Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ọ̀nà wo ni ikú àwọn ẹni ìdúróṣinṣin gbà ṣe “iyebíye ní ojú Jèhófà”?

▪ Onísáàmù kan tí Ọlọ́run mí sí kọ ọ́ lórin pé: “Iyebíye ní ojú Jèhófà ni ikú àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀.” (Sm. 116:15) Ìwàláàyè olùjọ́sìn Jèhófà kọ̀ọ̀kan ṣe iyebíye gan-an ní ojú rẹ̀. Àmọ́, ohun tí onísáàmù náà ní lọ́kàn nínú Sáàmù 116 yìí ré kọjá ikú ẹnì kan ṣoṣo.

Bí ẹnì kan bá ń sọ àsọyé ìsìnkú Kristẹni kan, kò yẹ kó lo ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 116:15 fún onítọ̀hún, kódà bí ẹni náà bá tiẹ̀ jẹ́ olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà títí dójú ikú. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọ̀rọ̀ inú Sáàmù yẹn ní ìtumọ̀ tó gbòòrò ju ìyẹn lọ. Ó túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ka ikú àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ lódindi sí àdánù ńlá tó bẹ́ẹ̀ tó fi jẹ́ pé kò ní gbà kí irú rẹ̀ wáyé.—Wo Sáàmù 72:14; 116:8.

Ìwé Sáàmù 116:15 mú kó dá wa lójú pé Jèhófà kò ní jẹ́ kí a gbá àwọn ìránṣẹ́ òun tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin kúrò lórí ilẹ̀ ayé lódindi. Kódà, ìtàn wa lóde òní fi hàn pé a ti fara da ọ̀pọ̀ àdánwò àti inúnibíni líle koko, èyí sì fi ẹ̀rí hàn lọ́nà tó ṣe kedere pé Ọlọ́run kò ní jẹ́ kí wọ́n pa wá run.

Torí pé agbára Jèhófà kò ní ààlà tó sì dájú pé gbogbo ohun tó ní lọ́kàn ló máa ṣe, kò ní jẹ́ kí wọ́n pa gbogbo wa lódindi run. Bí Ọlọ́run bá fàyè gba ìyẹn pẹ́nrẹ́n, ńṣe ló máa dà bíi pé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lágbára jù ú lọ, ìyẹn ò sì lè ṣẹlẹ̀ láé! Á wá di pé ète rẹ̀ láti sọ ilẹ̀ ayé di ibi tí àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà á máa gbé kò ní ní ìmúṣẹ mọ́, irú ìyẹn kò sì lè wáyé. (Ais. 45:18; 55:10, 11) Bí Jèhófà bá sì fàyè gba irú rẹ̀ pẹ́nrẹ́n, a jẹ́ pé ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ sí Jèhófà máa dópin lórí ilẹ̀ ayé nìyẹn, bí kò bá sí ẹnikẹ́ni tí yóò máa sìn ín nínú àwọn àgbàlá orí ilẹ̀ ayé ti tẹ́ńpìlì tẹ̀mí rẹ̀ títóbi! Kò ní sí ìpìlẹ̀ fún “ayé tuntun,” ìyẹn àwùjọ àwọn èèyàn olódodo tí yóò máa gbé lórí ilẹ̀ ayé, lábẹ́ “ọ̀run tuntun.” (Ìṣí. 21:1) Bákan náà, bí kò bá sí ẹnikẹ́ni lórí ilẹ̀ ayé tí Ìjọba Ọlọ́run á máa ṣàkóso lé lórí, á jẹ́ pé Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi kò ní wáyé mọ́ nìyẹn.—Ìṣí. 20:4, 5.

Bí Ọlọ́run bá fàyè gba àwọn ọ̀tá rẹ̀ láti pa àwọn èèyàn rẹ̀ lódindi run kúrò lórí ilẹ̀ ayé, ọ̀pọ̀ ìbéèrè ló máa jẹ yọ nípa ipò Ọlọ́run àti orúkọ rẹ̀. Bí irú rẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ńṣe ló máa tàbùkù sí ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Síwájú sí i, torí ọ̀wọ̀ tí Jèhófà ní fún ara rẹ̀ àti orúkọ mímọ́ rẹ̀, kò ní fàyè gba ikú àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ lódindi. Tún wá gbé èyí yẹ̀ wò: Níwọ̀n bí “kò [ti] sí àìṣèdájọ́ òdodo” lọ́dọ̀ Ọlọ́run, kò ní kùnà láé láti pa àwùjọ àwọn èèyàn tí wọ́n ti ń fi ìdúróṣinṣin sìn ín mọ́. (Diu. 32:4; Jẹ́n. 18:25) Síwájú sí i, bí Jèhófà bá fàyè gbà á pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn ìránṣẹ́ òun run, ìyẹn máa lòdì sí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó sọ pé: “Jèhófà kì yóò kọ àwọn ènìyàn rẹ̀ tì, nítorí orúkọ ńlá rẹ̀.” (1 Sám. 12:22) Ní tòótọ́, “Jèhófà kì yóò ṣá àwọn ènìyàn rẹ̀ tì, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi ogún tirẹ̀ sílẹ̀.”—Sm. 94:14.

Ohun ìtùnú gbáà ló jẹ́ láti mọ̀ pé àwọn èèyàn Jèhófà kò ní pa run láé lórí ilẹ̀ ayé! Torí náà, ní gbogbo ọ̀nà, ẹ jẹ́ ká máa bá a nìṣó láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run, ká sì ní ìgbọ́kànlé nínú ìlérí rẹ̀ pé: “Ohun ìjà yòówù tí a bá ṣe sí ọ kì yóò ṣe àṣeyọrí sí rere, ahọ́n èyíkéyìí tí ó bá sì dìde sí ọ nínú ìdájọ́ ni ìwọ yóò dá lẹ́bi. Èyí ni ohun ìní àjogúnbá àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà, ọ̀dọ̀ mi sì ni òdodo wọn ti wá.”—Aísá. 54:17.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 22]

Ọlọ́run kò ní jẹ́ kí wọ́n pa àwọn èèyàn òun run