“Jẹ́ Onígboyà Àti Alágbára Gidigidi”
“Jẹ́ Onígboyà Àti Alágbára Gidigidi”
“Jẹ́ onígboyà àti alágbára gidigidi . . . Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ.” —JÓṢ. 1:7-9.
BÁWO LO ṢE MÁA DÁHÙN?
․․․․․
Àwọn ọ̀nà wo ni Énọ́kù àti Nóà gbà fi ìgboyà hàn?
․․․․․
Báwo ni ọ̀nà tí àwọn obìnrin kan ní àtijọ́ gbà lo ìgbàgbọ́ àti ìgboyà ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa?
․․․․․
Àwọn àpẹẹrẹ wo ló wú ẹ lórí nípa báwọn ọ̀dọ́ ṣe lo ìgboyà?
1, 2. (a) Bá a ṣe ń gbé ìgbé ayé wa, kí la máa ń nílò nígbà míì ká lè jẹ́ adúróṣinṣin? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
ÒDÌ KEJÌ ìgboyà ni ìbẹ̀rù, ìtìjú àti ojo. Tá a bá gbọ́ pé ẹnì kan jẹ́ onígboyà, ohun tá a máa rò ni pé ẹni náà jẹ́ alágbára, akíkanjú àti aláìṣojo. Àmọ́ ìgbà míì wà tá a máa nílò ìgboyà ká tó lè jẹ́ adúróṣinṣin bá a ṣe ń gbé ìgbé ayé wa.
2 Àwọn kan tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn kò bẹ̀rù nígbà tí wọ́n dojú kọ àdánwò. Àwọn míì lo ìgboyà nígbà tí wọ́n dojú kọ àwọn ohun tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà. Kí la lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ àwọn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn pé wọ́n jẹ́ onígboyà? Báwo la ṣe lè jẹ́ onígboyà?
ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ ONÍGBOYÀ NÍNÚ AYÉ TÁWỌN ÈÈYÀN KÒ TI ṢE ÌFẸ́ ỌLỌ́RUN
3. Kí ni Énọ́kù sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run?
3 Ó gba ìgboyà kí ẹnì kan tó lè jẹ́ ẹlẹ́rìí fún Jèhófà láàárín àwọn èèyàn burúkú tó gbé láyé ṣáájú Ìkún-omi ọjọ́ Nóà. Síbẹ̀, Énọ́kù tó jẹ́ “ẹnì keje nínú ìlà láti ọ̀dọ̀ Ádámù,” fi ìgboyà jẹ́ iṣẹ́ tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ yìí. Ó ní: “Wò ó! Jèhófà wá pẹ̀lú ẹgbẹẹgbàárùn-ún rẹ̀ mímọ́, láti mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún sí gbogbo ènìyàn, àti láti dá gbogbo aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run lẹ́bi nípa gbogbo ìṣe àìṣèfẹ́ Ọlọ́run wọn, èyí tí wọ́n ṣe lọ́nà àìṣèfẹ́ Ọlọ́run, àti nípa gbogbo ohun amúnigbọ̀nrìrì tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run ti sọ lòdì sí i.” (Júúdà 14, 15) Énọ́kù sọ̀rọ̀ bíi pé ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá ló ń sọ torí ó dá a lójú pé àsọtẹ́lẹ̀ yẹn máa ní ìmúṣẹ. Àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run sì pa run ní tòótọ́ nígbà tí Ọlọ́run mú àkúnya omi wá sórí ilẹ̀ ayé!
4. Lábẹ́ àwọn ipò wo ni Nóà ti ‘bá Ọlọ́run rìn’?
4 Ọdún 2370 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni Ìkún-omi náà wáyé, èyí sì jẹ́ ohun tó lé ní àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀ta [650] ọdún lẹ́yìn tí Énọ́kù sọ àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run fi rán an. Láàárín àkókò yìí, wọ́n ti bí Nóà, ó ti ní ìdílé tirẹ̀, òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì ti kan ọkọ̀ áàkì. Àwọn áńgẹ́lì burúkú ti gbé ara èèyàn wọ̀, wọ́n ti fẹ́ àwọn ọmọbìnrin tó rẹwà fún ara wọn, wọ́n sì ti bí àwọn Néfílímù. Síwájú sí i, ìwà burúkú àwọn èèyàn ti wá pọ̀ gan-an, ilẹ̀ ayé sì kún fún ìwà ipá. (Jẹ́n. 6:1-5, 9, 11) Láìka àwọn ipò yìí sí, “Nóà bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn” ó sì fi ìgboyà wàásù gẹ́gẹ́ bí “oníwàásù òdodo.” (Ka 2 Pétérù 2:4, 5.) A nílò irú ìgboyà kan náà ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí.
WỌ́N LO ÌGBÀGBỌ́ ÀTI ÌGBOYÀ
5. Báwo ni Mósè ṣe lo ìgbàgbọ́ àti ìgboyà?
5 A lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára Mósè tó lo ìgbàgbọ́ àti ìgboyà. (Héb. 11:24-27) Láti ọdún 1513 sí ọdún 1473 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Ọlọ́run lo Mósè láti kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì, ó sì darí wọn nínú aginjù. Mósè ronú pé òun kò kúnjú ìwọ̀n láti ṣe iṣẹ́ yìí, àmọ́ ó tẹ́wọ́ gbà á. (Ẹ́kís. 6:12) Ọ̀pọ̀ ìgbà ni òun àti Áárónì arákùnrin rẹ̀ lọ síwájú Fáráò Ọba Íjíbítì tó jẹ́ òǹrorò, wọ́n sì fi ìgboyà kéde Ìyọnu Mẹ́wàá tí Jèhófà fi tàbùkù sí àwọn òrìṣà ilẹ̀ Íjíbítì tó sì fi gba àwọn èèyàn Rẹ̀ sílẹ̀. (Ẹ́kís., orí 7-12) Mósè lo ìgbàgbọ́ àti ìgboyà torí pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn rẹ̀ gbágbáágbá, bó ṣe wà lẹ́yìn àwa náà lónìí.—Diu. 33:27.
6. Bí àwọn aláṣẹ bá fi ọ̀rọ̀ wá wa lẹ́nu wò, báwo la ṣe lè fi ìgboyà wàásù?
6 A nílò ìgboyà bíi ti Mósè torí Jésù sọ pé: “Wọn yóò fà yín lọ síwájú àwọn gómìnà àti àwọn ọba nítorí mi, láti ṣe ẹ̀rí fún wọn àti fún àwọn orílẹ̀-èdè. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí wọ́n bá fà yín léni lọ́wọ́, ẹ má ṣàníyàn nípa báwo tàbí kí ni ẹ ó sọ; nítorí a ó fi ohun tí ẹ ó sọ fún yín ní wákàtí yẹn; nítorí kì í wulẹ̀ ṣe ẹ̀yin ni ẹni tí ń sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀mí Baba yín ni ó ń sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ yín.” (Mát. 10:18-20) Bí àwọn aláṣẹ bá fi ọ̀rọ̀ wá wa lẹ́nu wò, ẹ̀mí Jèhófà máa jẹ́ ká lè fi ìgbàgbọ́ àti ìgboyà jẹ́rìí lọ́nà tó fi ọ̀wọ̀ hàn.—Ka Lúùkù 12:11, 12.
7. Kí nìdí tí Jóṣúà fi lo ìgboyà tó sì ṣàṣeyọrí?
7 Ohun tó mú kí Jóṣúà tó di aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́yìn Mósè ní ìgbàgbọ́ àti ìgboyà ni pé ó máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Òfin Ọlọ́run déédéé. Ní ọdún 1473 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti wà ní sẹpẹ́ láti wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Ọlọ́run pàṣẹ fún Jóṣúà pé kí ó “jẹ́ onígboyà àti alágbára gidigidi.” Bí Jóṣúà bá pa Òfin Ọlọ́run mọ́, ó máa hùwà ọgbọ́n á sì ṣàṣeyọrí. Ọlọ́run tún sọ fún un pé: “Má gbọ̀n rìrì tàbí kí o jáyà, nítorí Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ ní ibikíbi tí o bá lọ.” (Jóṣ. 1:7-9) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ti ní láti fún Jóṣúà lókun gan-an ni! Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú rẹ̀ lóòótọ́, torí pé nígbà tó fi máa di ọdún 1467 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìyẹn láàárín ọdún mẹ́fà péré, ó ti ṣẹ́gun ibi tó pọ̀ jù lọ lára Ilẹ̀ Ìlérí.
ÀWỌN AKÍKANJÚ OBÌNRIN TÍ WỌ́N MÚ ÌDÚRÓ WỌN
8. Báwo ni ọ̀nà tí Ráhábù gbà lo ìgbàgbọ́ àti ìgboyà ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa?
8 Jálẹ̀ ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún, ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin tó jẹ́ onígboyà mú ìdúró wọn gẹ́gẹ́ bí akíkanjú olùjọ́sìn Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, Ráhábù, aṣẹ́wó kan tó gbé ní ìlú Jẹ́ríkò lo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ìgboyà tó ní mú kó tọ́jú àwọn amí méjì tí Jóṣúà rán jáde, lẹ́yìn náà ló darí àwọn ẹmẹ̀wà ọba ìlú náà tí wọ́n ń wá wọn gba ibòmíràn. Ọlọ́run dá òun àti agbo ilé rẹ̀ sí nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì gba ìlú Jẹ́ríkò. Ráhábù jáwọ́ nínú iṣẹ́ tó ń mú kó máa dẹ́ṣẹ̀, ó fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà, ó sì di ìyá ńlá Mèsáyà. (Jóṣ. 2:1-6; 6:22, 23; Mát. 1:1, 5) Jèhófà bù kún un lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí ìgbàgbọ́ àti ìgboyà rẹ̀!
9. Báwo ni Dèbórà, Bárákì àti Jáẹ́lì ṣe lo ìgboyà?
9 Ní nǹkan bí ọdún 1450 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, lẹ́yìn ikú Jóṣúà, àwọn onídàájọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìdájọ́ ní Ísírẹ́lì. Jábínì ọba Kénáánì ti tẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lórí ba fún ogún ọdún. Ọlọ́run ní kí Dèbórà tó jẹ́ wòlíì obìnrin sọ fún Bárákì Onídàájọ́ pé kó bá ọba náà jà. Bárákì kó ẹgbàá márùn-ún [10,000] ọkùnrin jọ sórí Òkè Tábórì ó sì ṣe tán láti gbógun ti Sísérà tó jẹ́ olórí ogun Jábínì, tó kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún [900] kẹ̀kẹ́ ogun wọn wọ àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Kíṣónì. Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yan lọ sínú pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì náà, Ọlọ́run mú kí ìkún-omi ya wá lójijì, ó sì sọ pápá ogun náà di ibi àbàtà èyí tó mú kí kẹ̀kẹ́ ogun àwọn ará Kénáánì má lè lọ. Àwọn ọmọ ogún Bárákì ṣẹ́gun, ‘gbogbo ibùdó Sísérà sì ti ojú idà ṣubú.’ Sísérà fúnra rẹ̀ wá ààbò lọ sínú àgọ́ Jáẹ́lì, àmọ́ lẹ́yìn tó ti sùn lọ, Jáẹ́lì pa á. Ní ìbámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ tí Dèbórà sọ fún Bárákì, ọwọ́ obìnrin, ìyẹn Jáẹ́lì, ni “ohun ẹwà” ìṣẹ́gun yìí bọ́ sí. Torí pé Dèbórà, Bárákì àti Jáẹ́lì lo ìgboyà, ilẹ̀ Ísírẹ́lì “kò sì ní ìyọlẹ́nu kankan mọ́ fún ogójì ọdún.” (Oníd. 4:1-9, 14-22; 5:20, 21, 31) Ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n jẹ́ olùjọsìn Ọlọ́run ti lo irú ìgbàgbọ́ àti ìgboyà bẹ́ẹ̀.
Ọ̀RỌ̀ WA LÈ MÚ KÁWỌN ÈÈYÀN NÍ ÌGBOYÀ
10. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ọ̀rọ̀ wa lè mú káwọn èèyàn ní ìgboyà?
10 Ohun tá a bá sọ lè mú káwọn tá a jọ ń sin Jèhófà ní ìgboyà. Ní ọ̀rúndún kọkànlá ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Dáfídì Ọba sọ fún ọmọ rẹ̀ Sólómọ́nì pé: “Jẹ́ onígboyà àti alágbára kí o sì gbé ìgbésẹ̀. Má fòyà tàbí kí o jáyà, nítorí Jèhófà Ọlọ́run, Ọlọ́run mi, wà pẹ̀lú rẹ. Òun kì yóò kọ̀ ọ́ tì tàbí kí ó fi ọ́ sílẹ̀ títí gbogbo iṣẹ́ tí ó jẹ́ ti iṣẹ́ ìsìn ilé Jèhófà yóò fi parí.” (1 Kíró. 28:20) Sólómọ́nì lo ìgboyà ó sì kọ́ tẹ́ńpìlì tó kàmàmà fún Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù.
11. Báwo ni ọ̀rọ̀ tí ọmọdébìnrin Ísírẹ́lì kan fi ìgboyà sọ ṣe ran ọkùnrin kan lọ́wọ́?
11 Ní ọ̀rúndún kẹwàá ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ọ̀rọ̀ tí ọmọdébìnrin Ísírẹ́lì kan fi ìgboyà sọ mú kí adẹ́tẹ̀ kan rí ìwòsàn. Àwọn ẹgbẹ́ onísùnmọ̀mí ló mú ọmọdébìnrin yìí lẹ́rú, ó sì wá di ọmọ ọ̀dọ̀ nílé Náámánì, ọ̀gágun ilẹ̀ Síríà. Ọmọdébìnrin yìí ti gbọ́ nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jèhófà tọwọ́ wòlíì Èlíṣà ṣe, torí náà, ó sọ fún ìyàwó Náámánì pé bí ọkọ rẹ̀ bá lè lọ sí Ísírẹ́lì, wòlíì Ọlọ́run máa wo ẹ̀tẹ̀ rẹ̀ sàn. Náámánì gba ọ̀rọ̀ ọmọdébìnrin náà, ó lọ sí Ísírẹ́lì, ó rí ìwòsàn gbà, ó sì di olùjọ́sìn Jèhófà. (2 Ọba 5:1-3, 10-17) Bó o bá jẹ́ ọ̀dọ́ tó fẹ́ràn Ọlọ́run bí ọmọdébìnrin yẹn ti ṣe, Ọlọ́run lè fún ẹ ní ìgboyà láti wàásù fún àwọn olùkọ́, àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ ọmọléèwé àti àwọn èèyàn míì.
12. Kí ni àwọn èèyàn ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Hesekáyà Ọba?
12 Tá a bá sọ ọ̀rọ̀ tó yẹ fún ẹnì kan tó wà nínú ìṣòro, irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ lè fún un ní ìgboyà. Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Ásíríà wá gbéjà ko Jerúsálẹ́mù ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Hesekáyà Ọba sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ onígboyà àti alágbára. Ẹ má fòyà tàbí kí ẹ jáyà nítorí ọba Ásíríà àti ní tìtorí gbogbo ogunlọ́gọ̀ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀; nítorí àwọn tí ó wà pẹ̀lú wa pọ̀ ju àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀. Apá tí ó jẹ́ ẹran ara ni ó wà pẹ̀lú rẹ̀, ṣùgbọ́n Jèhófà Ọlọ́run wa ni ó wà pẹ̀lú wa láti ràn wá lọ́wọ́ àti láti ja àwọn ìjà ogun wa.” Kí ni àwọn èèyàn náà ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí? Họ́wù, ńṣe ni “àwọn ènìyàn náà . . . bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ọ̀rọ̀ Hesekáyà ọba Júdà gbé ara wọn ró”! (2 Kíró. 32:7, 8) Irú ọ̀rọ̀ tí ń gbéni ró bẹ́ẹ̀ lè túbọ̀ fún àwa àti àwọn Kristẹni mìíràn ní ìgboyà bí àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí wa bá bẹ̀rẹ̀ sí í fúngun mọ́ wa.
13. Àpẹẹrẹ ìgboyà wo la rí lára Ọbadáyà tó jẹ́ alámòójútó ilé Áhábù Ọba?
13 Nígbà míì ohun tí a kò sọ ló máa fi hàn pé a ní ìgboyà. Ní ọ̀rúndún kẹwàá ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Ọbadáyà tó jẹ́ alámòójútó ilé Áhábù Ọba fi ìgboyà tọ́jú ọgọ́rùn-ún kan lára àwọn wòlíì Jèhófà pa mọ́ “ní àádọ́ta-àádọ́ta nínú hòrò kan” kí Jésíbẹ́lì ayaba búburú má bàa pa wọ́n. (1 Ọba 18:4) Bíi ti Ọbadáyà tó ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, ọ̀pọ̀ lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó ń fi òtítọ́ sìn ín lónìí ti fìgboyà dáàbò bo àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ nípa kíkọ̀ láti fún àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí wọn ní ìsọfúnni nípa àwọn ará wọn.
Ẹ́SÍTÉRÌ—AYABA TÓ NÍGBOYÀ
14, 15. Báwo ni Ẹ́sítérì Ayaba ṣe fi ìgbàgbọ́ àti ìgboyà hàn, kí sì ni àbájáde rẹ̀?
14 Ẹ́sítérì tó jẹ́ aya Ọba Páṣíà fi ìgbàgbọ́ àti ìgboyà ńlá hàn nígbà tí Hámánì tó jẹ́ ẹni búburú pète láti pa gbogbo àwọn Júù tó wà ní Ilẹ̀ Ọba Páṣíà run ní ọ̀rúndún karùn-ún ṣáájú Sànmánì Kristẹni, èyí sì fi ẹ̀mí gbogbo àwọn Júù náà sínú ewu. Abájọ tí wọ́n fi ṣọ̀fọ̀, tí wọ́n gbààwẹ̀, tó sì tún dájú pé wọ́n fi tọkàntọkàn gbàdúrà! (Ẹ́sít. 4:1-3) Ọ̀rọ̀ yìí kó ẹ̀dùn ọkàn bá Ẹ́sítérì Ayaba gan-an ni. Módékáì tó jẹ́ ìbátan rẹ̀ fi ẹ̀dà kan ránṣẹ́ sí i lára òfin tí wọ́n ṣe pé kí wọ́n pa àwọn Júù nípakúpa, ó sì pàṣẹ fún un pé kó fara hàn níwájú ọba láti bẹ̀bẹ̀ pé kí ọba fojúure hàn sí àwọn Júù bíi tirẹ̀. Àmọ́, béèyàn bá lọ sọ́dọ̀ ọba láìjẹ́ pé ọba sọ pé kó wá, pípa ni wọ́n máa pa onítọ̀hún.—Ẹ́sít. 4:4-11.
15 Síbẹ̀, Módékáì sọ fún Ẹ́sítérì pé: ‘Bí ìwọ bá dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní àkókò yìí, ìtura àti ìdáǹdè yóò dìde láti ibòmíràn. Ta sì ni ó mọ̀ bóyá nítorí irú àkókò yìí ni ìwọ fi dé ipò ọlá ayaba?’ Ẹ́sítérì rọ Módékáì pé kó kó àwọn Júù tó wà ní Ṣúṣánì jọ kí wọ́n sì gbààwẹ̀ nítorí òun. Ó wá sọ pé: “Èmi yóò gbààwẹ̀ bákan náà, látàrí ìyẹn, èmi yóò sì wọlé tọ ọba lọ, èyí tí kò bá òfin mu; bí ó bá ṣe pé èmi yóò ṣègbé, èmi yóò ṣègbé.” (Ẹ́sít. 4:12-17) Ẹ́sítérì fi ìgboyà gbé ìgbésẹ̀, ìwé Ẹ́sítérì sì fi hàn pé Ọlọ́run gba àwọn èèyàn rẹ̀. Lóde òní, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn tó ti ya ara wọn sí mímọ́, máa ń fi irú ìgboyà bẹ́ẹ̀ hàn bí wọ́n bá dojú kọ àdánwò, “Olùgbọ́ àdúrà” sì máa ń tì wọ́n lẹ́yìn ní gbogbo ìgbà.—Ka Sáàmù 65:2; 118:6.
“Ẹ MỌ́KÀNLE”
16. Ẹ̀kọ́ wo làwọn ọ̀dọ́ wa lè rí kọ́ lára Jésù?
16 Ní àkókò kan ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni, Jésù tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá wà nínú tẹ́ńpìlì. Àwọn òbí rẹ̀ rí i tí ‘ó jókòó sáàárín àwọn olùkọ́, ó ń fetí sí wọn, ó sì ń bi wọ́n ní ìbéèrè.’ Láfikún sí i, “gbogbo àwọn tí ń fetí sí i ni wọ́n ń ṣe kàyéfì léraléra nítorí òye rẹ̀ àti àwọn ìdáhùn rẹ̀.” (Lúùkù 2:41-50) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀dọ́ ni Jésù, ó ní ìgbàgbọ́ àti ìgboyà tó jẹ́ kó lè máa bi àwọn àgbàlagbà tó jẹ́ olùkọ́ ní tẹ́ńpìlì yẹn ní ìbéèrè. Bí àwọn ọ̀dọ́ tó wà nínú ìjọ Kristẹni bá fi àpẹẹrẹ Jésù sọ́kàn, ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n lè máa lo gbogbo àǹfààní tí wọ́n bá ní láti ‘ṣe ìgbèjà níwájú olúkúlùkù ẹni tí ó bá fi dandan béèrè ìdí fún ìrètí tí ń bẹ nínú wọn.’—1 Pét. 3:15.
17. Kí nìdí tí Jésù fi rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n “mọ́kànle,” kí sì nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ jẹ́ onígboyà?
17 Jésù rọ àwọn míì pé kí wọ́n “mọ́kànle.” (Mát. 9:2, 22) Ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Wò ó! Wákàtí náà ń bọ̀, ní tòótọ́, ó ti dé, nígbà tí a óò tú yín ká, olúkúlùkù sí ilé tirẹ̀, ẹ ó sì fi èmi nìkan sílẹ̀; síbẹ̀síbẹ̀, èmi kò wà ní èmi nìkan, nítorí pé Baba wà pẹ̀lú mi. Mo ti sọ nǹkan wọ̀nyí fún yín kí ẹ lè ní àlàáfíà nípasẹ̀ mi. Nínú ayé, ẹ óò máa ní ìpọ́njú, ṣùgbọ́n ẹ mọ́kànle! Mo ti ṣẹ́gun ayé.” (Jòh. 16:32, 33) Bíi ti àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní ọ̀rúndún kìíní, ayé kórìíra wa, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe jẹ́ ká dà bí àwọn èèyàn ayé. Tá a bá ń ronú nípa bí Ọmọ Ọlọ́run ṣe jẹ́ onígboyà, èyí lè fún àwa náà ní ìgboyà tí a kò fi ní jẹ́ kí ayé yìí sọ wá di ẹlẹ́gbin. Jésù ṣẹ́gun ayé, àwa náà sì lè ṣẹ́gun ayé.—Jòh. 17:16; Ják. 1:27.
“JẸ́ ONÍGBOYÀ GIDI GAN-AN!”
18, 19. Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe fi ìgbàgbọ́ àti ìgboyà hàn?
18 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fara da ọ̀pọ̀ ìdánwò. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí àwọn Júù tó wà ní Jerúsálẹ́mù ì bá ti pa á bí kì í bá ṣe ti àwọn ọmọ ogun Róòmù tí wọ́n gbà á sílẹ̀. Ní alẹ́, “Olúwa dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì wí pé: ‘Jẹ́ onígboyà gidi gan-an! Nítorí pé bí o ti ń jẹ́rìí kúnnákúnná nípa àwọn nǹkan tí ó ní í ṣe pẹ̀lú mi ní Jerúsálẹ́mù, bẹ́ẹ̀ náà ni ìwọ tún gbọ́dọ̀ jẹ́rìí ní Róòmù.’” (Ìṣe 23:11) Ohun tí Pọ́ọ̀lù sì ṣe gan-an nìyẹn.
19 Ẹ̀rù kò ba Pọ́ọ̀lù láti dẹ́bi fún ‘àwọn àpọ́sítélì adárarégèé’ tí wọ́n ń fẹ́ láti ba ìjọ Kọ́ríńtì jẹ́. (2 Kọ́r. 11:5; 12:11) Àwọn àpọ́sítélì wọ̀nyẹn kò lè mú ẹ̀rí kankan wá tó fi hàn pé wọ́n jẹ́ àpọ́sítélì, àmọ́ Pọ́ọ̀lù lè fẹ̀rí hàn pé Jésù ló rán òun torí àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sí i, bí ìfisẹ́wọ̀n, lílù, àwọn ìrìn àjò tó léwu, àwọn ewu mìíràn, ebi, òùngbẹ àti àìlèsùn àti àníyàn fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni. (Ka 2 Kọ́ríńtì 11:23-28.) Ìgbàgbọ́ àti ìgboyà ńlá ló fi hàn, ìyẹn sì jẹ́ ẹ̀rí pé Ọlọ́run ló fún un lágbára!
20, 21. (a) Sọ àpẹẹrẹ kan tó fi hàn pé a gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó láti lo ìgboyà. (b) Ní àwọn ìgbà wo ló pọn dandan pé ká lo ìgboyà, kí ló sì lè dá wa lójú?
20 Kì í ṣe gbogbo Kristẹni ló máa dojú kọ inúnibíni tó le koko. Síbẹ̀, gbogbo wa gbọ́dọ̀ lo ìgboyà ká lè fara da àwọn ipò tó nira nínú ayé. Àpẹẹrẹ kan rèé: Ọ̀dọ́kùnrin kan lórílẹ̀-èdè Brazil wà nínú ẹgbẹ́ àwọn ọmọọ̀ta. Lẹ́yìn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó rí i pé ó yẹ kí òun yí ìgbésí ayé òun pa dà, àmọ́ bí ẹnikẹ́ni bá kúrò nínú ẹgbẹ́ àwọn ọmọọ̀ta yẹn ńṣe ni wọ́n máa pa á. Ó gbàdúrà, ó sì fi Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé ìdí tó fi gbọ́dọ̀ fi ẹgbẹ́ náà sílẹ̀ fún olórí wọn. Wọ́n yọ̀ǹda pé kí ọ̀dọ́kùnrin náà máa lọ, wọn kò fi ìyà kankan jẹ ẹ́, ó sì di akéde Ìjọba Ọlọ́run.
21 Ó gba ìgboyà kéèyàn tó lè wàásù ìhìn rere. Àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́ nílò ìgboyà bí wọ́n bá ní láti jẹ́ adúróṣinṣin ní ilé ìwé. Ó lè gba ìgboyà kéèyàn tó lè gba ààyè ìsinmi níbi iṣẹ́ nítorí kó lè lọ sí àpéjọ àgbègbè ní àwọn ọjọ́ tí wọ́n máa fi ṣe é. Ọ̀pọ̀ ìdí ló tún wà tá a fi nílò ìgboyà. Àmọ́, ìṣòro yòówù kó máa dojú kọ wá, Jèhófà máa gbọ́ “àdúrà ìgbàgbọ́” wa. (Ják. 5:15) Ó sì dájú pé ó máa fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ká lè “jẹ́ onígboyà àti alágbára gidigidi”!
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Énọ́kù fi ìgboyà wàásù nínú ayé táwọn èèyàn kò ti ṣèfẹ́ Ọlọ́run
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Jáẹ́lì jẹ́ onígboyà àti alágbára