bí kò ti mọ ibi tí omi wà àti bó ṣe máa rí oúnjẹ jẹ, tí kò sì mọ bó ṣe máa débi tó ń lọ láì fara pa, ńṣe ló wulẹ̀ ń fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu. Bó ṣe rí náà nìyẹn bí ẹnì kan bá rò pé òun lè darí ara òun nínú ayé búburú yìí láìgbà kí Ọlọ́run fi ọ̀nà tó tọ́ han òun. Ńṣe ni irú ẹni bẹ́ẹ̀ ń fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu. Ọ̀nà kan tá a lè gbà kógo já nínú ètò àwọn nǹkan yìí ni pé ká gbàdúrà sí Jèhófà ká sì bẹ̀ ẹ́ bí Dáfídì ti ṣe, pé: “Jẹ́ kí àwọn ìṣísẹ̀ mi fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin ní àwọn òpó ọ̀nà rẹ, nínú èyí tí a kì yóò ti mú kí àwọn ipasẹ̀ mi kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n dájúdájú.” (Sm. 17:5; 23:3) Báwo la ṣe lè rí irú ìtọ́sọ́nà yìí gbà?
9. Bá a ṣe fi hàn nínú àwòrán ojú ìwé 17, báwo ni ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe lè darí wa síbi tó tọ́?
9 Tá a bá níwà ìrẹ̀lẹ̀ tá a sì ṣe tán láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó máa jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ máa darí àwọn ìṣísẹ̀ wa síbi tó tọ́. Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ tàbí ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run ṣe máa ràn wá lọ́wọ́? Jésù ṣàlàyé fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Olùrànlọ́wọ́ náà, ẹ̀mí mímọ́, èyí tí Baba yóò rán ní orúkọ mi, èyíinì ni yóò kọ́ yín ní ohun gbogbo, tí yóò sì mú gbogbo ohun tí mo ti sọ fún yín padà wá sí ìrántí yín.” (Jòh. 14:26) Tá a bá ń gbàdúrà déédéé ká tó kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tó fi mọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ Kristi, ẹ̀mí mímọ́ á jẹ́ kí òye tá a ní nípa ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n Jèhófà pọ̀ sí i, ká bàa lè máa ṣe ohun tó fẹ́. (1 Kọ́r. 2:10) Ní àfikún sí ìyẹn, bí ohun tí a kò rò tẹ́lẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí wa, ẹ̀mí Ọlọ́run máa fi ọ̀nà tó yẹ ká tọ̀ hàn wá. Ó máa jẹ́ ká rántí àwọn ìlànà Bíbélì tá a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ àti bá a ṣe lè máa fi àwọn ìlànà náà sílò ká bàa lè ṣe ìpinnu tó tọ́.
Ẹ̀mí Ọlọ́run Darí Jésù
10, 11. Kí ni Ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Ọlọ́run retí pé kí ẹ̀mí mímọ́ ṣe fóun, báwo sì ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe ràn án lọ́wọ́?
10 Ìdí kejì tó fi yẹ ká jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa darí wa ni pé Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ darí Ọmọ tirẹ̀ náà. Kí Ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Ọlọ́run tó wá sórí ilẹ̀ ayé, ó mọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ pé: “Ẹ̀mí Jèhófà yóò sì bà lé e, ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òye, ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbára ńlá, ẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù Jèhófà.” (Aísá. 11:2) Ẹ fi ojú inú wo bó ṣe máa wu Jésù tó láti rí ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí Ọlọ́run gbà nínú ipò tó bára rẹ̀ nígbà tó fi gbé lórí ilẹ̀ ayé!
11 Ọ̀rọ̀ Jèhófà ṣẹ. Ìwé Ìhìn Rere ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ kété lẹ́yìn tí Jòhánù ti ri Jésù bọmi. Ó sọ pé: “Wàyí o, Jésù, bí ó ti kún fún ẹ̀mí mímọ́, ó kúrò ní Jọ́dánì, ẹ̀mí sì ṣamọ̀nà rẹ̀ káàkiri nínú aginjù.” (Lúùkù 4:1) Nígbà tí Jésù fi wà nínú aginjù, tó ń gbààwẹ̀, tó ń gbàdúrà, tó sì ń ṣàṣàrò, ó ṣeé ṣe kí Jèhófà fún Ọmọ rẹ̀ ní ìtọ́ni àti ìlàlóye nípa àwọn nǹkan tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí i. Ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run ń darí èrò àti ọkàn Jésù, ó ń mú kó ronú lọ́nà tó tọ́ kó sì ṣe àwọn ìpinnu tó yẹ. Èyí mú kó ṣeé ṣe fún Jésù láti mọ ohun tó yẹ kó ṣe bí ọ̀ràn èyíkéyìí bá wáyé, ohun tí Bàbá rẹ̀ sì fẹ́ kó ṣe gan-an ló ṣe.
12. Kí nìdí tó fi pọn dandan pé ká béèrè pé kí Ọlọ́run jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ máa darí wa?
12 Jésù mọyì ipa ribiribi tí ẹ̀mí Ọlọ́run kó nínú ìgbésí ayé rẹ̀, torí náà ó jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n máa béèrè fún ẹ̀mí mímọ́ kí wọ́n sì jẹ́ kó máa darí wọn. (Ka Lúùkù 11:9-13.) Kí nìdí tíyẹn fi ṣe pàtàkì gan-an fún wa? Ìdí ni pé ó lè yí èrò wa pa dà kó sì jẹ́ ká ní èrò inú ti Kristi. (Róòmù 12:2; 1 Kọ́r. 2:16) Tá a bá ń jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí ìgbésí ayé wa, a ó lè máa ronú bíi ti Kristi a ó sì máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.—1 Pét. 2:21.
Ẹ̀mí Ayé Lè Darí Wa Gba Ibi Tí Kò Yẹ
13. Kí ni ẹ̀mí ayé, kí ló sì máa ń ṣe?
13 Ìdí kẹta tó fi yẹ ká jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí wa ni pé bí ẹ̀mí Ọlọ́run kò bá darí wa, ẹ̀mí àìmọ́ tó ń darí ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn lónìí lè ṣì wá lọ́nà. Ayé yìí ní ẹ̀mí tirẹ̀, ẹ̀mí yìí lágbára, ó sì máa ń fi ipá mú àwọn èèyàn ṣe ohun tó lòdì pátápátá sí nǹkan tí ẹ̀mí mímọ́ máa fẹ́ ká ṣe. Dípò tí ẹ̀mí ayé á fi mú káwọn èèyàn ní èrò inú ti Kristi, ńṣe ló máa ń mú kí èrò wọn àti ohun tí wọ́n ń ṣe jọ ti Sátánì tó ń ṣàkóso ayé. (Ka Éfésù 2:1-3; Títù 3:3.) Bí ẹnì kan bá gbà pé kí ẹ̀mí ayé máa darí òun, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn iṣẹ́ ti ara, ohun tó máa yọrí sí kò ní dára, kò sì ní jẹ́ kó jogún Ìjọba Ọlọ́run.—Gál. 5:19-21.
14, 15. Báwo la ṣe lè gbéjà ko ẹ̀mí ayé?
14 Jèhófà ti mú kó ṣeé ṣe fún wa láti gbéjà ko ẹ̀mí ayé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ká “máa bá a lọ ní gbígba agbára nínú Olúwa àti nínú agbára ńlá okun rẹ̀ . . . [ká] bàa lè dúró tiiri ní ọjọ́ burúkú náà.” (Éfé. 6:10, 13) Jèhófà ń lo ẹ̀mí rẹ̀ láti fún wa lágbára ká má bàa gba Sátánì láyè láti darí wa gba ibi tí kò yẹ. (Ìṣí. 12:9) Ẹ̀mí ayé lágbára, kò sì ṣeé sá fún pátápátá. Àmọ́, ohun tá a lè ṣe wà tí kò fi ní sọ wá dìbàjẹ́. Ẹ̀mí mímọ́ lágbára jù ú lọ, ó sì máa ràn wá lọ́wọ́!
15 Àpọ́sítélì Pétérù sọ nípa àwọn tó fi ẹ̀sìn Kristẹni sílẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní pé: “Ní pípa ipa ọ̀nà títọ́ tì, a ti ṣì wọ́n lọ́nà.” (2 Pét. 2:15) Ẹ wo bó ṣe yẹ ká kún fún ọpẹ́ gidigidi tó pé “kì í ṣe ẹ̀mí ayé ni àwa gbà, bí kò ṣe ẹ̀mí tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá”! (1 Kọ́r. 2:12) Tá a bá ń jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa darí wa, tá a sì ń lo gbogbo ìpèsè tí Jèhófà ń mú kó wà lárọ̀ọ́wọ́tó wa kí àjọṣe tá a ní pẹ̀lú rẹ̀ má bàa bà jẹ́, a ó lè gbéjà ko ẹ̀mí èṣù tó ń darí ayé búburú yìí.—Gál. 5:16.
Ẹ̀mí Mímọ́ Ń Mú Ká Ní Àwọn Ànímọ́ Rere
16. Àwọn ànímọ́ wo ni ẹ̀mí mímọ́ ń mú ká ní?
16 Ìdí kẹrin tó fi yẹ ká fẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa ṣiṣẹ́ nínú wa ni pé ó máa ń mú kí àwọn tó bá gbà kó máa darí ìgbésí ayé àwọn ní àwọn ànímọ́ rere. (Ka Gálátíà 5:22, 23.) Nínú gbogbo wa, ta ni kò ní fẹ́ kóun túbọ̀ máa fìfẹ́ hàn, kí inú òun máa dùn, kóun sì tún jẹ́ ẹni tó nífẹ̀ẹ́ àlàáfíà? Ta ni nínú wa tí kò ní fẹ́ kí ìpamọ́ra, inú rere àti ìwà rere tóun ní pọ̀ sí i? Ta ni nínú wa tí kò ní fẹ́ láti gbádùn àǹfààní tó wà nínú kéèyàn túbọ̀ ní ìgbàgbọ́, ìwà tútù àti ìkóra-ẹni-níjàánu? Àwa, àwọn ìbátan wa àtàwọn ará ìjọ wa ń jàǹfààní látinú àwọn ànímọ́ rere tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń mú ká ní nínú ìgbésí ayé wa. Ńṣe ló yẹ ká máa bá a nìṣó láti ní àwọn ànímọ́ náà; wọn kò lè pọ̀ jù, kò sì sí èyí tí a kò nílò lára àwọn ànímọ́ tí wọ́n para pọ̀ jẹ́ èso ti ẹ̀mí yìí.
17. Báwo la ṣe lè túbọ̀ ní ọ̀kan lara àwọn ànímọ́ tó para pọ̀ jẹ́ èso ti ẹ̀mí?
17 Ó bọ́gbọ́n mu ká yẹ ara wa wò ká lè rí i dájú pé ọ̀rọ̀ wa àti ìwà wa ń fi hàn pé ẹ̀mí mímọ́ ló ń darí wa, a sì ní àwọn ànímọ́ tó para pọ̀ jẹ́ èso ti ẹ̀mí. (2 Kọ́r. 13:5a; Gál. 5:25) Tá a bá rí i pé a nílò àwọn kan lára àwọn ànímọ́ tó para pọ̀ jẹ́ èso ti ẹ̀mí, a lè túbọ̀ sapá láti jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa darí wa ká bàa lè ní irú àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀. Bá a ṣe lè ṣe èyí ni pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan ànímọ́ tó jẹ́ apá kan èso ti ẹ̀mí nípa lílo Bíbélì àtàwọn ìwé wa tó jíròrò wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, a ó lè fòye mọ bó ṣe yẹ ká máa fi àwọn ànímọ́ tó para pọ̀ jẹ́ èso ti ẹ̀mí ṣèwà hù lójoojúmọ́, ká sì wá sapá láti túbọ̀ ní irú ànímọ́ bẹ́ẹ̀. * Bá a ti ń kíyè sí àbájáde ọ̀nà tí ẹ̀mí Ọlọ́run gbà ń darí wa àti àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni, ìdí tó fi gbọ́dọ̀ máa darí wa á wá ṣe kedere sí wa.
Ṣé Ò Ń Jẹ́ Kí Ẹ̀mí Ọlọ́run Máa Darí Rẹ?
18. Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ fún wa nípa bó ṣe yẹ ká jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí wa?
18 Bíbélì sọ fún wa pé nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó rí bí ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe lágbára tó nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Ó gbà kó máa darí òun, bó bá sì sún un láti ṣe ohun kan, ó máa ń gbà pẹ̀lú rẹ̀ á sì ṣe ohun náà. (Máàkù 1:12, 13; Lúùkù 4:14) Ṣé ìwọ náà máa ń jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run darí rẹ?
19. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe kí ẹ̀mí mímọ́ lè máa darí wa?
19 Ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run ṣì ń darí èrò àti ọkàn àwọn tó bá fẹ́ kó máa sún àwọn ṣiṣẹ́ kó sì máa darí àwọn. Báwo lo ṣe lè jẹ́ kó máa ṣiṣẹ́ lára rẹ kó lè máa darí rẹ síbi tó yẹ? Máa gbàdúrà déédéé sí Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ kó sì ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa gba ibi tó bá darí rẹ sí. (Ka Éfésù 3:14-16.) Máa ṣe ohun tó o gbàdúrà lé lórí nípa ṣíṣàwárí àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì, tí í ṣe Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ mí sí. (2 Tím. 3:16, 17) Ṣègbọràn sí ìtọ́ni ọlọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì, sì máa tara ṣàṣà láti gba ibi tí ẹ̀mí mímọ́ bá darí rẹ sí. Fi hàn pé o ní ìgbàgbọ́ pé Jèhófà lágbára láti darí rẹ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ nínú ayé búburú yìí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Wo ibi tá a ti jíròrò ọ̀kọ̀ọ̀kan ànímọ́ tó jẹ́ apá kan èso ti ẹ̀mí lábẹ́ kókó ọ̀rọ̀ náà, “Fruitage of God’s Spirit,” [Èso Ẹ̀mí Ọlọ́run] àti ibi tá a tò wọ́n sí tẹ̀ léra lábẹ́ àkòrí náà, “List by Aspect,” nínú àwọn ìwé atọ́ka tá à ń pè ní Watch Tower Publications Index.
Ṣó O Lóye Àwọn Kókó Pàtàkì Tá A Jíròrò?
• Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe lè máa darí ìgbésí ayé wa?
• Kí ni ìdí mẹ́rin tó fi yẹ ká fẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí wa?
• Ká bàa lè jàǹfààní kíkún nínú bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe ń darí wa, kí ló yẹ ká ṣe?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ẹ̀mí Ọlọ́run ló máa ń darí Jésù láti ṣe àwọn nǹkan
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ẹ̀mí Ọlọ́run ń darí èrò àti ọkàn àwọn èèyàn kó bàa lè sún wọn ṣiṣẹ́ kó sì tọ́ wọn sọ́nà