Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wọ́n Fi Ìgboyà Polongo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run!

Wọ́n Fi Ìgboyà Polongo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run!

Wọ́n Fi Ìgboyà Polongo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run!

Ìgboyà tàbí àìṣojo jẹ́ àwọn ànímọ́ táwọn èèyàn Ọlọ́run máa ń fi hàn bí wọ́n bá dojú kọ àtakò. Díẹ̀ lára àwọn ìwé wa, irú bíi “Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná” Nípa Ìjọba Ọlọ́run àti Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom jíròrò bí àwọn Kristẹni tòótọ́ ṣe lo ìgboyà àti bí wọ́n ṣe jẹ́ aláìṣojo. Bíi tàwọn tó jẹ́ onígbàgbọ́ bíi tiwa ní ọ̀rúndún kìíní, a máa ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún wa ní ẹ̀mí rẹ̀, kó sì ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa fi àìṣojo sọ̀rọ̀ rẹ̀.—Ìṣe 4:23-31.

Arákùnrin kan kọ̀wé nípa iṣẹ́ ìwàásù wa nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní pé: “Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ń fi ìtara pín apá keje ìwé Studies in the Scriptures tó ní àkọlé náà, The Finished Mystery káàkiri. Kódà ìpínkiri rẹ̀ pọ̀ ju bí wọ́n ṣe rò lọ. Ní ọdún 1918, a tẹ Ìròyìn Ìjọba Ọlọ́run No. 1. Lẹ́yìn rẹ̀ la tẹ Ìròyìn Ìjọba Ọlọ́run No. 2 láti fi ṣàlàyé ìdí tí àwọn aláṣẹ fi gbẹ́sẹ̀ lé ìwé The Finished Mystery. Ẹ̀yìn yẹn la wá tẹ Ìròyìn Ìjọba Ọlọ́run No. 3. Ẹgbẹ́ olóòótọ́ ti àwọn ẹni àmì òróró pín àwọn ìwé yìí délé dóko. Ó gba ìgbàgbọ́ àti ìgboyà kéèyàn tó lè máa pín Ìròyìn Ìjọba Ọlọ́run náà káàkiri.”

Lóde òní, àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di akéde Ìjọba Ọlọ́run sábà máa ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nípa bá a ṣe ń wàásù, àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀ nígbà yẹn. Arákùnrin kan tó ti ilẹ̀ Poland wá sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ ohun tójú rẹ̀ rí nígbà tó kọ́kọ́ jáde òde ẹ̀rí lọ́dún 1922. Ó ní: “Mi ò mọ bí màá ṣe fi ìwé náà lọni, mi ò sì mọ èdè Gẹ̀ẹ́sì sọ dáadáa, ńṣe ni mo wulẹ̀ dá dúró síwájú ọ́fíìsì dókítà kan tí mo sì kan ilẹ̀kùn. Nọ́ọ̀sì kan ló ṣí ilẹ̀kùn náà. Mi ò jẹ́ gbàgbé ọjọ́ yẹn, ńṣe ni ara mi ń gbọ̀n, ẹ̀rù sì ń bà mí. Bí mo ṣe ń ṣí àpò mi, gbogbo ìwé tó wà nínú rẹ̀ dà sórí ẹsẹ nọ́ọ̀sì náà. Mi ò mọ ohun tí mo sọ, ṣùgbọ́n mo fi ìwé kan sílẹ̀ fún un. Kí n tó kúrò níbẹ̀, mo ti ní ìgboyà mo sì mọ̀ pé Jèhófà ti bù kún mi. Lọ́jọ́ náà, mo fi ọ̀pọ̀ ìwé kékeré sóde ní òpópónà táwọn èèyàn ti ń tajà yẹn.”

Arábìnrin kan sọ pé: “Ní nǹkan bí ọdún 1933, ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin lo ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí wọ́n so ẹ̀rọ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ mọ́ láti máa fi wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run káàkiri.” Nígbà kan, òun àti tọkọtaya Ẹlẹ́rìí kan ń wàásù ní àgbègbè olókè kan ní ìpínlẹ̀ California, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ó rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Arákùnrin náà wa ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí wọ́n so ẹ̀rọ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ mọ́ náà lọ sí orí òkè, àwa sì wà nísàlẹ̀ nínú ìlú náà. Nígbà tó gbé àwo rẹ́kọ́ọ̀dù ìwàásù sí i, ńṣe ló dà bíi pé láti ọ̀run ni ohùn náà ti ń wá. Àwọn ará ìlú náà wá arákùnrin yìí títí, àmọ́ wọn kò rí i. Lẹ́yìn tí àwo náà parí, a tọ àwọn èèyàn náà lọ a sì wàásù fún wọn. Mo tẹ̀ lé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ méjì míì tí wọ́n so ẹ̀rọ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ mọ́, àmọ́ ńṣe ni ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn èèyàn náà kọ etí ikún sí ìwàásù wa. Síbẹ̀, kò sí bí wọn ò ṣe ní gbọ́rọ̀ wa torí pé ketekete ni wọ́n ń gbọ́ ohùn ìwàásù tó ń bú jáde látinú àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà nínú ilé wọn. Èyí mú ká rí i pé ìgbà gbogbo ni Jèhófà máa ń mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ wàásù lọ́nà tó tọ́, bó bá tó àkókò tó fẹ́ káwọn èèyàn gbọ́ ọ̀rọ̀ òun. Ọ̀nà tí wọ́n gbà wàásù yìí gba pé kí wọ́n lo ìgboyà débi tí wọ́n bá lè lò ó dé, àmọ́ kò sígbà kan tí ìgboyà náà kì í ṣe iṣẹ́ tó yẹ kó ṣe, ìyẹn sì ń mú ìyìn bá orúkọ Jèhófà.”

Láàárín ọdún 1930 sí ọdún 1944, a máa ń lo ẹ̀rọ giramafóònù àtàwọn àsọyé Bíbélì tí wọ́n gba ohùn rẹ̀ sílẹ̀ lóde ẹ̀rí. Arábìnrin kan rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sọ pé: “Arábìnrin ọ̀dọ́ kan gbé ẹ̀rọ giramafóònù dání bó ṣe ń lọ láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà. Lẹ́yìn tó ti gbé rẹ́kọ́ọ̀dù àsọyé náà sí i lẹ́nu ilẹ̀kùn tó dúró sí, ní ibi àbáwọlé kan báyìí, inú bí baálé ilé náà débi pé ó fi ẹsẹ̀ taari ẹ̀rọ giramafóònù náà síta. Àmọ́, kò sí èyíkéyìí nínú rẹ́kọ́ọ̀dù àsọyé náà tó fọ́. Àwọn ọkùnrin mẹ́ta kan tí wọ́n ń jẹun ọ̀sán nínú ọkọ̀ akẹ́rù kan tó wà nítòsí ibẹ̀ rí ohun tó ṣẹlẹ̀, wọ́n ké sí arábìnrin náà pé kó wá gbé rẹ́kọ́ọ̀dù àsọyé náà sí i káwọn lè gbọ́ ọ, wọ́n sì gba ìwé lọ́wọ́ rẹ̀. Èyí mú kó gbàgbé ìwà àìdáa tí baálé ilé yẹn hù sí i.” Ó gba ìgboyà láti fara da irú àwọn àdánwò bẹ́ẹ̀.

Arábìnrin kan náà yẹn sọ pé: “Mo rántí ìgbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í pín ìwé ìròyìn lójú pópó lọ́dún 1940. Kó tó dìgbà yẹn ńṣe la máa ń gbé ìsọfúnni káàkiri ìgboro. Àwọn arákùnrin àti arábìnrin máa ń tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ gbá ojú ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ títì, wọ́n á gbé àkọlé kan dání tó kà pé, ‘Ìsìn Jẹ́ Ìdẹkùn àti Wàyó’ àti ‘Sin Ọlọ́run àti Kristi Ọba.’ Bí wọ́n ti ń ṣe èyí, ni wọ́n tún ń fún àwọn èèyàn ní ìwé àṣàrò kúkúrú lọ́fẹ̀ẹ́. Ó gba ìgboyà kéèyàn tó lè kópa nínú àwọn apá iṣẹ́ ìsìn wa yìí, àmọ́ wọ́n mú ká ṣàṣeyọrí ohun tó jẹ́ ète Jèhófà pé kí aráyé rí àwọn èèyàn Ọlọ́run tí wọ́n ń mú orúkọ rẹ̀ tọ̀ wọ́n wá.”

Arábìnrin mìíràn sọ pé: “Ó ṣòro gan-an láti ṣe iṣẹ́ ìwé ìròyìn ní àwọn ìlú kéékèèké. Torí pé wọ́n ń ṣe inúnibíni rírorò sí àwọn Ẹlẹ́rìí nígbà yẹn. . . .  Ó gba ìgboyà láti dúró sí igun ọ̀nà kéèyàn mú ìwé ìròyìn dání kó sì máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n dábàá pé ká máa sọ nígbà yẹn. Síbẹ̀, a kì í sábàá pa ọjọ́ Saturday kankan jẹ. Nígbà míì àwọn èèyàn á yá mọ́ wa. Láwọn ìgbà míì, àwọn tí inú wọn kò dùn á pé lé wa lórí, nígbà míì tọ́rọ̀ bá sì ti rí bẹ́ẹ̀, ńṣe la máa ń dọ́gbọ́n lọ kúrò kí wọ́n má bàa gbéjà kò wá.”

Láìka inúnibíni táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fojú winá rẹ̀ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì sí, wọ́n ń fi ìgboyà bá iṣẹ́ ìwàásù wọn nìṣó. Nígbà kan tá a fi ọjọ́ mẹ́tàlélógójì [43] ṣe ìpolongo láàárín December 1, ọdún 1940 títí di January 12, ọdún 1941, nǹkan bí ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ [50,000] akéde tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà pín ìwé kékeré tó tó mílíọ̀nù mẹ́jọ fáwọn èèyàn.

Ọ̀pọ̀ àwọn àgbàlagbà tó wà nínú ètò Ọlọ́run kò jẹ́ gbàgbé àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn tó gba pé kí wọ́n lo ìgboyà. Àwọn kan sọ pé àwọn lo ìgboyà tó pọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún débi pé àwọn ò lè ṣe káwọn máà rántí àṣàyàn ọ̀rọ̀ táwọn sábà máa ń sọ pé, Lé ogun pa dà sí ibodè! A kò lè sọ bóyá irú ọ̀nà míì wà tá a máa gbà ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà kí òpin ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí tó dé. Àmọ́, bí Ọlọ́run ṣe ń tì wá lẹ́yìn, a ó máa bá a nìṣó láti fi ìgbàgbọ́ àti ìgboyà polongo ọ̀rọ̀ Jèhófà.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí tó wà ní ojú ìwé 9]

Kò sígbà tí wíwàásù Ìjọba Ọlọ́run kò gba ìgboyà