Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mo Ti Jàǹfààní Látinú Àwọn Ìyípadà Tí Mo Ṣe

Mo Ti Jàǹfààní Látinú Àwọn Ìyípadà Tí Mo Ṣe

Mo Ti Jàǹfààní Látinú Àwọn Ìyípadà Tí Mo Ṣe

Gẹ́gẹ́ bí James A. Thompson ṣe sọ

Gúúsù orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n bí mi sí ní ọdún 1928. Nígbà yẹn àwọn aláwọ̀ funfun àtàwọn aláwọ̀ dúdú kì í bá ara wọn da nǹkan pọ̀. Bí ẹnikẹ́ni bá sì fẹ́ ṣe ohun tó yàtọ̀ sí èyí, wọ́n lè jù ú sẹ́wọ̀n tàbí kí wọ́n ṣe ohun tó burú jù bẹ́ẹ̀ lọ sí i.

NÍ ÀKÓKÒ yẹn, láwọn ibì kan ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó jẹ́ aláwọ̀ funfun àti àwọn aláwọ̀ dúdú ní láti wà nínú ìjọ, àyíká àti àgbègbè tó yàtọ̀ síra. Ní ọdún 1937 bàbá mi di ìránṣẹ́ ẹgbẹ́ (tá à ń pè ní olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà báyìí) ní ìjọ táwọn aláwọ̀ dúdú wà nílùú Chattanooga, tó wà ní ìpínlẹ̀ Tennessee. Henry Nichols ni ìránṣẹ́ ẹgbẹ́ ní ìjọ táwọn aláwọ̀ funfun wà.

Inú mi máa ń dùn bí mo bá rántí ohun tí mo máa ń ṣe nígbà tí mo wà ní ọ̀dọ́. Ní alẹ́, mo máa ń jókòó sí ẹ̀yìnkùlé mo sì máa ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ tí bàbá mi àti Arákùnrin Nichols bá ń sọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ ló yé mi, mo fẹ́ láti máa wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ bàbá mi bí àwọn méjèèjì ṣe ń jíròrò ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà máa wàásù nítorí bí ipò nǹkan ṣe rí nígbà yẹn.

Ṣáájú àkókò yẹn, lọ́dún 1930, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó ba ìdílé wa nínú jẹ́ gan-an. Màmá mi kú, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò ju ọmọ ogún [20] ọdún lọ. Bó ṣe di pé Bàbá mi ló tọ́jú ẹ̀gbọ́n mi obìnrin, Doris àti èmi nìyẹn. Ọmọ ọdún mẹ́rin ni Doris, èmi sì jẹ́ ọmọ ọdún méjì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tíì pẹ́ tí bàbá mi ṣèrìbọmi, wọ́n ń ṣe dáadáa nínú ètò Ọlọ́run.

Àwọn Àpẹẹrẹ Rere Tí Mo Tẹ̀ Lé

Ní ọdún 1933, bàbá mi pàdé arábìnrin kan tó níwà rere. Lillie Mae Gwendolyn Thomas ni orúkọ rẹ̀, kò sì pẹ́ tí wọ́n fi ṣègbéyàwó. Bàbá mi àti ìyàwó wọn fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún èmi àti Doris nípa bó ṣe yẹ ká máa sin Jèhófà láìyẹsẹ̀.

Nígbà tó di ọdún 1938, wọ́n ní kí ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́wọ́ ti ìpinnu kan tí ètò Ọlọ́run ṣe pé orílé-iṣẹ́ wa ní Brooklyn, ní ìpínlẹ̀ New York, ni kó máa yan àwọn alàgbà sípò nínú ìjọ, dípò kí ìjọ máa dìbò yàn wọ́n. Nígbà tí àwọn kan nínú ìjọ Chattanooga kò fẹ́ láti fara mọ́ ìyípadà yẹn, bàbá mi jẹ́ kó ṣe kedere pé tọkàntọkàn làwọn fi fara mọ́ ìyípadà tó wáyé náà. Bí bàbá mi ṣe jẹ́ adúróṣinṣin àti bí ìyàwó wọn ṣe kọ́wọ́ tì wọ́n látọkàn wá ti ràn mí lọ́wọ́ títí dòní yìí.

Mo Ṣèrìbọmi Mo sì Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Alákòókò Kíkún

Ní ọdún 1940, àwọn ará mélòó kan nínú ìjọ wa háyà bọ́ọ̀sì kan kí wọ́n lè wọ̀ ọ́ lọ sí àpéjọ àgbègbè tó wáyé ní ìlú Detroit, ní ìpínlẹ̀ Michigan. Àwọn mélòó kan lára àwọn tá a jọ wọ bọ́ọ̀sì náà ṣe ìrìbọmi ní àpéjọ yẹn. Àwọn kan rò pé ó yẹ kí èmi náà ṣèrìbọmi torí pé àtìgbà tí mo ti wà lọ́mọ ọdún márùn-ún ni mo ti ń wàásù, mo sì máa ń lọ sóde ẹ̀rí déédéé.

Nígbà tí wọ́n béèrè ohun tó fà á tí mi ò fi ṣèrìbọmi, mo sọ fún wọn pé, “Ọ̀rọ̀ nípa ìrìbọmi ò tíì yé mi dáadáa.” Bàbá mi gbọ́ ohun tí mo sọ ó sì yà wọ́n lẹ́nu. Látìgbà yẹn, wọ́n fi kún ìsapá wọn láti jẹ́ kí n lóye ohun tó túmọ̀ sí láti ṣèrìbọmi àti ìdí tó fi ṣe pàtàkì. Ní oṣù mẹ́rin lẹ́yìn náà, nígbà tí ojú ọjọ́ tutù nini, ìyẹn ní October 1, ọdún 1940 mo ṣèrìbọmi nínú adágún omi kan lẹ́yìn ìlú Chattanooga.

Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá [14], mo bẹ̀rẹ̀ sí í gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nígbà ẹ̀rùn tá a bá ti gba ìsinmi kúrò ní ilé ẹ̀kọ́. Mo wàásù ní àwọn abúlé kékeré tó wà ní ìpínlẹ̀ Tennessee àti ìpínlẹ̀ Georgia tó wà nítòsí rẹ̀. Mo máa ń tètè jí, màá gbé oúnjẹ mi dání, màá sì lọ wọ ọkọ̀ ojú irin tàbí bọ́ọ̀sì ní aago mẹ́fà láti lọ sí ìpínlẹ̀ ìwàásù mi. Nǹkan bí aago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́ ni mo máa n pa dà. Kó tó di ọ̀sán mo ti máa ń jẹ oúnjẹ tí mo gbé dání tán. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo lówó tí mo lè fi ra oúnjẹ míì, mi ò lè wọ ṣọ́ọ̀bù tó wà ládùúgbò láti ra oúnjẹ torí aláwọ̀ dúdú ni mí. Lọ́jọ́ kan mo wọ ṣọ́ọ̀bù kan láti ra ìpápánu àmọ́ wọ́n ní kí n jáde. Ọpẹ́lọpẹ́ obìnrin aláwọ̀ funfun kan ló mú ìpápánu náà wá bá mi níta.

Nígbà tí mo wọ ilé ẹ̀kọ́ girama, àwọn èèyàn tó ń gbé ní gúúsù orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí i pé kí àwọn èèyàn máa bára wọn lò lọ́gbọọgba ti bẹ̀rẹ̀ sí í kóra jọ láti fi ẹ̀hónú hàn. Àwọn àjọ tó ń jà fún ẹ̀tọ́ àwọn aláwọ̀ dúdú irú bí àjọ NAACP (National Association for the Advancement of Colored People) ní kí àwọn ọmọléèwé máa fi ẹ̀hónú hàn. Wọ́n rọ̀ wá pé ká di ọmọ ẹgbẹ́ àjọ náà. Díẹ̀ lára iléèwé tí àwọn aláwọ̀ dúdú ń lọ, tó fi mọ́ iléèwé wa, fẹ́ kó jẹ́ pé gbogbo wa pátá la máa dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ náà. Wọ́n fúngun mọ́ mi pé kí n “ti ẹ̀yà wa lẹ́yìn.” Àmọ́ mo kọ̀, mo sì ṣàlàyé fún wọn pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú kì í sì í gbé ẹ̀yà kan ga ju òmíràn lọ. Torí náà mo gbà pé Ọlọ́run ló máa yanjú ìṣòro kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà.—Jòh. 17:14; Ìṣe 10:34, 35.

Kété lẹ́yìn tí mo parí iléèwé girama, mo pinnu láti lọ sí ìlú New York City. Àmọ́ kí n tó débẹ̀, mo dúró ní ìlú Filadẹ́fíà, ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania láti kí àwọn ọ̀rẹ́ mi tá a jọ pàdé ní àpéjọ àgbègbè kan tá a ṣe kọjá. Ìjọ tó wà níbẹ̀ ni mo ti kọ́kọ́ rí i tí àwọn aláwọ̀ dúdú àtàwọn aláwọ̀ funfun ti jọ ń ṣèpàdé. Nígbà ìbẹ̀wò alábòójútó arìnrìn-àjò, ó pè mí sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan ó sì sọ fún mi pé wọ́n ti yan iṣẹ́ kan fún mi ní ìpàdé tá a máa ṣe lẹ́yìn náà. Ìyẹn ló mú kó rọrùn fún mi láti dúró síbẹ̀.

Ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ tí mo ní nílùú Filadẹ́fíà ni ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Geraldine White. Mo fẹ́ràn láti máa pè é ní Gerri. Ó mọ Bíbélì dáadáa, ó sì mọ béèyàn ṣe ń bá àwọn onílé sọ̀rọ̀ lóde ẹ̀rí. Ohun tó mú kí ọ̀rọ̀ àwa méjèèjì wọ̀ gan-an ni pé òun náà fẹ́ di aṣáájú-ọ̀nà bíi tèmi. A ṣègbéyàwó ní April 23, ọdún 1949.

Wọ́n Pè Wá sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì

Ó ti wù wá tẹ́lẹ̀ láti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ká lè lọ sìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì ní ilẹ̀ àjèjì. Inú wá dùn láti ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ ká bàa lè tóótun láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ náà. Ká tó láǹfààní láti lọ sí Gílíádì a láǹfààní láti lọ sí ibi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Wọ́n kọ́kọ́ ní ká lọ sí àdúgbò Lawnside, ní ìpínlẹ̀ New Jersey. Lẹ́yìn náà a lọ sí ìlú Chester, ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania, ká tó wá lọ sí ìlú Atlantic City, ní ìpínlẹ̀ New Jersey. Nígbà tá a wà ní ìlú Atlantic City, a tóótun láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì torí ó ti pé ọdún méjì tá a ti ṣègbéyàwó. Ṣùgbọ́n wọn kò pè wá sí Gílíádì lákòókò yẹn. Kí nìdí tí wọn kò fi pè wá?

Láàárín ọdún 1950 sí ọdún 1954, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́kùnrin ni wọ́n ń mú wọṣẹ́ ológun kí wọ́n lè kópa nínú ìjà tó ń lọ lọ́wọ́ ní orílẹ̀-èdè Kòríà. Ó jọ pé ẹgbẹ́ tó ń mú àwọn ọkùnrin wọṣẹ́ ológun ní ìlú Filadẹ́fíà kò nífẹ̀ẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí pé a kì í dá sí tọ̀tún tòsì nínú ọ̀ràn ìṣèlú. Nígbà tó ṣe, adájọ́ kan sọ fún mi pé lẹ́yìn tí àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ gbé ọ̀ràn mi yẹ̀ wò, wọ́n rí i pé òótọ́ ni mi ò dá sí tọ̀tún tòsì. Torí náà, ní January 11, ọdún 1952, àjọ ìjọba àpapọ̀ tó ń rí sí ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn (Presidential Appeal Board) gbà pé mi ò lè wọṣẹ́ ológun torí pé mo jẹ́ òjíṣẹ́ Ọlọ́run.

Ní oṣù August ọdún yẹn, wọ́n pe èmi àti Gerri sí kíláàsì ogún [20] ti ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì tó bẹ̀rẹ̀ ní oṣù September. Nígbà tí ilé ẹ̀kọ́ yẹn ń lọ lọ́wọ́, ó wù wá pé kí wọ́n rán wa láti lọ wàásù ní ilẹ̀ òkèèrè. Ẹ̀gbọ́n mi obìnrin, Doris ti kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì ìkẹtàlá [13] ti ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì, ó sì ń sìn ní orílẹ̀-èdè Brazil. Ó ya èmi àti Gerri lẹ́nu gan-an nígbà tí wọ́n yàn wá sẹ́nu iṣẹ́ àyíká, wọ́n ní ká máa bẹ ìjọ àwọn aláwọ̀ dúdú tó wà ní gúúsù ìpínlẹ̀ Alabama wò! Ìyẹn dùn wá díẹ̀ torí a ti ní in lọ́kàn pé ilẹ̀ àjèjì ni wọ́n máa rán wa lọ.

Ìjọ Huntsville la kọ́kọ́ lọ bẹ̀ wò. Nígbà tá a débẹ̀, a lọ sí ilé arábìnrin tí wọ́n ní ká dé sí. Bí a ṣe ń já àwọn ẹrù wa, a gbọ́ tó ń sọ lórí fóònù pé, “Àwọn ọmọdé náà ti débí o.” Ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún [24] péré ni wa, ṣùgbọ́n ó tiẹ̀ dà bíi pé a kò tó bẹ́ẹ̀. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé nígbà tá a wà ní àyíká náà, orúkọ ìnagijẹ tí wọ́n fi ń pè wá ni Àwọn Ọmọdé Náà.

Àwọn èèyàn sábà máa ń ka àwọn tó wà ní gúúsù orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sí àwọn tó fọwọ́ pàtàkì mú Bíbélì. Torí náà, lọ́pọ̀ ìgbà, kókó pàtàkì mẹ́ta ni ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ wa máa ń dá lé.

(1) A ó sọ̀rọ̀ ṣókí nípa bí ipò ayé ṣe rí.

(2) A ó ṣàlàyé ọ̀nà tí Bíbélì sọ pé Ọlọ́run máa gbà yanjú ìṣòro aráyé.

(3) A ó sọ ohun tí Bíbélì sọ pé a gbọ́dọ̀ ṣe.

Lẹ́yìn náà, a máa ń fún wọn ní ìtẹ̀jáde tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó bá ohun tá a bá wọn jíròrò mu. Torí bí ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ yìí ṣe gbéṣẹ́ tó, wọ́n yan apá kan fún mi ní àpéjọ ẹgbẹ́ ayé tuntun [New World Society Assembly] tá a ṣe ní ọdún 1953 ní ìpínlẹ̀ New York. Ní àpéjọ náà mo ṣe àṣefihàn àwọn kókó pàtàkì mẹ́ta tí ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ wa máa ń dá lé.

Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, ní ìgbà ẹ̀rùn ọdún 1953, wọ́n yàn mí láti máa sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àgbègbè ní gúúsù orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, mo sì ń ṣèbẹ̀wò sáwọn àyíká àwọn aláwọ̀ dúdú. Àwọn àyíká tá à ń bẹ̀ wò kárí gbogbo àgbègbè ìpínlẹ̀ Virginia lọ sí Florida títí dé Alabama àti Tennessee tó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè náà. Kò sí àní-àní pé ó yẹ káwọn alábòójútó arìnrìn-àjò lè mú ara wọn bá onírúurú ipò mu. Bí àpẹẹrẹ, wọn kì í sábà kọ́ ilé ìwẹ̀ sínú àwọn ilé tá a máa ń dé sí, ẹ̀yìn ilé ìdáná la ti máa ń wẹ̀. Àmọ́, inú wá dùn pé apá ibẹ̀ yẹn ló máa ń gbóná jù nínú ilé náà!

Ìṣòro Kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà

Nígbà tá à ń sìn ní gúúsù orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ó gba pé ká máa ronú jinlẹ̀ ká sì máa lo ìdánúṣe ká bàa lè ṣàṣeyọrí. Wọn kì í jẹ́ kí àwọn aláwọ̀ dúdú lo ẹ̀rọ ìfọṣọ téèyàn máa ń sọ owó sínú ẹ̀ kó tó lò ó. Torí náà tí Gerri bá ti débẹ̀ ó máa sọ fún wọn pé “Ìyáàfin Thompson” ló ni aṣọ náà. Ọ̀pọ̀ máa ń rò pé ọmọ ọ̀dọ̀ ni Gerri àti pé “Ìyáàfin Thompson” ni ọ̀gá rẹ̀. Nígbà táwọn alábòójútó àgbègbè ń fi fíìmù náà, The New World Society in Action, han àwọn ìjọ, mo máa ń fi fóònù pè wọ́n ní ṣọ́ọ̀bù tá a ti lè rí ohun tó dà bí aṣọ ńlá tí fíìmù náà máa hàn sí lára, màá sọ pé “Ọ̀gbẹ́ni Thompson” ní kí wọ́n tọ́jú ìkan sílẹ̀ de òun. Lẹ́yìn náà màá lọ síbẹ̀ láti lọ gbé e. A máa ń hùwà ọmọlúwàbí nígbà gbogbo, a sì sábà máa ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa láìsí ìṣòro.

Wọ́n tún máa ń ṣe ẹ̀tanú sí àwọn tó wá láti àríwá orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ìwé ìròyìn kan ládùúgbò náà sọ nígbà kan pé Ọ̀gbẹ́ni James A. Thompson Kékeré tó ń ṣojú fún Watchtower Bible and Tract Society ti ìpínlẹ̀ New York máa sọ àsọyé ní àpéjọ kan. Ohun táwọn kan lóye èyí sí ni pé mo wá láti ìpínlẹ̀ New York, èyí mú kí wọ́n wọ́gi lé àdéhùn tá a ti ṣe láti lo gbọ̀ngàn iléèwé kan. Torí náà mo lọ bá àjọ iléèwé náà mo sì ṣàlàyé fún wọn pé ìlú Chattanooga ni mo ti kàwé. Ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n tó yọ̀ǹda pé ká ṣe àpéjọ àyíká wa níbẹ̀.

Ìṣòro kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà túbọ̀ ń pọ̀ sí i láàárín ọdún 1954 sí ọdún 1956, ó sì máa ń dá ìjà sílẹ̀ nígbà míì. Ní ọdún 1954, inú àwọn ará wa kan kò dùn torí pé aláwọ̀ dúdú kankan kò sọ̀rọ̀ lórí pèpéle láwọn àpéjọ àgbègbè mélòó kan. A rọ àwọn arákùnrin wa tó jẹ́ aláwọ̀ dúdú pé kí wọ́n ṣe sùúrù. Nígbà ẹ̀rùn tó tẹ̀ lé e, wọ́n yàn mí gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn olùbánisọ̀rọ̀. Lẹ́yìn náà, àwọn arákùnrin púpọ̀ sí i tí wọ́n jẹ́ aláwọ̀ dúdú ní apá gúúsù orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà bẹ̀rẹ̀ sí í níṣẹ́ ní àwọn àpéjọ.

Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà kò dá ìwà ipá sílẹ̀ mọ́ ní gúúsù orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àwọn aláwọ̀ dúdú àti àwọn aláwọ̀ funfun sì bẹ̀rẹ̀ sí í wà nínú ìjọ kan náà. Èyí gba pé ká bẹ̀rẹ̀ sí í tún àwọn akéde yàn sí àwọn ìjọ míì ká sì ṣàtúntò ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ àti ojúṣe àwọn tó ń mú ipò iwájú nínú ìjọ. Àwọn kan lára àwọn aláwọ̀ dúdú àti aláwọ̀ funfun kò fara mọ́ ìṣètò tuntun yìí. Àmọ́, ọ̀pọ̀ jù lọ ló fìwà jọ Baba wa ọ̀run tí kì í ṣojúsàájú. Kódà, ọ̀pọ̀ jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ láìka àwọ̀ wọn sí. Bí nǹkan ṣe rí nínú ìdílé wa nìyẹn nígbà tí mò ń dàgbà, ìyẹn láàárín ọdún 1930 sí ọdún 1949.

Iṣẹ́ Àyànfúnni Míì

Ní oṣù January ọdún 1969, wọ́n ní kí èmi àti Gerri lọ sìn ní orílẹ̀-èdè Guyana ní gúúsù ilẹ̀ Amẹ́ríkà, inú wa sì dùn láti lọ. A kọ́kọ́ lọ sí Brooklyn, ní ìpínlẹ̀ New York, níbi tí mo ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nípa bí mo ṣe lè ṣe àbójútó iṣẹ́ ìwàásù ní orílẹ̀-èdè Guyana. Oṣù July ọdún 1969 la débẹ̀. Lẹ́yìn tá a ti lo ọdún mẹ́rìndínlógún [16] lẹ́nu iṣẹ́ arìnrìn-àjò, kò rọrùn rárá láti máa gbé lójú kan. Òde ẹ̀rí ni Gerri ti sábà máa ń ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì tirẹ̀, èmi sì ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì.

Lára àwọn iṣẹ́ tí mo máa ń ṣe ni kí n ṣán oko, kí n fi ìwé ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ méjìdínlọ́gbọ̀n [28] tó wà lórílẹ̀-èdè náà, kí n sì máa jábọ̀ fún oríléeṣẹ́ ní ìlú Brooklyn. Ó máa ń tó wákàtí mẹ́rìnlá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tí mo fi máa ń ṣiṣẹ́ lóòjọ́. Iṣẹ́ takuntakun làwa méjèèjì ń ṣe, àmọ́ a gbádùn iṣẹ́ àyànfúnni wa. Nígbà tá a dé orílẹ̀-èdè Guyana àwọn akéde ẹgbẹ̀rún dín àádọ́ta [950] ló wà níbẹ̀; lónìí wọ́n ti lé ní ẹgbẹ̀rún méjì àbọ̀ [2,500].

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé à ń gbádùn ojú ọjọ́ tó tura, àwọn èso aládùn àti ewébẹ̀, ohun tó ń fún wa láyọ̀ jù lọ ni pé àwọn èèyàn onírẹ̀lẹ̀ tí wọ́n fẹ́ mọ ohun tó wà nínú Bíbélì ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Lọ́pọ̀ ìgbà Gerri máa ń kọ́ àwọn èèyàn tí iye wọ́n tó ogún lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ọ̀pọ̀ lára àwọn tá a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ló sì tẹ̀ síwájú nínú òtítọ́ débi tí wọ́n fi ṣèrìbọmi. Nígbà tó yá àwọn kan di aṣáájú-ọ̀nà, alàgbà ìjọ, kódà àwọn kan lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì kí àwọn náà lè di míṣọ́nnárì.

A Dojú Kọ Ìpèníjà àti Ìṣòro Ìlera

Ní ọdún 1983 àwọn òbí mi tí wọ́n wà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nílò ìrànlọ́wọ́. Èmi, Doris àti Gerri sì ṣe ìpàdé mọ̀lẹ́bí. Doris tó ti siṣẹ́ míṣọ́nnárì fún ọdún márùndínlógójì [35] ní orílẹ̀-èdè Brazil, gbà láti pa dà sílé láti lọ tọ́jú wọn. Doris sọ pé: “Kí nìdí tá a fi máa ní kí míṣọ́nnárì méjì fi iṣẹ́ sílẹ̀ nígbà tí iṣẹ́ náà kò ju ohun tí míṣọ́nnárì kan lè ṣe lọ?” Látìgbà táwọn òbí wa ti kú ni Doris ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní ìlú Chattanooga.

Ní ọdún 1995 àyẹ̀wò ìṣègùn fi hàn pé mo ní àrùn jẹjẹrẹ tó máa ń mú ẹ̀yà ara tó wà lábẹ́ àpò ìtọ̀ ọkùnrin, torí náà a ní láti pa dà sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. A fìdí kalẹ̀ sí ìlú Goldsboro ní ìpínlẹ̀ North Carolina, torí pé àárín méjì ibi tí ìdílé mi ń gbé ní ìpínlẹ̀ Tennessee àti ibi tí ìdílé Gerri ń gbé ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania ló wà. Ní báyìí, àrùn jẹjẹrẹ tó ń ṣe mí kò fi bẹ́ẹ̀ yọ mí lẹ́nu mọ́, a sì ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe tí kò lera ní ìjọ kan ní ìlú Goldsboro.

Bí mo bá rántí ohun tó lé ní ọdún márùnlélọ́gọ́ta [65] tá a ti lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, mo máa ń dúpẹ́ látọkànwá pé Jèhófà ti bù kún èmi àti Gerri torí àwọn ìyípadà tá a ṣe ká bàa lè sìn ín. Òótọ́ mà lọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ o, ó ní: “[Jèhófà] yóò hùwà lọ́nà ìdúróṣinṣin sí ẹni ìdúróṣinṣin”!—2 Sám. 22:26.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Bàbá mi àti Arákùnrin Nichols fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ fún mi

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Èmi àti Gerri rèé lọ́dún 1952, a ti gbára dì láti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Lẹ́yìn tá a jáde nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì, wọ́n rán wa láti lọ ṣiṣẹ́ arìnrìn-àjò ní gúúsù orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Lọ́dún 1966, àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àtàwọn ìyàwó wọn ń múra sílẹ̀ láti lọ sí àpéjọ àgbègbè tó wà fún àwọn aláwọ̀ dúdú àti aláwọ̀ funfun

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

A gbádùn iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní orílẹ̀-èdè Guyana