Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Jẹ́ Kí Ẹ̀mí Rere Gbilẹ̀ Nínú Ìjọ

Ẹ Jẹ́ Kí Ẹ̀mí Rere Gbilẹ̀ Nínú Ìjọ

Ẹ Jẹ́ Kí Ẹ̀mí Rere Gbilẹ̀ Nínú Ìjọ

“Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jésù Kristi Olúwa wà pẹ̀lú ẹ̀mí tí ẹ fi hàn.”—FÍLÍ. 4:23.

BÁWO LA ṢE LÈ MÚ KÍ Ẹ̀MÍ RERE GBILẸ̀ NÍNÚ ÌJỌ . . .

․․․․․

tá a bá wà ní ìpàdé?

․․․․․

tá a bá ń fi ìtara wàásù?

․․․․․

tá a bá sọ fún àwọn alàgbà pé ẹnì kan hùwà àìtọ́ tó burú jáì?

1. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù àti Jésù Kristi fi sọ̀rọ̀ rere nípa àwọn ìjọ tó wà ní ìlú Fílípì àti Tíátírà?

 ÀWỌN Kristẹni tó wà ní ìlú Fílípì ní ọ̀rúndún kìíní jẹ́ aláìní nípa tara. Àmọ́, wọ́n jẹ́ ọ̀làwọ́, wọ́n sì fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fáwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ nípa fífi ìfẹ́ hàn. (Fílí. 1:3-5, 9; 4:15, 16) Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi sọ fún wọn ní ìparí lẹ́tà tí Ọlọ́run mí sí i láti kọ sí wọn, pé: “Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jésù Kristi Olúwa wà pẹ̀lú ẹ̀mí tí ẹ fi hàn.” (Fílí. 4:23) Torí pé àwọn Kristẹni tó wà ní ìlú Tíátírà náà fi irú ẹ̀mí yìí hàn, Jésù Kristi tí Ọlọ́run ti ṣe lógo sọ fún wọn pé: “Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ, àti ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti ìfaradà rẹ, àti pé àwọn iṣẹ́ rẹ ti lọ́ọ́lọ́ọ́ pọ̀ ju àwọn ti ìṣáájú.”—Ìṣí. 2:19.

2. Báwo ni ìwà wa ṣe ń nípa lórí irú ẹ̀mí tí ìjọ wa ń fi hàn?

2 Lóde òní, ó ní irú ẹ̀mí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà ń fi hàn tàbí irú ìwà kan tó gbilẹ̀ níbẹ̀. Àwọn ìjọ kan wà tí àwọn ará tó wà níbẹ̀ jẹ́ ọlọ́yàyà tí wọ́n sì máa ń fìfẹ́ hàn. Àwọn míì máa ń fi ìtara kọ́wọ́ ti iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n sì fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Bí olúkúlùkù wa bá ní ẹ̀mí rere, a óò pa kún ìṣọ̀kan ìjọ a ó sì mú kó máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. (1 Kọ́r. 1:10) Àmọ́, tá a bá ní ẹ̀mí búburú, èyí lè ba ipò tẹ̀mí ìjọ jẹ́, kí ìtara fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run jó rẹ̀yìn, kí ìwà àìtọ́ sì máa gbilẹ̀ nínú ìjọ. (1 Kọ́r. 5:1; Ìṣí. 3:15, 16) Irú ẹ̀mí wo ló gbilẹ̀ nínú ìjọ tiyín? Báwo ni ìwọ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan ṣe lè mú kí ẹ̀mí rere gbilẹ̀ nínú ìjọ?

Ẹ MÚ KÍ Ẹ̀MÍ RERE GBILẸ̀

3, 4. Báwo la ṣe lè máa ‘gbé Jèhófà lárugẹ nínú ìjọ ńlá’?

3 Nígbà tí onísáàmù ń kọrin sí Jèhófà, ó sọ pé: “Èmi yóò máa gbé ọ lárugẹ nínú ìjọ ńlá; èmi yóò máa yìn ọ́ láàárín àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ níye.” (Sm. 35:18) Onísáàmù náà máa ń yin Jèhófà tó bá wà pẹ̀lú àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Àwọn ìpàdé tá a máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, tó fi mọ́ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́, máa ń fún wa ní àǹfààní tó pọ̀ láti fi hàn pé a jẹ́ onítara nígbà tá a bá ń lóhùn sí àwọn ìpàdé náà nípa sísọ ohun tá a gbà gbọ́. Gbogbo wa lè bi ara wa pé: ‘Ǹjẹ́ mo máa ń dáhùn nípàdé? Ṣé mo máa ń múra àwọn ìpàdé sílẹ̀ dáadáa, ṣé mo sì máa ń dáhùn lọ́nà tó nítumọ̀? Gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé, ǹjẹ́ mo máa ń ran àwọn ọmọ mi lọ́wọ́ láti múra ìdáhùn sílẹ̀, ṣé mo sì ń kọ́ wọn láti máa dáhùn lọ́rọ̀ tara wọn?’

4 A lè fi hàn nípa bá a ṣe ń kọrin pé a ní ọkàn-àyà tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, ìyẹn ọkàn tó múra tán láti ṣe ohun tó tọ́. Onísáàmù náà, Dáfídì sọ pé: “Ọkàn-àyà mi fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, Ọlọ́run, ọkàn-àyà mi fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin. Ṣe ni èmi yóò máa kọrin, tí èmi yóò sì máa kọ orin atunilára.” (Sm. 57:7) Àwọn orin tá à ń kọ láwọn ìpàdé ìjọ máa ń fún wa láǹfààní tó pọ̀ láti fi ọkàn-àyà tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin “kọ orin atunilára” sí Jèhófà. Bí a kò bá mọ àwọn kan lára àwọn orin náà, ǹjẹ́ a lè fi wọ́n dánra wò nígbà Ìjọsìn Ìdílé wa? Ẹ jẹ́ ká pinnu láti máa ‘kọrin sí Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé wa ká sì máa kọ orin atunilára sí i níwọ̀n ìgbà tí a bá wà.’—Sm. 104:33.

5, 6. Báwo la ṣe lè máa ṣe aájò àlejò ká sì tún jẹ́ ọ̀làwọ́, kí nìyẹn sì máa mú kó gbilẹ̀ nínú ìjọ?

5 Ọ̀nà míì tá a tún lè gbà mú kí ìfẹ́ gbilẹ̀ nínú ìjọ ni pé ká máa ṣe àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin lálejò. Ní orí tó gbẹ̀yìn lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn Hébérù, ó gbà wọ́n níyànjú pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ ará tí ẹ ní máa bá a lọ. Ẹ má gbàgbé aájò àlejò.” (Héb. 13:1, 2) Pípèsè oúnjẹ fún àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àtàwọn ìyàwó wọn tàbí fún àwọn ìránṣẹ́ alákòókò kíkún tó wà nínú ìjọ jẹ́ ọ̀nà tó dára gan-an tá a lè gbà ṣe aájò àlejò. Tún ronú nípa àwọn opó, àwọn ìdílé olóbìí kan, tàbí àwọn míì tí wọ́n lè jàǹfààní tó o bá pè wọ́n wá jẹun tàbí tó o ní kí wọ́n wá dára pọ̀ mọ́ yín nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe Ìjọsìn Ìdílé.

6 Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé kó gba àwọn míì níyànjú “láti máa ṣe rere, láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà, láti jẹ́ aláìṣahun, kí wọ́n múra tán láti ṣe àjọpín, kí wọ́n máa fi àìséwu to ìṣúra ìpìlẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ jọ fún ara wọn de ẹ̀yìn ọ̀la, kí wọ́n lè di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.” (1 Tím. 6:17-19) Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará bíi tiẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n ní ẹ̀mí ọ̀làwọ́. Kódà, ní àwọn àkókò tí ọ̀ràn àtijẹ àtimu kò bá fara rọ, a lè mú kí ẹ̀mí ọ̀làwọ́ gbilẹ̀. Ọ̀nà kan tó dára tá a lè gbà ṣe èyí ni pé tá a bá ní ohun ìrìnnà, ká fi gbé àwọn ará lọ sóde ẹ̀rí, a sì tún lè fi gbé àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́ lọ sí ìpàdé ká sì tún fi gbé wọn pa dà sílé. Kí sì ni àwọn tí wọ́n fi inú rere hàn sí lọ́nà yìí lè ṣe? Àwọn náà á mú kí ẹ̀mí rere máa gbilẹ̀ nínú ìjọ bí wọ́n bá fi ìmọrírì hàn, bóyá nípa fífi iye tí wọ́n lágbára ṣètìlẹ́yìn fún epo ọkọ̀ tó ń gbówó lórí. Bákan náà, tá a bá ń lo àkókò púpọ̀ sí i pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa, ǹjẹ́ ìyẹn ò ní mú kí wọ́n mọ̀ pé a ka àwọn sí àti pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn? Tá a bá ń ṣe àwọn iṣẹ́ rere “sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́” tá a sì múra tán láti ṣàjọpín àkókò wa àti ohun ìní wa pẹ̀lú wọn, ìfẹ́ tá a ní fún wọn á jinlẹ̀ sí i, èyí á sì tún mú kí ẹ̀mí ọ̀yàyà àti ẹ̀mí rere gbilẹ̀ nínú ìjọ.—Gál. 6:10.

7. Tá a bá ń pa àṣírí àwọn ẹlòmíì mọ́, báwo lèyí ṣe lè mú kí ẹ̀mí rere gbilẹ̀ nínú ìjọ?

7 Ẹ jẹ́ ká tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan míì tó lè mú kí ìfẹ́ tá a ní sáwọn ará wa túbọ̀ jinlẹ̀ sí i, ìyẹn jíjẹ́ ọ̀rẹ́ ara wa àti pípa àṣírí mọ́. (Ka Òwe 18:24.) Àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń pa àṣírí àárín ara wọn mọ́. Nígbà táwọn arákùnrin wa bá sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn àti bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára wọn fún wa, tó sì dá wọn lójú pé ọ̀rọ̀ náà kò ní lu síta, èyí á mú kí ìfẹ́ tá a ní síra wa jinlẹ̀ sí i. Ǹjẹ́ ká mú kí ẹ̀mí ìfẹ́ máa gbilẹ̀ nínú ìjọ ká sì máa bára wa lò bí agbo ìdílé kan ṣoṣo nípa jíjẹ́ ọ̀rẹ́ tó ṣeé finú hàn tó sì lè pa àṣírí mọ́.—Òwe 20:19.

MÁA FI ÌTARA ṢE IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́

8. Kí ni Jésù sọ fún àwọn ará Laodíkíà, kí sì nìdí?

8 Nígbà tí Jésù ń darí ọ̀rọ̀ sí àwọn ará Laodíkíà, ó sọ pé: “Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ, pé o kò tutù bẹ́ẹ̀ ni o kò gbóná. Èmi ì bá fẹ́ kí o tutù tàbí kẹ̀ kí o gbóná. Nípa báyìí, nítorí pé o lọ́wọ́ọ́wọ́, tí o kò sì gbóná tàbí tutù, èmi yóò pọ̀ ọ́ jáde kúrò ní ẹnu mi.” (Ìṣí. 3:15, 16) Àwọn ará Laodíkíà kò ní ìtara fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Ó sì jọ pé irú ìwà bẹ́ẹ̀ nípa lórí àjọṣe tó wà láàárín wọn pẹ̀lú. Torí náà, Jésù fìfẹ́ tọ́ wọn sọ́nà pé: “Gbogbo àwọn tí mo ní ìfẹ́ni fún ni mo ń fi ìbáwí tọ́ sọ́nà, tí mo sì ń bá wí. Nítorí náà, jẹ́ onítara, kí o sì ronú pìwà dà.”—Ìṣí. 3:19.

9. Báwo ni ọwọ́ tá a fi mú iṣẹ́ ìwàásù wa ṣe ń nípa lórí ẹ̀mí ìjọ?

9 Tá a bá fẹ́ kí ẹ̀mí rere, tí ń gbéni ró máa gbilẹ̀ nínú ìjọ, a gbọ́dọ̀ jẹ́ onítara lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ọ̀kan lára ohun tí ìjọ wà fún ni láti wá àwọn ẹni bí àgùntàn rí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa ká sì kọ́ wọ́n lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Torí náà, ó yẹ ká máa fi ìtara kópa nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, bí Jésù ti ṣe. (Mát. 28:19, 20; Lúùkù 4:43) Bí ìtara tá a ní fún iṣẹ́ ìwàásù bá ṣe pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni ìṣọ̀kan wa gẹ́gẹ́ bí “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run” ṣe máa pọ̀ tó. (1 Kọ́r. 3:9) Bá a ti ń kíyè sí ọ̀nà táwọn míì ń gbà gbèjà ìgbàgbọ́ wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n sì ń fi ìmọrírì hàn fún àwọn nǹkan tẹ̀mí, èyí ń mú ká nífẹ̀ẹ́ wọn ká sì túbọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún wọn. Bákan náà, bá a ṣe ń sìn “ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́” pẹ̀lú wọn nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run tún ń mú ká máa wà ní ìṣọ̀kan nínú ìjọ.—Ka Sefanáyà 3:9.

10. Tá a bá mú kí iṣẹ́ ìsìn pápá wa sunwọ̀n sí i, ipa wo ló máa ní lórí àwọn míì nínú ìjọ?

10 Bá a ṣe ń sapá láti mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa sunwọ̀n sí i tún máa ń ní ipa rere lórí àwọn míì. Bí a bá ṣe ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn tá à ń bá pàdé túbọ̀ máa jẹ wá lógún, tá à ń sapá láti mú kí ọ̀nà tá a gbà ń ṣàlàyé òtítọ́ fún àwọn tó ń gbọ́rọ̀ wa gbéṣẹ́ sí i, bẹ́ẹ̀ ni ìtara tá a fi ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ á túbọ̀ máa pọ̀ sí i. (Mát. 9:36, 37) Tá a bá ń fi ìtara ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, èyí lè mú kí àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí náà di onítara. Dípò kí Jésù rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jáde lọ́kọ̀ọ̀kan láti lọ wàásù, ńṣe ló rán wọn lọ ní méjìméjì. (Lúùkù 10:1) Ìṣírí lèyí jẹ́ fún wọn, wọ́n sì tún rí ìdálẹ́kọ̀ọ́ gbà. Àmọ́, ó tún mú kí ìtara tí wọ́n ní fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ pọ̀ sí i. Ǹjẹ́ kì í wu àwa náà pé ká bá àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ onítara ṣiṣẹ́? Ìtara ọkàn wọn máa ń fún wa níṣìírí, kì í sì í jẹ́ kó rẹ̀ wá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.—Róòmù 1:12.

Ẹ MÁ ṢE RÁHÙN Ẹ MÁ SÌ ṢE HÙWÀ ÀÌTỌ́

11. Ìwà wo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan hù nígbà ayé Mósè, ipa wo lèyí sì ní lórí wọn?

11 Láàárín ọ̀sẹ̀ mélòó kan lẹ́yìn tí Ísírẹ́lì di orílẹ̀-èdè, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di aláìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ráhùn. Èyí mú kí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà àtàwọn aṣojú rẹ̀. (Ẹ́kís. 16:1, 2) Díẹ̀ péré lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì ni wọ́n dé Ilẹ̀ Ìlérí. Kódà, Ọlọ́run kò jẹ́ kí Mósè pàápàá wọ ilẹ̀ náà torí ohun tó ṣe nígbà tí ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì hùwà tí kò dára! (Diu. 32:48-52) Kí la lè ṣe lónìí tí a kò fi ní dẹni tó ń hùwà tí kò dára?

12. Kí la lè ṣe tí a kò fi ní máa ráhùn?

12 A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má bàa máa ráhùn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tá a bá ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tá a sì ń bọ̀wọ̀ fún àṣẹ, ó máa ṣe wá láǹfààní, síbẹ̀ ó yẹ ká kíyè sára nípa irú àwọn tá à ń bá kẹ́gbẹ́. Tá a bá yan eré ìnàjú tí kò tọ́ tàbí tá à ń lo àkókò tó pọ̀ jù pẹ̀lú àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí àwọn ọmọ iléèwé wa tí kò ní ọ̀wọ̀ fún àwọn ìlànà òdodo, ó lè ní ipa tí kò tọ́ lórí wa. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu ká dín àjọṣe wa kù pẹ̀lú àwọn tó lè ní ipa tí kò tọ́ lórí wa tàbí àwọn tí wọ́n ń fẹ́ láti máa ṣe tinú wọn.—Òwe 13:20.

13. Bí ẹ̀mí ìráhùn bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbilẹ̀ nínú ìjọ, àwọn ìwà míì tó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ wo ló lè yọrí sí?

13 Bí ẹ̀mí ìráhùn bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbilẹ̀ nínú ìjọ, ó lè mú kí àwọn ará bẹ̀rẹ̀ sí í hu àwọn ìwà míì tó lè ba àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ríráhùn lè ba àlàáfíà àti ìṣọ̀kan ìjọ jẹ́. Bákan náà, tá a bá ń ráhùn nípa àwọn ará wa, èyí lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá wọn, ó sì tún lè mú ká jẹ̀bi ìbanilórúkọjẹ́ àti ìkẹ́gàn. (Léf. 19:16; 1 Kọ́r. 5:11) Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn kan tó ń ráhùn nínú ìjọ “ń ṣàìka ipò olúwa sí, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ àwọn ẹni ògo tèébútèébú.” (Júúdà 8, 16) Ó dájú pé inú Ọlọ́run kò dùn sí àwọn tó ráhùn lọ́nà yẹn lòdì sí àwọn tó ń múpò iwájú.

14, 15. (a) Bí ìwà àìtọ́ bá ń bà á nìṣó tí a kò sì ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀, ipa wo ló lè ní lórí ìjọ lápapọ̀? (b) Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá mọ̀ pé ẹnì kan ti dá ẹ̀ṣẹ̀ ìkọ̀kọ̀?

14 Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá mọ̀ pé ẹnì kan ti dá ẹ̀ṣẹ̀ ìkọ̀kọ̀, bóyá tó ń mu ọtí àmujù, tó ń wo ohun tó ń mú ọkàn ẹni fà sí ìṣekúṣe tàbí tó ń ṣe ìṣekúṣe? (Éfé. 5:11, 12) Tá a bá fojú pa ìwà àìtọ́ tó burú jáì tí ẹnì kan hù rẹ́, ó lè máà jẹ́ kí ẹ̀mí Jèhófà ṣiṣẹ́ dáádáá nínú ìjọ, ó sì lè ba àlàáfíà ìjọ lápapọ̀ jẹ́. (Gál. 5:19-23) Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní tó wà ní ìjọ Kọ́ríńtì pé kí wọ́n mú ìwà burúkú kúrò nínú ìjọ wọn. Bákan náà, lóde òní, àwa pẹ̀lú gbọ́dọ̀ mú ìwà tó lè ṣàkóbá fún ìjọ kúrò kí ẹ̀mí rere, tí ń gbéni ró lè máa gbilẹ̀ nínú ìjọ. Kí lo lè ṣe láti pa kún àlàáfíà tó wà nínú ìjọ?

15 Bá a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ó ṣe pàtàkì pé ká máa pa àṣírí mọ́ bí àwọn ọ̀ràn kan bá wáyé, ní pàtàkì bí àwọn èèyàn bá sọ bí ọ̀ràn ṣe rí lára wọn tàbí ohun tó wà lọ́kàn wọn fún wa. Kì í ṣe ohun tó dáa pé ká máa sọ àṣírí àwọn ẹlòmíì káàkiri, ó sì máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn báni. Àmọ́ ṣá o, bó bá jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì ni ẹni náà dá, ńṣe ló yẹ ká sọ fún àwọn tí Ìwé Mímọ́ fún láṣẹ láti bójú tó irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, ìyẹn àwọn alàgbà ìjọ. (Ka Léfítíkù 5:1.) Torí náà tá a bá mọ̀ pé arákùnrin tàbí arábìnrin kan ti hu irú ìwà àìtọ́ bẹ́ẹ̀, ká sọ fún ẹni náà pé kó lọ sọ ọ̀rọ̀ náà fún àwọn alàgbà, kí wọ́n lè ràn án lọ́wọ́. (Ják. 5:13-15) Àmọ́, bí ẹni náà kò bá lọ sọ fún àwọn alàgbà láàárín àkókò to bójú mu, àwa fúnra wa gbọ́dọ̀ sọ fún wọn nípa ìwà àìtọ́ náà.

16. Tá a bá sọ fún àwọn alàgbà pé ẹnì kan ti hu ìwà àìtọ́ tó burú jáì, báwo nìyẹn ṣe lè mú kí ẹ̀mí rere gbilẹ̀ nínú ìjọ?

16 Ibi ààbò tẹ̀mí ni ìjọ Kristẹni jẹ́, a sì gbọ́dọ̀ dáàbò bò ó nípa sísọ fún àwọn alàgbà bí ìwà àìtọ́ tó burú jáì bá wáyé. Bí àwọn alàgbà bá pe orí oníwà àìtọ́ náà wálé, tó ronú pìwà dà tó sì gba ìbáwí àti ìtọ́sọ́nà tí wọ́n fún un, kò ní wu ẹ̀mí rere ìjọ léwu mọ́. Àmọ́ bí ẹni tó dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì náà kò bá ronú pìwà dà ńkọ́, tí kò sì ṣiṣẹ́ lórí ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tí àwọn alàgbà fún un? Yíyọ tí wọ́n bá yọ ẹni náà kúrò nínú ìjọ máa yọrí sí “ìparun,” tàbí mímú ohun tó lè ṣàkóbá fún ìjọ kúrò láàárín wa, ó sì máa mú ká pa ẹ̀mí rere ìjọ mọ́. (Ka 1 Kọ́ríńtì 5:5.) Ó dájú pé ká tó lè pa ẹ̀mí rere ìjọ mọ́, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gbọ́dọ̀ ṣe ohun tó tọ́, ká fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà, ká sì dáàbò bo ìjọ nípa ṣíṣe ohun tó máa ran àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ lọ́wọ́.

Ẹ MÁA PA “ÌṢỌ̀KANṢOṢO Ẹ̀MÍ” MỌ́

17, 18. Kí ló máa jẹ́ ká lè “máa pá ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́”?

17 Ohun tó mú kí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní ọ̀rúndún kìíní wà ní ìṣọ̀kan nínú ìjọ ni pé wọ́n fi “ara wọn fún ẹ̀kọ́ àwọn àpọ́sítélì.” (Ìṣe 2:42) Wọ́n mọyì ìmọ̀ràn àti ìtọ́sọ́nà látinú Ìwé Mímọ́ tí wọ́n ń rí gbà lọ́dọ̀ àwọn àgbà ọkùnrin. Torí pé, lóde òní, àwọn alàgbà ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye, èyí jẹ́ ìṣírí fún gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ, ó sì ń mú kí wọ́n wà ní ìṣọ̀kan. (1 Kọ́r. 1:10) Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tó dá lórí Bíbélì tí ètò Jèhófà ń fún wa, tá a sì ń tẹ̀ lé ìdarí àwọn alàgbà, ńṣe là ń fi hàn pé à ń “fi taratara sakun láti máa pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè asonipọ̀ṣọ̀kan ti àlàáfíà.”—Éfé. 4:3.

18 Torí náà, ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe kí ẹ̀mí rere, tí ń gbéni ró lè máa gbilẹ̀ nínú ìjọ. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dá wa lójú pé ‘inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jésù Kristi Olúwa máa wà pẹ̀lú ẹ̀mí tí a fi hàn.’—Fílí. 4:23.

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Ǹjẹ́ o máa ń mú kí ẹ̀mí rere gbilẹ̀ nípa mímúra sílẹ̀ láti dáhùn lọ́nà tó nítumọ̀?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Pa kún ẹ̀mí rere ìjọ nípa mímọ àwọn orin wa