‘Wọ́n Ń Fi Mí Ṣe Ìran Wò’
Látinú Àpamọ́ Wa
‘Wọ́n Ń Fi Mí Ṣe Ìran Wò’
Nígbà tí Charlotte White tó jẹ́ oníwàásù alákòókò kíkún ti àpótí tó ní táyà lẹ́sẹ̀ wọ ìlú Louisville, tó wà ní ìpínlẹ̀ Kentucky lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ńṣe làwọn èèyàn dojú bò ó.
ỌDÚN 1908 ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé, àrímáleèlọ ni ohun àrà tuntun tí Arábìnrin White gbé dé yìí jẹ́ fáwọn ará ìlú, ìyẹn Àpótí Ìwé tó ní táyà lẹ́sẹ̀. Ó sọ pé: “Àwọn èèyàn ò yé sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ńṣe ni wọ́n ń fi mí ṣe ìran wò.”
Lẹ́yìn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n ń pè ní Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà yẹn, ti fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́, wọn rí i pé ó pọn dandan kí wọ́n mú ọ̀rọ̀ òtítọ́ tó ṣeyebíye tí wọ́n ti kọ́ tọ àwọn èèyàn lọ. Ọ̀pọ̀ nínú wọn lóye ohun tí Bíbélì fi kọ́ni lẹ́yìn tí wọ́n ti ka àwọn ìwé tó sọ̀rọ̀ nípa ẹgbẹ̀rún ọdún ìṣàkóso Kristi, ìyẹn Millennial Dawn (tá a wá mọ̀ nígbà tó yá sí Studies in the Scriptures). Àwọn tó fẹ́ lára àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyẹn, tó sì ṣeé ṣe fún láti rìnrìn àjò jákèjádò àwọn ìlú, abúlé àtàwọn àrọko, mú àwọn ìwé táwọn kan pè ní “Ìwé Tó Ń Ranni Lọ́wọ́ Láti Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì” yìí, tọ àwọn mìíràn tó ń yán hànhàn láti kà wọ́n lọ.
Nígbà yẹn lọ́hùn-ún ní ọdún 1908, Àpá Kìíní sí Ìkẹfà ìwé náà ni Arábìnrin White àtàwọn míì tó ń fi ìtara polongo Ìjọba Ọlọ́run máa ń mú tọ àwọn èèyàn lọ. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó dọ́là méjì owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà tí wọ́n máa ń ta àwọn ìwé ẹlẹ́yìn-líle tí wọ́n fi aṣọ ṣe èèpo ẹ̀yìn wọn yìí. Dípò kí wọ́n kó àwọn ìwé náà lé àwọn èèyàn lọ́wọ́ lójú ẹsẹ̀, ńṣe ni wọ́n á gba orúkọ àwọn tó bá fẹ́ gbà wọ́n sílẹ̀, wọ́n á wá pa dà kó àwọn ìwé náà lọ fún wọn. Èyí sábà máa ń jẹ́ lọ́jọ́ tí wọ́n bá gba owó oṣù, kí wọ́n lè san owó táṣẹ́rẹ́ fún iye tó ná wa láti tẹ ìwé náà. Ẹnì kan tí kò fẹ́ràn iṣẹ́ ìwàásù wa ṣàròyé pé iye táwọn èèyàn máa ń san bí wọ́n bá gba àwọn ìwé náà ti kéré jù!
Malinda Keefer rántí pé ìgbà kan wà tí iye tí àwọn kan máa ń béèrè fún lára àwọn ìwé náà máa ń tó igba [200] sí ọ̀ọ́dúnrún [300] lọ́sẹ̀. Àmọ́, bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe fẹ́ràn
àwọn ìwé Millennial Dawn yìí mú kí ìṣòro kan jẹ yọ. Ìṣòro náà ní í ṣe pẹ̀lú bí ọ̀kọ̀ọ̀kan lára àwọn ìwé náà ṣe tóbi tó. Iye ojú ìwé tí apá kẹfà nìkan ní jẹ́ òjì-lé-lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [740]! Kódà, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ sọ pé: “Àádọ́ta irú ìwé bẹ́ẹ̀ wúwo tó ìdá mẹ́ta àpò sìmẹ́ǹtì kan,” èyí tó máa ń mú kó “ṣòro gan-an,” pàápàá jù lọ fún àwọn arábìnrin láti kó wọn tọ àwọn èèyàn lọ.Kó lè rọrùn láti máa kó àwọn ìwé yìí tọ àwọn èèyàn lọ, Arákùnrin James Cole ṣe férémù kan tó ní táyà méjì, tó ṣeé ká, tó sì ṣeé de àpótí mọ́. Níwọ̀n bí kò ti pọn dandan pé kí arákùnrin tó ṣe férémù náà máa fi ọwọ́ kó àwọn páálí tó kún fún ìwé mọ́, ó sọ pé: “Mi ò gbé ẹrù tó lè yẹ̀ mí léjìká mọ́.” Ó fi ohun èlò tuntun náà han àwùjọ àwọn ará tó wá sí àpéjọ tí Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe lọ́dún 1908 ní ìlú Cincinnati, ní ìpínlẹ̀ Ohio. Inú àwùjọ náà sì dùn gan-an. Wọ́n kọ “Dawn-Mobile” (tó túmọ̀ sí àpótí tá a fi ń kó àwọn ìwé Millennial Dawn) sára àwọn ohun tí wọ́n fi máa ń de férémù náà mọ́ ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún àti ẹ̀gbẹ́ òsì àpótí náà, torí pé ohun tí wọ́n sábà máa ń fi kó nìyẹn. Lẹ́yìn táwọn ará ti bẹ̀rẹ̀ sí í lo àpótí ìwé náà, kò pẹ́ tó fi rọrùn fún wọn láti máa fi ọwọ́ kan ṣoṣo tì í bí ìwé bá tiẹ̀ kún inú rẹ̀. Wọ́n lè dín gíga àpótí ìwé náà kù, ó sì ṣeé gbé gba ojú ọ̀nà tí wọn kò da ọ̀dà sí. Lẹ́yìn tí iṣẹ́ ìwàásù bá ti parí lọ́jọ́ kan, wọ́n lè ká táyà rẹ̀ kúrò nílẹ̀ kí wọ́n sì pa á mọ́ ẹgbẹ́ àpótí náà. Nípa báyìí, á ṣeé fọwọ́ gbé lọ sílé tàbí kí wọ́n gbé e sínú takisí.
Àwọn arábìnrin tó wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún lè gba Àpótí Ìwé náà lọ́fẹ̀ẹ́, àmọ́ dọ́là méjì ààbọ̀ owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà ni àwọn mìíràn ń gbà á. Arábìnrin Keefer, tó wà nínú fọ́tò yìí, mọ Àpótí Ìwé náà lò débi pé ó lè fi ọwọ́ kan ṣoṣo ti àpótí tó kún fún ìwé kó sì tún fi ọwọ́ kejì fa báàgì tí ìwé wà nínú rẹ̀ dání. Ó máa ń wá àwọn tó fẹ́ gbọ́rọ̀ wa lọ sí ibì kan tí wọ́n ti ń wa kùsà ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, orí afárá ló máa ń gbà kọjá, ó sì máa ń pààrà ibẹ̀ ní ìgbà mẹ́ta tàbí mẹ́rin lọ́jọ́ tó bá kó ìwé lọ fún wọn.
Ní ọdún 1987, awakọ̀ òfuurufú kan ṣe báàgì ìkẹ́rù tó ní táyà lẹ́sẹ̀, irú èyí tá a sábà máa ń rí báyìí láwọn pápákọ̀ òfuurufú àti láwọn òpópónà tí ọ̀pọ̀ èrò máa ń gbà kọjá. Àmọ́, ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, ó jọ pé ó wu àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì onítara náà báwọn èèyàn ṣe ń fi wọ́n ṣe ìran wò bí wọ́n ṣe ń fa àwọn àpótí náà lọ tí wọ́n ń fà wọ́n bọ̀ nígbà tí wọ́n bá ń fún irúgbìn òtítọ́ Bíbélì káàkiri.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí tó wà ní ojú ìwé 32]
Orí afárá ni Arábìnrin Keefer máa ń gbà kọjá, ó sì máa ń pààrà ibẹ̀ ní ìgbà mẹ́ta tàbí mẹ́rin lọ́jọ́ tó bá kó ìwé lọ fún wọn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]
Ó mú kó rọrùn láti máa kó àwọn ìwé “Millennial Dawn” tọ àwọn èèyàn lọ