Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ṣó o gbádùn kíka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí:

Báwo ni àṣìṣe Sólómọ́nì ṣe lè jẹ́ àríkọ́gbọ́n fún wa?

Ọlọ́run lo Sólómọ́nì Ọba, ó sì bù kún un. Àmọ́, nígbà ìṣàkóso Sólómọ́nì, kò tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run mọ́. Ó gbé ọmọbìnrin Fáráò tó jẹ́ kèfèrí níyàwó, ó fẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyàwó, ó sì fàyè gba àwọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ kèfèrí yẹn láti mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́wọ́ sí ìjọsìn èké. A ní láti ṣọ́ra kó má lọ di pé ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ àwa náà á wá máa hùwà tí kò dáa tàbí ká ní èrò tí kò tọ́. (Diu. 7:1-4; 17:17; 1 Ọba 11:4-8)—12/15, ojú ìwé 10 sí 12.

Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Sárà jẹ́ obìnrin tó bẹ̀rù Ọlọ́run tó sì jẹ́ aya àtàtà?

Nígbà tí Ọlọ́run pàṣẹ fún Ábúráhámù pé kó kúrò ní ìlú Úrì, èyí gba pé kó fi àwọn ẹbí, àwọn ọ̀rẹ́ àti irú ìgbésí ayé tó ti mọ́ ọn lára sílẹ̀, kó sì lọ sí ibi tí kò mọ̀ rí. Síbẹ̀ Sárà fọwọ́ sowọ́ pọ̀, ó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run pé yóò bù kún òun. Ó bọ̀wọ̀ fún Ábúráhámù, ó sì fi ìwà rere ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́.—1/1, ojú ìwé 8.

Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ pé kí Ábúráhámù fi ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n rúbọ?

Ó ṣe pàtàkì ká rántí pé Ọlọ́run kò gba Ábúráhámù láyè láti fi Ísákì rúbọ. Ohun tí Ọlọ́run ní kí Ábúráhámù ṣe yìí jẹ́ àpẹẹrẹ bó ṣe máa fi Jésù Ọmọ rẹ̀ rúbọ. Ó sì jẹ́ ká rí ohun ńlá tí ìrúbọ yẹn ná Ọlọ́run.—1/1, ojú ìwé 23.

Kí ló fi hàn pé láti ọ̀rúndún kìíní wá ni àwọn ojúlówó Kristẹni mélòó kan tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró á ti máa wà lórí ilẹ̀ ayé?

Nínú àkàwé kan tí Jésù ṣe nípa “àlìkámà” àti “àwọn èpò,” “irúgbìn àtàtà” náà dúró fún “àwọn ọmọ ìjọba náà.” (Mát. 13:24-30, 38) Àwọn èpò àti àlìkámà náà yóò jọ dàgbà pa pọ̀ títí di ìgbà ìkórè. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò lè fi gbogbo ẹnu sọ àwọn èèyàn tó jẹ́ ara ẹgbẹ́ àlìkámà nígbà yẹn, àmọ́ ohun kan tó dájú ni pé àwọn kan máa wà títí di àkókò wa.—1/15, ojú ìwé 7.

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ló máa yọrí sí ogun Amágẹ́dọ́nì?

Àwọn orílẹ̀-èdè yóò kéde “àlàáfíà àti ààbò” lọ́nà kan tó máa hàn kedere. (1 Tẹs. 5:3) Àwọn ìjọba ayé yóò dojú ìjà kọ ẹ̀sìn èké. (Ìṣí. 17:15-18) Wọn yóò gbéjà ko àwọn olùjọ́sìn tòótọ́. Nígbà náà ni òpin yóò sì dé.—2/1, ojú ìwé 9.

Kí la lè ṣe tí a kò fi ní máa ṣe ìlara àwọn èèyàn?

Àwọn ohun tá a lè ṣe tó máa ràn wá lọ́wọ́ nìyí: Sapá kó o lè ní ìfẹ́ àti ìfẹ́ni ará, máa bá àwọn èèyàn Ọlọ́run kẹ́gbẹ́ pọ̀, máa ṣe rere, “máa yọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń yọ̀.” (Róòmù 12:15)—2/15, ojú ìwé 16 àti 17.

Àwọn wo ló ń sọ èdè Nahuatl, kí la sì ń ṣe fún wọn?

Àwọn Aztec ayé ọjọ́un ló ń sọ èdè náà, àwọn èèyàn tó jẹ́ mílíọ̀nù kan àtààbọ̀ [1,500,000] ló ṣì ń sọ èdè náà báyìí lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Àwọn Ẹlẹ́rìí ń wàásù ní èdè Nahuatl, díẹ̀ lára àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa sì wà ní èdè náà.—3/1, ojú ìwé 13 àti 14.

Tá a bá ń fún àwọn èèyàn ní ìmọ̀ràn, àwọn ìlànà wo ló yẹ ká fi sọ́kàn?

Fòye mọ bí ọ̀rọ̀ ṣe jẹ́ gan-an. Ronú kó o tó dáhùn. Fi ìrẹ̀lẹ̀ lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Tó bá ṣeé ṣe, ṣe ìwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run. Ṣọ́ra fún ṣíṣe ìpinnu fún àwọn èèyàn.—3/15, ojú ìwé 7 sí 9.

Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ fún àwọn olùgbọ́ rẹ̀ pé kí wọ́n bá ẹni tó bá gbéṣẹ́ fún wọn dé ibùsọ̀ kejì? (Mát. 5:41)

Ní àkókò yẹn ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì, àwọn ará Róòmù tó ń ṣàkóso lè fipá gbé iṣẹ́ fún ẹnì kan. Ohun tí Jésù ní lọ́kàn nígbà tó rọ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ pé kí wọ́n bá a dé ibùsọ̀ kejì ni pé, bí àwọn aláṣẹ bá gbé iṣẹ́ kan fún wọn lọ́nà tó bófin mu, wọ́n ní láti ṣe iṣẹ́ náà, kí wọ́n má sì ṣe bínú.—4/1, ojú ìwé 9.