Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Má Ṣe Jẹ́ Kí Àìlera Ba Ayọ̀ Rẹ Jẹ́

Má Ṣe Jẹ́ Kí Àìlera Ba Ayọ̀ Rẹ Jẹ́

Má Ṣe Jẹ́ Kí Àìlera Ba Ayọ̀ Rẹ Jẹ́

FOJÚ inú wò ó pé bó o ṣe jí láàárọ̀ ló ti wù ẹ́ pé kí ilẹ̀ ọjọ́ yẹn ti ṣú. Èyí lè jẹ́ torí pé o tún ní láti fara da ìrora àti ìdààmú ọkàn tó ń bá ẹ fínra. Ó tiẹ̀ lè máa ṣe ẹ́ bíi ti Jóòbù tó sọ pé: “Ó sàn kí n kú dípò gbogbo ìyà tó ń jẹ mí yìí.” (Jóòbù 7:15, The New English Bible) Kí la lè ṣe bí ìṣòro náà bá ń bá a nìṣó àní fún ọ̀pọ̀ ọdún?

Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Mefibóṣẹ́tì, ọmọ Jónátánì tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Dáfídì Ọba nìyẹn. Nígbà tí Mefibóṣẹ́tì ṣì jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún, ó “ṣubú, ó sì yarọ.” (2 Sám. 4:4) Nígbà tí wọ́n purọ́ mọ́ ọn pé ó dìtẹ̀ mọ́ ọba tí èyí sì mú kó pàdánù àwọn nǹkan ìní rẹ̀, ìdààmú ọkàn tó bá a ti ní láti fi kún ìrora tó ń ní torí pé ó yarọ. Síbẹ̀, ó ń bá a nìṣó láti jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà ní ti pé ó fara da àìlera, ìbanilórúkọjẹ́ àti ìjákulẹ̀, kò sì jẹ́ kí ìyẹn ba ayọ̀ òun jẹ́.—2 Sám. 9:6-10; 16:1-4; 19:24-30.

Àpẹẹrẹ mìíràn ni ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Nígbà kan ó sọ̀rọ̀ nípa “ẹ̀gún kan” tó wà nínú “ẹran ara” rẹ̀, tó ní láti fara dà. (2 Kọ́r. 12:7) Ẹ̀gún tó ń sọ náà lè jẹ́ àìlera ọlọ́jọ́ pípẹ́, tàbí kó jẹ́ àwọn tí kò gbà pé òótọ́ ni Pọ́ọ̀lù jẹ́ àpọ́sítélì. Èyí ó wù kó jẹ́, ìṣòro náà kò lọ bọ̀rọ̀, ó sì ní láti fara da ìrora tàbí ìdààmú ọkàn tí ìṣòro náà ń mú wá.—2 Kọ́r. 12:9, 10.

Àìsàn líle koko tó ń tánni lókun tàbí ìdààmú ọkàn ń bá àwọn kan lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run fínra lónìí. Nígbà tí Magdalena wà lọ́mọ ọdún méjìdínlógún [18] àyẹ̀wò ìṣègùn fi hàn pé ó ní àìsàn kan tó máa ń jẹ́ kí àwọn agbóguntàrùn inú ara máa gbógun ti àwọn ẹ̀yà míì nínú ara. Magdalena sọ pé: “Ìdààmú bá mi. Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ìṣòro mi bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i, oúnjẹ ò dà dáadáa nínú mi mọ́, egbò ẹnu mú mi, gògóńgò sì bẹ̀rẹ̀ sí í dùn mí.” Ní ti Izabela, àìsàn tó ń bá a fínra kò fi bẹ́ẹ̀ hàn sóde. Ó ṣàlàyé pé: “Látìgbà kékeré ni mo ti ní ìsoríkọ́. Ó máa ń jẹ́ kí ẹ̀rù bà mí, mi kì í lè mí dáadáa, inú sì máa ń bù mí so. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń rẹ̀ mí tẹnutẹnu.”

Mọ Ibi Tí Agbára Rẹ Mọ

Àìsàn àti àìlera lè mú kí ayé tojú sú ẹ. Bí ọ̀rọ̀ bá ti rí bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o fara balẹ̀ gbé ọ̀rọ̀ ara rẹ yẹ̀ wò. Ó lè má rọrùn fún ẹ láti gbà pé ó níbi tí agbára rẹ́ mọ. Magdalena sọ pé: “Àìsàn mi ń burú sí i. Lọ́pọ̀ ìgbà ó máa ń rẹ̀ mí gan-an débi pé mi ò ní lè dìde lórí bẹ́ẹ̀dì. Torí pé mi ò lè sọ ọwọ́ tí àìsàn mí tún máa gbé, èyí mú kó ṣòro fún mi gan-an láti wéwèé ohun tí mo bá fẹ́ ṣe ṣáájú. Ohun tó máa ń ká mi lára jù lọ ni pé mi ò lè ṣe tó bí mo ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.”

Zbigniew ṣàlàyé pé: “Bí ọdún ti ń gorí ọdún, àìsàn tó máa ń mú oríkèé ara wú tán mi lókun, ó sì ń ba oríkèé-ríkèé ara mi jẹ́. Nígbà míì, tí oríkèé ara mi bá wú gan-an, mi ò ní lè ṣe iṣẹ́ tí ò tó nǹkan pàápàá. Ìyẹn máa ń jẹ́ kí gbogbo nǹkan tojú sú mi.”

Ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn, àyẹ̀wò ìṣègùn fi hàn pé Barbara ní káńsà inú ọpọlọ. Ó sọ pé: “Ara mi ṣàdédé yí pa dà. Mi ò lókun nínú mọ́. Orí máa ń fọ́ mi lemọ́lemọ́, mi kì í sì í lè pọkàn pọ̀. Ní báyìí tí mo ti rí i pé ó níbi tí agbára mi mọ, mo ní láti tún ọ̀rọ̀ ara mi gbé yẹ̀ wò.”

Gbogbo àwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn lókè yìí ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà. Ṣíṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ ni wọ́n kà sí pàtàkì jù lọ. Wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run pátápátá, ó sì ń tì wọ́n lẹ́yìn.—Òwe 3:5, 6.

Báwo Ni Jèhófà Ṣe Ń Pèsè Ìrànlọ́wọ́?

Bí ohunkóhun bá ń pọ́n wa lójú, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má lọ máa rò pé ìṣòro tó dé bá wa fi hàn pé inú Ọlọ́run kò dùn sí wa. (Ìdárò 3:33) Ronú nípa ohun tí Jóòbù fojú winá rẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó jẹ́ “aláìlẹ́bi àti adúróṣánṣán.” (Jóòbù 1:8) Ọlọ́run kì í fi ohun tó jẹ́ ibi dán ẹnikẹ́ni wò. (Ják. 1:13) Gbogbo àìlera, tó fi mọ́ àwọn àìsàn tó le koko àti ìdààmú ọkàn jẹ́ ohun ìbànújẹ́ tá a jogún látọ̀dọ̀ àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà.—Róòmù 5:12.

Àmọ́, Jèhófà àti Jésù kò ní fi àwọn olódodo sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́. (Sm. 34:15) Láwọn ìgbà tí ìgbésí ayé bá nira fun wa gan-an la túbọ̀ máa ń mọyì rẹ̀ pé Ọlọ́run jẹ́ ‘ibi ìsádi wa àti ibi odi agbára wa.’ (Sm. 91:2) Torí náà, kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ tí a kò fi ní pàdánù ayọ̀ wa tá a bá ń fojú winá àwọn ìṣòro tí kò rọrùn láti mú kúrò?

Àdúrà: Bíi ti àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ìgbà àtijọ́, ìwọ náà lè ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Baba wa ọ̀run nínú àdúrà. (Sm. 55:22) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o lè ní “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.” Àlàáfíà ọkàn yẹn ‘yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ àti agbára èrò orí rẹ.’ (Fílí. 4:6, 7) Báwo ni Magdalena ṣe ń fara da àìsàn rẹ̀ tó ń burú sí i? Ó fi hàn pé òun gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run nípa gbígbàdúrà sí i. Ó sọ pé: “Bí mo ṣe ń sọ ohun tó wà lọ́kàn mi fún Jèhófà máa ń mú kí ara tù mí, ó sì máa ń jẹ́ kí n láyọ̀. Ní báyìí, mo ti wá mọ ohun tó túmọ̀ sí láti máa gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run lójoojúmọ́.”—2 Kọ́r. 1:3, 4.

Ní ìdáhùn sí àdúrà rẹ, Jèhófà lè fún ẹ́ lágbára nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ẹgbẹ́ ará tá a jọ jẹ́ Kristẹni. O kò ní retí pé kí Ọlọ́run mú àìsàn tó ń ṣe ẹ́ kúrò lọ́nà ìyanu. Síbẹ̀, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run lè fún ẹ ní ọgbọ́n àti okun tó o nílò kó o bàa lè fara da ìpọ́njú kọ̀ọ̀kan tó bá dé bá ẹ. (Òwe 2:7) Ó lè fún ẹ lókun, kó sì fún ẹ ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.”—2 Kọ́r. 4:7.

Ìdílé: Bí àwọn tẹ́ ẹ jọ ń gbélé bá ń fi ìfẹ́ àti àánú hàn sí ẹ, èyí lè mú kó rọrùn fún ẹ láti fara da àìlera rẹ. Ṣùgbọ́n, fi sọ́kàn pé àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ náà ní ìṣòro tó ń bá wọn fínra. Ó lè jẹ́ pé bíi tìẹ, wọn kò mọ ohun tí wọ́n lè ṣe sí ọ̀ràn náà. Síbẹ̀, wọn ò jẹ́ fi ẹ́ sílẹ̀, kódà nígbà ìṣòro. Bí ẹ bá ń gbàdúrà pa pọ̀ wàá lè ní ọkàn-àyà píparọ́rọ́.—Òwe 14:30.

Barbara sọ nípa ọmọbìnrin rẹ̀ àtàwọn ọ̀dọ́bìnrin míì nínú ìjọ pé: “Bí wọ́n ṣe ń ràn mí lọ́wọ́ máa ń mú kó ṣeé ṣe fún mi láti jáde òde ẹ̀rí. Ìtara wọn máa ń fún mi níṣìírí ó sì ń fún mi láyọ̀.” Zbigniew mọyì bí ìyàwó rẹ̀ ṣe ń ràn án lọ́wọ́ gan-an ni. Ó sọ pé: “Òun ló máa ń ṣe èyí tó pọ̀ jù lọ lára iṣẹ́ ilé. Òun ló máa ń wọṣọ fún mi, òun ló sì sábà máa ń bá mi gbé báàgì mi bí mo bá ń lọ sípàdé àti bí mo bá wà lóde ẹ̀rí.”

Àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni: Tá a bá wà pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni, wọ́n máa ń fún wa níṣìírí wọ́n sì máa ń tù wá nínú. Bó bá ṣẹlẹ̀ pé àìsàn tó ń ṣe ẹ́ ò jẹ́ kó o lè lọ sí ìpàdé ńkọ́? Magdalena sọ pé: “Ìjọ máa ń rí sí i pé a gba ohùn ìpàdé sórí kásẹ́ẹ̀tì kí n lè tẹ́tí sí i, mo sì máa ń jàǹfààní nínú ẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tá a jọ jẹ́ ará máa ń pè mí láti béèrè ohun táwọn tún lè ṣe láti ràn mí lọ́wọ́. Wọ́n máa ń kọ lẹ́tà sí mi láti fún mi níṣìírí. Ti pé wọn ò gbàgbé mi, tí ọ̀rọ̀ ìlera mi sì jẹ wọ́n lógún máa ń jẹ́ kí n lè fara dà á.”

Izabela, tó níṣòro ìdààmú ọkàn sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn tó dà bíi bàbá àti ìyá fún mi ló wà nínú ìjọ, wọ́n máa ń tẹ́tí sí mi wọ́n sì máa ń gbìyànjú láti lóye ohun tó ń ṣe mí. Bí ìdílé ni àwọn ará nínú ìjọ ṣe rí sí mi, ibẹ̀ ni mo ti máa ń rí àlàáfíà àti ayọ̀.”

Ó dáa kí àwọn tí onírúurú àdánwò dé bá ṣọ́ra kí wọ́n má bàa ‘ya ara wọn sọ́tọ̀.’ Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí wọ́n mọyì ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tí wọ́n ní pẹ̀lú àwọn ará nínú ìjọ. (Òwe 18:1) Èyí á fún àwọn míì tó ń rí wọn ní ìṣírí lọ́pọ̀lọpọ̀. Ó lè kọ́kọ́ ṣòro fún ẹ láti sọ ohun tó o nílò fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ. Síbẹ̀ àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ Kristẹni máa mọyì rẹ̀ bó o bá sọ ohun tó ń ṣe ẹ́ gan-an. Ó máa jẹ́ kí wọ́n lè fi “ìfẹ́ni ará tí kò ní àgàbàgebè” hàn sí ẹ. (1 Pét. 1:22) O ò ṣe jẹ́ kí àwọn ará mọ̀ bó o bá nílò ẹni táá máa fi ọkọ̀ gbé ẹ lọ sípàdé, ẹni tí wàá máa bá ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, tàbí ẹni tẹ́ ẹ ó jọ máa fọ̀rọ̀ gbé ara yín ró? Síbẹ̀ ó ṣe pàtàkì pé ká má máa béèrè ju ohun tí agbára wọn gbé àmọ́ ká mọrírì ohun tí wọ́n ń ṣe láti ràn wá lọ́wọ́.

Má sọ̀rètí nù: Lọ́pọ̀ ìgbà ọwọ́ rẹ ló kù sí láti fara da àìsàn líle koko láì jẹ́ kó ba ayọ̀ rẹ jẹ́. Bó bá jẹ́ pé ìgbà gbogbo lojú rẹ ń kọ́rẹ́ lọ́wọ́, tó o sì ń ro àròkàn, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í ro èrò tí kò tọ́. Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀mí ènìyàn lè fara da àrùn rẹ̀; ṣùgbọ́n ní ti ẹ̀mí tí ìdààmú bá, ta ní lè mú un mọ́ra?”—Òwe 18:14.

Magdalena sọ pé: “Mo sapá gidigidi láti má máa gbé ìṣòro mi sọ́kàn. Mo máa ń gbádùn ara mi lọ́jọ́ tí ara mi bá le. Ó máa ń jẹ́ ìṣírí fún mi láti ka ìtàn ìgbésí ayé àwọn tó di ìṣòtítọ́ wọn mú láìka àìsàn líle koko tí wọ́n ní sí.” Ohun tó ń fún Izabela lókun ni pé ó mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun ó sì mọyì òun. Ó sọ pé: “Mo mọ̀ pé mo wúlò, mi ò sì wà láàyè lásán. Mo sì ní ìrètí àgbàyanu ní ọjọ́ ọ̀la.”

Zbigniew sọ pé: “Àìlera mi kọ́ mi béèyàn ṣe ń jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti onígbọràn. Ó jẹ́ kí n máa fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà, kí n máa fi ojú tó tọ́ wo nǹkan, kí n sì máa dárí jini látọkàn wá. Mo ti kọ́ láti máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, mi kì í sì í jẹ́ kí ohunkóhun bà mí nínú jẹ́. Kódà, èyí ti mú kí n máa tẹ̀ síwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run.”

Má ṣe gbàgbé pé Jèhófà ń kíyè sí ìfaradà rẹ. Ó ń dùn ún pé ò ń jìyà, ó sì ń bójú tó ẹ. Kì yóò ‘gbàgbé iṣẹ́ rẹ àti ìfẹ́ tí o fi hàn fún orúkọ rẹ̀.’ (Héb. 6:10) Fi ìlérí tó ṣe fún gbogbo àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀ sọ́kàn, ó ní: “Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.”—Héb. 13:5.

Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan bó bá ṣẹlẹ̀ pé àárẹ̀ mú ẹ, pọkàn pọ̀ sórí ìrètí àgbàyanu ti gbígbé nínú ayé tuntun. Àkókò náà ń yára sún mọ́lé nígbà tí ìwọ yóò fi ojú ara rẹ rí àwọn ìbùkún tí Ìjọba Ọlọ́run yóò mú wá sórí ilẹ̀ ayé!

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Bí Wọ́n Tilẹ̀ Ń Ṣàìsàn Líle Koko Wọn Kò Dẹ́kun Láti Máa Wàásù

“Mi ò lè dá rìn mọ́, torí náà, ìyàwó mi tàbí àwọn ará míì lọ́kùnrin àti lóbìnrin máa ń bá mi lọ sóde ẹ̀rí. Mo máa ń há ọ̀rọ̀ tí màá sọ àti ẹsẹ Bíbélì tí màá lò sórí.”—Jerzy, tí kò ríran dáadáa mọ́.

“Yàtọ̀ sí lílo fóònù láti wàásù, mo tún máa ń kọ lẹ́tà, mo sì máa ń kọ̀wé déédéé sáwọn mélòó kan tó bá fìfẹ́ hàn. Nígbà tí mo wà nílé ìwòsàn, mo sábà máa ń fi Bíbélì àti ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí ẹ̀gbẹ́ bẹ́ẹ̀dì mi. Ìyẹn ti mú kí n bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò tó lárinrin pẹ̀lú ọ̀pọ̀ èèyàn.”—Magdalena, tó ní àìsàn tó ń jẹ́ kí àwọn agbóguntàrùn inú ara máa gbógun ti àwọn ẹ̀yà míì nínú ara.

“Mo fẹ́ràn láti máa wàásù láti ilé dé ilé, àmọ́ nígbà tí ara mi kò bá gbé e, mo máa ń fi fóònù wàásù.”—Izabela, tó ní ìsoríkọ́ tó lé kenkà.

“Mo fẹ́ràn kí n máa lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò kí n sì tún máa bá àwọn míì lọ síbi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní ọjọ́ tí ara mi bá le, mo máa ń fẹ́ láti wàásù láti ilé dé ilé.”—Barbara, tó ní káńsà inú ọpọlọ.

“Àpò kékeré tí mo máa ń kó ìwé ìròyìn sí ni mo máa ń gbé dání. Mo sì máa ń wà lóde ẹ̀rí títí dìgbà tí oríkèé tó ń ro mí bá tún bẹ̀rẹ̀.”—Zbigniew, tó ní àìsàn tó máa ń mú oríkèé ara wú.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Tọmọdé tàgbà ló lè fúnni ní ìṣírí