Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Fi Ọkàn-àyà Pípé Sin Jèhófà

Máa Fi Ọkàn-àyà Pípé Sin Jèhófà

Máa Fi Ọkàn-àyà Pípé Sin Jèhófà

“Ọmọkùnrin mi, mọ Ọlọ́run baba rẹ kí o sì fi ọkàn-àyà pípé pérépéré . . . sìn ín.”—1 KÍRÓ. 28:9.

WÁ ÌDÁHÙN SÍ ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

Kí ni ọkàn ìṣàpẹẹrẹ?

Ọ̀nà wo la lè gbà ṣàyẹ̀wò ohun tó wà nínú ọkàn-àyà wa?

Báwo la ṣe lè máa fi ọkàn-àyà pípé sin Jèhófà?

1, 2. (a) Ẹ̀yà ara wo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ ju àwọn ẹ̀yà ara yòókù lọ? (b) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká mọ ohun tí ọkàn ìṣàpẹẹrẹ túmọ̀ sí?

 Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀yà ara èèyàn lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Bí àpẹẹrẹ, baba ńlá ìgbàanì Jóòbù, sọ pé: “Kò sí ìwà ipá ní àtẹ́lẹwọ́ mi.” Sólómọ́nì Ọba sọ pé: “Ìròyìn tí ó dára a máa mú àwọn egungun sanra.” Jèhófà mú un dá Ísíkíẹ́lì lójú pé: “Bí dáyámọ́ǹdì, tí ó le ju akọ òkúta lọ, ni mo ti ṣe iwájú orí rẹ.” Àwọn èèyàn kan sì sọ fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé: “Àwọn ohun kan tí ó ṣàjèjì sí etí wa ni ìwọ ń mú wọlé wá.”—Jóòbù 16:17; Òwe 15:30; Ìsík. 3:9; Ìṣe 17:20.

2 Àmọ́ ẹ̀yà ara kan wà tí Bíbélì sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ ju ẹ̀yà ara yòókù lọ. Ìyẹn ni ẹ̀yà ara tí Hánà olóòótọ́ mẹ́nu kàn nínú àdúrà. Ó sọ pé: “Ọkàn-àyà mi yọ ayọ̀ ńláǹlà nínú Jèhófà.” (1 Sám. 2:1) Kódà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún [1,000] ìgbà tí àwọn tó kọ Bíbélì mẹ́nu ba ọkàn lọ̀nà ìṣàpẹẹrẹ. Torí náà, ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká mọ ohun tí “ọkàn-àyà” tàbí ọkàn ìṣàpẹẹrẹ dúró fún, torí Bíbélì sọ pé a ní láti fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ.—Ka Òwe 4:23.

KÍ NI ỌKÀN ÌṢÀPẸẸRẸ?

3. Báwo la ṣe lè fi òye mọ ohun tí “ọkàn-àyà” túmọ̀ sí nínú Bíbélì? Ṣàpèjúwe.

3 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò sọ ìtumọ̀ “ọkàn-àyà” bí ìwé atúmọ̀ èdè ṣe máa ń ṣe, ó mú ká lè fi òye mọ ohun tí ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí. Lọ́nà wo? A lè ṣàpèjúwe rẹ̀ báyìí: Ronú nípa ògiri kan tí wọ́n ya àwòrán sí nípa títo ọ̀pọ̀ òkúta aláràbarà kéékèèké pa pọ̀. Bí èèyàn bá rìn sẹ́yìn kó lè rí àwòrán náà látòkè délẹ̀, ó máa kíyè sí i pé ó ní irú ọnà tàbí àwòrán tí òkúta tí wọ́n rọra tò pọ̀ náà gbé jáde. Bákan náà, tá a bá fara balẹ̀ kíyè sí ọ̀pọ̀ ibi tí wọ́n ti lo “ọkàn-àyà” nínú Bíbélì, tá a sì ṣe àkópọ̀ gbogbo ohun tá a kíyè sí, a lè fi òye mọ̀ pé ńṣe ni àwọn ìtọ́kasí náà gbé irú ọnà tàbí àwòrán kan pàtó yọ. Kí ni àwòrán tó gbé yọ?

4. (a) Kí ni “ọkàn-àyà” dúró fún? (b) Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Mátíù 22:37?

4 Àwọn tó kọ Bíbélì lo “ọkàn-àyà” láti ṣàpèjúwe àpapọ̀ ohun tí ẹnì kan jẹ́ ní inú lọ́hùn-ún. Lára irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ ọkàn wa, ohun tí à ń rò, irú ẹni tí a jẹ́, irú ìwà tí à ń hù, àwọn ohun tí a lè ṣe, àwọn ohun tó máa ń sún wa ṣe nǹkan àti àwọn àfojúsùn wa. (Ka Diutarónómì 15:7; Òwe 16:9; Ìṣe 2:26.) Gẹ́gẹ́ bí ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ ṣe sọ, ọkàn-àyà ni “àpapọ̀ ohun tí ẹnì kan jẹ́ ní inú lọ́hùn-ún.” Àmọ́, ìgbà míì wà tí “ọkàn-àyà” máa ń ní ìtumọ̀ tí kò fi bẹ́ẹ̀ gbòòrò. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.” (Mát. 22:37) Níbí yìí, “ọkàn-àyà” dúró fún ìmọ̀lára, ìfẹ́ ọkàn àti bí nǹkan ṣe ń rí lára wa gan-an. Ṣùgbọ́n, nítorí pé Jésù mẹ́nu kan ọkàn-àyà, ọkàn àti èrò inú lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, ohun tó ń tẹnu mọ́ ni pé a gbọ́dọ̀ fi ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run hàn nínú bí nǹkan ṣe ń rí lára wa àti nínú ọ̀nà tá a gbà ń gbé ìgbé ayé wa àti bá a ṣe ń lo èrò orí wa. (Jòh. 17:3; Éfé. 6:6) Àmọ́, bí Bíbélì bá lo “ọkàn-àyà” nìkan, àpapọ̀ ohun tí èèyàn jẹ́ ní inú lọ́hùn-ún ló máa ń dúró fún.

ÌDÍ TÁ A FI GBỌ́DỌ̀ MÁA FI ÌṢỌ́ ṢỌ́ ỌKÀN-ÀYÀ WA

5. Kí nìdí tá a fi fẹ́ láti sa gbogbo ipá wa ká lè máa fi ọkàn-àyà pípé sin Jèhófà?

5 Dáfídì Ọba rán Sólómọ́nì létí nípa ọkàn-àyà pé: “Ọmọkùnrin mi, mọ Ọlọ́run baba rẹ kí o sì fi ọkàn-àyà pípé pérépéré àti ọkàn tí ó kún fún inú dídùn sìn ín; nítorí gbogbo ọkàn-àyà ni Jèhófà ń wá, gbogbo ìtẹ̀sí ìrònú sì ni ó ń fi òye mọ̀.” (1 Kíró. 28:9) Dájúdájú, Jèhófà ni Olùṣàyẹ̀wò gbogbo ọkàn-àyà, títí kan ọkàn-àyà tiwa náà. (Òwe 17:3; 21:2) Ohun tó bá sì rí nínú ọkàn-àyà wa máa ní ipa púpọ̀ lórí àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ àti ọjọ́ ọ̀la wa. Torí náà, ìdí rere wà tá a gbọ́dọ̀ fi tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run mí sí Dáfídì láti kọ nípa sísa gbogbo ipá wa ká lè máa fi ọkàn-àyà pípé sin Jèhófà.

6. Kí la gbọ́dọ̀ mọ̀ nípa ìpinnu wa láti máa sin Jèhófà?

6 Bí àwa èèyàn Jèhófà ṣe ń fi ìtara ṣe iṣẹ́ ìsìn wa ń fi hàn pé òótọ́ ló wù wá pé ká máa fi ọkàn-àyà pípé sin Ọlọ́run. Síbẹ̀, a mọ̀ pé pákáǹleke inú ayé búburú Sátánì yìí àti èròkérò tó máa ń wá sí wa lọ́kàn láti dẹ́ṣẹ̀ máa ń lágbára gan-an lórí wa, wọ́n sì lè sọ ìpinnu wa láti máa sin Ọlọ́run tọkàntọkàn di ahẹrẹpẹ. (Jer. 17:9; Éfé. 2:2) Torí náà, a ní láti máa ṣàyẹ̀wò ọkàn-àyà wa déédéé, ká lè máa rí i dájú pé ìpinnu wa láti sin Ọlọ́run ṣì lágbára àti pé a kò tíì máa fi ọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ojúṣe wa. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?

7. Kí ló máa ń fi ohun tó wà nínú ọkàn-àyà wa hàn?

7 Béèyàn ò ṣe lè rí ohun tó wà ní inú igi kan, bẹ́ẹ̀ náà ni a kò lè fojú rí ohun tó wà ní inú ọkàn-àyà wa. Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ nínú Ìwàásù Orí Òkè, bí a ṣe lè fi àwọn èso tí igi kan ń so pinnu bóyá igi náà dára tàbí kò dára, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ohun tí à ń ṣe nínú ìgbésí ayé wa ṣe máa ń fi ohun tó wà nínú ọkàn-àyà wa hàn. (Mát. 7:17-20) Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀kan yẹ̀ wò nínú irú àwọn ohun bẹ́ẹ̀.

Ọ̀NÀ PÀTÀKÌ KAN TÁ A LÈ GBÀ ṢÀYẸ̀WÒ ỌKÀN-ÀYÀ WA

8. Báwo ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Mátíù 6:33 ṣe jẹ mọ́ ohun tó wà nínú ọkàn-àyà wa?

8 Nínú ìwàásù kan náà yẹn, Jésù ti kọ́kọ́ jẹ́ kí àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ mọ ohun tí wọ́n lè ṣe tó máa fi hàn pé ohun tó wà nínú ọkàn-àyà wọn ni pé kí wọ́n máa sin Jèhófà tọkàntọkàn. Ó sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.” (Mát. 6:33) Lóòótọ́, ohun tí a bá fi sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wa máa ń hàn nínú ohun tí à ń fẹ́, ohun tí à ń rò àti ohun tí à ń wéwèé nínú ọkàn-àyà wa. Torí náà, ọ̀nà pàtàkì kan tá a fi lè mọ̀ bóyá à ń fi ọkàn-àyà pípé sin Ọlọ́run ni pé ká máa ṣe àyẹ̀wò àwọn ohun tí à ń fi sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wa.

9. Kí ni Jésù ní kí àwọn kan wá ṣe, kí ni ìdáhùn wọn sì jẹ́ ká mọ̀ nípa wọn?

9 Kò tíì pẹ́ lẹ́yìn tí Jésù rọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n ‘máa bá a nìṣó ní wíwá ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́,’ tí ìṣẹ̀lẹ̀ kan fi wáyé tó jẹ́ ká rí bí ohun tí ẹnì kan fi sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe máa ń fi ohun tó wà nínú ọkàn-àyà rẹ̀ hàn. Nígbà tí Lúùkù tó kọ ọ̀kan lára àwọn ìwé Ìhìn Rere dẹ́nu lé ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, ó sọ pé Jésù “gbé ojú rẹ̀ sọ́nà gangan láti lọ sí Jerúsálẹ́mù,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí òun níbẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Nígbà tí òun àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ “ń lọ ní ojú ọ̀nà,” Jésù pàdé àwọn ọkùnrin kan ó sì sọ fún wọn pé kí wọ́n “di ọmọlẹ́yìn [òun].” Àwọn ọkùnrin yẹn fẹ́ gba ìkésíni Jésù, àmọ́ àwọn ohun kan wà tí wọ́n kọ́kọ́ fẹ́ ṣe. Ọ̀kan lára wọ́n dá Jésù lóhùn pé: “Gbà mí láyè láti kọ́kọ́ lọ sìnkú baba mi.” Òmíràn sọ pé: “Èmi yóò tẹ̀ lé ọ, Olúwa; ṣùgbọ́n kọ́kọ́ gbà mí láyè láti sọ pé ó dìgbòóṣe fún àwọn tí ń bẹ ní agbo ilé mi.” (Lúùkù 9:51, 57-61) Ẹ wo bí ìpinnu tó fìdí múlẹ̀ gbọn-in tí Jésù ṣe tọkàntọkàn ṣe yàtọ̀ sí àwáwí tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tí àwọn ọkùnrin yẹn ṣe! Bí àwọn ọkùnrin yẹn ṣe fi ohun tó jẹ wọ́n lógún ṣáájú wíwá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé, wọn kò ṣe tán láti fi ọkàn-àyà pípé sin Ọlọ́run.

10. (a) Kí ni àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ ìkésíni rẹ̀? (b) Àpèjúwe kúkúrú wo ni Jésù fún wọn?

10 A kò dà bí àwọn ọkùnrin tí wọ́n fi ẹnu lásán sọ pé àwọn máa di ọmọ ẹ̀yìn Jésù yẹn, a ti ṣe ohun tó mọ́gbọ́n dání nípa dídi ọmọlẹ́yìn rẹ̀ a sì ti ń sin Jèhófà lójoojúmọ́ báyìí. Lọ́nà yìí, à ń fi ohun tá à ń rò nípa Jèhófà nínú ọkàn-àyà wa hàn. Àmọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè máa ṣe déédéé nínú ìjọ, a ṣì gbọ́dọ̀ ṣọ́ra torí pé ohun kan wà tó lè fi ọkàn-àyà wa sínú ewu. Kí ni ohun náà? Nínú ìjíròrò Jésù pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tí wọ́n fi ẹnu lásán sọ pé àwọn máa di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ yẹn, ó jẹ́ ká mọ ohun tí ewu náà jẹ́ nígbà tó sọ pé: “Kò sí ènìyàn tí ó ti fi ọwọ́ rẹ̀ lé ohun ìtúlẹ̀, tí ó sì ń wo àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn tí ó yẹ dáadáa fún ìjọba Ọlọ́run.” (Lúùkù 9:62) Kí la lè rí kọ́ nínú àpèjúwe yẹn?

ǸJẸ́ À Ń “RỌ̀ MỌ́ OHUN RERE”?

11. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí iṣẹ́ alágbàṣe tó ń lo ohun èlò ìtúlẹ̀ nínú àpèjúwe Jésù, kí sì nìdí?

11 Kí ẹ̀kọ́ tí Jésù fẹ́ fi àpèjúwe kúkúrú yẹn kọ́ wa lè ṣe kedere, ẹ jẹ́ ká fi àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ díẹ̀ kún àwòrán tó fẹ́ kó gbé wá sí wa lọ́kàn. Ọwọ́ alágbàṣe kan dí bó ṣe ń lo ohun èlò ìtúlẹ̀. Àmọ́, bó ṣe ń bá iṣẹ́ rẹ̀ nìṣó kò yéé ronú nípa àwọn tó fi sílé, aya àtàwọn ọmọ, àwọn ọ̀rẹ́, oúnjẹ, orin, bí wọ́n ṣe máa ń para wọn lẹ́rìn-ín àti bó ṣe máa ń wà lábẹ́ ibòji. Ọkàn rẹ̀ wá ń fà sí àwọn nǹkan yẹn. Lẹ́yìn tí alágbàṣe yẹn ti fi ohun èlò ìtúlẹ̀ kọ ilẹ̀ tó pọ̀ gan-an, ìfẹ́ tó ní sí àwọn nǹkan tó máa ń mú kí ìgbésí ayé gbádùn mọ́ni yìí gbà á lọ́kàn débi pé ó yí pa dà láti wo “àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé alágbàṣe náà ṣì ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ láti ṣe kí wọ́n tó parí gbígbin irúgbìn sórí ilẹ̀ náà, ọkàn rẹ̀ ti pínyà, ìyẹn sì pa iṣẹ́ rẹ̀ lára. Láìsí àní-àní, alágbàṣe yẹn já ọ̀gá rẹ̀ kulẹ̀ torí pé kò ní ẹ̀mí ìfaradà.

12. Báwo ni àwọn Kristẹni kan lóde òní ṣe lè bá ara wọn nínú ipò kan náà bíi ti alágbàṣe inú àpèjúwe Jésù?

12 Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo bí ohun tó jọ èyí ṣe lè ṣẹlẹ̀ lóde òní. Alágbàṣe náà lè dúró fún Kristẹni èyíkéyìí tó dà bíi pé ó ń ṣe dáradára, àmọ́ tó wà nínú ewu nípa tẹ̀mí. Ní àfiwé, ẹ jẹ́ ká fi ọkàn yàwòrán arákùnrin kan tí ọwọ́ rẹ̀ máa ń dí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Àmọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń lọ sí àwọn ìpàdé àti òde ẹ̀rí, kò yéé ronú nípa àwọn nǹkan kan tó fẹ́ràn lára àwọn ohun tó jẹ́ ti ayé. Ọkàn rẹ̀ ń fà sí àwọn nǹkan yẹn gan-an. Lẹ́yìn tó ti lo ọdún mélòó kan lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, ìfẹ́ tó ní fún àwọn nǹkan ti ayé yìí wá gbà á lọ́kàn gan-an débi tó fi yí pa dà tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wo “àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé púpọ̀ ṣì wà láti ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, arákùnrin náà kò “di ọ̀rọ̀ ìyè mú ṣinṣin,” èyí sì ṣe ìpalára fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. (Fílí. 2:16) Kì í dùn mọ́ Jèhófà tó jẹ́ “Ọ̀gá ìkórè” nínú bí ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kò bá lo ìfaradà mọ́.—Lúùkù 10:2.

13. Kí ló wé mọ́ fífi ọkàn-àyà pípé sin Jèhófà?

13 Ẹ̀kọ́ tó ṣe kedere ni èyí kọ́ wa. Ó dára gan-an tá a bá ń kópa déédéé nínú àwọn ìgbòkègbodò tó gbámúṣé tó sì ń fúnni láyọ̀, bíi lílọ sí àwọn ìpàdé ìjọ àti òde ẹ̀rí. Àmọ́, fífi ọkàn-àyà pípé sin Jèhófà tún gba pé ká ṣe ohun tó ju ìyẹn lọ. (2 Kíró. 25:1, 2, 27) Bí Kristẹni kan bá ṣì ń nífẹ̀ẹ́ sí “àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn” nínú ọkàn-àyà rẹ̀, ìyẹn àwọn kan lára àwọn ohun tó jẹ́ ti ayé, ó lè pàdánù àjọṣe tó dára tó ní pẹ̀lú Ọlọ́run. (Lúùkù 17:32) Àyàfi tá a bá “fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ohun burúkú [tá a sì] rọ̀ mọ́ ohun rere” la tó lè “yẹ dáadáa fún ìjọba Ọlọ́run.” (Róòmù. 12:9; Lúùkù 9:62) Torí náà, gbogbo wa gbọ́dọ̀ rí i dájú pé bó ti wù kí ohunkóhun nínú ayé Sátánì yìí wúlò tàbí kó gbádùn mọ́ wa tó, a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó fà wá sẹ́yìn kúrò nínú fífi gbogbo ọkàn-àyà wa bójú tó gbogbo nǹkan tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run.—2 Kọ́r. 11:14; ka Fílípì 3:13, 14.

MÁA WÀ LÓJÚFÒ!

14, 15. (a) Báwo ni Sátánì ṣe máa ń fẹ́ láti sọ ọkàn-àyà wa di ìdàkudà? (b) Ṣe àpèjúwe ohun tó mú kí ọgbọ́n tí Sátánì ń lò léwu gan-an.

14 Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ló mú ká ya ara wa sí mímọ́ fún un. Láti ìgbà yẹn wá, ọ̀pọ̀ nínú wa ti fi hàn fún ọ̀pọ̀ ọdún pé a kò ní jẹ́ kí ohunkóhun dí wa lọ́wọ́ láti máa fi ọkàn-àyà pípé sin Jèhófà. Àmọ́, Sátánì kò tíì ṣíwọ́ láti máa dán wa wò. Ọkàn-àyà wa ló sì fi ṣe àfojúsùn rẹ̀. (Éfé. 6:12) Àmọ́ ṣá o, òun náà lè ti mọ̀ pé a ò kàn ní ṣàdédé fi Jèhófà sílẹ̀. Torí náà, ó máa ń fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ lo “ètò àwọn nǹkan yìí” kó bàa lè sọ ìtara àtọkànwá tá a ní fún Ọlọ́run di ahẹrẹpẹ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. (Ka Máàkù 4:18, 19.) Kí nìdí tí ọgbọ́n tí Sátánì ń lò fi ń mú kó rí àwọn èèyàn tàn jẹ?

15 Láti dáhùn ìbéèrè yìí, fojú inú wò ó pé ò ń fi ìmọ́lẹ̀ gílóòbù tó lágbára gan-an ka ìwé, àmọ́ ṣàdédé ni gílóòbù náà jó. Ó rọrùn fún ẹ láti mọ̀ pé ńṣe ní gílóòbù náà jó, torí pé o bá ara rẹ nínú òkùnkùn biribiri, lo bá fi gílóòbù míì pààrọ̀ èyí tó jó yẹn. Inú iyàrá náà sì pa dà mọ́lẹ̀ rekete. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kejì, iná yẹn kan náà lo fi ń kàwé. Àmọ́, o kò mọ̀ pé ẹnì kan ti pààrọ̀ gílóòbù náà ó sì ti fi òmíràn tí agbára rẹ̀ fi díẹ̀ dín kù sí ti àkọ́kọ́ sí i. Ǹjẹ́ o máa kíyè sí ìyàtọ̀ náà? Bóyá ni. Ká tún wá sọ pé lọ́jọ́ kejì ẹnì kan tún pààrọ̀ gílóòbù náà, ó wá fi èyí tí agbára rẹ̀ tún fi díẹ̀ dín kù sí i ńkọ́? Ó ṣì ṣeé ṣe kó o má mọ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé ńṣe ni agbára gílóòbù náà ń dín kù díẹ̀díẹ̀, o sì lè má fura. Bákan náà, ipa búburú tí ayé Sátánì máa ń ní lórí wa lè mú kí ìtara wa bẹ̀rẹ̀ sí í dín kù díẹ̀díẹ̀. Bí ọ̀rọ̀ bá sì rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé Sátánì ti mú kí ìtara àtọkànwá, tí kò lábùlà, tá a ní fún Jèhófà dín kù sí ti tẹ́lẹ̀ nìyẹn. Bí Kristẹni kan kò bá wà lójúfò, ó lè ṣàì kíyè sí ìyípadà tó rọra ń wáyé yẹn.—Mát. 24:42; 1 Pét. 5:8.

ÀDÚRÀ ṢE PÀTÀKÌ

16. Báwo la ṣe lè dáàbò bo ara wa lọ́wọ́ àwọn ètekéte Sátánì?

16 Báwo la ṣe lè dáàbò bo ara wa lọ́wọ́ irú àwọn ètekéte tí Sátánì ń lò yẹn ká sì máa fi ọkàn-àyà pípé sin Jèhófà? (2 Kọ́r. 2:11) Àdúrà ṣe pàtàkì. Pọ́ọ̀lù gba àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ níyànjú pé kí wọ́n “dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí àwọn ètekéte Èṣù.” Lẹ́yìn náà ló tún rọ̀ wọ́n pé: “Pẹ̀lú gbogbo oríṣi àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ . . . , ẹ máa bá a lọ ní gbígbàdúrà ní gbogbo ìgbà.”—Éfé. 6:11, 18; 1 Pét. 4:7.

17. Kí la rí kọ́ nínú àwọn àdúrà Jésù?

17 Ká lè dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí Sátánì, ó bọ́gbọ́n mu pé ká fara wé Jésù tó fẹ́ràn láti máa gbàdúrà, èyí tó fi hàn pé ó wù ú gan-an pé kó máa fi ọkàn-àyà pípé sin Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ṣàkíyèsí ohun tí Lúùkù kọ nípa bí Jésù ṣe gbàdúrà ní alẹ́ tó ṣáájú ikú rẹ̀, ó ní: “Bí ó ti wà nínú ìroragógó, ó ń bá a lọ ní títúbọ̀ fi taratara gbàdúrà.” (Lúùkù 22:44) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ti máa ń fi ìtara gbàdúrà tẹ́lẹ̀, lọ́tẹ̀ yìí, ó dojú kọ àdánwò tó lágbára jù lọ nínú ìgbésí ayé rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, torí náà, ó ‘túbọ̀ fi taratara’ gbàdúrà, Jèhófà sì dáhùn àdúrà rẹ̀. Àpẹẹrẹ Jésù fi hàn pé àwọn ìgbà míì wà téèyàn máa ní láti gbàdúrà kíkankíkan. Torí náà, bí àdánwò tá à ń dojú kọ bá ṣe pọ̀ tó àti bí ètekéte Sátánì bá ṣe túbọ̀ ń lágbára tó, bẹ́ẹ̀ ló ṣe yẹ ká máa ‘túbọ̀ fi taratara’ gbàdúrà pé kí Jèhófà dáàbò bò wá.

18. (a) Kí ló yẹ ká bi ara wa lórí ọ̀ràn àdúrà, kí sì nìdí? (b) Àwọn nǹkan wo ló máa ń nípa lórí ọkàn-àyà wa, ní àwọn ọ̀nà wo sì ni? (Wo  àpótí tó wà ní ojú ìwé 16.)

18 Báwo ni irú àdúrà bẹ́ẹ̀ ṣe máa nípa lórí wa? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín.” (Fílí. 4:6, 7) Bẹ́ẹ̀ ni o, a gbọ́dọ̀ máa fi ìtara gbàdúrà, ká sì tún máa gbàdúrà déédéé, ká bàa lè máa fi ọkàn-àyà pípé sin Jèhófà. (Lúùkù 6:12) Torí náà, bi ara rẹ pé, ‘Báwo ni mo ṣe ń fi ìtara gbàdúrà tó, ṣé mo sì máa ń gbàdúrà déédéé?’ (Mát. 7:7; Róòmù 12:12) Ìdáhùn rẹ sí ìbéèrè yìí á jẹ́ kó o mọ bó ṣe ń wù ẹ́ tó láti máa sin Ọlọ́run tọkàntọkàn.

19. Kí lo máa ṣe kó o lè máa fi ọkàn-àyà pípé sin Jèhófà?

19 Gẹ́gẹ́ bí a ṣe jíròrò rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí, àwọn ohun tá a bá fi sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wa lè jẹ́ ká mọ púpọ̀ nípa ọkàn-àyà wa. A fẹ́ láti rí i dájú pé àwọn ohun tá a ti fi sílẹ̀ sẹ́yìn tàbí ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ Sátánì kò ba ìpinnu wa láti máa fi ọkàn-àyà pípé sin Jèhófà jẹ́. (Ka Lúùkù 21:19, 34-36.) Torí náà, bíi ti Dáfídì, à ń bá a nìṣó láti máa bẹ Jèhófà pé kó “mú ọkàn-àyà [wa] ṣọ̀kan.”—Sáàmù 86:11.

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 16]

OHUN MẸ́TA TÓ MÁA Ń NÍPA LÓRÍ ỌKÀN-ÀYÀ WA

Bí a ṣe lè ṣe àwọn ohun tó máa ṣe ọkàn wa láǹfààní bẹ́ẹ̀ náà la ṣe lè ṣe àwọn ohun táá jẹ́ kí ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa máa ṣiṣẹ́ dáádáá. Ronú lórí ohun pàtàkì mẹ́ta yìí:

1 Oúnjẹ: A gbọ́dọ̀ máa jẹ oúnjẹ aṣaralóore tó pọ̀ tó kí ọkàn wa lè máa ṣiṣẹ́ dáadáa. Bákan náà, a gbọ́dọ̀ rí i dájú pé à ń jẹ oúnjẹ tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀ ní àjẹtẹ́rùn nípa dídá kẹ́kọ̀ọ́, ṣíṣe àṣàrò àti lílọ sí ìpàdé déédéé.—Sm. 1:1, 2; Òwe 15:28; Héb. 10:24, 25.

 2 Eré Ìmárale: Kí ọkàn wa lè máa ṣiṣẹ́ dáadáa, ìgbà míì wà tá a máa nílò eré ìmárale tó máa jẹ́ kó lù kìkì. Bákan náà, tá a bá ń fi ìtara kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, bóyá nípa lílo ara wa tokuntokun tàbí nípa ṣíṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, èyí á mú kí ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa máa ṣiṣẹ́ dáadáa.—Lúùkù 13:24; Fílí. 3:12.

3 Àwọn Tó Yí Wa Ká: Àárín àwọn èèyàn tí kò ṣèfẹ́ Ọlọ́run là ń gbé, àwọn náà la sì ń bá ṣiṣẹ́. Èyí lè fa àìbalẹ̀ ọkàn, ó sì lè kó pákáǹleke bá ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa. Àmọ́, a lè dín irú pákáǹleke bẹ́ẹ̀ kù tá a bá ń kẹ́gbẹ́ pọ̀ déédéé pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni torí pé ọ̀rọ̀ wa jẹ wọ́n lógún, wọ́n sì ń fi ọkàn-àyà pípé sin Ọlọ́run.—Sm. 119:63; Òwe 13:20.