Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè “Jí Lójú Oorun”
Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè “Jí Lójú Oorun”
“Ẹ mọ àsìkò, pé wákàtí ti tó nísinsìnyí fún yín láti jí lójú oorun.”—RÓÒMÙ 13:11.
ǸJẸ́ O LÈ ṢÀLÀYÉ?
․․․․․
Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí àwa Kristẹni máa wà lójúfò nípa tẹ̀mí?
․․․․․
Kí nìdí tó fi yẹ káwọn òjíṣẹ́ tó wà lójúfò máa fetí sílẹ̀ kí wọ́n sì ní àkíyèsí?
․․․․․
Ipa wo ni inú rere àti ìwà pẹ̀lẹ́ ń kó nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
1, 2. Irú oorun wo ni ọ̀pọ̀ èèyàn ń sùn, kí nìdí tó fi yẹ kí wọ́n jí kúrò lójú oorun náà?
ẸGBẸẸGBẸ̀RÚN èèyàn ló ń kú lọ́dọọdún torí pé wọ́n ń tòògbé tàbí kí wọ́n máa sùn nígbà tí wọ́n ń wakọ̀. Iṣẹ́ ń bọ́ lọ́wọ́ àwọn míì torí pé wọn kì í jí lásìkò kí wọ́n lè lọ síbi iṣẹ́ tàbí kí wọ́n máa sùn lẹ́nu iṣẹ́. Títòògbé nípa tẹ̀mí tiẹ̀ tún lè ṣàkóbá tó ju èyí lọ. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹni tí ó wà lójúfò.”—Ìṣí. 16:14-16.
2 Bí ọjọ́ ńlá Jèhófà ṣe ń sún mọ́lé, ojú oorun nípa tẹ̀mí ni aráyé lápapọ̀ wà. Kódà àwọn kan lára àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ti pe àwọn ọmọ ìjọ wọn ní ‘àwọn òmìrán tó ń sàsùnpara,’ torí pé wọ́n ń sùn nípa tẹ̀mí. Kí ni oorun nípa tẹ̀mí? Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí àwọn Kristẹni tòótọ́ wà lójúfò? Báwo la ṣe lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè jí lójú oorun nípa tẹ̀mí?
KÍ NI OORUN NÍPA TẸ̀MÍ?
3. Kí lo lè sọ nípa ẹni tí kò wà lójúfò nípa tẹ̀mí?
3 Bí èèyàn bá ń sùn kì í lè ṣe ohunkóhun. Àmọ́, ní ti àwọn tó ń sùn nípa tẹ̀mí, àwọn nǹkan tí kò ní í ṣe pẹ̀lú rírí ojú rere Ọlọ́run lè mú kí ọwọ́ wọ́n dí. Àwọn àníyàn ìgbésí ayé, wíwá ìgbádùn, ipò iyì tàbí ọrọ̀ lè mú kí ọwọ́ wọ́n dí gan-an. Gbogbo èyí kì í jẹ́ kí wọ́n lè fi ọwọ́ pàtàkì mú àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run. Àmọ́, àwọn tó wà lójúfò nípa tẹ̀mí mọ̀ pé à ń gbé “ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” torí náà wọ́n máa ń lo gbogbo àkókò wọn láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.—2 Pét. 3:3, 4; Lúùkù 21:34-36.
4. Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a máa sùn gẹ́gẹ́ bí àwọn yòókù ti ń ṣe”?
4 Ka 1 Tẹsalóníkà 5:4-8. Nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ níyànjú pé kí wọ́n má ṣe “máa sùn gẹ́gẹ́ bí àwọn yòókù ti ń ṣe.” Kí ló ní lọ́kàn? Ọ̀nà kan tá a lè gbà “máa sùn” ni pé ká má fi ọwọ́ pàtàkì mú àwọn ìlànà Jèhófà nípa bó ṣe yẹ ká máa hùwà. Ọ̀nà míì ni pé ká má kọbi ara sí i pé àkókò tí Jèhófà máa pa àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Rẹ̀ run ti sún mọ́lé. A gbọ́dọ̀ rí i dájú pé irú àwọn tí kò ṣèfẹ́ Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ kò mú ká bẹ̀rẹ̀ sí í ronú ká sì máa hùwà bíi tiwọn.
5. Èrò wo ni àwọn tó ń sùn nípa tẹ̀mí máa ń ní?
5 Àwọn kan máa ń ronú pé kò sí Ọlọ́run kankan tó máa yẹ àwọn lọ́wọ́ wò, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ tan ara wọn jẹ́. (Sm. 53:1) Àwọn míì máa ń rò pé ọ̀rọ̀ aráyé kò jẹ Ọlọ́run lógún, torí náà wọn kò rí ìdí tó fi yẹ ká ka irú Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ sí. Síbẹ̀ àwọn mìíràn máa ń rò pé lílọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ló máa sọ àwọn di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Ojú oorun nípa tẹ̀mí ni irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ wà, ó sì yẹ kí wọ́n jí lójú oorun. Báwo la ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́?
ÀWA FÚNRA WA GBỌ́DỌ̀ WÀ LÓJÚFÒ
6. Kí nìdí tí àwọn Kristẹni fi gbọ́dọ̀ máa sapá kí wọ́n má bàa sùn nípa tẹ̀mí?
6 Ká bàa lè wà nípò láti jí àwọn míì lójú oorun, àwa fúnra wa gbọ́dọ̀ wà lójúfò. Àmọ́, báwo la ṣe lè wà lójúfò? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi hàn pé oorun tẹ̀mí ní í ṣe pẹ̀lú “àwọn iṣẹ́ tí ó jẹ́ ti òkùnkùn,” irú bí àwọn àríyá aláriwo, mímu àmuyíràá, ìbádàpọ̀ tí ó tàpá sófin, ìwà àìníjàánu, gbọ́nmi-si-omi-ò-to àti owú. (Ka Róòmù 13:11-14.) Ó máa ń ṣòro láti sá fún irú àwọn nǹkan wọ̀nyí. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa wà lójúfò. Bí awakọ̀ kan bá fojú tẹ́ńbẹ́lú ewu tó wà nínú kéèyàn sùn lọ tó bá ń wakọ̀, ńṣe ló ń fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu. Torí náà, ó ṣe pàtàkì gan-an fún àwa Kristẹni láti máa wà lójúfò torí pé oorun nípa tẹ̀mí lè ṣekú pani.
7. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí wa tá a bá ní èrò tí kò tọ́ nípa àwọn tá à ń wàásù fún?
7 Bí àpẹẹrẹ, Kristẹni kan lè ronú pé gbogbo àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù òun ni kò fẹ́ gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, èyí lè sọ ọ́ di ẹni tí kì í ka nǹkan sí. (Òwe 6:10, 11) Ó sì lè máa ronú pé, ‘Bí ẹnikẹ́ni kò bá ní tẹ́tí sí ìwàásù, kí nìdí téèyàn á fi máa sapá gidigidi kó lè lọ wàásù fún wọn tàbí kó lè ràn wọ́n lọ́wọ́?’ Òótọ́ ni pé ní báyìí, ọ̀pọ̀ èèyàn lè máa sùn nípa tẹ̀mí, àmọ́ ipò wọn àti ìwà wọn lè yí pa dà. Àwọn kan máa ń ta jí wọ́n á sì gbọ́ ọ̀rọ̀ wa. Bí àwa fúnra wa bá wà lójúfò la lè ràn wọ́n lọ́wọ́. A lè ṣe èyí nípa wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún wọn ní onírúurú ọ̀nà tó máa mú kó fà wọ́n mọ́ra. Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tá a lè máa gbà wà lójúfò ni pé ká máa rán ara wa létí ìdí tí iṣẹ́ ìwàásù wa fi ṣe pàtàkì.
KÍ LÓ MÚ KÍ IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ WA ṢE PÀTÀKÌ?
8. Kí nìdí tí iṣẹ́ ìwàásù wa fi ṣe pàtàkì gan-an?
8 Fi sọ́kàn pé bí àwọn èèyàn bá gbọ́ ìwàásù wa tàbí wọn kò gbọ́, ìwàásù wa ń bọlá fún Jèhófà, ó sì tún ń kó ipa pàtàkì nínú bí ète rẹ̀ ṣe ń ní ìmúṣẹ. Láìpẹ́, Jèhófà máa fìyà jẹ àwọn tí kò bá ṣègbọràn sí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ohun táwọn èèyàn bá ṣe lẹ́yìn tá a wàásù ìhìn rere fún wọn ló máa pinnu irú ìdájọ́ tí wọ́n máa gbà. (2 Tẹs. 1:8, 9) Láfikún sí i, àṣìṣe ló máa jẹ́ fún Kristẹni kan láti ronú pé kò pọn dandan kéèyàn máa wàásù tokuntokun torí pé “àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” (Ìṣe 24:15) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ kó yé wa pé ńṣe ni àwọn tí Jésù kà sí “ewúrẹ́” máa lọ “sínú ìkékúrò àìnípẹ̀kun.” Ọlọ́run ń fi àánú tó ní sí àwọn èèyàn hàn nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù, èyí tó ń mú kó ṣeé ṣe fáwọn èèyàn láti yí pa dà kí wọ́n sì jèrè “ìyè àìnípẹ̀kun.” (Mát. 25:32, 41, 46; Róòmù 10:13-15) Bí a kò bá wàásù, báwo làwọn èèyàn ṣe máa ní àǹfààní láti gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tó lè túmọ̀ sí ìgbàlà fún wọn?
9. Báwo ni ìwọ àtàwọn míì ṣe ń jàǹfààní látinú wíwàásù ìhìn rere?
9 A tún máa ń jàǹfààní látinú wíwàásù ìhìn rere. (Ka 1 Tímótì 4:16.) Ǹjẹ́ o ti kíyè sí i pé sísọ̀rọ̀ nípa Jèhófà àti àwọn ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe ń fún ìgbàgbọ́ rẹ lágbára ó sì tún ń mú kí ìfẹ́ tó o ní fún Ọlọ́run pọ̀ sí i? Ǹjẹ́ kò sì ti ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ní àwọn ànímọ́ Kristẹni? Ǹjẹ́ bó o ṣe ń fọkàn sin Ọlọ́run nípa wíwàásù kì í jẹ́ kí ayọ̀ rẹ túbọ̀ pọ̀ sí i? Ọ̀pọ̀ àwọn tó ti ní àǹfààní láti fi òtítọ́ kọ́ àwọn míì ti láyọ̀ gan-an torí pé wọ́n ti rí bí ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe mú kí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà gbé ìgbé ayé wọn sunwọ̀n sí i.
Ẹ JẸ́ ẸNI TÓ NÍ ÀKÍYÈSÍ
10, 11. (a) Báwo ni Jésù àti Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé àwọn jẹ́ ẹni tó wà lójúfò tó sì tún ní àkíyèsí? (b) Sọ bá a ṣe lè mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa sunwọ̀n sí i tá a bá wà lójúfò tá a sì tún ní àkíyèsí.
10 Onírúurú ọ̀nà ló wà tá a lè gbà mú kí ẹnì kọ̀ọ̀kan nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere. Torí náà, àwa Kristẹni tá à ń wàásù ìhìn rere gbọ́dọ̀ ní àkíyèsí. Àpẹẹrẹ Jésù là ń tẹ̀ lé. Níwọ̀n bí Jésù ti jẹ́ ẹni pípé, ó mọ̀ pé inú ń bí Farisí kan bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sọ ohunkóhun, ó mọ̀ pé obìnrin kan tó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ronú pìwà dà látọkàn wá, ó sì mọ̀ pé obìnrin opó kan ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ. (Lúùkù 7:37-50; 21:1-4) Jésù lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ torí pé ó mọ ohun tí wọ́n ṣaláìní. Àmọ́, kò dìgbà tí ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan bá di ẹni pípé kó tó lè mọ béèyàn ṣe máa ń kíyè sí nǹkan dáadáa. A lè rí àpẹẹrẹ èyí lára àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Bó ṣe máa ń gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kalẹ̀ máa ń fa onírúurú àwùjọ àtàwọn èèyàn mọ́ra bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà wọn yàtọ̀ síra.—Ìṣe 17:22, 23, 34; 1 Kọ́r. 9:19-23.
11 Tá a bá ń sapá láti wà lójúfò tá a sì ní àkíyèsí bíi ti Jésù àti Pọ́ọ̀lù, a lè fòye mọ ọ̀nà tó dára jù lọ tá a lè gbà mú káwọn tá à ń bá pàdé nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́. Bí àpẹẹrẹ, bó bá kù díẹ̀ kó o dé ọ̀dọ̀ ẹnì kan, kíyè sí àwọn àmì tó lè jẹ́ kó o mọ àṣà ìbílẹ̀ rẹ̀, ohun tó nífẹ̀ẹ́ sí, tàbí ipò tí ìdílé rẹ̀ wà. Bóyá o lè kíyè sí ohun tí wọ́n ń ṣe lọ́wọ́ kó o sì bá wọn sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ nípa rẹ̀ tó o bá bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ.
12. Tá a bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ ṣọ́ra nípa ọ̀rọ̀ tá à ń sọ?
12 Tá a bá wà lójúfò lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, a kò ní jẹ́ kí ohunkóhun fa ìpínyà ọkàn fún wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè ní ìjíròrò tó ń gbéni ró pẹ̀lú ẹni tá a jọ ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Síbẹ̀, ó yẹ ká rántí pé torí ká lè wàásù fáwọn èèyàn la ṣe ń jáde òde ẹ̀rí. (Oníw. 3:1, 7) Torí náà, bá a ṣe ń lọ láti ilé kan sí èkejì, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí ọ̀rọ̀ tá à ń sọ pẹ̀lú ẹni tá a jọ ń ṣiṣẹ́ má ṣe gbé ọkàn wa kúrò nínú iṣẹ́ ìwàásù wa. Ọ̀nà kan tó dára tá a lè gbà pọkàn pọ̀ sórí ohun tá a torí rẹ̀ lọ sóde ẹ̀rí ni pé ká máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tá a máa fẹ́ láti bá àwọn tó bá fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa sọ. Bákan náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé fóònù alágbèéká lè wúlò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa láwọn ìgbà míì, a gbọ́dọ̀ rí i dájú pé bá a ṣe ń lo fóònù wa kò pàkúta sí ọ̀rọ̀ tá à ń bá onílé sọ.
FI HÀN PÉ Ọ̀RỌ̀ ÀWỌN ÈÈYÀN JẸ Ọ́ LÓGÚN
13, 14. (a) Báwo la ṣe lè fòye mọ ohun tí ẹnì kan nífẹ̀ẹ́ sí? (b) Kí ló lè mú káwọn èèyàn fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run?
13 Àwọn òjíṣẹ́ tí wọ́n wà lójúfò tí wọ́n sì ní àkíyèsí máa ń fara balẹ̀ fetí sí àwọn tí wọ́n bá bá pàdé. Àwọn ìbéèrè wo ló lè mú kí ẹni tó o bá pàdé ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀? Ṣé ó ń ṣàníyàn nípa bí ìsìn ṣe pọ̀ rẹpẹtẹ, báwọn èèyàn ṣe ń hùwà ipá ní àdúgbò tó ń gbé, tàbí bí ìjọba èèyàn ṣe ń kùnà? Ǹjẹ́ o lè mú káwọn èèyàn kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run nípa ṣíṣàlàyé ọ̀nà àgbàyanu tí Ọlọ́run gbà dá àwọn nǹkan ẹlẹ́mìí fún wọn tàbí kó o mú kí wọ́n rí bí ìmọ̀ràn Bíbélì ṣe gbéṣẹ́ tó? Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ sí àdúrà, tó fi mọ́ àwọn tí kò gbà pé Ọlọ́run wà pàápàá. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ń ṣe kàyéfì pé bóyá ni ẹnikẹ́ni ń gbọ́ àdúrà àwọn. Àwọn ìbéèrè kan sì wà tó lè fa àwọn kan lọ́kàn mọ́ra, irú bíi: Ǹjẹ́ gbogbo àdúrà ni Ọlọ́run ń gbọ́? Bí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀, kí la gbọ́dọ̀ ṣe kí Ọlọ́run lè gbọ́ àdúrà wa?
14 Ó ṣeé ṣe ká kẹ́kọ̀ọ́ ohun tó pọ̀ nípa bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú àwọn èèyàn tá a bá ń kíyè sí bí àwọn akéde tó ní ìrírí ṣe ń gbé ọ̀rọ̀ wọn kalẹ̀. Kíyè sí bí wọ́n ṣe máa ń bi onílé ní ìbéèrè láìjẹ́ kó dà bíi pé ńṣe ni wọ́n ń fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò tàbí pé wọ́n ń ṣe ojúmìító. Báwo ni ohùn tí wọ́n fi sọ̀rọ̀ àti ìrí ojú wọn ṣe fi hàn pé òótọ́ ni wọ́n fẹ́ láti lóye ohun tí onílé ní lọ́kàn?—Òwe 15:13.
BÁ A ṢE LÈ JẸ́ ONÍNÚÚRE ÀTI Ọ̀JÁFÁFÁ
15. Kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́ onínúure lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa?
15 Ṣé o máa fẹ́ kí ẹnì kan jí ẹ tó o bá sun oorun àsùnwọra? Kì í tu ọ̀pọ̀ èèyàn lára bí wọ́n bá ṣàdédé jí wọn lójú oorun. Ohun tó dára jù lọ ni pé kí wọ́n rọra jí ẹni tó bá wà lójú oorun. Bákan náà ni ọ̀rọ̀ rí tá a bá ń sapá láti mú káwọn èèyàn ta jí lójú oorun nípa tẹ̀mí. Bí àpẹẹrẹ, bí ẹnì kan bá bínú nígbà tó o lọ wàásù fún un, kí ló dára jù lọ pé kó o ṣe? Jẹ́ kó mọ̀ pé o kò wá láti ṣe ohun tó máa mú un bínú, lẹ́yìn náà, dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ pé kò fi ọ̀rọ̀ sí abẹ́ ahọ́n sọ, kó o sì fi ibẹ̀ sílẹ̀ jẹ́ẹ́. (Òwe 15:1; 17:14; 2 Tím. 2:24) Inú rere tó o fi hàn lè mú kí irú èèyàn bẹ́ẹ̀ ṣe dáadáa nígbà míì tí Ẹlẹ́rìí kan bá lọ wàásù fún un.
16, 17. Báwo la ṣe lè lo òye lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa?
16 Láwọn ìgbà míì, bí onílé bá rò pé ọ̀nà tó rọrùn jù tí òun lè fi bẹ́gi dínà ọ̀rọ̀ rẹ ní kí òun sọ pé, “Rárá, mi ò fẹ́ gbọ́. Mo ní ìsìn tèmi” tàbí, “Mi ò nífẹ̀ẹ́ sí i,” ó ṣì lè ṣeé ṣe fún ẹ láti máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. Tó o bá jẹ́ ọ̀jáfáfá, tí o kò sì juwọ́ sílẹ̀, ó ṣeé ṣe kó o lè bi onílé náà ní ìbéèrè kan tó máa fà á lọ́kàn mọ́ra èyí tó máa jẹ́ kó fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run.—Ka Kólósè 4:6.
17 Nígbà míì, tá a bá pàdé àwọn èèyàn tí wọ́n rò pé ọwọ́ àwọn ti dí jù láti tẹ́tí sílẹ̀, ohun tó dára jù lọ ni pé ká jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a rí i bẹ́ẹ̀, ká sì fi ibẹ̀ sílẹ̀. Àmọ́, àwọn ìgbà míì wà tó o lè fi òye mọ̀ pé o lè sọ ọ̀rọ̀ ṣókí tó sì nítumọ̀. Àwọn ará kan máa ń ṣí Bíbélì, wọ́n á ka ẹsẹ kan tó ń múni ronú jinlẹ̀, wọ́n á sì bi onílé ní ìbéèrè kan tí wọ́n máa dáhùn nígbà tí wọ́n bá pa dà wá, kò sì ní gbà wọ́n tó ìṣẹ́jú kan. Ìgbà míì wà tí irú ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ ṣókí tí wọ́n lò ti mú kí onílé ní ìfẹ́ ọkàn tó pọ̀ débi tó fi wá rí i pé ọwọ́ òun kò dí jù láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ṣókí. Ìwọ náà lè gbìyànjú rẹ̀ wò bó o bá wà nípò láti ṣe bẹ́ẹ̀.
18. Kí la lè ṣe ká lè túbọ̀ já fáfá tá a bá ń jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà?
18 Ó máa ṣeé ṣe fún wa láti mú kí àwọn èèyàn tá à ń bá pàdé nínú ìgbòkègbodò wa ojoojúmọ́ fẹ́ láti gbọ́ ìhìn rere, tá a bá ń wà ní ìmúrasílẹ̀ láti jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà. Ọ̀pọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin máa ń kó ìwé sínú àpò aṣọ wọn tàbí kí wọ́n kó wọn sínú báàgì. Wọ́n tún lè ní ẹsẹ Bíbélì kan pàtó lọ́kàn tí wọ́n máa fẹ́ láti fi bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ bí àǹfààní bá ṣí sílẹ̀. O lè bá alábòójútó iṣẹ́-ìsìn tàbí àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó wà ní ìjọ rẹ sọ̀rọ̀ pé kí wọ́n ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ bó o ṣe lè máa múra sílẹ̀.
BÁ A ṢE LÈ FỌGBỌ́N RAN ÀWỌN ÌBÁTAN WA LỌ́WỌ́
19. Kí nìdí tí a kò fi gbọ́dọ̀ jẹ́ kó sú wa láti ran àwọn ìbátan wa lọ́wọ́?
19 Ohun tó máa ń wù wá jù lọ ni pé ká wàásù ìhìn rere fún àwọn ìbátan wa kí wọ́n lè di ìránṣẹ́ Jèhófà. (Jóṣ. 2:13; Ìṣe 10:24, 48; 16:31, 32) Bí àwọn ìbátan wa kò bá tẹ́tí sí wa nígbà tá a kọ́kọ́ bá wọn sọ̀rọ̀, ìyẹn lè mú kó sú wa láti gbìyànjú lẹ́ẹ̀kan sí i. A lè máa ronú pé kò sí ohun tá a lè ṣe tàbí ohun tá a lè sọ tó máa yí ìwà wọn pa dà. Síbẹ̀, àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tó o kọ́kọ́ bá wọn sọ̀rọ̀ lè ti yí ìgbésí ayé wọn tàbí ojú tí wọ́n fi ń wo nǹkan pa dà. Ó sì ṣeé ṣe kó o ti túbọ̀ já fáfá nínú béèyàn ṣe ń ṣàlàyé òtítọ́ débi pé wọ́n á fẹ́ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ báyìí.
20. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa lo ọgbọ́n tá a bá ń bá àwọn ìbátan wa sọ̀rọ̀?
20 Ó yẹ ká máa gba bí ọ̀rọ̀ bá ṣe rí lára àwọn ìbátan wa rò. (Róòmù 2:4) Ǹjẹ́ kò yẹ ká máa bá àwọn ìbátan wa sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ bá a ti ń ṣe fáwọn tá à ń bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? Ẹ jẹ́ ká máa fi ohùn tútù bá wọn sọ̀rọ̀ ká sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn. Bí kì í tilẹ̀ ṣe gbogbo ìgbà la ó máa wàásù fún wọn, ó yẹ ká jẹ́ kí wọ́n rí ọ̀nà tí òtítọ́ ti gbà ràn wá lọ́wọ́. (Éfé. 4:23, 24) Mú kó ṣe kedere sí wọn pé ohun tó mú kó o máa gbé ìgbé ayé tó sàn jù ni pé Jèhófà ti “kọ́ [ẹ] kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní.” (Aísá. 48:17) Jẹ́ kí àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ rí àpẹẹrẹ bó ṣe yẹ kí Kristẹni kan máa gbé ìgbé ayé rẹ̀ lára rẹ.
21, 22. Sọ ìrírí kan tó jẹ́ ká rí àǹfààní tó wà nínú pé ká má juwọ́ sílẹ̀ tá a bá ń ran àwọn ìbátan wa lọ́wọ́ kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.
21 Láìpẹ́ yìí, arábìnrin kan kọ̀wé pé: “Gbogbo ìgbà ni mo máa ń fi ìwà àti ọ̀rọ̀ ẹnu mi wàásù fún àwọn tẹ̀gbọ́n tàbúrò mi, lọ́kùnrin àti lóbìnrin, tí gbogbo wọn jẹ́ mẹ́tàlá. Mi ò kì ń jẹ́ kí ọdún kan kọjá lọ láì kọ̀wé sí wọn lọ́kọ̀ọ̀kan. Síbẹ̀, èmi nìkan ṣoṣo ní Ẹlẹ́rìí nínú ìdílé wa láti ọgbọ̀n [30] ọdún sẹ́yìn.”
22 Arábìnrin náà ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Lọ́jọ́ kan, mo fi fóònù pe ọ̀kan lára àwọn ẹ̀gbọ́n mi obìnrin tó ń gbé ní ibi tó jìn gan-an. Ó sọ fún mi pé òun ní kí bàbá ìjọ òun máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tí mo sọ fún un pé inú mi á dùn láti ràn án lọ́wọ́, ó sọ pé: ‘Ó dára, àmọ́ mo fẹ́ kó o mọ̀ ní báyìí pé: Mi ò ní di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láé.’ Lẹ́yìn tí mo fi ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? ránṣẹ́ sí i, mo máa ń pè é lórí fóònù lóòrèkóòrè. Àmọ́ kò tíì ṣí ìwé náà wò títí dìgbà yẹn. Níkẹyìn, mo ní kó lọ mú ìwé náà, a lo ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún láti kà á lórí fóònù, a sì jíròrò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n kọ síbẹ̀. Lẹ́yìn tá a ti ṣe bẹ́ẹ̀ láwọn ìgbà mélòó kan, ó fẹ́ ká máa lò ju ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lọ láti fi kẹ́kọ̀ọ́. Lẹ́yìn náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í pè mí lórí fóònù ká lè jọ máa ṣèkẹ́kọ̀ọ́. Nígbà míì, ó lè jẹ́ kí n tó jí ní òwúrọ̀, ó sì máa ń tó ìgbà méjì lóòjọ́ láwọn ọjọ́ míì. Ní ọdún tó tẹ̀ lé e, ó ṣèrìbọmi, ní ọdún tó tẹ̀ lé ìyẹn, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà.”
23. Kí nìdí tí kò fi yẹ kó rẹ̀ wá tá a bá ń sapá láti jí àwọn èèyàn lójú oorun nípa tẹ̀mí?
23 Ká bàa lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti jí lójú oorun nípa tẹ̀mí, ó gba pé ká já fáfá ká sì máa sapá láìdáwọ́ dúró. Bá a ṣe ń sapá láti ran àwọn ọlọ́kàn tútù lọ́wọ́, wọ́n ń gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Kárí ayé lóṣooṣù, ìpíndọ́gba àwọn tó ń ṣe ìrìbọmi tí wọ́n sì ń di Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà ju ọ̀kẹ́ kan [20,000] lọ. Torí náà, ẹ jẹ́ ká fi ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún Ákípọ́sì, tó jẹ́ arákùnrin wa kan ní ọ̀rúndún kìíní sọ́kàn. Ó ní: “Máa ṣọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí o tẹ́wọ́ gbà nínú Olúwa, kí o lè mú un ṣẹ.” (Kól. 4:17) Àpilẹ̀kọ tó kàn máa jẹ́ kí gbogbo wa mọ ohun tó túmọ̀ sí láti máa fi sọ́kàn pé iṣẹ́ ìwàásù jẹ́ kánjúkánjú.
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 13]
ÀWỌN OHUN TÓ LÈ MÚ KÓ O MÁA WÀ LÓJÚFÒ
▪ Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ dí lẹ́nu ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run
▪ Sá fún àwọn iṣẹ́ tí í ṣe ti òkùnkùn
▪ Mọ ewu tó wà nínú kéèyàn máa tòògbé nípa tẹ̀mí
▪ Máa ní èrò rere nípa àwọn èèyàn tí wọ́n wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù rẹ
▪ Máa wàásù fáwọn èèyàn ní onírúurú ọ̀nà
▪ Máa rántí bí iṣẹ́ ìwàásù rẹ ti ṣe pàtàkì tó