Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Adùn Ń Bẹ ní Ọwọ́ Ọ̀tún Rẹ Títí Láé”

“Adùn Ń Bẹ ní Ọwọ́ Ọ̀tún Rẹ Títí Láé”

Ìtàn Ìgbésí Ayé

“Adùn Ń Bẹ ní Ọwọ́ Ọ̀tún Rẹ Títí Láé”

GẸ́GẸ́ BÍ LOIS DIDUR ṢE SỌ Ọ́

Ǹjẹ́ o lè rántí iye ìgbà tó o ti sọ ọ́ rí nígbèésí ayé rẹ pé, ‘Ká ní mo mọ̀ ni, ọ̀tọ̀ ni ohun tí mi ò bá yàn.’ Lẹ́yìn àádọ́ta [50] ọdún tí mo ti lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, mi ò lè rántí ohun búburú kan tó kọjá àfaradà tó ṣẹlẹ̀ sí mi látàrí bí mo ṣe wà ní ọwọ́ ọ̀tún Jèhófà. Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé ìdí tí mo fi sọ bẹ́ẹ̀.

ỌDÚN 1939 ni wọ́n bí mi, ìgbèríko Saskatchewan tó wà lórílẹ̀-èdè Kánádà ni èmi àti àwọn ẹ̀gbọ́n mi obìnrin mẹ́ta pẹ̀lú àwọn àbúrò mi méjì, ọkùnrin kan àti obìnrin kan, gbé dàgbà. Kò sí wàhálà kankan fún wa ní oko wa. Lọ́jọ́ kan, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wàásù fún bàbá mi, mo sì béèrè lọ́wọ́ wọn bóyá Ọlọ́run ní orúkọ. Wọ́n fi orúkọ náà, Jèhófà, hàn wá nínú Sáàmù 83:18. Ìyẹn sì jẹ́ kí n fẹ́ láti mọ púpọ̀ sí i nípa Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Láwọn ọdún yẹn, iléèwé tó ní yàrá kan ṣoṣo ni àwọn ọmọ tó ń gbé lóko máa ń lọ títí tí wọ́n á fi pé nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́tàlá. Wọ́n máa ń gun ẹṣin tàbí kí wọ́n fi ẹsẹ̀ rin ọ̀pọ̀ ibùsọ̀ kí wọ́n tó dé iléèwé. Àwọn ìdílé tó wà ní àgbègbè náà ló máa ń pèsè ohun tí àwọn olùkọ́ bá nílò. Lọ́dún kan báyìí, àwọn òbí mi ló kàn láti gba John Didur, tó jẹ́ olùkọ́ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé wá sílé.

Mi ò tiẹ̀ mọ̀ pé ọ̀dọ́kùnrin yìí náà nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gan-an. Ìgbà kan wà tí mò ń gbóríyìn fún ìjọba Kọ́múníìsì àti ìjọba àjùmọ̀ní, èyí tí bàbá mi ń ṣagbátẹrù rẹ̀. John rọra fèsì pé: “Èèyàn kankan kò lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso ẹlòmíì. Ọlọ́run nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.” Èyí sì mú ká túbọ̀ ní ọ̀pọ̀ ìjíròrò alárinrin.

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọdún 1931 ni wọ́n bí John, ó ti gbọ́ nípa wàhálà tó bá àwọn èèyàn nígbà ogun. Nígbà tí Ogun Kòríà jà lọ́dún 1950, ó béèrè lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì pé kí ló fà á tí wọn fi ń lọ́wọ́ sí ogun. Gbogbo wọn ló sọ pé kò sí ohun tó burú nínú kí Kristẹni máa jagun. Lẹ́yìn náà, ló wá bi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìbéèrè yẹn. Wọ́n sì fi ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa ojú tí àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ fi wo ogun jíjà hàn án. John ṣe ìrìbọmi lọ́dún 1955. Ní ọdún tó tẹ̀ lé e, èmi náà ṣe ìrìbọmi. Àwa méjèèjì mọ̀ pé a fẹ́ fi ìgbésí ayé wa àti okun wa sin Jèhófà. (Sm. 37:3, 4) Ní oṣù July ọdún 1957, èmi àti John ṣe ìgbéyàwó.

Fún ọ̀pọ̀ ọdún, àpéjọ àgbègbè la sábà máa ń wà ní àyájọ́ ọjọ́ ìgbéyàwó wa. Inú wa máa ń dùn pé àárín ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún ìgbéyàwó la wà. Ọdún 1958 la kọ́kọ́ lọ sí àpéjọ àgbáyé. Àwa márùn-ún wọ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ láti ìgbèríko Saskatchewan lọ sí ìlú New York City, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ọ̀sẹ̀ kan gbáko la fi rin ìrìn àjò náà, a máa ń wakọ̀ lójúmọmọ, a sì máa ń sùn nínú àgọ́ bí ilẹ̀ bá ṣú. Ẹnu yà wá gan-an nígbà tí arákùnrin kan tá a pàdé ní ìlú Bethlehem, ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania, sọ pé ká wá sun ilé àwọn lálẹ́ ọjọ́ yẹn. Inú rere tó fi hàn sí wa jẹ́ kí aṣọ wá mọ́ tónítóní, ká sì ṣeé wò, nígbà tá a dé ìlú New York City. Àpéjọ ńlá yẹn tẹ̀ ẹ́ mọ́ wa lọ́kàn pé adùn àrà ọ̀tọ̀ ló wà nínú sísin Jèhófà. Bí onísáàmù ṣe sọ, “adùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ títí láé.”—Sm. 16:11.

IṢẸ́ AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ

Ní ọdún kan lẹ́yìn àpéjọ àgbáyé yẹn, a bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Inú ọkọ̀ àfiṣelé kékeré kan tó wà lórí òkè ní ìgbèríko Saskatchewan là ń gbé. Látibẹ̀, a máa ń rí ilẹ̀ tó fẹ̀ lọ salalu, lára wọn sì jẹ́ ìpínlẹ̀ ìwàásù wa.

Lọ́jọ́ kan, a rí lẹ́tà kan tó múnú wa dùn gbà láti ẹ̀ka ọ́fíìsì. Mo sáré lọ bá John níbi tó ti ń tún katakata kan ṣe. Ohun tó wà nínú lẹ́tà náà ni pé ká wá lọ ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní ìlú Red Lake, ní ẹkùn-ìpínlẹ̀ Ontario. Níwọ̀n bí a kò ti mọ ibẹ̀, a yára gbé àwòrán ilẹ̀ láti wá ibi tí ìlú náà wà.

Ibẹ̀ yàtọ̀ gan-an sí ibi gbalasa tí à ń gbé tẹ́lẹ̀. Ní báyìí, a máa ń rí igbó kìjikìji àtàwọn ìlú kéékèèké tí wọ́n kọ́ sí itòsí ibi tí wọ́n ti ń wa góòlù. Nígbà tí à ń wá ilé ní ọjọ́ àkọ́kọ́ tá a débẹ̀, ọmọdébìnrin kan gbọ́ ohun tí à ń bá aládùúgbò rẹ̀ sọ. Ó sáré lọ sọ fún ìyá rẹ̀ nílé, ìyá rẹ̀ sì fún wa ní ibi tí a sùn sí lálẹ́ ọjọ́ yẹn. Inú yàrá kan tí eruku ti bò, tó wà nínú àjàalẹ̀ ni wọ́n gbé ibùsùn tá a lò sí. Lọ́jọ́ kejì, a rí ilé oníyàrá méjì kan tí wọ́n fi igi kọ́. Ilé náà kò ní omi ẹ̀rọ, kò ní ohun èlò ilé, àyàfi àdògán kan tí wọ́n fi ń gbé omi kaná. A ra àwọn nǹkan díẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń ta àwọn nǹkan àlòkù, kò sì pẹ́ rárá tí ara wa fi bẹ̀rẹ̀ sí í mọlé.

Kéèyàn tó lè rí ìjọ èyíkéyìí, ó máa rin ìrìn igba ó lé mẹ́sàn-án [209] kìlómítà. Ilẹ̀ Yúróòpù ni ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ṣiṣẹ́ láwọn ibi tí wọ́n ti ń wa góòlù náà ti wá, wọ́n sì máa ń sọ pé ká bá àwọn wá Bíbélì ní èdè àwọn. Ní àkókò díẹ̀, a ti ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó jẹ́ ọgbọ̀n, àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ náà sì ń lọ déédéé. Láàárín oṣù mẹ́fà, ìjọ kékeré kan ti wà níbẹ̀.

Ọkọ obìnrin kan tí a bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ké sí àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì wọn lórí fóònù pé kó wá ṣàlàyé fún ìyàwó òun pé ẹ̀kọ́ tá a fi ń kọ́ ọ kò tọ̀nà. Nígbà tí àlùfáà náà dé, ó sọ pé ó yẹ ká fi ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan kún ẹ̀kọ́ tá a fi ń kọ́ àwọn èèyàn. Obìnrin náà gbé Bíbélì ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì jáde, ó sì ní kí àlùfáà náà fi ohun tó ń sọ han òun nínú Bíbélì. Ńṣe ni àlùfáà yẹn ju Bíbélì náà sórí tábìlì, ó sọ pé òun kò ní láti fi Bíbélì ti ọ̀rọ̀ òun lẹ́yìn. Nígbà tó fẹ́ máa lọ, ó fi èdè Ukrainian sọ fún wọn pé kí wọ́n lé wa jáde kúrò nínú ilé wọn, kí wọ́n má sì jẹ́ ká wọlé wọn mọ́. Kò mọ̀ pé John gbọ́ èdè Ukrainian!

Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tá a fi kúrò ní ìlú Red Lake, torí John fẹ́ lọ gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ láti di alábòójútó àyíká. Àmọ́, ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà, nígbà tí John ń sọ àsọyé ìrìbọmi ní àpéjọ àgbègbè, ọkọ obìnrin yẹn wà lára àwọn tó fẹ́ ṣe ìrìbọmi. Ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì yẹn wá ló mú kí ọkùnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàyẹ̀wò Bíbélì fúnra rẹ̀.

ỌWỌ́ WA DÍ LẸNU IṢẸ́ ARÌNRÌN-ÀJÒ

Nígbà tá a wà lẹ́nu iṣẹ́ arìnrìn-àjò, bá a ṣe máa ń dé sí ọ̀dọ̀ onírúurú ìdílé máa ń dùn mọ́ wa gan-an. Àwa àti àwọn tó máa ń gbà wá sílé tí wọ́n sì ń sọ bí nǹkan ṣe ń lọ sí nínú ìgbésí ayé wọn fún wa túbọ̀ mọwọ́ ara wa. Nígbà kan báyìí, a wà nínú yàrá kan nínú ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì tí kò ní ẹ̀rọ tó ń mú kí ilé móoru nígbà òtútù. A máa ń mọ̀ tí arábìnrin àgbàlagbà kan tá a dé sí ilé rẹ̀ bá rọra wọ inú yàrá wa ní òwúrọ̀ kùtùkùtù kó le tan iná sí sítóòfù kékeré kan tó wà níbẹ̀. Lẹ́yìn náà, á wá lọ gbé bàsíà kan àti omi tó lọ́ wọ́ọ́rọ́ wá, ká lè wẹ̀ ká tó jáde lọ. Mo kẹ́kọ̀ọ́ gan-an látinú bí màmá yìí ṣe máa ń ṣe jẹ́jẹ́.

Iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò mú kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. A sìn ní àyíká kan ní ẹkùn-ìpínlẹ̀ Alberta. Ìlú kan wà tí wọ́n ti ń wa àwọn ohun àlùmọ́nì inú ilẹ̀ ní apá àríwá ẹkùn-ìpínlẹ̀ yìí tó jìnnà gan-an, arábìnrin kan sì ń gbé ibẹ̀. Ojú wo ni ètò Jèhófà fi wo arábìnrin tó dá wà yẹn? Ní oṣù mẹ́fà-mẹ́fà, a máa ń wọ ọkọ̀ òfuurufú lọ síbi tó wà, a sì máa ń lo ọ̀sẹ̀ kan pẹ̀lú rẹ̀, a jọ máa ń lọ sóde ẹ̀rí, a sì máa ń ṣe ìpàdé pẹ̀lú rẹ̀ bá a ṣe máa ń ṣe nínú ìjọ táwọn ará pọ̀ sí. Èyí rán wa létí bí Jèhófà ṣe máa ń fìfẹ́ bójú tó ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àgùntàn rẹ̀ kéékèèké.

A máa ń kàn sí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń fún wa ní ilé tí à ń dé sí. Èyí mú mi rántí ọ̀kan lára àwọn ẹ̀bùn tí John kọ́kọ́ fún mi, ìyẹn àpótí mèremère kan tí ìwé àjákọ kún inú rẹ̀. A gbádùn ká máa kọ lẹ́tà sí àwọn ọ̀rẹ́ wa, a sì máa ń lo irú àwọn ohun ìkọ̀wé bẹ́ẹ̀. Mo ṣì mọyì àpótí tí ìwé àjákọ wà nínú rẹ̀ yẹn.

Nígbà tí a wà ní àyíká kan ní ìlú Toronto, arákùnrin kan tẹ̀ wá láago láti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì tó wà ní orílẹ̀-èdè Kánádà, ó sì béèrè bóyá a máa fẹ́ wá sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Àmọ́, ìgbà wo ló fẹ́ ká fún òun lésì? Ó ní: “Tó bá ṣeé ṣe, ní ọ̀la.” Ó rí èsì tó ń fẹ́ gbà.

IṢẸ́ ÌSÌN BẸ́TẸ́LÌ

Bá a ṣe ń ti inú iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún kan bọ́ sí òmíràn là ń rí onírúurú adùn tó ń ti ọwọ́ Jèhófà wá. Ó sì ń bá a lọ bẹ́ẹ̀ nígbà tá a dé Bẹ́tẹ́lì lọ́dún 1977. Bá a ṣe ń ní àjọṣe pẹ̀lú àwọn kan lára àwọn ẹni àmì òróró jẹ́ ká rí onírúurú ànímọ́ tí wọ́n ní àti bí wọ́n ṣe ní ọ̀wọ̀ gíga fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

Ìgbòkègbodò wa tuntun ní Bẹ́tẹ́lì bá wa lára mu. Bí àpẹẹrẹ, a kò tún di aṣọ wa sínú àpò mọ́, inú kọ́bọ́ọ̀dù là ń tọ́jú rẹ̀ sí, a sì tún ní ìjọ kan pàtó tá à ń dara pọ̀ mọ́. Yàtọ̀ sí iṣẹ́ tí mò ń ṣe, mímú àwọn tó wá ṣèbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì rìn yíká inú ọgbà wa tún máa ń fún mi láyọ̀. Mo máa ń ṣàlàyé iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe ní Bẹ́tẹ́lì fún àwọn ará tó wá ṣèbẹ̀wò náà, màá gbọ́ ohun tí wọ́n ní láti sọ, màá sì tún dáhùn àwọn ìbéèrè wọn.

Ọdún ń gorí ọdún, nígbà tó sì di ọdún 1997, wọ́n ní kí John wá lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ fún Àwọn Tó Wà Nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ní ìlú Patterson, ìpínlẹ̀ New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Lẹ́yìn náà, wọ́n bi wá bóyá a máa lè lọ sí orílẹ̀-èdè Ukraine. Wọ́n ní ká ronú nípa rẹ̀ dáadáa, ká sì gbàdúrà nípa rẹ̀. Nígbà tó fi máa di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, a ti gbà láti lọ.

A LỌ SÌN NÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ UKRAINE

A ti lọ ṣe àpéjọ àgbáyé ńlá kan ní ìlú St. Petersburg, lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà lọ́dún 1992, a sì ṣe òmíràn ní ìlú Kiev, lórílẹ̀-èdè Ukraine lọ́dún 1993. Àpéjọ méjèèjì yẹn ti jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa tó wà ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù. Àjà kejì ilé àtijọ́ kan báyìí tó wà ní ìlú Lviv là ń gbé nígbà tá a dé orílẹ̀-èdè Ukraine. Látinú yàrá wa, a máa ń gba ojú fèrèsé wo ọgbà kékeré kan, a sì máa ń rí àkùkọ pupa ńlá kan àti àwọn ọmọ adìyẹ níbẹ̀. Ńṣe ló máa ń ṣe mí bíi pé mo wà ní oko wa ní Saskatchewan. Àwa méjìlá là ń gbé inú ilé yẹn. Lójoojúmọ́, a máa ń tètè jí ní òwúrọ̀, a ó sì wọkọ̀ gba àárín ìgboro ìlú náà kọjá láti lọ ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì.

Báwo ni gbígbé ní orílẹ̀-èdè Ukraine ṣe rí lára wa? Bá a ṣe ń wà láàárín ọ̀pọ̀ àwọn tó ti kojú àdánwò, ìfòfindè àti ìfisẹ́wọ̀n yìí máa ń mú ká rẹ ara wa sílẹ̀. Láìka ohun tí wọ́n fojú winá rẹ̀ sí, ìgbàgbọ́ wọn ṣì lágbára. Tá a bá gbóríyìn fún wọn, ohun tí wọ́n máa ń sọ ni pé, “Jèhófà la ṣe é fún.” Kò sígbà kankan tó ṣe wọ́n bíi pé Jèhófà pa wọ́n tì. Kódà, títí di báyìí, tó o bá dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹnì kan tó ṣe ẹ́ lóore, ó ṣeé ṣe kó sọ pé, “Jèhófà ló ṣe é,” láti fi hàn pé Jèhófà ni Orísun ohun rere gbogbo.

Lórílẹ̀-èdè Ukraine, ẹsẹ̀ ni ọ̀pọ̀ àwọn ará fi ń rìn lọ sí ìpàdé, torí náà wọ́n máa ń ní àkókò láti bá ara wọn sọ̀rọ̀ àti láti fún ara wọn ní ìṣírí. Ìrìn náà sì lè gbà tó wákàtí kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ìjọ tó wà ní ìlú Lviv lé ní àádọ́ta [50], mọ́kànlélógún [21] lára wọ́n sì ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba ńlá kan. Láwọn ọjọ́ Sunday, ó máa ń gbádùn mọ́ni láti rí bí àwọn ará ṣe ń rọ́ wá sí ìpàdé.

Kò pẹ́ tá a fi mọwọ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà níbẹ̀, ara wọn balẹ̀ wọ́n sì máa ń hára gàgà láti bójú tó àwọn ẹlòmíì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣòro fún mi láti gbọ́ èdè wọn, kódà títí di báyìí, wọ́n ṣì ń ní sùúrù fún mi. Èyí sì máa ń hàn nínú ìrísí ojú wọn àti ọ̀rọ̀ onínúure tí wọ́n máa ń sọ.

Àpẹẹrẹ bí àwọn ará ṣe fọkàn tán ara wọn hàn gbangba nígbà àpéjọ àgbáyé tá a ṣe ni ìlú Kiev, lọ́dún 2003. Bá a ṣe sọ̀ kalẹ̀ látinú ọkọ̀ rélùwéè abẹ́ ilẹ̀, níbi tí èrò ti ń wọ́ tìrítìrí, ọmọdébìnrin kan wá bá wa, ó sì fohùn jẹ́jẹ́ sọ pé, “Mo ti sọ nù. Mi ò rí ìyá àgbà mọ́.” Ohun tó jẹ́ kó mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí ni wá ni báàjì tá a fi sáyà. Ẹ̀rù kò ba ọmọ náà, kò sì sunkún. Ìyàwó alábòójútó àyíká tó wà pẹ̀lú wa mú ọmọ náà lọ sí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Àwọn Ohun Tó Sọ Nù Tá A Rí He, ní pápá ìṣeré náà. Kò pẹ́ tí ọmọ náà fi rí ìyá àgbà tó ń wá. Bí ọmọ yìí ṣe fọkàn tán wa wú mi lórí gan-an ni, pẹ̀lú bí èèyàn ṣe pọ̀ bí omi níbẹ̀.

Àwọn ará láti ọ̀pọ̀ ilẹ̀ wá sí orílẹ̀-èdè Ukraine fún ìyàsímímọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tuntun lóṣù May ọdún 2001. Lẹ́yìn àkànṣe àsọyé ní pápá ìṣeré kan láàárọ̀ ọjọ́ Sunday, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ará ló wá wo Bẹ́tẹ́lì tuntun náà. Mi ò lè gbàgbé ohun tí mo rí! Ó wú mi lórí gan-an láti rí àwọn ará tí wọ́n wà létòlétò tí wọ́n sì ń lọ wọ́ọ́rọ́wọ́ yìí. Èyí mú kí n túbọ̀ mọyì adùn tó ń wá látinú sísin Ọlọ́run.

ÌYÍPADÀ DÉ LÓJIJÌ

Ó bà mí nínú jẹ́ pé lọ́dún 2004, àyẹ̀wò fi hàn pé John ní àrùn jẹjẹrẹ. A lọ sí orílẹ̀-èdè Kánádà kó lè lọ gba ìtọ́jú. Apá àkọ́kọ́ lára ìtọ́jú àkànṣe tí wọ́n fún un, èyí tó gba pé kó lo oògùn tó pọ̀, ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pọ̀ jù, ó sì lo ọ̀sẹ̀ mélòó kan níbi tí wọ́n ti ń fún un ní ìtọ́jú àkànṣe náà. Mo dúpẹ́ pé ara rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í pa dà bọ̀ sípò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò lè sọ̀rọ̀ dáadáa mọ́, ó máa ń hàn lójú rẹ̀ pé ó mọrírì gbogbo àwọn tó wá kí i.

Àmọ́, ara rẹ̀ kò yá tán, ó sì kú ní November 27, ọdún 2004. Ńṣe ló ń ṣe mí bíi pé mo pàdánù ẹ̀yà ara mi kan tó ṣe pàtàkì gan-an. Èmi àti John gbádùn iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà gan-an. Kí ni màá ṣe báyìí? Mo pinnu láti pa dà sí orílẹ̀-èdè Ukraine. Mo dúpẹ́ gan-an fún ìfẹ́ tí àwọn tá a jọ ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì àtàwọn ará nínú ìjọ fi hàn sí mi.

Kò sí ìgbà kankan nínú ìgbésí ayé wa tá a kábàámọ̀ àwọn ìpinnu tá a ṣe. Ìgbésí ayé mi dùn bí oyin, mo sì ní àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà. Mo mọ̀ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló ṣì wà láti kọ́ nípa oore Jèhófà, mo sì nírètí láti máa bá iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run nìṣó títí láé torí pé ní tòótọ́, mo ti rí ‘adùn ní ọwọ́ ọ̀tún Jèhófà.’

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

“Kò sí ìgbà kankan nínú ìgbésí ayé wa tá a kábàámọ̀ àwọn ìpinnu tá a ṣe”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Nígbà tí èmi àti John ṣègbéyàwó

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Nígbà tí mò ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní ìlú Red Lake, ní ẹkùn-ìpínlẹ̀ Ontario

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Èmi àti John rèé ní orílẹ̀-èdè Ukraine, lọ́dún 2002