Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àádọ́rin Ọdún Rèé Tí Mo Ti Ń Di Ibi Gbígbárìyẹ̀ Lára Aṣọ Ẹni Tí Í Ṣe Júù Mú

Àádọ́rin Ọdún Rèé Tí Mo Ti Ń Di Ibi Gbígbárìyẹ̀ Lára Aṣọ Ẹni Tí Í Ṣe Júù Mú

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Àádọ́rin Ọdún Rèé Tí Mo Ti Ń Di Ibi Gbígbárìyẹ̀ Lára Aṣọ Ẹni Tí Í Ṣe Júù Mú

Gẹ́gẹ́ bí Leonard Smith ṣe sọ ọ́

Nígbà tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ lé ní ọmọ ọdún mẹ́tàlá, ibi méjì kan wà nínú Bíbélì tó wọ̀ mí lọ́kàn. Gbogbo ẹ̀ ti lé ní àádọ́rin [70] ọdún báyìí, àmọ́ mo ṣì lè rántí ìgbà tí mo lóye ohun tó wà nínú Sekaráyà 8:23. Èyí tó sọ nípa àwọn “ọkùnrin mẹ́wàá” tí wọ́n ń di “ibi gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ ọkùnrin kan tí ó jẹ́ Júù” mú. Wọ́n sọ fún Júù náà pé: “Àwa yóò bá yín lọ, nítorí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.”

ỌKÙNRIN JÚÙ náà dúró fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, àwọn “ọkùnrin mẹ́wàá” náà dúró fún “àwọn àgùntàn mìíràn” tàbí “àwọn Jónádábù” gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń pè wọ́n nígbà yẹn. * (Jòh. 10:16) Nígbà tí mo lóye òtítọ́ yìí, mo wá rí i pé kí n tó lè gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé, mo ní láti máa ṣètìlẹ́yìn fún ẹgbẹ́ àwọn ẹni àmì òróró láìyẹsẹ̀.

Àkàwé “àwọn àgùntàn” àti “àwọn ewúrẹ́” tí Jésù ṣe nínú Mátíù 25:31-46 tún wú mi lórí gan-an. “Àwọn àgùntàn” dúró fún àwọn tó rí ojú rere Ọlọ́run ní àkókò òpin torí pé wọ́n ṣe dáadáa sí àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Kristi tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé. Ọ̀dọ́ ni mí, mo sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Jónádábù, ìyẹn mú kí n sọ fún ara mi pé, ‘Len, tó o bá fẹ́ kí Kristi kà ẹ́ mọ́ àgùntàn rẹ̀, o ní láti máa ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin rẹ̀, kó o sì máa gba ibi tí wọ́n bá darí rẹ sí.’ Ó ti lé ní àádọ́rin [70] ọdún báyìí tí òye tí mo ní yìí ti ń tọ́ mi sọ́nà.

‘KÍ NI OJÚṢE MI?’

Ọdún 1925 ni màmá mi ṣe ìrìbọmi ní gbọ̀ngàn ìpàdé kan tó wà ní Bẹ́tẹ́lì. Orúkọ tí wọ́n ń pe gbọ̀ngàn náà ni London Tabernacle, àwọn ará tó ń gbé ní àgbègbè ibẹ̀ ló sì ń lò ó. Wọ́n bí mi ní October 15, ọdún 1926. Mo ṣe ìrìbọmi ní oṣù March, ọdún 1940, nígbà àpéjọ kan tá a ṣe ní ìlú Dover tó wà ní etíkun orílẹ̀-èdè England. Bí mo ṣe ń dàgbà ni mo túbọ̀ ń nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀kan lára àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ni màmá mi, màmá mi ni Júù tí mo kọ́kọ́ di ‘ibi gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ’ rẹ̀ mú. Nígbà yẹn, bàbá mi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin kò tíì máa sin Jèhófà. Ìjọ Gillingham tó wà ní gúúsù ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè England ni à ń dara pọ̀ mọ́, ọ̀pọ̀ àwọn ará ìjọ náà ló sì jẹ́ ẹni àmì òróró. Màmá mi máa ń fi ìtara wàásù, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀.

Ní àpéjọ àgbègbè kan tá a ṣe ní ìlú Leicester lóṣù September ọdún 1941, a gbọ́ àsọyé kan tó dá lórí ìwà títọ́. Olùbánisọ̀rọ̀ náà sì ṣàlàyé nípa ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. Nínú àsọyé yẹn ni mo ti kọ́kọ́ lóye pé ọ̀ràn tó wáyé láàárín Sátánì àti Jèhófà kàn wá. Torí náà, a gbọ́dọ̀ fi hàn pé ti Jèhófà la jẹ́ ká sì máa pa ìwà títọ́ wa sí i mọ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run.

Ní àpéjọ àgbègbè yẹn, wọ́n tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ìsìn aṣáájú-ọ̀nà, wọ́n sì gba àwọn èwe níyànjú pé kí wọ́n fi ṣe àfojúsùn wọn. Àsọyé kan tó ní àkòrí náà “Ojúṣe Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà Nínú Ètò Ọlọ́run” mú kí n bi ara mi pé ‘Kí ni ojúṣe mi?’ Àpéjọ àgbègbè yẹn ló mú un dá mi lójú pé ojúṣe mi gẹ́gẹ́ bíi Jónádábù kan ni pé kí n máa fi gbogbo agbára mi ran ẹgbẹ́ àwọn ẹni àmì òróró lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù. Torí náà, ní àpéjọ tá a ṣe ni ìlú Leicester yẹn ni mo ti fọwọ́ sí ìwé ìwọṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.

IṢẸ́ ÌSÌN AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ NÍGBÀ OGUN

Ní December 1, ọdún 1941, nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, wọ́n yàn mí láti sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Màmá mi ni aṣáájú-ọ̀nà àkọ́kọ́ tí mo bá ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n lẹ́yìn nǹkan bí ọdún kan, màmá mi ní láti fi iṣẹ́ ìsìn aṣáájú-ọ̀nà sílẹ̀ nítorí àìlera wọn. Ẹ̀ka Ọ́fíìsì tó wà ní London wá ní kí èmi àti Arákùnrin Ron Parkin jọ máa ṣiṣẹ́, ní báyìí ó wà lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka lórílẹ̀-èdè Puerto Rico.

Wọ́n rán wa lọ sí ìlú Broadstairs àti ìlú Ramsgate tí wọ́n wà ní etíkun ní ẹkùn ìpínlẹ̀ Kent, a sì gba yàrá kan níbẹ̀. Owó ìtìlẹyìn tí wọ́n máa ń fún àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe lóṣooṣù nígbà yẹn jẹ́ nǹkan bíi dọ́là mẹ́jọ owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Torí náà, tá a bá ti san owó ilé wa, owó díẹ̀ ló máa ń ṣẹ́ kù sí wa lọ́wọ́, a kì í sì í mọ bá a ṣe máa rí owó ra oúnjẹ bí ebi bá dé. Àmọ́ lọ́nà kan tàbí òmíràn, Jèhófà máa ń pèsè àwọn ohun tá a nílò fún wa.

Kẹ̀kẹ́ la sábà máa ń gùn, a ó sì di ẹrù sorí rẹ̀, ṣùgbọ́n bí ẹ̀fúùfù tó ń fẹ́ wá láti okùn Àtìláńtíìkì bá bì lù wá, ńṣe la máa ń fi tagbáratagbára wà á. A tún fojú winá ewu àwọn ọkọ̀ òfúrufú tó ń rọ̀jò ọta àtàwọn àdó olóró tó ń fò níbàǹbalẹ̀ gba ẹkùn ìpínlẹ̀ Kent lọ sí ìlú London láti lọ ṣọṣẹ́. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí mo ní láti fò látorí kẹ̀kẹ́ mi tí mo sì bẹ́ sínú kòtò kan nígbà tí bọ́ǹbù kan fò gba orí mi kọjá tó sì lọ bú gbàù nínú pápá kan tó wà nítòsí ibẹ̀. Síbẹ̀ náà, àwọn ọdún tá a fi ṣe aṣáájú-ọ̀nà ní ẹkùn ìpínlẹ̀ Kent lárinrin.

MO LỌ SÌN NÍ BẸ́TẸ́LÌ

Màmá mi sábà máa ń sọ ọ̀rọ̀ tó dáa nípa Bẹ́tẹ́lì. Wọ́n máa ń sọ pé, “kò sí nǹkan tó máa wù mí bíi pé kí ìwọ náà lọ sìn ní Bẹ́tẹ́lì.” Nítorí náà, ní oṣù January, ọdún 1946, nígbà tí mo gba lẹ́tà kan tí wọ́n fi pè mí pé kí n wá ràn wọ́n lọ́wọ́ ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní London fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta, ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi, ayọ̀ mi sì kún. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́ta náà, Arákùnrin Pryce Hughes tó jẹ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ka sọ pé kí n dúró sí Bẹ́tẹ́lì. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí mo gbà níbẹ̀ wúlò fún mi jálẹ̀ ìgbésí ayé mi.

Nǹkan bí ọgbọ̀n [30] ni àwọn tó wà nínú ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà ní London nígbà yẹn, ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn ló jẹ́ ọ̀dọ́kùnrin tí kò tíì ṣègbéyàwó. Bákan náà, àwọn arákùnrin mélòó kan tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró wà níbẹ̀, lára wọn ni Pryce Hughes, Edgar Clay àti Jack Barr tó wá di ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí lẹ́yìn ìgbà yẹn. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́, àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún mi láti máa ṣètìlẹ́yìn fún àwọn arákùnrin Kristi tó jẹ́ “ọwọ̀n” yìí, nípa ṣíṣe iṣẹ́ lábẹ́ àbójútó wọn nípa tẹ̀mí!—Gál. 2:9.

Lọ́jọ́ kan, arákùnrin kan sọ fún mi pé arábìnrin kan wà lẹ́nu ọ̀nà àbáwọlé tó ń béèrè mi. Ó yà mí lẹ́nu pé màmá mi ni arábìnrin náà, wọ́n sì fi nǹkan kan há abíyá. Wọ́n ní àwọn kò ní wọlé káwọn má bàa dí mi lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ mi, àmọ́ wọ́n gbé nǹkan náà fún mi wọ́n sì lọ. Ẹ̀wù òtútù kan ló wà nínú rẹ̀. Bí màmá mi ṣe fìfẹ́ hàn sí mi yìí rán mi létí bí Hánà ṣe máa ń mú aṣọ lọ fún Sámúẹ́lì ọmọdékùnrin rẹ̀ nígbà tí ó ń sìn nínú àgọ́ ìjọsìn.—1 Sám. 2:18, 19.

MÁNIGBÀGBÉ NI ILÉ Ẹ̀KỌ́ GÍLÍÁDÌ JẸ́ FÚN MI

Ní Ọdún 1947, wọ́n pe márùn-ún lára àwa tá à ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, a sì lọ sí kíláàsì kọkànlá ní ọdún tó tẹ̀ lé e. Nígbà tá a dé ibi tí ilé ẹ̀kọ́ náà wà ní apá àríwá ìlú New York, otútù ibẹ̀ pọ̀ gan-an. Ṣùgbọ́n, inú mi dùn gan-an pé ẹ̀wù otútù tí màmá mi fún mi ṣì wà lọ́wọ́ mi!

Mánigbàgbé ni oṣù mẹ́fà tí mo lò ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì jẹ́ fún mi. Bí mo ṣe ń ní ìfararora pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè mẹ́rìndínlógún [16] ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ mú kí ojú tí mo fi ń wo nǹkan yí pa dà. Ní àfikún sí àwọn àǹfààní tí mo rí nípa tẹ̀mí ní ilé ẹ̀kọ́ náà, mo tún jàǹfààní nínú àjọṣe tí mo ní pẹ̀lú àwọn Kristẹni tó dàgbà nípa tẹ̀mí. Nígbà tó yá, Lloyd Barry tá a jọ jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́, Albert Schroeder tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ wa àti John Booth tó jẹ́ alábòójútó Oko Society (ibi tí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì wà nígbà náà) di ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Mo mọyì ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tí àwọn arákùnrin wọ̀nyí fún mi àti bí ìdúróṣinṣin wọn sí Jèhófà àti ètò rẹ̀ ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà fún mi.

MO DI ALÁBÒÓJÚTÓ ÀYÍKÁ MO SÌ TÚN PA DÀ SÍ BẸ́TẸ́LÌ

Bí mo ṣe ń ṣe tán ní Gílíádì, wọ́n yàn mí pé kí n lọ ṣe iṣẹ́ alábòójútó àyíká ní ìpínlẹ̀ Ohio, ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21] ni mí nígbà yẹn, àmọ́ àwọn ará ibẹ̀ gbà mí tọwọ́tẹsẹ̀ láìka ti ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ tó ṣì wà lára mi sí. Mo kẹ́kọ̀ọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ látọ̀dọ̀ àwọn àgbàlagbà onírìírí tó wà ní àyíká yẹn.

Lẹ́yìn oṣù díẹ̀, wọ́n pè mí pa dà sí Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn pé kí n wá gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ síwájú sí i. Láàárín àkókò yẹn ni mo mọ àwọn kan tó jẹ́ ọwọ̀n nínú ètò Ọlọ́run, irú bíi Milton Henschel, Karl Klein, Nathan Knorr, T. J. (Bud) Sullivan àti Lyman Swingle, gbogbo wọn ló ti fìgbà kan rí jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Ìrírí amóríyá ló jẹ́ láti rí wọn lẹ́nu iṣẹ́, kéèyàn sì rí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà gbé ìgbésí ayé wọn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Èyí wá mú kí ìgbọ́kànlé tí mo ní nínú ètò Jèhófà pọ̀ sí i. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n rán mi pa dà sí ilẹ̀ Yúróòpù láti máa bá iṣẹ́ ìsìn mi nìṣó.

Màmá mi kú ní oṣù February, ọdún 1950. Lẹ́yìn ètò ìsìnkú wọn, mo bá bàbá mi àti Dora ẹ̀gbọ́n mi obìnrin sọ òdodo ọ̀rọ̀. Mo béèrè bóyá wọ́n á pinnu pé àwọn máa kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ní báyìí tí màmá mi ti kú, tí èmi náà sì ti fi ilé sílẹ̀. Wọ́n mọ arákùnrin àgbàlagbà ẹni àmì òróró kan tó ń jẹ́ Harry Browning wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún un, torí náà wọ́n gbà kó kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Láàárín ọdún kan, bàbá mi àti Dora ṣe ìrìbọmi. Nígbà tó yá, wọ́n yan Bàbá mi gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ nínú ìjọ Gillingham. Lẹ́yìn ikú Bàbá wa, Dora àti alàgbà kan tó ń jẹ́ Roy Moreton ṣe ìgbéyàwó, Dora sì fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà títí di ìgbà ikú rẹ̀ ní ọdún 2010.

MO LỌ ṢÈRÀNWỌ́ NÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ FARANSÉ

Nígbà tí mo wà ní ilé ẹ̀kọ́ ìjọba, mo kọ́ èdè Faransé, Jámánì àti Látìn. Àmọ́, èdè Faransé ló le jù fún mi láti kọ́ nínú èdè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Torí bẹ́ẹ̀, ó ṣe mí bákan nígbà tí wọ́n ní kí n lọ ṣèrànwọ́ ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní ìlú Paris ní orílẹ̀-èdè Faransé. Nígbà tí mo dé ibẹ̀ mo ní àǹfààní láti bá arákùnrin àgbàlagbà kan tó ń jẹ́ Henri Geiger ṣiṣẹ́, ẹni àmì òróró ni, òun sì ni ìránṣẹ́ ẹ̀ka. Lóòótọ́ iṣẹ́ yìí kò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn, mo sì ṣe ọ̀pọ̀ àṣìṣe, àmọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan ni mo rí kọ́ nípa bí mo ṣe lè máa bá àwọn èèyàn gbé pọ̀ ní àlàáfíà.

Ní àfikún sí i, ní ọdún 1951, mo wà lára àwọn tó ṣètò àpéjọ àgbáyé tá a kọ́kọ́ ṣe ní ìlú Paris lẹ́yìn ogun. Alábòójútó arìnrìn-àjò kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Léopold Jontès wá sí Bẹ́tẹ́lì láti ràn mí lọ́wọ́. Nígbà tó yá, wọ́n yan Léopold gẹ́gẹ́ bí alábòójútó ẹ̀ka. Gbọ̀ngàn eré ìdárayá kan tó wà ní ìtòsí irin gogoro kan tí wọ́n ń pè ní Eiffel Tower la ti ṣe àpéjọ náà. Orílẹ̀-èdè méjìdínlọ́gbọ̀n [28] ni àwọn èèyàn ti wá sí àpéjọ náà. Ní ọjọ́ tó kẹ́yìn àpéjọ, inú ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] àwọn Ẹlẹ́rìí tó wá láti orílẹ̀-èdè Faransé dùn gan-an láti rí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ó lé irínwó àti mẹ́rìndínlọ́gọ́ta èèyàn [10,456] tó wá sí àpéjọ náà.

Nígbà tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ dé orílẹ̀-èdè Faransé, mi ò mọ èdè Faransé sọ dáadáa. Ibi tí ọ̀rọ̀ náà wá burú sí ni pé, ìgbà tí mo bá mọ bí mo ṣe lè sọ ohun tó wà lọ́kàn mi nìkan ni mo máa ń sọ̀rọ̀, kí n má bàa ṣe àṣìṣe. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, bí èèyàn kò bá ṣe àṣìṣe, kò sẹ́ni tó máa tọ́ ọ sọ́nà, kò sì ní lè tẹ̀ síwájú.

Kí n lè wá nǹkan ṣe sí ọ̀ràn náà, mo lọ fi orúkọ sílẹ̀ nílé ìwé kan tí wọ́n ti ń kọ́ àwọn tó bá wá láti ilẹ̀ òkèèrè ní èdè Faransé. Ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ ní àwọn ọjọ́ tí a kò bá ní ìpàdé ni mo máa ń lọ síbẹ̀. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ràn èdè Faransé, ìfẹ́ yìí sì ń pọ̀ sí i bí ọdún ṣe ń gorí ọdún. Ìrànlọ́wọ́ ńlá ni èdè yìí jẹ́ fún mi, torí pé ó jẹ́ kí n lè ran ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní orílẹ̀-èdè Faransé lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè. Nígbà tó yá, èmi fúnra mi di atúmọ̀ èdè, mo sì ń túmọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì sí èdè Faransé. Àǹfààní ló jẹ́ fún mi láti máa mú kí oúnjẹ tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀ tí ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ ń pèsè dé ọ̀dọ̀ àwọn ará tó ń sọ èdè Faransé kárí ayé.—Mát. 24:45-47.

ÌGBÉYÀWÓ ÀTI ÀWỌN ÀǸFÀÀNÍ IṢẸ́ ÌSÌN MÍÌ

Ní ọdún 1956, mo gbé Esther arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Switzerland níyàwó, ìyẹn sì jẹ́ ọdún díẹ̀ lẹ́yìn tá a pàdé. Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Bẹ́tẹ́lì tó wà ní London (ìyẹn London Tabernacle tí màmá mi ti ṣe ìrìbọmi) la ti ṣe ìgbéyàwó. Arákùnrin Hughes ló sọ àsọyé ìgbéyàwó wa. Màmá Esther tó jẹ́ ẹni àmì òróró náà sì wà níbẹ̀. Kì í ṣe pé ìgbéyàwó mi jẹ́ kí n ní alábàákẹ́gbẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ mi, tó sì tún jẹ́ olóòótọ́ nìkan ni, àmọ́ ó tún máa ń jẹ́ kí n gbádùn ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tó ṣeyebíye fún ọ̀pọ̀ wákàtí bí mo bá wà pẹ̀lú màmá ìyàwó mi tó jẹ́ ẹni tí nǹkan tẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn. Màmá ìyàwó mi parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé lọ́dún 2000.

Lẹ́yìn ìgbéyàwó wa, ìta ni èmi àti Esther ń gbé. Mo ṣì ń túmọ̀ èdè ní Bẹ́tẹ́lì, àmọ́ Esther ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní ìgbèríko kan ní ìlú Paris. Ó ṣeé ṣe fún un láti ran àwọn mélòó kan lọ́wọ́ láti di ìránṣẹ́ Jèhófà. Ní ọdún 1964 wọ́n ní kí èmi àti ìyàwó mi wá máa gbé ní Bẹ́tẹ́lì. Ní ọdún 1976 tí wọ́n kọ́kọ́ dá ìṣètò Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka sílẹ̀, mo wà lára àwọn tí wọ́n yàn sínú ìgbìmọ̀ náà. Látìgbà tí èmi àti Esther sì ti ṣe ìgbéyàwó ló ti ń tì mí lẹ́yìn tìfẹ́tìfẹ́.

“Ẹ KÌ YÓÒ NÍ MI NÍGBÀ GBOGBO”

Mo máa ń láǹfààní láti ṣèbẹ̀wò sí oríléeṣẹ́ wa ní ìpínlẹ̀ New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, látìgbàdégbà. Láwọn ìgbà tí mo bá lọ síbẹ̀, àwọn tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa ń fún mi ní ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà kan tí mo sọ ohun tó wà lọ́kàn mi nípa bí mo ṣe máa parí iṣẹ́ kan lásìkò tí wọ́n ní ká parí rẹ̀, Arákùnrin Knorr rẹ́rìn-ín músẹ́, ó sì sọ pé: “Má yọra ẹ lẹ́nu. Ṣáà máa ṣiṣẹ́!” Látìgbà yẹn, ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé tí iṣẹ́ bá ti pọ̀ nílẹ̀, dípò kí n máa bẹ̀rù, ńṣe ni mo máa ń mú wọn ṣe lọ́kọ̀ọ̀kan, màá sì parí gbogbo wọn lásìkò.

Nígbà tó ku díẹ̀ kí Jésù kú, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ kì yóò ní mi nígbà gbogbo” pẹ̀lú yín. (Mát. 26:11) Àwa àgùntàn mìíràn náà mọ̀ pé a kò lè ní àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Kristi pẹ̀lú wa lórí ilẹ̀ ayé nígbà gbogbo. Nítorí náà, mo máa ń kà á sí àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ pé fún ohun tó lé ní àádọ́rin [70] ọdún ni mo ti ń ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn ẹni àmì òróró, mo sì dúpẹ́ pé mo láǹfààní láti di ibi gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ ẹni tí í ṣe Júù mú.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Fún àlàyé lórí “Jónádábù,” wo ìwé Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom, ojú ìwé 83, 165 àti 166 àti Ilé Ìṣọ́ January 1, 1998, ojú ìwé 13, ìpínrọ̀ 5 àti 6.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 21]

Arákùnrin Knorr rẹ́rìn-ín músẹ́, ó sì sọ pé: “Má yọra ẹ lẹ́nu. Ṣáà máa ṣiṣẹ́!”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

(Apá òsì) Màmá àti bàbá mi

(Apá ọ̀tún) Èmi rèé nínú ọgbà ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì ní ọdún 1948, mo wọ ẹ̀wù òtútù tí màmá mi fún mi

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Mò ń ṣe ògbufọ̀ àsọyé Arákùnrin Lloyd Barry nígbà ìyàsímímọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní orílẹ̀-èdè Faransé lọ́dún 1997

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

(Apá òsì) Èmi àti Esther rèé lọ́jọ́ ìgbéyàwó wa

(Apá ọ̀tún) A wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù