Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bá A Ṣe Ń Tọ́jú Àwọn Ohun Tá A Ti Lò Látijọ́

Bá A Ṣe Ń Tọ́jú Àwọn Ohun Tá A Ti Lò Látijọ́

Látinú Àpamọ́ Wa

Bá A Ṣe Ń Tọ́jú Àwọn Ohun Tá A Ti Lò Látijọ́

ÀWA Èèyàn Jèhófà ní ọ̀pọ̀ nǹkan iyebíye tá a ti lò rí nínú ìjọsìn wa. Ogún tẹ̀mí làwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́. A lè rí àkọsílẹ̀ tó fani mọ́ra nípa wọn nínú àwọn ìwé, àwọn fọ́tò, àwọn lẹ́tà, ìtàn ìgbésí ayé àwọn ará àtàwọn nǹkan míì tó jẹ mọ́ ìjọsìn wa, iṣẹ́ ìwàásù wa àti ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́ kí nìdí tí a kò fi fẹ́ kí àwọn nǹkan wọ̀nyí pa run, tá a sì fẹ́ máa rántí àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá? Ńṣe ni ọ̀rọ̀ náà dà bíi ti àwọn olórí ìdílé ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, tí Jèhófà pàṣẹ fún pé kí wọ́n máa sọ àwọn òfin òun àtàwọn ohun àgbàyanu tí òun ti ṣe fún àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè “gbé ìgbọ́kànlé wọn ka Ọlọ́run tìkára rẹ̀.”—Sm. 78:1-7.

Ó ti pẹ́ tí àwọn ohun tó wà ní àpamọ́ yìí ti ń kó ipa ribiribi nínú bí ète Jèhófà ṣe ń ní ìmúṣẹ. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àwọn alátakò gbìyànjú láti dá iṣẹ́ àtúnkọ́ tẹ́ńpìlì dúró ní Jerúsálẹ́mù, ọba pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe àyẹ̀wò àwọn àkọsílẹ̀ tó wà níbi tí wọ́n ń tọ́jú àwọn ìṣúra sí ní Ekibátánà, tí í ṣe olú ìlú Mídíà. Ibẹ̀ ni wọ́n ti rí ìwé tí Kírúsì Ọba fi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láṣẹ pé kí wọ́n tún tẹ́ńpìlì kọ́. (Ẹ́sírà 6:1-4, 12) Nípa báyìí, ó ṣeé ṣe fún wọn láti tún tẹ́ńpìlì náà kọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run. Bákan náà, Lúùkù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere lo àwọn ìsọfúnni tó wà ní ìpamọ́, torí ó sọ pé òun “tọpasẹ̀ ohun gbogbo láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpéye.”—Lúùkù 1:1-4.

Ọwọ́ pàtàkì ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí fi mú ìtàn nípa ètò Ọlọ́run. Nígbà tí ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń ṣàlàyé bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa tọ́jú àwọn ohun iyebíye tó jẹ́ ogún tẹ̀mí wa, ká máa ṣe àkọsílẹ̀ wọn, ká sì jẹ́ káwọn tó ń bọ̀ lẹ́yìn mọ̀ nípa wọn, ó sọ pé, “Ká lè mọ ibi tí à ń lọ, ó yẹ ká mọ ibi tí a ti ń bọ̀.” Èyí ló fà á tó fi jẹ́ pé lẹ́nu àìpẹ́ yìí ètò Ọlọ́run dá Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Àpamọ́ sílẹ̀ ní oríléeṣẹ́ wa ní Brooklyn, New York lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Abẹ́ Ìgbìmọ̀ Ìkọ̀wé ni ẹ̀ka tuntun yìí wà.

“FỌ́TÒ ÌDÍLÉ” WA ÀTI “ÀWỌN OHUN ÀJOGÚNBÁ”

Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́ ni ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ń di ìtàn, ó sì máa ń ṣe ọ̀pọ̀ jù lọ lára wa bíi pé ká ní àkọsílẹ̀ tó túbọ̀ péye nípa ohun tó ti ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé wa. Torí náà, ní Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Àpamọ́, iṣẹ́ ribiribi ń lọ lọ́wọ́ láti rí sí i pé à ń tọ́jú àwọn ohun iyebíye tó ń pọ̀ sí i, èyí tá à ń lò nínú ìjọsìn wa, ká sì ṣe àkọsílẹ̀ wọn. Àwọn fọ́tò tí a tò nigín-nigín sí ibi Àpamọ́ yìí ni a lè sọ pé ó jẹ́ apá kan “fọ́tò ìdílé” wa. Àwọn ìṣúra iyebíye míì tó tún wà níbẹ̀ ni àwọn ìwé tá a kọ́kọ́ tẹ̀, ìtàn alárinrin táwọn ará kọ ránṣẹ́ nípa ara wọn àti àwọn ohun ìrántí tó wúlò lọ́pọ̀lọpọ̀. Àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ “àwọn ohun àjogúnbá” tí wọ́n ń jẹ́ ká lóye àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìtàn nípa ètò Ọlọ́run, wọ́n sì ń mú kí ọkàn wa balẹ̀ pé kò sí ohun tó máa ba àjọṣe tí ìdílé tẹ̀mí wa ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́.

Kó o lè mọ púpọ̀ sí i nípa Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Àpamọ́, a fẹ́ kó o máa ka àpilẹ̀kọ tuntun tá a pè ní, “Látinú Àpamọ́ Wa.” A ó máa tẹ̀ ẹ́ jáde látìgbàdégbà nínú ẹ̀dá Ilé Ìṣọ́ tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́. Bí àpẹẹrẹ, àpilẹ̀kọ kan máa wà nínú ẹ̀dà tó ń bọ̀ lọ́nà, èyí tó máa ní àwọn àwòrán tá a dìídì ṣètò láti dáhùn àwọn ìbéèrè bíi: Kí ló ń jẹ́ Àpótí Ìwé? Àwọn wo ló lò ó? Ìgbà wo ni wọ́n lò ó, kí ni wọ́n sì lò ó fún?

Bí fọ́tò ṣe máa ń jẹ́ kí ìdílé rántí ọ̀pọ̀ ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ohun tó wà ní ibi Àpamọ́ wa á ṣe jẹ́ ká mọ púpọ̀ sí i nípa àwa tá à ń sin Ọlọ́run lóde òní àtàwọn tó ti sìn ín ṣáájú wa. Ó máa jẹ́ ká mọ̀ nípa ìgbàgbọ́ àti ìgboyà wọn, nípa ayọ̀ tí wọ́n ní àtàwọn ìṣòro tí wọ́n dojú kọ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ àti bí Ọlọ́run ṣe darí àwọn èèyàn rẹ̀, tó sì tì wọ́n lẹ́yìn gbágbáágbá. (Diu. 33:27) Ó dá wa lójú pé Jèhófà máa bù kún wa bá a ti ń sapá láti máa tọ́jú àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìtàn nípa ètò Ọlọ́run ká bàa lè túbọ̀ wà ní ìṣọ̀kan ká sì ní okun tó pọ̀ sí i láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Àlàyé Síwájú Sí I

Bí àwọn tó ń kọ àwọn ìwé wa, àwọn ayàwòrán, àwọn tó ń ṣèwádìí àtàwọn míì bá ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí ìwé kan, àwo DVD tàbí ìsọfúnni mìíràn tó dá lórí Bíbélì, wọ́n máa ń lo àwọn ìsọfúnni tó wà ní ìpamọ́. Torí náà Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Àpamọ́ ń fi ìṣọ́ra kó onírúurú ìsọfúnni nípa ọ̀pọ̀ ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá jọ lọ́nà tó mọ́gbọ́n dání. Wọ́n máa ń rí irú àwọn ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ ní àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì, ẹ̀ka ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì, látinú ìjọ, látọ̀dọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan àti látọ̀dọ̀ àjọ táwọn èèyàn dá sílẹ̀. Ohun tí iṣẹ́ wọn dá lé rèé:

Ìkójọ àti Àyẹ̀wò: Ẹ̀ka yìí ń bá a nìṣó láti máa kó àwọn nǹkan iyebíye jọ sínú Àpamọ́ wa. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ohun tó wà níbẹ̀ ló jẹ́ pé ẹnì kan táwọn ìbátan rẹ̀ ti ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà látìgbà pípẹ́ sẹ́yìn ló fi ta wá lọ́rẹ tàbí ló yá wa. Bá a ti ń ṣe àyẹ̀wò irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ tá a sì ń fi wọ́n wéra ń jẹ́ ká túbọ̀ lóye ìtàn nípa ètò Ọlọ́run ká sì túbọ̀ mọyì àwọn tí ìtàn náà ṣojú wọn.

Àkójọ Létòlétò: Ẹgbẹẹgbẹ̀rún nǹkan tá à ń lò ló wà ní Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Àpamọ́, àwọn kan lára wọn ti lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún. Ọkàn-ò-jọ̀kan ni àwọn nǹkan tó wà níbẹ̀, a sì gbọ́dọ̀ fara balẹ̀ ṣe àkójọ wọn létòlétò ká lè rí wọn lò tó bá yá.

Ìtọ́jú àti Àtúnṣe: A máa ń lo ọ̀nà táwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ máa ń gbà tún nǹkan ṣe láti ṣe àtúnṣe àwọn ìwé àtàwọn ohun èlò míì tó ti di ẹlẹgẹ́ ká bàa lè tọ́jú wọn. A máa ń tọ́jú àwọn ìwé, fọ́tò, ìròyìn tá a gé pa mọ́, àwòrán sinimá àtàwọn ohùn tá a gbà sílẹ̀ sínú kọ̀ǹpútà. Èyí máa ń mú kó ṣeé ṣe fún wa láti wò wọ́n lórí kọ̀ǹpútà kí àwọn ohun ṣíṣeyebíye tí wọ́n fi ta wá lọ́rẹ tàbí tí wọ́n yá wa náà má bàa bà jẹ́ bá a ṣe ń gbé wọn lọ gbé wọn bọ̀.

Bá A Ṣe Ń Kó Wọn Pa Mọ́ àti Bá A Ṣe Ń Rí Wọn Lò: A máa ń tọ́jú àwọn ohun tó wà ní ìpamọ́ yìí lọ́nà tó wà létòlétò kí wọ́n má bàa sọ nù, kí ìmọ́lẹ̀ àti ọ̀rinrin má sì bà wọ́n jẹ́. A ti ń ṣètò bí a ó ṣe máa tọ́jú àwọn ìṣúra iyebíye yìí sínú kọ̀ǹpútà kó lè rọrùn láti lò wọ́n fún ìwádìí kó má sì ṣòro láti wá wọn rí.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

1. Ìwé tí wọ́n fi ké sí àwọn èèyàn láti wá wo “Photo-Drama of Creation” [Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá]. 2. Orúkọ àwọn tó san àsansílẹ̀-owó fún ìwé ìròyìn. 3. Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí wọ́n so ẹ̀rọ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ mọ́. 4. Èèpo ẹ̀yìn Ilé Ìṣọ́ April 15, 1912. 5. Ìwé ìfisẹ́wọ̀n J. F. Rutherford. 6. Makirofóònù ilé iṣẹ́ rédíò WBBR. 7. Ẹ̀rọ giramafóònù. 8. Àpótí ìwé. 9. Àkọsílẹ̀ ẹnì kan. 10. Wáyà tí wọ́n tẹ̀ ránṣẹ́ sí J. F. Rutherford.