Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kọ́ Bó O Ṣe Lè Máa Ṣọ́nà Látinú Àpẹẹrẹ Àwọn Àpọ́sítélì Jésù

Kọ́ Bó O Ṣe Lè Máa Ṣọ́nà Látinú Àpẹẹrẹ Àwọn Àpọ́sítélì Jésù

Kọ́ Bó O Ṣe Lè Máa Ṣọ́nà Látinú Àpẹẹrẹ Àwọn Àpọ́sítélì Jésù

“Ẹ . . . máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà pẹ̀lú mi.”—MÁT. 26:38.

1-3. Àṣìṣe wo ni àwọn àpọ́sítélì ṣe lálẹ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé, kí ló sì fi hàn pé wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ látinú àṣìṣe wọn?

 FOJÚ inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé. Jésù ti wà ní ọ̀kan lára ibi tó fẹ́ràn láti máa lọ, ìyẹn ní ọgbà Gẹtisémánì, tó wà ní apá ìlà oòrùn ìlú Jerúsálẹ́mù. Òun àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ni wọ́n jọ lọ síbẹ̀. Ọ̀pọ̀ nǹkan tó ṣe pàtàkì ni Jésù ń rò lọ́kàn, torí náà ó nílò ibì kan tó ti lè dá wà kó bàa lè gbàdúrà.—Mát. 26:36; Jòh. 18:1, 2.

2 Mẹ́ta lára àwọn àpọ́sítélì, Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù, bá Jésù lọ sí àárín gbùngbùn ọgbà náà. Kó tó lọ gbàdúrà, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ dúró síhìn-ín, kí ẹ sì máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà pẹ̀lú mi.” Nígbà tó fi máa pa dà dé, wọ́n ti sùn lọ fọnfọn. Ó tún wá rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.” Síbẹ̀, ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló tún bá wọn lójú oorun! Lẹ́yìn náà, lálẹ́ ọjọ́ yẹn kan náà, gbogbo àwọn àpọ́sítélì kò bá Jésù ṣọ́nà. Kódà, wọ́n pa Jésù tì, wọ́n sì fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ!—Mát. 26:38, 41, 56.

3 Láìsí àní-àní, ó dun àwọn àpọ́sítélì pé wọn kò bá Jésù ṣọ́nà. Kò pẹ́ tí àwọn ọkùnrin olóòótọ́ yẹn fi kẹ́kọ̀ọ́ lára àṣìṣe tí wọ́n ṣe. Ìwé Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì fi hàn pé wọ́n ń bá a nìṣó láti máa sọ́nà, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ tó tayọ lélẹ̀. Àpẹẹrẹ tí wọ́n fi lélẹ̀ yìí ti ní láti ran àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni lọ́wọ́ káwọn náà lè máa ṣọ́nà. Ní àkókò yìí, ó ṣe pàtàkì ju ti ìgbàkígbà rí lọ pé ká máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà. (Mát. 24:42) Ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn ẹ̀kọ́ mẹ́ta tá a lè rí kọ́ látinú ìwé Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì nípa bá a ṣe lè máa ṣọ́nà.

WỌ́N KÍYÈ SÍ BÍ Ẹ̀MÍ MÍMỌ́ ṢE Ń DARÍ WỌN SÍ IBI TÍ WỌ́N TI MÁA WÀÁSÙ

4, 5. Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe darí Pọ́ọ̀lù àtàwọn tó bá a rìnrìn àjò?

4 Ohun àkọ́kọ́ tá a lè rí kọ́ ni pé àwọn àpọ́sítélì ń kíyè sí bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe ń darí wọn sí ibi tí wọ́n ti máa wàásù. Bíbélì sọ fún wa bí Jésù ṣe lo ẹ̀mí Ọlọ́run láti darí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àtàwọn tó bá a rìnrìn àjò kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀. (Ìṣe 2:33) Ẹ jẹ́ ká dara pọ̀ mọ́ wọn nínú ìrìn àjò náà.—Ka Ìṣe 16:6-10.

5 Pọ́ọ̀lù, Sílà àti Tímótì gbéra nílùú Lísírà ní gúúsù ìlú Gálátíà. Ní ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà, wọ́n dé òpópónà Róòmù kan tó já sí apá ìwọ̀ oòrùn ibi táwọn èèyàn pọ̀ sí jù lọ ní àgbègbè Éṣíà. Wọ́n fẹ́ láti gba ọ̀nà yẹn, kí wọ́n lè ṣèbẹ̀wò sáwọn ìlú tó ti yẹ kí ọ̀pọ̀ èèyàn gbọ́ nípa Kristi. Àmọ́, ohun kan ṣẹlẹ̀ tí kò jẹ́ kí wọ́n lè gba ọ̀nà náà. Ẹsẹ 6 sọ pé: “Wọ́n gba Fíríjíà àti ilẹ̀ Gálátíà kọjá, nítorí pé ẹ̀mí mímọ́ ka sísọ ọ̀rọ̀ náà ní àgbègbè Éṣíà léèwọ̀ fún wọn.” Àmọ́ lọ́nà kan tí Bíbélì kò ṣàlàyé, ẹ̀mí mímọ́ kò gba àwọn arìnrìn-àjò náà láyè láti lọ wàásù ní agbègbè Éṣíà. Ó ṣe kedere pé Jésù fẹ́ láti fi ẹ̀mí Ọlọ́run darí Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò lọ sí ibòmíràn.

6, 7. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù àti àwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò nítòsí Bítíníà? (b) Ìpinnu wo làwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣe, kí ló sì yọrí sí?

6 Ibo ni Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò lọ? Ẹsẹ 7 ṣàlàyé pé: “Síwájú sí i, nígbà tí wọ́n dé Máísíà, wọ́n sapá láti lọ sí Bítíníà, ṣùgbọ́n ẹ̀mí Jésù kò gbà wọ́n láyè.” Níwọ̀n bí ẹ̀mí kò ti jẹ́ kí Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò wàásù ní Éṣíà, wọ́n gba apá àríwá lọ, kí wọ́n lè lọ wàásù ní àwọn ìlú tó wà ní Bítíníà. Àmọ́, nígbà tí wọ́n sún mọ́ Bítíníà, Jésù tún lo ẹ̀mí mímọ́ láti dá wọn dúró. Níbi tọ́rọ̀ dé yìí, àwọn ọkùnrin náà ti ní láti máa ṣe kàyéfì. Wọ́n mọ ohun tí wọ́n máa wàásù àti wọ́n ṣe máa wàásù, àmọ́ wọn kò mọ ibi tí wọ́n ti máa wàásù. Èyí dà bíi ká sọ pé: “Wọ́n kọ́kọ́ kan ilẹ̀kùn tó wọ ilẹ̀ Éṣíà, àmọ́ ńṣe ló tì gbọn-in. Wọ́n tún kan ilẹ̀kùn tó wọ Bítíníà, ńṣe nìyẹn náà tì gbọn-in. Ṣé ìyẹn wá mú kí wọ́n ṣíwọ́ kíkan ilẹ̀kùn táá mú kí wọ́n láǹfààní láti wàásù? Wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀, torí pé wọ́n ní ìtara fún iṣẹ́ ìwàásù.

7 Ní báyìí, àwọn ọkùnrin náà ṣe ìpinnu kan tó dà bíi pé ó ṣàjèjì. Ẹsẹ 8 sọ fún wa pé: “Wọ́n ré Máísíà kọjá, wọ́n sì sọ̀ kalẹ̀ wá sí Tíróásì.” Ìyẹn fi hàn pé àwọn arìnrìn-àjò náà forí lé apá ìwọ̀ oòrùn, wọ́n sì rin ìrìn nǹkan bí ọ̀tàlélẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [560] kìlómítà láti ìlú kan dé òmíràn, títí tí wọ́n fi dé etíkun Tíróásì, ìyẹn ẹnubodè ìlú Makedóníà. Ìlú yìí ni ibì kẹta tí Pọ́ọ̀lù àti àwọn tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò ti gbìyànjú láti kan ilẹ̀kùn táá mú kí wọ́n láǹfààní láti wàásù, ẹ̀mí mímọ́ sì gbà wọ́n láyè láti wàásù níbẹ̀! Ẹsẹ 9 sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà. Ó ní: “Ní òru, ìran kan sì fara han Pọ́ọ̀lù: ọkùnrin kan ará Makedóníà dúró, ó ń pàrọwà fún un, ó sì wí pé: ‘Ré kọjá wá sí Makedóníà, kí o sì ràn wá lọ́wọ́.’” Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Pọ́ọ̀lù ti wá mọ ibi tó ti máa wàásù. Láìjáfara, àwọn ọkùnrin náà wọ ọkọ ojú omi lọ sí Makedóníà.

8, 9. Kí la lè rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù nígbà ìrìn àjò rẹ̀?

8 Kí la lè rí kọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn? Kíyè sí i pé lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù gbéra ìrìn àjò lọ sí Éṣíà ni ẹ̀mí Ọlọ́run tó darí rẹ̀. Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù sì ti dé ìtòsí Bítíníà ni Jésù tó fún un ní ìtọ́ni síwájú sí i. Sì tún kíyè sí i pé lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù dé Tíróásì ni Jésù tó darí rẹ̀ pé kó lọ sí Makedóníà. Jésù tó jẹ́ Orí ìjọ Ọlọ́run lè darí àwa náà lọ́nà tó fara jọ èyí. (Kól. 1:18) Bí àpẹẹrẹ, o lè ti máa ronú pé wàá fẹ́ láti sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà tàbí kó o lọ sí àgbègbè kan tí wọ́n ti nílò àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run púpọ̀ sí i. Àmọ́, ó lè jẹ́ pé lẹ́yìn tó o bá ti ṣe àwọn ohun tó máa mú kí ọwọ́ rẹ tẹ àfojúsùn rẹ ni Jésù máa tó fi ẹ̀mí Ọlọ́run darí rẹ. Wo àpèjúwe yìí ná: Kí awakọ̀ kan tó lè darí ọkọ̀ sọ́tùn-ún tàbí sósì, ọkọ̀ náà gbọ́dọ̀ wà lórí ìrìn. Bákan náà, Jésù lè fi ẹ̀mí Ọlọ́run darí wa láti mọ bí a ṣe lè mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gbòòrò sí i, àmọ́, ìyẹn á jẹ́ lẹ́yìn tá a bá ti sapá gidigidi kí ọwọ́ wa lè tẹ àfojúsùn náà.

9 Bó bá wá ṣẹlẹ̀ pé àwọn ìsapá rẹ kò tètè yọrí sí ibi tó o fẹ́ ńkọ́? Ṣó yẹ kó o máa rò pé ẹ̀mí Ọlọ́run kò darí rẹ kó o wá torí rẹ̀ rẹ̀wẹ̀sì? Rántí pé Pọ́ọ̀lù náà dojú kọ àwọn ohun tó lè mú kó rẹ̀wẹ̀sì. Síbẹ̀, ó ń bá a nìṣó láti máa sapá, títí tó fi láǹfààní láti wàásù. Bákan náà, bí o bá ń bá a nìṣó láti máa wá “ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò” ìwọ pẹ̀lú lè rí èrè púpọ̀ gbà.—1 Kọ́r. 16:9.

WỌ́N WÀ LÓJÚFÒ, WỌ́N SÌ JẸ́ KÍ ÀDÚRÀ JẸ ÀWỌN LỌ́KÀN

10. Kí ló fi hàn pé ká lè máa wà lójúfò, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àdúrà jẹ wá lọ́kàn?

10 Ní báyìí, ronú nípa ẹ̀kọ́ kejì tá a lè rí kọ́ nípa bá a ṣe lè máa ṣọ́nà látinú àpẹẹrẹ àwọn arákùnrin wa ní ọ̀rúndún kìíní: Wọ́n wà lójúfò, wọ́n sì jẹ́ kí àdúrà jẹ àwọn lọ́kàn. (1 Pét. 4:7) Ká lè máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa gbàdúrà. Rántí pé kí wọ́n tó wá mú Jésù nínú ọgbà Gẹtisémánì, ó sọ fún mẹ́ta nínú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo.”Mát. 26:41.

11, 12. Kí ló mú kí Hẹ́rọ́dù fi ara ni àwọn Kristẹni, tó fi mọ́ Pétérù, kí ló sì ṣe fún wọn?

11 Pétérù wà nínú ọgbà Gẹtisémánì nígbà tí Jésù sọ̀rọ̀ yìí. Lẹ́yìn ìgbà yẹn ni òun fúnra rẹ̀ wá rí bí àdúrà àtọkànwá ti ṣe pàtàkì tó. (Ka Ìṣe 12:1-6.) A rí i kà nínú àwọn ẹsẹ tó bẹ̀rẹ̀ Ìṣe orí 12 pé Hẹ́rọ́dù bẹ̀rẹ̀ sí í ni àwọn Kristẹni lára kó lè rí ojúure àwọn Júù. Ó ṣeé ṣe kó mọ̀ pé àpọ́sítélì ni Jákọ́bù àti pé ó sún mọ́ Jésù dáadáa. Torí náà, Hẹ́rọ́dù mú kí wọ́n “fi idà” pa Jákọ́bù. (Ẹsẹ 2) Bí ìjọ ṣe pàdánù àpọ́sítélì tó jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún wọn nìyẹn. Ìdánwò ńlá nìyẹn jẹ́ fún àwọn ará!

12 Kí wá ni Hẹ́rọ́dù ṣe lẹ́yìn náà? Ẹsẹ 3 ṣàlàyé pé: “Bí ó ti rí i pé ó dùn mọ́ àwọn Júù nínú, ó tẹ̀ síwájú láti fi àṣẹ ọba mú Pétérù pẹ̀lú.” Àmọ́, Ọlọ́run máa ń ṣe ọ̀nà àbáyọ fún àwọn àpọ́sítélì, tó fi mọ́ Pétérù, tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n nígbà kan. (Ìṣe 5:17-20) Ó sì ṣeé ṣe kí Hẹ́rọ́dù mọ̀ bẹ́ẹ̀. Lọ́tẹ̀ yìí, olóṣèlú tó gbọ́n féfé yìí kò fẹ́ kí Pétérù bọ́ mọ́ òun lọ́wọ́. Ó fi Pétérù sí ìkáwọ́ “ọ̀wọ́ mẹ́rin àwọn oníṣẹ́ àṣegbà tí ọ̀wọ́ kọ̀ọ̀kan ní ọmọ ogun mẹ́rin-mẹ́rin nínú láti máa ṣọ́ ọ, níwọ̀n bí ó ti pète-pèrò láti mú un jáde fún àwọn ènìyàn náà lẹ́yìn ìrékọjá.” (Ẹsẹ 4) Ìyẹn mà ga o! Hẹ́rọ́dù ní kí wọ́n kó ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ sí Pétérù lọ́wọ́, kó sì wà láàárín ẹ̀ṣọ́ méjì. Àpapọ̀ àwọn ẹ̀ṣọ́ mẹ́rìndínlógún [16] tó ń ṣọ́ ọ ń ṣe iṣẹ́ àṣegbà tọ̀sán tòru kí àpọ́sítélì náà má bàa lọ mọ́ wọn lọ́wọ́. Ohun tí Hẹ́rọ́dù ń pète-pèrò láti ṣe ni pé kó mú Pétérù wá síwájú àwọn èèyàn lẹ́yìn Ìrékọjá, kó lè fi pípa tí wọ́n máa pa á dá wọn lára yá. Nínú ipò tó nira yìí, kí làwọn Kristẹni yòókù lè ṣe?

13, 14. (a) Kí ni ìjọ ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ pé wọ́n ti fi Pétérù sẹ́wọ̀n? (b) Kí la lè rí kọ́ nínú àdúrà tí àwọn Kristẹni yòókù gbà nítorí Pétérù?

13 Ìjọ mọ ohun náà gan-an tó yẹ kí wọ́n ṣe. Ẹsẹ 5 sọ pé: “Nítorí náà, Pétérù ni a pa mọ́ sínú ẹ̀wọ̀n; ṣùgbọ́n ìjọ ń gbàdúrà lọ́nà gbígbónájanjan sí Ọlọ́run nítorí rẹ̀.” Dájúdájú, àdúrà gbígbónájanjan, tó ti ọkàn wá ni wọ́n gbà nítorí arákùnrin wọn olùfẹ́ ọ̀wọ́n yìí. Torí náà, wọn kò jẹ́ kí ikú Jákọ́bù mú àwọn rẹ̀wẹ̀sì tàbí kí wọ́n rò pé àdúrà àwọn kò já mọ́ nǹkan kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n mọ̀ pé ojú tó ṣe pàtàkì ni Jèhófà fi máa ń wo àdúrà àwọn tó ń fòótọ́ sìn ín. Ó sì máa ń dáhùn irú àwọn àdúrà bẹ́ẹ̀, bí wọ́n bá gbà á ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀.—Héb. 13:18, 19; Ják. 5:16.

14 Kí la lè rí kọ́ nínú àdúrà tí àwọn Kristẹni yòókù gbà nítorí Pétérù? Tá a bá fẹ́ máa bá a nìṣó láti ṣọ́nà, kì í ṣe ara wa nìkan ló yẹ ká máa gbàdúrà fún, a tún gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà fún àwọn ará wa pẹ̀lú. (Éfé. 6:18) Ǹjẹ́ o mọ àwọn ará tí wọ́n ń fara da ọ̀pọ̀ ìṣòro? Ó lè jẹ́ inúnibíni, fífi òfin de iṣẹ́ ìwàásù tàbí ìjábá ni àwọn kan ń fara dà. Ǹjẹ́ o lè máa rántí wọn nínú àdúrà àtọkànwá rẹ? O lè mọ àwọn kan tí wọ́n ń fara da àwọn ìṣòro tí kò fi bẹ́ẹ̀ hàn sí àwọn ẹlòmíì. Wọ́n lè máa sapá láti borí àwọn ìṣòro ìdílé, ìrẹ̀wẹ̀sì, tàbí àìlera. Tó o bá ń bá Jèhófà tó jẹ́ “Olùgbọ́ àdúrà” sọ̀rọ̀, ǹjẹ́ o lè ronú nípa àwọn èèyàn pàtó kan, kó o sì dárúkọ wọn nínú àdúrà rẹ?—Sm. 65:2.

15, 16. (a) Ṣàlàyé bí áńgẹ́lì Jèhófà ṣe ṣe ọ̀nà àbájáde fún Pétérù nígbà tó wà lẹ́wọ̀n. (Wo àwòrán tó wà nísàlẹ̀.) (b) Kí nìdí tí ọ̀nà tí Jèhófà gbà dá Pétérù nídè fi jẹ́ ìtùnú fún wa?

15 Àmọ́, kí ló ṣẹlẹ̀ sí Pétérù? Ní alẹ́ ọjọ́ tó lò kẹ́yìn lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ọ̀pọ̀ ohun àgbàyanu ló ṣẹlẹ̀ sí i. (Ka Ìṣe 12:7-11.) Díẹ̀ rèé lára ohun tó ṣẹlẹ̀: Pétérù sùn lọ fọnfọn láàárín àwọn ẹ̀ṣọ́ méjì tó ń ṣọ́ ọ, nígbà tí ìmọ́lẹ̀ ńlá kan ṣàdédé mọ́lẹ̀ yòò nínú ẹ̀wọ̀n tó wà. Áńgẹ́lì kan ló wà níbẹ̀, ó sì dájú pé àwọn ẹ̀ṣọ́ náà kò rí i. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó jí Pétérù lójú oorun. Àwọn ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ tí wọ́n kó sí i lọ́wọ́ já bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ̀! Lẹ́yìn náà, áńgẹ́lì náà ní kó tẹ̀ lé òun jáde kúrò nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà. Wọ́n gba àárín àwọn ẹ̀ṣọ́ tó wà níta lọ síbi ilẹ̀kùn gìrìwò tí wọ́n fi irin ṣe. Ilẹ̀kùn náà sì ṣí “fúnra rẹ̀.” Gbàrà tí wọ́n jáde síta, áńgẹ́lì náà pòórá. Pétérù dòmìnira!

16 Tá a bá ronú lórí agbára tí Jèhófà ní láti dá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nídè, ǹjẹ́ kì í fún ìgbàgbọ́ wa lókun? Òótọ́ ni pé lóde òní, a kì í retí pé kí Jèhófà dá wa nídè lọ́nà ìyanu bó ṣe ṣe fún Pétérù. Àmọ́, ó dá àwa náà lójú hán-únhán-ún pé Ọlọ́run máa ń lo agbára rẹ̀ nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. (2 Kíró. 16:9) Ó lè lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tó lágbára láti mú ká lè kojú àdánwò èyíkéyìí tó bá dé bá wa. (2 Kọ́r. 4:7; 2 Pét. 2:9) Jèhófà sì máa tó fún Ọmọ rẹ̀ lágbára láti dá àìmọye èèyàn nídè kúrò lọ́wọ́ ikú, tó dà bí ọgbà ẹ̀wọ̀n tí kì í sọ pé ẹlẹ́wọ̀n tó. (Jòh. 5:28, 29) Ìgbàgbọ́ tá a ní nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run lè mú ká ní ìgboyà tó pọ̀ tá a bá dojú kọ ìṣòro.

WỌ́N JẸ́RÌÍ KÚNNÁKÚNNÁ LÁÌKA ÀTAKÒ SÍ

17. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi àpẹẹrẹ tó tayọ̀ lélẹ̀ ní ti fífi ìtara wàásù àti lọ́nà tó fi hàn pé iṣẹ́ náà jẹ́ kánjúkánjú?

17 Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀kọ́ kẹta tá a rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ àwọn àpọ́sítélì nípa bá a ṣe lè máa ṣọ́nà: Wọ́n ń bá a nìṣó láti máa jẹ́rìí kúnnákúnná láìka àtakò sí. Ká lè máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa fi ìtara wàásù, ká sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó fi hàn pé iṣẹ́ náà jẹ́ kánjúkánjú. Tó bá di pé ká fi ìtara wàásù, àpẹẹrẹ títayọ ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́. Ó fi ìtara ṣe iṣẹ́ náà, ó rìnrìn àjò lọ sí àwọn ibi tó jìnnà ó sì dá ọ̀pọ̀ ìjọ sílẹ̀. Ó fara da ọ̀pọ̀ ìnira, síbẹ̀ ó ń bá a nìṣó láti máa fi ìtara wàásù, ó sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó fi hàn pé iṣẹ́ náà jẹ́ kánjúkánjú.—2 Kọ́r. 11:23-29.

18. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe ń bá a nìṣó láti máa jẹ́rìí nígbà tó wà ní àhámọ́ ní ìlú Róòmù?

18 Ronú nípa ìgbà tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa Pọ́ọ̀lù kẹ́yìn nínú ìwé Ìṣe, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Ìṣe orí 28. Pọ́ọ̀lù ti dé sí Róòmù kó lè wá jẹ́jọ́ níwájú Nérò. Wọ́n fi í sí àhámọ́, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ de ọwọ́ rẹ̀ mọ́ ti ẹ̀ṣọ́ tó ń ṣọ́ ọ. Síbẹ̀, ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ náà kò dí àpọ́sítélì náà lọ́wọ́ láti máa fi ìtara wàásù! Pọ́ọ̀lù ń bá a nìṣó láti máa wá ọ̀nà tó lè gbà jẹ́rìí fáwọn èèyàn. (Ka Ìṣe 28:17, 23, 24.) Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti fi ọjọ́ mẹ́ta sinmi lẹ́yìn ìrìn-àjò rẹ̀ wá sí ìlú Róòmù, ó pe àwọn sàràkí-sàràkí jọ lára àwọn Júù kó lè jẹ́rìí fún wọn. Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣètò ọjọ́ kan, ó sì túbọ̀ jẹ́rìí fún wọn. Ẹsẹ 23 sọ pé: “Wọ́n [àwọn Júù tó wà ládùúgbò náà] ṣètò ọjọ́ kan pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní iye púpọ̀ ní ibùwọ̀ rẹ̀. Ó sì ṣàlàyé ọ̀ràn náà fún wọn nípa jíjẹ́rìí kúnnákúnná nípa ìjọba Ọlọ́run àti nípa lílo ìyíniléròpadà pẹ̀lú wọn nípa Jésù láti inú òfin Mósè àti àwọn Wòlíì, láti òwúrọ̀ títí di ìrọ̀lẹ́.”

19, 20. (a) Kí ló mú káwọn kan gbọ́ ìwàásù Pọ́ọ̀lù? (b) Kí ni Pọ́ọ̀lù ṣe nígbà tó rí i pé gbogbo àwọn tí òun wàásù fún kọ́ ló gba ìhìn rere náà?

19 Kí ló mú káwọn kan gbọ́ ìwàásù Pọ́ọ̀lù? Kíyè sí i pé ẹsẹ 23 sọ àwọn ìdí mélòó kan. (1) Ìwàásù rẹ̀ dá lórí Ìjọba Ọlọ́run àti Jésù Kristi. (2) Ó gbìyànjú láti mú kí ìwàásù rẹ̀ wọ àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ lọ́kàn “nípa lílo ìyíniléròpadà.” (3) Ó bá wọn fèrò wérò látinú Ìwé Mímọ́. (4) Ó fi hàn pé òun ṣe tán láti yááfì ohunkóhun nípa wíwàásù “láti òwúrọ̀ títí di ìrọ̀lẹ́.” Pọ́ọ̀lù jẹ́rìí lọ́nà tó wọ àwọn èèyàn náà lọ́kàn, àmọ́ gbogbo wọn kọ́ ló gba ohun tó sọ gbọ́. Ẹsẹ 24 sọ pé: “Àwọn kan . . . gba àwọn ohun tí ó sọ gbọ́; àwọn mìíràn kò sì gbà gbọ́.” Àwọn èèyàn náà yapa síra wọn, wọ́n sì jáde lọ.

20 Ṣé ọkàn Pọ́ọ̀lù bà jẹ́ torí pé kì í ṣe gbogbo àwọn tó wàásù fún ló gba ìhìn rere náà? Ó tì o! Ìṣe 28:30, 31 sọ fún wa pé: “Ó dúró fún ọdún méjì gbáko nínú ilé tí òun fúnra rẹ̀ háyà, òun a sì fi inú rere gba gbogbo àwọn tí wọ́n wọlé wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ní wíwàásù ìjọba Ọlọ́run fún wọn àti kíkọ́ni ní àwọn nǹkan nípa Jésù Kristi Olúwa pẹ̀lú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ńláǹlà, láìsí ìdílọ́wọ́.” Ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró yìí ló parí ìwé Ìṣe.

21. Kí la lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù nígbà tí wọ́n fi òfin dè é pé kò gbọ́dọ̀ jáde nílé?

21 Kí la lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù? Nígbà tí wọ́n fi òfin dè é pé kò gbọ́dọ̀ jáde nílé, kò ṣeé ṣe fún un láti máa wàásù láti ilé dé ilé. Síbẹ̀, kò rẹ̀wẹ̀sì, ó ń bá a nìṣó láti máa wàásù fún gbogbo àwọn tó bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Bákan náà, lónìí, ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn Ọlọ́run ń láyọ̀, wọ́n sì ń bá a nìṣó láti máa wàásù bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fi wọ́n sẹ́wọ̀n láìtọ́, nítorí ìgbàgbọ́ wọn. A rí lára àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ọ̀wọ́n tí wọn ò lè jáde nílé mọ́ tàbí tí wọ́n tiẹ̀ ń gbé láwọn ilé tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn àgbàlagbà torí pé wọ́n ti darúgbó tàbí torí pé wọ́n ń ṣàìsàn. Síbẹ̀, wọ́n máa ń wàásù fún àwọn dókítà, àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn àti àwọn míì tó bá wá sọ́dọ̀ wọn, bí agbára wọ́n bá ṣe mọ. Ohun tó wà lọ́kàn wọn ni bí wọ́n á ṣe máa jẹ́rìí kúnnákúnná nípa Ìjọba Ọlọ́run. A mà mọrírì àpẹẹrẹ wọn o!

22. (a) Ìwé wo ló ń mú ká túbọ̀ lóye ohun tó wà nínú Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì? (Wo àpótí tó wà lókè.) (b) Kí lo pinnu láti ṣe bó o ṣe ń dúró de òpin ètò àwọn nǹkan ògbólógbòó yìí?

22 Ìwé Ìṣe sọ̀rọ̀ nípa àwọn àpọ́sítélì àtàwọn Kristẹni mìíràn ní ọ̀rúndún kìíní. Láìsí àní-àní, ọ̀pọ̀ nǹkan la lè rí kọ́ nípa bá a ṣe lè máa ṣọ́nà látinú àpẹẹrẹ wọn. Bá a ṣe ń dúró de òpin ètò àwọn nǹkan ògbólógbòó yìí, ẹ jẹ́ ká pinnu láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní wọ̀nyẹn nípa fífi ìgboyà àti ìtara jẹ́rìí. Kò sí àǹfààní tá a lè ní nísinsìnyí tó kọjá “jíjẹ́rìí kúnnákúnná” nípa ìjọba Ọlọ́run!—Ìṣe 28:23.

KÍ LO LÈ RÍ KỌ́ NÍPA:

․․․․․

Bí wọ́n ṣe kíyè sí bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe ń darí wọn sí ibi tí wọ́n ti máa wàásù?

․․․․․

Bí wọ́n ṣe wà lójúfò, tí wọ́n sì jẹ́ kí àdúrà jẹ àwọn lọ́kàn?

․․․․․

Bí wọ́n ṣe jẹ́rìí kúnnákúnná láìka àtakò sí?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 13]

“ÌWÉ ÌṢE TI WÁ YÉ MÍ KEDERE BÁYÌÍ”

Lẹ́yìn tí alábòójútó arìnrìn-àjò kan ti ka ìwé “Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná” Nípa Ìjọba Ọlọ́run, ó sọ bó ṣe gbádùn ìwé náà tó. Ó ní: “Ìwé Ìṣe ti wá yé mi kedere báyìí. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà tí mo ti ka ìwé Ìṣe, ṣe ni mo dà bí ẹni tó ń tan àbẹ́là rìn nínú òkùnkùn tó sì fi ìgò tó dọ̀tí sójú. Àmọ́ ní báyìí, ṣe ni mò ń ṣọpẹ́ pé ohun tó wà nínú ìwé náà ti túbọ̀ ṣe kedere sí mi bí ìgbà téèyàn ń rìn nínú ìmọ́lẹ̀ oòrùn tó ń tàn yanran.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Áńgẹ́lì kan darí Pétérù gba ẹnu ilẹ̀kùn gìrìwò tí wọ́n fi irin ṣe kọjá