Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìlara Lè Mú Kéèyàn Ní Èròkerò

Ìlara Lè Mú Kéèyàn Ní Èròkerò

Ìlara Lè Mú Kéèyàn Ní Èròkerò

Ọ̀gágun Napoleon Bonaparte ní in. Olú Ọba Julius Caesar ní in. Alẹkisáńdà Ńlá náà ní in. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ní agbára àti ògo, síbẹ̀ ìlara mú kí wọ́n ní èròkerò. Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ṣe ìlara ẹlòmíì.

Onímọ̀ ọgbọ́n orí tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Bertrand Russell, sọ pé: “Napoleon ṣe ìlara Caesar, Caesar ṣe ìlara Alẹkisáńdà [Ńlá], kò sì sí àní-àní pé Alẹkisáńdà ṣe ìlara Hercules, tí kò tilẹ̀ gbé ayé rí.” Kò sẹ́ni tí kò lè ṣe ìlara, láìka bí ọrọ̀ rẹ̀ ṣe pọ̀ tó sí, bó ṣe ní ìwà rere tó àti bó ṣe ṣàṣeyọrí tó.

Ìlara ni kéèyàn máa di àwọn míì sínú torí ohun ìní wọn, àṣeyọrí wọn, àwọn àǹfààní tí wọ́n ní àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ìwé kan tó ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì, èyí tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀, sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìlara àti owú. Ó ní: “‘Owú‘ . . . túmọ̀ sí kéèyàn fẹ́ láti dà bí ẹlòmíì, nígbà tí ọ̀rọ̀ náà ‘ìlara’ túmọ̀ sí kéèyàn fẹ́ kí ohun tó jẹ́ ti ẹlòmíì di tẹni.” Kì í wulẹ̀ ṣe pé ojú onílara ń wọ ohun táwọn míì ní nìkan ni, àmọ́ ó máa ń fẹ́ láti gbà á lọ́wọ́ wọn.

Ó bọ́gbọ́n mu pé ká mọ ohun tó lè sọ wá di onílara àti àwọn ohun tó lè jẹ́ àbájáde rẹ̀. Ó tún ṣe pàtàkì pé ká mọ àwọn ohun tá a lè ṣe tá ò fi ní jẹ́ kí ìlara máa darí ìgbésí ayé wa.

OHUN TÓ LÈ SỌ ÈÈYÀN DI ONÍLARA

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa èèyàn aláìpé ní “ìtẹ̀sí láti ṣe ìlara,” onírúurú nǹkan ló lè mú kí ìtẹ̀sí yìí túbọ̀ lágbára gan-an nínú èèyàn. (Ják. 4:5) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ọ̀kan nínú wọn nígbà tó kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a di olùgbéra-ẹni-lárugẹ, ní ríru ìdíje sókè pẹ̀lú ara wa lẹ́nì kìíní-kejì, ní ṣíṣe ìlara ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.” (Gál. 5:26) Àìpé máa ń mú ká fẹ́ láti ṣe ìlara àwọn ẹlòmíì. Bíbá àwọn ẹlòmíì díje sì lè mú kí ìlara náà túbọ̀ pọ̀ sí i. Àwọn Kristẹni méjì tí wọ́n ń jẹ́ Cristina àti José * rí i pé bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn.

Cristina, tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé, sọ pé: “Mo sábà máa ń ṣe ìlara àwọn ẹlòmíì. Mo máa ń fi ohun tí wọ́n ní wé ohun tí èmi kò ní.” Nígbà kan, Cristina ń jẹun pẹ̀lú alábòójútó arìnrìn-àjò kan àti ìyàwó rẹ̀. Nígbà tí Cristina kíyè sí i pé díẹ̀ ni ọjọ́ orí tòun, ti Eric ọkọ òun, ti alábòójútó arìnrìn-àjò náà àti ti ìyàwó rẹ̀ fi yàtọ̀ síra àti pé wọ́n ti jọ ní irú àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan náà rí nígbà kan, ó sọ pé: “Alàgbà ni ọkọ tèmi náà! Kí ló wá fà á tẹ́ ẹ fi wà nínú iṣẹ́ ìsìn arìnrìn-àjò táwa ò sì jẹ́ nǹkan kan?” Bó ṣe wù ú pé kó jẹ́ òun lòun wà nípò táwọn tọkọtaya náà wà mú kó máa ṣe ìlara wọn. Ìyẹn mú kó gbàgbé iṣẹ́ rere tí òun àti ọkọ rẹ̀ ń ṣe, ohun tí wọ́n ń fi ìgbésí ayé wọn ṣe kò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn.

Ó wu José pé kó jẹ́ ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ. Àmọ́, nígbà tí àwọn míì di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí òun kò sì ní àǹfààní rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìlara wọn ó sì di olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà sínú. José jẹ́wọ́ pé: “Ìlara mú kí n kórìíra arákùnrin yìí mo sì máa ń gba ohun tó bá ṣe sódì. Bí ẹnì kan bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìlara, tara rẹ̀ nìkan ni yóò máa rò, kò sì ní lè ronú bó ṣe tọ́ mọ́.”

OHUN TÍ ÀWỌN ÀPẸẸRẸ INÚ BÍBÉLÌ KỌ́ WA

Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ ló wà nínú Bíbélì tá a lè fi ṣe àríkọ́gbọ́n. (1 Kọ́r. 10:11) Díẹ̀ lára àwọn àpẹẹrẹ náà jẹ́ ká mọ bí ìlara ṣe máa ń bẹ̀rẹ̀, wọ́n sì tún jẹ́ ká mọ bó ṣe máa ń mú kí àwọn tó bá fàyè gbà á láti borí wọn ní èròkerò.

Bí àpẹẹrẹ, Kéènì tó jẹ́ àkọ́bí Ádámù àti Éfà bínú nígbà tí Jèhófà gba ẹbọ Ébẹ́lì ṣùgbọ́n tí kò gba tirẹ̀. Kéènì ì bá ti yàn láti ṣe ohun tó tọ́, àmọ́ ńṣe ló jẹ́ kí ìlara ru bo òun lójú débi tó fi pa àbúrò rẹ̀. (Jẹ́n. 4:4-8) Abájọ tí Bíbélì fi sọ nípa Kéènì pé “ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ẹni burúkú náà,” Sátánì!—1 Jòh. 3:12.

Àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù mẹ́wẹ̀ẹ̀wá ṣe ìlara rẹ̀ torí pé bàbá wọn fẹ́ràn rẹ̀ gan-an. Wọ́n wá túbọ̀ kórìíra Jósẹ́fù nígbà tó rọ́ àwọn àlá tó lá nípa ọjọ́ iwájú fún wọn. Kódà, wọ́n fẹ́ láti pa á. Níkẹyìn, wọ́n tà á sóko ẹrú, wọ́n sì hùwà ìkà nípa mímú kí bàbá wọn gbà gbọ́ pé Jósẹ́fù ti kú. (Jẹ́n. 37:4-11, 23-28, 31-33) Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, wọ́n gbà pé àwọn ti dẹ́ṣẹ̀, wọ́n sì sọ fún ara wọn pé: “Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, a jẹ̀bi nípa arákùnrin wa, nítorí pé a rí wàhálà ọkàn rẹ̀ nígbà tí ó fi taratara bẹ̀bẹ̀ fún ìyọ́nú lọ́dọ̀ wa, ṣùgbọ́n àwa kò fetí sílẹ̀.”—Jẹ́n. 42:21; 50:15-19.

Ohun tó fà á tí Kórà, Dátánì àti Ábírámù fi ṣe ìlara ni pé wọ́n fi àǹfààní tí wọ́n ní wé ti Mósè àti Áárónì. Wọ́n fẹ̀sùn kan Mósè pé ó ń “ṣe bí ọmọ aládé” ó sì ń gbé ara rẹ̀ ga ju àwọn yòókù lọ. (Núm. 16:13) Irọ́ ni wọ́n fi èyí pa. (Núm. 11:14, 15) Jèhófà fúnra rẹ̀ ló yan Mósè. Àmọ́, àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà ṣe ìlara Mósè nítorí ipò tó wà. Níkẹyìn, ìlara wọn mú kí Jèhófà pa wọ́n run.—Sm. 106:16, 17.

Sólómọ́nì Ọba rí ohun tí ìlara lè sún èèyàn ṣe. Obìnrin kan tí ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí ti kú gbìyànjú láti tan ẹni tí wọ́n jọ bímọ sígbà kan náà kí ìyẹn lè rò pé ọmọ tòun ló kú. Nígbà tí wọ́n gbé ẹjọ́ náà dé iwájú Sólómọ́nì, obìnrin òpùrọ́ náà tiẹ̀ gbà pé kí ọba pa ọmọ tó wà láàyè náà. Àmọ́, Sólómọ́nì rí sí i pé ìyá ọmọ náà gan-an ni wọ́n gbé e fún.—1 Ọba 3:16-27.

Ìgbẹ̀yìn ìlara kì í dára. Àwọn àpẹẹrẹ inú Ìwé Mímọ́ tá a ti gbé yẹ̀ wò yìí fi hàn pé ìlara lè yọrí sí ìkórìíra, ìṣègbè àti mímọ̀ọ́mọ̀ pànìyàn. Síwájú sí i, kò sí èyíkéyìí nínú àwọn tá a ti jíròrò pé wọ́n ṣe ìlara sí tó ṣe ohunkóhun tó fi yẹ kí wọ́n ṣe ìlara wọn. Ǹjẹ́ ohunkóhun wà tá a lè ṣe tí ìlara kò fi ní máa darí ìgbésí ayé wa? Àwọn nǹkan wo la lè ṣe tí a kò fi ní jẹ́ onílara?

ÀWỌN Ọ̀NÀ TÁ A LÈ GBÀ BORÍ ÌLARA!

Ẹ ní ìfẹ́ àti ìfẹ́ni ará. Àpọ́sítélì Pétérù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé: “Nísinsìnyí tí ẹ ti wẹ ọkàn yín mọ́ gaara nípa ìgbọràn yín sí òtítọ́ pẹ̀lú ìfẹ́ni ará tí kò ní àgàbàgebè gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì lọ́nà gbígbóná janjan láti inú ọkàn-àyà wá.” (1 Pét. 1:22) Kí ni ìfẹ́ yìí túmọ̀ sí? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere. Ìfẹ́ kì í jowú, kì í fọ́nnu, kì í wú fùkẹ̀, kì í hùwà lọ́nà tí kò bójú mu, kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan.” (1 Kọ́r. 13:4, 5) Tá a bá ní ìfẹ́ yìí sí àwọn èèyàn, ǹjẹ́ kò ní sún wa láti paná ìtẹ̀sí búburú tó lè mú ká máa ṣe ìlara? (1 Pét. 2:1) Dípò kí Jónátánì máa ṣe ìlara Dáfídì, ó “nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkàn òun tìkára rẹ̀.”—1 Sám. 18:1.

Máa bá àwọn èèyàn Ọlọ́run kẹ́gbẹ́ pọ̀. Ẹni tó kọ Sáàmù kẹtàléláàádọ́rin [73] ṣe ìlara àwọn èèyàn búburú tí wọ́n ń gbé ìgbé ayé yọ̀tọ̀mì, láìní ìṣòro. Àmọ́, ó ṣẹ́pá ìlara náà nípa lílọ sínú “ibùjọsìn títóbi lọ́lá ti Ọlọ́run.” (Sm. 73:3-5, 17) Bí ẹni tó kọ Sáàmù yìí ṣe bá àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run kẹ́gbẹ́ pọ̀ jẹ́ kó mọyì àwọn ìbùkún tó rí látinú bó ṣe ‘sún mọ́ Ọlọ́run.’ (Sm. 73:28) Tá a bá ń pé jọ déédéé pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ láwọn ìpàdé ìjọ, àwa náà lè túbọ̀ mọyì àwọn ìbùkún tá à ń rí.

Máa ṣe rere. Lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti rí i pé Kéènì ti ń ṣe ìlara àbúrò rẹ̀ tó sì kórìíra rẹ̀, ó sọ fún un pé: “Yíjú sí ṣíṣe rere.” (Jẹ́n. 4:7) Kí ló túmọ̀ sí fún àwọn Kristẹni láti máa ‘ṣe rere’? Jésù sọ pé a ‘gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run wa pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà wa àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú wa. Ká sì nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa gẹ́gẹ́ bí ara wa.’ (Mát. 22:37-39) Tó bá jẹ́ pé ohun tó jẹ wá lógún jù lọ nígbèésí ayé wa ni pé ká máa sin Jèhófà ká sì máa ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́, èyí á mú ká ní ìtẹ́lọ́rùn. Ìtẹ́lọ́rùn tá a ní yìí kò ní jẹ́ ká máa fẹ́ láti ṣe ìlara wọn. Ọ̀nà kan tó dára tá a lè gbà sin Ọlọ́run, ká sì máa ṣe ohun tó dára fún àwọn aládùúgbò wa ni pé ká máa kó ipa tó jọjú nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, èyí á sì mú ká rí “ìbùkún Jèhófà.”—Òwe 10:22.

“Ẹ máa yọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń yọ̀.” (Róòmù 12:15) Jésù bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ yọ̀ torí pé wọ́n ṣe àṣeyọrí, ó sì ṣàlàyé pé wọ́n máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù tó pọ̀ ju ti òun lọ. (Lúùkù 10:17, 21; Jòh. 14:12) Gbogbo àwa èèyàn Jèhófà la wà ní ìṣọ̀kan; torí náà, bí ẹnikẹ́ni nínú wa bá ṣe àṣeyọrí, gbogbo wa la máa ń jàǹfààní látinú àṣeyọrí tó ṣe. (1 Kọ́r. 12:25, 26) Torí náà, ṣé kò wá yẹ ká máa yọ̀ nígbà táwọn míì bá ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó ju tiwa lọ, dípò tá a ó fi máa ṣe ìlara wọn?

KÒ RỌRÙN!

Ó lè pẹ́ kéèyàn tó ṣẹ́pá ṣíṣe ìlara. Cristina sọ pé: “Ó ṣì máa ń ṣe mí gan-an bíi pé kí n ṣe ìlara àwọn ẹlòmíì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò wù mí láti máa ṣe ìlara, ó ṣì máa ń wá sí mi lọ́kàn, torí náà ńṣe ni mo máa ń yára gbé ọkàn kúrò níbẹ̀.” Bákan náà ni ọ̀rọ̀ rí pẹ̀lú José. Ó sọ pé: “Jèhófà ti ràn mí lọ́wọ́ kí n lè mọrírì àwọn ànímọ́ rere tí olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà náà ní. Àjọṣe tó dára tí mo ní pẹ̀lú Ọlọ́run sì ti ṣe mí láǹfààní gan-an.”

Ọ̀kan lára “àwọn iṣẹ́ ti ara” ni ìlara jẹ́. Ó sì yẹ kí gbogbo Kristẹni sapá láti borí rẹ̀. (Gál. 5:19-21) Bí a kò bá fàyè gba ìlara láti máa darí wa, a óò túbọ̀ máa láyọ̀, a ó sì máa ṣe ohun tí yóò máa mú inú Jèhófà tó jẹ́ Baba wa ọ̀run dùn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ A ti yí àwọn orúkọ náà pa dà.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí tó wà ní ojú ìwé 17]

“Ẹ máa yọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń yọ̀”