Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bá A Ṣe Lè Máa Rúbọ Sí Jèhófà Tọkàntọkàn

Bá A Ṣe Lè Máa Rúbọ Sí Jèhófà Tọkàntọkàn

Bá A Ṣe Lè Máa Rúbọ Sí Jèhófà Tọkàntọkàn

“Ohun yòówù tí ẹ bá ń ṣe, ẹ fi tọkàntọkàn ṣe é bí ẹni pé fún Jèhófà.”—KÓL. 3:23.

1-3. (a) Ǹjẹ́ ikú Jésù lórí òpó igi oró túmọ̀ sí pé Jèhófà kò fẹ́ ká rú ẹbọ èyíkéyìí mọ́? Ṣàlàyé. (b) Àwọn ìbéèrè wo ló ṣeé ṣe ká fẹ́ láti wá ìdáhùn sí nípa àwọn ẹbọ tá à ń rú lóde òní?

 NÍ Ọ̀RÚNDÚN kìíní Sànmánì Kristẹni, Jèhófà ṣí i payá fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé ẹbọ ìràpadà Jésù ti fi òpin sí Òfin Mósè. (Kól. 2:13, 14) Gbogbo ìrúbọ tí àwọn Júù ti ń ṣe láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn kò pọn dandan mọ́, wọn kò sì wúlò fún ohunkóhun mọ́. Òfin ti ṣe àṣeparí iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ . . . tí ń sinni lọ sọ́dọ̀ Kristi.”—Gál. 3:24.

2 Èyí kò túmọ̀ sí pé ẹbọ rírú kò já mọ́ nǹkan kan lójú àwọn Kristẹni o. Kàkà bẹ́ẹ̀, àpọ́sítélì Pétérù sọ pé ó ṣe pàtàkì pé ká “máa rú àwọn ẹbọ ti ẹ̀mí tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi.” (1 Pét. 2:5) Síwájú sí i, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti mú kó ṣe kedere pé gbogbo ohun tó rọ̀ mọ́ ìgbésí ayé Kristẹni kan tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ la lè kà sí “ẹbọ.”—Róòmù 12:1.

3 Torí náà, Kristẹni kan máa ń rúbọ sí Jèhófà yálà nípa fífún un ní àwọn ohun kan tàbí nípa yíyááfì àwọn ohun kan kó lè sìn ín lọ́nà tó ṣètẹ́wọ́gbà. Látàrí ohun tá a mọ̀ nípa ohun tí Ọlọ́run sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa ẹbọ rírú, báwo ló ṣe lè dá wa lójú pé gbogbo ẹbọ tá à ń rú lónìí ni Jèhófà tẹ́wọ́ gbà?

ẸBỌ TÁ À Ń RÚ LÓJOOJÚMỌ́

4. Kí la gbọ́dọ̀ máa rántí nípa gbogbo ohun tá à ń ṣe lójoojúmọ́?

4 Bá a ti ń gbé ìgbé ayé wa ojoojúmọ́, ó lè dà bí ohun tó ṣòro fún wa láti ka àwọn ohun tá à ń ṣe sí rírú ẹbọ sí Jèhófà. Ó lè jọ pé iṣẹ́ ilé, iṣẹ́ iléèwé, iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, ọjà rírà, àtàwọn nǹkan míì tá à ń ṣe kò fi bẹ́ẹ̀ ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ìjọsìn wa. Àmọ́, bó o bá ti ya ìgbésí ayé rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà tàbí tó ò ń fojú sọ́nà pé kò ní pẹ́ tí wàá fi ṣe bẹ́ẹ̀, ojú tó o fi ń wo àwọn ìgbòkègbodò tara ṣe pàtàkì. Gbogbo wákàtí mẹ́rìnlélógún tó wà nínú ọjọ́ kan la fi jẹ́ Kristẹni. Torí náà, ó yẹ ká máa fi àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ sílò nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe. Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi rọ̀ wá pé: “Ohun yòówù tí ẹ bá ń ṣe, ẹ fi tọkàntọkàn ṣe é bí ẹni pé fún Jèhófà, kì í sì í ṣe fún ènìyàn.”—Ka Kólósè 3:18-24.

5, 6. Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká máa gbé yẹ̀ wò lójoojúmọ́ nípa àṣọ wa àti ìwà wa?

5 Àwọn ìgbòkègbodò tara tí Kristẹni kan máa ń lọ́wọ́ sí lójoojúmọ́ kì í ṣe ara iṣẹ́ ìsìn mímọ́ rẹ̀. Síbẹ̀, bí Pọ́ọ̀lù ṣe rọ̀ wá pé ká máa ṣiṣẹ́ “tọkàntọkàn . . . bí ẹni pé fún Jèhófà” máa ń mú ká ronú nípa ìgbésí ayé wa látòkèdélẹ̀. Torí náà, báwo la ṣe lè máa ṣe ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí? Ṣé gbogbo ìgbà là ń hùwà tó bójú mu tá a sì ń múra bí ọmọlúwàbí? Àbí, tá a bá ń lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò ojoojúmọ́, ṣé ìwà wa tàbí ìmúra wa máa mú kí ojú tì wá láti sọ fún àwọn èèyàn pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá? Ká má rí i! Àwọn èèyàn Jèhófà kò ní fẹ́ ṣe ohunkóhun tó lè tàbùkù sí orúkọ Ọlọ́run.—Aísá. 43:10; 2 Kọ́r. 6:3, 4, 9.

6 Ẹ jẹ́ ká jíròrò bí ìfẹ́ tá a ní láti máa ṣiṣẹ́ “tọkàntọkàn . . . bí ẹni pé fún Jèhófà” ṣe lè kan bá a ṣe ń ronú àti bá a ṣe ń hùwà lábẹ́ àwọn ipò tó yàtọ̀ síra. Bí ìjíròrò náà ti ń bá a nìṣó, ẹ jẹ́ ká máa fi sọ́kàn pé gbogbo ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá fẹ́ fi rúbọ sí Jèhófà gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tó dára jù lọ.—Ẹ́kís. 23:19.

BÓ ṢE KAN ÌGBÉSÍ AYÉ RẸ

7. Kí ló túmọ̀ sí fún Kristẹni kan láti ya ara rẹ̀ sí mímọ́?

7 Nígbà tó o ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, ńṣe lo pinnu láti ṣe bẹ́ẹ̀ láìsí iyè méjì, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ó wá dà bí ìgbà tó o sọ fún Jèhófà pé nínú ìgbésí ayé rẹ látòkèdélẹ̀, òun ni wàá máa fi sí ipò àkọ́kọ́. (Ka Hébérù 10:7.) Ìpinnu tó dára lo ṣe yẹn. Láìsí àní-àní, o ti rí i pé tó o bá wá bó o ṣe lè mọ ojú tí Jèhófà fi wo ọ̀ràn kan, tó o sì ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ nípa irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, ó máa ń yọrí sí ibi tó dára jù lọ. (Aísá. 48:17, 18) Àwọn èèyàn Ọlọ́run jẹ́ mímọ́ wọ́n sì máa ń láyọ̀ torí pé wọ́n máa ń fi àwọn ànímọ́ Ẹni tó ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ ṣèwà hù.—Léf. 11:44; 1 Tím. 1:11.

8. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì ká máa rántí pé Jèhófà ka àwọn ẹbọ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì rú sí mímọ́?

8 Jèhófà ka ẹbọ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rú sí mímọ́. (Léf. 6:25; 7:1) Ọ̀rọ̀ Hébérù tá a túmọ̀ sí “ìjẹ́mímọ́” lédè Yorùbá dúró fún ìyàsọ́tọ̀, ìyàsọ́tọ̀ gedegbe tàbí ìyàsímímọ́ fún Ọlọ́run. Tá a bá fẹ́ kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba àwọn ẹbọ wa, wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tá a yà sọ́tọ̀ tí ẹ̀mí ayé kò sì kó àbààwọ́n bá. A kò gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí èyíkéyìí lára àwọn nǹkan tí Jèhófà kórìíra. (Ka 1 Jòhánù 2:15-17.) Ní kedere, èyí túmọ̀ sí pé a gbọ́dọ̀ yẹra fún ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun tó lè sọ wá di ẹlẹ́gbin lójú Ọlọ́run. (Aísá. 2:4; Ìṣí. 18:4) Ó tún túmọ̀ sí pé a kò ní máa tẹ ojú wa mọ́ ohun àìmọ́ tàbí ìṣekúṣe tàbí ká máa fi ọkàn yàwòrán irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀.—Kól. 3:5, 6.

9. Báwo ni ìwà tí Kristẹni kan ń hù sáwọn èèyàn ti ṣe pàtàkì tó, kí sì nìdí?

9 Pọ́ọ̀lù rọ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ pé: “Ẹ má gbàgbé rere ṣíṣe àti ṣíṣe àjọpín àwọn nǹkan pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, nítorí irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ.” (Héb. 13:16) Torí náà, Jèhófà máa ń ka jíjẹ́ ẹni rere àti ṣíṣe ohun rere fáwọn èèyàn sí ẹbọ tí òun tẹ́wọ́ gbà. Ọ̀kan lára ohun tá a fi ń dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀ ni pé wọ́n máa ń jẹ́ kí ọ̀ràn àwọn èèyàn jẹ àwọn lógún torí ìfẹ́ tí wọ́n ní sí wọn.—Jòh. 13:34, 35; Kól. 1:10.

ÀWỌN ẸBỌ TÁ À Ń RÚ NÍNÚ ÌJỌSÌN

10, 11. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa àti ìjọsìn wa, ipa wo ló sì yẹ kí èyí ní lórí wa?

10 Ọ̀kan lára ọ̀nà tó hàn gbangba jù lọ táwa Kristẹni ń gbà ṣe ohun tó dára fáwọn èèyàn jẹ́ nípasẹ̀ “ìpolongo ìrètí wa ní gbangba.” Ṣé o máa ń lo gbogbo àǹfààní tó o bá ní láti jẹ́rìí? Pọ́ọ̀lù pe ìgbòkègbodò Kristẹni tó ṣe pàtàkì yìí ní “ẹbọ ìyìn . . . , èyíinì ni, èso ètè tí ń ṣe ìpolongo ní gbangba sí orúkọ [Ọlọ́run].” (Héb. 10:23; 13:15; Hós. 14:2) Ọ̀pọ̀ nǹkan la lè sọ nípa bí àkókò tá à ń lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ṣe pọ̀ tó àti bó ṣe gbéṣẹ́ tó, a sì ti ṣètò ọ̀pọ̀ lára àwọn apá Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn lọ́nà tí wọ́n á fi mú ká lè máa ronú lórí àwọn ohun tó kan iṣẹ́ ìsìn wa. Àmọ́, láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀, níwọ̀n bí iṣẹ́ ìsìn pápá wa àti ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà ti jẹ́ “ẹbọ ìyìn,” èyí tí í ṣe apá kan ìjọsìn wa, irú ẹbọ bẹ́ẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tó dára jù lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò olúkúlùkù wa yàtọ̀ síra, bí àkókò tá à ń lò láti fi polongo ìhìn rere bá ṣe pọ̀ tó sábà máa ń fi bá a ṣe mọrírì àwọn nǹkan tẹ̀mí tó hàn.

11 Àwa Kristẹni máa ń sin Ọlọ́run déédéé yálà nínú ilé tàbí nínú ìjọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí ń gba àkókò, ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe nìyẹn. Òótọ́ ni pé a kì í pa ọjọ́ ìsinmi Sábáàtì mọ́, a kì í sì í rìnrìn-àjò ọdọọdún lọ sí Jerúsálẹ́mù láti lọ ṣe àjọyọ̀. Àmọ́, àwọn ohun kan wà táwa Kristẹni ń ṣe lónìí tó dúró fún àwọn ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì wọ̀nyẹn ṣe. Ọlọ́run ṣì fẹ́ ká yẹra fún àwọn òkú iṣẹ́, ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ká máa gbàdúrà, ká sì máa lọ sáwọn ìpàdé ìjọ. Ojúṣe àwọn Kristẹni tó jẹ́ olórí ìdílé ni pé kí wọ́n máa ṣe ìjọsìn ìdílé pẹ̀lú àwọn tó wà nínú ìdílé wọn. (1 Tẹs. 5:17; Héb. 10:24, 25) Bá a ṣe ń ronú nípa àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí wa, ó dára ká máa bi ara wa pé, ‘Ǹjẹ́ mo lè mú kí ìjọsìn mi sunwọ̀n sí i?’

12. (a) Kí la lè fi tùràrí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì máa ń sun bí wọ́n bá ń jọ́sìn wé lónìí? (b) Kí ló yẹ kí ìfiwéra yìí mú ká ṣe nípa ohun tá à ń sọ nígbà tá a bá ń gbàdúrà?

12 Dáfídì Ọba kọrin sí Jèhófà, ó ní: “Kí a pèsè àdúrà mi sílẹ̀ bí tùràrí níwájú rẹ.” (Sm. 141:2) Ronú díẹ̀ nípa àdúrà rẹ ná, bó o ṣe ń gbàdúrà déédéé sí àti bí àdúrà rẹ ṣe ń nítumọ̀ sí. Ìwé Ìṣípayá fi “àdúrà àwọn ẹni mímọ́” wé tùràrí torí pé ńṣe ni àdúrà tó ṣètẹ́wọ́gbà máa ń gòkè tọ Jèhófà lọ bí òórùn dídùn tó gbádùn mọ́ni. (Ìṣí. 5:8) Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, wọ́n gbọ́dọ̀ ṣọ́ra bí wọ́n bá ń ṣe tùràrí tí wọ́n máa ń sun déédéé lórí pẹpẹ Jèhófà, wọ́n sì gbọ́dọ̀ ṣe é gẹ́lẹ́ bí Ọlọ́run ṣe pàṣẹ fún wọn. Bí wọ́n bá sun ún ní ìbámu pẹ̀lú ìtọ́ni tí Jèhófà fún wọn nìkan ló tó lè ṣètẹ́wọ́gbà. (Ẹ́kís. 30:34-37; Léf. 10:1, 2) Bí àwa náà bá ń kó ọ̀rọ̀ inú àdúrà wa jọ lọ́nà yìí, tá a sì gbà á látọkàn wá, ó dá wa lójú pé Jèhófà máa tẹ́wọ́ gbà á.

BÁ A ṢE Ń FÚNNI ÀTI BÁ A ṢE Ń RÍ GBÀ

13, 14. (a) Kí ni Ẹpafíródítù àti àwọn ará ìjọ Fílípì ṣe fún Pọ́ọ̀lù, ojú wo sì ni àpọ́sítélì náà fi wò ó? (b) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ẹpafíródítù àti àwọn ará ìjọ Fílípì?

13 A lè fi àwọn ọrẹ owó tá a fi ń ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ kárí ayé wé ẹbọ rírú, yálà irú ọrẹ bẹ́ẹ̀ pọ̀ tàbí ó kéré. (Máàkù 12:41-44) Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni, ìjọ tó wà ní ìlú Fílípì rán Ẹpafíródítù lọ sí ìlú Róòmù kó lè lọ ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́. Ó dájú pé ẹni tí àwọn ará ìjọ Fílípì rán láti lọ ṣojú fún wọn yìí gbé ẹ̀bùn owó tí wọ́n fi rán an dání. Èyí kọ́ ni ìgbà àkọ́kọ́ tí àwọn ará Fílípì fi ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí Pọ́ọ̀lù. Inú rere tí wọ́n fi hàn sí Pọ́ọ̀lù kò ní jẹ́ kó máa ṣàníyàn nípa ọ̀ràn ìnáwó á sì lè lo àkókò púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ojú wo ni Pọ́ọ̀lù fi wo ẹ̀bùn náà? Ó pè é ní “òórùn tí ń run dídùn, ẹbọ tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó wu Ọlọ́run gidigidi.” (Ka Fílípì 4:15-19.) Ó dájú pé Pọ́ọ̀lù mọrírì inú rere tí àwọn ará Fílípì fi hàn sí i yìí, Jèhófà pẹ̀lú sì mọrírì rẹ̀.

14 Bákan náà, lónìí, Jèhófà mọrírì àwọn ọrẹ tá a fi ń ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ kárí ayé gidigidi. Síwájú sí i, ó ṣèlérí pé tá a bá ń bá a nìṣó láti máa fi ire Ìjọba Ọlọ́run sí ipò kìíní ní ìgbésí ayé wa, òun máa fún wa ní gbogbo nǹkan tá a ṣe aláìní nípa tara àti nípa tẹ̀mí.—Mát. 6:33; Lúùkù 6:38.

FI HÀN PÉ O MOORE

15. Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó ò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún?

15 Ó máa gba àkókò gígùn tá a bá ní ká máa to àwọn ìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà lẹ́sẹẹsẹ. Ǹjẹ́ kò yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ lójoojúmọ́ pé ó mú ká wà láàyè? Ó fún wa ní gbogbo ohun ìgbẹ́mìíró tá a nílò, irú bí oúnjẹ, aṣọ àti ibùgbé tó fi mọ́ afẹ́fẹ́ tá à ń mí símú. Ní àfikún sí ìyẹn, ìgbàgbọ́ wa tá a gbé karí ìmọ̀ pípéye ń mú ká ní ìrètí. Ó yẹ ká máa sin Jèhófà ká sì máa rú ẹbọ ìyìn sí i, nítorí irú ẹni tó jẹ́ àti nítorí àwọn ohun tó ti ṣe fún wa.—Ka Ìṣípayá 4:11.

16. Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo ẹbọ ìràpadà Kristi?

16 Gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, ẹ̀bùn tó ṣeyebíye jù lọ tí Ọlọ́run fún aráyé ni ẹbọ ìràpadà Kristi. Èyí jẹ́ ọ̀nà títayọ tí Ọlọ́run gbà fi ìfẹ́ tó ní sí wa hàn. (1 Jòh. 4:10) Irú ojú wo ló yẹ ká fi wo ẹbọ náà? Pọ́ọ̀lù polongo pé: “Ìfẹ́ tí Kristi ní sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún wa, nítorí èyí ni ohun tí àwa ti ṣèdájọ́, pé ọkùnrin kan kú fún gbogbo ènìyàn; . . . ó sì kú fún gbogbo wọn kí àwọn tí ó wà láàyè má ṣe tún wà láàyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú fún wọn, tí a sì gbé dìde.” (2 Kọ́r. 5:14, 15) Ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni pé tá a bá mọrírì inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, a ó máa gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó fi hàn pé à ń bọlá fún Òun àti Ọmọ Rẹ̀. À ń fi ìfẹ́ àti ìmọrírì tá a ní fún Ọlọ́run àti Kristi hàn tá a bá ń ṣègbọràn tó sì ń wù wá láti wàásù ká sì sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn.—1 Tím. 2:3, 4; 1 Jòh. 5:3.

17, 18. Àwọn ọ̀nà wo ni àwọn kan ti gbà mú kí ẹbọ ìyìn tí wọ́n ń rú sí Jèhófà pọ̀ sí i? Sọ àpẹẹrẹ kan.

17 Ṣé ó máa ṣeé ṣe fún ẹ láti mú kí ẹbọ ìyìn tó ò ń rú sí Ọlọ́run sunwọ̀n sí i? Lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti ronú lórí gbogbo ohun rere tí Jèhófà ti ṣe fún wọn, ìyẹn ti mú kí wọ́n ṣètò àkókò àtàwọn ìgbòkègbodò wọn kí wọ́n lè túbọ̀ máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti àwọn ìgbòkègbodò míì tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run. Ó ti ṣeé ṣe fún àwọn kan láti máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fún oṣù kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lọ́dọọdún, àwọn míì sì ti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Kódà, àwọn míì ti dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń kọ́ àwọn ilé tá à ń lò fún ìjọsìn Jèhófà. Ǹjẹ́ ọ̀nà tó dára jù lọ kọ́ nìwọ̀nyí tá a lè gbà fi hàn pé a moore? Bó bá jẹ́ pé torí ká lè fi ìmoore àti ọpẹ́ hàn la ṣe ń kópa nínú àwọn iṣẹ́ ìsìn mímọ́ yìí, a jẹ́ pé èrò tó tọ́ ló sún wa ṣe é, ó sì máa ṣètẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run.

18 Ọ̀pọ̀ Kristẹni ló ń wù pé kí wọ́n máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà. Morena jẹ́ ọ̀kan lára irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Ó wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tó ní nípa ìjọsìn Ọlọ́run nínú ẹ̀sìn Kátólíìkì tí wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà àti nínú ìmọ̀ ọgbọ́n orí tí àwọn ará Éṣíà fi ń kọ́ni. Àmọ́ kò rí ìdáhùn tó tẹ́ ẹ lọ́rùn níbi méjèèjì. Àfìgbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló tó rí nǹkan pa òùngbẹ tẹ̀mí tó ń gbẹ ẹ́. Morena mọyì àwọn ìdáhùn tó rí nínú Ìwé Mímọ́ àti bí àwọn ìdáhùn yẹn ṣe mú kí ìgbésí ayé rẹ̀ nítumọ̀, èyí sì mú kó fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nípa lílo gbogbo okun rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Kété lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, ó sì di aṣáájú-ọ̀nà déédéé gbàrà tí àǹfààní ṣí sílẹ̀ fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọgbọ̀n [30] ọdún ti kọjá látìgbà náà wá, Morena ṣì wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún.

19. Báwo lo ṣe lè mú kí àwọn ẹbọ tó ò ń rú sí Jèhófà pọ̀ sí i?

19 Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ni ipò wọn kò yọ̀ǹda fún láti ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Síbẹ̀, gbogbo wa pátá la lè rú àwọn ẹbọ tẹ̀mí tó ṣètẹ́wọ́gbà sí Jèhófà tá a bá ń ṣe ohun yòówù tí agbára wa gbé láti ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìgbà gbogbo là ń ṣojú fún Jèhófà, a gbọ́dọ̀ máa fi àwọn ìlànà òdodo rẹ̀ ṣe ìwà hù. Ìgbàgbọ́ tá a ní mú ká ní ìgbọ́kànlé kíkún nínú bí àwọn ètè Ọlọ́run ṣe ń ní ìmúṣẹ. Ní ti àwọn iṣẹ́ rere, à ń lọ́wọ́ nínú títan ìhìn rere kálẹ̀. Ẹ jẹ́ kí ọ̀pọ̀ yanturu ohun tó wà nínú ọkàn wa àti ìmọrírì tá a ní fún gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa mú ká máa bá a nìṣó láti máa rúbọ sí Jèhófà tọkàntọkàn.

WÒ Ó BÓYÁ O LÈ RÍ ÌDÁHÙN SÍ ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

․․․․․

Báwo la ṣe lè máa bọlá fún Jèhófà nínú àwọn ohun tá à ń ṣe lójoojúmọ́?

․․․․․

Irú àwọn ẹbọ wo là ń rú nínú ìjọsìn Ọlọ́run?

․․․․․

Báwo la ṣe lè fún Jèhófà ní àwọn ohun ìní wa?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí tó wà ní ojú ìwé 25]

Ṣé àwọn ohun rere tí Jèhófà ń ṣe ń mú kí ẹbọ ìyìn rẹ sunwọ̀n sí i?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ṣé o máa ń lo gbogbo àǹfààní tó o bá ní láti jẹ́rìí?