Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú ‘Kókó Òtítọ́’

Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú ‘Kókó Òtítọ́’

Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú ‘Kókó Òtítọ́’

“[Ẹ̀yín ní] kókó ìmọ̀ àti ti òtítọ́ inú Òfin.”—RÓÒMÙ 2:20.

1. Kí nìdí tó fi yẹ ká fẹ́ láti mọ bí Òfin Mósè ti ṣe pàtàkì tó?

 BÍ KÒ bá sí ti àwọn ohun tí Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ sínú Ìwé Mímọ́ ni, ì bá ṣòro fún wa láti mọ bí ọ̀pọ̀ apá tí Òfin Mósè pín sí ti ṣe pàtàkì tó. Bí àpẹẹrẹ, nínú lẹ́tà tó kọ sí àwọn Hébérù, ó ṣàlàyé ohun tó mú kó ṣeé ṣe fún Jésù, ‘àlùfáà àgbà tí ó jẹ́ olùṣòtítọ́,’ láti rú “ẹbọ ìpẹ̀tù” lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún tún un ṣe mọ́ láé, èyí tó mú kó ṣeé ṣe fún àwọn tó ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ láti rí “ìdáǹdè àìnípẹ̀kun.” (Héb. 2:17; 9:11, 12) Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé ńṣe ni àgọ́ ìjọsìn wulẹ̀ jẹ́ “òjìji àwọn ohun ti ọ̀run” àti pé Jésù di Alárinà “májẹ̀mú tí ó dára” ju èyí tí Mósè ṣe alárinà rẹ̀ lọ. (Héb. 7:22; 8:1-5) Nígbà ayé Pọ́ọ̀lù, àlàyé tó ṣe nípa Òfin Mósè ṣe pàtàkì gan-an fún àwọn Kristẹni, bẹ́ẹ̀ náà ló sì ṣe pàtàkì lóde òní. Wọ́n mú ká túbọ̀ lóye bí àwọn ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún wa ti ṣe pàtàkì tó.

2. Kí ló mú kí àwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù mọ̀ nípa Òfin Ọlọ́run ju àwọn Kèfèrí lọ?

2 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tó wà ní ìlú Róòmù, àwọn ará tí wọ́n jẹ́ Júù tí wọ́n sì ti gba ìtọ́ni nínú Òfin Mósè ló darí díẹ̀ lára ọ̀rọ̀ tó sọ sí. Ó gbà pé àwọn yẹn ní àǹfààní láti ní “kókó ìmọ̀ àti ti òtítọ́” nípa Jèhófà àtàwọn ìlànà òdodo rẹ̀ torí pé wọ́n mọ Òfin Ọlọ́run. Òye tí àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Júù ní nípa ‘kókó òtítọ́’ àti ọ̀wọ̀ àtọkànwá tí wọ́n ní fún un ló mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti máa tọ́ àwọn tí kò mọ Òfin tí Jèhófà ti fún àwọn èèyàn rẹ̀ sọ́nà, kí wọ́n máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n sì máa fi àwọn ohun tó yẹ kí wọ́n mọ̀ nípa Jèhófà hàn wọ́n, ohun tí àwọn Júù tó wà ṣáájú wọn náà sì ṣe nìyẹn.—Ka Róòmù 2:17-20.

Ó ṢÀPẸẸRẸ ẸBỌ JÉSÙ

3. Báwo la ṣe lè jàǹfààní tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ẹbọ tí àwọn Júù rú kí ẹ̀sìn Kristẹni tó bẹ̀rẹ̀?

3 Ó ṣe pàtàkì pé ká mọ kókó òtítọ́ tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ká bàa lè lóye àwọn ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn láti ṣe. Àwọn ìlànà inú Òfin Mósè ṣì ṣe pàtàkì fún wa gan-an lónìí. Torí náà, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ọ̀kan ṣoṣo lára apá tí Òfin yẹn pín sí. Apá yẹn ní ín ṣe pẹ̀lú bí onírúurú ẹbọ àtàwọn ọrẹ ẹbọ ṣe darí àwọn Júù tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ sí Kristi tó sì jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n máa ṣe. Níwọ̀n bí ó sì ti jẹ́ pé ìlànà tí Jèhófà fẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ máa tẹ̀ lé kì í yí pa dà, a óò tún rí i pé Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa ẹbọ àti àwọn ọrẹ ẹbọ lè mú kí àwa náà ronú nípa bí iṣẹ́ ìsìn mímọ́ wa ṣe jẹ́ ojúlówó tó.—Mál. 3:6.

4, 5. (a) Kí ni Òfin Mósè máa ń jẹ́ kí àwọn èèyàn Ọlọ́run rántí? (b) Kí ni òfin Ọlọ́run nípa ẹbọ rírú ṣàpẹẹrẹ?

4 Ọ̀pọ̀ lára apá tí Òfin Mósè pín sí ló ń jẹ́ kí àwọn Júù ìgbàanì rántí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni àwọn. Bí àpẹẹrẹ, bí ẹnì kan bá fọwọ́ kan òkú èèyàn, ó gbọ́dọ̀ ṣe ìwẹ̀nùmọ́. Kí àlùfáà bàa lè ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún un, ó máa mú màlúù pupa kan tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá lọ sọ́dọ̀ àlùfáà. Àlùfáà á pa màlúù náà, á sì fi iná sun ún. Á wá tọ́jú eérú rẹ̀ kí wọ́n lè fi ṣe “omi ìwẹ̀nùmọ́” tí wọ́n máa wọ́n sára ẹni tí wọ́n fẹ́ ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún ní ọjọ́ kẹta àti ní ọjọ́ keje lẹ́yìn tó di aláìmọ́. (Núm. 19:1-13) Bákan náà, kí àwọn èèyàn lè máa rántí pé láti ìgbà tí obìnrin bá ti bímọ ni ọmọ náà ti jogún àìpé àti ẹ̀ṣẹ̀, òfin sọ pé kí irú obìnrin bẹ́ẹ̀ jẹ́ aláìmọ́ fún àwọn àkókò kan, lẹ́yìn ìyẹn ló máa wá lọ rú ẹbọ láti tọrọ ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.—Léf. 12:1-8.

5 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún máa ń fi ẹran rúbọ nítorí ọ̀pọ̀ nǹkan míì tó kan ìgbésí ayé wọn ojoojúmọ́ kí wọ́n lè ṣètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Yálà àwọn olùjọ́sìn yìí mọ̀ bẹ́ẹ̀ tàbí wọn kò mọ̀ bẹ́ẹ̀, àwọn ẹbọ yìí àti àwọn tí wọ́n rú nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà lẹ́yìn ìgbà náà jẹ́ “òjìji” ẹbọ pípé tí Jésù rú.—Héb. 10:1-10.

OHUN TÍ ẸBỌ NÁÀ FI HÀN

6, 7. (a) Àwọn nǹkan wo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń gbé yẹ̀ wò kí wọ́n tó yan ohun tí wọ́n máa fi rúbọ, kí sì ni èyí ṣàpẹẹrẹ? (b) Àwọn ìbéèrè wo la lè bi ara wa?

6 Ìlànà pàtàkì kan tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń tẹ̀ lé tí wọ́n bá fẹ́ pinnu irú ẹran tí wọ́n máa fi rúbọ sí Jèhófà ni pé kí ẹran náà jẹ́ èyí tí “ara rẹ̀ dá ṣáṣá” ní gbogbo ọ̀nà, kò gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tó fọ́jú, tó fara pa, tó lábùkù lára tàbí èyí tó ń ṣàìsàn. (Léf. 22:20-22) Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá fi èso tàbí ọkà rúbọ sí Jèhófà, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ “àkọ́so,” “èyí tí ó dára jù lọ” nínú irè oko wọn. (Núm. 18:12, 29) Jèhófà kò ní gba ẹbọ wọn bí wọ́n bá lo àwọn ohun tí kò dára. Ohun pàtàkì tí Ọlọ́run béèrè nípa fífi ẹran rúbọ fi hàn pé ẹbọ Jésù máa jẹ́ èyí tí kò lábààwọ́n àti èyí tí kò léèérí àti pé ohun tí Jèhófà kà sí ohun tó dára jù lọ tó sì ṣe pàtàkì jù lọ ló máa fi rúbọ kó bàa lè ra aráyé pa dà.—1 Pét. 1:18, 19.

7 Bó bá jẹ́ pé òótọ́ ni ẹni tó fẹ́ rúbọ mọyì gbogbo oore Jèhófà, ǹjẹ́ inú rẹ̀ kò ní dùn láti yan èyí tó dára jù lọ lára àwọn ohun tó ní kó lè fi rúbọ? Ọwọ́ ẹni tó fẹ́ rúbọ náà ló kù sí láti pinnu bí ohun tó máa fi rúbọ á ṣe dára tó. Àmọ́ ṣá o, ó mọ̀ pé inú Ọlọ́run kò ní dùn sí ẹbọ tó lábùkù torí pé ńṣe nìyẹn máa fi hàn pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ka ẹbọ rírú sí ohun gbà-má-pa-mí-jẹ, kódà ẹrù ìnira ni. (Ka Málákì 1:6-8, 13.) Ó yẹ kí èyí mú ká ronú nípa iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run, ká sì bi ara wa pé: ‘Kí ló mú kí n máa sin Jèhófà? Ǹjẹ́ ó yẹ kí n ṣàyẹ̀wò bí iṣẹ́ ìsìn mi ṣe jẹ́ ojúlówó tó àti ohun tó mú kí n máa sin Ọlọ́run?’

8, 9. Kí nìdí tó fi yẹ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ń mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rúbọ?

8 Bó bá jẹ́ pé ńṣe ni ọmọ Ísírẹ́lì kan fẹ́ fínnúfíndọ̀ rúbọ sí Jèhófà torí pé ó mọyì oore rẹ̀ látọkàn wá tàbí tó fẹ́ rú ẹbọ sísun kó bàa lè rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run, ó lè má ṣòro fún un láti yan irú ẹran tó tọ́ láti fi rúbọ. Inú irú olùjọ́sìn bẹ́ẹ̀ máa dùn láti fún Jèhófà ní ẹran tó kà sí èyí tó dára jù lọ. Lóde òní, àwọn Kristẹni kì í rúbọ lọ́nà tí Òfin Mósè là kalẹ̀; síbẹ̀ wọ́n máa ń rúbọ ní ti pé wọ́n máa ń lo àkókò wọn, okun wọn àti ohun ìní wọn láti sin Jèhófà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ìrètí tí àwọn Kristẹni ní, èyí tí wọ́n ń ‘polongo rẹ̀ ní gbangba’ àti “rere ṣíṣe àti ṣíṣe àjọpín àwọn nǹkan pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn” jẹ́ àwọn ẹbọ tí inú Ọlọ́run dùn sí. (Héb. 13:15, 16) Ọ̀nà tí àwọn èèyàn Jèhófà ń gbà ṣe àwọn nǹkan yẹn jẹ́ ká rí bí wọ́n ṣe moore tó tí wọ́n sì mọrírì gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún wọn. Torí náà ọ̀nà tí à ń gbà lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run lóde òní àti ohun tó ń mú ká fẹ́ láti lọ́wọ́ nínú rẹ̀ jọ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì tí wọ́n fínnúfíndọ̀ rúbọ sí Jèhófà.

9 Àmọ́, kí la lè sọ nípa ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi tí Òfin Mósè béèrè lọ́wọ́ ẹnì kan tó bá ṣe àṣemáṣe? Ǹjẹ́ o rò pé bí Òfin ṣe kàn án nípá fún ẹni náà kò ní jẹ́ kó rú ẹbọ náà látọkàn wá àti pé ó máa nípa lórí ìṣesí rẹ̀? Àbí ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni onítọ̀hún á fi ìlọ́tìkọ̀ rú ẹbọ náà? (Léf. 4:27, 28) Kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀ bí ẹni tí ọ̀rọ̀ kàn kò bá fẹ́ kí àjọṣe rere tó ní pẹ̀lú Jèhófà bà jẹ́.

10. “Àwọn ẹbọ” wo ni àwa Kristẹni lè rú ká lè pa dà ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà àtàwọn ará wa?

10 Bákan náà lóde òní, o lè rí i pé o ti ṣẹ arákùnrin tàbí arábìnrin kan láìmọ̀, bóyá nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ kan tó o sọ tàbí ìwà kan tó o hù láìronú jinlẹ̀. Ẹ̀rí ọkàn rẹ lè jẹ́ kó o mọ̀ pé o ti ṣe ohun tó kù díẹ̀ káàtó. Ẹnikẹ́ni tó bá fi ọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn rẹ̀ sí Jèhófà á sa gbogbo ipá rẹ̀ láti yanjú ọ̀rọ̀ náà, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Èyí lè gba pé kó tọrọ àforíjì látọkàn wá lọ́wọ́ ẹni tó ṣẹ̀ náà, tó bá sì jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì ló dá, kó tọ àwọn alábòójútó onífẹ̀ẹ́ nínú ìjọ lọ kí wọ́n lè ràn án lọ́wọ́. (Mát. 5:23, 24; Ják. 5:14, 15) Èyí fi hàn pé ká tó lè yanjú ẹ̀ṣẹ̀ tá a ṣẹ èèyàn bíi tiwa tàbí Ọlọrun, ó máa ná wa ní nǹkan kan. Àmọ́ tá a bá rú irú “àwọn ẹbọ” bẹ́ẹ̀, a máa pa dà ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà àti àwọn ará wa, a ó sì ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. Èyí á wá jẹ́ kó dá wa lójú pé, ọ̀nà Jèhófà ló dára jù lọ.

11, 12. (a) Báwo ni wọ́n ṣe máa ń rú àwọn ẹbọ ìdàpọ̀? (b) Kí ni àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ kọ́ wa nípa ìjọsìn tòótọ́ lóde òní?

11 Àwọn ẹbọ kan wà tí Òfin Mósè ní kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa rú, èyí tí Bíbélì pè ní ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀. Èyí ṣàpẹẹrẹ wíwà ní àlàáfíà pẹ̀lú Jèhófà. Ẹni tó mú irú ọrẹ ẹbọ bẹ́ẹ̀ wá àti ìdílé rẹ̀ máa ń jẹ ẹran tí wọ́n fi rúbọ náà, bóyá ní ọ̀kan lára àwọn yàrá ìjẹun tó wà nínú tẹ́ńpìlì. Àlùfáà tó bá wọn rúbọ máa gba díẹ̀ lára ẹran náà, àwọn àlùfáà míì tó ń ṣiṣẹ́ nínú tẹ́ńpìlì náà á sì gbà nínú rẹ̀. (Léf. 3:1, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé NW; 7:31-33) Torí pé olùjọ́sìn tó rú ẹbọ náà fẹ́ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run ló ṣe wá rú ẹbọ náà. Ńṣe ló dà bí ìgbà tí olùjọ́sìn náà, ìdílé rẹ̀, àwọn àlùfáà àti Jèhófà fúnra rẹ̀ jọ ń jẹun pa pọ̀ tayọ̀tayọ̀, ní àlàáfíà.

12 Ńṣe ni rírú ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ dà bí ìgbà téèyàn pe Jèhófà síbi àpèjẹ. Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ ló sì jẹ́ fún ọmọ Ísírẹ́lì kan pé Jèhófà gbà láti wá sí irú àpèjẹ bẹ́ẹ̀. Kò sí àní-àní pé ẹni náà máa fẹ́ láti lo ẹran tó dára jù lọ láti ṣe ẹni pàtàkì yìí lálejò. Rírú àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ jẹ́ ara kókó òtítọ́ inú Òfin, ó sì fi hàn pé gbogbo àwọn tó bá fẹ́ sún mọ́ Ẹlẹ́dàá pẹ́kípẹ́kí, tí wọ́n sì fẹ́ láti wà ní àlàáfíà pẹ̀lú rẹ̀ lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ ìrúbọ títóbi jù lọ tí Jésù ṣe. Lóde òní, a lè bá Jèhófà dọ́rẹ̀ẹ́ ká sì gbádùn àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀ bá a ṣe ń fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda àwọn ohun ìní wa tá a sì ń lo okun wa nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀.

ÀWỌN ÌKÌLỌ̀ NÍPA ẸBỌ RÍRÚ

13, 14. Kí nìdí tí Jèhófà kò fi gba ohun tí Sọ́ọ̀lù Ọba fẹ́ fi rúbọ?

13 Kí Jèhófà tó lè gba àwọn ẹbọ tí Òfin Mósè là kalẹ̀, ẹni tó rú ẹbọ náà gbọ́dọ̀ ní èrò tó tọ́ àti ọkàn mímọ́. Nínú Bíbélì, a rí ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn ẹbọ tí ṣètẹ́wọ́gbà lójú Ọlọ́run, tó sì jẹ́ ìkìlọ̀ fún wa. Kí nìdí tí Ọlọ́run kò fi tẹ́wọ́ gba àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àpẹẹrẹ méjì.

14 Wòlíì Sámúẹ́lì sọ fún Sọ́ọ̀lù Ọba pé àkókò ti tó fún Jèhófà láti ṣe ìdájọ́ àwọn ọmọ Ámálékì. Torí náà, Sọ́ọ̀lù ní láti pa orílẹ̀-èdè tó jẹ́ ọ̀tá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yìí run pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹran ọ̀sìn tó wà níbẹ̀. Àmọ́, lẹ́yìn tí Sọ́ọ̀lù ṣẹ́gun, ó ní kí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ dá Ágágì tó jẹ́ ọba àwọn ọmọ Ámálékì sí. Sọ́ọ̀lù tún dá àwọn tó dára jù lọ lára àwọn ohun ọ̀sìn wọn sí gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n lè fi rúbọ sí Jèhófà. (1 Sám. 15:2, 3, 21) Kí ni Jèhófà wá ṣe? Ó kọ Sọ́ọ̀lù nítorí pé ó ṣàìgbọràn. (Ka 1 Sámúẹ́lì 15:22, 23.) Kí la rí kọ́ nínú èyí? Òun tá a rí kọ́ ni pé kí Ọlọ́run tó lè tẹ́wọ́ gba ẹbọ ẹnì kan ẹni náà gbọ́dọ̀ máa pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́.

15. Kí ni ìwà burúkú tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan tó rúbọ nígbà ayé Aísáyà hù fi hàn?

15 A rí àpẹẹrẹ irú èyí nínú ìwé Aísáyà. Nígbà ayé Aísáyà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń rúbọ sí Jèhófà. Àmọ́ ìwà burúkú wọn kò jẹ́ kí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba ẹbọ wọn. Jèhófà béèrè pé: “Àǹfààní kí ni ògìdìgbó àwọn ẹbọ yín jẹ́ fún mi? Odindi ọrẹ ẹbọ sísun ti àgbò àti ọ̀rá àwọn ẹran tí a bọ́ dáadáa ti tó mi gẹ́ẹ́; èmi kò sì ní inú dídùn sí ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹgbọrọ akọ màlúù àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn àti òbúkọ. . . . Ẹ ṣíwọ́ mímú àwọn ọrẹ ẹbọ ọkà tí kò ní láárí wá. Tùràrí—ó jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí fún mi.” Kí ni ìṣòro wọn? Ọlọ́run sọ fún wọn pé: “Bí ẹ tilẹ̀ gba àdúrà púpọ̀, èmi kò ní fetí sílẹ̀; àní ọwọ́ yín kún fún ìtàjẹ̀sílẹ̀. Ẹ wẹ̀; ẹ jẹ́ kí ara yín mọ́; ẹ mú búburú ìbánilò yín kúrò ní iwájú mi; ẹ ṣíwọ́ ṣíṣe búburú.”—Aísá. 1:11-16.

16. Kí ló lè mú kí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba ẹbọ kan?

16 Inú Jèhófà kì í dùn sí ẹbọ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà. Àmọ́ ṣá o, Ọlọ́run máa ń gbọ́ àdúrà àwọn tó ń sapá tọkàntọkàn láti máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, ó sì máa ń tẹ́wọ́ gba ọrẹ ẹbọ wọn. Kókó inú Òfin ti kọ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pé wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ àti pé wọ́n nílò ìdáríjì. (Gál. 3:19) Ohun tí wọ́n mọ̀ yìí máa ń jẹ́ kí wọ́n ní ìròbìnújẹ́ ọkàn. Bákan náà lóde òní, a ní láti mọ̀ pé a nílò ẹbọ Kristi, èyí tó lágbára láti ṣètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Tí a bá lóye èyí, tí a sì mọrírì rẹ̀, Jèhófà á ní “inú dídùn” sí gbogbo ohun tá à ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀.—Ka Sáàmù 51:17, 19.

LO ÌGBÀGBỌ́ NÍNÚ ẸBỌ JÉSÙ!

17-19. (a) Báwo la ṣe lè fi han Jèhófà pé a mọrírì ẹbọ ìràpadà Jésù tó pèsè? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

17 A ní àǹfààní kan tí àwọn èèyàn tó gbé ayé kí ẹ̀sìn Kristẹni tó bẹ̀rẹ̀ kò ní, ìyẹn ni pé “òjìji” àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe ni wọ́n rí, àmọ́ àwa ní èyí tó jẹ́ ojúlówó. (Héb. 10:1) Àwọn òfin tó ní ín ṣe pẹ̀lú ẹbọ rírú ń jẹ́ kí àwọn Júù ní ìwà tó máa jẹ́ kí wọ́n lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run, kí wọ́n ní ìmọrírì àtọkànwá, kí wọ́n fẹ́ láti fún un ní ohun ìní wọn tó dára jù lọ, kí wọ́n sì gbà pé àwọn nílò ìdáǹdè. Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn àlàyé tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ló jẹ́ ká lóye pé nípasẹ̀ ìràpadà, Jèhófà máa mú ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ ti dá sílẹ̀ kúrò títí láé àti pé ní báyìí ó ń jẹ́ ká ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀. Ìpèsè àgbàyanu mà ni ẹbọ ìràpadà Jésù jẹ́ o!—Gál. 3:13; Héb. 9:9, 14.

18 Àmọ́ ṣá o, ká tó lè jàǹfààní nínú ẹbọ ìràpadà náà, ohun tá a nílò kọjá wíwulẹ̀ lóye ohun tó túmọ̀ sí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Òfin ti di akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa tí ń sinni lọ sọ́dọ̀ Kristi, kí a lè polongo wa ní olódodo nítorí ìgbàgbọ́.” (Gál. 3:24) Àmọ́, irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ kò lè wà láìsí àwọn iṣẹ́. (Ják. 2:26) Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi fún àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní tí wọ́n ní kókó ìmọ̀ tó wà nínú Òfin Mósè ní ìṣírí pé kí wọ́n lo ìmọ̀ tí wọ́n ní. Bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìwà wọn máa bá àwọn ìlànà Ọlọ́run tí wọ́n fi ń kọ́ àwọn mìíràn mu.—Ka Róòmù 2:21-23.

19 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run kò retí pé kí àwọn Kristẹni lóde òní máa pa Òfin Mósè mọ́, wọ́n ṣì gbọ́dọ̀ máa rú àwọn ẹbọ tí Jèhófà tẹ́wọ́ gbà. A máa jíròrò bá a ṣe lè ṣe é nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

WÁ ÌDÁHÙN SÍ ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

․․․․․

Kí ni àwọn ẹbọ tí Òfin Mósè là kalẹ̀ fún àwọn Júù ṣàpẹẹrẹ?

․․․․․

Kí ló mú kí àwọn kan lára àwọn ẹbọ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rú jọ ẹbọ tí àwọn Kristẹni ń rú lóde òní?

․․․․․

Kí ló lè mú kí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba ẹbọ kan tàbí kó máà tẹ́wọ́ gbà á?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí tó wà ní ojú ìwé 17]

Ìlànà tí Jèhófà fẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ máa tẹ̀ lé kì í yí pa dà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Irú ẹran wo ni ìwọ ì bá fi rúbọ sí Jèhófà?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Àwọn tó rú ẹbọ tó ṣètẹ́wọ́gbà sí Jèhófà máa ń rí ojúure rẹ̀