Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ṣó o ti fara balẹ̀ ka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí:

• Ta ni Olivétan, kí sì nìdí tó fi yẹ ká fẹ́ mọ̀ nípa iṣẹ́ rẹ̀?

Ọmọ ilẹ̀ Faransé náà Pierre Robert ló ń jẹ́ Olivétan. Nígbà Àtúnṣe Ìsìn tó wáyé ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, ó túmọ̀ Bíbélì sí èdè Faransé. Ó lo “alábòójútó” dípò “bíṣọ́ọ̀bù,” àti “ìjọ” dípò “ṣọ́ọ̀ṣì.” Ní àwọn ibì kan, ó lo orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn “Jèhófà.”—9/1, ojú ìwé 18 sí 20.

• Kí nìdí tí Ọlọ́run fi sọ fún àwọn ọmọ Léfì pé: “Èmi ni ìpín rẹ”?

Àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì yòókù rí ilẹ̀ gbà gẹ́gẹ́ bí ogún, àmọ́ àwọn ọmọ Léfì ní Jèhófà gẹ́gẹ́ bí “ìpín” wọn. (Núm. 18:20) Wọn kò ní jogún ilẹ̀, àmọ́ Ọlọ́run fún wọn ní àkànṣe àǹfààní iṣẹ́ ìsìn. Síbẹ̀ Jèhófà pèsè àwọn ohun ìgbẹ́mìíró tí wọ́n nílò. Lónìí, àwọn tó láǹfààní láti máa mú kí àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run tẹ̀ síwájú ní ìdánilójú pé Ọlọ́run máa pèsè àwọn ohun ìgbẹ́mìíró tí wọ́n nílò fún wọn.—9/15, ojú ìwé 7 sí 8 àti 13.

• Báwo la ṣe mọ ìgbà tí àwọn ará Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù àtijọ́ run?

Àwọn òpìtàn ayé àtijọ́ fúnni ní ìsọfúnni tó yàtọ̀ síra, tó sì ta ko ara wọn nípa àwọn ọba tó ṣàkóso ilẹ̀ Bábílónì àti ìgbà tí wọ́n ṣàkóso. Síbẹ̀, àwọn ọ̀mọ̀wé fara mọ́ ọn pé ọdùn 539 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, tó jẹ́ ọdún pàtàkì nínú ìtàn, ni Kírúsì Kejì ṣẹ́gun Bábílónì. Ó dá àwọn Júù sílẹ̀ ní ìgbèkùn, wọ́n sì pa dà dé ìlú ìbílẹ̀ wọn ní ọdún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Bíbélì sọ pé àádọ́rin [70] ọdún ni àwọn Júù fi wà ní ìgbèkùn. Torí náà, ó ní láti jẹ́ pé ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni Jerúsálẹ́mù ṣubú. (2 Kíró. 36:21, 22; Jer. 29:10; Dán. 9:1, 2)—10/1, ojú ìwé 26 sí 31.

• Kí ló lè ran Kristẹni kan lọ́wọ́ láti pinnu bóyá eré ìtura kan ṣàǹfààní?

Kó o lè pinnu bóyá irú eré ìtura tó o fẹ́ràn ṣàǹfààní tó sì bójú mu lójú Ọlọ́run, ó dáa kó o bi ara rẹ pé: Kí ni eré náà ní nínú? Ìgbà wo ló yẹ kí n ṣe irú eré ìtura bẹ́ẹ̀? Àwọn wo la jọ máa ṣeré ìtura náà?—10/15, ojú ìwé 9 sí 12.

• Kí nìdí tí kò fi dáa láti ṣẹ́yún?

Ìwàláàyè jẹ́ ohun mímọ́ lójú Ọlọ́run, ẹ̀dá alààyè ni Ọlọ́run ka ọmọ tó wà nínú ìyá rẹ̀ sí. (Sm. 139:16) Ìpànìyàn ló jẹ́ téèyàn bá ṣẹ́yún, ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé lábẹ́ Òfin Mósè, èèyàn tó bá ṣe ọmọ tó wà nínú ikùn léṣe máa jíhìn. (Ẹ́kís. 21:22, 23)—11/1, ojú ìwé 6.

• Báwo ni ohun tó wà nínú Òwe 7:6-23 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún wíwo ohun tó lè mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe?

Àkọsílẹ̀ náà sọ̀rọ̀ nípa ọ̀dọ́kùnrin kan tó rìn gba ibì kan tó mọ̀ pé obìnrin aṣẹ́wó kan ń gbé. Obìnrin náà sún un dẹ́ṣẹ̀. Lónìí, àwa pẹ̀lú gbọ́dọ̀ sapá láti má ṣe lọ sórí àwọn ìkànnì Íńtánẹ́ẹ̀tì tá a ti lè rí àwọn àwòrán tí ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe, ó sì ṣe pàtàkì pé ká tó rí irú àwọn àwòrán bẹ́ẹ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ló yẹ ká ti gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ràn wá lọ́wọ́.—11/15, ojú ìwé 9 sí 10.

• Báwo la ṣe mọ̀ pé ayé kò ní pa run ní ọdún 2012?

Nítorí ọ̀nà tí àwọn Máyà gbà ń ka àkókò lórí kàlẹ́ńdà wọn àtijọ́, àwọn kan rò pé ọdún 2012 ni ayé máa pa run. Àmọ́, èyí kò lè rí bẹ́ẹ̀, torí pé Jèhófà dá ilẹ̀ ayé kí a lè máa gbé inú rẹ̀. Bíbélì sọ pé ilẹ̀ ayé máa wà títí láé. (Oníw. 1:4; Aísá. 45:18)—12/1, ojú ìwé 10.

• Àwọn wo lára àwọn tó kọ Bíbélì ló wà ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni?

Ó dà bíi pé mẹ́fà lára àwọn tó kọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì wà níbẹ̀. Àwọn àpọ́sítélì mẹ́ta wà níbẹ̀, ìyẹn Mátíù, Jòhánù àti Pétérù. Méjì lára àwọn ọmọ ìyá Jésù, Jákọ́bù àti Júúdà, pẹ̀lú wà níbẹ̀. Ó sì ṣeé ṣe kí ọ̀dọ́kùnrin náà Máàkù wà níbẹ̀ pẹ̀lú.—12/1, ojú ìwé 22.